Bíbélì—Ìwé Atọ́nà fún Gbígbé Ìgbésí Ayé
Bíbélì—Ìwé Atọ́nà fún Gbígbé Ìgbésí Ayé
“Ọ̀RỌ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára, ó mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ . . . ó sì lè fi òye mọ ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.” (Hébérù 4:12) Báa ṣe ṣàpèjúwe ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ṣe yìí fi hàn dájú pé Bíbélì kì í kàn ṣe ìwé kan tó dára nìkan, ó tún jù bẹ́ẹ̀ lọ.
Ẹnì kan tó jẹ́ òǹkọ̀wé nípa ìsìn sọ̀rọ̀ náà láìfi bọpobọyọ̀ pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ṣe pàtàkì fún ìgbésí ayé wa bí èémí táa ń mí ṣe ṣe pàtàkì.” Ó wá fi kún un pé: “Nígbà tóo bá gbé ọ̀ràn nípa báa ṣe ń fẹ́ ìwòsàn àti báa ṣe nílò rẹ̀ tó lóde òní yẹ̀ wò, tóo wá ka Bíbélì pẹ̀lú èrò yẹn lọ́kàn, àbájáde rẹ̀ á ṣe ọ́ ní kàyéfì.” Gẹ́gẹ́ bí àtùpà tó mọ́lẹ̀ kedere ni Bíbélì ṣe ń tan ìmọ́lẹ̀ sórí ọ̀pọ̀ ìbéèrè dídíjú àti àwọn ìṣòro tó wà nínú ìgbésí ayé òde òní.—Sáàmù 119:105.
Àní sẹ́, ọgbọ́n tí Bíbélì ń fi kọ́ni ní agbára láti yí ìrònú wa padà, ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti yanjú àwọn ìṣòro wa, ó ń mú kí ìgbésí ayé wa sunwọ̀n sí i, ó sì ń fún wa ní agbára láti kojú àwọn ipò tí a kò lè yí padà. Lékè gbogbo rẹ̀, Bíbélì mú kó ṣeé ṣe fún wa láti mọ Ọlọ́run kí a sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.
Ìwé Tó Ń Fúnni Ní Ète
Jèhófà Ọlọ́run, Ẹni tó ni Bíbélì, ‘mọ gbogbo ọ̀nà wa lámọ̀dunjú.’ Ó mọ àwọn àìní wa nípa ti ara, nípa ti èrò inú, àti nípa tẹ̀mí ju bí àwa fúnra wa ti mọ̀ ọ́n lọ. (Sáàmù 139:1-3) Ó fi àròjinlẹ̀ fún wa ní ààlà tó ṣe kedere lórí ìhùwàsí ẹ̀dá ènìyàn. (Míkà 6:8) Ó bọ́gbọ́n mu láti wá bí a ó ṣe lóye àwọn ààlà wọ̀nyẹn àtàwọn ìdarí rẹ̀, kí a sì kọ́ bí a ó ṣe máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú wọn. Onísáàmù náà sọ pé, aláyọ̀ ni ènìyàn náà tí “inú dídùn rẹ̀ wà nínú òfin Jèhófà. Gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe ni yóò sì máa kẹ́sẹ járí.” (Sáàmù 1:1-3) Dájúdájú, ó yẹ ká ṣàyẹ̀wò irú ìfojúsọ́nà bẹ́ẹ̀.
Maurice, tó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ olùkọ́, máa ń fìgbà gbogbo gbà pé Bíbélì níye lórí tó bá kan ọ̀ràn nípa ìtàn àti bí a ṣe kọ ọ́. Ṣùgbọ́n ó ń ṣe iyèméjì nípa pé bóyá ó ní ìmísí Ọlọ́run. Lẹ́yìn tí Maurice fetí sí àlàyé kan nípa ìdí tí Ọlọ́run fi fún ènìyàn ní Ọ̀rọ̀ rẹ̀ táa kọ sílẹ̀, ó wá ṣàyẹ̀wò àwọn àsọtẹ́lẹ̀ bíi mélòó kan nínú Bíbélì. Nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, ó ti kẹ́kọ̀ọ́ ìtàn ayé ìgbàanì, ìtàn àròsọ, ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìmọ̀ nípa ilẹ̀ ayé àti ìwàláàyè inú rẹ̀. Òun fúnra rẹ̀ jẹ́wọ́ pé ọgbọ́n àgbọ́njù tí òun gbọ́n lójú
ara òun ni kò jẹ́ kí òun rí àìmọye àwọn àpẹẹrẹ tó ti ìjótìítọ́ Bíbélì lẹ́yìn. “Ọrọ̀ àti fàájì ìgbésí ayé tí mò ń lépa ló gba gbogbo àkókò mi. Ó ṣeni láàánú pé n kò lóye, mo sì jẹ́ aláìmọ̀kan nípa adùn àti òtítọ́ tó wà nínú ìwé títóbi lọ́lá jù lọ tí a tíì kọ rí náà.”Nísinsìnyí tí Maurice ti pé ẹni àádọ́rin ọdún, ó ń tọ́ka sí àkọsílẹ̀ nípa bí Jésù ṣe fara han àpọ́sítélì Tọ́másì, ó sì ń sọ lọ́nà tó fi ìmọrírì hàn pé: “A ti mú ọwọ́ mi lọ síbi ‘ọgbẹ́ tó ń ṣẹ̀jẹ̀’ náà, èyí tí yóò lé gbogbo iyèméjì tí mo ń ṣe lórí bí Bíbélì ṣe jẹ́ òtítọ́ dànù.” (Jòhánù 20:24-29) Gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe sọ ọ́, Bíbélì ń tú àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà fó, ó sì ń jẹ́ kí ìgbésí ayé ẹni ní ìtumọ̀. Ìwé tó wà fún gbígbé ìgbésí ayé rere ni lóòótọ́.
Ó Ń Yanjú Ìṣòro fún Àwọn Tí Ìdààmú Bá
Bíbélì tún fúnni ní ìmọ̀ràn tó ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú ìwà burúkú. Ó ṣeé ṣe fún Daniel láti jáwọ́ nínú sìgá mímu tó jẹ́ ìwà àìmọ́, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣíwọ́ lílọ sí àwọn àríyá aláriwo àti mímu ọtí àmupara. (Róòmù 13:13; 2 Kọ́ríńtì 7:1; Gálátíà 5:19-21) Ká sọ tòótọ́, ó gba ìsapá gidi láti kó irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ dànù ká sì gbé “àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀.” (Éfésù 4:22-24) Daniel sọ pé “Ìpèníjà gbáà ni, nítorí pé aláìpé gidi ni wá.” Síbẹ̀síbẹ̀, ó ṣe àṣeyọrí. Ojoojúmọ́ ni Daniel wá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run báyìí, ìyẹn sì ń jẹ́ kí ó sún mọ́ Jèhófà dáadáa.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Daniel kò ka Bíbélì rí, ó ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún un, ó sì máa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run lálaalẹ́. Síbẹ̀, o ku nǹkan kan fún un. Kò láyọ̀ rárá. Nǹkan yí padà fún un nígbà tó rí orúkọ Ọlọ́run nínú Bíbélì fún ìgbà àkọ́kọ́. (Ẹ́kísódù 6:3; Sáàmù 83:18) Lẹ́yìn ìyẹn, ó wá ń lo orúkọ náà Jèhófà nígbà tó bá ń gbàdúrà, àdúrà rẹ̀ sì ti di èyí tó túbọ̀ nítumọ̀ gan-an. “Jèhófà wá di ẹni tó sún mọ́ mi jù lọ, òun ṣì ni ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ jù lọ di báa ti ń sọ̀rọ̀ yìí.”
Kó tó di pé Daniel bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, èrò rẹ̀ nípa ọjọ́ iwájú kò ṣíni lórí rárá. Ó sọ pé: “Kò dìgbà tí orí èèyàn bá pé bí nǹkan míì kó tó mọ ohun tó ń lọ nínú ayé. Ẹ̀rù bà mí gan-an, mo sì gbìyànjú láti jẹ́ kí ọwọ́ mi di kí n lè mú un kúrò lọ́kàn mi.” Ẹ̀yìn ìyẹn ló wá kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run yóò fìdí ìdájọ́ òdodo múlẹ̀ fún gbogbo èèyàn lórí ilẹ̀ ayé kan tí a fọ̀ mọ́ tónítóní, níbi tí àwọn èèyàn onígbọràn ti lè gbádùn àlàáfíà àti ayọ̀ ayérayé. (Sáàmù 37:10, 11; Dáníẹ́lì 2:44; Ìṣípayá 21:3, 4) Nísinsìnyí, Daniel ni ìrètí tó dájú. Ipa tí ń fọkàn ẹni balẹ̀ tí Bíbélì ní lórí rẹ̀ ti jẹ́ kó ní èrò tó tọ̀nà nípa ìgbésí ayé.
Ìrànlọ́wọ́ Láti Ṣẹ́pá Àwọn Ìdààmú Ọkàn
Ọmọ ọdún méje péré ni George nígbà tí ìyá rẹ̀ kú. Ẹ̀rù àtisùn lóru máa ń bà á nítorí ó rò pé bóyá òun kò ní jí lọ́jọ́ kejì. Lẹ́yìn náà, ó wá ka ohun ti Jésù sọ nípa ikú àti àjíǹde pé: “Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn [Jésù], wọn yóò sì jáde wá.” Orí rẹ̀ tún wú nígbà tó ka ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Èmi ni àjíǹde àti ìyè. Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè.” (Jòhánù 5:28, 29; 11:25) Irú èrò bẹ́ẹ̀ dún bí èyí tó bọ́gbọ́n mu tó sì ń tuni nínú. George sọ pé: “Kì í ṣe pé òtítọ́ wulẹ̀ ń fani lọ́kàn mọ́ra nìkan ni, àmọ́ ó tún ń wọni lọ́kàn pẹ̀lú.”
Daniel táa mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀ náà tún ní àwọn nǹkan tó ń bà á nínú jẹ́. Ìyá rẹ̀ kò lè dá nìkan gbọ́ bùkátà rẹ̀, nípa bẹ́ẹ̀ ó wá bẹ̀rẹ̀ sí gbé lọ́dọ̀ àwọn èèyàn káàkiri. Gbogbo ìgbà ló máa ń dà bí àlejò, ó sì ń wù ú láti wà nínú ìdílé kan tó nífẹ̀ẹ́, tó sì lè fọkàn rẹ̀ balẹ̀. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ó rí ohun tó ń wá nípasẹ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ń kọ́. Daniel wá ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ Kristẹni ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì di ara ìdílé tẹ̀mí kan, níbi tó
ti wá mọ̀ pé a tẹ́wọ́ gba òun àti pé àwọn ẹlòmíràn nífẹ̀ẹ́ òun. Ní ti tòótọ́, Bíbélì ṣàǹfààní láwọn ọ̀nà kan tó wúlò tó sì ń tu ọkàn lára.Rántí pé Jèhófà rí ohun tó wà ní ọkàn-àyà wa, ó sì mọ ohun táa ń fẹ́. Ọlọ́run “ń díwọ̀n àwọn ọkàn-àyà,” ó sì ń fún “olúkúlùkù ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà rẹ̀.”—Òwe 21:2; Jeremáyà 17:10.
Ìmọ̀ràn Tó Wúlò fún Ìgbésí Ayé Ìdílé
Bíbélì fúnni ní ìmọ̀ràn tó wúlò lórí ọ̀ràn nípa àjọṣepọ̀ ẹ̀dá. George sọ pé: “Ṣíṣe gbúngbùngbún síra ẹni àti èdè àìyedè wà lára àwọn ipò tí kì í jẹ́ kí nǹkan fara rọ nínú ìgbésí ayé.” Báwo ló ṣe kojú wọn? “Bí mo bá rí i pé inú ẹnì kan kò dùn sí mi, ìmọ̀ràn tààrà tó wà nínú Mátíù 5:23, 24, tó sọ pé: ‘Wá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin rẹ,’ ni mo máa ń lò. Pé mo tiẹ̀ lè sọ̀rọ̀ nípa èdè àìyedè náà máa ń mú èso rere jáde. Mo nímọ̀lára pé mo ní àlàáfíà Ọlọ́run tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ó ń ṣiṣẹ́. Ó sì wúlò gan-an ni.”—Fílípì 4:6, 7.
Nígbà tí gbọ́nmisi-omi-ò-to bá wà láàárín tọkọtaya, àwọn méjèèjì ní láti “yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú.” (Jákọ́bù 1:19) Irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ máa ń mú kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ sunwọ̀n sí i. George fi kún un pé: “Nígbà tí mo tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó sọ pé kí n nífẹ̀ẹ́ ìyàwó mi, kí n sì máa ṣe sí i bí mo ṣe ń ṣe sí ara mi, kíá ni mo rí àbájáde rẹ̀. Ó wá túbọ̀ rọrùn fún un láti bọ̀wọ̀ fún mi.” (Éfésù 5:28-33) Bẹ́ẹ̀ ni o, Bíbélì kọ́ wa bí a ṣe lè mọ àìpé tiwa fúnra wa kí a sì kápá rẹ̀ àti bí a ṣe lè ṣàṣeyọrí ní fífarada àìpé ti àwọn ẹlòmíràn.
Ìmọ̀ràn Tó Wà Pẹ́ Títí
Sólómọ́nì ọlọgbọ́n Ọba sọ pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” (Òwe 3:5, 6) Ẹ ò ri pé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn kò lọ́jú pọ̀ rárá, ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ sì ni wọ́n!
Bíbélì ń nípa tó dára lórí ẹni. Ó jẹ́ kí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run mú ìgbésí ayé wọn bá ìfẹ́ rẹ̀ mu, kí wọ́n sì rí ayọ̀ nínú ‘rírìn nínú òfin Jèhófà.’ (Sáàmù 119:1) Ipòkípò ti a lè wà, ìtọ́ni àti ìmọ̀ràn táa nílò wà nínú Bíbélì. (Aísáyà 48:17, 18) Máa kà á lójoojúmọ́, ṣe àṣàrò lórí ohun tí o kà, kí o sì fi í sílò. Yóò jẹ́ kí èrò inú rẹ̀ ṣe kedere, kí ó sì máa dá lórí ohun tó mọ́ tó sì gbámúṣé. (Fílípì 4:8, 9) Kì í ṣe kìkì bí a ṣe ń gbé ìgbésí ayé tí a sì ń gbádùn rẹ̀ nìkan lo máa kọ́, wàá tún kọ́ bí a ṣe ń nífẹ̀ẹ́ Ẹlẹ́dàá tó fún wa ní ìwàláàyè pẹ̀lú.
Nípa títẹ̀lé irú ipa ọ̀nà yìí, bí Bíbélì ṣe rí lójú àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn—ló ṣe máa rí lójú tìẹ náà—pé kì í ṣe pé ó kàn jẹ́ ìwé kan tó dára. Yóò hàn kedere pé ó jẹ́ ìwé atọ́nà fún gbígbé ìgbésí ayé ní tòótọ́!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Bíbélì lè fún ìpinnu rẹ lókun láti ṣẹ́pá àwọn ìwà tí ń pani lára
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Bíbélì ń kọ́ ẹ bóo ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run dáadáa