Dídúró Ṣinṣin Ti Jèhófà
Dídúró Ṣinṣin Ti Jèhófà
BÍ ÌDÚRÓṢINṢIN bá tilẹ̀ jẹ́ ohun kan tó ṣọ̀wọ́n gan-an lóde òní, síbẹ̀ ó jẹ́ ànímọ́ kan táa ń rí lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ náà, Jèhófà. Ẹnì kan tí ó jẹ́ adúróṣinṣin máa ń dúró gbọn-in lábẹ́ àdánwò, ẹsẹ̀ rẹ̀ kì í sì í yẹ̀ bó ti wù kí àdánwò náà pẹ́ tó. Gbé ọ̀rọ̀ Hesekáyà Ọba rere yẹ̀ wò. Bíbélì sọ pé: “Lẹ́yìn rẹ̀, kò tún wá sí ẹnì kankan tí ó dà bí rẹ̀ nínú gbogbo ọba Júdà, àní àwọn tí wọ́n wà ṣáájú rẹ̀ pàápàá.” Kí ló mú kí Hesekáyà jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ bẹ́ẹ̀? Ó “ń bá a nìṣó ní fífà mọ́ Jèhófà,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó ń jọ́sìn Mólékì, ọlọ́run èké, ló yí i ká. Àní, Hesekáyà “kò yà kúrò nínú títọ̀ [Jèhófà] lẹ́yìn, ṣùgbọ́n ó ń bá a lọ láti pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.”—2 Àwọn Ọba 18:1-6.
Ẹlòmíràn tó tún dúró ṣinṣin ti Jèhófà ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Àkọsílẹ̀ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ táa rí nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì jẹ́rìí sí i dáadáa pé Pọ́ọ̀lù fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ sí Ọlọ́run láìdáwọ́dúró. Nígbà tó kù díẹ̀ kí ìwàláàyè rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé dópin, Pọ́ọ̀lù sọ nípa ara rẹ̀ pé: “Mo ti ja ìjà àtàtà náà, mo ti sáré ní ipa ọ̀nà eré ìje náà dé ìparí, mo ti pa ìgbàgbọ́ mọ́.”—2 Tímótì 4:7.
Ẹ wo àwọn àpẹẹrẹ àtàtà nípa ìdúróṣinṣin táa rí lára Hesekáyà àti Pọ́ọ̀lù! Ì bá dára táa bá lè fara wé ìgbàgbọ́ wọn nípa dídúró ṣinṣin ti Jèhófà, Ọlọ́run Atóbilọ́lá wa.—Hébérù 13:7.