Àwọn Ẹbọ Ìyìn Tí Inú Jèhófà Dùn Sí
Àwọn Ẹbọ Ìyìn Tí Inú Jèhófà Dùn Sí
“Ẹ fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà.”—Róòmù 12:1.
1. Kí ni Bíbélì sọ nípa ibi tí agbára ìtóye àwọn ẹbọ tí wọ́n rú lábẹ́ Òfin Mósè mọ?
“NÍWỌ̀N bí Òfin ti ní òjìji àwọn ohun rere tí ń bọ̀, ṣùgbọ́n tí kì í ṣe kókó inú àwọn ohun náà gan-an, àwọn ènìyàn kò lè fi àwọn ẹbọ kan náà tí wọ́n ń rú nígbà gbogbo láti ọdún dé ọdún sọ àwọn tí ń wá di pípé.” (Hébérù 10:1) Nínú ọ̀rọ̀ tó sọjú abẹ níkòó yìí, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù là á mọ́lẹ̀ pé gbogbo ẹbọ táwọn èèyàn rú lábẹ́ Òfin Mósè kò ní ìtóye pípẹ́ títí fún ìgbàlà aráyé.—Kólósè 2:16, 17.
2. Èé ṣe tí sísapá láti lóye kúlẹ̀kúlẹ̀ ìsọfúnni inú Bíbélì nípa àwọn ọrẹ ẹbọ àti àwọn ẹbọ tó wà nínú Òfin kò fi lè já sásán?
2 Èyí ha túmọ̀ sí pé ìsọfúnni tó wà nínú àwọn Ìwé Márùn-ún Àkọ́kọ́ nínú Bíbélì nípa àwọn ọrẹ ẹbọ àti àwọn ẹbọ kò wúlò rárá fún àwa Kristẹni lónìí ni bí? Rárá o, àní lẹ́nu àìpẹ́ yìí ni àwọn tó forúkọ sílẹ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run nínú àwọn ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé, ṣẹ̀ṣẹ̀ parí kíka àwọn ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Bíbélì, ó sì lé díẹ̀ lọ́dún kan tí wọ́n fi kà á. Àwọn kan ti sapá kárakára láti kà á, kí wọ́n sì lóye gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀. Gbogbo ìsapá wọn ha ti já sásán bí? Kò tiẹ̀ lè já sásán ni, torí pé “gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.” (Róòmù 15:4) Ìbéèrè tó wá wà nílẹ̀ báyìí ni pé, “Ìtọ́ni” àti “ìtùnú” wo la lè rí jèrè látinú àkójọ ìsọfúnni tó wà nínú Òfin nípa àwọn ọrẹ ẹbọ àti àwọn ẹbọ?
Fún Ìtọ́ni àti Ìtùnú Wa
3. Kí ni ohun pàtàkì táa nílò?
3 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a kò sọ fún wa pé a gbọ́dọ̀ máa rú àwọn ẹbọ gidi tí Òfin là sílẹ̀, síbẹ̀ a ṣì nílò ohun tí àwọn ẹbọ náà ṣe ní àwọn ọ̀nà kan fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, èyíinì ni, kí a lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wa gbà, kí a sì rí ojú rere Ọlọ́run. Níwọ̀n bí a kì í ti í rú ẹbọ gidi mọ́, báwo la ṣe lè rí irú àwọn àǹfààní yẹn? Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí i pé ó ní ibi tí agbára àwọn ẹbọ tí a fi ẹran rú mọ, ó wá polongo pé: “Nígbà tí [Jésù] wá sí ayé, ó wí pé: ‘Ẹbọ àti ọrẹ ẹbọ ni ìwọ kò fẹ́, ṣùgbọ́n ìwọ ti pèsè ara kan fún mi. Ìwọ kò tẹ́wọ́ gba àwọn odindi ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.’ Nígbà náà ni mo wí pé, ‘Wò ó! Mo dé (nínú àkájọ ìwé ni a ti kọ ọ́ nípa mi) láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run.’”—Hébérù 10:5-7.
4. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe lo Sáàmù ogójì, ẹsẹ kẹfà sí ìkẹjọ fún Jésù Kristi?
