“Ní Ti Tòótọ́ Ni A Gbé Olúwa Dìde!”
“Ní Ti Tòótọ́ Ni A Gbé Olúwa Dìde!”
Fojú inú wo bí ìrẹ̀wẹ̀sì tó bá àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ti pọ̀ tó nígbà tí wọ́n pa Olúwa wọn. Ó jọ pé ìrètí wọ́n ti kú, gẹ́gẹ́ bí òkú tí Jósẹ́fù ará Arimatíà lọ gbé sin sínú sàréè. Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo ìfojúsọ́nà pé Jésù yóò mú àjàgà Róòmù kúrò lọ́rùn àwọn Júù tún forí ṣánpọ́n.
KÁ SỌ pé ibi tọ́ràn parí sí nìyẹn ni, bóyá lẹnikẹ́ni ì bá tún gbúròó àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù mọ́, bí àwọn èèyàn ò ṣe gbúròó àwọn ọmọlẹ́yìn ọ̀pọ̀ tó pe ara wọn ní Mèsáyà mọ́. Ṣùgbọ́n Jésù ń bẹ láàyè o! Ìwé Mímọ́ sọ pé ó fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní àwọn ìgbà bíi mélòó kan láìpẹ́ lẹ́yìn ikú rẹ̀. Ìyẹn ló sún àwọn kan lára wọn, tí wọ́n fi sọ tìtaratìtara pé: “Ní ti tòótọ́ ni a gbé Olúwa dìde!”—Lúùkù 24:34.
Ó di dandan kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi gbà gbọ́ pé Jésù ni Mèsáyà náà. Nígbà tí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro, tí wọ́n máa ń tọ́ka sí ní pàtàkì láti fi hàn pé òun ni Mèsáyà náà ni ẹ̀rí nípa àjíǹde rẹ̀ kúrò nínú òkú. Àní sẹ́, “pẹ̀lú agbára ńlá ni àwọn àpọ́sítélì fi ń bá a lọ ní jíjẹ́ ẹ̀rí nípa àjíǹde Jésù Olúwa.”—Ìṣe 4:33.
Ká ní ó ṣeé ṣe fún ẹnikẹ́ni láti mú ẹ̀rí jáde ni, tó fi hàn pé ayédèrú ni àjíǹde yìí—bóyá nípa mímú kí ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn jẹ́wọ́ pé ayédèrú ni tàbí nípa fífi hàn pé òkú Jésù ṣì wà
nínú ibojì náà—láti ìbẹ̀rẹ̀ pàá ni ẹ̀sìn Kristẹni ì bá ti kógbá sílé. Ṣùgbọ́n kò kógbá sílé. Níwọ̀n bí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ti mọ̀ pé Kristi ń bẹ láàyè, ńṣe ni wọ́n ń pòkìkí àjíǹde rẹ̀ níbi gbogbo, ogunlọ́gọ̀ sì gba Kristi táa ti jí dìde gbọ́.Èé ṣe tí ìwọ náà fi lè gba àjíǹde Jésù gbọ́? Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé lóòótọ́ ló jíǹde?
Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kóo Gbé Ẹ̀rí Náà Yẹ̀ Wò?
Gbogbo Ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ló ròyìn nípa àjíǹde Jésù. (Mátíù 28:1-10; Máàkù 16:1-8; Lúùkù 24:1-12; Jòhánù 20:1-29) a Àwọn apá ibòmíràn nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì jẹ́rìí sí i pé dájúdájú ni a gbé Kristi dìde kúrò nínú òkú.
Abájọ táwọn ọmọlẹ́yìn Jésù fi ń kéde àjíǹde rẹ̀! Bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni Ọlọ́run gbé e dìde sí ìyè, ìròyìn àgbàyanu nìyẹn lágbàáyé. Ó túmọ̀ sí pé Ọlọ́run wà. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó túmọ̀ sí pé Jésù ń bẹ láàyè nísinsìnyí.
Báwo nìyẹn ṣe kàn wá? Tóò, Jésù gbàdúrà pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Dájúdájú, a lè jèrè ìmọ̀ tí ń fúnni ní ìyè nípa Jésù àti Baba rẹ̀. Nípa fífi irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ sílò, bí a tilẹ̀ kú, a lè jí àwa náà dìde, torí pé a jí Jésù dìde. (Jòhánù 5:28, 29) A lè ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun nínú párádísè orí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run níkàáwọ́ Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀ ológo, àti Ọba àwọn ọba.—Aísáyà 9:6, 7; Lúùkù 23:43; Ìṣípayá 17:14.
Nítorí náà, ọ̀rọ̀ nípa bóyá lóòótọ́ ni Jésù jíǹde kúrò nínú òkú ṣe pàtàkì púpọ̀. Ó kan ìgbésí ayé wa nísinsìnyí àti ìrètí wa fún ọjọ́ ọ̀la. Ìyẹn la fi ní kóo jẹ́ ká jọ ṣàyẹ̀wò oríṣi ẹ̀rí mẹ́rin tó fi hàn pé Jésù kú, a sì jí i dìde.
Lóòótọ́ Ni Jésù Kú Lórí Igi
Àwọn oníyèmejì kan sọ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n kan Jésù mọ́gi, kò kú sórí igi ní tòótọ́. Wọ́n ní ó kàn sún mọ́ bèbè ikú ni, wọ́n ní títutù tí sàréè náà tutù mú kó sọ jí. Ṣùgbọ́n, gbogbo ìsọfúnni tó wà fi hàn gbangba pé òkú Jésù ni wọ́n tẹ́ sínú sàréè.
Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé gbangba wálíà ni wọ́n ti pa Jésù, àwọn èèyàn wà níbẹ̀ tó fojú ara wọn rí i pé orí igi ló kú sí ní tòótọ́. Balógun ọ̀rún tí wọ́n ní kó lọ bójú tó bí wọ́n ṣe pa á jẹ́rìí pé ó ti kú. Amọṣẹ́dunjú ni ọ̀gágun náà, ara iṣẹ́ rẹ̀ sì ni láti pinnu bóyá ẹnì kan ti kú lóòótọ́. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìgbà tí ẹ̀rí fi hàn dájú pé Jésù ti kú ni Gómìnà Róòmù náà, Pọ́ńtíù Pílátù, tó yọ̀ǹda kí Jósẹ́fù ará Arimatíà gbé òkú Jésù lọ sí itẹ́.—Máàkù 15:39-46.
Wọ́n Bá Ibojì ní Ṣíṣófo
Ibojì tó ṣófo ni ẹ̀rí àkọ́kọ́ tó mú un dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn lójú pé Jésù ti jíǹde, ẹ̀rí yìí kò sì ṣeé já ní koro. Inú ibojì tuntun ni wọ́n tẹ́ Jésù sí, èyí tí wọn ò tẹ́ ẹnikẹ́ni sí rí. Ibẹ̀ ò jìnnà síbi tí wọ́n ti kàn án mọ́gi, kò sì láṣìmọ̀ rárá nígbà yẹn. (Jòhánù 19:41, 42) Ọ̀rọ̀ inú gbogbo àwọn Ìwé Ìhìn Rere ló bára mu rẹ́gí pé nígbà táwọn ọ̀rẹ́ Jésù dé ibojì náà ní àárọ̀ ọjọ́ kẹta lẹ́yìn ikú rẹ̀, òkú rẹ̀ kò sí níbẹ̀ mọ́.—Mátíù 28:1-7; Máàkù 16:1-7; Lúùkù 24:1-3; Jòhánù 20:1-10.
Ibojì tó ṣófo náà ṣe àwọn ọ̀tá Jésù ní kàyéfì, gẹ́gẹ́ bó ti ṣe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ní kàyéfì. Ó ti pẹ́ táwọn ọ̀tá rẹ̀ ti ń làkàkà láti rẹ́yìn rẹ̀, kí wọ́n sì gbé e sin. Lẹ́yìn tí ọwọ́ wọn tẹ góńgó wọn, wọn ò sinmi, wọ́n tún fi ẹ̀ṣọ́ síbẹ̀, wọ́n sì dí ibojì náà pa. Ṣùgbọ́n, ní àárọ̀ ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀, ó ti ṣófo.
Ṣé àwọn ọ̀rẹ́ Jésù wá gbé òkú rẹ̀ kúrò nínú ibojì ni? Kò jẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀, nítorí àwọn Ìwé Ìhìn Rere fi hàn pé ìdààmú ńlá bá wọn lẹ́yìn ikú rẹ̀. Síwájú sí i, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ kò ní fojú winá inúnibíni, wọn ò sì ní fi ẹ̀mí wọn lélẹ̀ fún ohun tí wọ́n mọ̀ pé ayédèrú ni.
Ta ló sọ ibojì náà dòfo? Kò tiẹ̀ lè jẹ́ àwọn ọ̀tá Jésù ló lọ gbé òkú rẹ̀. Bó bá jẹ́ àwọn ni, ó dájú pé kíá ni wọ́n á gbé e jáde lẹ́yìn náà láti fi táṣìírí àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó sọ pé ńṣe ni Jésù jíǹde àti pé ó wà láàyè. Àmọ́ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ ò ṣẹlẹ̀ rárá, nítorí pé iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run ni.
Ní ọ̀sẹ̀ mélòó kan lẹ́yìn náà, àwọn ọ̀tá Jésù kò lẹ́nu ọ̀rọ̀ rárá nígbà tí Pétérù jẹ́rìí pé: “Ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: Jésù ará Násárétì, ọkùnrin tí Ọlọ́run fi hàn ní gbangba fún yín nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ agbára àti àmì àgbàyanu àti iṣẹ́ àmì tí Ọlọ́run ṣe nípasẹ̀ rẹ̀ láàárín yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin fúnra yín ti mọ̀, ọkùnrin yìí, gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a fà léni lọ́wọ́ nípasẹ̀ ète tí a ti pa àti ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run, ni ẹ ti ọwọ́ àwọn ènìyàn aláìlófin kàn mọ́ òpó igi, tí ẹ sì pa. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jí i dìde nípa títú àwọn ìroragógó ikú, nítorí kò ṣeé ṣe pé kí ó máa bá a lọ láti dì í mú ṣinṣin. Nítorí Dáfídì sọ nípa rẹ̀ pé, ‘Mo ní Jèhófà níwájú mi nígbà gbogbo . . . Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹran ara mi pàápàá yóò máa gbé ní ìrètí; nítorí ìwọ kì yóò fi ọkàn mi sílẹ̀ sínú Hédíìsì, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò jẹ́ kí ẹni ìdúróṣinṣin rẹ rí ìdíbàjẹ́.’”—Ìṣe 2:22-27.
Ọ̀pọ̀ Èèyàn Ló Rí Jésù Tó Jíǹde Náà
Lúùkù, tó kọ ọ̀kan lára àwọn Ìwé Ìhìn Rere, sọ nínú ìwé Ìṣe pé: “Àwọn [àpọ́sítélì] pẹ̀lú ni [Jésù] fi ara rẹ̀ hàn fún láàyè nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ ẹ̀rí dídánilójú hán-ún hán-ún lẹ́yìn tí ó ti jìyà, tí wọ́n ń rí i jálẹ̀jálẹ̀ ogójì ọjọ́, tí ó sì ń sọ àwọn nǹkan nípa ìjọba Ọlọ́run.” (Ìṣe 1:2, 3) Àwọn kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn rí Jésù tó jíǹde náà nígbà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀—nínú ọgbà, lójú ọ̀nà, lẹ́nu oúnjẹ, lẹ́bàá Òkun Tìbéríà.—Mátíù 28:8-10; Lúùkù 24:13-43; Jòhánù 21:1-23.
Àwọn olùṣelámèyítọ́ kan sọ pé àwọn ò gbà pé ìfarahàn wọ̀nyí wáyé lóòótọ́. Wọ́n ní àwọn tó kọ̀wé ló kàn gbé ìtàn wọ̀nyí jókòó, wọ́n sì ń sọ pé ìtàn wọ̀nyí takora. Ká sòótọ́, ìyàtọ̀ díẹ̀díẹ̀ tó wà nínú àwọn Ìwé Ìhìn Rere jẹ́ ẹ̀rí pé àwọn tó kọ ọ́ kò di rìkíṣí kankan. Òye wa nípa Jésù á túbọ̀ kún sí i ni, nígbà tí òǹkọ̀wé kan bá fún wa ní àfikún ìsọfúnni nípa àwọn àkọsílẹ̀ táwọn yòókù kọ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan nínú ìgbésí ayé Kristi lórí ilẹ̀ ayé.
Ṣé àwọn tó sọ pé àwọn rí Jésù lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀ ń ṣe ìrànrán ni? Kò lè jẹ́ bẹ́ẹ̀ rárá, nítorí ọ̀pọ̀ èèyàn ló rí i. Lára wọn ni àwọn apẹja, àwọn obìnrin, òṣìṣẹ́ ìjọba, àti àpọ́sítélì Tọ́másì oníyèmejì pàápàá, tó jẹ́ pé ìgbà tó rí ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro pé Jésù ti jíǹde kúrò nínú òkú ló tó gbà gbọ́. (Jòhánù 20:24-29) Kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan, kì í ṣe ẹ̀ẹ̀mejì làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kò kọ́kọ́ dá Olúwa wọn tó ti jíǹde náà mọ̀. Nígbà kan, àwọn tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ló rí i, ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn ṣì ń bẹ láàyè nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ẹ̀rí tó ti àjíǹde náà lẹ́yìn.—1 Kọ́ríńtì 15:6.
Jésù Tí Ń Bẹ Láàyè Ń Nípa Lórí Àwọn Èèyàn
Ọ̀ràn nípa àjíǹde Jésù kì í kàn-án ṣe ọ̀ràn fífẹ́ láti mọ fìn-ín ìdí kókò tàbí ká kàn rí nǹkan jiyàn lé lórí lásán. Òtítọ́ náà pé Jésù ń bẹ láàyè ti nípa tó dáa lórí àwọn èèyàn níbi gbogbo. Láti ọ̀rúndún kìíní, àìmọye èèyàn tó ń dágunlá tàbí tó ń gbógun ti ẹ̀sìn Kristẹni tẹ́lẹ̀ ló ti yí padà, wọ́n sì ti wá gbà gbọ́ dájú pé èyí lẹ̀sìn tòótọ́. Kí ló yí wọn padà? Ẹ̀kọ́ Ìwé Mímọ́ ti jẹ́ kí wọ́n rí i pé Ọlọ́run jí Jésù dìde sí ìyè gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí ológo ní ọ̀run. (Fílípì 2:8-11) Wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù àti nínú ètò tí Jèhófà Ọlọ́run ṣe fún ìgbàlà nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Kristi. (Róòmù 5:8) Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ti rí ojúlówó ayọ̀ nípa ṣíṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ àti nípa gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ Jésù.
Ronú nípa ohun tí jíjẹ́ Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní túmọ̀ sí. Kò gbéni dépò iyì àti ipò agbára, bẹ́ẹ̀ ni kò sọni dọlọ́rọ̀. Òdìkejì pátápátá ni, ní ti pé ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ìjímìjí ló ‘fi ìdùnnú gba pípiyẹ́ àwọn nǹkan ìní wọn,’ nítorí ìgbàgbọ́ wọn. (Hébérù 10:34) Ẹ̀sìn Kristẹni ń béèrè fún ìgbésí ayé ìfara-ẹni-rúbọ àti fífarada inúnibíni tó ti yọrí sí kíkú ikú ajẹ́rìíkú ní ọ̀pọ̀ ìgbà.
Kí àwọn kan tó di ọmọlẹ́yìn Kristi, wọ́n ní àǹfààní láti wà ní ipò ọlá, kí wọ́n sì lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀. Sọ́ọ̀lù ará Tásù kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ gbajúgbajà olùkọ́ Òfin tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gàmálíẹ́lì, àwọn Júù sì ti bẹ̀rẹ̀ sí fi ojú ẹni títayọ lọ́lá wo Sọ́ọ̀lù. (Ìṣe 9:1, 2; 22:3; Gálátíà 1:14) Síbẹ̀, Sọ́ọ̀lù di àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Òun àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn kọ ipò ọlá àti agbára tí ayé yìí ń fúnni. Èé ṣe? Kí ó bàa lè ṣeé ṣe fún wọn láti kéde iṣẹ́ ìrètí tòótọ́ táa gbé ka àwọn ìlérí Ọlọ́run àti láti kéde òtítọ́ náà pé a ti jí Jésù Kristi dìde kúrò nínú òkú ni. (Kólósè 1:28) Wọ́n ṣe tán láti jìyà nítorí ohun tí wọ́n mọ̀ pé a gbé karí òtítọ́.
Bákan náà ló rí fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn lónìí. O lè rí wọn nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé. Àwọn Ẹlẹ́rìí fi tìfẹ́tìfẹ́ pè ọ́ wá síbi àṣeyẹ ọdọọdún ti ikú Kristi, èyí tí yóò wáyé lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀ lọ́jọ́ Sunday, April 8, 2001. Inú wọn yóò dùn bí o bá lè wá síbi ayẹyẹ ọ̀hún àti sí gbogbo ìpàdé tí wọ́n ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, èyí tí wọ́n ń ṣe nínú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn.
O ò ṣe kẹ́kọ̀ọ́ síwájú sí i, kì í ṣe kìkì nípa ikú àti àjíǹde Jésù nìkan o, ṣùgbọ́n pẹ̀lúpẹ̀lù nípa ìgbésí ayé rẹ̀ àtàwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀? Ó ń ké sí wa pé ká máa bọ̀ lọ́dọ̀ òun. (Mátíù 11:28-30) Wá nǹkan ṣe nísinsìnyí láti jèrè ìmọ̀ pípéye nípa Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè túmọ̀ sí ìyè ayérayé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run níkàáwọ́ Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ẹ̀rí tó fi hàn pé òótọ́ làwọn Ìwé Ìhìn Rere, wo ọ̀rọ̀ náà “Àwọn Ìwé Ìhìn Rere—Ṣé Ìtàn Gidi Ni Tàbí Àròsọ?” nínú Ilé Ìṣọ́ May 15, 2000.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ti rí ayọ̀ tòótọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 6]
Látinú ìwé Self-Pronouncing Edition of the Holy Bible, tó ní ẹ̀dà King James àti ẹ̀dà Revised nínú