Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Ká Ní Ẹ̀mí Ìfara-Ẹni-Rúbọ?
Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Ká Ní Ẹ̀mí Ìfara-Ẹni-Rúbọ?
Bill tó ti lé ní ẹni àádọ́ta ọdún ní ìdílé ti ara rẹ̀, olùkọ́ ló sì jẹ́ nínú iṣẹ́ ìkọ́lé. Láti ìbẹ̀rẹ̀ títí fi dé ìparí ọdún, ó máa ń lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀sẹ̀ láti fi ṣètò kí ó sì tún lọ́wọ́ nínú kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba fún àwọn ìjọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, láìgba kọ́bọ̀. Emma jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún, ó kàwé gan-an, ọ̀jọ̀gbọ́n gidi sì ni. Dípò kí ó máa lépa àwọn góńgó tara rẹ̀ nìkan àti afẹ́ ayé, ó máa ń lo àádọ́rin wákàtí lóṣooṣù gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́, ó ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti lóye Bíbélì. Maurice àti Betty ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́. Kàkà kí wọ́n kàn máa gbádùn ní kẹlẹlẹ báyìí, wọ́n ti ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn láti lọ ran àwọn ará ibẹ̀ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ète Ọlọ́run fún ilẹ̀ ayé.
ÀWỌN èèyàn táa sọ̀rọ̀ wọn lókè yìí kò ka ara wọn sí àkàndá tàbí ẹ̀dá àrà ọ̀tọ̀. Èèyàn bíi tiwa ni wọ́n, tó ń ṣe ohun tí wọ́n gbà pé ó tọ́ ní ṣíṣe. Èé ṣe tí wọ́n fi ń lo àkókò, okun, agbára, àti dúkìá wọn fún ire àwọn ẹlòmíì? Ohun tó ń sún wọn ṣe bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ jíjinlẹ̀ fún Ọlọ́run àti fún àwọn aládùúgbò wọn. Ìfẹ́ yìí ti jẹ́ kí kálukú wọ́n ní ojúlówó ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ.
Kí ni à ń pè ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ? Tóò, kò dìgbà téèyàn bẹ̀rẹ̀ sí gbé ìgbésí ayé ìṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́ tàbí kó máa ráre ká tó gbà pé ó ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ. Kì í ṣọ̀ràn ìkára-ẹni-lọ́wọ́-kò lọ́nà àṣejù, tí kì í jẹ́ kéèyàn ní ayọ̀ tàbí ìdùnnú. Gẹ́gẹ́ bí ìwé atúmọ̀ èdè The Shorter Oxford English Dictionary ti wí, ohun tí ìfara-ẹni-rúbọ wulẹ̀ túmọ̀ sí ni “yíyááfì ire, ayọ̀, àti ìfẹ́ tara ẹni, nítorí ojúṣe tàbí nítorí ire àwọn ẹlòmíì.”
Jésù Kristi Ni Àpẹẹrẹ Títayọ Jù Lọ
Jésù Kristi, Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run ni àpẹẹrẹ títayọ jù lọ nípa ẹnì kan tó ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ. Kó tó wá sílé ayé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn, ó dájú pé ìgbésí ayé rẹ̀ ní láti kún fún ayọ̀ àti ìdùnnú tó ga jù lọ. Àjọṣe tímọ́tímọ́ wà láàárín òun àti Bàbá rẹ̀ àti pẹ̀lú àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí. Kò tán síbẹ̀ o, gẹ́gẹ́ bí “àgbà òṣìṣẹ́,” Ọmọ Ọlọ́run lo agbára rẹ̀ nínú àwọn iṣẹ́ tí ń peni níjà tó sì ń mórí ẹni yá gágá. (Òwe 8:30, 31) Ó dájú pé ipò tó wà ga fíìfíì ju èyí tí ẹni tó lọ́rọ̀ jù lọ láyé lè gbádùn. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé òun ló wà ní ipò kejì sí Jèhófà Ọlọ́run, ó ní ìgbéga àti àǹfààní ní ọ̀run.