4 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Sáàmù ogójì, ẹsẹ kẹfà sí ìkẹjọ, ó sọ pé Jésù kò wá láti mú kí “ẹbọ àti ọrẹ ẹbọ,” àti “àwọn odindi ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀” máa wà lọ títí, Ọlọ́run ò tiẹ̀ tẹ́wọ́ gba gbogbo rẹ̀ mọ́ nígbà tí Pọ́ọ̀lù fi ń kọ̀wé yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ara tí Jésù gbé wá jẹ́ ara kan tí Bàbá rẹ̀ ọ̀run pèsè fún un, ara tí ó ṣe rẹ́gí pẹ̀lú èyí tí Ọlọ́run pèsè nígbà tí Ó dá Ádámù. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7; Lúùkù 1:35; 1 Kọ́ríńtì 15:22, 45) Gẹ́gẹ́ bí Ọmọ pípé ti Ọlọ́run, Jésù ni “irú-ọmọ” obìnrin náà, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ tẹ́lẹ̀ nínú Jẹ́nẹ́sísì orí kẹta, ẹsẹ kẹẹ̀ẹ́dógún. Òun ni yóò gbé àwọn ìgbésẹ̀ láti ‘pa Sátánì ní orí,’ bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù alára ni a ó ‘pa ní gìgísẹ̀.’ Lọ́nà yìí, Jésù di ọ̀nà tí Jèhófà pèsè fún ìgbàlà aráyé, ìyẹn ọ̀nà tí àwọn tó ní ìgbàgbọ́ ti ń wá láti ìgbà ayé Ébẹ́lì.
5, 6. Kí ni ọ̀nà tó sàn jù tí àwọn Kristẹni ní láti gbà tọ Ọlọ́run lọ?
5 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ipa pàtàkì tí Jésù kó yìí, ó sọ pé: “Ẹni náà tí kò mọ ẹ̀ṣẹ̀ ni òun sọ di ẹ̀ṣẹ̀ fún wa, kí àwa lè di òdodo Ọlọ́run nípasẹ̀ rẹ̀.” (2 Kọ́ríńtì 5:21) Gbólóhùn náà “sọ di ẹ̀ṣẹ̀” ni a tún lè túmọ̀ sí “sọ di ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.” Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Òun . . . ni ẹbọ ìpẹ̀tù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, síbẹ̀ kì í ṣe fún tiwa nìkan ṣùgbọ́n fún ti gbogbo ayé pẹ̀lú.” (1 Jòhánù 2:2) Fún ìdí yìí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé fúngbà díẹ̀ ni àwọn ẹbọ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń rú fi ṣí ọ̀nà láti tọ Ọlọ́run lọ sílẹ̀ fún wọn, àwọn Kristẹni ní tiwọn ní ọ̀nà tó sàn ju ìyẹn lọ láti fi tọ Ọlọ́run lọ—ìyẹn ni ẹbọ Jésù Kristi. (Jòhánù 14:6; 1 Pétérù 3:18) Bí a bá lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà tí Ọlọ́run pèsè, tí a sì ṣègbọràn sí I, àwa náà lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wa gbà, kí a sì rí ojú rere àti ìbùkún Ọlọ́run. (Jòhánù 3:17, 18) Orísun ìtùnú ha kọ́ nìyẹn bí? Àmọ́ o, báwo la ṣe lè fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà náà?
6 Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé àwọn Kristẹni ní ọ̀nà tó sàn jù láti tọ Ọlọ́run lọ, ó wá to ọ̀nà mẹ́ta tí a lè gbà fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́ àti ìmọrírì fún ìpèsè onífẹ̀ẹ́ tí Ọlọ́run ṣe lẹ́sẹẹsẹ, gẹ́gẹ́ bó ti wà nínú ìwé Hébérù orí kẹwàá, ẹsẹ kejìlélógún sí ìkẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó ní “ọ̀nà ìwọlé sínú ibi mímọ́,” ìyẹn, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó ní ìpè ti ọ̀run, ni Pọ́ọ̀lù darí ọ̀rọ̀ ìyànjú náà sí ní tààràtà, síbẹ̀síbẹ̀ ó dájú pé gbogbo ọmọ aráyé ló yẹ kí wọ́n fiyè sí ọ̀rọ̀ ìmísí tí Pọ́ọ̀lù sọ, bí wọ́n bá fẹ́ jàǹfààní látinú ẹbọ ìpẹ̀tù Jésù.—Hébérù 10:19.
