Fífúnrúgbìn Òtítọ́ Ìjọba Náà
Fífúnrúgbìn Òtítọ́ Ìjọba Náà
“Ní òwúrọ̀, fún irúgbìn rẹ àti títí di ìrọ̀lẹ́, má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ sinmi.”—ONÍWÀÁSÙ 11:6.
1. Lọ́nà wo làwọn Kristẹni fi ń fúnrúgbìn lónìí?
IṢẸ́ pàtàkì ni iṣẹ́ àgbẹ̀ láwùjọ àwọn Hébérù ayé ọjọ́un. Ìdí nìyẹn tí Jésù, tó lo gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn ní Ilẹ̀ Ìlérí, fi lo àwọn àpèjúwe tó jẹ mọ́ iṣẹ́ àgbẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ó fi wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run wé fífúnrúgbìn. (Mátíù 13:1-9, 18-23; Lúùkù 8:5-15) Títí di báa ti ń wí yìí, yálà à ń gbé láwùjọ tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ àgbẹ̀ àbí bẹ́ẹ̀ kọ́, fífún irúgbìn tẹ̀mí bí àwọn àgbẹ̀ ṣe ń fúnrúgbìn ni iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ táwọn Kristẹni ń ṣe.
2. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù wa ti ṣe pàtàkì tó, kí sì ni díẹ̀ lára ohun tí à ń ṣe lónìí fún ìtẹ̀síwájú iṣẹ́ náà?
2 Àǹfààní ńlá ló jẹ́ láti nípìn-ín nínú fífúnrúgbìn òtítọ́ Bíbélì ní àkókò òpin yìí. Ìwé Róòmù orí kẹwàá, ẹsẹ ìkẹrìnlá àti ìkẹẹ̀ẹ́dógún tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì iṣẹ́ yìí, ó sọ pé: “Báwo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yóò ṣe gbọ́ láìsí ẹnì kan láti wàásù? Báwo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yóò ṣe wàásù láìjẹ́ pé a rán wọn jáde? Gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ẹsẹ̀ àwọn tí ń polongo ìhìn rere àwọn ohun rere mà dára rèǹtè-rente o!’” Ó ṣe pàtàkì gan-an lákòókò táa wà yìí, àní ju ti ìgbàkigbà rí lọ, láti tẹ̀ síwájú pẹ̀lú ẹ̀mí tó dáa báa ti ń ṣe iṣẹ́ yìí tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́. Ìdí nìyẹn táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń báṣẹ́ lọ pẹrẹu láìbojúwẹ̀yìn, tí wọ́n ń tẹ Bíbélì àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jáde, tí wọ́n sì ń pín wọn kiri ní òjì-lé-lọ́ọ̀ọ́dúnrún [340] èdè. Àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tí wọ́n lé ní ẹgbàá mẹ́sàn-án [18,000] ló ń ṣiṣẹ́ lórí àwọn ìwé wọ̀nyí ní orílé iṣẹ́ àti ní àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ wọn ní onírúurú ilẹ̀. Ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́fà àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń nípìn-ín nínú pípín ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọ̀nyí jákèjádò ayé.
3. Kí ni a ń ṣe ní àṣeyọrí nípa fífúnrúgbìn òtítọ́ Ìjọba náà?
3 Èso wo ni iṣẹ́ àṣekára yìí ti so? Gẹ́gẹ́ bó ti rí ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ẹ̀sìn Kristẹni, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló ń tẹ́wọ́ gba òtítọ́ lónìí. (Ìṣe 2:41, 46, 47) Àmọ́ ohun tó tún ṣe pàtàkì ju ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn akéde Ìjọba táa ṣẹ̀ṣẹ̀ batisí ni òtítọ́ náà pé iṣẹ́ ìjẹ́rìí ńlá yìí ń ṣètìlẹyìn fún ìsọdimímọ́ orúkọ Jèhófà àti ìdáláre rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà. (Mátíù 6:9) Síwájú sí i, ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń tún ayé ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe, ó sì lè ṣamọ̀nà sí ìgbàlà wọn.—Ìṣe 13:47.
