Kíkẹ́kọ̀ọ́—Ó Ṣàǹfààní, Ó Sì Gbádùn Mọ́ni
Kíkẹ́kọ̀ọ́—Ó Ṣàǹfààní, Ó Sì Gbádùn Mọ́ni
“Bí o bá ń bá a nìṣó ní wíwá a . . . , ìwọ yóò . . . rí ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an.”—ÒWE 2:4, 5.
1. Báwo ni kíkàwé fún ìnàjú ṣe lè fún wa ní ìdùnnú púpọ̀?
Ọ̀PỌ̀ ènìyàn ló kàn ń kàwé fún ìgbádùn. Bí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ táa ń kà bá jẹ́ èyí tó gbámúṣé, kíkàwé lè jẹ́ ohun kán táa fi ń najú. Yàtọ̀ sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì tí wọ́n ń kà déédéé, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn Kristẹni kan máa ń gbádùn kíka Sáàmù, ìwé Òwe, àti àwọn ìwé Ìhìn Rere, tàbí àwọn apá ibòmíràn nínú Bíbélì. Ẹwà èdè tó wà níbẹ̀ àti èrò tí ọ̀rọ̀ ibẹ̀ gbé jáde máa ń tù wọ́n lára gan-an ni. Ohun táwọn mìíràn yan láti kà fún ìnàjú ni ìwé Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ìwé ìròyìn Jí!, ìtàn ìgbésí ayé tó wà nínú ìwé àtìgbàdégbà yìí, tàbí àwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ẹ̀kọ́ nípa ìtàn, ìmọ̀ nípa ilẹ̀ ayé àti ìwàláàyè inú rẹ̀, àti ẹ̀kọ́ nípa ìṣẹ̀dá.
2, 3. (a) Ọ̀nà wo la lè gbà fi ìsọfúnni nípa tẹ̀mí wé oúnjẹ líle? (b) Kí ni kíkẹ́kọ̀ọ́ ní nínú?
2 Nígbà tí kíkàwé lè jẹ́ ohun kan táa fi ń najú, kíkẹ́kọ̀ọ́ máa ń gba ìsapá táa lo ọpọlọ fún. Onímọ̀ ọgbọ́n orí nì, Francis Bacon, kọ̀wé pé: “Àwọn ìwé kan wà táa kan lè tọ́ wò, àwọn mìíràn wà táa ní láti gbé mì, àwọn díẹ̀ sì wà táa ní láti jẹ lẹ́nu kó sì dà nínú wa.” Ara èyí tó kẹ́yìn yìí gan-an ni Bíbélì wà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nípa rẹ̀ [Kristi, bí a ti fi hàn nípasẹ̀ Ọba àti Àlùfáà Melikisédékì] a ní púpọ̀ láti sọ, tí ó sì ṣòro láti ṣàlàyé, níwọ̀n bí ẹ ti yigbì ní gbígbọ́. . . . Oúnjẹ líle jẹ́ ti àwọn ènìyàn tí ó dàgbà dénú, ti àwọn tí wọ́n tipasẹ̀ lílò kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” (Hébérù 5:11, 14) A gbọ́dọ̀ jẹ oúnjẹ líle kúnná lẹ́nu kó tó di pé a gbé e mì kó sì dà nínú wa. Ìsọfúnni jíjinlẹ̀ nípa tẹ̀mí náà gba ríronú jinlẹ̀ kó tó lè wọ̀ wá lọ́kàn, kó sì dúró síbẹ̀.
3 Ìwé atúmọ̀ èdè kan túmọ̀ “kíkẹ́kọ̀ọ́” sí “ọ̀nà tàbí bí a ṣe ń lo èrò inú láti jèrè ìmọ̀ tàbí òye, bíi nípa kíkàwé, ṣíṣèwádìí, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.” Ó wá túmọ̀ sí pé kíkẹ́kọ̀ọ́ kọjá ká kàn kàwé lọ gààràgà, bóyá ká tiẹ̀ máa fàlà sábẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ kan báa ti ń kà á lọ. Kíkẹ́kọ̀ọ́ túmọ̀ sí iṣẹ́, ìsapá tí a fi ọpọlọ ṣe, àti lílo agbára ìrònú wa. Àmọ́ ṣá o, bí kíkẹ́kọ̀ọ́ tiẹ̀ gba ìsapá, ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé kò lè gbádùn mọ́ni.
Mímú Kí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Gbádùn Mọ́ni
4. Gẹ́gẹ́ bí onísáàmù ti sọ, báwo ni kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ń tuni lára tí ó sì ṣàǹfààní?
4 Kíkà Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lè tuni lára kí ó sì fi okun kún okun wa. Onísáàmù náà kéde pé: “Òfin Jèhófà pé, ó ń mú ọkàn padà wá. Ìránnilétí Jèhófà ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, ó ń sọ aláìní ìrírí di ọlọ́gbọ́n. Àwọn àṣẹ ìtọ́ni láti ọ̀dọ̀ Jèhófà dúró ṣánṣán, wọ́n ń mú ọkàn-àyà yọ̀; àṣẹ Jèhófà mọ́, ó ń mú kí ojú mọ́lẹ̀.” (Sáàmù 19:7, 8) Òfin àti ìránnilétí Jèhófà ń ta ọkàn wa jí, ó ń fi kún ipò tẹ̀mí wa, ó ń fún wa láyọ̀ àtọkànwá, ó sì ń mú ojú wa mọ́lẹ̀ láti rí àwọn ète àgbàyanu Jèhófà kedere. Èyí mà múnú ẹni dùn o!
5. Àwọn ọ̀nà wo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ fi lè mú ìdùnnú ńlá wá fún wa?
5 Nígbà táa bá rí i pé iṣẹ́ wa ń yọrí sí rere, yóò túbọ̀ máa wù wáá ṣe. Nítorí náà, táa bá fẹ́ gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́, a gbọ́dọ̀ yára kánkán láti lo ìmọ̀ tuntun táa ṣẹ̀ṣẹ̀ rí gbà. Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Ẹni tí ó bá ń wo inú òfin pípé tí í ṣe ti òmìnira ní àwòfín, tí ó sì tẹpẹlẹ mọ́ ọn, ẹni yìí, nítorí tí kò di olùgbọ́ tí ń gbàgbé, bí kò ṣe olùṣe iṣẹ́ náà, yóò láyọ̀ nínú ṣíṣe é.” (Jákọ́bù 1:25) Títètè fi àwọn ohun táa ń kọ́ sílò máa ń mú ìtẹ́lọ́rùn tó ga wá. Ṣíṣèwádìí pẹ̀lú ète àtidáhùn ìbéèrè kan tí wọ́n bi wá nígbà táa ń wàásù tàbí nígbà tí a ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ yóò mú ayọ̀ ńlá wá fún wa.
Níní Ìfẹ́ni fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
6. Báwo ni òǹkọ̀wé Sáàmù kọkàndínlọ́gọ́fà ṣe sọ ìfẹ́ni rẹ̀ fún ọ̀rọ̀ Jèhófà jáde?
6 Ẹni tó kọ Sáàmù kọkàndínlọ́gọ́fà, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ Hesekáyà nígbà tó ṣì wà lọ́mọdé gẹ́gẹ́ bí ọmọ ọba, fí ìfẹ́ni tó ní fún ọ̀rọ̀ Jèhófà hàn. Ní èdè ewì, ó sọ pé: “Nítorí pé èmi yóò fi ìfẹ́ni hàn fún àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ rẹ. Èmi kì yóò gbàgbé ọ̀rọ̀ rẹ. Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn ìránnilétí rẹ ni mo ní ìfẹ́ni fún . . . Èmi yóò sì fi ìfẹ́ni hàn fún àwọn àṣẹ rẹ, tí mo ti nífẹ̀ẹ́. Kí àánú rẹ tọ̀ mí wá, kí n lè máa wà láàyè nìṣó; nítorí pé òfin rẹ ni ohun tí mo ní ìfẹ́ni fún. Mo ti ń yánhànhàn fún ìgbàlà rẹ, Jèhófà, òfin rẹ ni mo sì ní ìfẹ́ni fún.”—Sáàmù 119:16, 24, 47, 77, 174.
