Jèhófà—Alágbára Ńlá
Jèhófà—Alágbára Ńlá
“Nítorí ọ̀pọ̀ yanturu okun rẹ̀ alágbára gíga, àti ní ti pé òun ní okun inú nínú agbára, kò sí ìkankan nínú wọn tí ó dàwáàrí.”—AÍSÁYÀ 40:26.
1, 2. (a) Orísun agbára tó ṣeé fojú rí wo ni gbogbo wa gbára lé? (b) Ṣàlàyé bó ṣe jẹ́ pé Jèhófà ní Orísun gbogbo agbára pátápátá.
AGBÁRA jẹ́ ohun kan tí ọ̀pọ̀ lára wa kò fi bẹ́ẹ̀ kà sí. Fún àpẹẹrẹ, agbára káká la fi ń ronú kan agbára iná mànàmáná tó ń fún wa ní ìmọ́lẹ̀ àti ooru tàbí tí ń mú kó rọrùn fún wa láti lo ẹ̀rọ abánáṣiṣẹ́ èyíkéyìí táa bá ní. Àyàfi ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan tí wọ́n bá múná lọ la máa ń rántí pé láìsí agbára iná mànàmáná, nǹkan ò lè lọ déédéé láwọn ìlú ńláńlá wa. Ọ̀pọ̀ jù lọ iná mànàmáná táa gbára lé ló máa ń wá lọ́nà tí kò ṣe tààrà láti orísun agbára tí ilẹ̀ ayé gbára lé jù lọ—ìyẹn ni oòrùn. a Ní ìṣẹ́jú àáyá kọ̀ọ̀kan, àwọn ohun tí ń bá oòrùn ṣiṣẹ́ yìí máa ń lo mílíọ̀nù márùn-ún tọ́ọ̀nù agbára átọ́ọ̀mù láti fún ilẹ̀ ayé ní agbára tí ń gbẹ́mìí ró.
2 Ibo ni gbogbo agbára inú oòrùn yìí ti ń wá? Ta ló dá ilé iṣẹ́ amúnáwá tí ń bẹ lájùlé ọ̀run yìí? Jèhófà Ọlọ́run ni. Nígbà tí Sáàmù 74:16 ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ó ní: “Ìwọ tìkára rẹ ni ó pèsè orísun ìmọ́lẹ̀ sílẹ̀, àní oòrùn.” Dájúdájú, Jèhófà ni Orísun gbogbo agbára pátápátá, àní gẹ́gẹ́ bó ṣe jẹ́ pé òun ni Orísun gbogbo ìwàláàyè. (Sáàmù 36:9) A kò gbọ́dọ̀ fojú di agbára rẹ̀ láé. Nípasẹ̀ wòlíì Aísáyà, Jèhófà rán wa létí pé, ká bojú wo àwọn ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lókè ọ̀run, àwọn nǹkan bí oòrùn àti òṣùpá, kí a sì ronú nípa bí wọ́n ṣe déhìn-ín. “Ẹ gbé ojú yín sókè réré, kí ẹ sì wò. Ta ni ó dá nǹkan wọ̀nyí? Ẹni tí ń mú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn jáde wá ni, àní ní iye-iye, àwọn tí ó jẹ́ pé àní orúkọ ni ó fi ń pe gbogbo wọn. Nítorí ọ̀pọ̀ yanturu okun rẹ̀ alágbára gíga, àti ní ti pé òun ní okun inú nínú agbára, kò sí ìkankan nínú wọn tí ó dàwáàrí.”—Aísáyà 40:26; Jeremáyà 32:17.
