Ìwọ́ Ha Rántí Bí?
Ìwọ́ Ha Rántí Bí?
Ǹjẹ́ o mọrírì kíka àwọn ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ ti ẹnu àìpẹ́ yìí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, wò ó bóyá o lè dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí:
• Èé ṣe tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ìrètí kẹ́yìn àwọn ohun tí ó tò lẹ́sẹẹsẹ sínú Róòmù 5:3-5?
Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan mélòó kan lára àwọn nǹkan táwọn Kristẹni ń nírìírí rẹ̀—ìyẹn ìpọ́njú, ìfaradà, ipò ìtẹ́wọ́gbà, àti ìrètí. “Ìrètí” yìí kì í ṣe ìrètí tẹ́nì kan kọ́kọ́ jèrè nínú Bíbélì, àmọ́ ó jẹ́ ìrètí tó lágbára, tó jinlẹ̀, tó sì ti di ara ẹni, èyí tí Kristẹni kan lè jèrè bí àkókò ti ń lọ.—12/15, ojú ìwé 22, 23.
• Èé ṣe tí Kristẹni kan lóde òní fi lè nífẹ̀ẹ́ sí àwọn eré ìdárayá tí wọ́n máa ń ṣe ní Gíríìsì ìgbàanì?
Lílóye irú àwọn eré ìdárayá wọ̀nyẹn àti bí wọ́n ṣe máa ń ṣe wọ́n lè tan ìmọ́lẹ̀ sórí àwọn ẹsẹ Bíbélì mélòó kan. Àwọn kan lára wọn tọ́ka sí ‘dídíje ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà àfilélẹ̀,’ ‘mímú gbogbo ẹrù wíwúwo kúrò, kí a sì máa wo àpẹẹrẹ Jésù,’ ‘sísáré ní ipa ọ̀nà eré ìje náà dé ìparí’ àti gbígba adé, tàbí ẹ̀bùn náà. (2 Tímótì 2:5; 4:7, 8; Hébérù 12:1, 2; 1 Kọ́ríńtì 9:24, 25; 1 Pétérù 5:4)—1/1, ojú ìwé 28-30.
• Ọ̀nà tó jẹ́ tuntun láti kéde ìhìn rere náà wo ló wá sójú táyé ní January 1914?
Ìgbà yẹn ni wọ́n gbé “Photo-Drama of Creation” [“Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá”] jáde. Èyí tó ní àfihàn alábala mẹ́rin nínú, tí àwòrán tó ń rìn àti ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn àwòrán ara ògiri aláwọ̀ mèremère wà nínú rẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ àwòrán náà ló ń fara hàn bí a ti ń gbọ́ àwọn àsọyé tí wọ́n gbà sílẹ̀ sínú giramafóònù èyí tí ń ṣàlàyé àwòrán náà. Ogún ẹ̀dà àwòkẹ́kọ̀ọ́ yìí ni wọ́n ṣe, wọ́n sì lò wọ́n gan-an láti kọ́ àwọn èèyàn ní ìhìn Bíbélì.—1/15, ojú ìwé 8, 9.
• Báwo ni Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ṣe yàtọ̀ sí àjọ táa fòfin gbé kalẹ̀?
Nígbà tó jẹ́ pé àwọn mẹ́ńbà ló máa ń dìbò yan àwọn olùdarí àjọ tí a fòfin gbé kalẹ̀, ènìyàn kankan kọ́ ló yan Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso bí kò ṣe Jésù Kristi. Kò pọndandan pé kí àwọn olùdarí onírúurú àjọ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò jẹ́ mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso. Níbi ìpàdé ọdọọdún tí Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso tí wọ́n ti ń sìn tẹ́lẹ̀ rí gẹ́gẹ́ bí olùdarí àti alábòójútó, ti fínnúfíndọ̀ fi ipò wọn sílẹ̀. Àwọn arákùnrin tó tóótun nínú àwọn “àgùntàn mìíràn” sì rọ́pò wọn. (Jòhánù 10:16) Nípa bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe fún àwọn mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso láti túbọ̀ lo àkókò sí i fún pípèsè oúnjẹ tẹ̀mí, ó sì ń jẹ́ kí wọ́n lè tipa bẹ́ẹ̀ túbọ̀ máa bìkítà fún àwọn ohun tí ẹgbẹ́ ará jákèjádò ayé ṣaláìní nípa tẹ̀mí.—1/15, ojú ìwé 29, 31.
