Jèhófà Pèsè Ibi Ìsinmi Fáwọn Èèyàn Rẹ̀
Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
Jèhófà Pèsè Ibi Ìsinmi Fáwọn Èèyàn Rẹ̀
RÍRÍ ibòòji kan lórí òkè ńlá, níbi tó ṣe é yà sí láti sinmi máa ń múnú arìnrìn àjò kan tó ti rẹ̀ dùn. Ní Nepal, chautara lorúkọ tí wọ́n máa ń pe irú àwọn ibi ìsinmi bẹ́ẹ̀. Irú chautara kan bẹ́ẹ̀ lè rọra wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ igi òpòpó títóbi kan, ibẹ̀ yẹn á sì wá jẹ́ ibòòji kan téèyàn lè jókòó sí kó sì sinmi. Pípèsè chautara kan jẹ́ àmì inúrere, bẹ́ẹ̀ sì rèé, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn tó ń pèsè rẹ̀ ni a kì í mọ̀ sójú.
Àwọn ìrírí tó wá láti Nepal fi hàn bí Jèhófà Ọlọ́run ṣe di Orísun ayọ̀ àti ìtura tẹ̀mí fún ọ̀pọ̀ àwọn “arìnrìn-àjò” tó ti rẹ̀ nínú ètò àwọn nǹkan yìí.—Sáàmù 23:2.
• Ìlú ńlá Pokhara rírẹwà, níbi tí Òkè Ńlá Himalaya tí yìnyín bò pitimu ti ń fúnni ní ìran àgbàyanu, ni Lil Kumari ń gbé. Ṣùgbọ́n, ìṣòro ìṣúnná owó tí ìdílé Lil Kumari ní ń kó ìdààmú bá a, ó wá rò pé kò fi bẹ́ẹ̀ sí ìrètí fún òun mọ́. Nígbà tí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀ ẹ́ wò, ìrètí amọ́kànyọ̀ tó wà nínú Bíbélì wú u lórí gan an ni, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló sì béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Lil Kumari ń gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, kò rọrùn fún un láti máa bá a nìṣó, nítorí àtakò líle koko tó ń wá látọ̀dọ̀ ìdílé rẹ̀. Síbẹ̀ obìnrin náà kò jáwọ́. Ó ń wá sí àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé ó sì ń fi ohun tó ń kọ́ sílò, pàápàá jù lọ lórí ọ̀ràn pé kí aya máa ní ìtẹríba. Àbájáde èyí ni pé, ìyá Lil Kumari àti ọkọ rẹ̀ wá rí i pé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà ń ṣe gbogbo ìdílé wọn láǹfààní.
Ọkọ́ rẹ̀ àti àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ bíi mélòó kan ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run báyìí. Ní àpéjọ kan tó wáyé láìpẹ́ yìí ní Pokhara, Lil Kumari àti àwọn mẹ́ẹ̀ẹ́dógún mìíràn lára àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ni wọ́n jọ gbádùn ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Ó sọ pé: “Ilé mi ti wá jẹ́ ibi ìsinmi, nítorí ìdílé wa ti wá wà níṣọ̀kan nínú ìjọsìn tòótọ́ báyìí, mo sì ti wá ní ìbàlẹ̀ ọkàn tó dájú.”
• Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin ka kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ léèwọ̀ ní Nepal, ó ṣì ń ní ipa lílágbára lórí ọ̀nà táwọn èèyàn ń gbà gbé ìgbésí ayé wọn níbẹ̀. Ìdí rèé tí ọ̀pọ̀ fí fẹ́ mọ ohun tí Bíbélì ní í sọ nípa ẹ̀tọ́ ọgbọọgba àti àìṣègbè. Kíkẹ́kọ̀ọ́ pé “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú” mú ìyípadà ńlá bá ìgbésí ayé Surya Maya àti ìdílé rẹ̀.—Ìṣe 10:34.
Ìwà ìrẹ́nijẹ tó máa ń tìdí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ wá àti ìnira tí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àti àṣà ìbílẹ̀ tó ti fẹsẹ̀ rinlẹ̀ ń fà, ló ń kó ìdààmú bá Surya Maya. Nítorí pé Surya Maya jẹ́ obìnrin onífọkànsìn, ọ̀pọ̀ ọdún ló ti ń bẹ àwọn òrìṣà rẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́. Àmọ́ kò síkankan nínú àdúrà rẹ̀ tó gbà. Lọ́jọ́ kan, bó ṣe ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ ni Babita, tó jẹ́ ọmọọmọ rẹ̀ obìnrin lọ bá a, tó sì sọ fún un pé: “Kí ló dé tó jẹ́ àwọn òrìṣà tí kò lè ṣe nǹkankan lẹ̀ ń bẹ̀ pé kí wọ́n ràn yín lọ́wọ́?”
Àṣé ìyá Babita ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Pẹ̀lú ìtara ọkàn ni Babita fi ké sí ìyá rẹ̀ àgbà láti wá sí ìpàdé Kristẹni. Nígbà ti Surya Maya débẹ̀, ó yà á lẹ́nu láti rí àwọn èèyàn tó tinú onírúurú ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà wá, tí wọ́n jọ ń gbádùn bíbá ara wọn kẹ́gbẹ́ láìsí ẹ̀tanú kankan. Kíá ló sọ pé kí wọ́n wá máa bá òun ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí yọrí sí pípa tí àwọn aládùúgbò rẹ̀ pa á tì, kò torí ẹ̀ bọkàn jẹ́; bẹ́ẹ̀ sì ni kò jẹ́ kí àìmọ̀wékà àti àìmọ̀wékọ dáadáa dí òun lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.
Ọdún mẹ́jọ ti kọjá báyìí, mẹ́fà nínú àwọn mẹ́ńbà ìdílé rẹ̀ ló sì ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, títí kan ọkọ rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta. Òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, ìyẹn aṣáájú ọ̀nà déédéé ni Surya Maya nísinsìnyí, tayọ̀tayọ̀ ló sì fi ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti sọ ẹrù ìnira wọn sílẹ̀ ní ibi ìsinmi tòótọ́, èyí tó jẹ́ pé Jèhófà nìkan ló ń fi fúnni.