4. Báwo ni ọ̀ràn àwọn tí àwọn àpọ́sítélì wàásù fún ṣe ká wọn lára tó?
4 Àwọn àpọ́sítélì mọ̀ ní àmọ̀dunjú pé ìhìn rere náà ṣe pàtàkì púpọ̀púpọ̀ torí pé ẹ̀mí àwọn èèyàn wé mọ́ ọn, ọ̀ràn àwọn tí wọ́n wàásù fún sì ká wọn lára gan-an ni. Èyí ṣe kedere nínú ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, nígbà tó kọ̀wé pé: “Ní níní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún yín, ó dùn mọ́ wa nínú jọjọ láti fún yín, kì í ṣe ìhìn rere Ọlọ́run nìkan, ṣùgbọ́n ọkàn àwa fúnra wa pẹ̀lú, nítorí ẹ di olùfẹ́ ọ̀wọ́n fún wa.” (1 Tẹsalóníkà 2:8) Nípa fífi irú àníyàn àtọkànwá bẹ́ẹ̀ hàn fáwọn èèyàn, ńṣe ni Pọ́ọ̀lù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù ń fara wé Jésù àtàwọn áńgẹ́lì ọ̀run, àwọn tí iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà yìí wà ní góńgó ẹ̀mí wọn. Ẹ jẹ́ ká ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ipa pàtàkì táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run wọ̀nyí tí ń bẹ lọ́run ń kó nínú fífúnrúgbìn òtítọ́ Ìjọba náà, kí á sì wo bí àpẹẹrẹ wọn ṣe ń fún wa níṣìírí láti ṣe ipa tiwa.
Jésù—Afúnrúgbìn Òtítọ́ Ìjọba Náà
5. Iṣẹ́ wo ni Jésù fi ara rẹ̀ jìn nígbà tó wà láyé?
5 Jésù, ọkùnrin pípé, ní agbára láti pèsè ọ̀pọ̀ ohun rere nípa tara fáwọn èèyàn tó wà nígbà ayé rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ó lè ti wá ojútùú sí àwọn ohun tó rú àwọn èèyàn ìgbà ayé rẹ̀ lójú nínú iṣẹ́ ìṣègùn, tàbí kó fi kún ìmọ̀ ènìyàn nípa àwọn ẹ̀kọ́ mìíràn tó jẹ́ ti sáyẹ́ǹsì. Síbẹ̀, ó là á mọ́lẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ pé iṣẹ́ táa gbé lé òun lọ́wọ́ ni láti wàásù ìhìn rere. (Lúùkù 4:17-21) Nígbà tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ sì ń parí lọ, ó ṣàlàyé pé: “Nítorí èyí ni a ṣe bí mi, nítorí èyí sì ni mo ṣe wá sí ayé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́.” (Jòhánù 18:37) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ṣe ni ọwọ́ rẹ̀ dí fọ́fọ́ lẹ́nu fífúnrúgbìn òtítọ́ Ìjọba náà. Kíkọ́ àwọn èèyàn tó wà láyé nígbà yẹn lẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run àtàwọn ète Rẹ̀ ṣe pàtàkì ju ìmọ̀ ẹ̀kọ́ mìíràn tí Jésù ì bá fún wọn.—Róòmù 11:33-36.
6, 7. (a) Àdéhùn pàtàkì wo ni Jésù ṣe kó tó gòkè re ọ̀run, báwo ló sì ṣe ń mú un ṣẹ? (b) Báwo ni ojú tí Jésù fi wo iṣẹ́ ìwàásù náà ṣe ń nípa lórí ìwọ alára?
