Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Ká Níwà Funfun?

Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Ká Níwà Funfun?

Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Ká Níwà Funfun?

ỌKÙNRIN ará Japan kan tó jẹ́ ẹni nǹkan bí ogójì sí ọgọ́ta ọdún, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kunihito, ṣí wá sí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà lẹ́nu àìpẹ́ yìí. a Láàárín ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan tó dé síbẹ̀, ó dojú kọ ipò kan tó fẹ́rẹ̀ẹ́ gba ìjẹ lẹ́nu rẹ̀. Kunihito sọ pé: “Nígbà tí ọ̀gá mi béèrè lọ́wọ́ mi bóyá mo lè bójú tó ẹrù iṣẹ́ kan, ó dá mi lójú pé mo lè ṣe é dáadáa. Àmọ́, nítorí pé ohun tí wọ́n fi kọ́ mi láti kékeré ni pé ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ wà lára nǹkan táa fi ń mọ̀ bóyá èèyàn ní ìwà funfun, mo wá fèsì pé: ‘Mi ò lè sọ bóyá màá lè ṣe é, àmọ́ màá sa gbogbo ipá mi.’ Létí ọ̀gá mi tó jẹ́ ará Amẹ́ríkà, ńṣe lọ̀rọ̀ yẹn dún bí ẹni pé mi ò tóótun rárá, tí n kò sì dá ara mi lójú. Nígbà tí mo ti wá mọ ìyẹn, mo rí i pé mo ní láti ṣe àwọn àtúnṣe kan.”

Maria, tí ń gbé New York City jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tó mọ̀wé bí nǹkan míì, inú rẹ̀ sì máa ń dùn láti ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́. Juan, tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ bíi tirẹ̀, máa ń fẹ́ kí Maria ran òun náà lọ́wọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àmọ́, ó tún wá ní ìfẹ́ takọtabo sí i, ó sì gbìyànjú láti fa ojú rẹ̀ mọ́ra. Pẹ̀lú bó ṣe wu Maria láti jẹ́ oníwà mímọ́ tó, ó gbà fún Juan, ó sì di ẹni tó lọ́wọ́ nínú ìwà pálapàla.

Ìpèníjà ńlá ló jẹ́ láti níwà funfun nínú ayé òde òní tó kún fún àṣà tó yàtọ̀ síra àti ìwà ìbàjẹ́. Kí wá ni ìdí tó fi yẹ ká níwà funfun? Ìdí ni pé híhu ìwà funfun ń mú inú Ọlọ́run dùn, ó sì dájú pé ọ̀pọ̀ jù lọ wa ló ń wá àtirí ojú rere rẹ̀.

Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ń gba àwọn tó ń kà á níyànjú láti níwà funfun. Fún àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ìwà funfun yòówù tí ó bá wà, ohun yòówù tí ó bá sì wà tí ó yẹ fún ìyìn, ẹ máa bá a lọ ní gbígba nǹkan wọ̀nyí rò.” (Fílípì 4:8) Àpọ́sítélì Pétérù náà tún rọ̀ wá pé kí a ṣe ‘ìsapá àfi-taratara-ṣe láti pèsè ìwà funfun kún ìgbàgbọ́ wa.’ (2 Pétérù 1:5) Àmọ́, kí ni ìwà funfun? Ṣé a lè kọ́ ọ nínú kíláàsì? Báwo la ṣe lè ní in?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.