Bí Wọ́n Ṣe Kojú Ẹ̀mí Ṣohun-Tẹ́gbẹ́-Ń-Ṣe
Bí Wọ́n Ṣe Kojú Ẹ̀mí Ṣohun-Tẹ́gbẹ́-Ń-Ṣe
FÍFẸ́ láti jẹ́ ẹni tó bẹ́gbẹ́ mu ti mú kí ọ̀pọ̀ ṣe ohun tó bá èrò àti ìṣe àwọn tó jẹ́ ojúgbà wọn mu. Ní pàtàkì jù lọ, àwọn ọ̀dọ́ nílò okun láti sọ pé rárá, a ò ní bá wọn lọ́wọ́ nínú àṣà tí ń pani lára, bí ìjoògùnyó àti ìwà pálapàla takọtabo. Báwo ni wọ́n ṣe lè kojú ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe?
Àwọn ọ̀dọ́bìnrin méjì tí wọn kò tíì pé ọmọ ogún ọdún kọ̀wé láti Poland lẹ́nu àìpẹ́ yìí pé: “Ẹ̀mí ayé hàn kedere láàárín ọ̀pọ̀ lára àwọn ojúgbà wa. Wọ́n ń jí ìwé wò nígbà ìdánwò, ọ̀rọ̀ rírùn ló kún ẹnu wọn, wọ́n sì kúndùn kí wọ́n máa wọ àwọn aṣọ tó lòde àti kí wọ́n máa gbọ́ orin burúkú tó kún fún àwọn ọ̀rọ̀ nípa ìṣekúṣe. Inú wa mà dùn o, pé a ní àwọn àpilẹ̀kọ tó bá àwa ọ̀dọ́ wí, tó sì ń dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ ipa tí àìní ìtẹ́lọ́rùn àti ìwà ọ̀tẹ̀ àwọn ọ̀dọ́langba máa ń ní lórí ẹni!
“A ò lè sọ bí ọpẹ́ wa ṣe pọ̀ tó fún àwọn àpilẹ̀kọ inú Ilé Ìṣọ́ tó jẹ́ ká mọ̀ pé àwa táa jẹ́ ọ̀dọ́ wúlò, àwọn èèyàn sì mọyì wa. Àwọn ìmọ̀ràn táa ti gbà látinú Bíbélì ti ràn wá lọ́wọ́ láti gbé ìgbésẹ̀ tó dára kí a lè máa múnú Jèhófà Ọlọ́run dùn nìṣó. Ó dá wa lójú pé fífi òtítọ́ sin Jèhófà ni ọ̀nà ìgbésí ayé tó dára jù lọ.”
Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn ọ̀dọ́ lè kojú ẹ̀mí-ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe. Nípa kíkọ́ “agbára ìwòye” wọn, àwọn Kristẹni ọ̀dọ́ ń kọ́ bí a ṣe ń ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu tí kò fi “ẹ̀mí ayé” hàn, bí kò ṣe “ẹ̀mí tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.”—Hébérù 5:14; 1 Kọ́ríńtì 2:12.