6 Jésù pe ara rẹ̀ ní Afúnrúgbìn òtítọ́ Ìjọba náà. (Jòhánù 4:35-38) Gbogbo àǹfààní tó ṣí sílẹ̀ ló fi fúnrúgbìn ìhìn rere náà. Kódà nígbà tó ń kú lọ lórí òpó igi, ó pòkìkí ìhìn rere nípa párádísè orí ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ iwájú. (Lúùkù 23:43) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àníyàn àtọkànwá rẹ̀ pé kí á wàásù ìhìn rere náà kò dópin nígbà tó kú lórí òpó igi oró. Kó tó di pé ó gòkè re ọ̀run, ó pàṣẹ pé káwọn àpọ́sítélì òun máa bá a lọ ní fífúnrúgbìn òtítọ́ Ìjọba náà, kí wọ́n sì máa sọni di ọmọ ẹ̀yìn. Nígbà náà ni Jésù wá ṣe ìlérí pàtàkì kan. Ó sọ pé: “Wò ó! mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.”—Mátíù 28:19, 20.
7 Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, Jésù ṣàdéhùn pé òun yóò máa ti iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà lẹ́yìn, òun yóò máa darí rẹ̀, òun yóò sì máa dáàbò bò ó “ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” Títí di òní olónìí ni Jésù ṣì nífẹ̀ẹ́ gidigidi sí iṣẹ́ ìjíhìnrere náà. Òun ni Aṣáájú wa, tó ń bójú tó iṣẹ́ fífúnrúgbìn òtítọ́ Ìjọba náà. (Mátíù 23:10) Gẹ́gẹ́ bí Orí ìjọ Kristẹni, ìkáwọ́ rẹ̀ ni Jèhófà fi iṣẹ́ tó kárí ayé yìí sí.—Éfésù 1:22, 23; Kólósè 1:18.
Àwọn Áńgẹ́lì Ń Polongo Làbárè Amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀
8, 9. (a) Báwo làwọn áńgẹ́lì ṣe fi hàn pé àwọn ní ìfẹ́ jíjinlẹ̀ sí àwọn ìgbòkègbodò ọmọ aráyé? (b) Báwo la ṣe lè sọ pé a jẹ́ ìran àpéwò ní gbọ̀ngàn ìwòran fáwọn áńgẹ́lì?
8 Nígbà tí Jèhófà dá ilẹ̀ ayé, àwọn áńgẹ́lì “fi ìdùnnú ké jáde, [wọ́n] . . . sì bẹ̀rẹ̀ sí hó yèè nínú ìyìn.” (Jóòbù 38:4-7) Látìgbà yẹn làwọn ẹ̀dá ọ̀run wọ̀nyí ti ní ìfẹ́ jíjinlẹ̀ sí àwọn ìgbòkègbodò ọmọ aráyé. Jèhófà ti lò wọ́n láti ṣe àwọn ìkéde àtọ̀runwá fáwọn èèyàn. (Sáàmù 103:20) Wọ́n sì ti ṣe èyí gan-an nínú àwọn ìkéde tó jẹ mọ́ títan ìhìn rere kálẹ̀ ní ọjọ́ wa. Nínú ìṣípayá táa fi fún àpọ́sítélì Jòhánù, ó rí “áńgẹ́lì . . . tí ń fò ní agbedeméjì ọ̀run,” tó ní “ìhìn rere àìnípẹ̀kun láti polongo gẹ́gẹ́ bí làbárè amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn, ó ń sọ ní ohùn rara pé: ‘Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí wákàtí ìdájọ́ láti ọwọ́ rẹ̀ ti dé.’”—Ìṣípayá 14:6, 7.
9 Bíbélì pe àwọn áńgẹ́lì ní “ẹ̀mí fún iṣẹ́ ìsìn gbogbo ènìyàn, tí a rán jáde láti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn tí yóò jogún ìgbàlà.” (Hébérù 1:14) Bí àwọn áńgẹ́lì ti ń fi ìtara ṣe iṣẹ́ táa yàn fún wọn, wọ́n láǹfààní láti fara balẹ̀ wo àwa àti iṣẹ́ wa. Bí ẹni pé a wà lórí ìtàgé nínú gbọ̀ngàn ìwòran tó wà lójútáyé, a ń ṣe iṣẹ́ wa níwájú àwùjọ tí ń wòran látọ̀run. (1 Kọ́ríńtì 4:9) Ẹ wo bí èyí ṣe ń múni ṣe gírí, tó sì tún ń wúni lórí tó láti mọ̀ pé a kò dá nìkan ṣiṣẹ́ fífúnrúgbìn òtítọ́ Ìjọba náà!
