Ẹ Wá Jèhófà Kí Ọjọ́ Ìbínú Rẹ̀ Tó Dé
Ẹ Wá Jèhófà Kí Ọjọ́ Ìbínú Rẹ̀ Tó Dé
“Ẹ wá Jèhófà . . . Ẹ wá òdodo, ẹ wá ọkàn-tútù. Bóyá a lè pa yín mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Jèhófà.”—SEFANÁYÀ 2:3.
1. Báwo ni ipò tẹ̀mí Júdà ṣe rí nígbà tí Sefanáyà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀?
SEFANÁYÀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ lákòókò kan tó le koko nínú ìtàn Júdà. Ipò tẹ̀mí orílẹ̀-èdè náà ti jó rẹ̀yìn. Ọ̀dọ̀ àwọn babalóòṣà àtàwọn awòràwọ̀ làwọn èèyàn náà ti lọ ń gba ìtọ́sọ́nà, kàkà kí wọ́n gbọ́kàn lé Jèhófà. Ìjọsìn Báálì, àti ààtò ìbímọlémọ rẹ̀, gba ilẹ̀ náà kan. Ńṣe làwọn aṣáájú láàárín ìlú, ìyẹn àwọn ọmọ aládé, àwọn ọ̀tọ̀kùlú, àtàwọn onídàájọ́, ń ni àwọn tó yẹ kí wọ́n dáàbò bò lára. (Sefanáyà 1:9; 3:3) Abájọ tí Jèhófà fi pinnu pé òun yóò ‘na ọwọ́ òun jáde,’ kí òun sì fi pa Júdà àti Jerúsálẹ́mù run!—Sefanáyà 1:4.
2. Ìrètí wo ló wà fáwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní Júdà?
2 Ṣùgbọ́n, bí ipò náà ti burú tóo nì, ìrètí díẹ̀ ṣì wà. Jòsáyà, tí í ṣe ọmọ Ámónì, ló wà lórí ìtẹ́ báyìí. Ọmọdé ni Jòsáyà lóòótọ́, ṣùgbọ́n ó fẹ́ràn Jèhófà tọkàntọkàn. Bí ọba tuntun yìí bá lè mú ìjọsìn tòótọ́ padà bọ̀ sípò ní Júdà, ìyẹn á mà mú àwọn díẹ̀ tí wọ́n ń fi ìṣòtítọ́ sin Ọlọ́run tòótọ́ lọ́kàn le o! Ó ṣeé ṣe kí ìyẹn sún àwọn mìíràn láti dara pọ̀ mọ́ wọn, kí a sì dá àwọn náà sí ní ọjọ́ ìbínú Jèhófà.
Ohun Téèyàn Gbọ́dọ̀ Ṣe Láti Lè Là Á Já
3, 4. Kí ni ohun mẹ́ta téèyàn gbọ́dọ̀ ṣe kí a tó lè dá a sí ní “ọjọ́ ìbínú Jèhófà”?
3 Ṣé lóòótọ́ la óò dá àwọn kan sí lọ́jọ́ ìbínú Jèhófà? Bẹ́ẹ̀ ni, bí wọ́n bá ṣe nǹkan mẹ́ta tí Sefanáyà 2:2, 3 sọ. Bí a ó ṣe máa ka ẹsẹ wọ̀nyí, ẹ jẹ́ ká fara balẹ̀ kíyè sí àwọn ohun wọ̀nyẹn táa gbọ́dọ̀ ṣe. Sefanáyà kọ̀wé pé: “Kí ìlànà àgbékalẹ̀ náà tó bí ohunkóhun, kí ọjọ́ náà tó kọjá lọ bí ìyàngbò, kí ìbínú jíjófòfò Jèhófà tó wá sórí yín, kí ọjọ́ ìbínú Jèhófà tó wá sórí yín, ẹ wá Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́kàn tútù ilẹ̀ ayé, tí ń fi ìpinnu ìdájọ́ Tirẹ̀ ṣe ìwà hù. Ẹ wá òdodo, ẹ wá ọkàn-tútù. Bóyá a lè pa yín mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Jèhófà.”
4 Nítorí náà, kí a tó lè pa ẹnì kan mọ́, ẹni náà gbọ́dọ̀ (1) wá Jèhófà, (2) kí ó wá òdodo, àti (3) kí ó wá ọkàn-tútù. Ó yẹ kí á nífẹ̀ẹ́ gidigidi sí àtimọ àwọn ohun àìgbọ́dọ̀máṣe yìí lónìí. Èé ṣe? Nítorí pé bí Júdà àti Jerúsálẹ́mù ṣe dojú kọ ọjọ́ ìjíhìn ní ọ̀rúndún keje ṣááju Sànmánì Tiwa, bẹ́ẹ̀ náà làwọn orílẹ̀-èdè Kirisẹ́ńdọ̀mù àti gbogbo àwọn ẹni ibi pàápàá yóò ṣe fẹ́ figagbága pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run nígbà “ìpọ́njú ńlá” tí ń bọ̀. (Mátíù 24:21) Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ ká pa òun mọ́ lákòókò yẹn gbọ́dọ̀ gbé ìgbésẹ̀ gúnmọ́ nísinsìnyí. Nípa ṣíṣe kí ni? Nípa wíwá Jèhófà, wíwá òdodo, àti nípa wíwá ọkàn-tútù kó tó pẹ́ jù!
5. Kí ni ‘wíwá Jèhófà’ wé mọ́ lónìí?
5 O lè sọ pé: ‘Ìránṣẹ́ Ọlọ́run kúkú ni mí, mo ti ṣèyàsímímọ́, mo sì ti ṣèrìbọmi, Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí. Ṣé mi ò tíì ṣe gbogbo ohun tí a béèrè ni?’ Ká sòótọ́, lẹ́yìn yíya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, àwọn ohun mìíràn kù táa gbọ́dọ̀ ṣe. Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ya ara rẹ̀ sí mímọ́, àmọ́ lọ́jọ́ Sefanáyà, àwọn èèyàn Júdà kò gbé ìgbé ayé wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ tí wọ́n ṣe. Nítorí ìyẹn, orílẹ̀-èdè náà di àpatì. ‘Wíwá Jèhófà’ lónìí wé mọ́ níní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú rẹ̀, kí a sì dara pọ̀ mọ́ ètò rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé. Ó túmọ̀ sí mímọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn nǹkan, kí a sì mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára rẹ̀. A ń wá Jèhófà nípa fífarabalẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ṣíṣàṣàrò lórí ohun táa kọ́, àti fífi ìmọ̀ràn rẹ̀ sílò nínú ìgbésí ayé wa. Bí a sì ṣe ń wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà nínú àdúrà àtọkànwá, táa sì ń tọ ọ̀nà tí ẹ̀mí mímọ́ fẹ́ ká máa tọ̀, àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà yóò máa jinlẹ̀ sí i, ìfẹ́ yóò sì máa sún wa láti sìn ín ‘pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà wa, àti ọkàn wa, àti okunra wa.’—Diutarónómì 6:5; Gálátíà 5:22-25; Fílípì 4:6, 7; Ìṣípayá 4:11.
6. Báwo la ṣe lè máa “wá òdodo,” èé sì ti ṣe tí èyí fi ṣeé ṣe nínú ayé yìí pàápàá?
6 Nǹkan kejì tó jẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe, tí Sefanáyà 2:3 mẹ́nu kàn ni pé kí a “wá òdodo.” Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wa ló ṣe àwọn ìyípadà pàtàkì kí a lè tóótun fún ìrìbọmi Kristẹni. Ṣùgbọ́n, a gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ìlànà òdodo Ọlọ́run jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé wa. Àwọn kan wà tó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀, wọ́n ń ṣe dáadáa, àmọ́ ní báyìí, wọ́n ti jẹ́ kí ayé yìí kó èèràn ràn wọ́n. Àwa náà mọ̀ pé kò rọrùn láti wá òdodo, nítorí pé àwọn èèyàn tí kò rí ohun tó burú nínú ìṣekúṣe, irọ́ pípa, àtàwọn ẹ̀ṣẹ̀ míì ló yí wa ká. Àmọ́, ìfẹ́ tó lágbára láti mú inú Jèhófà dùn lè borí ìtẹ̀sí èyíkéyìí láti wá ojú rere ayé yìí nípa fífẹ́ láti máa ṣe báyé ṣe ń ṣe. Júdà pàdánù ojú rere Ọlọ́run nítorí pé ó ń gbìyànjú láti ṣe bíi ti àwọn orílẹ̀-èdè tó yí i ká, tí wọ́n jẹ́ aláìnáání Ọlọ́run. Nítorí náà, dípò ṣíṣàfarawé ayé, ẹ jẹ́ kí á jẹ́ “aláfarawé Ọlọ́run,” ká máa mú “àkópọ̀ ìwà tuntun . . . tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin” dàgbà.—Éfésù 4:24; 5:1.
7. Báwo la ṣe lè máa “wá ọkàn-tútù”?
7 Kókó kẹta tí Sefanáyà orí kejì, ẹsẹ ìkẹta mẹ́nu kàn ni pé báa bá fẹ́ ká pa wá mọ́ lọ́jọ́ ìbínú Jèhófà, a gbọ́dọ̀ máa “wá ọkàn-tútù.” Ojoojúmọ́ là ń bá àwọn ọkùnrin, obìnrin, àtàwọn ọ̀dọ́ tí kò ní ọkàn-tútù rárá pàdé. Lójú tiwọn, ohun àbùkù ni kéèyàn jẹ́ ọlọ́kàn-tútù. Ẹni tó bá sì níwà ìtẹríba, ọ̀dẹ̀ ni wọ́n kà á sí. Wọ́n máa ń rinkinkin mọ́ nǹkan, tara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀, èrò tiwọn sì máa ń jọ wọ́n lójú jù. Ohun tí wọ́n bá pè ní “ẹ̀tọ́” wọn àti ìfẹ́ inú wọn ló gbọ́dọ̀ di ṣíṣe. Á mà kúkú burú o, bí àwa náà bá lọ ní irú ẹ̀mí wọ̀nyẹn! Àkókò rèé láti “wá ọkàn-tútù.” Lọ́nà wo? Nípa títẹríba fún Ọlọ́run, fífi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ gba ìbáwí rẹ̀, kí a sì máa ṣe ohun tó fẹ́.
Èé Ṣe Tó Fi Jẹ́ “Bóyá” La Ó Pa Wá Mọ́?
8. Kí ni ìlò ọ̀rọ̀ náà “bóyá” nínú Sefanáyà 2:3 fi hàn?
8 Kíyè sí i pé Sefanáyà 2:3 sọ pé: “Bóyá a lè pa yín mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Jèhófà.” Kí ló fà á tó fi lo ọ̀rọ̀ náà “bóyá,” nígbà tó ń bá àwọn “ọlọ́kàn-tútù ilẹ̀ ayé” sọ̀rọ̀? Òótọ́ ni pé àwọn ọlọ́kàn-tútù wọ̀nyẹn ti gbé ìgbésẹ̀ tó dára, ṣùgbọ́n wọn ò gbọ́dọ̀ dá ara wọn lójú jù. Wọn ò tíì fi ìṣòtítọ́ sìn dé òpin ìwàláàyè wọn. Àwọn kan lára wọn ṣì lè kó sínú pańpẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. Bẹ́ẹ̀ lọ̀ràn tiwa náà rí o. Jésù sọ pé: “Ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.” (Mátíù 24:13) Àní sẹ́, bí a óò bá rí ìgbàlà lọ́jọ́ ìbínú Jèhófà, a gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó ní ṣíṣe ohun tí ó tọ́ lójú rẹ̀. Ṣé ohun tí ìwọ yóò máa ṣe láìyẹhùn nìyẹn?
9. Àwọn ìgbésẹ̀ adúróṣinṣin wo ni ọ̀dọ́mọdé Jòsáyà Ọba gbé?
9 Ó jọ pé ọ̀rọ̀ Sefanáyà sún Jòsáyà Ọba láti “wá Jèhófà.” Ìwé mímọ́ sọ pé: “Ní ọdún kẹjọ ìgbà ìjọba rẹ̀, nígbà tí [Jòsáyà] ṣì jẹ́ ọmọdékùnrin [nǹkan bí ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún], ó bẹ̀rẹ̀ sí wá Ọlọ́run Dáfídì baba ńlá rẹ̀.” (2 Kíróníkà 34:3) Jòsáyà tún ‘ń wá òdodo,’ nítorí a kà á pé: “Ní ọdún kejìlá [nígbà tí Jòsáyà jẹ́ ẹni nǹkan bí ogún ọdún] sì ni ó bẹ̀rẹ̀ sí fọ àwọn ibi gíga àti àwọn òpó ọlọ́wọ̀ àti àwọn ère fífín àti àwọn ère dídà kúrò ní Júdà àti Jerúsálẹ́mù. Síwájú sí i, wọ́n bi àwọn pẹpẹ àwọn Báálì wó níwájú rẹ̀.” (2 Kíróníkà 34:3, 4) Jòsáyà tún ‘wá ọkàn-tútù’ pẹ̀lú, nítorí pé ó fi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ gbé ìgbésẹ̀ tó mú inú Jèhófà dùn nípa mímú ìbọ̀rìṣà àtàwọn àṣà ẹ̀sìn èké mìíràn kúrò ní ilẹ̀ náà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ wọ̀nyí á mà mú inú àwọn ọlọ́kàn tútù yòókù dùn o!
10. Kí ló ṣẹlẹ̀ ní Júdà lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, ṣùgbọ́n àwọn wo la dá sí?
10 Ọ̀pọ̀ àwọn Júù ló padà sọ́dọ̀ Jèhófà nígbà ìṣàkóso Jòsáyà. Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn ikú ọba náà, púpọ̀ wọn ló padà sí ọ̀nà tí wọ́n ń tọ̀ tẹ́lẹ̀—àní wọ́n padà sínú àwọn àṣà tí Ọlọ́run kò fẹ́ rárá. Gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti wí tẹ́lẹ̀, àwọn ará Bábílónì ṣẹ́gun Júdà, wọ́n sì pa Jerúsálẹ́mù tí í ṣe olú ìlú rẹ̀ run lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ṣùgbọ́n o, gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ kọ́ ló pa run. Àwọn èèyàn bíi wòlíì Jeremáyà, Ebedi-mélékì ará Etiópíà, àwọn àtọmọdọ́mọ Jónádábù, àtàwọn mìíràn tó jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run ni a pa mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Jèhófà yẹn.—Jeremáyà 35:18, 19; 39:11, 12, 15-18.
Ẹ Gbọ́ O, Ẹ̀yin Ọ̀tá Ọlọ́run!
11. Èé ṣe tó fi jẹ́ ìpèníjà láti dúró bí olóòótọ́ sí Ọlọ́run lóde òní, ṣùgbọ́n kí ló yẹ kí àwọn tó ń bá àwọn èèyàn Jèhófà ṣọ̀tá kíyè sí?
11 Báa ti ń dúró kí ọjọ́ ìbínú Jèhófà dé sórí ètò burúkú ìsinsìnyí, a “ń bá onírúurú àdánwò pàdé.” (Jákọ́bù 1:2) Ní àwọn ilẹ̀ kan tí wọ́n ti sọ pé àwọn ò ní kí ẹnikẹ́ni má ṣe ẹ̀sìn tó wù ú, àwọn àlùfáà ọlọ́gbọ́n àrékérekè ti lo ipò tí wọ́n ní lọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ láti ṣe inúnibíni rírorò sáwọn èèyàn Ọlọ́run. Àwọn agbékèéyíde ń parọ́ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n ń pè wọ́n ní “ẹgbẹ́ òkùnkùn.” Ọlọ́run kúkú rí gbogbo àìdáa tí wọ́n ń ṣe—wọn ò sì ní lọ láìjìyà. Á dáa káwọn ọ̀tá rẹ̀ kíyè sí ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn kan tó bá àwọn èèyàn rẹ̀ ṣọ̀tá láyé ọjọ́un, irú bí àwọn Filísínì. Àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ pé: “Ní ti Gásà, yóò di ìlú ńlá tí a pa tì; Áṣíkẹ́lónì yóò sì di ahoro. Ní ti Áṣídódì, ọ̀sán ganrínganrín ni wọn yóò lé e jáde; àti ní ti Ékírónì, a ó fà á tu.” Àwọn ìlú Filísínì náà Gásà, Áṣíkẹ́lónì, Áṣídódì, àti Ékírónì yóò dahoro pátápátá ni.—Sefanáyà 2:4-7.
12. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Filísíà, Móábù, àti Ámónì?
12 Àsọtẹ́lẹ̀ náà ń bá a lọ, pé: “Mo ti gbọ́ ẹ̀gàn láti ọ̀dọ̀ Móábù àti àwọn ọ̀rọ̀ èébú àwọn ọmọ Ámónì, èyí tí wọ́n ti fi gan àwọn ènìyàn mi, tí wọ́n sì ń bá a nìṣó ní gbígbé àgbéré ńláǹlà sí ìpínlẹ̀ wọn.” (Sefanáyà 2:8) Òótọ́ ni pé àwọn ará Bábílónì tó wá kógun ja Íjíbítì àti Etiópíà hàn wọ́n léèmọ̀. Àmọ́ ìdájọ́ wo ni Ọlọ́run ṣe fún Móábù àti Ámónì, àwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Lọ́ọ̀tì, tí í ṣe ọmọ ẹ̀gbọ́n Ábúráhámù? Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Móábù alára yóò dà bí Sódómù gẹ́lẹ́, àti àwọn ọmọ Ámónì bí Gòmórà.” Ọ̀ràn wọn kò ní rí bíi ti àwọn ìyá ńlá wọn, ìyẹn àwọn ọmọbìnrin Lọ́ọ̀tì méjèèjì, tí wọ́n la ìparun Sódómù àti Gòmórà já. Ní ti Móábù àti Ámónì agbéraga, wọn ò ní bọ́ lọ́wọ́ ìdájọ́ Ọlọ́run. (Sefanáyà 2:9-12; Jẹ́nẹ́sísì 19:16, 23-26, 36-38) Ilẹ̀ Filísíà àtàwọn ìlú rẹ̀ dà lónìí? Móábù àti Ámónì tí ń ṣe kọ́ńdú-kọ́ńdú nígbà yẹn dà? Ò báà wá wọn dọ̀la, o ò ní rí wọn.
13. Kí ni awalẹ̀pìtàn kan ṣàwárí ní Nínéfè?
13 Ìgbà ayé Sefanáyà ni Ilẹ̀ Ọba Ásíríà wà ní òtéńté agbára rẹ̀. Nígbà tí Austen Layard, tó jẹ́ awalẹ̀pìtàn ń ṣàpèjúwe apá kan ààfin ọba tó hú jáde ní Nínéfè, tí í ṣe olú ìlú Ásíríà, ó kọ̀wé pé: “Ṣe ni wọ́n pín àwọn òrùlé wọn sí ìpele-ìpele tó dọ́gba níbùú lóròó, wọ́n fi àwòrán òdòdó tàbí ẹranko ṣọ̀ṣọ́ sí wọn lára. Wọ́n fi eyín erin ṣọ̀ṣọ́ sára àwọn kan, wọ́n wá fi àwọn nǹkan olówó iyebíye yí etí ìpele kọ̀ọ̀kan ká. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé wúrà àti fàdákà ni wọ́n fi kun igi àjà àti ara ògiri iyàrá, ó tilẹ̀ lè jẹ́ pé ṣe ni wọ́n lẹ̀ wọ́n mọ́ ọn; àwọn igi tó ṣọ̀wọ́n ni wọ́n fi ṣe àwọn iṣẹ́ táa figi ṣe, igi kédárì ló sì pọ̀ jù nínú wọn.” Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Sefanáyà ṣe sọ tẹ́lẹ̀, a ó pa Ásíríà run, Nínéfè olú ìlú rẹ̀ yóò sì “di ahoro.”—Sefanáyà 2:13.
14. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Sefanáyà ṣe ṣẹ mọ́ Nínéfè lára?
14 Kò ju ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún péré lẹ́yìn tí Sefanáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí tí wọ́n fi pa Nínéfè alágbára run, wọ́n sọ ààfin ọba rẹ̀ di àlàpà. Bẹ́ẹ̀ ni o, wọ́n pa ìlú agbéraga náà run. Sefanáyà ṣàpèjúwe lọ́nà tó ṣe kedere bí ìparundahoro náà ti tó, ó wí pé: “Ẹyẹ òfú àti òòrẹ̀ yóò sùn mọ́jú láàárín àwọn ọpọ́n orí ọwọ̀n rẹ̀ [tó ti wó] gan-an. Ohùn kan yóò máa kọrin lójú fèrèsé. Ìparundahoro yóò wà ní ibi àbáwọlé.” (Sefanáyà 2:14, 15) Àwọn ilé ńláńlá tó wà ní Nínéfè á di kìkì ilé ẹyẹ òfú àti òòrẹ̀. Ní àwọn òpópónà ìlú náà, a ò ní gbọ́ ìró àwọn oníṣòwò, a ò ní gbọ́ ìró àwọn jagunjagun, bẹ́ẹ̀ ni a ò ní gbọ́ ohùn àwọn àlùfáà mọ́. Láwọn ojú pópó térò ti ń wọ́ lọ wọ́ bọ̀ tẹ́lẹ̀, ohùn kan ṣoṣo tí a óò máa gbọ́ lójú fèrèsé ni ohùn kan tí ń dún lọ́nà tí ń mú kára èèyàn máa sẹ́gìíìrì, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ orin arò tí ẹyẹ kan ń kọ tàbí ìró afẹ́fẹ́. Báyìí ni kí gbogbo àwọn ọ̀tá Ọlọ́run ṣègbé o!
15. Kí la rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Filísíà, Móábù, Ámónì, àti Ásíríà?
15 Kí la rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Filísíà, Móábù, Ámónì, àti Ásíríà? Ohun táa rí kọ́ ni pé: Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà, a ò gbọ́dọ̀ bẹ̀rù àwọn ọ̀tá wa. Ọlọ́run rí itú tí àwọn tó ń tako àwọn ènìyàn rẹ̀ ń pa. Jèhófà kọjú ìjà sáwọn ọ̀tá rẹ̀ nígbà yẹn, yóò sì mú ìdájọ́ ṣẹ sórí gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé lónìí. Ṣùgbọ́n àwọn olùlàájá yóò wà, ìyẹn ni ‘ogunlọ́gọ̀ ńlá láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.’ (Ìṣípayá 7:9) Ìwọ náà lè wà lára wọn o—àmọ́ ìyẹn á ṣeé ṣe kìkì bí o bá ń bá a nìṣó ní wíwá Jèhófà, tí o ń wá òdodo, tí o sì ń wá ọkàn-tútù.
Ègbé Ni Fáwọn Oníwà Àìtọ́ Tí Ń Ṣàfojúdi!
16. Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ Sefanáyà sọ nípa àwọn ọmọ aládé àtàwọn aṣáájú ìsìn Júdà, èé sì ti ṣe tí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fi bá Kirisẹ́ńdọ̀mù mu?
16 Àsọtẹ́lẹ̀ Sefanáyà tún darí àfiyèsí sí Júdà àti Jerúsálẹ́mù. Sefanáyà 3:1, 2 sọ pé: “Ègbé ni fún ẹni tí ń ṣọ̀tẹ̀, tí ó sì ń sọ ara rẹ̀ di eléèérí, ìlú ńlá tí ń nini lára! Kò fetí sí ohùn; kò tẹ́wọ́ gba ìbáwí. Kò ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà. Kò sún mọ́ Ọlọ́run rẹ̀.” Ó mà ṣe o, pé àwọn èèyàn Jèhófà kò náání gbogbo ìbáwí rẹ̀! Ìwà àìláàánú àwọn ọmọ aládé, àwọn ọ̀tọ̀kùlú, àtàwọn onídàájọ́ kọjá sísọ. Sefanáyà bẹnu àtẹ́ lu àwọn aṣáájú ìsìn nítorí ìwà àìnítìjú wọn, ó ní: “Àwọn wòlíì rẹ̀ jẹ́ aláfojúdi, wọ́n jẹ́ aládàkàdekè ènìyàn. Àwọn àlùfáà rẹ̀ alára sọ ohun tí ó jẹ́ mímọ́ di aláìmọ́; wọ́n ṣe ohun àìtọ́ sí òfin.” (Sefanáyà 3:3, 4) Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí mà kúkú ṣàpèjúwe ipò táwọn wòlíì àti àlùfáà Kirisẹ́ńdọ̀mù wà lónìí o! Àní ìwà àfojúdi ọ̀hún wá bá wọn dédìí yíyọ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì tí wọ́n ṣe, wọ́n sì ń fi àwọn ẹ̀kọ́ tí kò jóòótọ́ nípa Ẹni tí wọ́n sọ pé àwọn ń sìn kọ́ni.
17. Yálà àwọn èèyàn gbọ́ tàbí wọn ò gbọ́, èé ṣe tí a ó fi máa bá iṣẹ́ pípolongo ìhìn rere náà nìṣó?
17 Nínú ojú àánú Jèhófà, ó kìlọ̀ fáwọn èèyàn rẹ̀ ayé ọjọ́un nípa ìgbésẹ̀ tóun fẹ́ gbé. Ó rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì—àwọn bíi Sefanáyà àti Jeremáyà, àtàwọn míì—láti rọ àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n ronú pìwà dà. Àní, “Jèhófà . . . kì yóò ṣe àìṣòdodo rárá. Òròòwúrọ̀ ni ó ń fúnni ní ìpinnu ìdájọ́ rẹ̀. Ní ojúmọmọ, kò lè ṣe kí ó máà sí.” Kí ni ìhùwàpadà wọn? Sefanáyà sọ pé: “Ṣùgbọ́n aláìṣòdodo kò mọ ìtìjú.” (Sefanáyà 3:5) Irú ìkìlọ̀ yẹn ń lọ lọ́wọ́ báyìí. Bí o bá jẹ́ akéde ìhìn rere náà, a jẹ́ pé o ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìkìlọ̀ yìí. Máa bá a nìṣó ní pípolongo ìhìn rere náà láìdábọ̀ o! Yálà àwọn èèyàn gbọ́ o, tàbí wọn ò gbọ́, Ọlọ́run gbà pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ ń yọrí sí rere níwọ̀n ìgbà tí o bá ń fòtítọ́ inú ṣe é; kò sídìí fún títijú bí o ti ń fìtara ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run.
18. Báwo ni Sefanáyà 3:6 yóò ṣe nímùúṣẹ?
18 Ọlọ́run ò ní fi ìmúṣẹ ìdájọ́ rẹ̀ mọ sórí sísọ Kirisẹ́ńdọ̀mù dahoro. Jèhófà nasẹ̀ ìbáwí rẹ̀ dé ọ̀dọ̀ gbogbo orílẹ̀-èdè, ó sọ pé: “Mo ké àwọn orílẹ̀-èdè kúrò; àwọn ilé gogoro wọn tí ó wà ní igun odi ni a sọ di ahoro. Mo pa àwọn ojú pópó wọn run di ahoro, tí kò fi sí ẹni tí ń gbà á kọjá. Àwọn ìlú ńlá wọn ni a sọ di ahoro.” (Sefanáyà 3:6) Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dájú tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí Jèhófà fi sọ̀rọ̀ ìparun náà bí ẹni pé ó ti ṣẹlẹ̀. Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn ìlú Filísíà, Móábù, àti Ámónì? Kí ló sì ṣẹlẹ̀ sí Nínéfè, olú ìlú Ásíríà? Ìparun wọn jẹ́ àríkọ́gbọ́n fáwọn orílẹ̀-èdè òde òní. Ọlọ́run kò ṣeé gàn o.
Máa Bá A Nìṣó Ní Wíwá Jèhófà
19. Àwọn ìbéèrè tó gbèrò wo la lè béèrè?
19 Lọ́jọ́ Sefanáyà, Ọlọ́run tú ìbínú rẹ̀ dà sórí àwọn tí ń fi ìwà ìkà sọ “gbogbo ìbánilò wọn di èyí tí ń pani run.” (Sefanáyà 3:7) Ohun kan náà ni yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ tiwa. Ǹjẹ́ o rí ẹ̀rí náà pé ọjọ́ ìbínú Jèhófà ti sún mọ́lé? Ǹjẹ́ o ń bá a nìṣó ní ‘wíwá Jèhófà’ nípa kíka Ọ̀rọ̀ rẹ̀ déédéé—àní lójoojúmọ́? Ǹjẹ́ o ‘ń wá òdodo’ nípa gbígbé ìgbé ayé ìwà rere, ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Ọlọ́run? Ṣé o sì ‘ń wá ọkàn-tútù’ nípa jíjẹ́ onínú tútù, tí o sì ní ẹ̀mí ìtẹríba fún Ọlọ́run àti àwọn ètò tí ó ṣe fún ìgbàlà?
20. Àwọn ìbéèrè wo la óò gbé yẹ̀ wò nínú èyí tó gbẹ̀yìn nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ wọ̀nyí lórí àsọtẹ́lẹ̀ Sefanáyà?
20 Bí a bá ń fi ìṣòtítọ́ wá Jèhófà, òdodo, àti ọkàn-tútù, a lè retí láti gbádùn ọ̀pọ̀ ìbùkún nísinsìnyí—bẹ́ẹ̀ ni, àní ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” wọ̀nyí tí ń dán ìgbàgbọ́ ẹni wò. (2 Tímótì 3:1-5; Òwe 10:22) Àmọ́ a lè béèrè pé, ‘Ọ̀nà wo ni àwa ìránṣẹ́ Jèhófà òde òní gbà ń rí ìbùkún, àwọn ìbùkún ọjọ́ ọ̀la wo sì ni àsọtẹ́lẹ̀ Sefanáyà sọ pé ó wà fáwọn tí a ó pa mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Jèhófà tó ti sún mọ́lé gírígírí yìí?’
Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?
• Báwo làwọn èèyàn ṣe ‘ń wá Jèhófà’?
• Kí ni ‘wíwá òdodo’ wé mọ́?
• Báwo la ṣe lè máa “wá ọkàn-tútù”?
• Èé ṣe tó fi yẹ ká máa wá Jèhófà, ká máa wá òdodo, ká sì máa wá ọkàn-tútù?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ṣé o ń wá Jèhófà nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àdúrà àtọkànwá?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Ogunlọ́gọ̀ ńlá yóò la ọjọ́ ìbínú Jèhófà já nítorí pé wọ́n ń bá a nìṣó ní wíwá Jèhófà