• Àwọn àpẹẹrẹ méjì wo la lè gbé yẹ̀ wò nínú Bíbélì láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí a ṣe lè borí ìrẹ̀wẹ̀sì?
Ọ̀kan ni ti Hánà, ìyá Sámúẹ́lì. Ì bá ti rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí Élì, àlùfáà àgbà ní Ísírẹ́lì ṣì í lóye. Dípò ìyẹn, ńṣe ló fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ṣàlàyé fún un láìfi ọ̀rọ̀ náà bọpobọyọ̀. Síwájú sí i, Hánà kò di Élì sínú. Ẹnì kejì ni Máàkù, tó ti ní láti rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kò fẹ́ kó tẹ̀ lé wọ́n lọ sí ìrìn àjò míṣọ́nnárì. Dípò tí ì bá fi jẹ́ kí àǹfààní tí òun pàdánù yìí kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá òun, ńṣe ló ń bá iṣẹ́ ìsìn aláápọn rẹ̀ nìṣó, tó ń bá Bánábà rin ìrìn àjò.—2/1, ojú ìwé 20-22.
• Èé ṣe tó fi yẹ káwọn Kristẹni ṣọ́ra nípa fífún àwọn ẹlòmíràn ní ẹ̀dà àkójọ ìlànà tí Kọ̀ǹpútà fi ń ṣiṣẹ́ (computer software programs) tàbí gbígbà á lọ́wọ́ wọn?
Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn àkójọ ìlànà tí kọ̀ǹpútà fi ń ṣiṣẹ́ (títí kan àwọn eré orí kọ̀ǹpútà) ló ní ìwé àṣẹ tó ń béèrè pé kí ẹni tó ni ín tàbí ẹni tó ń lò ó fi àkójọ ìlànà náà sínú kọ̀ǹpútà kan. Ó sábà máa ń jẹ́ rírú òfin oní-nǹkan téèyàn bá ṣe ẹ̀dà rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn, kódà báa tiẹ̀ ń fún wọ́n lọ́fẹ̀ẹ́ pàápàá. Àwọn Kristẹni fẹ́ ṣègbọràn sí òfin, ‘sísan ohun tí í ṣe ti Késárì padà fún Késárì.’ (Máàkù 12:17)—2/15, ojú ìwé 20-22.
• Àwọn wo ni Cyril àti Methodius, ipa wo ni wọ́n sì kó nínú ẹ̀kọ́ Bíbélì?
Àwọn ni tẹ̀gbọ́n tàbúrò tí wọ́n bí ní Tẹsalóníkà, ilẹ̀ Gíríìsì, ní ọ̀rúndún kẹsàn-án. Wọ́n hùmọ̀ ọ̀nà ìkọ̀wé kan fún àwọn tó ń sọ èdè Slavic, wọ́n sì túmọ̀ apá tó pọ̀ jù lọ nínú Bíbélì sí èdè Slavic.—3/1, ojú ìwé 28, 29.
• Kí ni gbólóhùn náà “gbígbé èrò inú ka ẹ̀mí” túmọ̀ sí?—Róòmù 8:6.
Ó túmọ̀ sí jíjẹ́ kí ipá ìṣiṣẹ́ Jèhófà máa darí wa, kó máa ṣàkóso wa, kó sì máa sún wa ṣiṣẹ́. A lè jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa ṣiṣẹ́ lára wa nípa kíka Bíbélì ká sì máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, nípa fífi tọkàntọkàn ṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run, àti nípa gbígbàdúrà fún ẹ̀mí Ọlọ́run.—3/15, ojú ìwé 15.
• Kí la lè ṣe tó bá dà bíi pé àwọn èèyàn ṣì wá lóye?
Ó ṣe pàtàkì láti wá ọ̀nà láti fi ẹ̀mí ìfẹ́ yanjú ọ̀ràn náà. Tó bá dà bíi pé ìyẹn ò kẹ́sẹ járí, má ṣe sọ̀rètí nù. Béèrè òye àti ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Jèhófà, ẹni tí “ń díwọ̀n àwọn ọkàn-àyà.” (Òwe 21:2; 1 Sámúẹ́lì 16:7)—4/1, ojú ìwé 21-23.