Máa Fiyè Sí Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run Fún Ọjọ́ Wa
Máa Fiyè Sí Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run Fún Ọjọ́ Wa
“Kí ó yé ọ, ọmọ ènìyàn, pé ìran náà wà fún àkókò òpin.”—DÁNÍẸ́LÌ 8:17.
1. Kí ni Jèhófà fẹ́ kí gbogbo ènìyàn mọ̀ nípa ọjọ́ wa?
JÈHÓFÀ kò fi ìmọ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la mọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀ nìkan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ Olùṣí àwọn àṣírí payá. Àní, ṣe ló ń fẹ́ kí gbogbo wa mọ̀ pé a ti rìn jìnnà wọnú “àkókò òpin.” Ìròyìn tó ṣe pàtàkì mà lèyí o fún bílíọ̀nù mẹ́fà ènìyàn tó ń gbé ayé nísinsìnyí!
2. Èé ṣe tí àwọn ènìyàn fi ń ṣàníyàn nípa ọjọ́ ọ̀la aráyé?
2 Ǹjẹ́ ó yani lẹ́nu rárá pé ayé burúkú yìí ń sún mọ́ òpin rẹ̀? Ènìyàn lè rìn lórí òṣùpá, ṣùgbọ́n lọ́pọ̀ ibi lórí pílánẹ́ẹ̀tì yìí, kò lè gbafẹ́ lọ sóde láìbẹ̀rù. Ó lè ní gbogbo nǹkan ìgbàlódé sínú ilé, ṣùgbọ́n kò lè dáwọ́ títú tí àwọn ìdílé ń tú ká dúró. Ó lè fi ọ̀wààrà ìsọfúnni kún inú ayé dẹ́múdẹ́mú, ṣùgbọ́n kò lè kọ́ àwọn ènìyàn bí wọ́n ṣe lè gbé pọ̀ ní àlàáfíà. Àwọn ìkùnà wọ̀nyí ti ọ̀pọ̀ yanturu ẹ̀rí láti inú Ìwé Mímọ́ lẹ́yìn pé àkókò òpin là ń gbé.
3. Ìgbà wo la kọ́kọ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ náà “àkókò òpin” lórí ilẹ̀ ayé?
3 Áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì ló kọ́kọ́ lo ọ̀rọ̀ tó gbàfiyèsí yìí—“àkókò òpin”—ní nǹkan bí ẹgbẹ̀tàlá ọdún sẹ́yìn. Wòlíì Ọlọ́run kan tí jìnnìjìnnì bá gbọ́ tí Gébúrẹ́lì sọ pé: “Kí ó yé ọ, ọmọ ènìyàn, pé ìran náà wà fún àkókò òpin.”—Dáníẹ́lì 8:17.
“Àkókò Òpin” Nìyí!
4. Àwọn ọ̀nà míì wo ni Bíbélì gbà tọ́ka sí àkókò òpin?
4 Ìgbà mẹ́fà ni gbólóhùn náà “àkókò òpin” àti “àkókò òpin tí a yàn kalẹ̀” fara hàn nínú ìwé Dáníẹ́lì. (Dáníẹ́lì 8:17, 19; 11:35, 40; 12:4, 9) Wọ́n ní í ṣe pẹ̀lú “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ tẹ́lẹ̀. (2 Tímótì 3:1-5) Jésù Kristi tọ́ka sí ìgbà kan náà gẹ́gẹ́ bí ìgbà “wíwàníhìn-ín” rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba tí a gbé gorí ìtẹ́ ní ọ̀run.—Mátíù 24:37-39.
5, 6. Àwọn wo ló ti “lọ káàkiri” ní àkókò òpin yìí, kí sì ni àbájáde rẹ̀?
5 Dáníẹ́lì orí kejìlá, ẹsẹ kẹrin sọ pé: “Ní ti ìwọ, Dáníẹ́lì, ṣe àwọn ọ̀rọ̀ náà ní àṣírí, kí o sì fi èdìdì di ìwé náà, títí di àkókò òpin. Ọ̀pọ̀ yóò máa lọ káàkiri, ìmọ̀ tòótọ́ yóò sì di púpọ̀ yanturu.” Ọ̀pọ̀ nínú ohun tí Dáníẹ́lì kọ sílẹ̀ ni a mú kí ó wà ní àṣírí tí a sì fèdìdì dì tí ènìyàn kò fi lóye wọn fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún. Ọjọ́ òní wá ńkọ́?