7, 8. (a) Gẹ́gẹ́ bí ìwé kan táa ṣèwádìí nínú rẹ̀ ti sọ, kí ló túmọ̀ sí láti “fi ìfẹ́ni hàn” fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? (b) Báwo la ṣe lè fi ìfẹ́ wa hàn fún Ọ̀rọ̀ Jèhófà? (d) Báwo ni Ẹ́sírà ṣe múra ara rẹ̀ sílẹ̀ kí ó tó ka Òfin Jèhófà?
7 Láti ṣàlàyé ọ̀rọ̀ táa túmọ̀ sí “fi ìfẹ́ni hàn” nínú Sáàmù kọkàndínlọ́gọ́fà, ìwé atúmọ̀ èdè kan lórí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sọ pé: “Bí a ṣe lò ó nínú ẹsẹ kẹrìndínlógún bá [ọ̀rọ̀ ìṣe] fún yíyọ̀ . . . àti fún ṣíṣe àṣàrò . . . mu. Bó ṣe lọ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé ni pé: yọ̀, ṣàṣàrò, ní inú dídùn sí . . . Àpapọ̀ yìí lè túmọ̀ sí pé ríronú jinlẹ̀ ni ọ̀nà tí ẹnì kan lè gbà ní inú dídùn sí ọ̀rọ̀ Yáwè. . . . Ìtumọ̀ náà tún ní èrò kan tí ń wọni lákínyẹmí ara nínú.” a
8 Bẹ́ẹ̀ ni o, ìfẹ́ táa ní fún Ọ̀rọ̀ Jèhófà gbọ́dọ̀ wá láti inú ọkàn-àyà wa, níbi tí ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ ti ń wá. A gbọ́dọ̀ ní inú dídùn sí síséraró díẹ̀ láti ronú lórí àwọn àyọkà kan táa ṣẹ̀ṣẹ̀ kà. A gbọ́dọ̀ fẹ̀sọ̀ ronú lórí àwọn èrò tẹ̀mí jíjinlẹ̀, kí a fi ara wa fún wọn pátápátá, kí a sì máa ṣàṣàrò lórí wọn. Èyí ń béèrè fífarabalẹ̀ ronú àti gbígbàdúrà. Bíi ti Ẹ́sírà, a gbọ́dọ̀ múra ọkàn-àyà wa sílẹ̀ láti ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí a sì kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Òun la kọ̀wé nípa rẹ̀ pé: “Ẹ́sírà fúnra rẹ̀ ti múra ọkàn-àyà rẹ̀ sílẹ̀ láti ṣe ìwádìí nínú òfin Jèhófà àti láti pa á mọ́ àti láti máa kọ́ni ní ìlànà àti ìdájọ́ òdodo ní Ísírẹ́lì.” (Ẹ́sírà 7:10) Kíyè sí ète mẹ́ta tí Ẹ́sírà fi múra ọkàn-àyà rẹ̀ sílẹ̀: láti kẹ́kọ̀ọ́, láti fi ohun tó ń kọ́ sílò, àti láti kọ́ni. Ó yẹ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.
Kíkẹ́kọ̀ọ́ Jẹ́ Ìṣe Ìjọsìn Kan
9, 10. (a) Àwọn ọ̀nà wo ni onísáàmù náà gbà ṣàníyàn nípa Ọ̀rọ̀ Jèhófà? (b) Kí ni ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Hébérù tí a tú sí “kí [ẹnì kan] ṣàníyàn” túmọ̀ sí? (d) Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì fún wa láti ka kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí “ìṣe ìjọsìn kan”?
9 Onísáàmù náà sọ pé òun ń ṣàníyàn nípa òfin, àṣẹ, àti àwọn ìránnilétí Jèhófà. Ó kọ ọ́ lórin pé: “Ṣe ni èmi yóò máa fi àwọn àṣẹ ìtọ́ni rẹ ṣe ìdàníyàn mi, èmi yóò sì máa gbára lé àwọn ipa ọ̀nà rẹ. Èmi yóò sì gbé àtẹ́lẹwọ́ mi sókè sí àwọn àṣẹ rẹ, tí mo ti nífẹ̀ẹ́, ṣe ni èmi yóò máa fi àwọn ìlànà rẹ ṣe ìdàníyàn mi. Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o! Òun ni mo fi ń ṣe ìdàníyàn mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀. Mo ti wá ní ìjìnlẹ̀ òye ju gbogbo àwọn olùkọ́ mi, nítorí pé àwọn ìránnilétí rẹ ni ìdàníyàn mi.” (Sáàmù 119:15, 48, 97, 99) Kí ni kí ‘ẹnì kan’ fi Ọ̀rọ̀ Jèhófà ‘ṣe ìdàníyàn rẹ̀’ túmọ̀ sí?
10 Ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Hébérù náà tí a túmọ̀ sí “kí [ẹnì kan] ṣàníyàn” tún túmọ̀ sí “ṣàṣàrò, ronú jinlẹ̀,” “da ọ̀ràn kan rò lọ́kàn ẹni.” “A lò ó fún fífarabalẹ̀ ronú lórí iṣẹ́ Ọlọ́run . . . àti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” (Theological Wordbook of the Old Testament) Ọ̀rọ̀ orúkọ náà, “àníyàn” tọ́ka sí “bí onísáàmù náà ṣe ń ṣàṣàrò,” “tí ìfẹ́ ń sún un láti kẹ́kọ̀ọ́” òfin Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí “ìṣe ìjọsìn kan.” Bí a bá ka kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run si apá kan ìjọsìn wa yóò jẹ́ kí a mọ ìjẹ́pàtàkì rẹ̀. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ fi tọkàntọkàn ṣe é pẹ̀lú àǹfààní àdúrà. Ìkẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ apá kan ìjọsìn wa, a sì ń ṣe é láti mú kí ìjọsìn wa sunwọ̀n sí i.
Títúbọ̀ Walẹ̀ Jìn Sínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
11. Báwo ni Jèhófà ṣe ń ṣí àwọn èrò tẹ̀mí jíjinlẹ̀ payá fún àwọn ènìyàn rẹ̀?
11 Pẹ̀lú ìjọnilójú ọlọ́wọ̀ ni onísáàmù náà fi kígbe pé: “Àwọn iṣẹ́ rẹ mà tóbi o, Jèhófà! Ìrònú rẹ jinlẹ̀ gidigidi.” (Sáàmù 92:5) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà sọ̀rọ̀ nípa “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run,” àwọn èrò jíjinlẹ̀ tí Jèhófà ṣí payá fún àwọn ènìyàn rẹ̀ “nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀” tó ń ṣiṣẹ́ lára ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye náà. (1 Kọ́ríńtì 2:10; Mátíù 24:45) Ẹgbẹ́ ẹrú náà ń fi taápọntaápọn pèsè oúnjẹ amáralókun nípa tẹ̀mí fún gbogbo èèyàn—“wàrà” fún àwọn ẹni tuntun àmọ́ “oúnjẹ líle” fún “àwọn ènìyàn tí ó dàgbà dénú.”—Hébérù 5:11-14.
12. Fúnni lápẹẹrẹ kan nípa “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run” tí ẹgbẹ́ ẹrú náà ti ṣàlàyé.
12 Táa bá fẹ́ lóye irú “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run” bẹ́ẹ̀, ó pọndandan fún wa láti kẹ́kọ̀ọ́ tàdúràtàdúrà, kí a sì ronú lórí Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, a ti tẹ àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tó dára jáde tó fi hàn pé Jèhófà lè ṣe ohun tó tọ́ kó sì tún fi àánú hàn nígbà kan náà. Pé ó ń fi àánú hàn kò túmọ̀ sí pé ìyẹn ń tẹ́ńbẹ́lú ìdájọ́ òdodo rẹ̀; dípò ìyẹn, àánú àtọ̀runwá jẹ́ ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń fi ìdájọ́ òdodo àti ìfẹ́ rẹ̀ hàn. Nígbà tí Jèhófà bá ń dá ẹlẹ́ṣẹ̀ kan lẹ́jọ́, ó máa ń kọ́kọ́ wò ó bóyá ó ṣeé ṣe láti fi àánú hàn lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ ìràpadà Ọmọ rẹ̀. Bí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà ò bá wá ronú pìwà dà tàbí tó jẹ́ olórí kunkun, Ọlọ́run á wá ṣe ìdájọ́ òdodo láìsí ọ̀rọ̀ pé ó ń lo àánú tí kò nídìí. Èyí ó wù kó jẹ́, òun jẹ́ olódodo sí àwọn ìlànà gíga rẹ̀. b (Róòmù 3:21-26) ‘Ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n Ọlọ́run má pọ̀ o!’—Róòmù 11:33.
13. Báwo ló ṣe yẹ ká fi ìmọrírì hàn fún “àròpọ̀ iye” òtítọ́ tẹ̀mí táa ti ṣí payá fún wa títí di ìsinsìnyí?
13 Bíi ti onísáàmù náà, inú wa dùn lórí kókó náà pé Jèhófà sọ ọ̀pọ̀ lára èrò inú rẹ̀ fún wa. Dáfídì kọ̀wé pé: “Lójú mi, àwọn ìrònú rẹ mà ṣe iyebíye o! Ọlọ́run, àròpọ̀ iye wọn pátápátá mà pọ̀ o! Ká ní mo fẹ́ gbìyànjú láti kà wọ́n ni, wọ́n pọ̀ ju àwọn egunrín iyanrìn pàápàá.” (Sáàmù 139:17, 18) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìmọ̀ táa ní lónìí kò ju bíńtín lára àìmọye èrò tí Jèhófà máa ṣí payá fún wa títí ayé fáàbàdà, síbẹ̀ a mọyì “àròpọ̀ iye” òtítọ́ tẹ̀mí ṣíṣeyebíye tó ti ṣí payá fún wa títí di ìsinsìnyí táa sì túbọ̀ ń walẹ̀ jìn wọnú àròpọ̀ náà, tàbí wọnú kókó inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Sáàmù 119:160, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.
Ìsapá àti Àwọn Irin Iṣẹ́ Táa Nílò
14. Báwo ni Òwe orí kẹfà ẹsẹ ìkíní sí ìkẹfà ṣe tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ìsapá nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
14 Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó jinlẹ̀ ń béèrè ìsapá. A ó rí kókó yìí kedere táa bá fara balẹ̀ ka ìwé Òwe orí kejì, ẹsẹ ìkíní sí ìkẹfà. Kíyè sí àwọn ọ̀rọ̀ ìṣe tó gbéṣẹ́ tí Sólómọ́nì Ọba lò láti tẹnu mọ́ ìsapá tí a ó ṣe ká tó lè gba ìmọ̀, ọgbọ́n, àti ìfòyemọ̀ Ọlọ́run. Ó kọ̀wé pé: “Ọmọ mi, bí ìwọ yóò bá gba àwọn àsọjáde mi, tí ìwọ yóò sì fi àwọn àṣẹ tèmi ṣúra sọ́dọ̀ rẹ, láti lè dẹ etí rẹ sí ọgbọ́n, kí o lè fi ọkàn-àyà rẹ sí ìfòyemọ̀; jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí o bá ké pe òye, tí o sì fọ ohùn rẹ jáde sí ìfòyemọ̀, bí o bá ń bá a nìṣó ní wíwá a bí fàdákà, tí o sì ń bá a nìṣó ní wíwá a kiri bí àwọn ìṣúra fífarasin, bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò lóye ìbẹ̀rù Jèhófà, ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an. Nítorí Jèhófà fúnra rẹ̀ ní ń fúnni ní ọgbọ́n; láti ẹnu rẹ̀ ni ìmọ̀ àti ìfòyemọ̀ ti ń wá.” Bẹ́ẹ̀ ni o, ìkẹ́kọ̀ọ́ tó ṣàǹfààní gba ṣíṣèwádìí, wíwa ilẹ̀, bí ẹni ń wá ìṣúra fífarasin kiri.
15. Àpèjúwe inú Bíbélì wo ló tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ọ̀nà ìkẹ́kọ̀ọ́ tó dára?
15 Ìkẹ́kọ̀ọ́ tó ń bù kúnni nípa tẹ̀mí tún fẹ́ ọ̀nà ìkẹ́kọ̀ọ́ tó dáa. Sólómọ́nì kọ̀wé pé: “Bí irinṣẹ́ tí a fi irin ṣe bá ti kújú, tí ẹnì kan kò sì pọ́n ọn, nígbà náà, ìmí tirẹ̀ ni yóò fi tiraka.” (Oníwàásù 10:10) Bí òṣìṣẹ́ kan bá ń lo irinṣẹ́ kan tó kújú tàbí tí kò bá lò ó dáadáa, yóò wulẹ̀ máa fi agbára rẹ̀ ṣòfò ni, iṣẹ́ rẹ̀ kò sì ní jẹ́ ojúlówó. Bákan náà ni àǹfààní táa ń rí nínú àkókò táa fi ń kẹ́kọ̀ọ́ lè yàtọ̀ síra gan-an, níwọ̀n bí èyí tí sinmi lórí àwọn ọ̀nà táa gba ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ wa. Àwọn ìmọ̀ràn àtàtà tó ṣeé mú lò kí ìkẹ́kọ̀ọ́ wa lè sunwọ̀n sí i la lè rí nínú Ẹ̀kọ́ keje, nínú Iwe-Amọna Ile Ẹkọ Iṣẹ Ojiṣẹ Ijọba Ọlọrun. c
16. Àwọn ìmọ̀ràn wo la fún wa tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ tó jinlẹ̀?
16 Nígbà tí oníṣẹ́ ọnà kan bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀, yóò kó gbogbo àwọn irinṣẹ́ tó fẹ́ lò jọ. Bákan náà, táa bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́, a gbọ́dọ̀ yẹ ibi ìkówèésí wa wò kí a sì yan àwọn irinṣẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ táa ó lò. Níwọ̀n bí kíkẹ́kọ̀ọ́ ti jẹ́ iṣẹ́ tó sì gba ìsapá táa ń fi ọpọlọ ṣe, ó tún dáa ká máa jókòó lọ́nà tó dára lákòókò táa bá ń ṣe é. Táa bá fẹ́ kí ọpọlọ wa jí pépé, yóò dára kí a jókòó sórí àga kan tí tábìlì tàbí àga ìkọ̀wé wà níwájú rẹ̀ dípò tí a ó fi sùn sórí ibùsùn tàbí ká jókòó sórí àga aláfẹ̀yìntì. Lẹ́yìn tí o bá ti pọkàn pọ̀ sórí ẹ̀kọ́ náà fúngbà díẹ̀, o lè dìde kóo nara díẹ̀ tàbí kóo jáde síta láti lọ gba atẹ́gùn díẹ̀ sára.
17, 18. Fúnni lápẹẹrẹ báa ṣe ń lo àwọn irinṣẹ́ àtàtà tí o ní níkàáwọ́ fún ìkẹ́kọ̀ọ́.
17 Ọ̀pọ̀ irinṣẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ tí kò láfiwé la tún ní lárọ̀ọ́wọ́tó wa. Èyí tó jẹ́ àkọ́kọ́ lára wọn ni Bíbélì ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó nísinsìnyí lódindi tàbí lápá kan ní èdè mẹ́tàdínlógójì. Ẹ̀dà tó wọ́pọ̀ jù lọ lára Ìtumọ̀ Ayé Tuntun náà ní atọ́ka, àti “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àwọn Ìwé Inú Bíbélì” tí ó jẹ́ kí a mọ orúkọ àwọn tó kọ Bíbélì, ibi tí wọ́n ti kọ ọ́ àti àkókò tó gbà wọ́n láti kọ ọ́. Ó tún ní atọ́ka àṣàyàn ọ̀rọ̀ Bíbélì, àsomọ́, àti àwòrán ilẹ̀. Ní àwọn èdè kan, a tẹ Bíbélì yìí ní ẹ̀dà kan tó tóbi, tí a mọ̀ sí Bíbélì atọ́ka. Ó ní gbogbo apá tí a sọ lókè yìí àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn nínú, títí kan àwọn àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé gbígbòòrò, tí a tọ́ka sí àwọn náà. Ǹjẹ́ o máa ń lo àwọn ohun tó wà ní àrọ́wọ́tó ni èdè rẹ̀ dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ láti walẹ̀ jìn sínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
18 Irinṣẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ tí kò ṣeé díye lé mìíràn ni ìdìpọ̀ alápá méjì ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Bíbélì náà, Insight on the Scriptures. Bí o bá ní ìwé yìí ní èdè tóo lóye, ó gbọ́dọ̀ máa wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ ní gbogbo ìgbà tóo bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́. Yóò fún ọ ní àwọn ìsọfúnni tóo nílò lórí ọ̀pọ̀ jù lọ àkòrí ọ̀rọ̀ Bíbélì. Irinṣẹ́ tó tún ṣèrànwọ́ bákan náà ni ìwé “All Scripture Is Inspired of God and Beneficial.” Nígbà táa bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí ka ìwé tuntun kan lára àwọn ìwé Bíbélì, ó dára láti yẹ ẹ̀kọ́ tó bá á mu wẹ́kú wò nínú ìwé “All Scripture” láti mọ ọ̀gangan ibi tí ọ̀rọ̀ náà ti ṣẹlẹ̀ àti ìtàn tó yìí ká, kí a sì lè mọ àkópọ̀ ọ̀rọ̀ inú ìwé Bíbélì náà àti bí wọ́n ṣe wúlò fún wa. Irinṣẹ́ mìíràn tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí ní àfikún sí àwọn tí a tẹ̀ jáde ni Watchtower Library tí a ṣe sínú ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà, tó ti wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní èdè mẹ́sàn-án báyìí.
