Àwọn Ìwé Ìhìn Rere—Ṣé Ìtàn Gidi Ni Tàbí Àròsọ?
Àwọn Ìwé Ìhìn Rere—Ṣé Ìtàn Gidi Ni Tàbí Àròsọ?
KÁRÍ ayé ni ìtàn Jésù ará Násárétì—ìyẹn ọ̀dọ́kùnrin tó yí ìtàn ẹ̀dá padà—ti wọnú àwùjọ ẹ̀dá bí eegun ti wọnú ẹran tí ẹran sì wọnú eegun. Ó wà lára ẹ̀kọ́ táwọn èèyàn lọ ń kọ́ níléèwé, àtèyí tí wọ́n ń kọ́ nílé. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé àwọn ìwé Ìhìn Rere jẹ́ orísun ọ̀pọ̀ òótọ́ ọ̀rọ̀ tí kò mọ sí sáà kan, àtàwọn àṣàyàn ọ̀rọ̀ àtayébáyé, bíi, “Kí ọ̀rọ̀ yín Bẹ́ẹ̀ ni sáà túmọ̀ sí Bẹ́ẹ̀ ni, Bẹ́ẹ̀ kọ́ yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́.” (Mátíù 5:37) Kódà, ó lè jẹ́ ohun tó wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere làwọn òbí ẹ fi tọ́ ẹ, yálà Kristẹni ni wọ́n àbí bẹ́ẹ̀ kọ́.
Fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ olóòótọ́ ọmọlẹ́yìn Kristi, àwọn ìwé Ìhìn Rere ṣàpèjúwe ọkùnrin náà tí wọ́n ṣe tán láti tìtorí ẹ̀ jìyà, kí wọ́n sì kú fún. Ìyẹn nìkan kọ́ o, àwọn ìwé Ìhìn Rere tún ń jẹ́ kéèyàn ní ìgboyà, ìfaradà, ìgbàgbọ́, àti ìrètí. Fún ìdí yìí, ǹjẹ́ o ò gbà pé ó yẹ kí ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro wà, kẹ́nì kan tó lè sọ ọ́ jáde lẹ́nu pé àròsọ lásán ni ìtàn wọ̀nyí? Báa bá wo ipa kíkàmàmà táwọn ìwé Ìhìn Rere ti ní lórí ìrònú àti ìwà ẹ̀dá, ǹjẹ́ o ò ní béèrè fún ẹ̀rí tó dájú ṣáká bẹ́nì kan bá ń fi yé ẹ pé ọ̀rọ̀ inú wọn kì í ṣòótọ́?
Dákun gbé àwọn ìbéèrè amúnironújinlẹ̀ bíi mélòó kan yẹ̀ wò nípa àwọn ìwé Ìhìn Rere. Kí ìwọ fúnra rẹ gbọ́ nǹkan táwọn kan tó ti kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nípa àwọn ìwé Ìhìn Rere sọ nípa ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yìí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan lára wọn sọ pé àwọn kì í ṣe Kristẹni. Lẹ́yìn náà, o lè wá ṣe ìpinnu tó bá òye rẹ mu.
ÀWỌN ÌBÉÈRÈ FÚN ÀGBÉYẸ̀WÒ
◆ Ó ha lè jẹ́ pé àwọn akọ̀wé-kọwúrà ló ronú kọ àwọn ìwé Ìhìn Rere bí?
Robert Funk, tó jẹ́ olùdásílẹ̀ Àpérò Jésù, sọ pé: “Mátíù, Máàkù, Lúùkù àti Jòhánù ló ‘polówó Mèsáyà’ lọ́nà tó fi lè bá ẹ̀kọ́ Kristẹni tó jẹ yọ lẹ́yìn ikú Jésù mu.” Àmọ́ o, ọ̀kẹ́ àìmọye tó gbọ́rọ̀ Jésù, tó rí ohun tó ṣe, tó sì rí i lẹ́yìn tó jíǹde, ṣì wà láàyè nígbà tí wọ́n ń kọ àwọn ìwé Ìhìn Rere lọ́wọ́. Àwọn èèyàn wọ̀nyí ò sọ pé onímàkàrúrù làwọn tó kọ àwọn ìwé Ìhìn Rere.