6 Ní àkókò òpin yìí, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni olùṣòtítọ́ ti “lọ káàkiri” nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kí ni àbájáde rẹ̀? Bí Jèhófà ṣe fìbùkún sí i, ìmọ̀ tòótọ́ wá di púpọ̀ yanturu. Bí àpẹẹrẹ, a ti fi ìjìnlẹ̀ òye jíǹkí àwọn ẹni àmì òróró Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n fi lè lóye pé Jésù Kristi di Ọba lọ́run lọ́dún 1914. Ní híhùwà níbàámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì tí a kọ sínú Pétérù kejì orí kìíní, ẹsẹ kọkàndínlógún sí ìkọkànlélógún, ṣe ni irú àwọn ẹni àmì òróró bẹ́ẹ̀ àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn adúróṣinṣin ‘ń fiyè sí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀’ náà, ó sì dá wọn lójú hán-ún pé àkókò òpin nìyí.
7. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó mú kí ìwé Dáníẹ́lì ṣàrà ọ̀tọ̀?
7 Ìwé Dáníẹ́lì tún ṣàrà ọ̀tọ̀ láwọn ọ̀nà bíi mélòó kan. Inú rẹ̀ ni ọba kan ti kéde pé òun yóò pa àwọn amòye òun nítorí pé wọn kò lè rọ́ àdììtú àlá tí òun lá kí wọ́n sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n wòlíì Ọlọ́run yanjú ìṣòro náà. A ju àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mẹ́ta tí wọ́n kọ̀ láti jọ́sìn ère gìrìwò kan sínú iná ìléru kan tí wọ́n koná mọ́ lọ́nà tó fi túbọ̀ ń jó wòwòwò, síbẹ̀ wọ́n là á já láìjẹ́ pé iná jó wọn. Bí àjọyọ̀ kan ṣe ń lọ lọ́wọ́, ọgọ́rọ̀ọ̀rún ènìyàn rí ọwọ́ kan tí ń kọ àwọn àdììtú ọ̀rọ̀ sára ògiri ààfin. Àwọn ọlọ̀tẹ̀ burúkú mú kí wọ́n ju àgbàlagbà ọkùnrin kan sínú ihò kìnnìún, ṣùgbọ́n ó jáde wá láìfarapa rárá. A rí ẹranko mẹ́rin nínú ìran kan, ohun tí a sì sọ pé wọ́n dúró fún lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀ nasẹ̀ dé àkókò òpin.
8, 9. Báwo ni ìwé Dáníẹ́lì ṣe lè ṣe wá láǹfààní, pàápàá nísinsìnyí, ní àkókò òpin?
8 Dájúdájú, oríṣi ẹ̀ka méjì tó yàtọ̀ síra gan-an ló wà nínú ìwé Dáníẹ́lì. Ọ̀kan jẹ́ ìtàn, èkejì jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀. Ẹ̀ka méjèèjì ló lè gbé ìgbàgbọ́ wa ró. Ẹ̀ka tó jẹ́ ìtàn fi hàn wá pé Jèhófà Ọlọ́run ń bù kún àwọn tó bá pa ìwà títọ́ mọ́ sí i. Àwọn apá tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ gbé ìgbàgbọ́ ró nípa fífi hàn pé Jèhófà ti mọ bí ìtàn ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún—àní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún—tí ń bọ̀ ṣe máa rí.
