Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó Yẹ Kóo Mọ̀ Nípa Àjẹ́ Ṣíṣe

Ohun Tó Yẹ Kóo Mọ̀ Nípa Àjẹ́ Ṣíṣe

Ohun Tó Yẹ Kóo Mọ̀ Nípa Àjẹ́ Ṣíṣe

Ó ṢÒRO láti ṣàlàyé ohun tí àjẹ́ ṣíṣe jẹ́ lóde òní. Ìdí ni pé ọ̀kan-ò-jọ̀kan làwọn tó ń ṣe é. Wọn ò ní ẹni pàtó kan tó ń darí gbogbo wọn, wọn ò sì ní ẹ̀kọ́ tàbí ìwé mímọ́ tó lè mú ìgbàgbọ́ wọn ṣọ̀kan. Bákan náà, àṣà wọn, bí wọ́n ṣe ń ṣe nǹkan, ààtò ìsìn wọn, àti èrò wọn nípa òrìṣà tó yẹ kí wọ́n máa bọ ò dọ́gba. Òǹkọ̀wé kan sọ pé: “Wíwọ ẹgbẹ́ awo ń jẹ́ kí èèyàn wọnú ẹgbẹ́ àwọn tó ní ‘èròǹgbà tó pọ̀ lọ jàra.’” Òmíràn sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ohun tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Abọ̀rìṣà Lákọ̀tun fohùn ṣọ̀kan lé lórí.”

Lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn, àwọn àìfohùnṣọ̀kan náà kì í ṣe ìṣòro. Ìwé atọ́nà kan tí wọ́n ṣe fún àwọn tó ń fẹ́ di àjẹ́ sọ pé: “Tí wọ́n bá gbé àwọn ọ̀rọ̀ kan tó jọ pé ó ta kora ka iwájú ẹ, yiiri àwọn ọ̀rọ̀ náà wò dáadáa kí o sì pinnu èyí tí wàá mú. Ohun tí ọkàn ẹ bá ní kóo ṣe ni kóo ṣe. Lédè mìíràn, ìwọ sáà mú lára àwọn ààtò tí a tẹ̀ jáde àti àwọn ìwé àkànlò ààtò ìsìn láti pinnu ohun tóo gbà pé ó tọ́.”

Ní ti àwọn tó mọ bí òtítọ́ ṣe rí, ìṣòro ni irú àwọn àìfohùnṣọ̀kan bẹ́ẹ̀ jẹ́. Kò sí tàbí ṣùgbọ́n nínú òtítọ́, ohun tó ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ ni. Kì í ṣe nítorí pé èèyàn kan ronú tàbí ó retí tàbí ó gbà gbọ́ pé ohun kan jẹ́ òótọ́ ló mú kí nǹkan náà jẹ́ òtítọ́. Fún àpẹẹrẹ, ní àkókò kan, àwọn dókítà gbà gbọ́ pé àwọn lè wo ẹni tó ní òtútù àyà sàn nípa gígé òòyẹ̀ adìyẹ sí méjì, kí àwọn sì na awẹ́ méjèèjì lé onítọ̀hún láyà. Ó dájú pé ọ̀pọ̀ àwọn tí àìsàn yìí ń ṣe fi tọkàntọkàn gbà gbọ́ pé ọ̀nà ìtọ́jú yìí á mú kí ara àwọn yá. Ṣùgbọ́n, ìgbàgbọ́ àti ìrètí wọn yìí kì í ṣe òótọ́—irú ìtọ́jú yẹn ò lè wo òtútù àyà sàn. Òótọ́ ò ṣeé ṣẹ̀dá; èèyàn máa ń sapá láti lóye rẹ̀ ni.

