Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ó Dá Òrùka Náà Padà Sọ́wọ́ Wọn

Ó Dá Òrùka Náà Padà Sọ́wọ́ Wọn

Ó Dá Òrùka Náà Padà Sọ́wọ́ Wọn

“WO ỌWỌ́ mi. Ǹjẹ́ o ríyàtọ̀ kankan?” Báyìí ni ọkùnrin kan ṣe na ọwọ́ rẹ̀ sí obìnrin kan tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, obìnrin náà wò ó lóòótọ́, ló bá rí i pé òrùka ìgbéyàwó ò sí lọ́wọ́ ọkùnrin náà mọ́. Ó ṣàlàyé pé àjọṣe òun àti aya òun ò wọ̀ mọ́, làwọn bá pinnu pé àwọn yóò kọra sílẹ̀. Ẹlẹ́rìí náà wí pé: “Rárá o! Gba ìwé yìí, kí ẹ lọ kà á. Yóò ràn yín lọ́wọ́ nípa ìgbéyàwó yín.” Bó ṣe fún un ní ẹ̀dà ìwé kan táa gbé ka Bíbélì nìyẹn, ìyẹn ni ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. a

Ní ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà, ọkùnrin náà padà wá sọ́dọ̀ Ẹlẹ́rìí náà tayọ̀tayọ̀. Ó fi ọwọ́ rẹ̀ hàn án. Lọ́tẹ̀ yìí, òrùka ìgbéyàwó rẹ̀ ti wà lọ́wọ́ rẹ̀. Ó sọ fún un pé, òun àti aya òun ti ka ìwé Ìmọ̀, àwọn sì ti ń láyọ̀ báyìí. Ìwé táà ń wí yìí ti dá òrùka náà padà sọ́wọ́ wọn.

Ìmọ̀ràn Bíbélì lè ran ọkọ àti aya kan lọ́wọ́ láti fi ojúlówó ìfẹ́ hàn sí ara wọn. Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé Ẹlẹ́dàá wa ló ṣe Bíbélì. Òun lẹni tó sọ pé: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn.”—Aísáyà 48:17.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ló tẹ̀ ẹ́ jáde.