Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Dúró Lọ́nà Pípé Pẹ̀lú Ìgbàgbọ́ Tó Fìdí Múlẹ̀

Ẹ Dúró Lọ́nà Pípé Pẹ̀lú Ìgbàgbọ́ Tó Fìdí Múlẹ̀

Ẹ Dúró Lọ́nà Pípé Pẹ̀lú Ìgbàgbọ́ Tó Fìdí Múlẹ̀

“Nígbà gbogbo ni ó ń tiraka nítorí yín nínú àwọn àdúrà rẹ̀, pé kí ẹ lè dúró lọ́nà tí ó pé níkẹyìn àti pẹ̀lú ìdálójú ìgbàgbọ́ tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in nínú gbogbo ìfẹ́ Ọlọ́run.”—KÓLÓSÈ 4:12.

1, 2. (a) Kí làwọn ará ìta kíyè sí nípa àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀? (b) Báwo ni ìwé Kólósè ṣe fi àníyàn onífẹ̀ẹ́ hàn?

 ÀWỌN ọmọlẹ́yìn Jésù nífẹ̀ẹ́ tó jinlẹ̀ sí àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wọn. Tertullian (òǹkọ̀wé ọ̀rúndún kejì àti ìkẹta Sànmánì Tiwa) sọ̀rọ̀ nípa inú rere tí wọ́n fi hàn sí àwọn ọmọ òrukàn, àwọn tálákà, àtàwọn arúgbó. Àwọn ẹ̀rí tó fi ìfẹ́ tí wọ́n ní hàn yìí wú àwọn aláìgbàgbọ́ lórí débi táwọn kan fi sọ̀rọ̀ nípa àwọn Kristẹni pé, ‘Wọ́n mà nífẹ̀ẹ́ ara wọn o.’

2 Ìwé Kólósè fi irú àníyàn onífẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn, èyí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Epafírásì alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ní fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó wà ní Kólósè. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí wọn pé: “Nígbà gbogbo ni” Epafírásì “ń tiraka nítorí yín nínú àwọn àdúrà rẹ̀, pé kí ẹ lè dúró lọ́nà tí ó pé níkẹyìn àti pẹ̀lú ìdálójú ìgbàgbọ́ tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in nínú gbogbo ìfẹ́ Ọlọ́run.” Ọ̀rọ̀ tó wà nínú Kólósè 4:12 pé: ‘Ẹ dúró lọ́nà tí ó pé pẹ̀lú ìdálójú ìgbàgbọ́ tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in nínú gbogbo ìfẹ́ Ọlọ́run’ ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò fi ṣe ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wa fún ọdún 2001.

3. Kí ni àwọn ohun méjì tí Epafírásì gbàdúrà fún?

3 Ẹ lè rí i pé ọ̀nà méjì ni àwọn àdúrà tí Epafírásì gbà fún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ pín sí: (1) pé kí wọ́n “dúró lọ́nà tí ó pé níkẹyìn” àti pé (2) kí wọ́n dúró “pẹ̀lú ìdálójú ìgbàgbọ́ tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in nínú gbogbo ìfẹ́ Ọlọ́run.” A kọ ìsọfúnni yìí sínú Ìwé Mímọ́ fún àǹfààní wa. Nítorí náà, bí ara rẹ pé, ‘Kí ni èmi gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan ní láti ṣe kí n tó lè dúró lọ́nà tí ó pé níkẹyìn àti pẹ̀lú ìdálójú ìgbàgbọ́ tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in nínú gbogbo ìfẹ́ Ọlọ́run? Bí mo sì ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, kí ni yóò jẹ́ àbájáde rẹ̀?’ Ẹ jẹ́ kí a wò ó.

Tiraka Láti “Dúró Lọ́nà Tí Ó Pé”

4. Ọ̀nà wo ni àwọn ará Kólósè fi ní láti “pé”?

4 Epafírásì fi tọkàntọkàn fẹ́ kí àwọn arákùnrin àti arábìnrin òun nípa tẹ̀mí ní Kólósè “dúró lọ́nà tí ó pé níkẹyìn.” Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù lò, tí a túmọ̀ rẹ̀ sí “pé” níbí yìí, lè ní ìtumọ̀ pípé, dàgbà di géńdé, tàbí dàgbà dénú. (Mátíù 19:21; Hébérù 5:14; Jákọ́bù 1:4, 25) Ó ṣeé ṣe kóo mọ̀ pé jíjẹ́ tí ẹnì kan jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ó ti ṣe batisí kò túmọ̀ sí pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti di géńdé Kristẹni. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn ará Éfésù tó ń gbé ní apá ìwọ̀ oòrùn Kólósè pé, kí àwọn olùṣọ́ àgùntàn àtàwọn olùkọ́ gbìyànjú láti ṣèrànwọ́ “títí gbogbo wa yóò fi dé ìṣọ̀kanṣoṣo nínú ìgbàgbọ́ àti nínú ìmọ̀ pípéye nípa Ọmọ Ọlọ́run, tí a ó fi di géńdé ọkùnrin, tí a ó fi dé orí ìwọ̀n ìdàgbàsókè tí ó jẹ́ ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Kristi.” Níbòmíràn, Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni láti “dàgbà di géńdé nínú agbára òye.”—Éfésù 4:8-13; 1 Kọ́ríńtì 14:20.

5. Báwo la ṣe lè fi dídàgbà di pípé ṣe olórí góńgó wa?

5 Bí àwọn kan ní Kólósè kò bá ì tíì di géńdé nípa tẹ̀mí tàbí tí wọn kò tíì dàgbà dénú, ó yẹ kí ìyẹn jẹ́ góńgó wọn. Ǹjẹ́ kò yẹ kí àwa náà ṣe bẹ́ẹ̀ lóde òní? Yálà a ti ṣe batisí láti ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún sẹ́yìn tàbí lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ǹjẹ́ a lè rí i kedere pé a ti tẹ̀ síwájú nínú agbára ìrònú àti ojú ìwòye wa? Ǹjẹ́ a máa ń gbé àwọn ìlànà Bíbélì yẹ̀ wò ká tó ṣe àwọn ìpinnu? Ǹjẹ́ àwọn ọ̀ràn tó ní í ṣe pẹ̀lú Ọlọ́run àti ire ìjọ ń kó ipa pàtàkì nínú ìgbésí ayé wa, àbí àyàbá ni wọ́n jẹ́? Kò sí báa ṣe lè ṣàpèjúwe gbogbo ọ̀nà táa lè gbà fi irú dídàgbà di pípé yẹn hàn, àmọ́ a óò mẹ́nu kan àpẹẹrẹ méjì.

6. Kí ni apá ibì kan tó ti lè ṣeé ṣe fún ẹnì kan láti tẹ̀ síwájú dé ìjẹ́pípé, bí Jèhófà ṣe jẹ́ pípé?

6 Àpẹẹrẹ àkọ́kọ́: Ká sọ pé àgbègbè tí wọ́n ti tọ́ wa dàgbà jẹ́ ibì kan tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀tanú tàbí gbúngbùngbún sí àwọn ẹ̀yà mìíràn, orílẹ̀-èdè mìíràn, tàbí ìpínlẹ̀ mìíràn ńkọ́? A ti wá mọ̀ báyìí pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, àwa náà kò sì gbọ́dọ̀ máa ṣe ojúsàájú. (Ìṣe 10:14, 15, 34, 35) Àwọn tí wọ́n wá láti irú àgbègbè yẹn wà nínú ìjọ tàbí ní àwọn ìjọ tí a jọ ń ṣe àpéjọ àyíká, a sì tipa bẹ́ẹ̀ ń wà pẹ̀lú wọn. Ṣùgbọ́n, títí dé àyè wo la fi ní èrò òdì tàbí táa fi ń fura sí àwọn tó ti irú ibi bẹ́ẹ̀ wá? Ṣé ńṣe la wá sọ ara wa di ‘aríjàgbá,’ táa máa ń yára ní èrò òdì bí ẹnì kan tó ti irú ibi bẹ́ẹ̀ wá bá ṣe àṣìṣe tàbí tó dágunlá sí wa láwọn ọ̀nà kan? Bi ara rẹ pé, ‘Ṣé ó yẹ kí n túbọ̀ tẹ̀ síwájú dórí níní èrò Ọlọ́run tí kì í ṣe ojúsàájú?’

7. Níní èrò wo nípa àwọn ẹlòmíràn ni dídi pípé gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni lè ní nínú?

7 Àpẹẹrẹ kejì: Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Fílípì 2:3 wí, a kò gbọ́dọ̀ ṣe ‘ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí a máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù wá lọ.’ Báwo la ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú èyí? Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní ibi tí àìlera rẹ̀ wà àti ibi tí ó lágbára sí. Tó bá jẹ́ pé tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ a tètè máa ń rí àṣìṣe àwọn ẹlòmíràn, ṣé a ti tẹ̀ síwájú báyìí, tí a ò retí mọ́ pé káwọn èèyàn fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ẹni “pípé”? (Jákọ́bù 3:2) Ju ti tẹ́lẹ̀ rí pàápàá, ǹjẹ́ ó ti ṣeé ṣe fún wa nísinsìnyí láti rí—tàbí ká tiẹ̀ máa wá—àwọn ọ̀nà tí àwọn ẹlòmíràn fi lọ́lá jù wá lọ? ‘Mo gbọ́dọ̀ gbà pé arábìnrin yìí lọ́lá jù mí lọ nínú jíjẹ́ onísùúrù.’ ‘Ìgbàgbọ́ ẹni yẹn lágbára ju tèmi lọ.’ ‘Ká sọ tòótọ́, ó mọ èèyàn kọ́ jù mí lọ.’ ‘Ó lọ́lá jù mí ní ti bó ṣe ń ṣàkóso ìbínú rẹ̀.’ Ó lè jẹ́ pé ó yẹ kí àwọn kan lára àwọn ará Kólósè tẹ̀ síwájú nínú èyí. Àwa náà ńkọ́?

8, 9. (a) Ọ̀nà wo ni Epafírásì fi gbàdúrà fún àwọn ará Kólósè láti “dúró” lọ́nà tí ó pé? (b) Kí ni ‘dídúró lọ́nà tí ó pé’ túmọ̀ sí nípa ọjọ́ iwájú?

8 Epafírásì gbàdúrà pé kí àwọn ará Kólósè “dúró lọ́nà tí ó pé.” Ní kedere, Epafírásì ń gbàdúrà sí Ọlọ́run pé títí dé ibi tí àwọn ará Kólósè jẹ́ pípé dé, tí wọ́n dàgbà dénú dé, tí wọ́n sì jẹ́ géńdé Kristẹni dé, wọn óò “dúró” sínú rẹ̀ tàbí pé wọn óò máa wà bẹ́ẹ̀ nìṣó.

9 A ò lè retí pé gbogbo ẹni tó di Kristẹni, kódà ẹnì kan tó ti dàgbà dénú, ni yóò máa bá a lọ bẹ́ẹ̀. Jésù sọ pé áńgẹ́lì kan tó jẹ́ ọmọ Ọlọ́run “kò . . . dúró ṣinṣin nínú òtítọ́.” (Jòhánù 8:44) Pọ́ọ̀lù náà tún rán àwọn Kristẹni létí nípa àwọn kan látijọ́, tí wọ́n ti sin Jèhófà fún àkókò kan, àmọ́ tí wọ́n ti kùnà. Ó kìlọ̀ fún àwọn arákùnrin tí a fi ẹ̀mí yàn pé: “Kí ẹni tí ó bá rò pé òun dúró kíyè sára kí ó má bàa ṣubú.” (1 Kọ́ríńtì 10:12) Èyí túbọ̀ fi hàn bí àdúrà tó gbà pé kí àwọn ará Kólósè “dúró lọ́nà tí ó pé níkẹyìn,” ṣe lágbára tó. Bí wọ́n bá ti lè di pípé, tí wọ́n di géńdé, wọ́n gbọ́dọ̀ máa bá a lọ, wọn kò gbọ́dọ̀ fà sẹ́yìn, kò gbọ́dọ̀ rẹ̀ wọ́n, tàbí kí wọ́n sú lọ. (Hébérù 2:1; 3:12; 6:6; 10:39; 12:25) Nípa bẹ́ẹ̀, wọn óò jẹ́ “pípé” ní ọjọ́ ìbẹ̀wò wọn àti ti ìtẹ́wọ́gbà níkẹyìn.—2 Kọ́ríńtì 5:10; 1 Pétérù 2:12.

10, 11. (a) Àpẹẹrẹ wo ni Epafírásì fi lélẹ̀ fún wa lórí ọ̀rọ̀ nípa àdúrà? (b) Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Epafírásì ṣe, irú ìpinnu wo ni wàá fẹ́ ṣe?

10 A ti jíròrò nípa bó ṣe ṣe pàtàkì tó láti dárúkọ àwọn ẹlòmíràn nínú àdúrà, kí a máa ṣe pàtó ní bíbéèrè pé kí Jèhófà ràn wọ́n lọ́wọ́, kó tù wọ́n nínú, kó bù kún wọn, kó sì fún wọn ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Irú àwọn àdúrà yẹn ni Epafírásì gbà fún àwọn ará Kólósè. A sì lè rí àwọn ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́, àní ó yẹ ká rí wọn nínú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn nípa irú ohun tó yẹ ká máa bá Jèhófà sọ nípa ara wa nínú àdúrà. Láìsí àní-àní, ó yẹ kí a bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ Jèhófà títí tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa yóò fi “dúró lọ́nà tí ó pé níkẹyìn.” Ǹjẹ́ o máa ń ṣe bẹ́ẹ̀?

11 O ò ṣe mẹ́nu kan ipò tóo wà nínú àdúrà? Bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nípa ibi tí ó ti gbìyànjú dé láti tẹ̀ síwájú sí dídi ‘pípé,’ dídi géńdé, àti dídàgbà dénú. Bẹ̀ ẹ́ pé kí ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ àwọn apá ibi tóo ṣì ti nílò láti dàgbà nípa tẹ̀mí. (Sáàmù 17:3; 139:23, 24) Dájúdájú, irú àwọn ibi bẹ́ẹ̀ wà. Nígbà náà, dípò tóo fi máa rẹ̀wẹ̀sì nítorí èyí, rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run lọ́nà tó ṣe kedere, là á mọ́lẹ̀ pé o nílò ìrànlọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú. Ṣe èyí ní ọ̀pọ̀ ìgbà. Àní, o ò ṣe pinnu pé ní ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀ yìí o, wàá gbàdúrà dé àyè kan pé wàá “dúró lọ́nà tí ó pé níkẹyìn.” Kí o sì wéwèé láti túbọ̀ ṣe é ní kíkún sí i, bí o ṣe ń ṣàgbéyẹ̀wò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún yìí. Nínú àdúrà rẹ, sọ nípa àwọn èrò tó lè mú ọ fà sẹ́yìn, tó lè mú ọ ṣàárẹ̀, tàbí mú ọ sú lọ kúrò nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run àti bi o ṣe lè yẹra fún ṣíṣe ìyẹn.—Éfésù 6:11, 13, 14, 18.

Gbàdúrà fún Ìgbàgbọ́ Tó Fìdí Múlẹ̀

12. Kí ni ìdí pàtàkì tí àwọn ará Kólósè fi nílò “ìdálójú ìgbàgbọ́ tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in”?

12 Epafírásì tún gbàdúrà fún ohun mìíràn tí ó ṣe pàtàkì bí àwọn ará Kólósè bá ní láti di ẹni tí a rí tó dúró ní ọ̀nà tó ṣètẹ́wọ́gbà lójú Ọlọ́run níkẹyìn. Ó sì ṣe pàtàkì fún àwa náà pẹ̀lú. Kí ni nǹkan náà? Ó gbàdúrà pé kí wọ́n lè dúró “pẹ̀lú ìdálójú ìgbàgbọ́ tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in nínú gbogbo ìfẹ́ Ọlọ́run.” Ẹ̀kọ́ àdámọ̀ àti ìmọ̀ ọgbọ́n orí tó burú jáì ló yí wọn ká, àwọn kan lára wọn sì dà bí ìjọsìn tòótọ́. Fún àpẹẹrẹ, wọ́n fòòró ẹ̀mí wọn pé kí wọ́n máa pa àwọn ọjọ́ kan mọ́ pẹ̀lú ààwẹ̀ àti àsè, gẹ́gẹ́ bó ṣe pọndandan nínú ẹ̀sìn àwọn Júù nígbà kan rí. Àwọn olùkọ́ èké darí àfiyèsí wọn sí àwọn áńgẹ́lì, ìyẹn àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára táa lò láti gbé Òfin náà lé Mósè lọ́wọ́. Fojú inú wo fífòòró ẹ̀mí èèyàn ní irú ọ̀nà bẹ́ẹ̀! Ọ̀pọ̀ èrò tó forí gbárí tó lè dani lọ́kàn rú ló wà nígbà yẹn.—Gálátíà 3:19; Kólósè 2:8, 16-18.

13. Mímọ kókó wo ló lè ran àwọn ará Kólósè lọ́wọ́, báwo sì ni irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?

13 Pọ́ọ̀lù tún takò wọ́n nípa títẹnu mọ́ ipa tí Jésù Kristi kó. “Bí ẹ ti tẹ́wọ́ gba Kristi Jésù Olúwa, ẹ máa bá a lọ ní rírìn ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, kí ẹ ta gbòǹgbò, kí a sì máa gbé yín ró nínú rẹ̀, kí ẹ sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ yín.” Bẹ́ẹ̀ ni o, ó pọndandan fún (àwọn ará Kólósè àtàwa náà) láti ní ìgbàgbọ́ kíkún nípa ipa tí Kristi kó nínú ète Ọlọ́run àti nínú ìgbésí ayé wa. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Nínú rẹ̀ ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ànímọ́ Ọlọ́run ń gbé gẹ́gẹ́ bí ara kan. Àti nítorí náà, ẹ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìní nípasẹ̀ rẹ̀, ẹni tí ó jẹ́ orí gbogbo ìjọba àti ọlá àṣẹ.”—Kólósè 2:6-10.

14. Báwo ni ìrètí ṣe jẹ́ ohun gidi kan fún àwọn tó wà ní Kólósè?

14 Àwọn Kristẹni tí a fi ẹ̀mí yàn ni àwọn ará Kólósè. Wọ́n ní ìrètí tí ó ṣe gúnmọ́, ìyẹn ni gbígbé ní òkè ọ̀run, ó sì di dandan fún wọn láti jẹ́ kí ìrètí yẹn máa wà digbí nínú ọkàn wọn. (Kólósè 1:5) Ó jẹ́ “ìfẹ́ Ọlọ́run” pé kí wọ́n ní ìgbàgbọ́ tó fìdí múlẹ̀ nípa bí ìrètí wọn ti dájú tó. Ǹjẹ́ ó yẹ kí ẹnikẹ́ni nínú wọn ṣiyèméjì nípa ìrètí yẹn? Rárá o! Ǹjẹ́ ó yẹ kí nǹkan yàtọ̀ lónìí fún gbogbo àwọn tó ń fojú sọ́nà fún ìyè tí Ọlọ́run yóò fúnni nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé? Ó tì o! Ó hàn gbangba pé ìrètí tó ṣe gúnmọ́ yẹn jẹ́ ara “ìfẹ́ Ọlọ́run.” Wàyí o, wá gbé àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yẹ̀ wò: Bí o bá ń tiraka láti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tó máa la “ìpọ́njú ńlá” já, báwo ni ìrètí rẹ ṣe jẹ́ ojúlówó tó? (Ìṣípayá 7:9, 14) Ṣé ara “ìdálójú ìgbàgbọ́” rẹ “tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in nínú gbogbo ìfẹ́ Ọlọ́run” ló jẹ́?

15. Àwọn ohun tó ní ìrètí nínú wo ni Pọ́ọ̀lù tò lẹ́sẹẹsẹ?

15 Táa bá ń sọ nípa “ìrètí,” kì í ṣe ohun kan tó kan ń wù wá, tàbí àlá kan tí kò lè ṣẹ la ń sọ. A lè rí èyí nínú àwọn ohun tí Pọ́ọ̀lù tò lẹ́sẹẹsẹ tí ó kọ́kọ́ sọ fún àwọn ará Róòmù níbẹ̀rẹ̀. Nínú àwọn ohun tí ó sọ yẹn, ọ̀kọ̀ọ̀kan ohun tó mẹ́nu kan ló so mọ́ èyí tó tẹ̀ lé e tàbí tó tọ́ka sí. Kíyè sí ibi tí Pọ́ọ̀lù fi “ìrètí” sí nínú ọ̀rọ̀ tí ó sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa yọ ayọ̀ ńláǹlà nígbà tí a bá wà nínú ìpọ́njú, níwọ̀n bí a ti mọ̀ pé ìpọ́njú ń mú ìfaradà wá; ìfaradà, ní tirẹ̀, ipò ìtẹ́wọ́gbà; ipò ìtẹ́wọ́gbà, ní tirẹ̀, ìrètí, ìrètí náà kì í sì í ṣamọ̀nà sí ìjákulẹ̀; nítorí a ti tú ìfẹ́ Ọlọ́run jáde sínú ọkàn-àyà wa nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́.”—Róòmù 5:3-5.

16. Bóo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì, ìrètí wo lo wá ní?

16 Nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́kọ́ sọ ohun tó wà nínú Bíbélì fún ọ, òtítọ́ kan ti ní láti gba àfiyèsí rẹ, irú bí ipò tí àwọn òkú wà tàbí àjíǹde. Fún ọ̀pọ̀ èèyàn, ohun tó máa ń jẹ́ tuntun sí wọn jù lọ ni bí Bíbélì ṣe jẹ́ kí a mọ̀ pé ó ṣeé ṣe láti wà láàyè nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Ìwọ rántí ìgbà tóo kọ́kọ́ gbọ́ ẹ̀kọ́ yẹn. Ìrètí àgbàyanu mà lèyí o—àìsàn àti ọjọ́ ogbó kò ní sí mọ́, wàá lè wà láàyè lọ láti gbádùn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, wàá ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹranko pàápàá! (Oníwàásù 9:5, 10; Aísáyà 65:17-25; Jòhánù 5:28, 29; Ìṣípayá 21:3, 4) Ìrètí àgbàyanu lo ní o!

17, 18. (a) Báwo ni àwọn ohun tí Pọ́ọ̀lù tó lẹ́sẹẹsẹ fún àwọn ará Róòmù ṣe ṣamọ̀nà sí ìrètí? (b) Irú ìrètí wo là ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú Róòmù 5:4, 5, ǹjẹ́ o sì ní irú ìrètí bẹ́ẹ̀?

17 Bí àkókò ti ń lọ, ó ṣeé ṣe kóo dojú kọ àwọn àtakò kan tàbí inúnibíni. (Mátíù 10:34-39; 24:9) Kódà lẹ́nu àìpẹ́ yìí, wọ́n ti piyẹ́ ilé àwọn Ẹlẹ́rìí ní onírúurú ilẹ̀ tàbí kí wọ́n fagbára sọ wọ́n di olùwá-ibi-ìsádi. Wọ́n ti fipá kọlu àwọn kan, wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn, tàbí kí wọ́n di ẹni tí wọ́n ń parọ́ mọ́ nínú àwọn ìròyìn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde. Inúnibíni yòówù tí o lè ti dojú kọ, gẹ́gẹ́ bí Róòmù 5:3 ṣe sọ, o lè yọ ayọ̀ ńláǹlà nínú ìpọ́njú, èyí sì ti mú àbájáde tó dára wá. Kódà bí Pọ́ọ̀lù ṣe kọ ọ́, ìpọ́njú náà ń jẹ́ kóo ní ìfaradà. Lẹ́yìn náà, ìfaradà ń yọrí sí ipò ìtẹ́wọ́gbà. O mọ̀ pé ò ń ṣe ohun tó dára, ìyẹn ni pé ò ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, nípa bẹ́ẹ̀, ọkàn rẹ balẹ̀ pé o tí rí ojú rere rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ ọ́, o mọ̀ pé o wà ní “ipò ìtẹ́wọ́gbà.” Pọ́ọ̀lù tún tẹ̀ síwájú, ó kọ̀wé pé, “ipò ìtẹ́wọ́gbà ní tirẹ̀ [ń mú] ìrètí [jáde].” Ìyẹn lè yà ọ́ lẹ́nu. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi “ìrètí” sí ibi tó jìnnà tó báyẹn nínú àwọn ohun tí ó tò lẹ́sẹẹsẹ náà? Ǹjẹ́ o ò ti nírètí tipẹ́tipẹ́, nígbà tóo kọ́kọ́ gbọ́ ìhìn rere náà?

18 Ó ṣe kedere pé kì í ṣe ìrètí táa kọ́kọ́ ní nípa ìwàláàyè pípé ni Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí níhìn-ín. Ohun tó ń tọ́ka sí lọ jìnnà ju ìyẹn lọ; ó jinnú jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó sì tún tani jí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nígbà táa bá fi ìṣòtítọ́ fara dà á, táa sì mọ̀ pé a ti rí ojú rere Ọlọ́run, èyí á ní ipa tó jinlẹ̀ lórí fífi kún ìrètí táa kọ́kọ́ ní àti fífún un lókun. Ìrètí táa ní báyìí á wá di èyí tó túbọ̀ jẹ́ ojúlówó, tó túbọ̀ lágbára sí i, tó sì túbọ̀ jẹ́ tiwa fúnra wa. Ìrètí tó jinlẹ̀ yìí túbọ̀ ń mọ́lẹ̀ yòò sí i. Ó di ara wa, ó wé mọ́ gbogbo bí a ṣe jẹ́. “Ìrètí náà kì í sì í ṣamọ̀nà sí ìjákulẹ̀; nítorí a ti tú ìfẹ́ Ọlọ́run jáde sínú ọkàn-àyà wa nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́.”

19. Báwo ni ìrètí rẹ ṣe ní láti jẹ́ ara àdúrà rẹ tí o ń gbà déédéé?

19 Àdúrà àtọkànwá Epafírásì ni pé kí àwọn arákùnrin àti arábìnrin òun tó wà ní Kólósè jára mọ́ ohun tó wà níwájú wọn, kí ó sì dá wọn lójú, kí wọ́n ní “ìdálójú ìgbàgbọ́ tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in nínú gbogbo ìfẹ́ Ọlọ́run.” Bákan náà, ẹ jẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa tọ Ọlọ́run lọ déédéé nípa ìrètí wa. Nínú àdúrà tí o ń dá nìkan gbà, fí ìrètí rẹ nípa ayé tuntun kún un. Sọ fún Jèhófà bó ṣe ń wù ẹ pé kí ó dé, pẹ̀lú ìdánilójú hán-ún-hán-ún pé yóò dé. Bẹ̀ ẹ́ pé kí ó ràn ọ́ lọ́wọ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ lè jinlẹ̀ sí i, kí ó sì gbòòrò sí i pẹ̀lú. Bí Epafírásì ṣe gbàdúrà pé kí àwọn ará Kólósè ní “ìdálójú ìgbàgbọ́ tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in nínú gbogbo ìfẹ́ Ọlọ́run,” ni kí ìwọ náà ṣe. Ṣe é nígbà gbogbo.

20. Bí àwọn díẹ̀ bá yapa kúrò ní ọ̀nà Kristẹni, èé ṣe tí kò fi yẹ kí èyí fa ìrẹ̀wẹ̀sì?

20 Má ṣe pín ọkàn rẹ níyà tàbí kí o rẹ̀wẹ̀sì nítorí pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló dúró lọ́nà pípé pẹ̀lú ìgbàgbọ́. Àwọn kan lè kùnà, wọ́n lè yapa lọ, tàbí kí wọ́n tiẹ̀ jáwọ́ pátápátá. Irú ohun bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn tó sún mọ́ Jésù jù lọ, ìyẹn àwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Àmọ́ nígbà tí Júdásì di ọ̀dàlẹ̀, ǹjẹ́ àwọn àpọ́sítélì yòókù dẹwọ́ tàbí kí wọ́n jáwọ́? Rárá o! Pétérù lo Sáàmù 109:8 láti fi hàn pé ẹlòmíràn yóò gba ipò Júdásì. Wọ́n yan ẹlòmíràn dípò rẹ̀, àwọn adúróṣinṣin ènìyàn Ọlọ́run sì ń fi taratara bá iṣẹ́ ìwàásù táa yàn fún wọn nìṣó. (Ìṣe 1:15-26) Wọ́n pinnu láti dúró lọ́nà pípé pẹ̀lú ìgbàgbọ́.

21, 22. Ọ̀nà wo ni wọ́n fi máa kíyè sí dídúró tí o dúró lọ́nà pípé pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tó fìdí múlẹ̀?

21 Jẹ́ kó dá ọ lójú dáadáa pé dídúró tí o dúró lọ́nà pípé àti pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tó fìdí múlẹ̀ nínú gbogbo ìfẹ́ Ọlọ́run ni a kò ní fojú kékeré wo. A ó kíyè sí i, a ó sì mọrírì rẹ̀ gidigidi. Àwọn wo ló máa ṣe yẹn?

22 Tóò, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin rẹ, tí wọ́n mọ ohun tí ò ń ṣe, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ, yóò kíyè sí i. Kódà bí ọ̀pọ̀ jù lọ wọn kò tiẹ̀ sọ ọ́ jáde, ipa tó máa ní yóò bá ohun tó wà nínú 1 Tẹsalóníkà 1:2-6 mu pé: “Àwa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa gbogbo yín nínú àwọn àdúrà wa, nítorí láìdabọ̀ ni a ń fi iṣẹ́ ìṣòtítọ́ yín sọ́kàn àti òpò onífẹ̀ẹ́ yín àti ìfaradà yín nítorí ìrètí yín nínú Olúwa wa Jésù Kristi níwájú Ọlọ́run àti Baba wa. Nítorí . . . ìhìn rere tí a ń wàásù kò fara hàn láàárín yín nínú ọ̀rọ̀ nìkan ṣùgbọ́n nínú agbára pẹ̀lú àti nínú ẹ̀mí mímọ́ àti ìdálójú ìgbàgbọ́ tí ó lágbára . . . ; ẹ sì di aláfarawé wa àti ti Olúwa.” Bákan náà ni yóò ṣe rí lára àwọn Kristẹni adúróṣinṣin tó yí ọ ká, bí wọ́n ṣe ń kíyè sí i pé o “dúró lọ́nà tí ó pé àti pẹ̀lú ìdálójú ìgbàgbọ́ tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in nínú gbogbo ìfẹ́ Ọlọ́run.”—Kólósè 1:23.

23. Kí ló yẹ kó jẹ́ ìpinnu rẹ nínú ọdún tó ń bọ̀ yìí?

23 Bẹ́ẹ̀ ló sì dájú pé, Baba rẹ ọ̀run yóò kíyè sí i, inú rẹ̀ yóò sì dùn sí ọ pẹ̀lú. Jẹ́ kí ìyẹn dá ọ lójú. Kí nìdí? Nítorí pé ò ń dúró lọ́nà pípé àti pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tó fìdí múlẹ̀ “nínú gbogbo ìfẹ́ Ọlọ́run.” Pọ́ọ̀lù kọ̀wé tí ń fúnni níṣìírí sí àwọn ará Kólósè nípa bí wọ́n ṣe ń rìn “lọ́nà tó yẹ Jèhófà fún ète wíwù ú ní kíkún.” (Kólósè 1:10) Dájúdájú, ó ṣeé ṣe fún ẹ̀dá ènìyàn aláìpé láti wù ú ní kíkún. Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin rẹ tó wà ní Kólósè ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn Kristẹni tó yí ọ ká nísinsìnyí ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀! Nítorí náà, nínú ọdún tó ń bọ̀ yìí, jẹ́ kí àdúrà tí o ń gbà lójoojúmọ́ àti bí o ṣe ń hùwà ní gbogbo ìgbà fi hàn pé o ti pinnu láti “dúró lọ́nà tí ó pé níkẹyìn àti pẹ̀lú ìdálójú ìgbàgbọ́ tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in nínú gbogbo ìfẹ́ Ọlọ́run.”

Ṣé O Lè Rántí?

• Kí ni ‘dídúró rẹ lọ́nà tí ó pé’ ní nínú?

• Kí làwọn nǹkan tó yẹ kóo sọ nípa ara rẹ nígbà tóo bá ń gbàdúrà?

• Gẹ́gẹ́ bí a ṣe dámọ̀ràn rẹ̀ nínú Róòmù 5:4, 5, irú ìrètí wo lo fẹ́ láti ní?

• Kí ni góńgó tí ìkẹ́kọ̀ọ́ wa ti sún ọ láti ní nínú ọdún tó ń bọ̀?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Epafírásì gbàdúrà pé kí àwọn arákùnrin òun dúró lọ́nà pípé, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tó fìdí múlẹ̀ nípa Kristi àti ìrètí wọn

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ló ní irú ìrètí tó dájú àti ìgbàgbọ́ tó fìdí múlẹ̀ bíi tìrẹ