Bíbélì sọ pé òún ní òtítọ́ nípa àwọn ọ̀ràn tẹ̀mí nínú. Nígbà tí Jésù Kristi wà láyé, ó gbàdúrà sí bàbá rẹ̀ pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòhánù 17:17) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí.” (2 Tímótì 3:16) Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń ṣe àjẹ́ kò gbà bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń wá agbára ìsúnniṣe àti ìtọ́sọ́nà nínú ìtàn àtẹnudẹ́nu, àwọn ẹ̀sìn ayé àtijọ́, àti nínú àròsọ inú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ pàápàá. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ kò bọ́gbọ́n mu kéèyàn tiẹ̀ gbé ohun tí Bíbélì sọ yẹ̀ wò? Ó ṣe tán, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ayé ló gbà pé ìwé mímọ́ ni. Ó tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìwé ìsìn tó tíì pẹ́ jù lọ tó ṣì wà. Ó gba àwọn tó kọ Bíbélì ní ẹgbẹ̀jọ ọdún, síbẹ̀ gbogbo ẹ̀kọ́ inú rẹ̀ ò fìkan pe méjì. Ẹ jẹ́ ká fi àwọn ohun tí Bíbélì fi kọ́ni wé díẹ̀ lára ohun tí àwọn tó ń ṣagbátẹrù àjẹ́ ṣíṣe gbà gbọ́.

Àwọn Wo Ló Ń Gbé Ilẹ̀ Ọba Ẹ̀mí?

Ìbéèrè pàtàkì kan nínú ọ̀ràn wíwá òye tẹ̀mí kiri ni pé, Àwọn wo ló ń gbé ilẹ̀ ọba ẹ̀mí? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù lára àwọn àjẹ́ ayé ìsinyìí ni ìgbàgbọ́ wọ́n dá lórí bíbọmọlẹ̀, àti onírúurú òòṣà, àwọn kan ń bọ òòṣà ńlá kan tó jẹ́ abo, tí wọ́n gbà pé ó jẹ́ abara-mẹ́ta, èyíinì ni omidan, ìyá, àti arúgbó kùjọ́kùjọ́, tó ṣàpẹẹrẹ ìpele mẹ́ta pàtàkì nínú ìgbésí ayé. Òòṣà kan tó hùwo sì ni ọkọ rẹ̀. Àwọn àjẹ́ míì máa ń bọ òòṣà tó jẹ́ akọ àti òòṣà tó jẹ́ abo pa pọ̀. Òǹkọ̀wé kan sọ pé: “Òòṣà abo àti Ọlọ́run ni wọ́n máa ń wò bí àpẹẹrẹ àwọn takọtabo ẹ̀dá ayé. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló [ní] ànímọ́ aláìlẹ́gbẹ́ tó jẹ́ pé tí a bá pa wọ́n pọ̀, àbájáde rẹ̀ á jẹ́ ṣíṣẹ̀dá ìwàláàyè tó bára mu.” Òǹkọ̀wé míì kọ̀wé pé: “Ọ̀kan lára yíyàn tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú Àjẹ́ Ṣíṣe ni yíyan àwọn òòṣà (Àwọn Òòṣà Akọ àti Àwọn Òòṣà Abo) tí wàá máa bọ. . . . Àjẹ́ tí o ń ṣe á jẹ́ kóo lè yan èyí tóo fẹ́, kóo sì máa bọ Òòṣà tóo yàn.”

Bíbélì ò ti èyíkéyìí lára àwọn èròǹgbà yìí lẹ́yìn. Jésù Kristi ya gbogbo iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ sọ́tọ̀ pátápátá fún kíkọ́ àwọn ẹlòmíràn nípa Jèhófà, “Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà.” (Jòhánù 17:3) Bíbélì sọ pé: “Jèhófà tóbi lọ́lá, ó sì yẹ fún ìyìn gidigidi, ó sì yẹ ní bíbẹ̀rù ju gbogbo ọlọ́run yòókù. Nítorí gbogbo ọlọ́run àwọn ènìyàn jẹ́ àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí.”—1 Kíróníkà 16:25, 26.

