Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Fífi Ìwà Ọ̀làwọ́ Hàn Lọ́pọ̀ Yanturu Ń Máyọ̀ Wá

Fífi Ìwà Ọ̀làwọ́ Hàn Lọ́pọ̀ Yanturu Ń Máyọ̀ Wá

Fífi Ìwà Ọ̀làwọ́ Hàn Lọ́pọ̀ Yanturu Ń Máyọ̀ Wá

GẸ́GẸ́ bíi Kristẹni alábòójútó tó jẹ́ onífẹ̀ẹ́, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàníyàn nípa ohun tó ṣàǹfààní jù lọ fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 11:28) Nítorí náà, nígbà tó di apá ìdajì ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, ó ṣètò ìkówójọ fún àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ aláìní ní Jùdíà, ó lo àǹfààní yẹn láti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ ṣíṣeyebíye nípa ìwà ọ̀làwọ́. Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ ọn pé Jèhófà fojú ribiribi wo fífúnni ọlọ́yàyà, ó wí pé: “Kí olúkúlùkù ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn-àyà rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀ tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.”—2 Kọ́ríńtì 9:7.

Nínú Ipò Òṣì Paraku, Síbẹ̀ Wọ́n Lawọ́

Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ni kò lókìkí láàárín ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà. Pọ́ọ̀lù kíyè sí i pé àwọn tó wà láàárín wọn “kì í ṣe ọ̀pọ̀ alágbára.” Wọ́n jẹ́ “àwọn ohun aláìlera ayé,” “àwọn ohun tí kò gbayì nínú ayé.” (1 Kọ́ríńtì 1:26-28) Fún àpẹẹrẹ, àwọn Kristẹni tó wà ní Makedóníà wà nínú “ipò òṣì paraku” àti “lábẹ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́.” Síbẹ̀ àwọn onírẹ̀lẹ̀ ará Makedóníà wọ̀nyẹn bẹ̀bẹ̀ fún àǹfààní láti fowó ṣètìlẹ́yìn fún “iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ fún àwọn ẹni mímọ́”; Pọ́ọ̀lù sì jẹ́rìí sí i pé ohun tí wọ́n dá “kọjá agbára wọn gan-an”!—2 Kọ́ríńtì 8:1-4.

Síbẹ̀síbẹ̀, kì í ṣe bí ohun tí wọ́n dá ṣe pọ̀ tó la fi ń sọ pé wọ́n lẹ́mìí ọ̀làwọ́. Àmọ́, ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni ohun tó sún wọn ṣe é, ìmúratán láti ṣàjọpín, àti irú ẹ̀mí tí wọ́n fi ṣe é. Pọ́ọ̀lù jẹ́ kí àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì mọ̀ pé èrò inú àti ọkàn-àyà lápapọ̀ ló ń kópa nínú ṣíṣe ìtọrẹ. Ó sọ pé: “Mo mọ ìmúratán èrò inú yín, èyí tí mo fi ń ṣògo nípa yín fún àwọn ará Makedóníà, . . . ìtara yín sì ti ru ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn sókè.” Wọ́n ti ‘pinnu nínú ọkàn-àyà wọn’ láti fúnni pẹ̀lú ẹ̀mí ọ̀làwọ́.—2 Kọ́ríńtì 9:2, 7.

‘Ẹ̀mí Wọn Ru Wọ́n Sókè’

Ó lè jẹ́ ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn ni àpẹẹrẹ fífúnni pẹ̀lú ẹ̀mí ọ̀làwọ́ tó ti ṣẹlẹ̀ ṣáájú, èyí tó ṣẹlẹ̀ nínú aginjù ní ohun tó lé ní ọ̀rúndún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ṣáájú àkókò rẹ̀. Àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá ti gbòmìnira kúrò lóko ẹrú ní Íjíbítì. Wọ́n ti wà ní ẹsẹ̀ Òkè Sínáì báyìí, Jèhófà sì pàṣẹ fún wọn láti kọ́ àgọ́ ìjọsìn fún jíjọ́sìn, kí wọ́n sì kó àwọn ohun èlò ìjọsìn kún inú rẹ̀. Èyí yóò gba ọ̀pọ̀ dúkìá, a sì ké sí orílẹ̀-èdè náà láti mú ọrẹ wá.