3. Báwo la ṣe ń jàǹfààní nínú bí Jèhófà ṣe ń lo agbára rẹ̀?
3 Níwọ̀n bí Jèhófà ti jẹ́ alágbára ńlá, ẹ jẹ́ ká lọ fọkàn wa balẹ̀ pé oòrùn kò ní dẹ́kun àtimáa fún wa ní ìmọ́lẹ̀ àti ooru tí a nílò fún ìwàláàyè wa. Àmọ́ ṣá o, ohun táa nílò agbára Ọlọ́run fún ju àwọn ohun ti ara tó jẹ́ kòṣeémánìí lọ. Báa ṣe rà wá padà nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, ìrètí táa ní nípa ọjọ́ ọ̀la, àti ìgbẹ́kẹ̀lé táa ní nínú Jèhófà, gbogbo rẹ̀ ló so pọ̀ mọ́ bó ṣe ń lo agbára rẹ̀. (Sáàmù 28:6-9; Aísáyà 50:2) Bíbélì kún fún ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ tó jẹ́rìí sí agbára tí Jèhófà ní láti ṣẹ̀dá àti láti rani padà, láti gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là àti láti pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ run.
Agbára Ọlọ́run Hàn Kedere Nínú Ìṣẹ̀dá
4. (a) Ipa wo ni òfuurufú tí Dáfídì ń wò ní alaalẹ́ ní lórí rẹ̀? (b) Kí ni àwọn ìṣẹ̀dá tí ń bẹ ní ọ̀run fi hàn nípa agbára Ọlọ́run?
4 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé “agbára ayérayé” ẹlẹ́dàá wa ‘ni a lè fòye mọ̀ kedere láti inú àwọn ohun tí ó dá.’ (Róòmù 1:20) Láwọn ọ̀rúndún tó ṣáájú, onísáàmù náà, Dáfídì, tó jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn ti ní láti máa wo ojú òfuurufú ní alaalẹ́, tí yóò ti máa fòye mọ bí a ṣe ṣe àgbáálá ayé lógo tó, àti bí agbára Olùṣẹ̀dá rẹ̀ ti tó. Ó kọ̀wé pé: “Nígbà tí mo rí ọ̀run rẹ, àwọn iṣẹ́ ìka rẹ, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tí o ti pèsè sílẹ̀, kí ni ẹni kíkú tí o fi ń fi í sọ́kàn, àti ọmọ ará ayé tí o fi ń tọ́jú rẹ̀?” (Sáàmù 8:3, 4) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ̀nba ìmọ̀ díẹ̀ ni Dáfídì ní nípa àwọn ìṣẹ̀dá tí ń bẹ ní ọ̀run, síbẹ̀ ó mọ̀ pé òun ò já mọ́ nǹkankan rárá táa bá fi òun wé Ẹlẹ́dàá àgbáálá ayé wa tó lọ salalu yìí. Lónìí, àwọn onímọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀dá inú sánmà mọ ohun tó pọ̀ gan-an nípa bí àgbáálá ayé ṣe tóbi tó àti nípa agbára tó mú un dúró. Fún àpẹẹrẹ, wọ́n sọ fún wa pé agbára tí oòrùn wa máa ń tú jáde ní ìṣẹ́jú àáyá kọ̀ọ̀kan dọ́gba pẹ̀lú agbára tí ọ̀kẹ́ márùn-ún mílíọ̀nù tọ́ọ̀nù bọ́ǹbù TNT ń tú jáde. b Ìwọ̀nba díẹ̀ bíńtín lára agbára yẹn ló ń dé ilẹ̀ ayé o; síbẹ̀ ìwọ̀nba díẹ̀ yẹn ti tó láti gbé gbogbo ẹ̀mí tó wà lórí ilẹ̀ ayé wa ró. Síbẹ̀síbẹ̀, kì í ṣe oòrùn tiwa yìí ni ìràwọ̀ tó lágbára jù lọ nínú àwọn ọ̀run o. Àwọn ìràwọ̀ kan wà tó jẹ́ pé agbára tí wọ́n ń tú jáde ní ìṣẹ́jú àáyá kọ̀ọ̀kan péré tó gbogbo èyí tí oòrùn wa ń fi odindi ọjọ́ kan tú jáde o. Tó bá wá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ náà wá fojú inú wo bí agbára Ẹni tó dá irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ sájùlé ọ̀run yóò ti pọ̀ tó! Abájọ tí Élíhù fi kókìkí pé: “Ní ti Olódùmarè, àwa kò lè rídìí rẹ̀; ó ga ní agbára.”—Jóòbù 37:23.