Èṣù wá ńkọ́? Ìwé atúmọ̀ èdè náà, Webster’s Ninth New Collegiate Dictionary, sọ pé ṣíṣe àjẹ́ túmọ̀ sí “bíbá èṣù sọ̀rọ̀.” Á ṣòro ká tó lè rí àjẹ́ kan lónìí táá gbà pé òótọ́ ni ìtumọ̀ yìí, nítorí pé púpọ̀ wọn ò tiẹ̀ gbà pé Sátánì Èṣù wà. Èrò ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan, tí ìwé ìròyìn The Irish Times pè ní “ọ̀gá nínú àjẹ́, tó tún jẹ́ aṣáájú ọ̀kan lára ẹgbẹ́ àjẹ́ tó lókìkí jù lọ ní Ireland,” ni pé: “Táa bá gbà gbọ́ pé Èṣù wà, ó fi hàn pé a tẹ́wọ́ gba ẹ̀sìn Kristẹni nìyẹn . . . [Èṣù] ò lè máa gbé àgbáálá ayé níbi tí Ọlọ́run kò sí.”

Bíbélì sọ pé Èṣù wà, ó sì sọ pé òun ló ń fa èyí tó pọ̀ jù nínú ìjìyà àti rúkèrúdò tó ń ṣẹlẹ̀ láyé. (Ìṣípayá 12:12) Jésù ò kàn máa fi kọ́ àwọn èèyàn pé Èṣù wà nìkan, àmọ́ ó tún fi yéni pé èèyàn lè máa ṣe ohun tí Èṣù fẹ́ láìmọ̀. Fún àpẹẹrẹ, àwọn aṣáájú ìsìn ẹlẹ́mìí mo-mọ́-tán ní ọ̀rúndún kìíní sọ pé lọ́nà kan, ọmọ Ọlọ́run làwọn, wọ́n sì gbà gbọ́ pé àwọn ń ṣèfẹ́ Ọlọ́run. Nítorí pé Jésù lè fòye mọ ohun tó wà lọ́kàn wọn, ó mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Ó sọ ọ́ kò wọ́n lójú pé: “Láti ọ̀dọ̀ Èṣù baba yín ni ẹ ti wá, ẹ sì ń fẹ́ láti ṣe àwọn ìfẹ́-ọkàn baba yín.” (Jòhánù 8:44) Síwájú sí i, Bíbélì sọ nínú ìwé Ìṣípayá pé, Èṣù “ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.”—Ìṣípayá 12:9.

Ṣé Iṣẹ́ Òkùnkùn Lè Ṣèèyàn Lóore?

Ó dájú pé iṣẹ́ òkùnkùn jẹ́ ara ìbẹ́mìílò. Ọ̀pọ̀ èèyàn láyé àtijọ́ àti lóde òní ló gbà gbọ́ pé nítorí àtiṣe àwọn èèyàn léṣe làwọn àjẹ́ ṣe máa ń ṣe iṣẹ́ òkùnkùn. Àwọn èèyàn máa ń sọ pé àwọn àjẹ́ lágbára láti fìyà jẹ èèyàn gan-an tàbí kí wọ́n tilẹ̀ pààyàn nípasẹ̀ iṣẹ́ òkùnkùn. Láti ọjọ́ táláyé ti dáyé, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ohun burúkú kan tí àwọn èèyàn kì í sọ pé àwọn àjẹ́ ló fà á, títí kan àìsàn, ikú, àti kí nǹkan oko máà dáa.