19. (a) Èé ṣe ti Jèhófà fi pèsè àwọn irinṣẹ́ tó dára láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún wa? (b) Kí la nílò fún kíka Bíbélì àti kíkẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó dára?
19 Jèhófà ti tipasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” pèsè gbogbo irin iṣẹ́ wọ̀nyí kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé lè ‘wá kí wọ́n sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an.’ (Òwe 2:4, 5) Ọ̀nà ìkẹ́kọ̀ọ́ tó dára ń mú kó ṣeé ṣe fún wa láti túbọ̀ ní ìmọ̀ Jèhófà síwájú sí i kí a sì gbádùn àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú rẹ̀. (Sáàmù 63:1-8) Dájúdájú, kíkẹ́kọ̀ọ́ túmọ̀ sí iṣẹ́, ṣùgbọ́n iṣẹ́ tó gbádùn mọ́ni tó sì ṣàǹfààní ni. Àmọ́ ṣa o, ó máa ń gba àkókò, ó sì ṣeé ṣe kí o máa ronú pé, ‘Ibo ni màá ti rí àkókò láti máa ka Bíbélì kí n sì máa dá kẹ́kọ̀ọ́ bó ti tọ́ àti bó ti yẹ?’ Apá yìí ni a ó gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kẹ́yìn nínú ọ̀wọ́ yìí.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwé atúmọ̀ èdè New International Dictionary of Old Testament Theology & Exegesis, Ìdìpọ̀ kẹrin, ojú ìwé 205 sí 207.
b Wo Ilé Ìṣọ́ August 1, 1998, ojú ìwé 13, ìpínrọ̀ 7. Gẹ́gẹ́ bí ara ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, o lè tún àwọn àpilẹ̀kọ méjèèjì tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ẹ̀dà yẹn yẹ̀ wò títí kan ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ lórí “ìdájọ́ òdodo,” “Àánú,” àti “Òdodo” tó wà nínú ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Bíbélì náà, Insight on the Scriptures, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
c Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde. Bí kò bá sí ìwé yìí ní èdè tìrẹ, àwọn ìmọ̀ràn àtàtà táa lè lò fún àwọn ọ̀nà ìkẹ́kọ̀ọ́ tó dára la lè rí nínú àwọn ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí: August 15, 1993, ojú ìwé 13 sí 17; February 1, 1987, ojú ìwé 30 sí 31.
Àwọn Ìbéèrè fún Àtúnyẹ̀wò
• Báwo la ṣe lè mú kí ìdákẹ́kọ̀ọ́ wa tura, kó sì ṣàǹfààní?
• Bíi ti onísáàmù, báwo la ṣe lè fi “ìfẹ́ni” àti “ìdàníyàn” hàn fún Ọ̀rọ̀ Jèhófà?
• Báwo ni Òwe orí kejì ẹsẹ ìkíní sí ìkẹfà ṣe fi ìjẹ́pàtàkì ìsapá hàn nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
• Kí ni àwọn irinṣẹ́ àtàtà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ tí Jèhófà pèsè fún wa?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Fífarabalẹ̀ ronú àti gbígbàdúrà ń ràn wá lọ́wọ́ láti mú ìfẹ́ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dàgbà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ǹjẹ́ o máa ń lo àwọn irinṣẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ tó wà níkàáwọ́ rẹ láti walẹ̀ jìn sínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?