Àwọn Ẹbọ Tí Inú Ọlọ́run Dùn Sí
Àwọn Ẹbọ Tí Inú Ọlọ́run Dùn Sí
“Olúkúlùkù àlùfáà àgbà ni a yàn sípò láti fi àwọn ẹ̀bùn àti ohun ẹbọ rúbọ.”—HÉBÉRÙ 8:3.
1. Èé ṣe táwọn èèyàn fi máa ń fẹ́ yíjú sí Ọlọ́run?
“Ó JỌ pé ìfẹ́ láti rúbọ jẹ́ ‘àdámọ́ni’ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ láti gbàdúrà ti jẹ́; ẹbọ rírú ń fi ohun téèyàn ń rò nípa ara rẹ̀ hàn, nígbà tó jẹ́ pé àdúrà gbígbà ń fi ohun téèyàn ń rò nípa Ọlọ́run hàn,” òpìtàn Bíbélì nì, Alfred Edersheim, ló kọ ọ̀rọ̀ òkè yìí. Látìgbà tí ẹ̀ṣẹ̀ ti wọ ayé ló ti ń fa ẹ̀dùn ọkàn nítorí ẹ̀bi, tí ó sì ti yà wá nípa sí Ọlọ́run, tí a sì wà láìlólùgbèjà. A fẹ́ bọ́ lọ́wọ́ nǹkan wọ̀nyí. Abájọ tó fi jẹ́ pé nígbà táwọn èèyàn bá bá ara wọn nínú irú ipò àìnírètí bẹ́ẹ̀, kíá ni wọ́n máa ń yíjú sí Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́.—Róòmù 5:12.
2. Àkọsílẹ̀ wo la rí nínú Bíbélì nípa àwọn ẹbọ táwọn èèyàn rú sí Ọlọ́run ní ìjímìjí?
2 Ibi tí Bíbélì ti kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa fífi àwọn nǹkan rúbọ sí Ọlọ́run ni ibi tó ti sọ̀rọ̀ nípa ìtàn Kéènì àti Ébẹ́lì. Ó kà pé: “Ó ṣẹlẹ̀ pé, ní òpin àwọn àkókò kan, Kéènì tẹ̀ síwájú láti mú àwọn èso kan tí ilẹ̀ mú jáde, wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ fún Jèhófà. Ṣùgbọ́n ní ti Ébẹ́lì, òun pẹ̀lú mú àwọn àkọ́bí nínú agbo ẹran rẹ̀ wá, àní àwọn apá tí ó lọ́ràá nínú wọn.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:3, 4) Lẹ́yìn ìgbà náà, a kà á pé dídá tí Ọlọ́run dá ẹ̀mí Nóà sí nígbà Ìkún Omi tó pa ìran búburú ọjọ́ rẹ̀ run, mú kí ó “rú ọrẹ ẹbọ sísun lórí pẹpẹ” sí Jèhófà. (Jẹ́nẹ́sísì 8:20) Nígbà àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan, àwọn ìlérí àti ìbùkún Ọlọ́run, sún Ábúráhámù tí í ṣe ìránṣẹ́ olóòótọ́ àti ọ̀rẹ́ Ọlọ́run láti ‘mọ pẹpẹ kan, ó sì pe orúkọ Jèhófà.’ (Jẹ́nẹ́sísì 12:8; 13:3, 4, 18) Lẹ́yìn náà, Ábúráhámù yege nínú ìdánwò ìgbàgbọ́ tó le jù lọ, nígbà tí Jèhófà sọ fún un pé kó fi Ísákì ọmọ rẹ̀ rú ẹbọ sísun. (Jẹ́nẹ́sísì 22:1-14) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àkọsílẹ̀ wọ̀nyí ṣe ṣókí, síbẹ̀ wọ́n là wá lóye lórí ọ̀ràn ẹbọ, gẹ́gẹ́ bí a ó ti rí i.
3. Ipa wo ni ẹbọ ń kó nínú ìjọsìn?
3 Látinú ohun táa rí nínú ìròyìn wọ̀nyí àtàwọn ìròyìn míì nínú Bíbélì, ó ṣe kedere pé rírú àwọn ẹbọ kan ti jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn, tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí Jèhófà tó gbé àwọn òfin pàtó kalẹ̀ nípa ẹbọ rírú. Ní ìbámu pẹ̀lú ìyẹn, ìwé kan táa ṣèwádìí nínú rẹ̀ pe “ẹbọ” ní “ààtò ẹ̀sìn, nínú èyí tí wọ́n ti máa ń fi nǹkan kan rúbọ sí ọlọ́run kan, kí èèyàn lè ní àjọṣe tó gún régé pẹ̀lú ohun tó kà sí ọlọ́wọ̀, tàbí kí ó mú irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ bọ̀ sípò.” Àmọ́ èyí gbé àwọn ìbéèrè pàtàkì kan dìde tó yẹ ká fara balẹ̀ gbé yẹ̀ wò, àwọn bíi: Èé ṣe táa fi nílò ẹbọ nínú ìjọsìn? Irú àwọn ẹbọ wo ni Ọlọ́run ń tẹ́wọ́ gbà? Àti pé ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ lónìí látinú àwọn ẹbọ ayé àtijọ́?
Èé Ṣe Táa Fi Nílò Ẹbọ?
4. Kí ni àbájáde rẹ̀ nígbà tí Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀?
4 Ẹ̀ṣẹ̀ tí Ádámù ṣẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́mọ̀dá ni. Mímú tó mú, tó sì jẹ lára èso igi ìmọ̀ rere àti búburú, jẹ́ ìwà àìgbọràn tó mọ̀ọ́mọ̀ hù. Ikú ni ìyà ìwà àìgbọràn náà, gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti sọ ní kedere tẹ́lẹ̀ pé: “Ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀, dájúdájú, ìwọ yóò kú.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:17) Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, Ádámù àti Éfà jẹ èrè ẹ̀ṣẹ̀—wọ́n ṣègbé.—Jẹ́nẹ́sísì 3:19; 5:3-5.
5. Èé ṣe tí Jèhófà fi gbé ìgbésẹ̀ nítorí àwọn ọmọ Ádámù, kí sì ni Ó ṣe fún wọn?
5 Àmọ́, àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù wá ńkọ́? Níwọ̀n bí wọ́n ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé látọ̀dọ̀ Ádámù, àwọn náà ò bọ́ lọ́wọ́ ìyara ẹni nípa sí Ọlọ́run, àìnírètí, àti ikú tó dé bá tọkọtaya àkọ́kọ́. (Róòmù 5:14) Ṣùgbọ́n, kì í ṣe pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo àti alágbára nìkan ni, àmọ́, ní pàtàkì jù lọ, ó tún jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́. (1 Jòhánù 4:8, 16) Nítorí náà, ó gbé ìgbésẹ̀ láti tún ọ̀ràn náà ṣe. Lẹ́yìn tí Bíbélì sọ pé “owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú,” ló wá sọ síwájú sí i pé, “ṣùgbọ́n ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.”—Róòmù 6:23.
6. Kí ni ìfẹ́ Jèhófà nípa ìbàjẹ́ tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù ṣe?
6 Ohun tí Ọlọ́run ṣe ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ kí ẹ̀bùn yẹn lè tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ ni pé ó pèsè nǹkan kan tí yóò kájú ohun tí ìrélànàkọjá Ádámù jẹ́ kí wọ́n pàdánù rẹ̀. Lédè Hébérù, ohun tó jọ pé ọ̀rọ̀ náà ka·pharʹ kọ́kọ́ túmọ̀ sí ni láti “kájú,” tàbí láti “pa rẹ́,” a tún máa ń túmọ̀ rẹ̀ sí “ètùtù.” a Lédè mìíràn, Jèhófà pèsè ohun tó bá a mu wẹ́kú láti fi kájú ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá látọ̀dọ̀ Ádámù, ó sì pa ìbàjẹ́ tí ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀hún ṣe rẹ́, kí àwọn tó bá tóótun fún ẹ̀bùn yẹn lè bọ́ lọ́wọ́ ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.—Róòmù 8:21.
7. (a) Ìrètí wo ni a pèsè nípasẹ̀ ìdájọ́ tí Ọlọ́run ṣe fún Sátánì? (b) Kí ni a gbọ́dọ̀ san fún ìdáǹdè aráyé kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú?
7 Kété lẹ́yìn tí tọkọtaya àkọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀ ni a sọ̀rọ̀ nípa ìrètí bíbọ́ lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Nígbà tí Jèhófà ń ṣèdájọ́ Sátánì, tí ejò náà dúró fún, Jèhófà sọ pé: “Èmi yóò sì fi ìṣọ̀tá sáàárín ìwọ àti obìnrin náà àti sáàárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ rẹ̀. Òun yóò pa ọ́ ní orí, ìwọ yóò sì pa á ní gìgísẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Nípasẹ̀ gbólóhùn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn, ìrètí dé wàyí fún gbogbo àwọn tó bá gba ìlérí yẹn gbọ́. Àmọ́ o, a gbọ́dọ̀ san nǹkan kan fún ìdáǹdè yẹn. Kì í kàn í ṣe pé Irú-Ọmọ tí a ṣèlérí náà yóò wulẹ̀ wá pa Sátánì run bẹ́ẹ̀ lásán; Irú Ọmọ náà ni a gbọ́dọ̀ pa ní gìgísẹ̀, ìyẹn ni pé, ó gbọ́dọ̀ kú, ṣùgbọ́n kò ní kú gbé.
8. (a) Báwo ni ọ̀ràn Kéènì ṣe já sí ìjákulẹ̀? (b) Èé ṣe tí ẹbọ Ébẹ́lì fi já sí ìtẹ́wọ́gbà lójú Ọlọ́run?
8 Láìsí àní-àní, Ádámù àti Éfà ronú púpọ̀púpọ̀ nípa ẹni tí Irú Ọmọ tí a ṣèlérí náà yóò jẹ́. Nígbà tí Éfà bí Kéènì, àkọ́bí rẹ̀ ọkùnrin, ó kéde pé: “Mo ti mú ọkùnrin kan jáde nípasẹ̀ àrànṣe Jèhófà.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:1) Ṣé kì í ṣe pé ó ń ronú pé ọmọ òun yìí ni yóò di Irú Ọmọ náà? Yálà ó ronú bẹ́ẹ̀ tàbí kò ronú bẹ́ẹ̀, ìjákulẹ̀ gbáà lọ̀ràn Kéènì àti ọrẹ ẹbọ rẹ̀ já sí. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, Ébẹ́lì àbúrò rẹ̀ gba ìlérí Ọlọ́run gbọ́, èyí sì sún un láti fi àwọn àkọ́bí nínú agbo ẹran rẹ̀ rúbọ sí Jèhófà. A kà á pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni Ébẹ́lì rú ẹbọ tí ó níye lórí ju ti Kéènì sí Ọlọ́run, nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ náà tí ó fi ní ẹ̀rí tí a jẹ́ sí i pé ó jẹ́ olódodo.”—Hébérù 11:4.
9. (a) Ébẹ́lì lo ìgbàgbọ́ nínú kí ni, báwo ló sì ṣe fi ìgbàgbọ́ yẹn hàn? (b) Iṣẹ́ wo ni ọrẹ ẹbọ Ébẹ́lì ṣe?