5. Kí ni ẹ̀rí agbára Jèhófà tí a rí nínú iṣẹ́ rẹ̀?
5 Tí a bá ‘wá iṣẹ́ Ọlọ́run kiri’ bí Dáfídì ti ṣe, a ó rí ẹ̀rí agbára rẹ̀ níbi gbogbo—ì báà jẹ́ nínú ẹ̀fúùfù àti ìgbì omi, nínú àrá àti mànàmáná, tàbí nínú àwọn alagbalúgbú odò àtàwọn òkè ńláńlá. (Sáàmù 111:2; Jóòbù 26:12-14) Síwájú sí i, gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ṣe rán Jóòbù létí, àwọn ẹranko pàápàá ń jẹ́rìí sí i pé Ó lágbára tó pọ̀. Lára àwọn wọ̀nyí ni Béhémótì, tàbí erinmi. Jèhófà sọ fún Jóòbù pé: “Agbára rẹ̀ wà ní ìgbáròkó rẹ̀ . . . Egungun rẹ̀ lílágbára dà bí àwọn ọ̀pá irin àsèjiná.” (Jóòbù 40:15-18) Bí ẹní mowó ní wọ́n ṣe mọ̀ nípa agbára tí akọ màlúù ìgbẹ́ ní láwọn àkókò tí wọ́n kọ Bíbélì, Dáfídì sì gbàdúrà pé kí a pa òun mọ́ kúrò ‘ní ẹnu kìnnìún àti kúrò lọ́wọ́ ìwo akọ màlúù ìgbẹ́.”—Sáàmù 22:21; Jóòbù 39:9-11.
6. Kí ni akọ màlúù ṣàpẹẹrẹ nínú Ìwé Mímọ́, èé ṣe tí ó sì fi jẹ́ bẹ́ẹ̀? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
6 Nítorí agbára tí akọ màlúù ní, a lò ó nínú Bíbélì láti ṣàpèjúwe agbára Jèhófà. c Ìran tí àpọ́sítélì Jòhánù rí nípa ìtẹ́ Jèhófà ṣàpèjúwe ẹ̀dá alààyè mẹ́rin, tí ọ̀kan nínú wọn ní ojú bíi ti akọ màlúù. (Ìṣípayá 4:6, 7) Láìsí àní-àní, ọ̀kan lára ànímọ́ Jèhófà tó ṣe kókó tí àwọn kérúbù wọ̀nyí ń fi hàn ni agbára. Àwọn mìíràn ni ìfẹ́, ọgbọ́n, àti ìdájọ́ òdodo. Níwọ̀n bí a ti rí i pé agbára jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ànímọ́ Ọlọ́run, lílóye agbára rẹ̀ dáradára, kí a sì mọ bó ṣe ń lò ó yóò mú kí a túbọ̀ sún mọ́ ọn, yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti fara wé àpẹẹrẹ rẹ̀ nípa lílo agbára èyíkéyìí tó bá wà níkàáwọ́ wa dáradára—Éfésù 5:1.
“Jèhófà Àwọn Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun, Ẹni Alágbára”
7. Báwo ló ṣe dá wa lójú pé rere ni yóò borí ibi?
7 Nínú Ìwé Mímọ́, a pe Jèhófà ní “Ọlọ́run Olódùmarè,” orúkọ oyè kan tó ń rán wa létí pé a kò gbọ́dọ̀ fojú di agbára rẹ̀ tàbí kí a máa ṣiyèméjì pé bóyá ló lágbára tó láti ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 17:1; Ẹ́kísódù 6:3) Ètò àwọn nǹkan búburú ti Sátánì lè dà bí ohun tó ti fẹsẹ̀ rinlẹ̀ dáadáa o, àmọ́ lójú Jèhófà, “àwọn orílẹ̀-èdè dà bí ẹ̀kán omi kan láti inú korobá; bí ekuru fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ lórí òṣùwọ̀n sì ni a kà wọ́n sí.” (Aísáyà 40:15) A dúpẹ́ pé irú agbára yìí ń bẹ lọ́wọ́ Ọlọ́run, nígbà náà, kò sí àní-àní pé bó ti wù ó rí, rere ni yóò borí ibi. Nígbà tí ìwà ibi bá gbalẹ̀ kan, a lè fọkàn balẹ̀ nítorí tí a mọ̀ pé “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ẹni Alágbára Ísírẹ́lì” yóò mú ibi kúrò títí láé.—Aísáyà 1:24: Sáàmù 37:9, 10.
8. Àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run wo ni Jèhófà ń pàṣẹ fún, ẹ̀rí wo ló sì fi agbára wọn hàn?
8 Ọ̀rọ̀ náà, “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun,” tó fara hàn nígbà ọ̀ọ́dúnrún dín mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [285] nínú Bíbélì, jẹ́ ọ̀nà mìíràn láti ránni létí agbára Ọlọ́run. “Ẹgbẹ́ ọmọ ogun” tí a mẹ́nu kàn níhìn-ín ni ogunlọ́gọ̀ ẹ̀dá ẹ̀mí tí Jèhófà ní níkàáwọ́. (Sáàmù 103:20, 21; 148:2) Ní òru ọjọ́ kan péré mà ni ọ̀kan ṣoṣo lára àwọn áńgẹ́lì wọ̀nyí pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [185,000] àwọn ọmọ ogun Ásíríà tí wọ́n ń gbèrò àtipa Jerúsálẹ́mù run. (2 Àwọn Ọba 19:35) Bí a bá mọ agbára tí àwọn ọmọ ogun Jèhófà tí ń bẹ lókè ọ̀run ní, kò ní rọrùn fún àwọn alátakò láti dáyà fò wá. Wòlíì Èlíṣà kò mikàn rárá nígbà tí àwọn ọmọ ogun tí wọ́n ń wá a, wá ká a mọ́lé, nítorí pé, láìṣe bíi ti ìránṣẹ́ rẹ̀, ó lè fojú ìgbàgbọ́ rí ogunlọ́gọ̀ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run tí wọ́n wà lẹ́yìn rẹ̀.—2 Àwọn Ọba 6:15-17.
9. Bíi ti Jésù, èé ṣe tó fi yẹ kí a ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ààbò Ọlọ́run?
9 Bákan náà ni Jésù ṣe gbára lé ìtìlẹ́yìn àwọn áńgẹ́lì nígbà tí àwọn èèyànkéèyàn wá yọ ọ̀kọ̀ àti àdá lọ́wọ́ wá bá a ní ọgbà Gẹtisémánì. Lẹ́yìn tó sọ fún Pétérù pé kó dá ọ̀kọ̀ rẹ̀ padà sí àyè rẹ̀, Jésù sọ fún un pé, tó bá pọndandan, Òun lè ké gbàjarè sí Baba òun láti fún òun ní “àwọn áńgẹ́lì tí ó ju líjíónì méjìlá.” (Mátíù 26:47, 52, 53) Báwa náà bá mọrírì àwọn ọmọ ogun ọ̀run tó wà níkàáwọ́ Ọlọ́run, a óò ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún pé, Ọlọ́run yóò tì wá lẹ́yìn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kí wá ni àwa yóò sọ sí nǹkan wọ̀nyí? Bí Ọlọ́run bá wà fún wa, ta ni yóò wà lòdì sí wa?”—Róòmù 8:31.
10. Àwọn wo ni Jèhófà ń tìtorí wọn lo agbára rẹ̀?