Máa Rú Àwọn Ẹbọ Mímọ́ Tí Kò Lẹ́gbin
7. (a) Báwo ni Hébérù orí kẹwàá, ẹsẹ kejìlélógún ṣe fi ohun tí wọ́n ń ṣe nígbà ìrúbọ hàn? (b) Kí ni wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n lè ní ìdánilójú pé Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba ẹbọ náà?
7 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni pé: “Ẹ jẹ́ kí a wá pẹ̀lú ọkàn-àyà tòótọ́ nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdánilójú ti ìgbàgbọ́, níwọ̀n bí a ti wẹ ọkàn-àyà wa mọ́ kúrò nínú ẹ̀rí-ọkàn burúkú, tí a sì ti fi omi tí ó mọ́ wẹ ara wa.” (Hébérù 10:22) Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, èdè tí a lò níhìn-ín tọ́ka sí ohun tí wọ́n ń ṣe nígbà tí wọ́n ń rú ẹbọ gidi lábẹ́ Òfin. Èyí bá a mu wẹ́kú, nítorí pé kí ẹbọ tó lè ṣe ìtẹ́wọ́gbà, wọ́n gbọ́dọ̀ fi ẹ̀mí tó tọ́ rú u, ohun ẹbọ sì gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́, aláìlẹ́gbin. Inú agbo tàbí ọ̀wọ́ ẹran ni wọ́n ti mú ẹran ẹbọ náà, ìyẹn ni pé ó jẹ́ ara àwọn ẹran tó mọ́, ó sì jẹ́ “èyí tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá,” tí kò lábùkù. Bó bá jẹ́ àwọn ẹ̀dá abìyẹ́ ni wọ́n fẹ́ fi rúbọ, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ yálà oriri tàbí ọmọ ẹyẹlé. Bí àwọn ohun ẹbọ náà bá sì dé ojú ìlà ohun tí a béèrè, a ó “fi ojú rere tẹ́wọ́ gbà á, kí ó le ṣe ètùtù fún un.” (Léfítíkù 1:2-4, 10, 14; 22:19-25) Ọrẹ ẹbọ ọkà kì í ní ìwúkàrà kankan nínú, nítorí pé ìwúkàrà jẹ́ àmì ìdíbàjẹ́; kì í sì í ní oyin nínú, bóyá èyí tọ́ka sí omi èso tó dùn bí oyin, tó sì lè mú nǹkan wú. Nígbà tí wọ́n bá ń rú ẹbọ—ì báà jẹ́ ẹbọ ti ẹran tàbí ti ọkà—lórí pẹpẹ, wọ́n máa ń fi iyọ̀ sí i, nítorí kì í jẹ́ kí nǹkan tètè bà jẹ́.—Léfítíkù 2:11-13.
8. (a) Kí ni ẹni tó mú ọrẹ ẹbọ wá gbọ́dọ̀ ṣe? (b) Báwo la ṣe lè rí i dájú pé Jèhófà tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa?
8 Ẹni tó mú ọrẹ ẹbọ wá ńkọ́? Òfin sọ pé ẹnikẹ́ni tó bá ń bọ̀ níwájú Jèhófà gbọ́dọ̀ wà ní mímọ́, láìlẹ́gbin. Ẹnì kan tó ti di ẹlẹ́gbin fún ìdí èyíkéyìí, gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ti ẹ̀bi wá, kí ó lè ní ìdúró mímọ́ níwájú Jèhófà kí Ó bàa lè tẹ́wọ́ gbà ọrẹ ẹbọ sísun tàbí ẹbọ ìdàpọ̀ rẹ̀. (Léfítíkù 5:1-6, 15, 17) Nítorí náà, ǹjẹ́ a mọrírì ìjẹ́pàtàkì níní ìdúró mímọ́ níwájú Jèhófà nígbà gbogbo? Bí a bá fẹ́ kí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa, a gbọ́dọ̀ yára láti ṣàtúnṣe nígbàkigbà táa bá rú òfin Ọlọ́run. A gbọ́dọ̀ máa tètè lo ìrànlọ́wọ́ tí Ọlọ́run ti pèsè fún wa—ìyẹn “àwọn àgbà ọkùnrin ìjọ” àti “ẹbọ ìpẹ̀tù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa,” èyíinì ni Jésù Kristi.—Jákọ́bù 5:14; 1 Jòhánù 2:1, 2.