Síbẹ̀síbẹ̀, Ọmọ Ọlọ́run “sọ ara rẹ̀ di òfìfo, ó sì gbé ìrísí ẹrú wọ̀, ó sì wá wà ní ìrí ènìyàn.” (Fílípì 2:7) Ó fi tinútinú yọ̀ǹda gbogbo àǹfààní tó ní, ó di ẹ̀dá ènìyàn, ó sì fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà láti lè mú ìbàjẹ́ tí Sátánì ṣe kúrò. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-7; Máàkù 10:45) Ìyẹn túmọ̀ sí wíwá bá ọmọ aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀ gbé nínú ayé tó wà lábẹ́ agbára Sátánì Èṣù. (1 Jòhánù 5:19) Ó tún túmọ̀ sí fífara da ìnira àti àìfararọ. Àmọ́, Jésù Kristi ti pinnu pé ohun tó bá gbà lòun máa fún un, òun ò ní ṣàìṣe ìfẹ́ Bàbá òun. (Mátíù 26:39; Jòhánù 5:30; 6:38) Èyí dojú ìfẹ́ àti ìdúróṣinṣin Jésù kọ ìdánwò tí kò ṣeé fẹnu sọ. Ibo ló múra tán láti forí tì í dé? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di onígbọràn títí dé ikú, bẹ́ẹ̀ ni, ikú lórí òpó igi oró.”—Fílípì 2:8.
“Ẹ Pa Ẹ̀mí Ìrònú Yìí Mọ́ Nínú Yín”
A fún wa níṣìírí láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá pé: “Ẹ pa ẹ̀mí ìrònú yìí mọ́ nínú yín, èyí tí ó wà nínú Kristi Jésù pẹ̀lú.” (Fílípì 2:5) Báwo la ṣe lè ṣe èyí? Ọ̀kan lára ọ̀nà táa lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni “kí [a] má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara [wa] nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.” (Fílípì 2:4) Ojúlówó ìfẹ́ “kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan.”—1 Kọ́ríńtì 13:5.
Àwọn èèyàn tó bìkítà sábà máa ń forí-fọrùn ṣe fún àwọn ẹlòmíràn. Àmọ́ lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ anìkànjọpọ́n. Ẹ̀mí tèmi-làkọ́kọ́ ló wà nínú ayé. A gbọ́dọ̀ yàgò fún ẹ̀mí ayé nítorí pé bó bá wọlé sí wa lára pẹ́nrẹ́n, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí darí ẹ̀mí àti ìrònú wa, èyí lè wá jẹ́ ká sọ ìfẹ́ ọkàn tara wa di ohun bàbàrà. Tó bá wá dà bẹ́ẹ̀, ìwà anìkànjọpọ́n ni yóò jẹ gàba lé gbogbo ohun táa bá ń ṣe—títí kan báa ṣe ń lo àkókò wa, okun wa, ohun ìní wa. Fún ìdí yìí, a ní láti jà fitafita láti lè dènà ẹ̀mí yìí.
Nígbà míì pàápàá, ìmọ̀ràn tó jọ ìmọ̀ràn rere lè paná ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ táa ní. Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù rí ibi tí ipa ọ̀nà ìfara-ẹni-rúbọ tí Jésù ń tọ̀ fẹ́ já sí, ó sọ pé: “Ṣàánú ara rẹ, Olúwa.” (Mátíù 16:22) Lójú tirẹ̀, kò sídìí tí Jésù fi ní láti múra tán láti kú nítorí ipò ọba aláṣẹ Bàbá rẹ̀ àti nítorí ìgbàlà ọmọ aráyé. Ìdí nìyẹn tó fi fẹ́ yí Jésù lọ́kàn padà, kí ó yà kúrò ní ipa ọ̀nà yẹn.
‘Sẹ́ Ara Rẹ’
Kí ni Jésù wá ṣe? Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Ó yí padà, ó bojú wo àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì bá Pétérù wí lọ́nà mímúná, ó sì wí pé: ‘Dẹ̀yìn lẹ́yìn mi, Sátánì, nítorí kì í ṣe àwọn ìrònú Ọlọ́run ni ìwọ ń rò, bí kò ṣe ti ènìyàn.’” Jésù wá pe ogunlọ́gọ̀ náà sọ́dọ̀ ara rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ó sì wí pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀, kí ó sì gbé òpó igi oró rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo.”—Máàkù 8:33, 34.
