A Kò Nìkan Wà Nígbà Táa Dán Ìgbàgbọ́ Wa Wò
A Kò Nìkan Wà Nígbà Táa Dán Ìgbàgbọ́ Wa Wò
Vicky jẹ́ ọmọdébìnrin tí gbogbo èèyàn fẹ́ràn—ara rẹ̀ yá gágá, ojú rẹ̀ gún régé, ó sì ń ta pọ́n-ún pọ́n-ún. Àní, inú wa dùn kọjá ààlà nígbà táa bí i nígbà ìrúwé ọdún 1993. Ìlú kékeré kan ní ìhà gúúsù ilẹ̀ Sweden là ń gbé, nǹkan sì ṣẹnuure fún wa gan-an.
ÀMỌ́, nígbà tí Vicky pé ọmọ ọdún kan ààbọ̀, ìgbésí ayé wa dà bí èyí tó ti polúkúrúmuṣu. Ó ti ń ṣàìsàn fún ọjọ́ bíi mélòó kan, la bá gbé e lọ sílé ìwòsàn. A ò lè gbàgbé ìṣẹ́jú náà tí dókítà sọ fún wa pé akọ àrùn leukemia ni ọmọbìnrin wa ní, ó jẹ́ àrùn jẹjẹrẹ ọmọdé, èyí tó máa ń ba sẹ́ẹ̀lì funfun inú ẹ̀jẹ̀ jẹ́.
Ó ṣòro fún wa láti gbà gbọ́ pé àrùn búburú yìí wà lára ọmọbìnrin wa kékeré. Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gbọ́njú ni, ikú ló sì ń fẹjú mọ́ ọn yìí. Nígbà tí dókítà náà ń gbìyànjú láti tù wá nínú, ó sọ pé àwọn lè fún un ní ìtọ́jú tó máa kẹ́sẹ járí títí dé àyè kan, èyí tó wé mọ́ ìtọ́jú tí wọ́n ń fi èròjà inú kẹ́míkà ṣe àti ọ̀pọ̀ ìfàjẹ̀sínilára. Èyí ló tún wá dá kún jìnnìjìnnì tó bá wa.
A Dán Ìgbàgbọ́ Wa Wò
A nífẹ̀ẹ́ ọmọbìnrin wa gan-an, a sì ń fẹ́ ìtọ́jú ìṣègùn tó dára jù lọ fún un. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ìfàjẹ̀sínilára kò lè wáyé rárá. A nígbàgbọ́ nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gan-an ni, èyí tó sọ ní kedere pé àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ ‘ta kété sí ẹ̀jẹ̀.’ (Ìṣe 15:28, 29) A tún mọ̀ pé ẹ̀jẹ̀ gbígbà sára pàápàá, ewu ni. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ló ti kó àrùn, tí wọ́n sì ti kú nítorí ẹ̀jẹ̀ gbígbà sára. Ohun mìíràn tí wọ́n tún lè ṣe ni pé kó gba ìtọ́jú tó jẹ́ ojúlówó gan-an, tí kò ní ìfàjẹ̀sínilára nínú. Nígbà tọ́rọ̀ wá dé ibi tó dé yìí ni a wá bẹ̀rẹ̀ si ja ìjà ìgbàgbọ́.
Kí wá ni ṣíṣe? A kàn sí Ẹ̀ka Ìpèsè Ìsọfúnni nípa Àwọn Ilé Ìwòsàn ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Sweden, fún ìrànlọ́wọ́. a Ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n lo ẹ̀rọ fax tí ń ṣàdàkọ ìsọfúnni láti ránṣẹ́ sí onírúurú ọsibítù tó wà nílẹ̀ Yúróòpù, tí wọ́n ń bá wa wá ọsibítù àti dókítà tó ṣe tán láti lo ìtọ́jú oníkẹ́míkà láìsí pé ó fa ẹ̀jẹ̀ síni lára. Ìtara àti ìfẹ́ tí àwọn Kristẹni arákùnrin wa fi hàn nígbà tí wọ́n ti ń sapá láti ràn wá lọ́wọ́ fún wa lókun gan-an ni. A kò nìkan wà nínú ìjà táa ń jà fún ìgbàgbọ́.
Láàárín wákàtí mélòó kan, wọ́n ti rí ilé ìwòsàn kan àti dókítà kan ní Homburg/Saar, ní ilẹ̀ Jámánì. Kíá ni wọ́n ṣètò bí a ṣe máa wọkọ̀ òfuurufú lọ síbẹ̀ lọ́jọ́ kejì kí wọ́n lè yẹ Vicky wò. Nígbà táa gúnlẹ̀, àwọn Kristẹni arákùnrin wa tí wọ́n wà ní ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Homburg, àti àwọn kan lára àwọn mọ̀lẹ́bí wa ti wà níbẹ̀ láti kí wa káàbọ̀. Aṣojú Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn ládùúgbò náà sì fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà kí wa káàbọ̀. Ó tẹ̀ lé wa dé ọsibítù ọ̀hún, ó sì bá wa ṣe gbogbo ohun tó yẹ ní ṣíṣe. Ọkàn wa balẹ̀ láti rí i pé kódà ní ilẹ̀ àjèjì pàápàá, a tún ní àwọn arákùnrin nípa tẹ̀mí tó ń ràn wá lọ́wọ́.
Ọkàn wa tún balẹ̀ sí i, nígbà táa dé ọ̀dọ̀ Dókítà Graf. Ó lójú àánú gan-an ni, ó sì mú un dá wa lójú pé òun á ṣe gbogbo ohun tí òun bá lè ṣe láti tọ́jú Vicky láìfa ẹ̀jẹ̀ sí i lára. Kódà bí èròjà pupa inú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tiẹ̀ lọ sílẹ̀ dórí ìwọ̀n dẹ̀sílítà márùn-ún [5 g/dl] péré, ó ṣe tán láti máa bá ìtọ́jú náà lọ láìfa ẹ̀jẹ̀ sí i lára. Ó tún sọ pé bí wọ́n ṣe tètè yẹ Vicky wò, àti ìgbésẹ̀ kíákíá táa gbé láti gbé e wá túbọ̀ jẹ́ kó láǹfààní àtirí ìtọ́jú tó máa kẹ́sẹ járí gbà. Ó jẹ́wọ́ pé ti Vicky yìí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí òun máa lo ìtọ́jú oníkẹ́míkà fúnni láìjẹ́ pé òun fa ẹ̀jẹ̀ síni lára. A dúpẹ́ gan-an, a sì mọrírì ìgboyà Dókítà Graf àti bó ṣe múra tán láti ṣèrànwọ́.
Ìṣòro Ìnáwó
Ìbéèrè tó wá dìde báyìí ni pé, Báwo la ṣe máa sanwó ìtọ́jú Vicky? Orí wa fò lọ nígbà tí wọ́n sọ fún wa pé ìtọ́jú tó máa gba ọdún méjì náà yóò ná wa ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́jọ [150,000] owó ilẹ̀ Jámánì. A ò tiẹ̀ ní iye tó sún mọ́ owó rẹpẹtẹ yẹn lọ́wọ́ rárá, síbẹ̀ ó di dandan láti bẹ̀rẹ̀ ìtọ́jú Vicky lójú ẹsẹ̀. Nígbà táa ti lè fi Sweden sílẹ̀, táa wá gba ìtọ́jú ní Jámánì, a ò lẹ́tọ̀ọ́ sí owó ìbánigbófò ìlera tí ìjọba máa ń fúnni. Báa ṣe wà níbẹ̀ nìyẹn o, pẹ̀lú ọmọbìnrin wa kékeré tó ń ṣàìsàn àti oníṣègùn tó múra tán láti ràn wá lọ́wọ́, àmọ́ owó táa ní lọ́wọ́ kò tó nǹkan.
Ilé ìwòsàn náà wá gbà wá sílẹ̀, wọ́n sọ pé ìtọ́jú náà yóò bẹ̀rẹ̀ lójú ẹsẹ̀ bí a bá lè san ọ̀kẹ́ kan [20,000] owó ilẹ̀ Jámánì sílẹ̀ kí a sì fọwọ́ síwèé pé a ó san èyí tó kù. Owó díẹ̀ tí a ní ní ìpamọ́ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ onífẹ̀ẹ́ látọ̀dọ̀ àwọn ẹbí àtọ̀rẹ́ mú kó ṣeé ṣe fún wa láti san ọ̀kẹ́ kan [20,000] owó ilẹ̀ Jámánì náà—àmọ́ èyí tó kù wá ń kọ́?
Lẹ́ẹ̀kan sí i, a tún rán wa létí pé a kò nìkan wà nínú ìjà táa ń jà fún ìgbàgbọ́. Arákùnrin tẹ̀mí kan, tí a ò tiẹ̀ mọ̀ rárá nígbà yẹn, múra tán láti bá wa san owó tó kù ọ̀hún. Àmọ́, kò ní sídìí láti lo owó ribiribi tó fẹ́ gbé sílẹ̀ yìí, níwọ̀n bó ti ṣeé ṣe fún wa láti ṣe àwọn ètò mìíràn.
Àwọn Ògbógi Nínú Ìmọ̀ Ìṣègùn Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́
Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìtọ́jú oníkẹ́míkà náà. Ọjọ́ ń gorí ọjọ́, ọ̀sẹ̀ ń gorí ọ̀sẹ̀. Ó máa ń ṣòro gan-an, ó sì máa ń tán àwa àti ọmọbìnrin wa lókun nígbà mìíràn. Yàtọ̀ síyẹn, inú wa máa ń dùn gan-an, a sì máa ń dúpẹ́ nígbà táa bá rí àwọn àmì tó fi hàn pé ara rẹ̀ ti ń yá. Ìtọ́jú oníkẹ́míkà náà gba oṣù mẹ́jọ gbáko. Dẹ̀sílítà mẹ́fà [6 g/dl] ni ìwọ̀n èròjà pupa inú ẹ̀jẹ̀ tó kéré jù lọ tí Vicky ní, Dókítà Graf sì mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ.
Ọdún mẹ́fà ti kọjá báyìí, àyẹ̀wò omi inú eegun ẹ̀yìn rẹ̀ táa ṣe kẹ́yìn sì fi hàn pé kò sí ohun tó jọ àrùn leukemia níbẹ̀ mọ́ rárá. Ó ti
di ọmọbìnrin tí inú rẹ̀ ń dùn ṣìnkìn báyìí láìní àmì àrùn náà lára mọ́. Bẹ́ẹ̀ ni o, ìyàlẹ́nu ńlá ló jẹ́ fún wa pé ara Vicky ti yá pátápátá. A mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ọmọdé ni àrùn yìí máa ń pa, bí wọ́n tiẹ̀ gba ìtọ́jú oníkẹ́míkà, táa sì fàjẹ̀ sí wọn lára.A ti ṣẹ́gun ìjà ìgbàgbọ́ tí a ń jà, àmọ́ kì í ṣe láìsí ìrànlọ́wọ́ àwọn ẹbí, àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin, àtàwọn ògbógi onímọ̀ ìṣègùn o. Ẹ̀ka Ìpèsè Ìsọfúnni fún Àwọn Ilé Ìwòsàn kò fi wá sílẹ̀ ní ìṣẹ́jú kan. Dókítà Graf àtàwọn alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀ lo òye iṣẹ́ wọn láti rí i pé ara Vicky yá. A dúpẹ́ gan-an fún gbogbo èyí.
A Ti Fún Ìgbàgbọ́ Wa Lókun
Àmọ́ ṣá o, lékè gbogbo rẹ̀, a dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, Ọlọ́run wa, nítorí ìtọ́jú onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ lórí wa, àti okun táa rí gbà nípasẹ̀ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Nígbà táa bá bojú wẹ̀yìn, a ń rí i pé a ti kẹ́kọ̀ọ́ ohun tó pọ̀ gan-an, a sì tún rí i bí ìrírí líle koko táa ní yìí ṣe fún ìgbàgbọ́ wa lókun.
Ohun tó jẹ́ olórí àníyàn àtọkànwá wa báyìí ni pé ká má ṣe jẹ́ kí àjọṣe táa ní pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run yingin, ká sì tún kọ́ ọmọbìnrin wa ní ìjẹ́pàtàkì gbígbé ìgbésí ayé tó wà níbàámu pẹ̀lú àwọn ohun tí Ọlọ́run béèrè. Dájúdájú, a fẹ́ fún un ní ogún tẹ̀mí tó dára kí ó lè rí ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè tó ń bọ̀ lórí ilẹ̀ ayé níhìn-ín.—A kọ ọ́ ránṣẹ́.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ẹ̀ka Ìpèsè Ìsọfúnni nípa Àwọn Ilé Ìwòsàn ló ń bójú tó iṣẹ́ Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn kárí ayé. Àwọn Kristẹni tó yọ̀ǹda ara wọn ni àwọn tó wà ní ẹ̀ka yìí, àwọn táa ti dá lẹ́kọ̀ọ́ nípa bí a ṣe ń fún àwọn oníṣègùn níṣìírí láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìsàn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó lé ní egbèje [1,400] Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn tó ń ran àwọn aláìsàn lọ́wọ́ ní ohun tó lé ní igba ilẹ̀.