Kí ni ohun tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ̀nyẹn wá ṣe? “Wọ́n wá, olúkúlùkù ẹni tí ọkàn-àyà rẹ̀ sún un ṣiṣẹ́, àti olúkúlùkù ẹni tí ẹ̀mí rẹ̀ ru ú sókè, wọ́n mú ọrẹ Jèhófà wá fún iṣẹ́ àgọ́ ìpàdé.” (Ẹ́kísódù 35:21) Ǹjẹ́ orílẹ̀-èdè náà fi ìwà ọ̀làwọ́ ṣe ìtọrẹ? Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tó kàmàmà! Ìròyìn tó tẹ̀ lé e yìí ni wọ́n mú wá fún Mósè: “Àwọn ènìyàn ń mú púpọ̀púpọ̀ wá ju ohun tí iṣẹ́ ìsìn náà béèrè láti ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà pa láṣẹ pé kí a ṣe.”—Ẹ́kísódù 36:5.

Kí ni ipò nǹkan ti rí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà yẹn lọ́hùn-ún? Kò tíì pẹ́ sí àkókò yẹn, tí wọ́n fi jẹ́ ẹrú lásánlàsàn, ‘tí ń ru ẹrù ìnira,’ tí wọ́n sì ń gbé ‘ìgbésí ayé kíkorò,’ ìyẹn ìgbésí ayé ‘ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́.’ (Ẹ́kísódù 1:11, 14; 3:7; 5:10-18) Nítorí náà, kò dájú pé wọ́n á fi bẹ́ẹ̀ rí jájẹ lọ títí. Lóòótọ́ làwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran kúrò ní ilẹ̀ tí wọ́n tí sìnrú. (Ẹ́kísódù 12:32) Àmọ́, ìyẹn ò lè fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ rẹpẹtẹ, nítorí pé kété tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣàròyé pé kò sí ẹran tàbí oúnjẹ fáwọn láti jẹ.—Ẹ́kísódù 16:3.

Ibo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti wá rí àwọn ohun iyebíye tí wọ́n fi tọrẹ fún kíkọ́ àgọ́ ìjọsìn náà? Àtọ̀dọ̀ àwọn ọ̀gá wọn tẹ́lẹ̀ ni, ìyẹn àwọn ará Íjíbítì. Bíbélì sọ pé: “Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì . . . bẹ̀rẹ̀ sí béèrè àwọn ohun èlò fàdákà àti àwọn ohun èlò wúrà àti àwọn aṣọ àlàbora lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì. . . . [Àwọn ará Íjíbítì] yọ̀ǹda ohun tí wọ́n béèrè.” Ìwà ọ̀làwọ́ táwọn ará Íjíbítì hù yìí jẹ́ ìbùkún látọ̀dọ̀ Jèhófà, kì í ṣe látọ̀dọ̀ Fáráò. Àkọsílẹ̀ àtọ̀runwá náà sọ pé: “Jèhófà sì fi ojú rere fún àwọn ènìyàn náà ní ojú àwọn ará Íjíbítì, tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn wọ̀nyí fi yọ̀ǹda ohun tí wọ́n béèrè.”—Ẹ́kísódù 12:35, 36.

Wáá fojú inú wo bó ṣe máa rí lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ìran kan tó ti jìyà gan-an níbi tí wọ́n ti ń sìnrú lọ́nà kíkorò, tí wọ́n sì fi nǹkan dù wọ́n. Wọ́n ti wá dòmìnira báyìí, wọ́n sì tún ní àwọn nǹkan ti ara lọ́pọ̀ yanturu. Báwo ni kíkó lára àwọn nǹkan ìní wọ̀nyẹn sílẹ̀ ṣe máa wá rí lára wọn? Wọ́n ti lè ronú pé ó ti di tàwọn ná, ó sì di dandan fáwọn láti fi gbọ́ tara àwọn. Àmọ́, nígbà táa pè wọ́n láti wá fowó ṣètọrẹ kí wọ́n lè kọ́wọ́ ti ìjọsìn tòótọ́ lẹ́yìn, wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀—wọn ò lọ́ tìkọ̀, wọn ò sì fi ìwà ahun ṣe é! Wọn ò gbàgbé pé Jèhófà ló mú kó ṣeé ṣe fún àwọn láti ní àwọn nǹkan ìní wọ̀nyẹn. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n fi ọ̀pọ̀ yanturu fàdákà àti wúrà àti ohun ọ̀sìn wọn tọrẹ. Wọ́n jẹ́ “ọlọ́kàn ìmúratán.” ‘Ọkàn-àyà’ wọn ‘sún wọn ṣiṣẹ́.’ ‘Ẹ̀mí wọn ru wọ́n sókè.’ Ní ti tòótọ́, “ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe . . . fún Jèhófà” ni.—Ẹ́kísódù 25:1-9; 35:4-9, 20-29; 36:3-7.

Mímúratán Láti Fúnni

Kì í ṣe bí ohun táa fi tọrẹ ṣe pọ̀ tó la fi ń mọ bí ẹni tó ń fúnni ní nǹkan ṣe níwà ọ̀làwọ́ tó. Ìgbà kan wà tí Jésù Kristi ń wo àwọn èèyàn tó ń fowó sínú àwọn àpótí ìṣúra inú tẹ́ńpìlì. Àwọn tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ ń kó ọ̀pọ̀ owó ẹyọ síbẹ̀, àmọ́ ó wú Jésù lórí nígbà tó rí obìnrin opó tálákà kan tó sọ ẹyọ owó kéékèèké méjì tí ìníyelórí wọn kéré gan-an síbẹ̀. Ó ní: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé opó yìí jẹ́ òtòṣì, ó sọ sínú rẹ̀ ju gbogbo wọn lọ. . . . Láti inú àìní rẹ̀, ó sọ gbogbo àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé tí ó ní sínú rẹ̀.”—Lúùkù 21:1-4; Máàkù 12:41-44.

Ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará Kọ́ríńtì bá èrò Jésù yìí mu wẹ́kú. Nígbà tó kan ọ̀rọ̀ nípa ṣíṣe ìtọrẹ láti ran àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn tí kò rí jájẹ lọ́wọ́, Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Bí ìmúratán bá kọ́kọ́ wà, ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà ní pàtàkì ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ènìyàn ní, kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ènìyàn kò ní.” (2 Kọ́ríńtì 8:12) Bẹ́ẹ̀ ni o, ṣíṣe ìtọrẹ kì í ṣe ọ̀ràn ìbánidíje tàbí ti ìfagagbága. Bí agbára ẹnì kan bá ṣe tó ló ṣe máa fi nǹkan tọrẹ, inú Jèhófà sì dùn sí irú ẹ̀mí ọ̀làwọ́ bẹ́ẹ̀.

Àmọ́ o, kò sẹ́ni tó lè sọ pé òun fẹ́ sọ Jèhófà di ọlọ́rọ̀, ẹni tó jẹ́ pé òun ló ni ohun gbogbo, ńṣe ni ṣíṣe ìtọrẹ wulẹ̀ jẹ́ ọ̀nà kan tó fún àwọn olùjọsìn láǹfààní láti fi ìfẹ́ tí wọ́n ní sí i hàn. (1 Kíróníkà 29:14-17) Ọrẹ táa fúnni, tí kì í ṣe lọ́nà ṣekárími tàbí fún ìdí kan tó jẹ́ ti ìmọtara-ẹni-nìkan, ṣùgbọ́n tó jẹ́ èyí táa fi ẹ̀mí tó dára ṣe ká lè gbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ, máa ń mú ayọ̀ àti ìbùkún Ọlọ́run wá. (Mátíù 6:1-4) Jésù sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) A lè nípìn-ín nínú ayọ̀ yẹn nípa lílo okun wa nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, àti nípa yíya ohun kan sọ́tọ̀ láti inú dúkìá wa ká lè fi ṣètìlẹ́yìn fún ìjọsìn tòótọ́ àti láti ṣèrànwọ́ fáwọn tó tọ́ sí.—1 Kọ́ríńtì 16:1, 2.

Mímúratán Láti Fúnni Lóde Òní

Lónìí, inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń dùn láti rí bí wíwàásù “ìhìn rere ìjọba yìí” ṣe ń tẹ̀ síwájú jákèjádò ayé. (Mátíù 24:14) Nínú ẹ̀wádún tó kẹ́yìn nínú ọ̀rúndún ogún, ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́ta ènìyàn tó fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wọn sí Jèhófà Ọlọ́run hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi, a sì dá nǹkan bí ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ìjọ tuntun sílẹ̀. Dájúdájú, ìdá mẹ́ta ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lónìí la dá sílẹ̀ láàárín ọdún mẹ́wàá tó kọjá! Ọ̀pọ̀ jù lọ ìbísí yìí ló jẹ́ àbájáde iṣẹ́ àṣekára táwọn ọkùnrin àtobìnrin tí wọ́n jẹ́ Kristẹni olóòótọ́ ṣe, ìyẹn àwọn tí wọ́n ń lo àkókò àti agbára wọn láti bẹ àwọn aládùúgbò wọn wò, àti láti sọ fún wọn nípa ète Jèhófà. Díẹ̀ lára ìbísí yẹn jẹ́ àbájáde iṣẹ́ àwọn míṣọ́nnárì, àwọn tí wọ́n fi ilé wọn sílẹ̀, tí wọ́n sì rin ìrìn àjò lọ sí ilẹ̀ jíjìn láti lọ ṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ wíwàásù Ìjọba náà. Ìbísí náà ti jẹ́ ká ní àwọn àyíká tuntun, tó mú kó pọndandan láti yan àwọn alábòójútó àyíká tuntun. Láfikún sí i, a nílò àwọn Bíbélì tó pọ̀ jù ti tẹ́lẹ̀ fún ṣíṣe iṣẹ́ ìwàásù àti ìdákẹ́kọ̀ọ́. Bẹ́ẹ̀ náà la tún nílò àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ táa ń tẹ̀ jáde ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè la sì ti mú àwọn ilé ẹ̀ka gbòòrò sí i tàbí ká kó wọn lọ síbi tó tóbi ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Gbogbo àìní wọ̀nyí la ń bójú tó nípasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe látọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn Jèhófà.

A Nílò Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba

Ohun tó hàn kedere pé a nílò báyìí ni àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, nítorí iye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń pọ̀ sí i. Ìwádìí kan táa ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2000 fí hàn pé a nílò ohun tó lé ni ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá Gbọ̀ngàn Ìjọba láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, níbi tí wọn ò ti fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́. Gbé Àǹgólà yẹ̀ wò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ogun abẹ́lé ń jà níbẹ̀, ìpíndọ́gba iye ìbísí tí orílẹ̀-èdè yẹn ń ní lọ́dọọdún jẹ́ ìpín mẹ́wàá nínú iye akéde Ìjọba náà tó wà níbẹ̀. Àmọ́, ọ̀pọ̀ jù lọ lára ìjọ ẹgbẹ̀ta ó lé márùndínlọ́gọ́rin [675] tó wà ní orílẹ̀-èdè ńlá tó wà ní Áfíríkà yìí ló ń ṣe ìpàdé wọn ní gbangba. Gbọ̀ngàn Ìjọba méjìlélógún péré ló wà lórílẹ̀-èdè náà, méjìlá péré lára wọn ló sì ní nǹkan táa lè pè ní òrùlé lórí.

Bákan náà ni ipò nǹkan ṣe rí ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Kóńgò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọ ọ̀ọ́dúnrún [300] ló wà ní Kinshasha tó jẹ́ olú ìlú wọn, síbẹ̀ wọn ò ní ju Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́wàá lọ. Orílẹ̀-èdè yìí nílò ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] Gbọ̀ngàn Ìjọba lápapọ̀. Nítorí yíya tí àwọn èèyàn ń ya wọnú ètò ní àwọn orílẹ̀-èdè Ìlà Oòrùn Yúróòpù, Rọ́ṣíà àti Ukraine ròyìn pé lápapọ̀, àwọn nílò ọgọ́rọ̀ọ̀rún Gbọ̀ngàn Ìjọba. Yíya tí àwọn èèyàn ń ya wọnú ètò ní Látìn Amẹ́ríkà la rí kedere ní Brazil, níbi tí àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ ti lé ní ìdajì mílíọ̀nù, tí wọ́n sì nílò Gbọ̀ngàn Ìjọba púpọ̀ sí i.

Láti kúnjú àwọn ohun tí à ń fẹ́ ní irú àwọn orílẹ̀-èdè bẹ́ẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan tí a mú yá kánkán fún kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ọrẹ táwọn arákùnrin jákèjádò ayé fìwà ọ̀làwọ́ dá la ń ná lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí, kí àwọn ìjọ tó tálákà jù lọ pàápàá lè ní ibi tó bójú mu fún ìjọsìn.

Gẹ́gẹ́ bó ṣe rí ní àkókò ti Ísírẹ́lì ìgbàanì, ọ̀pọ̀ nǹkan la lè ṣe láṣeparí nítorí pé àwọn Kristẹni tòótọ́ ‘fi àwọn ohun ìní wọn tí ó níye lórí bọlá fún Jèhófà.’ (Òwe 3:9, 10) Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò fẹ́ láti lo àǹfààní yìí láti dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni tí ọkàn-àyà rẹ̀ sún láti nípìn-ín nínú fífínnúfíndọ̀ ṣe ìtọrẹ yìí. A sì lè ní ìdánilójú pé ẹ̀mí Jèhófà yóò máa bá a lọ láti ru ọkàn-àyà àwọn ènìyàn rẹ̀ sókè kí wọ́n lè máa ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ Ìjọba náà tó ń gbòòrò sí i.

Bí ìgbòòrò jákèjádò ayé náà ti ń tẹ̀ síwájú, ǹjẹ́ kí a máa bá a lọ ní wíwá àwọn àǹfààní àtimáa fi ìtúraká àti ìmúratán wa hàn nínú lílo okun wa, àkókò wa, àti dúkìá wa. Ǹjẹ́ kí a sì gbádùn ayọ̀ tòótọ́ tí irú ẹ̀mí fífúnni bẹ́ẹ̀ ń mú wá.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 29]

“Ẹ FI ỌGBỌ́N NÁ AN!”

“Ọmọ ọdún mẹ́wàá ni mi. Mo ń fi owó yìí ránṣẹ́ kí ẹ lè fi ra bébà tàbí àwọn nǹkan mìíràn tí ẹ óò fi ṣe àwọn ìwé.”— Cindy.

“Mo fẹ́ fi owó yìí ránṣẹ́ sí yín, kí ẹ lè bá wa ṣe ìwé púpọ̀ sí i. Ńṣe ni mo tọ́jú owó yìí tí mo rí gbà nígbà tí mo bá dádì mi ṣiṣẹ́. Nítorí náà, ẹ fi ọgbọ́n ná an!”—Pam, ọmọ ọdún méje.

“Ìjì líle náà bà mí nínú jẹ́ gan-an. Mo lérò pé ẹ ò fara pa. Gbogbo owó [ìyẹn dọ́là méjì] tí mo ní nínú àpótí tí mo ń fi owó pa mọ́ sí nìyí.”—Allison, ọmọ ọdún mẹ́rin.

“Rudy lorúkọ mi, ọmọ ọdún mọ́kànlá sì ni mi. Ọmọ ọdún mẹ́fà ni Ralph, àbúrò mi ọkùnrin. Judith, àbúrò mi obìnrin sì jẹ́ ọmọ ọdún méjì ààbọ̀. A ti ń fi lára owó tí wọ́n ń fún wa pa mọ́ fún oṣù mẹ́ta, ká lè fi ṣèrànwọ́ fún àwọn arákùnrin wa tí wọ́n wà ní [àgbègbè ti ogun ti sọ di ẹdun arinlẹ̀]. Iye tí a rí kó jọ ni ogún dọ́là tí a ń fi ránṣẹ́ yìí.”