Ní nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn tí Pétérù fún Jésù ní ìmọ̀ràn yìí, ó fi hàn pé òun ti wá mọ ìtumọ̀ ìfara-ẹni-rúbọ báyìí. Kò rọ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n tẹ̀ ẹ́ jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, kí wọ́n sì máa ṣàánú ara wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, Pétérù gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n mú èrò inú wọn gbára dì fún ìgbòkègbodò, kí wọ́n sì jáwọ́ nínú àwọn ìfẹ́ ọkàn ti ayé tí wọ́n ní tẹ́lẹ̀. Láìfi àdánwò pè, wọ́n ní láti máa fi ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wọn.—1 Pétérù 1:6, 13, 14; 4:1, 2.
Ipa ọ̀nà tó lérè nínú jù lọ tí ẹnikẹ́ni nínú wa lè tọ̀ ni láti yọ̀ǹda ara wa fún Jèhófà, kí a máa fi ìṣòtítọ́ tẹ̀ lé Jésù Kristi, kí a sì jẹ́ kí Ọlọ́run máa darí àwọn ìgbòkègbodò wa. Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nínú ọ̀ràn yìí. Ẹ̀mí kánjúkánjú tó ní, àti bó ṣe mọrírì ohun tí Jèhófà ṣe fún un tó, sún un láti jáwọ́ nínú gbogbo ohun 2 Kọ́ríńtì 12:15) Pọ́ọ̀lù lo agbára rẹ̀ láti mú kí àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ire ti Ọlọ́run tẹ̀ síwájú, kì í ṣe ire tara rẹ̀.—Ìṣe 20:24; Fílípì 3:8.
tí ì bá máa lé kiri nínú ayé, èyí tí ì bá mú un yà bàrá kúrò nínú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Ní tèmi, ṣe ni èmi yóò máa fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ gan-an náwó, a ó sì ná mi tán pátápátá” nínú ṣíṣiṣẹ́ fún ire àwọn ẹlòmíì. (Báwo la ṣe lè yẹ ara wa wò láti mọ̀ bóyá a ní irú ẹ̀mí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní? A lè bi ara wa láwọn ìbéèrè bíi: Báwo ni mo ṣe ń lo àkókò mi, okun mi, agbára mi, àti ohun ìní mi? Ṣé mo máa ń lo nǹkan wọ̀nyí, àtàwọn ẹ̀bùn míì tó ṣeyebíye láti fi tẹ́ ara mi lọ́rùn, tàbí mo ń lò wọ́n láti fi ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́? Ǹjẹ́ mo ti ronú nípa títúbọ̀ nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà náà, èyíinì ni iṣẹ́ kíkéde ìhìn rere, bóyá kí n tilẹ̀ máa fi àkókò kíkún pòkìkí Ìjọba náà? Ǹjẹ́ mo lè túbọ̀ máa kọ́wọ́ ti àwọn ìgbòkègbodò bí kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí títún wọn ṣe? Ǹjẹ́ mo ń lo àwọn àǹfààní tí mo ní láti ran àwọn aláìní lọ́wọ́? Ǹjẹ́ mo ń fún Jèhófà ní ohun tí ó dára jù lọ?—Òwe 3:9.