Gbé ikú àti àjíǹde Kristi yẹ̀ wò. Kì í ṣe kìkì pé àwọn ìwé Ìhìn rere ròyìn nípa ikú àti àjíǹde Jésù nìkan ni, àmọ́ lẹ́tà onímìísí àkọ́kọ́ tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì ayé ọjọ́un tún sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ méjèèjì yìí. Ó kọ̀wé pé: “Mo fi lé yín lọ́wọ́, lára àwọn ohun àkọ́kọ́, èyíinì tí èmi pẹ̀lú gbà, pé Kristi kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí; àti pé a sin ín, bẹ́ẹ̀ ni, pé a ti gbé e dìde ní ọjọ́ kẹta gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí; àti pé ó fara han Kéfà, lẹ́yìn náà, àwọn méjìlá náà. Lẹ́yìn ìyẹn, ó fara han èyí tí ó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àwọn ará lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, púpọ̀ jù lọ nínú àwọn tí wọ́n ṣì wà títí di ìsinsìnyí, ṣùgbọ́n àwọn díẹ̀ ti sùn nínú ikú. Lẹ́yìn ìyẹn, ó fara han Jákọ́bù, lẹ́yìn náà, gbogbo àpọ́sítélì; ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn gbogbo rẹ̀, ó fara han èmi pẹ̀lú gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a bí ní kògbókògbó.” (1 Kọ́ríńtì 15:3-8) Irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ tọ́ràn ṣojú wọn ló lè pìtàn ìgbésí ayé Jésù gan-an.
Ẹ̀mí fífẹ́ láti ronú gbé ìtàn kan jókòó, èyí táwọn aṣelámèyítọ́ òde òní sọ pé òun ló wà nídìí ọ̀ràn yìí, kò sí nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Kàkà bẹ́ẹ̀, inú àwọn ìwé táwọn èèyàn míì ṣe ní ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa la ti lè rírú ẹ̀mí yẹn. Fún ìdí yìí, ìgbà tí ìpẹ̀yìndà kúrò nínú ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ wáyé láàárín àwọn tó ya Ìṣe 20:28-30.
kúrò nínú ìjọ àwọn àpọ́sítélì, làwọn ìtàn kan tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu nípa Kristi bẹ̀rẹ̀ sí yọ́ wọlé.—◆ Àbí ìtàn àtẹnudẹ́nu làwọn ìwé Ìhìn Rere ni?
Òǹkọ̀wé àti aṣelámèyítọ́ nì, C. S. Lewis, sọ pé ó nira fóun láti ka àwọn ìwé Ìhìn Rere sí ìtàn àtẹnudẹ́nu lásán-làsàn. Ó kọ̀wé pé: “Gẹ́gẹ́ bí òpìtàn tó jẹ́ ògbógi nípa àwọn ìwé ìtàn ìgbàanì, ohun yòówù táwọn ìwé Ìhìn Rere ì báà jẹ́, ó dá mi lójú hán-únhán-ún pé wọn kì í ṣe ìtàn àtẹnudẹ́nu. Kò sí àjásà nínú ìtàn wọnnì tí à bá fi sọ pé ìtàn àròsọ ni wọ́n. . . . Apá tó pọ̀ jù lọ nínú ìgbésí ayé Jésù ni a kò mọ̀, bẹ́ẹ̀ rèé, kò sẹ́ni tó fẹ́ kọ ìtàn àròsọ tó máa jẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀.” Ó tún gbàfiyèsí pé, bó tiẹ̀ jẹ́ pé gbajúgbajà nì, òpìtàn H. G. Wells, sọ pé Kristẹni kọ́ lòun, síbẹ̀ ó gbà pé: “Ọ̀rọ̀ àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin [tó kọ àwọn ìwé Ìhìn Rere] bára mu rẹ́gí, ní ti pé ẹnì kan tó wà ní ti gidi ni wọ́n ń ṣàpèjúwe rẹ̀; ohun tí wọ́n sọ . . . mú un dáni lójú pé èèyàn gidi ni wọ́n ń sọ̀rọ̀ rẹ̀.”
Ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀. Ẹni tó bá mọ àròkọọ́ kọ dáadáa ì bá sọ pé ayé gbọ́ ọ̀run mọ̀ nígbà tí Jésù padà dé, ì bá sọ pé ó sọ àwíyé kan tó fakíki, tàbí pé ó dé tògotògo nínú ìmọ́lẹ̀ títàn yòò. Àmọ́ kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe làwọn tó kọ àwọn ìwé Ìhìn Rere kàn sọ wẹ́rẹ́ pé ńṣe ló dúró níwájú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Ó jẹ́ kí wọ́n fọwọ́ kan òun, ó sì wá bi wọ́n pé: “Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, ẹ kò ní ohunkóhun láti jẹ, àbí ẹ ní?” (Jòhánù 21:5) Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nì, Gregg Easterbrook, wá sọ ní tirẹ̀ pé: “Irú àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ wọ̀nyí ló jẹ́ kéèyàn mọ̀ pé ìtàn gidi ni, kì í ṣe àròsọ.”
Ẹ̀sùn tí wọ́n fi sùn pé ìtàn àtẹnudẹ́nu làwọn ìwé Ìhìn Rere kò tún lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, àgàgà táa bá rántí pé àwọn rábì tó wà láyé nígbà tí wọ́n ń kọ àwọn ìwé Ìhìn rere kò gba gbẹ̀rẹ́ rárá nínú ọ̀nà tí wọ́n gbà ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Ọ̀nà àkọ́sórí ni wọ́n ń lò—o gbọ́dọ̀ máa sọ ọ́ léraléra tàbí kóo máa wí i tẹ̀ lé wọn títí wàá fi há a sórí ni. Ọ̀nà yìí á jẹ́ káwọn tó ń kọ àwọn ọ̀rọ̀ àti iṣẹ́ Jésù fara balẹ̀ kọ ọ́ lọ́nà pípéye, kò sì lè fàyè gba títún ìtàn náà sọ kó lè dùn.
◆ Bó bá ṣe pé ìtàn àtẹnudẹ́nu ló wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere, ǹjẹ́ á ṣeé tètè kó jọ kíákíá báyẹn lẹ́yìn ikú Jésù?
Lójú àwọn ẹ̀rí tó wà ńlẹ̀, àárín ọdún 41 sí 98 Sànmánì Tiwa ni wọ́n kọ àwọn ìwé Ìhìn Rere. Jésù kú lọ́dún 33 Sànmánì Tiwa. Tó fi hàn pé kò pẹ́ rárá lẹ́yìn tó parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n ṣe àkọsílẹ̀ ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀. Èyí wá jẹ́ ìṣòro ńlá fáwọn tó ń jiyàn pé ìtàn àtẹnudẹ́nu lásán làwọn ìwé Ìhìn Rere. Ó máa ń gba àkókò gígùn kí ìtàn àtẹnudẹ́nu tó tàn kálẹ̀. Àpẹẹrẹ kan ni ti ìtàn Iliad àti èyí tí wọ́n ń pè ní Odyssey tí ọ̀gbẹ́ni Homer akéwì Gíríìkì ìgbàanì kọ. Àwọn kan sọ pé ó gbà tó ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún kí àwọn ìwé ìtàn àròsọ tó fakíki wọ̀nyẹn tó tàn kálẹ̀, kó sì fẹsẹ̀ múlẹ̀. Ní ti àwọn ìwé Ìhìn Rere ńkọ́?
Òpìtàn náà, Will Durant, sọ nínú ìwé rẹ̀, Caesar and Christ, pé: “Tó bá jẹ́ pé àwọn gbáàtúù kéréje . . . ló fúnra wọn hùmọ̀ irú ẹni ńlá bẹ́ẹ̀, ẹni tí ìwà rẹ̀ fani mọ́ra gan-an, tó ní ìlànà ìwà híhù tó ga lọ́lá, tí ẹ̀mí ìṣọ̀kan ẹgbẹ́ ará tó ní sì wúni lórí jọjọ, ìyẹn ni ì bá jẹ́ iṣẹ́ ìyanu tó ta yọ gbogbo èyí tó wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere. Lẹ́yìn Ṣíṣe Lámèyítọ́ Ìtàn àti Ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ fún ọ̀rúndún méjì, ìtàn ìgbésí ayé Kristi, ìwà rẹ̀, àti ẹ̀kọ́ rẹ̀, ṣì ṣe kedere lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu, òun ló sì wá para pọ̀ jẹ́ apá tó fani mọ́ra jù lọ nínú ìtàn àwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn ayé.”
◆ Ṣé kì í ṣe pé wọ́n wá tún àwọn ìwé Ìhìn Rere kọ nígbà tó yá, kí wọ́n lè bá ipò àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ mu?
Àwọn aṣelámèyítọ́ kan ń jiyàn pé ọ̀nà àtigbégbá orókè táwọn Kristẹni ìjímìjí ń wá ló mú káwọn tó kọ àwọn ìwé Ìhìn Rere já àlùbọ́sà sí ìtàn Jésù, tàbí kí wọ́n bù mọ́ ọn. Àmọ́ táa bá fara balẹ̀ ka àwọn ìwé Ìhìn Rere, a óò rí i pé irú ìwà mọ̀náfìkí bẹ́ẹ̀ ò wáyé. Bó bá ṣe pé lóòótọ́ làwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní bù mọ́ ìròyìn àwọn ìwé Ìhìn Rere nípa Jésù, torí àtidọ́gbọ́n tan àwọn èèyàn jẹ, kí ló dé táwọn ọ̀rọ̀ tó bẹnu àtẹ́ lu àwọn Júù àti Kèfèrí ṣì wà nínú rẹ̀?
Àpẹẹrẹ kan ni èyí tó wà nínú Mátíù orí kẹfà, ẹsẹ̀ karùn-ún sí ìkeje, níbi táa ti fa ọ̀rọ̀ Jésù yọ, pé: “Nígbà tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ kò gbọ́dọ̀ dà bí àwọn alágàbàgebè; nítorí wọ́n fẹ́ láti máa gbàdúrà ní dídúró nínú àwọn sínágọ́gù àti ní àwọn igun oríta, kí àwọn ènìyàn bàa lè rí wọn. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Wọ́n ń gba èrè wọn ní kíkún.” Dájúdájú, ìbáwí kíkan ni èyí jẹ́ fáwọn aṣáájú ẹ̀sìn àwọn Júù. Jésù tún sọ síwájú sí i pé: “Nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, má ṣe sọ ohun kan náà ní àsọtúnsọ, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè [àwọn Kèfèrí] ti ń ṣe, nítorí wọ́n lérò pé a óò gbọ́ tiwọn nítorí lílò tí wọ́n ń lo ọ̀rọ̀ púpọ̀.” Nípa fífa ọ̀rọ̀ Jésù wọ̀nyí yọ, kì í ṣe pé àwọn tó kọ àwọn ìwé Ìhìn Rere fẹ́ jèrè ọkàn. Wọ́n kàn ṣe àkọsílẹ̀ àwọn gbólóhùn náà gan-an tí Jésù Kristi sọ ni.
Tún ronú nípa ohun táwọn ìwé Ìhìn Rere sọ nípa àwọn obìnrin tó lọ sí ibojì Jésù, tí wọ́n sì rí i pé ó ti ṣófo. (Máàkù 16:1-8) Gẹ́gẹ́ bí Gregg Easterbrook ti wí, “nínú ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé ọjọ́un, wọn kì í gbára lé ẹ̀rí látẹnu obìnrin: bí àpẹẹrẹ, ẹlẹ́rìí méjì tó jẹ́ ọkùnrin ti tó láti fi dá obìnrin kan lẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà, ṣùgbọ́n kò síye obìnrin tó lè jẹ́rìí, tí wọ́n á wá tìtorí ẹ̀ dá ọkùnrin kan lẹ́bi.” Àní, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù pàápàá kò gba àwọn obìnrin náà gbọ́! (Lúùkù 24:11) Kò jọ pé wọ́n lè dìídì hùmọ̀ irú ìtàn yẹn.
Àìsí àwọn àkàwé nínú ìwé Ìṣe àtàwọn ìwé Bíbélì tó jẹ́ lẹ́tà, jẹ́ ẹ̀rí lílágbára tó fi hàn pé kì í ṣe àwọn Kristẹni ìjímìjí ló fi àwọn àkàwé tó wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere síbẹ̀, bí kò ṣe pé ẹnu Jésù ni àwọn àkàwé wọ̀nyẹn ti jáde. Kò tán síbẹ̀ o, báa bá fara balẹ̀ ṣe ìfiwéra àwọn ìwé Ìhìn Rere àti àwọn lẹ́tà inú Bíbélì, a óò rí i pé kò sẹ́ni tó lọ fi ọgbọ́n àyínìke tún ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù tàbí tàwọn yòókù tó kọ Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì sọ, kí wọ́n sì wá sọ pé ẹnu Jésù làwọn ti gbọ́ ọ. Bó bá ṣe pé ẹgbẹ́ àwọn Kristẹni ìjímìjí ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀, ó kéré tán, à bá ṣì rí díẹ̀ lára ọ̀rọ̀ tó wà nínú lẹ́tà wọn nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere. Níwọ̀n bí kò ti sí irú ìyẹn, a lè fọwọ́ sọ̀yà pé bó ṣe ṣẹlẹ̀ gan-an ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ ló ṣe wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere, kò sírọ́ ńbẹ̀.
◆ Àwọn ibì kan tó jọ pé ó takora nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere ńkọ́?
Tipẹ́tipẹ́ làwọn aṣelámèyítọ́ ti ń sọ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsọfúnni tó wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere ló takora. Òpìtàn nì, Durant, sapá láti ṣàyẹ̀wò àwọn ìwé Ìhìn Rere láìgbè sọ́tùn-ún sósì—ó wò wọ́n gẹ́gẹ́ bí ìwé ìtàn pọ́n-ń-bélé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó sọ pé àwọn nǹkan kan wà nínú wọn táwọn kan lè sọ pé ó takora, síbẹ̀, ó sọ pé: “Àwọn ìtakora náà jẹ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, kì í ṣe ohun ṣíṣe kókó; àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú àwọn ìwé ìhìn rere bára mu rẹ́gírẹ́gí, ohun tí gbogbo wọ́n sì sọ nípa Kristi kò yàtọ̀ síra.”
Àwọn ohun táwọn kan sọ pé ó ta kora nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere kò ṣòroó ṣàlàyé rárá. Àpẹẹrẹ kan rèé: Mátíù orí kẹjọ, ẹsẹ karùn-ún sọ pé “ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan wá sọ́dọ̀ [Jésù], ó ń pàrọwà fún un” pé kó wo ìránṣẹ́kùnrin òun sàn. Nínú Lúùkù orí keje, ẹsẹ kẹta, a kà á pé ọ̀gá náà “rán àwọn àgbà ọkùnrin àwọn Júù lọ bá [Jésù] láti rọ̀ ọ́ láti wá, kí ó sì gba ẹrú [náà] là láìséwu.” Ọ̀gá náà rán àwọn alàgbà gẹ́gẹ́ bí aṣojú rẹ̀. Mátíù sọ pé ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun náà alára ló pàrọwà fún Jésù nítorí pé ọkùnrin náà pàrọwà yìí nípasẹ̀ àwọn àgbààgbà, tí wọ́n gbẹnu sọ fún un. Èyí wulẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ kan tó fi hàn pé àlàyé wà fún ohun táwọn kan sọ pé ó takora nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere.
Nípa ohun táwọn aṣelámèyítọ́ ìtàn àti ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ ń sọ ńkọ́, pé àwọn ìwé Ìhìn Rere kò dójú ìlà ohun tí wọ́n ń pè ní ìtàn gidi? Ọ̀gbẹ́ni Durant ń bọ́rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ìtara tí wọ́n ní nítorí àwọn ohun tí wọ́n ti ṣàwárí, ti sún àwọn tó ń ṣe Lámèyítọ́ Ìtàn àti Ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ láti tọpinpin Májẹ̀mú Tuntun ju bó ṣe yẹ lọ, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀ tọpinpin ìtàn ọgọ́rùn-ún àwọn olókìkí ìgbàanì—àwọn bíi Hammurabi, Dáfídì, Socrates—àròsọ lásán ni ìtàn wọ́n máa dà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ajíhìnrere wọnnì ní èrò tiwọn àti ìgbàgbọ́ tiwọn, ọ̀pọ̀ ohun tí wọ́n kọ sílẹ̀ ni aláròkọ kan ì bá fi pa mọ́—bí ìgbà táwọn àpọ́sítélì ń díje fún ipò gíga nínú Ìjọba náà, bí wọ́n ṣe bẹ́sẹ̀ wọn sọ̀rọ̀ nígbà tí wọ́n mú Jésù, sísẹ́ tí Pétérù sẹ́ Jésù . . . Kò sẹ́ni tó ń ka ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí tó lè máa ṣiyèméjì nípa bóyá àwọn èèyàn gidi làwọn èèyàn wọ̀nyí tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.”
◆ Ǹjẹ́ ẹ̀sìn Kristẹni òde òní ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere?
Àpérò Jésù polongo pé ìwádìí táwọn ṣe nípa àwọn ìwé Ìhìn Rere “kò ní nǹkan kan í ṣe pẹ̀lú ìlànà táwọn ìgbìmọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì ń tẹ̀ lé.” Àmọ́, òpìtàn Wells rí i pé ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ wà láàárín àwọn ẹ̀kọ́ Jésù gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere àti ẹ̀kọ́ àwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì. Ó kọ̀wé pé: “Kò sí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé àwọn àpọ́sítélì Jésù gbọ́ Mẹ́talọ́kan rí—àní bóyá kí wọ́n tiẹ̀ gbọ́ ọ lẹ́nu rẹ̀. . . . Bẹ́ẹ̀ náà ni [Jésù] kò sọ ẹyọ ọ̀rọ̀ kan nípa jíjọ́sìn Màríà ìyá rẹ̀, ní àwòrán òòṣà Isis, tí í ṣe Ayaba ọ̀run. Kò fọwọ́ sí ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fi ń kọ́ni, àtàwọn ohun tí wọ́n ń lò.” Fún ìdí yìí, èèyàn ò lè fi ẹ̀kọ́ àwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì pinnu ìníyelórí àwọn ìwé Ìhìn Rere.
KÍ LÈRÒ TÌRẸ?
Lẹ́yìn tóo ti gbé gbogbo kókó tó wà lókè yìí yẹ̀ wò, kí lèrò tìrẹ? Ǹjẹ́ ojúlówó ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ wà láti fi hàn pé ìtàn àròsọ lásán-làsàn làwọn ìwé Ìhìn Rere? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti rí i pé àwọn ìbéèrè àti iyèméjì tó ti dìde nípa jíjẹ́ òótọ́ àwọn ìwé Ìhìn Rere kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ rárá, kò sì lè yí èrò ẹni padà. Kí o lè mọ ìpinnu tó yẹ kí o ṣe, á dáa kí o ka àwọn ìwé Ìhìn Rere láìsí ẹ̀tanú. (Ìṣe 17:11) Nígbà tóo bá ronú nípa bí àwọn ìwé Ìhìn Rere ṣe ṣàpèjúwe ẹni tí Jésù jẹ́ lọ́nà tó bára mu, tí kò lábòsí, tó sì ṣe rẹ́gí, ìwọ náà á gbà pé àkọsílẹ̀ wọ̀nyí kì í ṣe ìtàn àròsọ rárá. a
Bóo bá fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tóo sì fi ìmọ̀ràn rẹ̀ sílò, wàá rí bó ṣe lè tún ayé ẹ ṣe. (Jòhánù 6:68) Àgàgà tóo bá ka àwọn ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere. Láfikún sí i, o lè kẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la alárinrin tí ń bẹ nípamọ́ fún aráyé onígbọràn.—Jòhánù 3:16; 17:3, 17.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo orí karùn-ún sí ìkeje ìwé The Bible—God’s Word or Man’s? tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde àti ìwé pẹlẹbẹ náà, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn tí Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania tẹ̀ jáde.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]
Ẹ̀rí Tó Fi Hàn Pé Òótọ́ ni Ìròyìn Náà
NÍ ỌDÚN mélòó kan sẹ́yìn, ará Ọsirélíà kan tó jẹ́ òǹkọ̀wé àti aṣelámèyítọ́ Bíbélì tẹ́lẹ̀ rí, jẹ́wọ́ pé: “Ìgbà àkọ́kọ́ rèé láyé mi, tí mo ṣe ohun tó yẹ kí oníròyìn kọ́kọ́ ṣe: mo ṣàyẹ̀wò ìsọfúnni tí mo ní lọ́wọ́. . . . Háà sì ṣe mí, nítorí pé ohun tí mo ń kà [nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere] kì í ṣe ìtàn àtẹnudẹ́nu, kò sì dún bí àròsọ. Ìròyìn pọ́n-ń-bélé ni. Ó jẹ́ ìròyìn látẹnu àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ àrà ọ̀tọ̀ wọ̀nyí ṣojú wọn tàbí àwọn tó gbọ́ látẹnu wọn . . . Àwọn àmì kan wà tó máa ń jẹ́ kéèyàn dá ìròyìn pọ́n-ń-bélé mọ̀ yàtọ̀, irú àwọn àmì yẹn sì wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere.”
Bákan náà ni E. M. Blaiklock, tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nípa àwọn ìwé ìtàn ìgbàanì, ní Yunifásítì Auckland, ṣe sọ pé: “Òpìtàn ni mo pe ara mi. Ojú ìtàn tòótọ́ ni mo fi ń wo àwọn Ìwé Ìtàn Ìgbàanì. Mo sì fẹ́ kó yé yín pé ẹ̀rí tó fi hàn pé Kristi gbé ayé, pé ó kú, àti pé ó jíǹde, fẹsẹ̀ múlẹ̀ ju ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ìsọfúnni tó wà nínú ìtàn ayé ọjọ́un.”
[Àwòrán ilẹ̀/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
FÒNÍṢÍÀ
GÁLÍLÌ
Odò Jọ́dánì
JÙDÍÀ
[Àwọn àwòrán]
“Ẹ̀rí tó fi hàn pé Kristi gbé ayé, pé ó kú, àti pé ó jíǹde, fẹsẹ̀ múlẹ̀ ju ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ìsọfúnni tó wà nínú ìtàn ayé ọjọ́un”—Ọ̀JỌ̀GBỌ́N E. M. BLAIKLOCK
[Credit Line]
Àwọn àwòrán ìsàlẹ̀: A gbé e ka àwòrán kan tó jẹ́ ti Pictorial Archive (Near Eastern History) Est. and Survey of Israel.