9. Kí ni ìyàtọ̀ pàtàkì tó wà láàárín àwọn ẹbọ tí wọ́n ń rú sí Jèhófà àtàwọn èyí táwọn èèyàn ń rú sáwọn èké ọlọ́run?
9 Ní tòótọ́, bí a ṣe tẹnu mọ́ ọn pé kò gbọ́dọ̀ ní ẹ̀gbin kankan ni olórí ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn ẹbọ tí wọ́n ń rú sí Jèhófà àtàwọn èyí táwọn èèyàn ń rú sí àwọn èké ọlọ́run ní àwọn orílẹ̀-èdè tó yí Ísírẹ́lì ká. Nígbà tí ìwé kan táa ṣèwádìí nínú rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ lórí ohun pàtàkì yìí tó mú kí àwọn ẹbọ tó wà nínú Òfin Mósè dá yàtọ̀, ó ṣàlàyé pé: “A lè ṣàkíyèsí pé àwọn ẹbọ náà kò ní nǹkan kan í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ wíwò tàbí àfọ̀ṣẹ; kò sí ṣíṣe bí ayírí nínú ìjọsìn, tàbí ṣíṣe ara ẹni léṣe, tàbí iṣẹ́ aṣẹ́wó mímọ́, kò gbọ́dọ̀ sí ohun tó jọ ààtò ìbímọlémọ onígbòónára tó kún fún àṣerégèé; kò sí fífi ènìyàn rúbọ; kò sí rírúbọ sáwọn òkú.” Gbogbo èyí pe àfiyèsí sí òkodoro òtítọ́ kan, pé: Jèhófà jẹ́ mímọ́, kò sì fàyè gba ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ìwà ìbàjẹ́ èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni kò tẹ́wọ́ gbà wọ́n. (Hábákúkù 1:13) Ìjọsìn àtàwọn ẹbọ tí a bá ń rú sí i gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́ àti aláìlẹ́gbin—ní ti ara, ní ti ìwà rere, àti nípa tẹ̀mí.—Léfítíkù 19:2; 1 Pétérù 1:14-16.
10. Lójú ọ̀rọ̀ ìyànjú Pọ́ọ̀lù tí a kọ sínú ìwé Róòmù orí kejìlá, ẹsẹ kìíní àti ìkejì, àyẹ̀wò ara ẹni wo ló yẹ ká ṣe?
10 Lójú ohun tí à ń sọ bọ̀ yìí, ó yẹ ká yẹ ara wa wò fínnífínní ní gbogbo apá ìgbésí ayé wa láti rí i dájú pé iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà ṣe ìtẹ́wọ́gbà sí i. A kò gbọ́dọ̀ ronú láé pé níwọ̀n ìgbà táa bá sáà ti ń lọ́wọ́ sí àwọn ìpàdé Kristẹni àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, a lè máa dán ohun tó bá wù wá wò lábẹ́lẹ̀. Bákan náà, a ò gbọ́dọ̀ rò pé lílọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò Kristẹni fún wa láṣẹ lọ́nà kan ṣá láti tẹ àwọn òfin Ọlọ́run lójú ní àwọn apá míì nínú ìgbésí ayé wa. (Róòmù 2:21, 22) A ò lè retí àtirí ìbùkún àti ojú rere Ọlọ́run bí a bá jẹ́ kí ohunkóhun tó jẹ́ aláìmọ́ tàbí ẹlẹ́gbin lójú rẹ̀ kó èérí bá ìrònú tàbí ìwà wa. A ò gbọ́dọ̀ gbàgbé ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù pé: “Mo fi ìyọ́nú Ọlọ́run pàrọwà fún yín, ẹ̀yin ará, pé kí ẹ fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ pẹ̀lú agbára ìmọnúúrò yín. Ẹ sì jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí, ṣùgbọ́n ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín padà, kí ẹ lè ṣàwárí fúnra yín ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.”—Róòmù 12:1, 2.
Máa Fi Tọkàntọkàn Rú Ẹbọ Ìyìn
11. Kí ni gbólóhùn náà, ‘ìpolongo ní gbangba,’ tó wà nínú Hébérù orí kẹwàá, ẹsẹ kẹtàlélógún wé mọ́?
11 Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Hébérù, ó wá pe àfiyèsí wàyí sí apá pàtàkì kan nínú ìjọsìn tòótọ́, ó ní: “Ẹ jẹ́ kí a di ìpolongo ìrètí wa ní gbangba mú ṣinṣin láìmikàn, nítorí olùṣòtítọ́ ni ẹni tí ó ṣèlérí.” (Hébérù 10:23) Ohun tí gbólóhùn náà, ‘ìpolongo ní gbangba,’ túmọ̀ sí láìlábùlà ni “ìjẹ́wọ́,” Pọ́ọ̀lù sì tún sọ̀rọ̀ nípa “ẹbọ ìyìn.” (Hébérù 13:15) Èyí rán wa létí irú ẹbọ tí àwọn èèyàn bí Ébẹ́lì, Nóà, àti Ábúráhámù rú.
12, 13. Kí ni ọmọ Ísírẹ́lì kan mọ̀ ní àmọ̀jẹ́wọ́ nígbà tó bá mú ọrẹ ẹbọ sísun wá, kí sì ni a lè ṣe láti fi hàn pé àwa náà ní irú ẹ̀mí yẹn?
12 Nígbà tí ọmọ Ísírẹ́lì kan bá mú ẹbọ sísun wá, ńṣe ló mú un wá “síwájú Jèhófà láti inú ìfẹ́ àtinúwá rẹ̀.” (Léfítíkù 1:3) Nípasẹ̀ irú ẹbọ bẹ́ẹ̀, ńṣe ló fínnúfíndọ̀ ṣe ìpolongo ní gbangba, tàbí ìjẹ́wọ́, ọ̀pọ̀ yanturu ìbùkún àti inú rere onífẹ̀ẹ́ Jèhófà sí àwọn ènìyàn rẹ̀. Kí a má gbàgbé pé ohun tó mú kí ẹbọ sísun dá yàtọ̀ ni pé gbogbo ọrẹ ẹbọ náà ni a ó sun lórí pẹpẹ—èyí sì jẹ́ àpẹẹrẹ ìfọkànsìn àti ìyàsímímọ́ láìkù síbì kan. Lọ́nà kan náà, a ń fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà náà àti pé a mọyì ìpèsè yẹn, táa bá ń fi tinútinú àti tọkàntọkàn rú “ẹbọ ìyìn, . . . èyíinì ni, èso ètè,” sí Jèhófà.
13 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni kì í rú ẹbọ gidi—ì báà ṣe ẹbọ tí a fi ẹran rú tàbí ti ewébẹ̀—síbẹ̀ wọ́n ní ẹrù iṣẹ́ láti jẹ́rìí nípa ìhìn rere Ìjọba náà àti láti sọ àwọn èèyàn di ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Ǹjẹ́ o máa ń lo àwọn àǹfààní tóo bá ní láti nípìn-ín nínú kíkéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní gbangba, kí àwọn èèyàn púpọ̀ sí i lè wá mọ àwọn nǹkan àgbàyanu tí Ọlọ́run ní nípamọ́ fún aráyé onígbọràn? Ǹjẹ́ o máa ń fi tinútinú lo àkókò àti okun rẹ láti kọ́ àwọn olùfìfẹ́hàn, kí o sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti di ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi? Ipa tí a ń fi ìtara kó nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, tó rí bí òórùn amáratuni tó ń jáde látinú ọrẹ ẹbọ sísun, máa ń mú inú Ọlọ́run dùn gan-an ni.—1 Kọ́ríńtì 15:58.
Máa Yọ̀ Nínú Àjọṣepọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run àti Èèyàn
14. Báwo ni ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù nínú Hébérù orí kẹwàá, ẹsẹ kẹrìnlélógún àti ìkẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ṣe bá ọ̀ràn nípa ẹbọ ìdàpọ̀ mu?
14 Níkẹyìn, Pọ́ọ̀lù pe àfiyèsí sí àjọṣe àárín àwa àti àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa báa ti ń sin Ọlọ́run. “Ẹ sì jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, bí àwọn kan ti ní àṣà náà, ṣùgbọ́n kí a máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì, pàápàá jù lọ bí ẹ ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.” (Hébérù 10:24, 25) Àwọn gbólóhùn náà, “láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà,” “ìpéjọpọ̀ ara wa,” àti “kí a máa fún ara ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì,” ń rán wa létí iṣẹ́ tí ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ ní Ísírẹ́lì ṣe fún àwọn èèyàn Ọlọ́run.