10 Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìdí wà fún wa láti gbẹ́kẹ̀ lé ààbò Jèhófà. Ó máa ń lo agbára rẹ̀ fún àǹfààní wa, ó sì máa ń lò ó lọ́nà tí kò fi ní forí gbárí pẹ̀lú àwọn ànímọ́ rẹ̀ mìíràn—ìyẹn ni ìdájọ́ òdodo, ọgbọ́n, àti ìfẹ́. (Jóòbù 37:23; Jeremáyà 10:12) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ńṣe làwọn alágbára sábà máa ń fọwọ́ ọlá gbá àwọn òtòṣì àtàwọn ẹni rírẹlẹ̀ lójú, ńṣe ni Jèhófà “ń gbé ẹni rírẹlẹ̀ dìde àní láti inú ekuru,” ó sì “pọ̀ gidigidi ní agbára láti gbani là.” (Sáàmù 113:5-7; Aísáyà 63:1) Gẹ́gẹ́ bí Màríà, ìyá Jésù, obìnrin oníwọ̀ntúnwọ̀nsì, ẹni tí kò ro ara rẹ̀ ju bó ti yẹ lọ yẹn, ṣe lóye rẹ̀, “Ẹni alágbára” náà máa ń lo agbára rẹ̀ nítorí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ láìṣojúṣàájú, ó ń rẹ onírera sílẹ̀, ó sì ń gbé ẹni rírẹlẹ̀ ga.—Lúùkù 1:46-53.
Jèhófà Fi Agbára Rẹ̀ Hàn fún Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀
11. Kí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí tó jẹ́rìí sí agbára Ọlọ́run lọ́dún 1513 ṣááju Sànmánì Tiwa?
11 Lọ́pọ̀ ìgbà ni Jèhófà ti fi agbára rẹ̀ hàn fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Ọ̀kan lára rẹ̀ ni ti Òkè Sínáì ní ọdún 1513 ṣááju Sànmánì Tiwa. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti kọ́kọ́ rí ẹ̀rí tó jinlẹ̀ nípa agbára Ọlọ́run nínú ọdún kan náà yẹn. Àwọn ìyọnu mẹ́wàá tí ń sọni di ahoro ti fi hàn pé alágbára ńlá ni Jèhófà , ó sì ti fi hàn pé ọlọ́run àwọn ara Íjíbítì ò lè ta pútú rárá. Kété lẹ́yìn ìyẹn, bí wọ́n ṣe sọdá Òkun pupa lọ́nà ìyanu àti bí àwọn ọmọ ogun Fáráò ṣe ṣègbé túbọ̀ fi ẹ̀rí hàn pé agbára ń bẹ lọ́wọ́ Ọlọ́run. Oṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà, ní ẹsẹ̀ Òkè Sínáì, Jèhófà ké sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti di ‘àkànṣe dúkìá òun nínú gbogbo àwọn ènìyàn yòókù.’ Àwọn náà sì ṣèlérí pé: “Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ ni àwa ti múra tán láti ṣe.” (Ẹ́kísódù 19:5, 8) Lẹ́yìn náà ni Jèhófà wá fi agbára rẹ̀ hàn wọ́n gan-an. Bí ààrá ti ń sán, tí mànàmáná ń kọ yẹ̀rì, tí ìró ipè ń dún lákọlákọ, bẹ́ẹ̀ ni èéfín bẹ̀rẹ̀ sí yọ lórí Òkè Sínáì, tí gbogbo ilẹ̀ sì mì tìtì. Gbogbo àwọn ènìyàn náà tó dúró sọ́ọ̀ọ́kán ló wá rìrì. Àmọ́, Mósè sọ fún wọn pé ìrírí yìí gbọ́dọ̀ kọ́ wọn ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, ìbẹ̀rù tí yóò sún wọn láti ṣègbọràn sí alágbára gbogbo àti Ọlọ́run òtítọ́ kan ṣoṣo náà, Jèhófà.—Ẹ́kísódù 19:16-19; 20:18-20.
12, 13. Ipò wo ló mú kí Èlíjà fi iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀, àmọ́, báwo ni Jèhófà ṣe fún un lókun?
12 Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn ìyẹn, nígbà ayé Èlíjà, Ọlọ́run tún fi agbára rẹ̀ hàn lẹ́ẹ̀kan sí i ní Òkè Sínáì. Wòlíì náà tí kọ́kọ́ rí i bí agbára Ọlọ́run ṣe ń ṣiṣẹ́. Nítorí pé fún ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ gbáko ni Ọlọ́run fi “ti àwọn ọ̀run” nítorí ìpẹ̀yìndà orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. (2 Kíróníkà 7:13) Láàárín àkókò ọ̀dá yẹn, àwọn ẹyẹ ìwò ló ń bọ́ Èlíjà ní àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Kẹ́rítì, lẹ́yìn náà ni ìyẹ̀fun kékeré àti òróró díẹ̀ tí obìnrin opó kan ní di èyí tí a sọ di púpọ̀ lọ́nà ìyanu, kí ó lè máa tibẹ̀ rí oúnjẹ jẹ. Jèhófà tiẹ̀ tún fún Èlíjà lágbára láti jí ọmọ opó yìí dìde. Níkẹyìn, níbi tí wọ́n ti ṣe ìdánwò ńlá tó múni gbọ̀n rìrì, èyí tí wọ́n fi mọ Ọlọ́run tòótọ́ ní Òkè Ńlá Kámẹ́lì, iná bọ́ sílẹ̀ láti òkè ọ̀run, ó sì jó ẹbọ Èlíjà. (1 Àwọn Ọba 17:4-24; 18:36-40) Síbẹ̀síbẹ̀, ẹ̀rù ba Èlíjà, ó sì rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí Jésíbẹ́lì lérí pé òun ó pa á. (1 Àwọn Ọba 19:1-4) Ló bá sá fi orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀, lérò pé iṣẹ́ òun gẹ́gẹ́ bíi wòlíì ti parí nìyẹn. Kí Jèhófà lè fi í lọ́kàn balẹ̀, kó sì fún un lókun, ó fúnra rẹ̀ fi agbára àtọ̀runwá hàn án.
13 Nígbà tí Èlíjà sá pa mọ́ sínú hòrò kan, ó rí agbára mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tó jẹ́ ohun ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ tí Jèhófà ń darí: ẹ̀fúùfù líle, ìsẹ̀lẹ̀, àti iná. Síbẹ̀, nígbà tí Jèhófà fẹ́ bá Èlíjà sọ̀rọ̀, “ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, rírẹlẹ̀” ló fi bá a sọ̀rọ̀. Ó fún un ni iṣẹ́ púpọ̀ sí i láti ṣe, ó sì tún sọ fún un pé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin ènìyàn mìíràn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ṣì wà ní ilẹ̀ náà. (1 Àwọn Ọba 19:9-18) Tó bá ṣẹlẹ̀ pé, bíi ti Èlíjà, ó ṣe wá bí ẹni pé a fẹ́ rẹ̀wẹ̀sì nítorí àìsí àṣeyọrí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, a lè bẹ Jèhófà pé kí ó fún wa ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá”—agbára tó lè fún wa lókun láti máa bá wíwàásù ìhìn rere náà lọ láìdábọ̀.—2 Kọ́ríńtì 4:7.
Agbára Jèhófà Jẹ́ Ẹ̀rí Ìdánilójú Pé Yóò Mú Ìlérí Rẹ̀ Ṣẹ
14. Kí ni orúkọ Jèhófà fúnra rẹ̀ fi hàn, báwo sì ni agbára rẹ̀ ṣe so pọ̀ mọ́ orúkọ rẹ̀?
14 Agbára Jèhófà tún ní í ṣe gidigidi pẹ̀lú orúkọ rẹ̀ àti mímú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Orúkọ aláìlẹ́gbẹ́ náà, Jèhófà, tó túmọ̀ sí “Alèwílèṣe,” fi hàn pé Jèhófà jẹ́ ẹni tó máa ń mú kí àwọn ìlérí Òun ṣẹ. Bó ti wù kí àwọn oníyèméjì máa kọminú nípa àwọn ète Ọlọ́run tó, kò sí ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni tó lè dí Ọlọ́run lọ́wọ́ pé kí àwọn ète rẹ̀ má ṣẹ. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ nígbà kan, “lọ́dọ̀ Ọlọ́run ohun gbogbo ṣeé ṣe.”—Mátíù 19:26.
15. Báwo lá ṣe rán Ábúráhámù àti Sárà létí pé kò sí ohun tó jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ jù fún Jèhófà?
15 Láti ṣàkàwé èyí, Jèhófà ṣèlérí fún Ábúráhámù àti Sárà nígbà kan pé òun ó sọ àwọn àtọmọdọ́mọ wọn di orílẹ̀-èdè ńlá. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ọdún ni wọ́n fi wà láìbímọ. Àwọn méjèèjì tí di arúgbó nígbà tí Jèhófà sọ fún wọn pé ìlérí náà ti fẹ́ ní ìmúṣẹ, ni Sárà bá bú sẹ́rìn-ín. Áńgẹ́lì náà fèsì pé: “Ohunkóhun ha ṣe àrà ọ̀tọ̀ jù fún Jèhófà bí?” (Jẹ́nẹ́sísì 12:1-3; 17:4-8; 18:10-14) Irínwó ọdún lẹ́yìn náà, nígbà tí Mósè kó àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù jọ—àwọn tí wọ́n ti di orílẹ̀-èdè ńlá báyìí—ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù, ó rán wọn létí pé Ọlọ́run ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Mósè sọ pé: “Ìwọ ṣì ń bá a lọ láti wà láàyè, nítorí tí [Jèhófà] nífẹ̀ẹ́ àwọn baba ńlá rẹ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi yan irú-ọmọ wọn lẹ́yìn wọn, tí ó sì mú ọ jáde kúrò ní Íjíbítì ní ojú rẹ̀ nípasẹ̀ agbára ńlá rẹ̀, láti lé àwọn orílẹ̀-èdè tí ó tóbi, tí ó sì jẹ́ alágbára ńlá jù ọ́ lọ, kúrò níwájú rẹ, kí a bàa lè mú ọ wọlé, láti fi ilẹ̀ wọn fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí lónìí yìí.”—Diutarónómì 4:37, 38.
16. Èé ṣe tí àwọn Sadusí fi ṣìnà pátápátá láti sọ pé àjíǹde àwọn òkú kò sí?
16 Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, àwọn Sadusí tí kò nígbàgbọ́ nínú àjíǹde gbọ́ wábiwọ́sí ọ̀rọ̀ lẹ́nu Jésù. Èé ṣe tí wọ́n fi kọ̀ láti gba ìlérí tí Ọlọ́run ṣe gbọ́ pé òun óò mú àwọn òkú padà wà láàyè? Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ kò mọ Ìwé Mímọ́ tàbí agbára Ọlọ́run.” (Mátíù 22:29) Ìwé Mímọ́ mú un dá wa lójú pé ‘gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn Ọmọ ènìyàn, wọn yóò sì jáde wá.’ (Jòhánù 5:27-29) Bí a bá mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa àjíǹde, ìgbọ́kànlé tí a ní nínú agbára Ọlọ́run yóò jẹ́ kó dá wa lójú pé a óò jí àwọn òkú dìde. Ọlọ́run “yóò gbé ikú mì títí láé, . . . nítorí pé Jèhófà tìkára rẹ̀ ti sọ ọ́.”—Aísáyà 25:8.
17. Àkókò wo lọ́jọ́ iwájú ni gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà yóò pọndandan lọ́nà àrà ọ̀tọ̀?
17 Láìpẹ́ sí àkókò táa wà yìí, àkókò kan yóò dé nígbà tí yóò pọndandan fún olúkúlùkù wa láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé àrà ọ̀tọ̀ nínú agbára Ọlọ́run tó lè gbani là. Sátánì Èṣù yóò gbógun ti àwọn ènìyàn Ọlọ́run, àwọn tó máa dà bí ẹni pé wọn ò láàbò. (Ìsíkíẹ́lì 38:14-16) Ìgbà yẹn ni Ọlọ́run yóò wá fi agbára ńlá rẹ̀ hàn nítorí tiwa, gbogbo èèyàn yóò sì wá mọ̀ pé òun ni Jèhófà. (Ìsíkíẹ́lì 38:21-23) Ìsinsìnyí ló yẹ ká gbé ìgbàgbọ́ àti ìgbọ́kànlé táa ní nínú Ọlọ́run Olódùmarè ró, kí a má bàá yẹsẹ̀ ní àkókò líle koko yẹn.
18. (a) Àwọn àǹfààní wo la rí nínú ṣíṣàsàrò lórí agbára Jèhófà? (b) Ìbéèrè wo la óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e?
18 Láìsí àní-àní, ọ̀pọ̀ ìdí ló wà fún wa táa fi ní láti ṣe àṣàrò lórí agbára Jèhófà. Bí a ṣe ń ronú lórí àwọn iṣẹ́ rẹ̀, a ń fi ìrẹ̀lẹ̀ sún wa láti yin Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá wa lógo, kí a sì dúpẹ́ pé ó ń lo agbára rẹ̀ lọ́nà tó fi ọgbọ́n àti ìfẹ́ hàn. Kò sí ẹni tí yóò lè dẹ́rù bà wá bí a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ẹgbẹ́ ọmọ ogun. Ìgbàgbọ́ tí a ní nínú àwọn ìlérí rẹ̀ kò sì ní yẹ̀ láé. Àmọ́ ṣá o, ẹ rántí pé àwòrán Ọlọ́run la dá wa. Nípa bẹ́ẹ̀, àwa náà lágbára—àmọ́, ó níbi tó mọ. Báwo la ṣe lè fara wé Ẹlẹ́dàá wa nínú ọ̀nà táa gbà ń lo agbára wa? Èyí la óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ ni pé àwọn ohun amúnájó tí a ń wà jáde nínú ilẹ̀, irú bíi pẹtiróòlù àti èédú—tó jẹ́ olórí orísun agbára tí àwọn ilé iṣẹ́ iná mànàmáná wa máa ń lò—ń gba agbára láti inú oòrùn.
b Ní ìfiwéra, nínú gbogbo bọ́ǹbù tí wọ́n tíì dán wò lágbàáyé, èyí tó lágbára jù lọ níbẹ̀ ni èyí tí agbára tó ń tú jáde tó mílíọ̀nù mẹ́tàdínlọ́gọ́ta tọ́ọ̀nù bọ́ǹbù TNT.
c Akọ màlúù ìgbẹ́ tí a tọ́ka sí nínú Bíbélì ní láti jẹ́ ẹhànnà akọ màlúù (urus lédè Látìn). Ní ẹgbàá ọdún sẹ́yìn, a rí àwọn ẹranko wọ̀nyí ní Gaul (tí a ń pè ní ilẹ̀ Faransé báyìí), ohun tí Julius Caesar sì kọ nípa wọn nìyí: “Àwọn urí wọ̀nyí tóbi tó erin dáadáa, àmọ́, nínú ìṣe, àwọ̀, àti ní ìrísí wọn, akọ màlúù ni wọ́n. Agbára wọn pọ̀, eré sì ń bẹ lẹ́sẹ̀ wọn: tí wọn bá fi lè rí ènìyàn tàbí ẹranko, kíá ni wọn óò yọwọ́ ìjà.”
Ǹjẹ́ O Lè Dáhùn Àwọn Ìbéèrè Wọ̀nyí?
• Báwo ni ìṣẹ̀dá ṣe jẹ́rìí sí agbára Jèhófà?
• Ẹgbẹ́ ọmọ ogun wo ni Jèhófà lè lò láti ti àwọn ènìyàn rẹ̀ lẹ́yìn?
• Àwọn àkókò wo ni Jèhófà fi agbára rẹ̀ hàn?
• Ẹ̀rí ìdánilójú wo la ní pé Jèhófà yóò mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
“Ẹ gbé ojú yín sókè réré, kí ẹ sì wò. Ta ni ó dá nǹkan wọ̀nyí?”
[Credit Line]
Fọ́tò látọwọ́ Malin, © IAC/RGO 1991
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ṣíṣàṣàrò lórí àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà fi agbára rẹ̀ hàn ń gbé ìgbàgbọ́ tí a ní nínú àwọn ìlérí rẹ̀ ró