“Àánú àwọn arákùnrin [tí ìjì líle pa lára] ṣé mi gan-an ni. Mo rí dọ́là mẹ́tàdínlógún nígbà tí mo bá dádì mi ṣiṣẹ́. Mi o fi owó yìí ránṣẹ́ fún ohun kan pàtó, nítorí náà, màá jẹ́ kẹ́ẹ pinnu ohun tẹ́ẹ máa lò ó fún.”—Maclean, ọmọ ọdún mẹ́jọ.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 31]

Àwọn Ọ̀nà Tí Àwọn Kan Yàn Láti Ṣètọrẹ

ỌRẸ FÚN IṢẸ́ YÍKÁ AYÉ

Ọ̀pọ̀ ya iye kan sọ́tọ̀, tàbí kí wọ́n ṣètò iye owó kan tí wọ́n ń fi sínú àwọn àpótí ọrẹ ti a kọ “Contributions for the Society’s Worldwide Work [Ọrẹ fún Iṣẹ́ Society Yíká Ayé]—Mátíù 24:14, sí lára.” Oṣooṣù làwọn ìjọ máa ń fi owó wọ̀nyí ránṣẹ́ sí orílé-iṣẹ́ ní Brooklyn, New York, tàbí ẹ̀ka ọ́fíìsì ti àgbègbè wọn.

O tún lè fi ìtọrẹ owó tí o fínnúfíndọ̀ ṣe ránṣẹ́ ní tààràtà sí Treasurer’s Office, Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania, 25 Columbia Heights, Brooklyn, New York 11201-2483, tàbí sí ọ́fíìsì Society tí ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ. O tún lè fi ohun ọ̀ṣọ́ ṣíṣeyebíye tàbí ohun àlùmọ́ọ́nì mìíràn ṣe ìtọrẹ. Lẹ́tà ṣókí kan tí ń fi hàn pé irú ohun bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹ̀bùn ní láti bá àwọn ọrẹ wọ̀nyí rìn.

ÌṢÈTÒ ỌRẸ TÓ NÍ IPÒ ÀFILÉLẸ̀

A lè fún Watch Tower Society ní owó lábẹ́ ìṣètò àkànṣe kan nínú èyí tí a óò dá owó náà padà fún olùtọrẹ náà, nígbà tó bá ti nílò rẹ̀. Fún àfikún àlàyé, jọ̀wọ́ kàn sí Treasurer’s Office ní àdírẹ́sì tí a kọ sókè yìí.

ÌWÉWÈÉ ONÍNÚURE

Ní àfikún sí ẹ̀bùn owó ní tààràtà àti ọrẹ tó ní ipò àfilélẹ̀, àwọn ọ̀nà mìíràn wà tí a lè gbà ṣètọrẹ fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn Ìjọba kárí ayé. Lára wọn ni:

Owó Ìbánigbófò: A lè kọ orúkọ Watch Tower Society gẹ́gẹ́ bí olùjàǹfààní ètò ìbánigbófò ẹ̀mí tàbí ìwéwèé owó ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́.

Àkáǹtì Owó ní Báńkì: A lè fi àkáǹtì owó ní báńkì, ìwé ẹ̀rí owó ìdókòwò, tàbí àkáǹtì owó ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ ẹnì kan sí ìkáwọ́ Watch Tower Society, tàbí kí a mú kí ó ṣeé san fún Society bí ẹni tó ni ín bá kú, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun tí báńkì àdúgbò bá béèrè.

Ìwé Ẹ̀tọ́ Lórí Owó Ìdókòwò àti Ẹ̀yáwó: A lè fí ìwé ẹ̀tọ́ lórí owó ìdókòwò àti ẹ̀yáwó ta Watch Tower Society lọ́rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn.

Dúkìá Ilé Tàbí Ilẹ̀: A lè fi dúkìá ilé tàbí ilẹ̀ tó ṣeé tà tọrẹ fún Watch Tower Society, yálà nípa fífi ṣe ẹ̀bùn, tàbí nípa pípa á mọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun ìní tí olùtọrẹ náà ṣì lè máa lò nígbà ayé rẹ̀. Onítọ̀hún ní láti kàn sí Society ṣáájú fífi ìwé àṣẹ sọ dúkìá ilé tàbí ilẹ̀ èyíkéyìí di ti Society.

Ìwé Ìhágún àti Ohun Ìní Àfisíkàáwọ́-Ẹni: A lè fi dúkìá tàbí owó sílẹ̀ bí ogún fún Watch Tower Society nípasẹ̀ ìwé ìhágún tí a ṣe lábẹ́ òfin, tàbí kí a kọ orúkọ Society gẹ́gẹ́ bí olùjàǹfààní ìwé àdéhùn fífi nǹkan sí ìkáwọ́ ẹni. Àwọn ohun ìní ìfisíkàáwọ́-ẹni tí ètò ìsìn kan ń jàǹfààní nínú rẹ̀ lè pèsè àwọn àǹfààní mélòó kan nínú ọ̀ràn owó orí.

Gẹ́gẹ́ bí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà, “ìwéwèé onínúure,” irú àwọn ọrẹ báwọ̀nyí ń béèrè fún àwọn ìwéwèé díẹ̀ lọ́dọ̀ ẹni tí ó ń ṣètọrẹ. Láti ṣèrànwọ́ fún àwọn èèyàn tí ń fẹ́ láti ṣe Society láǹfààní nípa irú ọ̀nà ìfúnni tí a wéwèé kan, Society ti ṣe ìwé pẹlẹbẹ kan lédè Gẹ̀ẹ́sì àti Spanish, tí a pé àkọlé rẹ̀ ní Charitable Planning to Benefit Kingdom Service Worldwide. A kọ ìwé pẹlẹbẹ náà láti dáhùn ọ̀pọ̀ ìbéèrè tí Society ti rí gbà nípa ẹ̀bùn, ìwé ìhágún, àti ohun ìní àfisíkàáwọ́-ẹni. Ó tún ní àfikún ìsọfúnni tó wúlò fún ìwéwèé ilé tàbí ilẹ̀, okòwò àti owó orí nínú. A sì pète rẹ̀ láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tó wà ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, tí ń wéwèé láti fún Society ní ẹ̀bùn àkànṣe nísinsìnyí, tàbí tí ń fẹ́ fi ẹ̀bùn sílẹ̀ nígbà tí wọ́n bá kú, kí wọ́n lè yan ọ̀nà tí ó ṣàǹfààní jù, tí ó sì gbéṣẹ́ jù láti ṣe é, ní gbígbé àyíká ipò ìdílé àti ti ara wọn yẹ̀ wò. A lè rí ìwé yìí gbà nípa bíbéèrè fún ẹ̀dà kan ní tààràtà láti ẹ̀ka Charitable Planning Office.

Lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ ti ka ìwé pẹlẹbẹ náà, tí wọ́n sì ti fọ̀rọ̀ wérọ̀ pẹ̀lú ẹ̀ka Charitable Planning Office, ó ti ṣeé ṣe fún wọn láti ṣètìlẹ́yìn fún Society, kí wọ́n sì tún mú kí àǹfààní owó orí pọ̀ sí i, fún ṣíṣe tí wọ́n ṣe é. A gbọ́dọ̀ fi èyíkéyìí lára ìṣètò wọ̀nyí tó àwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ka Charitable Planning Office létí, kí a sì fún wọn ní ẹ̀dà àkọsílẹ̀ èyíkéyìí tó bá tan mọ́ ọn. Tí o bá nífẹ̀ẹ́ sí èyíkéyìí nínú àwọn ìṣètò ìwéwèé onínúure wọ̀nyí, kàn sí ẹ̀ka Charitable Planning Office, yálà nípa kíkọ̀wé sí àdírẹ́sì tí a tò sísàlẹ̀ yìí tàbí kí o pè wọ́n lórí ẹ̀rọ tẹlifóònù, tàbí kí wọ́n kàn sí ọ́fíìsì Society tí ń bójú tó orílẹ̀-èdè wọn.

CHARITABLE PLANNING OFFICE

Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania

100 Watchtower Drive, Patterson, New York 12563-9204

Telephone: (845) 306-0707