15. Kí ni a rí i pé ó jọra láàárín ẹbọ ìdàpọ̀ àti àwọn ìpàdé Kristẹni?
15 Nígbà míì, a máa ń túmọ̀ èdè náà, “ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀,” sí “ọrẹ ẹbọ àlàáfíà.” Ọ̀rọ̀ tí èdè Hébérù lò fún “àlàáfíà” níhìn-ín jẹ́ ọ̀rọ̀ tó wé mọ́ ẹni púpọ̀, àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ pé ńṣe ló ń fi hàn pé lílọ́wọ́ nínú irú ẹbọ bẹ́ẹ̀ ń yọrí sí àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run àti àlàáfíà pẹ̀lú àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ ẹni. Nípa ẹbọ ìdàpọ̀, ẹ gbọ́ ohun tí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ, ó ní: “Ní tòdodo, èyí jẹ́ àsìkò àjọṣepọ̀ aláyọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run Onímájẹ̀mú, àní ó jẹ́ àsìkò tí Ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ láti di Àlejò Ísírẹ́lì láti bá wọn jẹ nínú ẹbọ náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Òun ni Ẹni tó sábà máa ń gbà wọ́n lálejò.” Èyí rán wa létí ìlérí Jésù pé: “Níbi tí ẹni méjì tàbí mẹ́ta bá kóra jọpọ̀ sí ní orúkọ mi, èmi wà níbẹ̀ láàárín wọn.” (Mátíù 18:20) Kò sígbà táa lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni tí a kì í jàǹfààní látinú ìfararora tí ń gbéni ró, àti ìtọ́ni tí ń fúnni níṣìírí, ó sì máa ń ṣe wá láǹfààní gan-an báa ti ń rántí pé Jésù Kristi Olúwa wa ń bẹ pẹ̀lú wa. Èyí máa ń mú kí ìpàdé Kristẹni jẹ́ ibi tí ń fúnni láyọ̀, tó sì ń fún ìgbàgbọ́ lókun ní tòótọ́.
16. Pẹ̀lú ohun táa ti sọ nípa ẹbọ ìdàpọ̀, kí ló ń mú kí àwọn ìpàdé Kristẹni fún wa láyọ̀ ní pàtàkì?
16 Nínú ẹbọ ìdàpọ̀, gbogbo ọ̀rá náà—èyí tó bo ìfun, kíndìnrín méjèèjì, àmọ́ ara ẹ̀dọ̀, àti èyí tó wà níbi abẹ́nú, títí kan ìrù ọlọ́ràá àgùntàn náà pàápàá—ni wọ́n ń fi rúbọ sí Jèhófà nípa sísun ún, tí wọ́n á sì mú un rú èéfín lórí pẹpẹ. (Léfítíkù 3:3-16) Ọ̀rá ni wọ́n kà sí apá tó dọ́ṣọ̀ jù lọ, tó sì dára jù lọ lára ẹran. Fífi í rúbọ lórí pẹpẹ túmọ̀ sí fífún Jèhófà ní apá tó dára jù lọ. Ohun tó ń mú kí àwọn ìpàdé Kristẹni fún wa láyọ̀ ní pàtàkì ni pé, kì í ṣe kìkì pé à ń rí ìtọ́ni gbà níbẹ̀ ni, ṣùgbọ́n a tún ń fi ìyìn fún Jèhófà níbẹ̀. A ń ṣe èyí nípa fífi gbogbo agbára wa kópa—àmọ́ nínú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀—nínú kíkọrin látọkànwá, títẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́, àti dídáhùn nígbà tí àyè rẹ̀ bá yọ. Onísáàmù náà pòkìkí pé: “Ẹ yin Jáà! Ẹ kọ orin tuntun sí Jèhófà, àti ìyìn rẹ̀ nínú ìjọ àwọn ẹni ìdúróṣinṣin.”—Sáàmù 149:1.
Ìbùkún Yabuga-Yabuga Látọ̀dọ̀ Jèhófà Ń Dúró Dè Wá
17, 18. (a) Ẹbọ títóbi lọ́lá wo ni Sólómọ́nì rú nígbà ayẹyẹ ṣíṣí tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù? (b) Àwọn ìbùkún wo làwọn èèyàn náà rí gbà nígbà ayẹyẹ ṣíṣí tẹ́ńpìlì?