A Ń Fi Ìháragàgà Ṣe Ojúṣe Wa
10. Báwo la ṣe lè lo ìmọ̀ràn rere tó wà nínú Oníwàásù orí kọkànlá, ẹsẹ ìkẹfà nínú iṣẹ́ ìjíhìnrere wa?
10 Èé ṣe tí Jésù àtàwọn áńgẹ́lì fi nífẹ̀ẹ́ tó pọ̀ tó yìí sí iṣẹ́ wa? Jésù mẹ́nu kan ìdí kan nígbà tó sọ pé: “Mo sọ fún yín, . . . ìdùnnú . . . máa ń sọ láàárín àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronú pìwà dà.” (Lúùkù 15:10) Àwa náà ní ìfẹ́ jíjinlẹ̀ yẹn sí àwọn èèyàn. Ìdí nìyẹn táa fi máa ń sa gbogbo ipá wa láti fúnrúgbìn òtítọ́ Ìjọba náà níbi gbogbo. Ọ̀rọ̀ tó wà nínú Oníwàásù orí kọkànlá, ẹsẹ ìkẹfà ṣeé lò fún iṣẹ́ wa. Bíbélì gbà wá níyànjú níbẹ̀ pé: “Ní òwúrọ̀, fún irúgbìn rẹ àti títí di ìrọ̀lẹ́, má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ sinmi; nítorí ìwọ kò mọ ibi tí èyí yóò ti ṣe àṣeyọrí sí rere, yálà níhìn-ín tàbí lọ́hùn-ún, tàbí kẹ̀, bóyá àwọn méjèèjì ni yóò dára bákan náà.” Òótọ́ kúkú ni pé ká tó rí ẹnì kan tó tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ tí à ń jẹ́, a lè ti rí ọgọ́rọ̀ọ̀rún tàbí ẹgbẹẹgbẹ̀rún pàápàá tí kò tẹ́wọ́ gbà á. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn áńgẹ́lì, inú wa máa ń dùn nígbà tí “ẹlẹ́ṣẹ̀ kan” ṣoṣo pàápàá bá tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìgbàlà.
11. Báwo làwọn ìtẹ̀jáde táa gbé ka Bíbélì ti gbéṣẹ́ tó?
11 Iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere kì í ṣe iṣẹ́ kékeré. Ìrànlọ́wọ́ pàtàkì kan táa ní nínú iṣẹ́ yìí làwọn ìtẹ̀jáde táa gbé ka Bíbélì, táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò. Ní àwọn ọ̀nà kan, ìtẹ̀jáde wọ̀nyí pẹ̀lú dà bí àwọn irúgbìn táa fọ́n síbi gbogbo. A ò mọ ibi tí wọn yóò ti so èso. Nígbà míì, ìtẹ̀jáde kan lè máa lọ ní àtọwọ́dọ́wọ́, kó tó dọ́wọ́ ẹni tó máa kà á. Jésù àtàwọn áńgẹ́lì tilẹ̀ lè mú káwọn nǹkan ṣẹlẹ̀ nígbà míì tí yóò ṣílẹ̀kùn àǹfààní fáwọn ọlọ́kàn títọ́. Ẹ jẹ́ ká gbọ́ àwọn ìrírí díẹ̀ tó fi hàn bí Jèhófà ṣe lè mú káwọn àgbàyanu àbájáde tí a kò retí wáyé, nípasẹ̀ àwọn ìwé táa fi fún àwọn èèyàn.
Iṣẹ́ Ọlọ́run Tòótọ́
12. Báwo ni ògbólógbòó ìwé ìròyìn kan ṣe ran ìdílé kan lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà?
12 Ní ọdún 1953, Robert, àti Lila, àtàwọn ọmọ wọn ṣí kúrò ní ìlú ńlá lọ sí ẹgẹrẹmìtì ilé oko kan tó wà ní abúléko Pennsylvania, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Láìpẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n kó débẹ̀, Robert pinnu pé òun máa kọ́ ilé ìwẹ̀ kan sábẹ́ àtẹ̀gùn táa ṣe mọ́ ara ògiri. Lẹ́yìn yíyọ àwọn pákó kan, ó wá rí i pé àwọn èkúté ti kó àwọn bébà táa ti gé wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́, àti èèpo àsálà, àtàwọn pàǹtírí mìíràn pa mọ́ sẹ́yìn ògiri. Níbẹ̀, nínú gbogbo pàǹtírí yẹn, ni ẹ̀dà ìwé ìròyìn The Golden Age kan wà. Robert nífẹ̀ẹ́ ní pàtàkì sí àpilẹ̀kọ kan nínú rẹ̀ tó dá lórí ọmọ títọ́. Ìtọ́ni tó ṣe kedere, táa gbé ka Bíbélì tó wà nínú ìwé ìròyìn náà wọ̀ ọ́ lọ́kàn tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi sọ fún Lila pé “ẹ̀sìn The Golden Age” làwọn máa ṣe. Láàárín ọ̀sẹ̀ díẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá kanlẹ̀kùn wọn, ṣùgbọ́n Robert sọ fún wọn pé “ẹ̀sìn Golden Age” nìkan ló wu àwọn í ṣe. Àwọn Ẹlẹ́rìí náà ṣàlàyé pé Awake! [Jí!] lorúkọ tuntun táa ń pe The Golden Age báyìí. Bí àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe bẹ̀rẹ̀ sí bá Robert àti Lila ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé nìyẹn, wọ́n sì ṣèrìbọmi nígbà tó yá. Ẹ̀wẹ̀, àwọn náà gbin irúgbìn òtítọ́ sínú àwọn ọmọ wọn, ó sì so wọ̀ǹtìwọnti. Lónìí, ó lé ní ogún àwọn mẹ́ńbà ìdílé yìí, títí kan gbogbo àwọn ọmọ Robert àti Lila méjèèje, tí wọ́n ti ṣèrìbọmi, tí wọ́n sì jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run.
13. Kí ló sún tọkọtaya kan ní Puerto Rico láti fìfẹ́ hàn sí Bíbélì?
13 Ní nǹkan bí ogójì ọdún sẹ́yìn, William àti Ada, tó jẹ́ tọkọtaya láti orílẹ̀-èdè Puerto Rico, kò nífẹ̀ẹ́ sí kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rárá. Ìgbàkigbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá kanlẹ̀kùn tọkọtaya yìí, ṣe ni wọ́n máa ń díbọ́n pé àwọn ò sí nílé. Lọ́jọ́ kan, William lọ síbi tí wọ́n ń kó ẹrù àtúntà sí, ó fẹ́ lọ ra nǹkan kan tó fẹ́ fi tún ilé ṣe. Bó ti yí ẹ̀yìn padà kóun máa lọ, ló bá tajú kán rí ìwé aláwọ̀ ewé àdàpọ̀ mọ́ yẹ́lò kan, tó wà nínú ohun ìkódọ̀tísí ńlá kan. Orúkọ ìwé náà ni Religion, ìwé kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti tẹ̀ jáde ní 1940. William mú ìwé náà wálé, inú rẹ̀ sì dùn gan-an láti kà nípa ìyàtọ̀ tó wà láàárín ẹ̀sìn èké àti ẹ̀sìn tòótọ́. Ìgbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ William àti Ada wò lẹ́yìn náà, wọ́n fi tayọ̀tayọ̀ fetí sí ìwàásù wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bá tọkọtaya náà ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Oṣù mélòó kan lẹ́yìn náà ni a batisí wọn nígbà Àpéjọ Àgbáyé Ìfẹ́ Àtọ̀runwá tó wáyé lọ́dún 1958. Látìgbà yẹn, wọ́n ti ran àwọn èèyàn tó lé ní àádọ́ta lọ́wọ́ láti di apá kan ẹgbẹ́ àwọn ará wa tí í ṣe Kristẹni.
14. Gẹ́gẹ́ bí ìrírí kan ti fi hàn, agbára wo ni àwọn ìwé wa táa gbé ka Bíbélì ní?
14 Ọmọ ọdún mọ́kànlá péré ni Karl, ó sì ya ìpátá díẹ̀. Ó jọ pé gbogbo ìgbà ló máa ń wọ̀jọ̀gbọ̀n. Bàbá rẹ̀, tí í ṣe oníwàásù Ìjọ Mẹ́tọ́díìsì, tó tún jẹ́ ará Jámánì, ti kọ́ ọ pé inú iná ọ̀run àpáàdì làwọn èèyàn búburú ń lọ lẹ́yìn ikú. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ẹ̀rù ọ̀run àpáàdì wá ń ba Karl gan-an. Lọ́jọ́ kan ní 1917, Karl rí ìwé ìléwọ́ kan lójú pópó, ó sì mú un. Bó ti ń kà á, kíá ni ojú rẹ̀ lọ síbi ìbéèrè náà tó sọ pé: “Kí ni ọ̀run àpáàdì?” Ìwé náà jẹ́ ìwé ìpè láti wá síbi àsọyé kan fún gbogbo èèyàn lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ náà ọ̀run àpáàdì, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, táa mọ̀ sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí, ló ṣètò àsọyé ọ̀hún. Ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà, lẹ́yìn tí Karl ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fúngbà bíi mélòó kan, a batisí rẹ̀, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ di ọ̀kan lára àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ní 1925, wọ́n ké sí i pé kó wá ṣiṣẹ́ ní orílé iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—ibẹ̀ ló sì ti ń sìn dòní. Ó ti lé ní ọgọ́rin ọdún tó ti wà lẹ́nu iṣẹ́ Kristẹni yìí, èyí tó bẹ̀rẹ̀ wẹ́rẹ́ pẹ̀lú ìwé pélébé tó rí lójú pópó.
15. Kí ni Jèhófà lè ṣe, bó bá ṣe tọ́ lójú rẹ̀?
15 Lóòótọ́, ó kọjá agbára èèyàn láti mọ̀ dájú bóyá àwọn áńgẹ́lì ló darí àwọn ìrírí yìí ní tààràtà, tàbí bóyá ó ní ibi tí wọ́n darí rẹ̀ dé. Síbẹ̀, a ò gbọ́dọ̀ ṣiyèméjì nípa bóyá Jésù àtàwọn áńgẹ́lì ń kópa gúnmọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù àti pé Jèhófà lè darí àwọn nǹkan bó bá ṣe tọ́ lójú rẹ̀. Àwọn ìrírí wọ̀nyí àti ọ̀pọ̀ irú wọn, fi hàn pé àwọn ìwé wa lè ní ipa rere nígbà táa bá fi wọ́n fáwọn èèyàn.
A Ti Fi Ìṣúra Kan Síkàáwọ́ Wa
16. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ 2 Kọ́ríńtì 4:7?
16 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ‘ìṣúra tó wà nínú àwọn ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe.’ Ìṣúra yẹn ni iṣẹ́ ìwàásù tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́, ohun èlò náà tí a fi amọ̀ ṣe ni àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí Jèhófà fi ìṣúra yìí síkàáwọ́ wọn. Níwọ̀n bí àwọn ẹ̀dá ènìyàn wọ̀nyí ti jẹ́ aláìpé, tí ó sì níbi tí agbára wọ́n mọ, Pọ́ọ̀lù ń bá a lọ láti sọ pé ìyọrísí fífún táa fún wọn ní irú iṣẹ́ yẹn ni “kí agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá lè jẹ́ ti Ọlọ́run, kí ó má sì jẹ́ èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ àwa fúnra wa jáde.” (2 Kọ́ríńtì 4:7) Dájúdájú, a lè gbára lé Jèhófà pé kó fún wa lágbára táa nílò ká lè ṣe iṣẹ́ náà láṣeyọrí.
17. Kí ni a óò bá pàdé báa ti ń fúnrúgbìn òtítọ́ Ìjọba náà, ṣùgbọ́n èé ṣe tó fi yẹ ká ní ojú ìwòye tó dáa?
17 A ní láti fi àwọn nǹkan kan du ara wa lọ́pọ̀ ìgbà. Ó lè nira tàbí kí ó má rọ̀ wá lọ́rùn láti ṣiṣẹ́ ní àwọn ìpínlẹ̀ kan. Àwọn àgbègbè kan wà tó jẹ́ pé ńṣe làwọn tó pọ̀ jù lọ ń fi wá pegi, kódà kó tiẹ̀ jẹ́ pé ìjà ni wọ́n ń gbé kò wá. A lè sapá-sapá nírú àwọn àdúgbò yẹn láìṣe àṣeyọrí gúnmọ́. Ṣùgbọ́n ìsapá náà tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ, nígbà tó jẹ́ pé ọ̀ràn tó wà nílẹ̀ yìí kì í ṣe kékeré rárá. Rántí pé àwọn irúgbìn tóo bá gbìn lè fún àwọn èèyàn ní ayọ̀ nísinsìnyí àti ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù 126:6 ti já sí òtítọ́, ó kà pé: “Láìkùnà, ẹni tí ń jáde lọ, àní tí ó ń sunkún, bí ó ti gbé irúgbìn ẹ̀kún àpò dání, láìkùnà, yóò fi igbe ìdùnnú wọlé wá, bí ó ti gbé àwọn ìtí rẹ̀ dání.”
18. Báwo la ṣe lè máa fiyè sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa nígbà gbogbo, kí sì ni ìdí tó fi yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀?
18 Ẹ jẹ́ ká lo gbogbo àǹfààní yíyẹ láti fúnrúgbìn òtítọ́ Ìjọba náà ní yanturu. Ǹjẹ́ kí a má ṣe gbàgbé láé pé, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwa là ń fúnrúgbìn táa sì ń bomi rin ín, síbẹ̀ Jèhófà ló ń jẹ́ kó dàgbà. (1 Kọ́ríńtì 3:6, 7) Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí Jésù àtàwọn áńgẹ́lì ti ń ṣe ojúṣe tiwọn láṣeyọrí, Jèhófà ń retí pé kí àwa náà ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ tiwa láṣeyọrí ní kíkún. (2 Tímótì 4:5) Ǹjẹ́ kí a máa fiyè sí ẹ̀kọ́ wa, àti ìṣarasíhùwà wa, àti ìháragàgà wa nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Kí nìdí? Pọ́ọ̀lù dáhùn pé: “Nípa ṣíṣe èyí, ìwọ yóò gba ara rẹ àti àwọn tí ń fetí sí ọ là.”—1 Tímótì 4:16.
Ẹ̀kọ́ Wo La Rí Kọ́?
• Lọ́nà wo ni iṣẹ́ fífúnrúgbìn táa ń ṣe fi ń yọrí sí rere?
• Báwo ni Jésù Kristi àtàwọn áńgẹ́lì ṣe ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìjíhìnrere lónìí?
• Èé ṣe tó fi yẹ ká máa fúnrúgbìn òtítọ́ Ìjọba náà yanturu?
• Nígbà táwọn èèyàn bá fi wá pegi tàbí tí wọ́n gbéjà kò wá nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, kí ló yẹ kó sún wa láti forí tì í?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Gẹ́gẹ́ bí àwọn àgbẹ̀ ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, àwọn Kristẹni lónìí ń fúnrúgbìn òtítọ́ Ìjọba náà ní yanturu
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ ọ̀kan-ò-jọ̀kan ìwé táa gbé ka Bíbélì jáde, wọ́n sì ń pín wọn kiri ní òjì-lé-lọ́ọ̀ọ́dúnrún [340] èdè