9 Onírúurú àsọtẹ́lẹ̀ tí Dáníẹ́lì kọ sílẹ̀ pe àfiyèsí wa sí Ìjọba Ọlọ́run. Bí a ṣe ń ṣàkíyèsí ìmúṣẹ irú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ ń lókun sí i, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìdánilójú tí a ní pé àkókò òpin la ń gbé. Àmọ́, àwọn aṣelámèyítọ́ kan ti gbógun ti Dáníẹ́lì, wọ́n sọ pé ńṣe ni a kọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé tí ń jórúkọ rẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó dà bí pé ó mú wọn ṣẹ ti ṣẹlẹ̀ tán. Bí àwọn ohun tí wọ́n sọ yẹn bá jóòótọ́, ìyẹn yóò gbé àwọn ìbéèrè gbankọgbì dìde sí ohun tí ìwé Dáníẹ́lì sọ nípa àkókò òpin. Àwọn oníyèmejì tún gbé ìbéèrè dìde sí ìtàn inú ìwé yẹn. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò rẹ̀.
Ó Ti Di Ẹjọ́ O!
10. Ọ̀nà wo la gbà fẹ̀sùn kan ìwé Dáníẹ́lì?
10 Fojú inú wò ó pé o wà nínú kóòtù kan, o ń gbọ́ bí ìgbẹ́jọ́ kan ṣe ń lọ lọ́wọ́. Agbẹjọ́rò ìjọba ń rin kinkin mọ́ ọn pé ẹni tí a fẹ̀sùn kàn yẹn jẹ̀bi èrú ṣíṣe. Bákan náà, ìwé Dáníẹ́lì fara hàn bí ojúlówó ìwé tí wòlíì Hébérù kan tó gbé ayé ní ọ̀rúndún keje sí ìkẹfà ṣááju Sànmánì Tiwa kọ. Àmọ́ àwọn aṣelámèyítọ́ rin kinkin mọ́ ọn pé ayédèrú ìwé ni. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ wò ó bóyá apá tó jẹ́ ìtàn nínú rẹ̀ bá ohun tí ìtàn fi hàn pé ó ṣẹlẹ̀ gan-an mu.
11, 12. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀sùn náà pé kò sẹ́nì kankan tó ń jẹ́ Bẹliṣásárì nínú ìtàn?
11 Ká tilẹ̀ gbé ohun tí a lè pè ní ọ̀ràn ọba tí ìwé mìíràn kò mẹ́nu kàn yẹ̀ wò ná. Dáníẹ́lì orí karùn-ún fi hàn pé Bẹliṣásárì lọba tí ń ṣàkóso Bábílónì nígbà tí wọ́n gba ìlú yẹn ní ọdún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa. Àwọn aṣelámèyítọ́ tako ọ̀rọ̀ yìí nítorí pé kò síbòmíràn tí a tún ti rí orúkọ Bẹliṣásárì yàtọ̀ sí inú Bíbélì. Kàkà bẹ́ẹ̀, Nábónídọ́sì ni àwọn òpìtàn ìgbàanì sọ pé ó jẹ́ ọba tó jẹ kẹ́yìn ní Bábílónì.
12 Àmọ́, lọ́dún 1854, a hú àwọn ọ̀pá alámọ̀ rìbìtì kan láti inú àwókù ìlú Úrì, ìlú ìgbàanì kan ní Bábílónì, tó wà ní ilẹ̀ Iraq tòde òní. Lára àwọn àkọsílẹ̀ tí wọ́n fín sára amọ̀ wọ̀nyí ni àdúrà kan tí Nábónídọ́sì Ọba gbà, inú rẹ̀ ló ti tọ́ka sí “Bel-sar-ussur, ọmọkùnrin mi àgbà.” Kódà àwọn aṣelámèyítọ́ wọ̀nyí gbà ní dandan, pé: Bẹliṣásárì inú ìwé Dáníẹ́lì lèyí. Nítorí náà, a kò ṣàìmẹ́nu kan ọba tí wọ́n ní a kò mẹ́nu kàn rárá, ó kàn jẹ́ pé ìwé ìtàn ayé kò tíì mọ̀ nípa rẹ̀ ni. Ọ̀kan ṣoṣo péré lèyí jẹ́ nínú àwọn ẹ̀rí pelemọ tó fi hàn pé àkọsílẹ̀ tòótọ́ gidi tó ṣeé gbà gbọ́ ni àwọn àkọsílẹ̀ Dáníẹ́lì jẹ́. Irú ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ fi hàn pé dájúdájú ìwé Dáníẹ́lì jẹ́ ara Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó yẹ ká fẹ̀sọ̀ kíyè sí nísinsìnyí gan- an, ní àkókò òpin.
13, 14. Ta ni Nebukadinésárì, ọlọ́run èké wo ló sì ń fọkàn sìn ní ti gidi?
13 Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí àwọn agbára ayé ṣe ń yọjú ní ìtòtẹ̀léra àti nípa ohun tí díẹ̀ lára àwọn alákòóso wọn yóò ṣe, jẹ́ ara apá pàtàkì inú ìwé Dáníẹ́lì. Ọ̀kan nínú àwọn alákòóso náà ni ẹnì kan tí a lè pè ní jagunjagun tó gbé ilẹ̀ ọba kan ró. Gẹ́gẹ́ bí ọmọ aládé Bábílónì, òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pa agbo ọmọ ogun Fáráò Nékò ti Íjíbítì nípakúpa ní ìlú Kákémíṣì. Ṣùgbọ́n iṣẹ́ kan tí wọ́n jẹ́ fún ọmọ ọba Bábílónì aṣẹ́gun náà mú kó di dandan pé kí ó fi ìràlẹ̀rálẹ̀ ogun tó kù sílẹ̀ fún àwọn ọ̀gágun rẹ̀ láti bójú tó. Bí Nebukadinésárì ọ̀dọ́ ṣe gbọ́ pé baba òun Nabopolásárì ti kú, ló bá gorí ìtẹ́ lọ́dún 624 ṣááju Sànmánì Tiwa. Láàárín ọdún mẹ́tàlélógójì tó fi ṣàkóso, ó gbé ilẹ̀ ọba kan ró, tó nasẹ̀ dé gbogbo agbègbè tó jẹ́ ti Ásíríà tẹ́lẹ̀, ó sì nasẹ̀ ilẹ̀ ọba rẹ̀ wọnú ilẹ̀ Síríà àti Palẹ́sìnì títí ó fi dé ààlà ilẹ̀ Íjíbítì.
14 Mádọ́kì, olú ọlọ́run àwọn ará Bábílónì, ni Nebukadinésárì ń fún ní ìfọkànsìn rẹ̀ ní pàtàkì. Mádọ́kì ni ọba ń gbé ògo gbogbo ìṣẹ́gun rẹ̀ fún. Ní Bábílónì, Nebukadinésárì kọ́ àwọn tẹ́ńpìlì Mádọ́kì àti ti ọ̀pọ̀ ọlọ́run àjúbàfún mìíràn ní Bábílónì, ó sì ṣe wọ́n lọ́ṣọ̀ọ́. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Mádọ́kì ni ọba Bábílónì yìí ya ère wúrà tó gbé kalẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dúrà sí mímọ́ fún. (Dáníẹ́lì 3:1, 2) Ó sì dà bíi pé tọkàntara ni Nebukadinésárì fi gbára lé iṣẹ́ wíwò nígbà tí ó bá ń wéwèé bó ṣe máa jagun.
15, 16. Kí ni Nebukadinésárì ṣe fún Bábílónì, kí ló sì ṣẹlẹ̀ nígbà tó fi títóbi rẹ̀ yangàn?
15 Ní ti pé ó parí odi Bábílónì onílọ̀ọ́po méjì tí baba rẹ̀ bẹ̀rẹ̀, Nebukadinésárì mú kí olú ìlú yìí dà bí ìlú tí kò ṣeé borí. A gbọ́ pé, láti lè tẹ́ ayaba rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ Mídíà, tó ń yán hànhàn fún àwọn òkè àti igbó ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ lọ́rùn, Nebukadinésárì ṣe àwọn ọgbà tí a so rọ̀—tí a kà sí ọ̀kan lára àwọn ohun ìyanu méje ayé ìgbàanì. Ó mú kí Bábílónì di ìlú ńlá olódi tó tóbi jù lọ lákòókò náà. Kẹ́ẹ sì wá wo bó ṣe ń fi ibùjókòó ìjọsìn èké yẹn yangàn tó!
16 Lọ́jọ́ kan, Nebukadinésárì yangàn pé: “Bábílónì Ńlá kọ́ yìí tí èmi fúnra mi . . . kọ́?” Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí Dáníẹ́lì orí kẹrin, ẹsẹ ọgbọ̀n sí ìkẹrìndínlógójì ṣe sọ, “nígbà tí ọ̀rọ̀ náà ṣì wà lẹ́nu ọba,” orí rẹ̀ dàrú. Kò lè ṣàkóso fún ọdún méje gbáko, ó sì ń jẹ ewéko, bí Dáníẹ́lì ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ gẹ́lẹ́. Lẹ́yìn náà, a dá ìjọba rẹ̀ padà fún un. Ǹjẹ́ o mọ ohun tí èyí túmọ̀ sí nínú ọ̀ràn àsọtẹ́lẹ̀? Ṣé o lè ṣàlàyé bí ìmúṣẹ rẹ̀ tó ṣe pàtàkì ṣe gbé wa dé àkókò òpin?
Sísọ̀rọ̀ Lórí Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀
17. Báwo lo ṣe máa ṣàpèjúwe àlá alásọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run jẹ́ kí Nebukadinésárì lá ní ọdún kejì ìjọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alákòóso ayé?
17 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ lórí díẹ̀ nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Dáníẹ́lì. Nínú ọdún kejì ìṣàkóso Nebukadinésárì gẹ́gẹ́ bí alákòóso ayé níbàámu pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì (ọdún 606 sí 605 ṣááju Sànmánì Tiwa), Ọlọ́run jẹ́ kó lá àlá kan tó kó jìnnìjìnnì bá a. Bí Dáníẹ́lì orí kejì ṣe sọ, àlá náà dá lórí ère arabarìbì kan tó ní orí wúrà, igẹ̀ àti apá fàdákà, ikùn àti itan bàbà, ojúgun irin, àti ẹsẹ̀ tó jẹ́ àdàpọ̀ irin àti amọ̀. Kí ni onírúurú ẹ̀ka ère náà dúró fún?
18. Kí ni orí wúrà, igẹ̀ àti apá fàdákà, àti ikùn àti itan bàbà tí ère inú àlá náà ní dúró fún?
18 Wòlíì Ọlọ́run sọ fún Nebukadinésárì pé: “Ìwọ ọba . . . ìwọ alára ni orí wúrà náà.” (Dáníẹ́lì 2:37, 38) Nebukadinésárì ni ó bẹ̀rẹ̀ ìlà àwọn ọba kan tó ṣàkóso Ilẹ̀ Ọba Bábílónì. Mídíà òun Páṣíà, tí igẹ̀ àti apá fàdákà ère náà dúró fún ló gbapò rẹ̀. Ilẹ̀ Ọba Gíríìsì tí ikùn àti itan bàbà dúró fún ló tẹ̀ lé e. Báwo ni agbára ayé yẹn ṣe pilẹ̀ṣẹ̀?
19, 20. Ta ni Alẹkisáńdà Ńlá, ipa wo ló sì kó nínú sísọ ilẹ̀ Gíríìsì di agbára ayé?
19 Ní ọ̀rúndún kẹrin ṣááju Sànmánì Tiwa, ọ̀dọ́mọkùnrin kan kó ipa pàtàkì nínú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì. Ọdún 356 ṣááju Sànmánì Tiwa ni wọ́n bí i, ayé sì wá ń pè é ní Alẹkisáńdà Ńlá. Nígbà tí wọ́n ṣìkà pa Fílípì, baba rẹ̀, lọ́dún 336 ṣááju Sànmánì Tiwa, Alẹkisáńdà tó jẹ́ ẹni ogún ọdún gorí ìtẹ́ ilẹ̀ Makedóníà.
20 Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù May ọdún 334 ṣááju Sànmánì Tiwa, Alẹkisáńdà bẹ̀rẹ̀ sí ja ogun àjàṣẹ́gun kiri. Ọmọ ogun rẹ̀ ò pọ̀, wọn ò ju ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ [30,000] ọmọ ogun tí ń fẹsẹ̀ rìn àti ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [5,000] agẹṣinjagun, ṣùgbọ́n agbára wọn kàmàmà. Ibi Odò Gíráníkọ́sì níhà àríwá ìwọ̀ oòrùn Éṣíà Kékeré (ilẹ̀ Turkey nísinsìnyí), ni Alẹkisáńdà ti kọ́kọ́ ṣẹ́gun ogun tó bá àwọn ará Páṣíà jà ní ọdún 334 ṣááju Sànmánì Tiwa. Nígbà tó fi máa di ọdún 326 ṣááju Sànmánì Tiwa, aṣẹ́gun mádàáwọ́dúró yìí ti tẹ àwọn ará Páṣíà lórí ba, ó sì ti lọ jìnnàjìnnà dé ìlà oòrùn Odò Indus, tó wà ní ilẹ̀ Pakistan òde òní. Àmọ́ wọ́n ṣẹ́gun Alẹkisáńdà nínú ogun ìkẹyìn tó jà nígbà tó wà ní Bábílónì. Ní June 13, ọdún 323 ṣááju Sànmánì Tiwa, ikú, tó jẹ́ àkòtagìrì ọ̀tá lu Alẹkisáńdà pa, lẹ́yìn ọdún méjìlélọ́gbọ̀n àti oṣù mẹ́jọ péré tó lò láyé. (1 Kọ́ríńtì 15:55) Àmọ́, nípasẹ̀ àwọn ogun àjàṣẹ́gun tó ń jà kiri, ilẹ̀ Gíríìsì ti di agbára ayé gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì ṣe sọ.
21. Ní àfikún sí Ilẹ̀ Ọba Róòmù, kí ni agbára ayé mìíràn tí ojúgun irin ère inú àlá náà ṣàpẹẹrẹ?
21 Kí ni ojúgun irin tí ère arabarìbì náà ní dúró fún? Tóò, ilẹ̀ Róòmù ni, tó dà bí irin tó fọ́ Ilẹ̀ Ọba Gíríìsì yángá. Àwọn ará Róòmù pa Jésù Kristi lórí òpó igi oró lọ́dún 33 Sànmánì Tiwa, láìtilẹ̀ bọ̀wọ̀ fún Ìjọba Ọlọ́run tó ń wàásù rẹ̀. Bí Róòmù ṣe ń sapá láti fọ́ ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́, ló bá gbógun ti àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe Ilẹ̀ Ọba Róòmù nìkan ni ojúgun irin ère inú àlá Nebukadinésárì dúró fún, ó tún kan àwọn ìjọba tó ti ara rẹ̀ jáde—ìyẹn ni Agbára Ayé ti Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà.
22. Báwo ni ère inú àlá náà ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti rí i pé a ti wọnú àkókò òpin náà gan-an?
22 Ìkẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ fi hàn pé a ti rìn jìnnà wọnú àkókò òpin, nítorí pé a ti dé ẹsẹ̀ àdàpọ̀ irin àti amọ̀ ère inú àlá náà. Àwọn ìjọba kan lóde òní dà bí irin tàbí abàṣẹwàá, nígbà tí àwọn kan sì dà bí amọ̀. Pẹ̀lú bí amọ̀ ṣe jẹ́ ohun ẹlẹgẹ́ tó, tó sì jẹ́ pé òun la fi dá “ọmọ aráyé,” síbẹ̀ àwọn alákòóso tó dà bí irin ti gbà láti jẹ́ kí àwọn gbáàtúù ènìyàn lẹ́nu ọ̀rọ̀ nínú ọ̀nà táwọn ìjọba gbà ń ṣàkóso wọn. (Dáníẹ́lì 2:43; Jóòbù 10:9) Àmọ́ ṣá o, bí ìgbà tí irin dà pọ̀ mọ́ amọ̀ ni ìgbà tí ìṣàkóso abàṣẹwàá àti àwọn gbáàtúù ènìyàn bá sọ pé àwọn dà pọ̀ mọ́ra. Ṣùgbọ́n Ìjọba Ọlọ́run yóò fi òpin sí àfọ́kù ìṣèlú ayé yìí láìpẹ́.—Dáníẹ́lì 2:44.
23. Báwo lo ṣe máa ṣàpèjúwe àlá tí Dáníẹ́lì lá àti ìran tó rí ní ọdún kìíní ìjọba Bẹliṣásárì?
23 Orí keje àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì tó ń gbani lọ́kàn tún mú wa dé àkókò òpin pẹ̀lú. Orí yìí sọ̀tàn ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún kìíní Bẹliṣásárì ọba Bábílónì. Nígbà yẹn tí Dáníẹ́lì ti lé lẹ́ni àádọ́rin ọdún, ó “lá àlá, ó sì rí àwọn ìran orí rẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀.” Ìran wọ̀nyẹn mà kó jìnnìjìnnì bá a o! Ó kígbe pé: “Wò ó! Ẹ̀fúùfù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ọ̀run ń ru alagbalúgbú òkun sókè. Ẹranko mẹ́rin tí ó tóbi fàkìàfakia sì ń jáde bọ̀ láti inú òkun, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yàtọ̀ síra.” (Dáníẹ́lì 7:1-8, 15) Àwọn àràmàǹdà ẹranko mà rèé o! Àkọ́kọ́ jẹ́ kìnnìún tó níyẹ̀ẹ́ lápá, ìkejì sì dà bíi béárì. Bẹ́ẹ̀ ni àmọ̀tẹ́kùn tó ní ìyẹ́ apá mẹ́rin àti orí mẹ́rin tún jáde wá! Ẹranko kẹrin tó lágbára lọ́nà kíkàmàmà ní eyín irin ńláńlá àti ìwo mẹ́wàá. Ní àárín ìwo mẹ́wàá tó ní ni ìwo kan tí ó “kéré” ti jáde wá, ó ní “ojú bí ojú ènìyàn” àti “ẹnu tí ń sọ àwọn nǹkan kàbìtìkàbìtì.” Abàmì ẹranko mà nìwọ̀nyí o!
24. Ní ìbámu pẹ̀lú Dáníẹ́lì orí keje, ẹsẹ kẹsàn-án sí ìkẹrìnlá, kí ni Dáníẹ́lì rí ní ọ̀run, kí sì ni ìran yìí ń tọ́ka sí?
24 Ìran Dáníẹ́lì tún yíjú sí ọ̀run. (Dáníẹ́lì 7:9-14) Ó rí Jèhófà Ọlọ́run, “Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé,” tó gúnwà lọ́nà ológo bí Onídàájọ́. ‘Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún ń ṣe ìránṣẹ́ fún un, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ́nà ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì ń dúró níwájú rẹ̀.’ Ọlọ́run dá àwọn ẹranko náà lẹ́jọ́ ẹ̀bi, ó gba ìṣàkóso kúrò lọ́wọ́ wọn, ó sì pa ẹranko kẹrin run. Agbára ìṣàkóso fún àkókò tí ó lọ kánrin, lórí “àwọn ènìyàn, àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè àti àwọn èdè,” ni a gbé wọ “ẹnì kan bí ọmọ ènìyàn.” Èyí tọ́ka sí àkókò òpin àti sí gígorí ìtẹ́ tí Jésù Kristi, Ọmọ ènìyàn gorí ìtẹ́ lọ́dún 1914.
25, 26. Àwọn ìbéèrè wo ló lè dìde nígbà táa bá ń ka ìwé Dáníẹ́lì, ìtẹ̀jáde wo ló sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti dáhùn wọn?
25 Ó dájú pé àwọn tó bá ń ka ìwé Dáníẹ́lì máa ní àwọn ìbéèrè. Bí àpẹẹrẹ, kí ni àwọn ẹranko mẹ́rin inú Dáníẹ́lì orí keje túmọ̀ sí? Kí ni àlàyé àsọtẹ́lẹ̀ nípa “àádọ́rin ọ̀sẹ̀,” tí a mẹ́nu kàn ní Dáníẹ́lì orí kẹsàn-án, ẹsẹ kẹrìnlélógún sí ìkẹtàdínlọ́gbọ̀n? Dáníẹ́lì orí kọkànlá náà ńkọ́, àti àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìforígbárí “ọba àríwá” àti “ọba gúúsù”? Kí la sì lè retí pé kí àwọn ọba wọ̀nyí máa ṣe ní àkókò òpin?
26 Tóò, Jèhófà ti jẹ́ kí àwọn ẹni àmì òróró ìránṣẹ́ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé, “àwọn ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ,” bí Dáníẹ́lì orí keje ẹsẹ ìkejìdínlógún ṣe pè wọ́n, lóye irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ yékéyéké. Láfikún sí i, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ti pèsè ìwé kan tí gbogbo wa yóò fi lè túbọ̀ lóye àwọn àkọsílẹ̀ onímìísí tí wòlíì Dáníẹ́lì kọ. (Mátíù 24:45) Èyí wà lárọ̀ọ́wọ́tó báyìí nípasẹ̀ ìwé tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ tẹ̀ jáde náà Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! Ìtẹ̀jáde olójú ewé okòó lé lọ́ọ̀ọ́dúnrún [320] yìí, tó ní àwọn àwòrán mèremère, ti tú gbogbo ọ̀rọ̀ inú ìwé Dáníẹ́lì yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́. Gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ tó ń gbé ìgbàgbọ́ ró àti gbogbo ìtàn tí Dáníẹ́lì, ààyò wòlíì, kọ sílẹ̀ ló gbé yẹ̀ wò.
Ó Ní Ìtumọ̀ Gidi fún Ọjọ́ Wa
27, 28. (a) Níbo ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Dáníẹ́lì ti nímùúṣẹ dé báyìí? (b) Àkókò wo là ń gbé, kí ló sì yẹ ká máa ṣe?
27 Wàyí o, gbé kókó pàtàkì yìí yẹ̀ wò: Yàtọ̀ sí ìwọ̀nba àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ mélòó kan, gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Dáníẹ́lì ló ti nímùúṣẹ. Bí àpẹẹrẹ, a ti rí ipò ayé tí ẹsẹ̀ ère inú àlá Dáníẹ́lì orí kejì dúró fún. Gbígbé Mèsáyà Ọba náà, Jésù Kristi, gorí ìtẹ́ lọ́dún 1914 ló tú ọ̀já kùkùté inú Dáníẹ́lì orí kẹrin. Bẹ́ẹ̀ ni, bí Dáníẹ́lì orí keje ṣe fi hàn, ìgbà náà ni Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé gbé ìṣàkóso fún Ọmọ ènìyàn.—Dáníẹ́lì 7:13, 14; Mátíù 16:27–17:9.
28 Gbogbo ẹ̀ẹ́dégbèjìlá [2,300] ọjọ́ ti inú Dáníẹ́lì orí kẹjọ àti àádọ́rùn-ún lé ní ẹgbẹ̀fà [1,290] ọjọ́ àti ẹ̀ẹ́dégbèje ọjọ́ ó lé márùndínlógójì [1,335] ti inú Dáníẹ́lì orí kejìlá bákan náà ló ti ní ìmúṣẹ kọjá—nínú ìtàn ayé. Ìkẹ́kọ̀ọ́ lórí Dáníẹ́lì orí kọkànlá fi hàn pé gídígbò láàárín “ọba àríwá” àti “ọba gúúsù” ti dé ògógóró rẹ̀. Gbogbo ìwọ̀nyí ló fi kún ẹ̀rí inú Ìwé Mímọ́ pé a ti rìn jìnnà wọnú àkókò òpin. Lójú ipò àrà ọ̀tọ̀ tí a wà níbi tọ́jọ́ dé yìí, kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe? Láìsí tàbí ṣùgbọ́n, a gbọ́dọ̀ máa fiyè sí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà Ọlọ́run.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí ni Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbo ènìyàn mọ̀ nípa ọjọ́ wa?
• Báwo ni ìwé Dáníẹ́lì ṣe lè gbé ìgbàgbọ́ wa ró?
• Kí ni àwọn ẹ̀yà ara ère inú àlá Nebukadinésárì, kí ni ìwọ̀nyí sì ṣàpẹẹrẹ?
• Kí ló yẹ fún àfiyèsí nípa ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé Dáníẹ́lì?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]