17 Nígbà ayẹyẹ ṣíṣí tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù, ní oṣù keje ọdún 1026 ṣááju Sànmánì Tiwa, Sólómọ́nì Ọba rú “ẹbọ títóbi lọ́lá níwájú Jèhófà,” àwọn ẹbọ tó rú ni “ẹbọ sísun àti ọrẹ ẹbọ ọkà àti àwọn apá ọlọ́ràá ti àwọn ẹbọ ìdàpọ̀.” Ní àfikún sí ohun tí wọ́n fi rúbọ nínú àwọn ọrẹ ẹbọ ọkà, àròpọ̀ ẹgbàá mọ́kànlá [22,000] màlúù àti ọ̀kẹ́ mẹ́fà [120,000] àgùntàn ni wọ́n fi rúbọ nígbà ayẹyẹ yẹn.—1 Àwọn Ọba 8:62-65.
18 Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo irú ìnáwónára tí ayẹyẹ tó hẹ̀rẹ̀ǹtẹ̀ yẹn mú lọ́wọ́? Síbẹ̀, ó dájú pé àwọn ìbùkún tí Ísírẹ́lì rí gbà pọ̀ ju ìnáwónára náà. Nígbà tí ayẹyẹ dídùn yùngbà náà parí, Sólómọ́nì “rán àwọn ènìyàn náà lọ; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí súre fún ọba, wọ́n sì lọ sí ilé wọn, wọ́n ń yọ̀, wọ́n sì ń ṣàríyá nínú ọkàn-àyà wọn lórí gbogbo oore tí Jèhófà ṣe fún Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀ àti fún Ísírẹ́lì àwọn ènìyàn rẹ̀.” (1 Àwọn Ọba 8:66) Ní tòótọ́, gẹ́gẹ́ bí Sólómọ́nì ti sọ ọ́ gan-an ló rí, “ìbùkún Jèhófà—èyíinì ni ohun tí ń sọni di ọlọ́rọ̀, kì í sì í fi ìrora kún un.”—Òwe 10:22.
19. Kí la lè ṣe láti rí àwọn ìbùkún yabuga-yabuga gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà nísinsìnyí àti títí láé?
19 À ń gbé báyìí ní sáà tí “kókó inú àwọn ohun náà gan-an” ti rọ́pò “òjìji àwọn ohun rere tí ń bọ̀.” (Hébérù 10:1) Gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà ńlá amápẹẹrẹṣẹ náà, Jésù Kristi ti wọ ọ̀run gan-an lọ, ó sì ti gbé ìtóye ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ kalẹ̀ láti fi ṣètùtù fún gbogbo àwọn tó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ rẹ̀. (Hébérù 9:10, 11, 24-26) Lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ ńlá yẹn àti nípa fífi tọkàntọkàn rú ẹbọ ìyìn wa tó jẹ́ mímọ́ àti aláìlẹ́gbin sí Ọlọ́run, àwa náà lè máa tẹ̀ síwájú nìṣó, ká máa ‘yọ̀, ká sì máa ṣàríyá nínú ọkàn-àyà,’ báa ti ń retí àwọn ìbùkún yabuga-yabuga lọ́jọ́ iwájú látọ̀dọ̀ Jèhófà.— Málákì 3:10.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
• Ìtọ́ni àti ìtùnú wo la lè rí jèrè látinú ìsọfúnni tó wà nínú Òfin nípa àwọn ẹbọ àti ọrẹ ẹbọ?
• Kí ni a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣe kí ẹbọ kan tó lè ní ìtẹ́wọ́gbà, kí sì ni èyí túmọ̀ sí fún wa?
• Ẹbọ wo ni àwa lè rú tó ṣeé fi wé ọrẹ ẹbọ sísun àfínnúfíndọ̀ṣe?
• Ní àwọn ọ̀nà wo ni àwọn ìpàdé Kristẹni fi bá ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ mu?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Jèhófà pèsè ẹbọ ìràpadà Jésù fún ìgbàlà aráyé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Kí iṣẹ́ ìsìn wa lè ṣe ìtẹ́wọ́gbà sí Jèhófà, kò gbọ́dọ̀ sí ẹ̀gbin kankan lára wa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
A ń fi hàn ní gbangba pé a mọyì oore Jèhófà nígbà táa bá lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà