O Lè Kẹ́sẹ Járí Láìka Bí Wọ́n Ṣe Tọ́ Ẹ Dàgbà Sí
O Lè Kẹ́sẹ Járí Láìka Bí Wọ́n Ṣe Tọ́ Ẹ Dàgbà Sí
ÀTIKÉKERÉ nìwà ọ̀tẹ̀ ti wà nínú Nicholas. a Nígbà tó yá, àwọn èròkérò tó ń jà gùdù nínú rẹ̀ sún un di ẹni tó ń joògùn yó, tó sì ń mutí lámujù. Nicholas ṣàlàyé pé: “Onímukúmu ni baba mi, ó sì kó ìyà púpọ̀ jẹ èmi àti arábìnrin mi.”
Nítorí ohun táwọn èèyàn mọ̀ nípa àwọn òbí Malinda, ẹni iyì ni wọ́n láwùjọ, wọn kì í sì í pa ṣọ́ọ̀ṣì jẹ. Àmọ́, wọ́n tún jẹ́ ògbólógbòó nínú ẹgbẹ́ òkùnkùn. Malinda, tó ti lé lẹ́ni ọgbọ̀n ọdún báyìí kédàárò pé: “Àwọn kan lára ohun tí wọ́n ń ṣe nínú ẹgbẹ́ òkùnkùn wọn máa ń kó mi nírìíra, ó sì máa ń kó ìdààmú bá mi nígbà tí mo wà lọ́mọdé.” Ó fi kún un pé: “Àtìgbà ti mo ti lè rántí nǹkan ni èrò àìnírètí àti ìmọ̀lára àìjámọ́ nǹkan kan tí wọ́n gbìn sí mi lọ́kàn ti máa ń nípa lórí mi.”
Ta ló lè sẹ́ pé ìgbà ọmọdé ọ̀pọ̀ èèyàn ló kún fún ìwà ipá, ìfìyàjẹni, àìbìkítà àwọn òbí, àti àwọn ohun búburú mìíràn? Ọgbẹ́ ìgbà ọmọdé tó kún fún ìbànújẹ́ kì í jiná bọ̀rọ̀. Àmọ́, ǹjẹ́ ó yẹ kí irú ìbànújẹ́ bẹ́ẹ̀ ṣàkóbá ayérayé fún ṣíṣe tí ó ṣeé ṣe fún ẹnì kan láti tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kó sì rí ayọ̀ tó jọjú? Láìka bí a ṣe tọ́ wọn dàgbà sí, ǹjẹ́ Nicholas àti Malinda lè kẹ́sẹ járí gẹ́gẹ́ bí oníwà títọ́? Kọ́kọ́ gbé àpẹẹrẹ Jòsáyà, Ọba Jùdíà yẹ̀ wò ná.
Àpẹẹrẹ Kan Látinú Ìwé Mímọ́
Jòsáyà ṣàkóso Júdà fún ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n ní ọ̀rúndún keje ṣááju Sànmánì Tiwa (659 sí 629 ṣááju Sànmánì Tiwa.) Ipò nǹkan burú jáì ní Júdà lákòókò tí Jòsáyà gorí oyè, lẹ́yìn tí wọ́n pa baba rẹ̀. Júdà àti Jerúsálẹ́mù kún fún àwọn olùjọsìn Báálì àtàwọn tó ń fi Málíkámù, ọlọ́run pàtàkì àwọn Ámónì, búra. Sefanáyà, wòlíì Ọlọ́run láyé ìgbà yẹn sọ pé, àwọn ọmọ aládé Jùdíà jẹ́ “kìnnìún tí ń ké ramúramù,” àwọn onídàájọ́ rẹ̀ sì jẹ́ “ìkookò ìrọ̀lẹ́.” Nípa bẹ́ẹ̀, ìwà ipá àti ẹ̀tàn kún gbogbo ilẹ̀ náà. Ọ̀pọ̀ ń sọ lọ́kàn wọn pé: “Jèhófà kì yóò ṣe rere, kì yóò sì ṣe búburú.”—Sefanáyà 1:3-2:3; 3:1-5.
Irú alákòóso wo ni Jòsáyà wá jẹ́? Òǹkọ̀wé ìtàn Bíbélì nì, Ẹ́sírà, kọ̀wé pé: “[Jòsáyà] bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà, ó sì ń rìn ní àwọn ọ̀nà Dáfídì baba ńlá rẹ̀; kò sì yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì.” (2 Kíróníkà 34:1, 2) Ó hàn gbangba pé Jòsáyà kẹ́sẹ járí ní ṣíṣe ohun tí ó tọ́ lójú Ọlọ́run. Àmọ́, inú ìdílé wo ló ti wá?
Ṣé Ìgbà Ọmọdé Tó Dára Ni Tàbí Èyí Tó Burú?
Nígbà tí wọ́n bí Jòsáyà ní ọdún 667 ṣááju Sànmánì Tiwa, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún péré ni Ámọ́nì, tó jẹ́ baba rẹ̀, Mánásè, tí í ṣe baba rẹ̀ àgbà ló sì ń jọba ní Júdà nígbà náà. Mánásè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọba tó burú jù lọ tó ṣàkóso lórí Júdà. Ó tẹ́ àwọn pẹpẹ fún Báálì, àní “ní ìwọ̀n tí ó bùáyà ni ó ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà.” Ó mú àwọn ọmọ rẹ̀ la iná já, ó ṣe iṣẹ́ òkùnkùn, ó woṣẹ́, ó gbé ìbẹ́mìílò lárugẹ, ó sì ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀. Mánásè tún kó àwọn ère gbígbẹ́ òpó ọlọ́wọ̀ tó ti ṣe wá sínú ilé Jèhófà. Ó sún Júdà àti Jerúsálẹ́mù “láti ṣe ohun tí ó burú ju ti àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà pa rẹ́ ráúráú kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”—2 Kíróníkà 33:1-9.
Mánásè burú tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí Jèhófà fi jẹ́ kí wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ dè é lọ́ sí Bábílónì, tó jẹ́ ọ̀kan 2 Kíróníkà 33:10-17.
lára àwọn ìlú ńlá ọba àwọn ará Ásíríà. Nígbà tí Mánásè wà nígbèkùn, ó ronú pìwà dà, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì tọrọ ìdáríjì lọ́dọ̀ Jèhófà. Ọlọ́run gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ fún ojú rere, ó sì mú un padà bọ̀ sípò ọba ní Jerúsálẹ́mù. Mánásè wá tún àwọn nǹkan ṣe, ó sì kẹ́sẹ járí láwọn ọ̀nà kan.—Ipa wo ni ìwà búburú Mánásè àti bó ṣe wá ronú pìwà dà níkẹyìn ní lórí Ámọ́nì, ọmọ rẹ̀? Òun náà tún wá burú bògìrì. Nígbà tí Mánásè ronú pìwà dà, tó sì sapá láti fọ gbogbo ẹ̀gbin tí òun fúnra rẹ̀ ti ṣe mọ́ kúrò ní orílẹ̀-èdè náà, Ámọ́nì ò tiẹ̀ ṣe bí ẹni pé òun rí i. Bí Ámọ́nì ṣe jogún ìtẹ́ náà lọ́mọ ọdún méjìlélógún ló “bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà, gan-an gẹ́gẹ́ bí Mánásè baba rẹ̀ ti ṣe.” Dípò tí ì bá fi rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Jèhófà, “Ámọ́nì jẹ́ ẹni tí ó mú kí ẹ̀bi pọ̀ sí i.” (2 Kíróníkà 33:21-23) Ọmọ ọdún mẹ́fà péré ni Jòsáyà nígbà tí Ámọ́nì di ọba Júdà. Ẹ ò rí i pé nǹkan ò dáa rárá nígbà tí Jòsáyà wà lọ́mọdé!
Ìṣàkóso burúkú ti Ámọ́nì dópin lẹ́yìn ọdún méjì, nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dìtẹ̀ mọ́ ọn, tí wọ́n sì pa á. Àmọ́, àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà pa àwọn tó dìtẹ̀ mọ́ Ámọ́nì, wọ́n sì fi Jòsáyà, ọmọ rẹ̀, jọba.—2 Kíróníkà 33:24, 25.
Láìfi gbogbo ipò búburú tó yí i ká nígbà ọmọdé pè, Jòsáyà bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tó dára lójú Jèhófà. Ìṣàkóso rẹ kẹ́sẹ járí gan-an tí Bíbélì fi sọ pé: “Kò sí ọba kankan bí tirẹ̀, tí ó fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ̀ àti gbogbo ọkàn rẹ̀ àti gbogbo okunra rẹ̀ padà sọ́dọ̀ Jèhófà, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo òfin Mósè; bẹ́ẹ̀ ni kò tíì sí ìkankan tí ó dìde bí tirẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.”—2 Àwọn Ọba 23:19-25.
Àpẹẹrẹ wíwúnilórí ni Jòsáyà mà jẹ́ o, fún àwọn tó ti fara da ipò tó burú jáì nígbà tí wọ́n wà lọ́mọdé! Ẹ̀kọ́ wo la lè kọ́ nínú àpẹẹrẹ rẹ̀? Kí ló ran Jòsáyà lọ́wọ́ láti yan ipa ọ̀nà rere, tó sì ń bá a lọ bẹ́ẹ̀?
Wá Ọ̀nà Láti Mọ Jèhófà
Ọ̀kan lára àwọn ohun tó ní ipa rere lórí Jòsáyà nígbà tó wà lọ́mọdé ni bí Mánásè, baba rẹ̀ àgbà, ṣe ronú pìwà dà. Bíbélì kò sọ bí àwọn méjèèjì ṣe wà pa pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni kò sọ ọjọ́ orí Jòsáyà nígbà tí Mánásè tún àwọn ọ̀nà rẹ̀ ṣe. Níwọ̀n bí ìdílé àwọn Júù ti máa ń sún mọ́ra, Mánásè ti lè gbìyànjú láti dáàbò bo ọmọ ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ohun tí ń sọni dìbàjẹ́ tó yí i ka, nípa gbígbin ọ̀wọ̀ fún Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́, àti ọ̀rọ̀ rẹ̀ sínú ọkàn-àyà rẹ̀. Ó ṣeé ṣé kó jẹ́ pé àwọn irúgbìn òtítọ́ tí Mánásè gbìn sọ́kàn Jòsáyà, pa pọ̀ mọ́ àwọn ipa tó dára mìíràn ló wá so èso rere níkẹyìn. Nígbà tó di ọdún kẹjọ tó ti wà lórí ìtẹ́ Júdà, Jòsáyà, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, bẹ̀rẹ̀ sí wá ọ̀nà láti mọ Jèhófà àti láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.—2 Kíróníkà 34:1-3.
Kìkì àǹfààní tẹ̀mí táwọn kan ní ní kékeré kò ju èyí tí wọ́n rí nípasẹ̀ ìbátan tó jìnnà sí wọn, tàbí nípasẹ̀ ojúlùmọ̀ kan, tàbí aládùúgbò kan. Síbẹ̀, bí wọ́n bá mú un dàgbà, irúgbìn tí wọ́n gbìn yẹn lè so èso rere tó bá yá. Malinda, táa mẹ́nu kàn níṣàájú, ní aládùúgbò kan tó dà bíi baba àgbà fún un, tó máa ń mú àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! wá sílé rẹ̀ déédéé. Bí inú rẹ̀ ṣe ń dùn nígbà tó rántí bàbá yìí, ó sọ pé: “Ohun tó wú mi lórí jù nípa aládùúgbò mi ni pé kì í ṣọdún. Èyí ṣe pàtàkì sí mi nítorí pé Halloween àtàwọn ọdún mìíràn jẹ́ àkókò tí wọ́n fi máa ń ṣe ààtò awo nínú ẹgbẹ́ òkùnkùn táwọn òbí mi wà.” Ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn náà, nígbà tí ọ̀rẹ́ kan ké sí Malinda láti wá sí ìpàdé Kristẹni ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó rántí aládùúgbò rẹ̀ yìí, ó sì tẹ́wọ́ gba ìkésíni náà. Ìyẹn ràn án lọ́wọ́ láti wá òtítọ́.
Rẹ Ara Rẹ Sílẹ̀ Níwájú Ọlọ́run
Àwọn àtúnṣe ìsìn ló gbòde kan nílẹ̀ Júdà lákòókò tí Jòsáyà ń ṣàkóso. Lẹ́yìn tí Jòsáyà ti fi ọdún mẹ́fà gbógun ti ìbọ̀rìṣà, tó sì fọ ilẹ̀ Júdà mọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí tún ilé Jèhófà ṣe. Nígbà tíṣẹ́ yẹn ń lọ lọ́wọ́, họ́wù, Hilikáyà, Àlùfáà Àgbà, ṣàwárí ohun iyebíye kan! Ó rí ẹ̀dà ìpilẹ̀ṣẹ̀ “ìwé òfin Jèhófà.” Hilikáyà fi ohun iyebíye tí wọ́n rí yìí síkàáwọ́ Ṣáfánì akọ̀wé, Ṣáfánì sì lọ ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ fún ọba. Ǹjẹ́ irú àṣeyọrí bẹ́ẹ̀ mú kí Jòsáyà, ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, jọ ara rẹ̀ lójú?—2 Kíróníkà 34:3-18.