9 Ìgbàgbọ́ tí Ébẹ́lì ní nínú Ọlọ́run kì í kàn-án ṣe ìgbàgbọ́ oréfèé, irú èyí tí Kéènì pàápàá ti lè ní. Ébẹ́lì ní ìgbàgbọ́ nínú ìlérí Ọlọ́run nípa Irú Ọmọ náà tí yóò mú ìgbàlà wá fún àwọn olóòótọ́ ẹ̀dá ènìyàn. A kò ṣí bí èyíinì yóò ṣe wáyé payá fún un, ṣùgbọ́n ìlérí Ọlọ́run jẹ́ kí Ébẹ́lì mọ̀ pé a ní láti pa ẹnì kan ní gìgísẹ̀. Dájúdájú, ó ti ní láti parí èrò sí pé a gbọ́dọ̀ ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀—ohun tí ẹbọ sì túmọ̀ sí gẹ́lẹ́ nìyẹn. Ébẹ́lì fi ẹ̀bùn kan tó ní ìwàláàyè àti ẹ̀jẹ̀ nínú rúbọ sí Orísun ìwàláàyè, bóyá láti fi hàn pé òun ń yán hànhàn, òun sì ń hára gàgà láti rí ìmúṣẹ ìlérí Jèhófà. Ìgbàgbọ́ tí Ébẹ́lì lò yìí ló mú kí ẹbọ rẹ̀ mú inú Jèhófà dùn, àti pé títí dé ìwọ̀n kan, ó ṣàpẹẹrẹ ohun tí ẹbọ jẹ́ gan-an—èyíinì ni, ọ̀nà tí ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ lè gbà tọ Ọlọ́run lọ, kí ó sì rí ojú rere rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 4:4; Hébérù 11:1, 6.
10. Báwo ni a ṣe mú kí ìtumọ̀ tí ẹbọ ní ṣe kedere nípa àṣẹ tí Jèhófà pa fún Ábúráhámù pé kí ó fi Ísákì rúbọ?
10 Ìtumọ̀ jíjinlẹ̀ tí ẹbọ ní hàn kedere-kèdèrè nígbà tí Jèhófà pàṣẹ fún Ábúráhámù pé kí ó fi Ísákì ọmọ rẹ̀ rú ẹbọ sísun. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìrúbọ yẹn ò wáyé ní ti gidi, síbẹ̀ ó ṣàpẹẹrẹ ohun tí Jèhófà alára yóò ṣe nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín—èyíinì ni, bí yóò ṣe fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo rú ẹbọ tó ju gbogbo ẹbọ lọ, kí ìfẹ́ Rẹ̀ fún ọmọ aráyé lè ní ìmúṣẹ. (Jòhánù 3:16) Àwọn ẹbọ àti ọrẹ ẹbọ tó wà nínú Òfin Mósè ni Jèhófà lò láti fi àwọn àpẹẹrẹ tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ lélẹ̀, láti kọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ àyànfẹ́ ní ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà, kí ìrètí ìgbàlà wọn sì lè dúró sán-ún. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú ìwọ̀nyí?
Àwọn Ẹbọ Tí Jèhófà Tẹ́wọ́ Gbà
11. Ọ̀nà méjì wo ni àwọn ọrẹ ẹbọ tí àlùfáà àgbà Ísírẹ́lì ń rú pín sí, kí sì ni ète wọn?
11 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Olúkúlùkù àlùfáà àgbà ni a yàn sípò láti fi àwọn ẹ̀bùn àti ohun ẹbọ rúbọ.” (Hébérù 8:3) Ṣàkíyèsí pé ọ̀nà méjì ni Pọ́ọ̀lù pín àwọn ẹbọ tí àlùfáà àgbà Ísírẹ́lì ìgbàanì ń rú sí, èyíinì ni, “àwọn ẹ̀bùn” àti “ohun ẹbọ,” tàbí “àwọn ohun ẹbọ . . . fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀.” (Hébérù 5:1) Àwọn èèyàn sábà máa ń fúnni lẹ́bùn láti fi ìfẹ́ àti ìmọrírì hàn, àti láti sọ àwọn èèyàn dọ̀rẹ́, tàbí láti fi wá ojú rere, tàbí láti lè rí ìtẹ́wọ́gbà. (Jẹ́nẹ́sísì 32:20; Òwe 18:16) Bákan náà, ọ̀pọ̀ ọrẹ ẹbọ tí Òfin là kalẹ̀ ni a lè kà sí “ẹ̀bùn” fún Ọlọ́run, láti fi rí ìtẹ́wọ́gbà àti ojú rere rẹ̀. b Ríré Òfin kọjá ń béèrè fún ìsanpadà, wọ́n sì máa ń rú “àwọn ohun ẹbọ . . . fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀,” láti fi ṣètùtù. Ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Bíbélì, àgàgà àwọn ìwé náà, Ẹ́kísódù, Léfítíkù, àti Númérì, ṣe àlàyé rẹpẹtẹ nípa onírúurú ẹbọ àti ọrẹ ẹbọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè máà rọrùn rárá láti kó gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa rẹ̀ ságbárí, ká sì máa rántí wọn, síbẹ̀síbẹ̀, á dára kí á pe àfiyèsí sí àwọn kókó pàtàkì kan nípa oríṣiríṣi ẹbọ tó wà.
12. Ibo nínú Bíbélì la ti lè rí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ẹbọ, tàbí ọrẹ ẹbọ, nínú Òfin?
12 A lè ṣàkíyèsí pé nínú Léfítíkù orí kìíní sí orí keje, oríṣi ọrẹ ẹbọ pàtàkì márùn-ún—èyíinì ni, ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ ọkà, ẹbọ ìdàpọ̀, ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi—ni a ṣàpèjúwe lọ́kọ̀ọ̀kan, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n máa ń rú àwọn kan nínú wọn pa pọ̀. A tún ṣàkíyèsí pé ẹ̀ẹ̀méjì ni wọ́n ṣàpèjúwe àwọn ọrẹ ẹbọ wọ̀nyí nínú orí wọ̀nyí, pẹ̀lú ète ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ́kàn: ìgbà àkọ́kọ́, nínú Léfítíkù orí kìíní ẹsẹ kejì sí orí kẹfà ẹsẹ keje, tó sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tí a ó fi rúbọ lórí pẹpẹ, àti ìgbà kejì, nínú Léfítíkù orí kẹfà ẹsẹ kẹjọ sí orí keje ẹsẹ kẹrìndínlógójì, tó ṣàlàyé àwọn apá táa yà sọ́tọ̀ fáwọn àlùfáà, àtàwọn apá tó jẹ́ tẹni tó mú ọrẹ ẹbọ wá. Nígbà tó wá di inú ìwé Númérì orí kejìdínlọ́gbọ̀n àti ìkọkàndínlọ́gbọ̀n, a wá rí ohun táa lè pè ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ kíkún rẹ́rẹ́, tó sọ ohun tí a óò máa fi rúbọ lójoojúmọ́, lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, lóṣooṣù, àti nígbà àwọn àjọyọ̀ ọdọọdún.
13. Ṣàlàyé àwọn ọrẹ ẹbọ tí wọ́n ń fínnúfíndọ̀ mú wá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn sí Ọlọ́run.
13 Lára àwọn ọrẹ ẹbọ tí wọ́n ń fínnúfíndọ̀ mú wá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn tàbí tí wọ́n ń rú kí ọ̀nà lè là láti tọ Ọlọ́run lọ láti lè jèrè ojú rere rẹ̀, ni ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ ọkà, àti ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀. Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò lédè Hébérù fún “ọrẹ ẹbọ sísun” túmọ̀ sí “ọrẹ ẹbọ ìgòkè” tàbí “ọrẹ ẹbọ tí ń lọ sókè.” Èyí sì ṣe rẹ́gí, nítorí pé nígbà tí wọ́n bá ń rú ọrẹ ẹbọ sísun, ńṣe ni wọ́n máa ń sun ẹran ẹbọ tí wọ́n ti pa lórí pẹpẹ, tí òórùn dídùn, tàbí òórùn amáratuni yóò sì máa lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run lókè ọ̀run. Ohun tí ọrẹ ẹbọ sísun fi yàtọ̀ sí gbogbo ẹbọ yòókù ni pé lẹ́yìn tí wọ́n bá ti wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yí pẹpẹ ká, odindi ẹran náà ni wọ́n máa ń fi rúbọ sí Ọlọ́run. Àwọn àlùfáà á mú “gbogbo rẹ̀ rú èéfín lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ àfinásun, ti òórùn amáratuni sí Jèhófà.”—Léfítíkù 1:3, 4, 9; Jẹ́nẹ́sísì 8:21.
14. Báwo ni wọ́n ṣe ń rú ọrẹ ẹbọ ọkà?
14 Orí kejì ìwé Léfítíkù la ti ṣàlàyé ọrẹ ẹbọ ọkà. Ó jẹ́ ọrẹ ẹbọ àfínnúfíndọ̀ṣe, àwọn ohun tí wọ́n sì fi ń rú u ni ìyẹ̀fun kíkúnná, tí wọ́n sábà máa ń fi òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́, wọ́n á sì fi oje igi tùràrí sí i. “Kí àlùfáà sì bu ẹ̀kúnwọ́ rẹ̀ láti inú ìyẹ̀fun rẹ̀ kíkúnná àti òróró rẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo oje igi tùràrí rẹ̀; kí ó sì mú un rú èéfín gẹ́gẹ́ bí ohun ìránnilétí rẹ̀ lórí pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ àfinásun, ti òórùn amáratuni sí Jèhófà.” (Léfítíkù 2:2) Oje igi tùràrí jẹ́ ọ̀kan lára èròjà tùràrí mímọ́ tí wọ́n máa ń sun lórí pẹpẹ tùràrí nínú àgọ́ ìjọsìn àti tẹ́ńpìlì. (Ẹ́kísódù 30:34-36) Ó dà bí ẹni pé èyí ni Dáfídì Ọba ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Kí a pèsè àdúrà mi sílẹ̀ bí tùràrí níwájú rẹ, àti gbígbé tí mo gbé àtẹ́lẹwọ́ mi sókè bí ọrẹ ẹbọ ọkà ìrọ̀lẹ́.”—Sáàmù 141:2.
15. Kí ni ète ẹbọ ìdàpọ̀?
15 Ọrẹ ẹbọ àfínnúfíndọ̀ṣe mìíràn ni ẹbọ ìdàpọ̀, èyí tí ìwé Léfítíkù orí kẹta ṣàlàyé rẹ̀. A tún lè túmọ̀ orúkọ yẹn sí “àwọn ọrẹ ẹbọ àlàáfíà.” Lédè Hébérù, ọ̀rọ̀ náà “àlàáfíà” kì í wulẹ̀ í ṣe ọ̀ràn àìsí ogun tàbí àìsí rúkèrúdò nìkan. Ìwé Studies in the Mosaic Institutions sọ pé: “Ó ní ìtumọ̀ yìí nínú Bíbélì, àmọ́ ó tún túmọ̀ sí ipò tàbí ìdúró àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run, aásìkí, ìdùnnú, àti ayọ̀.” Fún ìdí yìí, ìdí tí wọ́n fi ń rú ẹbọ ìdàpọ̀ kì í ṣe láti wá àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run, bíi pé nítorí kí wọ́n lè tù ú lójú, bí kò ṣe láti dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ tàbí láti ṣayẹyẹ ipò àlàáfíà amọ́kànyọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, èyí tí àwọn tí ó tẹ́wọ́ gbà ń gbádùn. Àwọn àlùfáà àti ẹni tó mú ohun ẹbọ wá máa ń jẹ lára ohun ẹbọ náà lẹ́yìn tí wọ́n bá ti fi ẹ̀jẹ̀ àti ọ̀rá rẹ̀ rúbọ sí Jèhófà tán. (Léfítíkù 3:17; 7:16-21; 19:5-8) Lọ́nà tó fani mọ́ra gan-an, tó sì jẹ́ ìṣàpẹẹrẹ, ṣe ni ẹni tó mú ọrẹ ẹbọ wá, àtàwọn àlùfáà, àti Jèhófà Ọlọ́run jọ ń jẹun pa pọ̀, tó jẹ́ àmì àjọṣe alálàáfíà tó wà láàárín wọn.
16. (a) Kí ni ète ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi? (b) Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín ọrẹ ẹbọ méjèèjì yìí àti ọrẹ ẹbọ sísun?
16 Ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi wà lára àwọn ẹbọ tí wọ́n ń rú láti fi rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà tàbí láti fi ṣètùtù fún ríré Òfin kọjá. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹbọ wọ̀nyí pẹ̀lú wé mọ́ sísun nǹkan lórí pẹpẹ, wọ́n yàtọ̀ sí ọrẹ ẹbọ sísun, ní ti pé kì í ṣe odindi ẹran náà ní wọ́n fi ń rúbọ sí Ọlọ́run, bí kò ṣe kìkì ọ̀rá àti àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ kan. Ńṣe ni wọ́n máa ń kó ìyókù ẹran náà dà sí òde ibùdó, tàbí nínú àwọn ọ̀ràn kan, àwọn àlùfáà ló máa ń jẹ ẹ́. Ó nídìí tí ìyàtọ̀ yìí fi wà. Ẹ̀bùn ni ọrẹ ẹbọ sísun tí wọ́n ń rú sí Ọlọ́run jẹ́, láti lè ní àǹfààní láti tọ̀ ọ́ lọ, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń fi odindi rẹ̀ láìkù síbì kan rúbọ sí Ọlọ́run. Ó tún yẹ fún àfiyèsí pé, wọ́n sábà máa ń rú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi kí wọ́n tó rú ọrẹ ẹbọ sísun, èyí tó fi hàn pé kí Ọlọ́run tó lè tẹ́wọ́ gba ẹ̀bùn ẹlẹ́ṣẹ̀ kan, ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ pọndandan.—Léfítíkù 8:14, 18; 9:2, 3; 16:3, 5.
17, 18. Kí ni ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wà fún, kí sì ni ète àwọn ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi?
17 Kìkì ẹ̀ṣẹ̀ tí a kò mọ̀ọ́mọ̀ dá sí Òfin nìkan ni a máa ń rú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún, èyíinì ni ẹ̀ṣẹ̀ tí a dá nítorí ìkùdíẹ̀-káàtó ti ẹran ara. “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkàn kan ṣèèṣì ṣẹ̀ nínú èyíkéyìí lára ohun tí Jèhófà pa láṣẹ pé kí a má ṣe,” nígbà náà kí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà mú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wá ní ìbámu pẹ̀lú ipò, tàbí ìdúró rẹ̀ láwùjọ. (Léfítíkù 4:2, 3, 22, 27) Àmọ́ o, ńṣe ni wọ́n máa ń ké àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà kúrò; kò sí ẹbọ kankan fún wọn.—Ẹ́kísódù 21:12-15; Léfítíkù 17:10; 20:2, 6, 10; Númérì 15:30; Hébérù 2:2.
18 A mú ìtumọ̀ àti ète ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi ṣe kedere nínú Léfítíkù orí karùn-ún àti orí kẹfà. Bóyá ẹnì kan dẹ́ṣẹ̀ láìmọ̀ọ́mọ̀. Síbẹ̀, ìrélànàkọjá rẹ̀ lè jẹ́ kó jẹ̀bi títẹ ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tàbí àwọn ẹ̀tọ́ Jèhófà Ọlọ́run lójú, ó sì gbọ́dọ̀ ṣètùtù fún ìwà àìtọ́ yẹn. Ìpele-ìpele sì ni oríṣiríṣi ẹ̀ṣẹ̀. Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kan jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó fara sin (5:2-6), àwọn kan jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ sí “àwọn ohun mímọ́ Jèhófà” (5:14-16), àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ míì, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í kúkú ṣe àìmọ̀ọ́mọ̀dá jálẹ̀jálẹ̀, wọ́n jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó wáyé nítorí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tàbí nítorí ìkùdíẹ̀-káàtó ti ẹran ara. (6:1-3). Ní àfikún sí jíjẹ́wọ́ irú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀, ẹlẹ́ṣẹ̀ náà ní láti san àsanfidípò níbi tó bá ti pọndandan, lẹ́yìn náà ni onítọ̀hún yóò tó mú ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi wá fún Jèhófà.—Léfítíkù 6:4-7.
Ohun Tó Sàn Jù Ṣì Wà Níwájú
19. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ísírẹ́lì ní Òfin àti àwọn ẹbọ rẹ̀, èé ṣe tí wọn kò fi rí ojú rere Ọlọ́run?
19 Òfin Mósè, pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ẹbọ àti ọrẹ ẹbọ rẹ̀, ni a fi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí ó lè ṣeé ṣe fún wọn láti tọ Ọlọ́run lọ, kí wọ́n lè rí ojú rere àti ìbùkún rẹ̀, kí wọ́n má sì pàdánù rẹ̀, títí Irú-Ọmọ tí a ṣèlérí náà yóò fi dé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tí òun fúnra rẹ̀ jẹ́ Júù àbínibí, sọ ọ́ lọ́nà yìí: “Òfin ti di akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa tí ń sinni lọ sọ́dọ̀ Kristi, kí a lè polongo wa ní olódodo nítorí ìgbàgbọ́.” (Gálátíà 3:24) Ó ṣeni láàánú pé Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan lódindi kò fetí sí ẹ̀kọ́ yẹn, ṣùgbọ́n wọ́n ṣi àǹfààní yẹn lò. Ìyẹn ló fà á tí gbogbo ẹbọ rẹpẹtẹ tí wọ́n sọ pé àwọn ń rú fi di ohun ìríra lójú Jèhófà, tó fi sọ pé: “Odindi ọrẹ ẹbọ sísun ti àgbò àti ọ̀rá àwọn ẹran tí a bọ́ dáadáa ti tó mi gẹ́ẹ́; èmi kò sì ní inú dídùn sí ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹgbọrọ akọ màlúù àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn àti òbúkọ.”—Aísáyà 1:11.
20. Kí ló ṣẹlẹ̀ lọ́dún 70 Sànmánì Tiwa sí Òfin àti àwọn ẹbọ rẹ̀?
20 Ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa, ètò nǹkan àwọn Júù, àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ àti ipò àlùfáà rẹ̀, dópin. Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn ẹbọ tí wọ́n ń rú gẹ́gẹ́ bí Òfin ti lànà rẹ̀ kò wá ṣeé ṣe mọ́. Ṣé ohun tí èyí wá túmọ̀ sí ni pé àwọn ẹbọ tí wọ́n ń rú, gẹ́gẹ́ bí apá pàtàkì Òfin náà, kò wá nítumọ̀ kankan fún àwọn olùjọ́sìn Ọlọ́run lóde òní? A óò gbé èyí yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwé Insight on the Scriptures, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde, ṣàlàyé pé: “Gẹ́gẹ́ bí a ṣe lò ó nínú Bíbélì, ìtumọ̀ pàtàkì tí ‘ètùtù’ ní ni ‘kíkájú’ tàbí ‘pàṣípààrọ̀,’ ohun táa sì fẹ́ fi ṣe pàṣípààrọ̀, tàbí táa fẹ́ fi ‘kájú’ òmíràn gbọ́dọ̀ jẹ́ ọgbọọgba. . . . Láti ṣe ètùtù tó kúnjú ìwọ̀n ohun tí Ádámù pàdánù, ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tí ìtóye rẹ̀ bá ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn pípé mu rẹ́gí la gbọ́dọ̀ pèsè.”
b Ọ̀rọ̀ Hébérù táa sábà máa ń tú sí “ọrẹ ẹbọ” ni qor·banʹ. Nígbà tí Máàkù ń ṣàkọsílẹ̀ bí Jésù ṣe bẹnu àtẹ́ lu ìwà àgàbàgebè àwọn akọ̀wé àti Farisí, ó ṣàlàyé pé “kọ́bánì” túmọ̀ sí “ẹ̀bùn tí a yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run.”—Máàkù 7:11.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Kí ló mú kí àwọn olóòótọ́ ìgbàanì rúbọ sí Jèhófà?
• Èé ṣe tí àwọn ẹbọ fi pọndandan?
• Oríṣi àwọn ẹbọ pàtàkì wo ni wọ́n ń rú lábẹ́ Òfin, kí sì ni ète wọn?
• Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ti wí, ète pàtàkì wo ni Òfin àti àwọn ẹbọ rẹ̀ ṣiṣẹ́ fún?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Ẹbọ Ébẹ́lì mú inú Ọlọ́run dùn nítorí ẹbọ rẹ̀ fi hàn kedere pé ó gba ìlérí Jèhófà gbọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ǹjẹ́ o mọyì ìjẹ́pàtàkì ìṣẹ̀lẹ̀ yìí?