Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mímọ Ọlọ́run Onífẹ̀ẹ́ Náà

Mímọ Ọlọ́run Onífẹ̀ẹ́ Náà

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

Mímọ Ọlọ́run Onífẹ̀ẹ́ Náà

ỌMỌ ọdún mẹ́rìndínlógún ni ará Brazil kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Antônio nígbà tí ayé ti sú u. Èrò pé ìmúlẹ̀mófo ni gbogbo rẹ̀ ló sún un dórí jíjoògùnyó àti mímu ọtí nímukúmu. Ó máa ń ronú àtipa ara rẹ̀ ṣáá ni. Àkókò yìí gan-an ló rántí ohun tí ìyá rẹ̀ sọ fún un tẹ́lẹ̀ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Àmọ́, ibo ni Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ yìí wà?

Kí Antônio lè jáwọ́ nínú àwọn ohun tó ti sọ di bára kú wọ̀nyí, ó wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì kan ládùúgbò rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Antônio di ògbóṣáṣá nínú Ìjọ Kátólíìkì, síbẹ̀ ó ṣì ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ Jésù tó sọ pé, “Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira” ṣì ń kọ ọ́ lóminú. (Jòhánù 8:32) Irú òmìnira wo ni Jésù ṣèlérí? Ṣọ́ọ̀ṣì náà kò lè dáhùn àwọn ìbéèrè rẹ̀ lọ́nà tó tẹ́ ẹ lọ́rùn. Ni Antônio bá tún yí padà bìrí sí ìwà rẹ̀ àtijọ́. Ó tilẹ̀ tún wá gàgaàrá lọ́tẹ̀ yìí.

Àárín àkókò yìí gan-an ni Maria, ìyàwó Antônio bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Antônio ò lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ìyàwó rẹ̀ ń kọ́ yìí, àmọ́ ó ka àwọn Ẹlẹ́rìí sí àwọn tó ń ṣe “ìsìn àwọn ará Amẹ́ríkà tí wọ́n sì ń ṣojú fún ìjọba àgbókèèrè-jẹ-gàba ti Amẹ́ríkà.”

Láìrẹ̀wẹ̀sì, Maria máa ń fi àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ àti Jí! sáwọn ibì kan káàkiri inú ilé, ìyẹn àwọn tó ní àwọn àpilẹ̀kọ tó rò pé yóò pe àfiyèsí Antônio. Nígbà tó sì jẹ́ pé Antônio nífẹ̀ẹ́ sí ìwé kíkà, ó máa ń yẹ àwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyí wò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tí ìyàwó rẹ̀ kò bá sí níbẹ̀. Ní ìgbà àkọ́kọ́ láyé rẹ̀, ó rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè rẹ̀ tó jẹ mọ́ Bíbélì. Ó sọ pé: “Mo tún bẹ̀rẹ̀ sí kíyè sí ìfẹ́ àti inú rere tí ìyàwó mi àti àwọn Ẹlẹ́rìí ń fi hàn sí mi.”

Nígbà tó di àárín ọdún 1992, Antônio pinnu pé òun náà yóò fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́, kò fi oògùn tó ń lò nílòkulò sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ló ń mutí yó kẹ́ri. Bí òun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan ṣe ń bọ̀ láti ìletò kan ní òru ọjọ́ kan ni àwọn ọlọ́pàá dá wọn dúró. Bí àwọn ọlọ́pàá ṣe rí kokéènì lápò Antônio ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí lù ú. Ọlọ́pàá kan tì í sínú ẹrẹ̀, ó sì na ìbọn olójú méjì sí i lójú. Ọlọ́pàá mìíràn wá kígbe pé: “Pa á sọnù!”

Bí Antônio ṣe dùbúlẹ̀ sínú ẹrẹ̀ yẹn ló ń rántí gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀. Kìkì àwọn ohun rere tó lè rántí ni ìdílé rẹ̀ àti Jèhófà. Ó gbàdúrà ṣókí, ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ Jèhófà. Láìsí ìdí kan tó ṣe gúnmọ́, àwọn ọlọ́pàá náà fi í sílẹ̀. Ó lọ sílé pẹ̀lú ìdánilójú pé Jèhófà ló dáàbò bo òun.

Antônio wá túbọ̀ jára mọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó ṣe ọ̀pọ̀ ìyípadà kí ó lè mú inú Jèhófà dùn. (Éfésù 4:22-24) Nípa lílo ìkóra-ẹni-níjàánu, ó bẹ̀rẹ̀ sí kojú ìṣòro oògùn líle rẹ̀. Síbẹ̀, ó ní láti gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn. Oṣù méjì tó lò ní ilé ìwòsàn ìmúbọ̀sípò fún un láǹfààní àtika ọ̀pọ̀ ìtẹ̀jáde tí a gbé karí Bíbélì, títí kan ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Antônio wá bẹ̀rẹ̀ sí sọ ohun tó ń kọ́ fún àwọn mìíràn tó ń gba ìtọ́jú.

Lẹ́yìn tí Antônio kúrò ní ilé ìwòsàn náà, ó ń bá ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ń kọ́ lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí nìṣó. Lónìí, Antônio, Maria, àwọn ọmọbìnrin wọn méjèèjì, àti ìyá Antônio ti ń sin Jèhófà pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé tó ṣọ̀kan. Antônio sọ pé: “Mo ti wá mọ ohun náà gan-an tó túmọ̀ sí ní báyìí pé ‘Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.’”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Ó ń wàásù ní Rio de Janeiro