Láyé ìsinyìí, àwọn àjẹ́ ò gbà rárá pé òótọ́ ni irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé púpọ̀ wọ́n gbà pé lóòótọ́ làwọn kọ̀ọ̀kan wà tó ń fi àjẹ́ tiwọn ṣìkà, wọ́n ní awo táwọn ń ṣe, àwọn fi ń ṣèèyàn láǹfààní ni, pé àwọn kì í fi ṣebi. Àwọn àjẹ́ Wicca ń fi yé àwọn èèyàn pé àṣegbé ò sí fẹ́ni tó ń ṣe iṣẹ́ òkùnkùn, wọ́n ní ìlọ́po mẹ́ta èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ló máa jẹ, wọ́n sì sọ pé ìyẹn gan-an ló ń fà á tí àwọn kì í fi í ṣépè. Ara àwọn iṣẹ́ awo tí wọ́n sọ pé ó dáa ni ṣíṣe oògùn ìṣọ́rí, tó máa jẹ́ káwọn oògùn burúkú tóo bá nínú ilé rẹ domi, èyí táwọn tó ń gbébẹ̀ tẹ́lẹ̀ ṣe, oògùn ìfẹ́, oògùn kí ara lè yá kí ara sì le, oògùn kí iṣẹ́ má bàa bọ́ lọ́wọ́ ẹ, tàbí oògùn owó. Pẹ̀lú gbogbo agbára wọ̀nyẹn tí wọ́n sọ pé ó wà lọ́wọ́ àwọn àjẹ́, kò yani lẹ́nu pé ṣe làwọn àjẹ́ túbọ̀ ń pọ̀ sí i.

Ṣùgbọ́n Bíbélì kò sọ pé àwọn iṣẹ́ òkùnkùn kan wà tí ń ṣeni lóore tí àwọn kàn kì í sì í ṣeni lóore. Nínú Òfin tí Mósè gbà, Ọlọ́run fi èrò rẹ̀ yé wọn yékéyéké. Ó sọ pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ pidán [ṣiṣẹ́ òkùnkùn].” (Léfítíkù 19:26) A tún kà á pé: “Kí a má ṣe rí láàárín rẹ . . . pidánpidán [oníṣẹ́ òkùnkùn] kan tàbí ẹnikẹ́ni tí ń wá àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí oníṣẹ́ oṣó, tàbí ẹni tí ń fi èèdì di àwọn ẹlòmíràn tàbí ẹnikẹ́ni tí ń wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ abẹ́mìílò.”—Diutarónómì 18:10, 11.

Èé ṣe tí Ọlọ́run fi sọ bẹ́ẹ̀? Kì í ṣe nítorí pé ó fẹ́ fi ohun táá ṣe wá láǹfààní dù wá. Ìdí tí Jèhófà ṣe fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní àwọn òfin yìí ni pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn, kò sì fẹ́ kí ìbẹ̀rù àti ìgbàgbọ́ nínú ohun asán gbé wọn dè. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní kí àwọn ìránṣẹ́ òun máa béèrè ohun tí wọ́n bá ń fẹ́ lọ́wọ́ òun. Òun ni Olùfúnni ní “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé.” (Jákọ́bù 1:17) Àpọ́sítélì Jòhánù mú un dá àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lójú pé: “Ohun yòówù tí a bá sì béèrè ni a ń rí gbà láti ọ̀dọ̀ [Ọlọ́run], nítorí a ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, a sì ń ṣe àwọn ohun tí ó dára lójú rẹ̀.”—1 Jòhánù 3:22.

Àwọn Ẹ̀mí Búburú Ńkọ́?

Ọ̀pọ̀ àjẹ́ ló gba ohun tí Bíbélì sọ lórí kókó yìí gbọ́, pé: Àwọn ẹ̀mí búburú wà. Nínú àròkọ kan, ẹnì kan tó jẹ́ agbátẹrù àjẹ́ ṣíṣe kìlọ̀ pé: “Àwọn Iwin wà lójúde: Wọn wà ní ilẹ̀ àìrí bíi tiwa tó kún fún àwọn ẹ̀dá alààyè. . . . Ọ̀rọ̀ náà, ‘Èṣù Kékeré’, ‘Ẹ̀mí Búburú’ àti ‘Ẹ̀mí Èṣù’ kúkú ṣe rẹ́gí. Àwọn ẹ̀mí wọ̀nyẹn lágbára gan-an. . . . Àwọn èyí tó ní làákàyè jù lọ nínú wọn . . . lè rọ́nà wọ ilẹ̀ ayé wa (bí ẹnì kan bá lè ràn wọ́n lọ́wọ́, tó sì ṣínà fún wọn). . . . Wọ́n lè wọnú ara rẹ . . . , kí wọ́n tiẹ̀ máa ṣàkóso rẹ dé àyè kan. Òótọ́ ni, ọ̀ràn yìí ò yàtọ̀ sí àwọn ìtàn àtijọ́ tí a ń gbọ́ nípa àwọn tí Ẹ̀mí Èṣù gbé dè.”

Nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, onírúurú ọ̀nà ni àwọn ẹ̀mí èṣù tó gbé àwọn èèyàn dè gbà ń pọ́n wọn lójú. Àwọn kan tí wọ́n gbé dè kò lè sọ̀rọ̀, ojú àwọn kan fọ́, àwọn kan ń ṣe bí ayírí, àwọn kan sì ní agbára tó ju ti ẹ̀dá lọ. (Mátíù 9:32; 12:22; 17:15, 18; Máàkù 5:2-5; Lúùkù 8:29; 9:42; 11:14; Ìṣe 19:16) Nígbà míì, ìrora náà máa ń pọ̀ sí i nígbà tí àwọn ẹ̀mí èṣù púpọ̀ bá ráyè wọnú ara ẹnì kan nígbà kan náà. (Lúùkù 8:2, 30) Nígbà náà, ó dájú pé ó ní ìdí gúnmọ́ tí Jèhófà fi ń kìlọ̀ fún àwọn èèyàn láti sá fún àjẹ́ ṣíṣe àti àwọn iṣẹ́ awo mìíràn.

Ìsìn Tí A Gbé Karí Òtítọ́

Ohun tó ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ṣàjẹ́ lónìí jẹ́ nítorí ó jọ pé kì í pani lára, ó ń gbére koni, pé ó sì jẹ́ ẹ̀sìn ìbílẹ̀. Ó ti di ohun tí wọ́n tẹ́wọ́ gbà láwọn àdúgbò kan. Wọn kì í bẹ̀rù rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ti sọ ọ́ di nǹkan ṣákálá. Lágbègbè tí fífàyè gba onírúurú ẹ̀sìn ti sún ọ̀pọ̀ èèyàn láti tẹ́wọ́ gba ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀ pàápàá, àjẹ́ ṣíṣe ti di ohun tó gbayì níbẹ̀.

Láìṣe àní-àní, agbo ẹ̀sìn ti di ibi tí èròǹgbà oríṣiríṣi ti ń ṣe kámi-kàmì-kámi, tí àwọn èèyàn ti láǹfààní láti yan èyí tó lè yanjú ìṣòro wọn, bí ìgbà tí èèyàn bá ra bàtà. Yàtọ̀ pátápátá sí èyí, Jésù sọ nípa yíyàn méjì péré. Ó wí pé: “Ẹ gba ẹnubodè tóóró wọlé; nítorí fífẹ̀ àti aláyè gbígbòòrò ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn tí ń gbà á wọlé; nígbà tí ó jẹ́ pé, tóóró ni ẹnubodè náà, híhá sì ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìyè, díẹ̀ sì ni àwọn tí ń rí i.” (Mátíù 7:13, 14) Bí ó ṣe sábà máa ń rí, a lómìnira láti yan ọ̀nà táa bá fẹ́ tọ̀. Ṣùgbọ́n nítorí pé ó wé mọ́ ire ayérayé wa, yíyàn yẹn ṣe pàtàkì gan-an. Láti rí ìlàlóye tẹ̀mí, a gbọ́dọ̀ lépa ọ̀nà òtítọ́—inú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, nìkan la ti lè rí ọ̀nà yẹn.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Láyé ìsinyìí, ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé àjẹ́ jẹ́ ẹ̀sìn ìbílẹ̀, tí kò lè ṣèpalára

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Iṣẹ́ òkùnkùn jẹ́ ara bíbẹ́mìílò

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Ǹjẹ́ kì í ṣe ìfẹ́ Èṣù làwọn tó ń ṣàjẹ́ ń ṣe láìmọ̀?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Bíbélì ń fi ọ̀nà òtítọ́ hanni