“Ayọ̀ Púpọ̀ Wà Nínú Fífúnni”
Ṣùgbọ́n o, ǹjẹ́ ó tiẹ̀ mọ́gbọ́n dání láti ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ? Bẹ́ẹ̀ ni o! Pọ́ọ̀lù mọ̀ látinú ìrírí ara rẹ̀ pé irú ẹ̀mí yẹn ń mérè wá lọ́pọ̀lọpọ̀. Ó fún un ní ayọ̀ ńláǹlà àti ìtẹ́lọ́rùn gígadabú. Ó ṣàlàyé èyí fún àwọn àgbà ọkùnrin tó wà ní Éfésù nígbà tó pàdé pẹ̀lú wọn nílùú Mílétù. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo ti fi hàn yín nínú ohun gbogbo pé nípa ṣíṣe òpò lọ́nà yìí [ìyẹn, lọ́nà ìfara-ẹni-rúbọ], ẹ gbọ́dọ̀ ṣèrànwọ́ fún àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìlera, ẹ sì gbọ́dọ̀ fi àwọn ọ̀rọ̀ Jésù Olúwa sọ́kàn, nígbà tí òun fúnra rẹ̀ wí pé, ‘Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.’” (Ìṣe 20:35) Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ti rí i pé níní irú ẹ̀mí yìí ń mú ayọ̀ ńláǹlà wá nísinsìnyí pàápàá. Yóò tún mú ayọ̀ wá lọ́jọ́ iwájú nígbà tí Jèhófà bá san èrè fún àwọn tó fi ire tirẹ̀ àti ti àwọn ẹlòmíì ṣíwájú tara wọn.—1 Tímótì 4:8-10.
Nígbà tí wọ́n bi Bill léèrè ìdí tó fi ń fi torí-tọrùn ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, ó sọ pé: “Ṣíṣèrànwọ́ lọ́nà yìí fáwọn ìjọ tó kéré ń fún mi ní ayọ̀ ńláǹlà. Mo máa ń gbádùn lílo ìmọ̀ àti òye iṣẹ́ tí mo ní fún àǹfààní àwọn ẹlòmíì.” Èé ṣe tí Emma fi yàn láti fi okun àti agbára rẹ̀ ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́? “Mi ò
tiẹ̀ lè ronú pé kí n máa ṣe nǹkan mìíràn. Nígbà tí mo ṣì jẹ́ ọ̀dọ́ tí àyè rẹ̀ ṣì ṣí sílẹ̀ fún mi, ó wù mí láti sa gbogbo ipá mi láti mú inú Jèhófà dùn kí n sì ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. Fífi díẹ̀ lára àwọn nǹkan tara tí mo ní rúbọ kò tíì pọ̀ jù. Nǹkan tó yẹ kí n ṣe ni mo wulẹ̀ ń ṣe látàrí gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún mi.”Maurice àti Betty kò kábàámọ̀ rárá pé àwọn kò gbé ìgbé-ayé ìdẹ̀ra, lẹ́yìn àwọn ọdún iṣẹ́ àṣekára tí wọ́n ṣe bí wọ́n ti ń tọ́ àwọn ọmọ tí wọ́n sì ń gbọ́ bùkátà ìdílé. Nísinsìnyí tí wọ́n ti fẹ̀yìn tì, wọ́n fẹ́ máa bá a nìṣó ní fífi ìgbésí ayé wọn ṣe ohun kan tó jọjú tó sì wúlò. Wọ́n sọ pé: “A ò fẹ́ jókòó gẹlẹtẹ, kí a kàn máa ṣe fàájì báyìí. Ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà ní ilẹ̀ òkèèrè ń fún wa ní àǹfààní láti máa bá a nìṣó ní ṣíṣe ohun tó mọ́yán lórí.”
Ìwọ ha ti pinnu láti jẹ́ olùfara-ẹni-rúbọ bí? Kò ní rọrùn o. Ìjàkadì á máa wáyé ṣáá láàárín ìfẹ́ ọkàn àwa ènìyàn aláìpé àti ìfẹ́ àtọkànwá táa ní láti máa ṣe ohun tó wu Ọlọ́run. (Róòmù 7:21-23) Ṣùgbọ́n a lè borí nínú ìjàkadì náà báa bá jẹ́ kí Jèhófà máa darí ìgbésí ayé wa. (Gálátíà 5:16, 17) Ó dájú pé òun yóò rántí iṣẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ táa ti ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, yóò sì bù kún wa lọ́pọ̀lọpọ̀. Àní, Jèhófà Ọlọ́run yóò ‘ṣí ibodè ibú omi ọ̀run, yóò sì tú ìbùkún dà sórí wa ní ti tòótọ́ títí kì yóò fi sí àìní mọ́.’—Málákì 3:10; Hébérù 6:10.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Jésù ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ. Ìwọ ńkọ́?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Pọ́ọ̀lù lo gbogbo agbára rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà