Ìgbàlà Fáwọn Tó Yan Ìmọ́lẹ̀
Ìgbàlà Fáwọn Tó Yan Ìmọ́lẹ̀
“Jèhófà ni ìmọ́lẹ̀ mi àti ìgbàlà mi. Ta ni èmi yóò bẹ̀rù?”—SÁÀMÙ 27:1.
1. Àwọn ìpèsè tí ń fúnni ní ìyè wo ni Jèhófà ṣe?
JÈHÓFÀ ni Orísun ìmọ́lẹ̀ tó jẹ́ kí ìwàláàyè ṣeé ṣe lórí ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:2, 14) Òun sì tún ni Ẹlẹ́dàá ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí, èyí tí ń fòpin sí òkùnkùn tí ń ṣekú pani nínú ayé Sátánì. (Aísáyà 60:2; 2 Kọ́ríńtì 4:6; Éfésù 5:8-11; 6:12) Àwọn tó yan ìmọ́lẹ̀ gbà pẹ̀lú onísáàmù náà pé: “Jèhófà ni ìmọ́lẹ̀ mi àti ìgbàlà mi. Ta ni èmi yóò bẹ̀rù?” (Sáàmù 27:1a) Àmọ́ o, bó ṣe ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Jésù, ìdájọ́ mímúná ń dúró de àwọn tó bá yan òkùnkùn.—Jòhánù 1:9-11; 3:19-21, 36.
2. Ní ayé ìgbàanì, kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn tí kò tẹ́wọ́ gba ìmọ́lẹ̀ Jèhófà, kí ló sì ṣẹlẹ̀ sáwọn tó fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀?
2 Nígbà ayé Aísáyà, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn tó bá Jèhófà dá májẹ̀mú ni kò tẹ́wọ́ gba ìmọ́lẹ̀ náà. Ìdí nìyẹn tí Aísáyà fi sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìparun ìjọba àríwá Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan. Nígbà tó sì di ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ pa run, wọ́n sì kó àwọn olùgbé Júdà lọ sígbèkùn. Ṣùgbọ́n a fún àwọn tó fetí sí ọ̀rọ̀ Jèhófà lókun láti dènà ìpẹ̀yìndà ọjọ́ wọnnì. Jèhófà ṣèlérí pé àwọn tó bá fetí sí òun yóò la ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa já. (Jeremáyà 21:8, 9) Lónìí, àwa táa fẹ́ràn ìmọ́lẹ̀ lè rí ẹ̀kọ́ púpọ̀ kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn.—Éfésù 5:5.
Ayọ̀ Àwọn Tó Wà Nínú Ìmọ́lẹ̀
3. Ìgbọ́kànlé wo la lè ní lónìí, “orílẹ̀-èdè òdodo” wo la fẹ́ràn, “ìlú ńlá tí ó lágbára” wo sì ni “orílẹ̀-èdè” yẹn ní?
3 “A ní ìlú ńlá tí ó lágbára. [Ọlọ́run] mú ìgbàlà pàápàá wá fún àwọn ògiri àti ohun àfiṣe-odi. Ẹ ṣí àwọn ẹnubodè, kí orílẹ̀-èdè òdodo tí ń pa ìwà ìṣòtítọ́ mọ́ lè wọlé.” (Aísáyà 26:1, 2) Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ ìdùnnú tí àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà sọ. Ojú Jèhófà làwọn Júù olóòótọ́ ìgbà ayé Aísáyà ń wò gẹ́gẹ́ bí Orísun kan ṣoṣo fún ààbò tòótọ́, wọn kò wojú àwọn òrìṣà táwọn ọmọ orílẹ̀-èdè wọn ń bọ. Àwa náà ní irú ìgbọ́kànlé yẹn lónìí. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, a fẹ́ràn “orílẹ̀-èdè òdodo” Jèhófà—ìyẹn “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” (Gálátíà 6:16; Mátíù 21:43) Jèhófà pẹ̀lú fẹ́ràn orílẹ̀-èdè yìí nítorí ìwà ìṣòtítọ́ rẹ̀. Nípasẹ̀ ìbùkún rẹ̀, Ísírẹ́lì Ọlọ́run ní “ìlú ńlá tí ó lágbára,” ètò àjọ tó dà bí ìlú ńlá, èyí tí ń ti Ísírẹ́lì Ọlọ́run lẹ́yìn, tó sì ń dáàbò bò ó.
4. Irú ẹ̀mí ìrònú wo ló yẹ kí a ní?
4 Àwọn tó wà nínú “ìlú ńlá” yìí mọ̀ ní àmọ̀dunjú pé “ìtẹ̀sí tí a tì lẹ́yìn dáadáa ni [Jèhófà] yóò fi ìṣọ́ ṣọ́ nínú àlàáfíà tí ń bá a nìṣó, nítorí pé [Jèhófà] ni a mú kí ẹnì kan gbẹ́kẹ̀ lé.” Jèhófà ń ṣètìlẹyìn fáwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé e, tó sì ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà òdodo rẹ̀. Abájọ táwọn olóòótọ́ tí ń bẹ ní Júdà fi ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ ìyànjú Aísáyà pé: “Ẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ní ìgbà gbogbo, nítorí pé inú Jáà Jèhófà ni Àpáta àkókò tí ó lọ kánrin wà.” (Aísáyà 26:3, 4; Sáàmù 9:10; 37:3; Òwe 3:5) Àwọn tó bá ní ẹ̀mí yẹn gbà pé “Jáà Jèhófà” nìkan ṣoṣo ni Àpáta ààbò tó wà. Wọ́n ń gbádùn “àlàáfíà tí ń bá a nìṣó” pẹ̀lú rẹ̀.—Fílípì 1:2; 4:6, 7.
Àwọn Ọ̀tá Ọlọ́run Tẹ́
5, 6. (a) Báwo ni Bábílónì ìgbàanì ṣe tẹ́? (b) Báwo ni “Bábílónì Ńlá” ṣe tẹ́?
5 Bí ìpọ́njú bá dé bá àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ńkọ́? Kí wọ́n má bẹ̀rù. Jèhófà máa ń fàyè gba irú nǹkan wọ̀nyẹn fún sáà kan, ṣùgbọ́n ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ó máa ń mú ìtura wá, á sì wá dá àwọn tó ń fa ìpọ́njú náà lẹ́jọ́. (2 Tẹsalóníkà 1:4-7; 2 Tímótì 1:8-10) Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀ràn “ìlú gíga” kan yẹ̀ wò. Aísáyà sọ pé: “[Jèhófà] ti rẹ àwọn tí ń gbé ibi gíga sílẹ̀, ìlú gíga. Ó rẹ̀ ẹ́ wálẹ̀, ó rẹ̀ ẹ́ kanlẹ̀; ó mú un fara kan ekuru. Ẹsẹ̀ yóò tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, ẹsẹ̀ ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́, ìṣísẹ̀ àwọn ẹni rírẹlẹ̀.” (Aísáyà 26:5, 6) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Bábílónì ni ìlú gíga tí ibí yìí ń sọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó dájú pé ìlú ńlá yẹn pọ́n àwọn èèyàn Ọlọ́run lójú. Àmọ́ kí ló ṣẹlẹ̀ sí Bábílónì? Ní ọdún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa, ó ṣubú sọ́wọ́ àwọn ará Mídíà àti Páṣíà. Ìlú yìí mà kúkú tẹ́ o!
6 Ní ọjọ́ tiwa, ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà bá ohun tó ṣẹlẹ̀ sí “Bábílónì Ńlá” láti 1919 mu wẹ́kú. Ìlú gíga yẹn tẹ́ pátápátá lọ́dún yẹn nígbà tó tú àwọn èèyàn Jèhófà sílẹ̀ tipátipá kúrò nínú ìgbèkùn tẹ̀mí. (Ìṣípayá 14:8) Kékeré tiẹ̀ ni ẹ̀tẹ́ yẹn lẹ́gbẹ̀ẹ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn. Ńṣe ni àwùjọ Kristẹni kéréje yẹn wá bẹ̀rẹ̀ sí ‘tẹ’ àwọn tó mú wọn lóǹdè tẹ́lẹ̀ rí ‘mọ́lẹ̀.’ Ní 1922, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kéde pé òpin Kirisẹ́ńdọ̀mù ń bọ̀, wọ́n ń polongo ìró ìpè kàkàkí áńgẹ́lì mẹ́rin náà, èyí tó wà nínú Ìṣípayá 8:7-12 àti ègbé mẹ́ta tí Ìṣípayá 9:1–11:15 sọ tẹ́lẹ̀.
“Ipa Ọ̀nà Olódodo Jẹ́ Ìdúróṣánṣán”
7. Ìtọ́sọ́nà wo làwọn tó yíjú sí ìmọ́lẹ̀ Jèhófà ń gbà, wọ́n nírètí nínú kí ni, wọ́n sì ń gbé kí ni gẹ̀gẹ̀?
7 Jèhófà ń pèsè ìgbàlà fáwọn tó bá yíjú sí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀, ó sì ń tọ́ wọn sọ́nà, gẹ́gẹ́ bí Aísáyà ti sọ tẹ̀ lé e, pé: “Ipa ọ̀nà olódodo jẹ́ ìdúróṣánṣán. Níwọ̀n bí ìwọ ti jẹ́ adúróṣánṣán, ìwọ yóò mú ipa ọ̀nà olódodo jọ̀lọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, nítorí ipa ọ̀nà àwọn ìdájọ́ rẹ, Jèhófà, ni a fi ní ìrètí nínú rẹ. Orúkọ rẹ àti ìrántí rẹ ni ohun tí ọkàn ń fẹ́.” (Aísáyà 26:7, 8) Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run olódodo, àwọn tó bá ń sìn ín sì gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ọ̀pá ìdiwọ̀n òdodo rẹ̀. Bí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà yóò máa tọ́ wọn sọ́nà, yóò máa mú ipa ọ̀nà wọn jọ̀lọ̀. Nípa gbígba ìtọ́sọ́nà rẹ̀, àwọn ọlọ́kàn tútù yìí ń fi hàn pé wọ́n nírètí nínú Jèhófà, wọ́n sì ń fi tọkàntọkàn gbé orúkọ rẹ̀, ìyẹn, “ìrántí” rẹ̀, gẹ̀gẹ̀.—Ẹ́kísódù 3:15.
8. Ẹ̀mí tó jẹ́ àwòkọ́ṣe wo ni Aísáyà fi hàn?
8 Aísáyà gbé orúkọ Jèhófà gẹ̀gẹ̀. Èyí ṣe kedere látinú ọ̀rọ̀ tó sọ tẹ̀ lé e, pé: “Ọkàn mi ni mo fi ṣe àfẹ́rí rẹ ní òru; bẹ́ẹ̀ ni, ẹ̀mí mi nínú mi ni mo fi ń wá ọ ṣáá; nítorí pé, nígbà tí àwọn ìdájọ́ bá ti ọ̀dọ̀ rẹ wá fún ilẹ̀ ayé, òdodo ni àwọn olùgbé ilẹ̀ eléso yóò kọ́ dájúdájú.” (Aísáyà 26:9) ‘Tọkàntọkàn,’ àní gbogbo ara, ni Aísáyà fi ṣe àfẹ́rí Jèhófà. Fojú inú wo bí wòlíì yẹn yóò ṣe máa fi àwọn àkókò pípa rọ́rọ́ lóru gbàdúrà sí Jèhófà, tí yóò máa sọ èrò tí ń bẹ ní ìsàlẹ̀ ọkàn rẹ̀ fún un, tí yóò sì máa fi tinútinú wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà. Àpẹẹrẹ yẹn mà dára o! Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Aísáyà kọ́ òdodo látinú àwọn ìdájọ́ Jèhófà. Nínú èyí, ó rán wa létí ìjẹ́pàtàkì lílajúsílẹ̀, àní wíwàlójúfò nígbà gbogbo láti lè mọ ohun tí Jèhófà fẹ́.
Àwọn Kan Yan Òkùnkùn
9, 10. Ẹ̀mí inú rere wo ni Jèhófà fi hàn sí orílẹ̀-èdè rẹ̀ aláìṣòótọ́, ṣùgbọ́n báwo ni wọ́n ṣe hùwà padà?
9 Jèhófà fi inú rere onífẹ̀ẹ́ ńláǹlà hàn sí Júdà, àmọ́, ó ṣeni láàánú pé gbogbo wọn kọ́ ló tẹ́wọ́ gbà á. Àìmọye ìgbà ni ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn yan ìṣọ̀tẹ̀ àti ìpẹ̀yìndà, dípò ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ Jèhófà. Aísáyà sọ pé: “Bí a tilẹ̀ fi ojú rere hàn sí ẹni burúkú, kò kúkú ní kọ́ òdodo. Ní ilẹ̀ ìfòtítọ́-hùwà ni yóò ti máa hùwà lọ́nà tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu, kì yóò sì rí ọlá ògo Jèhófà.”—Aísáyà 26:10.
10 Ní ìgbà ayé Aísáyà, nígbà tí Jèhófà fi ọwọ́ ara rẹ̀ gba Júdà lọ́wọ́ ọ̀tá, ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn ò gbà pé Jèhófà ló gba àwọn. Nígbà tó fi àlàáfíà jíǹkí wọn, orílẹ̀-èdè yẹn kò tilẹ̀ dúpẹ́. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n máa sin “àwọn ọ̀gá mìíràn,” níkẹyìn, ó jẹ́ kí a kó àwọn Júù lọ sígbèkùn ní Bábílónì lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa. (Aísáyà 26:11-13) Síbẹ̀síbẹ̀, ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, àṣẹ́kù orílẹ̀-èdè náà padà sí ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn, lẹ́yìn tí ìyà yẹn ti kọ́ wọn lọ́gbọ́n.
11, 12. (a) Kí ni ọjọ́ ọ̀la àwọn tó mú Júdà lóǹdè? (b) Ní 1919, kí ni ọjọ́ ọ̀la àwọn tó mú àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ẹni àmì òróró lóǹdè?
11 Àwọn tó mú Júdà lóǹdè wá ńkọ́ o? Aísáyà dáhùn lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Òkú ni wọ́n; wọn kì yóò wà láàyè. Ní jíjẹ́ aláìlè-ta-pútú nínú ikú, wọn kì yóò dìde. Nítorí náà, ìwọ ti yí àfiyèsí rẹ kí o lè pa wọ́n rẹ́ ráúráú, kí o sì pa gbogbo mímẹ́nu kàn wọ́n run.” (Aísáyà 26:14) Àní, Bábílónì kò ní ọjọ́ ọ̀la kankan mọ́ lẹ́yìn ìṣubú rẹ̀ lọ́dún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa. Nígbà tó bá yá, ìlú ńlá yẹn kò ní sí mọ́. Yóò di “aláìlè-ta-pútú nínú ikú,” ilẹ̀ ọba títóbi yẹn yóò di ohun ìtàn. Ìkìlọ̀ ńlá rèé o, fáwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé àwọn alágbára inú ayé yìí!
12 Àwọn apá kan nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí nímùúṣẹ nígbà tí Ọlọ́run yọ̀ǹda kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ẹni àmì òróró dèrò ìgbèkùn tẹ̀mí ní 1918, táa sì wá tú wọn sílẹ̀ ní 1919. Látìgbà yẹn ni kò ti sí ọjọ́ ọ̀la kankan mọ́ fún àwọn tó mú wọn lóǹdè, pàápàá jù lọ Kirisẹ́ńdọ̀mù. Àmọ́ àwọn ìbùkún tó wà nípamọ́ fáwọn èèyàn Jèhófà pọ̀ gidigidi.
“Ìwọ Ti Fi Kún Orílẹ̀-Èdè Náà”
13, 14. Àwọn ìbùkún jìngbìnnì wo ni àwọn ẹni àmì òróró ìránṣẹ́ Jèhófà ti ń gbádùn láti 1919?
13 Ọlọ́run bù kún ẹ̀mí ìrònúpìwàdà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ẹni àmì òróró ní 1919, ó sì mú wọn bí sí i. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, a pe àfiyèsí sórí kíkó ìyókù Ísírẹ́lì Ọlọ́run jọ, lẹ́yìn náà la wá bẹ̀rẹ̀ sí kó “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “àwọn àgùntàn mìíràn” jọ. (Ìṣípayá 7:9; Jòhánù 10:16) Asọtẹ́lẹ̀ Aísáyà mẹ́nu kan ìbùkún wọ̀nyí, ó ní: “Ìwọ ti fi kún orílẹ̀-èdè náà; Jèhófà, ìwọ ti fi kún orílẹ̀-èdè náà; ìwọ ti ṣe ara rẹ lógo. Ìwọ ti sún gbogbo ojú ààlà ilẹ̀ náà síwájú jìnnà-jìnnà. Jèhófà, nígbà wàhálà, wọ́n yí àfiyèsí wọn sọ́dọ̀ rẹ; wọ́n tú ọ̀rọ̀ àdúrà wúyẹ́wúyẹ́ jáde nígbà tí wọ́n rí ìbáwí rẹ.”—Aísáyà 26:15, 16.
14 Lóde òní, ojú ààlà Ísírẹ́lì Ọlọ́run ti nasẹ̀ dé gbogbo ilẹ̀ ayé. Ogunlọ́gọ̀ ńlá táa ti fi kún wọn ti tó nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́fà nísinsìnyí, wọ́n sì ń fi ìtara lọ́wọ́ sí iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere náà. (Mátíù 24:14) Ìbùkún ńlá látọ̀dọ̀ Jèhófà mà rèé o! Ẹ sì wo ògo ńlá tí èyí ti mú bá orúkọ rẹ̀! Iye ilẹ̀ táa ti ń gbọ́ orúkọ yẹn lóde òní jẹ́ igba ó lé márùndínlógójì [235]—tó fi hàn pé ìlérí rẹ̀ ti ṣẹ lọ́nà tó bùáyà.
15. Àjíǹde ìṣàpẹẹrẹ wo ló wáyé ní 1919?
15 Júdà kò lè bọ́ lóko ẹrú Bábílónì láìsí ìrànlọ́wọ́ Jèhófà. Wọn ò lè dá a ṣe. (Aísáyà 26:17, 18) Bákan náà, ìdásílẹ̀ Ísírẹ́lì Ọlọ́run ní 1919 jẹ́ ẹ̀rí ìtìlẹyìn Jèhófà. Kò lè wáyé láìjẹ́ pé ó lọ́wọ́ sí i. Ìyípadà nínú ipò wọn sì yani lẹ́nu débi pé Aísáyà fi wé àjíǹde, ó sọ pé: “Àwọn òkú rẹ yóò wà láàyè. Òkú tèmi—wọn yóò dìde. Ẹ jí, ẹ sì fi ìdùnnú ké jáde, ẹ̀yin olùgbé inú ekuru! Nítorí pé ìrì rẹ dà bí ìrì ewéko málò, ilẹ̀ ayé pàápàá yóò sì jẹ́ kí àwọn tí ó jẹ́ aláìlè-ta-pútú nínú ikú pàápàá jáde wá nínú ìbímọ.” (Aísáyà 26:19; Ìṣípayá 11:7-11) Bẹ́ẹ̀ ni, ṣe ni yóò dà bí ẹni pé a tún àwọn aláìlè-ta-pútú nínú ikú bí, kí wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ ìgbòkègbodò lákọ̀tun!
Ààbò ní Àkókò Eléwu
16, 17. (a) Kí làwọn Júù gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n lè la ìṣubú Bábílónì já lọ́dún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa? (b) Kí ni a lè sọ pé ‘àwọn yàrá ti inú lọ́hùn-ún’ jẹ́ lónìí, báwo sì ni wọ́n ṣe wúlò fún wa?
16 Kò sígbà táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kì í nílò ààbò rẹ̀. Àmọ́ láìpẹ́, òun yóò na ọwọ́ rẹ̀ jáde fún ìgbà ìkẹyìn láti fi gbéjà ko ayé Sátánì, àwọn olùjọsìn rẹ̀ yóò sì nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. (1 Jòhánù 5:19) Nípa àkókò eléwu yẹn, Jèhófà kìlọ̀ fún wa pé: “Lọ, ènìyàn mi, wọnú yàrá rẹ ti inú lọ́hùn-ún, kí o sì ti ilẹ̀kùn rẹ mọ́ ara rẹ. Fi ara rẹ pa mọ́ fún kìkì ìṣẹ́jú kan títí ìdálẹ́bi yóò fi ré kọjá. Nítorí pé, wò ó! Jèhófà ń jáde bọ̀ láti ipò rẹ̀, láti béèrè ìjíhìn fún ìṣìnà àwọn olùgbé ilẹ̀ náà lòdì sí òun, dájúdájú, ilẹ̀ náà yóò sì fi ìtàjẹ̀sílẹ̀ rẹ̀ hàn síta, kì yóò sì tún bo àwọn tirẹ̀ tí a pa mọ́.” (Aísáyà 26:20, 21; Sefanáyà 1:14) Ìkìlọ̀ yìí jẹ́ kí àwọn Júù mọ bí wọ́n ṣe lè la ìṣubú Bábílónì já lọ́dún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa. Àwọn tó kọbi ara sí ìkìlọ̀ yìí jókòó sínú ilé, wọn ò sì kó sọ́wọ́ àwọn ajagunṣẹ́gun tí ń bẹ lóde.
17 Lónìí, ‘àwọn yàrá ti inú lọ́hùn-ún’ tí àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ̀rọ̀ rẹ̀, ṣeé ṣe kó dúró fún ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́wàá-mẹ́wàá àwọn ìjọ èèyàn Jèhófà kárí ayé. Irú àwọn ìjọ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ibi ààbò nísinsìnyí pàápàá, wọ́n jẹ́ ibi tí àwọn Kristẹni ti ń rí ààbò láàárín àwọn ará, lábẹ́ ìtọ́jú onífẹ̀ẹ́ àwọn alàgbà. (Aísáyà 32:1, 2; Hébérù 10:24, 25) Èyí wá rí bẹ́ẹ̀ ní pàtàkì nítorí bí òpin ètò àwọn nǹkan yìí ti sún mọ́lé tó, nígbà tí lílàájá yóò sinmi lé ìgbọràn.—Sefanáyà 2:3.
18. Báwo ni Jèhófà yóò ṣe “pa ẹran ńlá abàmì inú òkun” náà láìpẹ́?
18 Nípa àkókò yẹn, Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà, tòun ti idà rẹ̀ líle tí ó tóbi, tí ó sì lágbára, yóò yí àfiyèsí rẹ̀ sí Léfíátánì, ejò tí ń yọ́ bẹ̀rẹ́, àní sí Léfíátánì, ejò wíwọ́, dájúdájú, òun yóò pa ẹran ńlá abàmì inú òkun, èyí tí ń bẹ nínú òkun.” (Aísáyà 27:1) Kí ni “Léfíátánì” òde òní? Ó hàn gbangba pé “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà,” Sátánì alára ni, àti ètò àwọn nǹkan búburú rẹ̀, tó fi ń bá Ísírẹ́lì Ọlọ́run jagun. (Ìṣípayá 12:9, 10, 17; 13:14, 16, 17) Ní 1919, Léfíátánì kò rí àwọn èèyàn Ọlọ́run gbé ṣe mọ́. Nígbà tó bá yá, yóò lọ ní àlọ rámirámi. (Ìṣípayá 19:19-21; 20:1-3, 10) Bí Jèhófà yóò ṣe “pa ẹran ńlá abàmì inú òkun” nìyẹn. Ní báyìí ná, kò sóhun tí Léfíátánì ń gbìyànjú láti ṣe sáwọn èèyàn Jèhófà tó máa kẹ́sẹ járí. (Aísáyà 54:17) Ẹ wo bí ìdánilójú yẹn ti ń fini lọ́kàn balẹ̀ tó!
“Ọgbà Àjàrà Wáìnì Tí Ń Yọ Ìfóófòó”
19. Ipò wo làwọn àṣẹ́kù wà lónìí?
19 Lójú gbogbo ìmọ́lẹ̀ yìí látọ̀dọ̀ Jèhófà, a kò ha ní ìdí fún ayọ̀ yíyọ̀ bí? Bẹ́ẹ̀ ni, a ní ìdí fún ayọ̀ yíyọ̀! Aísáyà ṣe àpèjúwe tó gún régé nípa ayọ̀ àwọn èèyàn Jèhófà nígbà tó kọ̀wé pé: “Ní ọjọ́ yẹn, ẹ kọrin sí obìnrin náà pé: ‘Ọgbà àjàrà wáìnì tí ń yọ ìfóófòó! Èmi, Jèhófà, yóò máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ. Ìṣẹ́jú-ìṣẹ́jú ni èmi yóò máa bomi rin ín. Kí ẹnikẹ́ni má bàa yí àfiyèsí rẹ̀ lòdì sí i, èmi yóò máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ ní òru àti ní ọ̀sán pàápàá.’” (Aísáyà 27:2, 3) Jèhófà ń bójú tó “ọgbà àjàrà” rẹ̀, ìyẹn, àṣẹ́kù Ísírẹ́lì Ọlọ́run, ó tún ń bójú tó àwọn òṣìṣẹ́kára alábàákẹ́gbẹ́ wọn. (Jòhánù 15:1-8) Ìyọrísí rẹ̀ ni èso tí ń mú ìyìn wá fórúkọ rẹ̀, tó sì ń fa ayọ̀ ńláǹlà láàárín àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé.
20. Báwo ni Jèhófà ṣe ń dáàbò bo ìjọ Kristẹni?
20 Inú wa dùn pé inú tó ń bí Jèhófà tẹ́lẹ̀ sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ẹni àmì òróró—èyí tó fà á tó fi fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n lọ sígbèkùn tẹ̀mí ní 1918—ti kásẹ̀ nílẹ̀. Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ pé: “Èmi kò ní ìhónú kankan. Ta ni yóò fún mi ní àwọn igi kéékèèké ẹlẹ́gùn-ún àti èpò nínú ìjà ogun? Ṣe ni èmi yóò gbé ẹsẹ̀ lé irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Èmi yóò dáná sí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lẹ́sẹ̀ kan náà. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ó di ibi odi agbára mi mú, kí ó wá àlàáfíà pẹ̀lú mi; àlàáfíà ni kí ó wá pẹ̀lú mi.” (Aísáyà 27:4, 5) Láti rí i dájú pé àjàrà rẹ̀ ń bá a lọ ni síso àsokún “wáìnì tí ń yọ ìfóófòó,” Jèhófà tẹ ohunkóhun tó bá jọ èpò tó lè sọ wọ́n dìbàjẹ́ rẹ́, ó sì pa á run. Fún ìdí yìí, kí ẹnikẹ́ni má wu ìjọ Kristẹni léwu o! Kí gbogbo èèyàn yáa ‘di ibi odi agbára Jèhófà mú’ ni o, ìyẹn ni pé kí wọ́n máa wá ojú rere àti ààbò rẹ̀. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ la fi ń wá àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run—àní ó ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí Aísáyà fi mẹ́nu kàn án lẹ́ẹ̀mejì.—Sáàmù 85:1, 2, 8; Róòmù 5:1.
21. Báwo ni ilẹ̀ eléso náà ṣe kún fún “èso”?
21 Àwọn ìbùkún náà ń bá a lọ, pé: “Ní àwọn ọjọ́ tí ń bọ̀, Jékọ́bù yóò ta gbòǹgbò, Ísírẹ́lì yóò mú ìtànná jáde, yóò sì rú jáde ní tòótọ́; ṣe ni wọn yóò wulẹ̀ fi èso kún ojú ilẹ̀ eléso.” (Aísáyà 27:6) Ẹsẹ yìí ti ń ní ìmúṣẹ láti 1919, èyí sì jẹ́ àgbàyanu ẹ̀rí nípa agbára Jèhófà. Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ti fi “èso,” ìyẹn, oúnjẹ tẹ̀mí tó dọ́ṣọ̀, kún ilẹ̀ ayé. Nínú ayé oníwà ìbàjẹ́ yìí, wọ́n ń fi tayọ̀tayọ̀ pa ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga Ọlọ́run mọ́. Jèhófà sì ń bá a nìṣó láti fi ìbísí jíǹkí wọn. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn, ìyẹn, àwọn àgùntàn mìíràn, “ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún [Ọlọ́run] tọ̀sán-tòru.” (Ìṣípayá 7:15) Ǹjẹ́ kí a má ṣe fi àǹfààní ńlá ti jíjẹ lára “èso” náà àti ti pípín in fáwọn ẹlòmíràn tàfàlà!
22. Àwọn ìbùkún wo ni àwọn tó tẹ́wọ́ gba ìmọ́lẹ̀ náà yóò ní?
22 Ní àwọn àkókò lílekoko yìí, tí òkùnkùn ti bo ilẹ̀ ayé, tí ìṣúdùdù sì bo àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè, ǹjẹ́ a kò dúpẹ́ pé Jèhófà ń tan ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí fáwọn èèyàn rẹ̀? (Aísáyà 60:2; Róòmù 2:19; 13:12) Ìbàlẹ̀ ọkàn àti inú dídùn nísinsìnyí àti ìyè àìnípẹ̀kun pàápàá lọ́jọ́ iwájú dájú fún gbogbo àwọn tó bá tẹ́wọ́ gba ìmọ́lẹ̀ náà. Nítorí náà, kí àwa táa fẹ́ràn ìmọ́lẹ̀ fi tọkàntọkàn yin Jèhófà lógo, ká sì sọ gẹ́gẹ́ bí onísáàmù náà pé: “Jèhófà ni odi agbára ìgbésí ayé mi. Ta ni èmi yóò ní ìbẹ̀rùbojo fún? Ní ìrètí nínú Jèhófà; jẹ́ onígboyà, sì jẹ́ kí ọkàn-àyà rẹ jẹ́ alágbára. Bẹ́ẹ̀ ni, ní ìrètí nínú Jèhófà.”—Sáàmù 27:1b, 14.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Báwo ni ọjọ́ ọ̀la àwọn tí ń ni àwọn èèyàn Jèhófà lára yóò ṣe rí?
• Ìbísí wo la sọ tẹ́lẹ̀ nínú Aísáyà?
• ‘Yàrá ti inú lọ́hùn-ún’ wo ló yẹ ká jókòó sí, èé sì ti ṣe?
• Èé ṣe tí ipò àwọn èèyàn Jèhófà fi ń mú ìyìn wá fún un?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 22]
ÌTẸ̀JÁDE TUNTUN
Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ìsọfúnni táa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ méjèèjì yìí wá látinú àsọyé kan táa sọ nígbà ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ àgbègbè fún ọdún 2000 sí 2001. Nígbà táa parí àsọyé náà, a mú ìwé tuntun kan jáde, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní. Ìwé olójú ewé 416 yìí dá lórí ìjíròrò orí ogójì àkọ́kọ́ nínú ìwé Aísáyà, láti ẹsẹ dé ẹsẹ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwọn olódodo nìkan ló lè ráyè wọ “ìlú ńlá tí ó lágbára” ti Jèhófà, ìyẹn, ètò àjọ rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Aísáyà wá Jèhófà “ní òru”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Jèhófà ń dáàbò bo “ọgbà àjàrà” rẹ̀, ó sì ń mú kó sèso