Ẹ́sírà kọ̀wé pé: “Gbàrà tí ọba gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ òfin náà, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó gbọn ẹ̀wù ara rẹ̀ ya.” Ìbànújẹ́ tó ti ọkàn wá lèyí, nítorí ó mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo àṣẹ Ọlọ́run ni àwọn baba ńlá àwọn pa mọ́. Ní ti tòótọ́, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ gbáà nìyí! Ojú ẹsẹ̀ ni ọba yan aṣojú márùn-ún láti lọ wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà nípasẹ̀ Húlídà, wòlíì obìnrin. Àwọn aṣojú náà wá jábọ̀, ohun tí wọ̀n sì sọ ní ṣókí ni pé: ‘Àjálù ń bọ̀ nítorí àìgbọràn tí ẹ ṣe sí Òfin Jèhófà. Àmọ́ nítorí pé ìwọ, Jòsáyà Ọba, rẹ ara rẹ sílẹ̀, a ó kó ọ jọ sínú itẹ́ rẹ ní àlàáfíà, ojú rẹ kì yóò sì rí àjálù náà.’ (2 Kíróníkà 34:19-28) Inú Jèhófà dùn sí ìṣarasíhùwà Jòsáyà.
Láìka bí a ṣe tọ́ wá dàgbà sí, àwa náà lè rẹ ara wa sílẹ̀ níwájú Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́, ká ní ẹ̀mí ìtẹríba fún un, ká sì máa fojú ribiribi wo Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Nicholas táa mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀ ṣe èyí. Ó sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbésí ayé mi ti dìdàkudà, nítorí ìjoògùnyó àti ọtí àmupara, síbẹ̀ mo nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì, mo sì ń wá bí ìgbésí ayé mi ṣe máa ní ète nínú. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, mo bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé, mo yí ìgbésí ayé mi padà, mo sì gba òtítọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni o, a lè ní ẹ̀mí ìtẹríba fún Ọlọ́run, ká sì máa fojú ribiribi wo Ọ̀rọ̀ rẹ̀, láìfi àyíká wa pè.
Jíjàǹfààní Látinú Ètò Tí Jèhófà Ṣe
Jòsáyà tún ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún àwọn wòlíì Jèhófà. Kì í ṣe pé ó lọ wádìí lọ́dọ̀ Húlídà wòlíì obìnrin nìkan ni, àmọ́ àwọn wòlíì mìíràn tó wà nígbà ayé rẹ̀ nípa lórí rẹ̀ gan-an. Fún àpẹẹrẹ, láìdábọ̀ ni Jeremáyà àti Sefanáyà ń kéde ìdájọ́ sórí ìbọ̀rìṣà táwọn èèyàn ń ṣe ní Júdà. Ẹ ò rí i pé fífiyè sí ìhìn wọn ti ní láti fún Jòsáyà lágbára nígbà tó ń gbógun ti ìjọsìn èké!—Jeremáyà 1:1, 2; 3:6-10; Sefanáyà 1:1-6.
“Ọ̀gá” náà, Jésù Kristi, ti yan ẹgbẹ́ àwọn Mátíù 24:45-47) Nípasẹ̀ àwọn ìtẹ̀jáde táa gbé ka Bíbélì àti ìgbòkègbodò tí ìjọ ń ṣe, ẹrú náà ń pe àfiyèsí sí àwọn àǹfààní tó wà nínú kíkọbi ara sí ìmọ̀ràn Bíbélì, ó sì tún ń fúnni nímọ̀ràn tó gbéṣẹ́ nípa bí a ṣe lè fi í sílò nínú ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́. Ẹ ò rí i pé ó dára gan-an pé ká lo ètò tí Jèhófà ṣe láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè borí ìwà èyíkéyìí tó kù díẹ̀ káàtó tó ti fẹ́ mọ́ wa lára! Àtikékeré ni Nicholas ti kórìíra àwọn aláṣẹ. Kódà bó ti ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àìlera yìí kò jẹ́ kó sin Jèhófà dójú ìwọ̀n. Ìṣòro ńlá ló jẹ́ fún un láti yí ìṣarasíhùwà yìí padà. Ṣùgbọ́n, bí àkókò ti ń lọ, ó kẹ́sẹ járí. Lọ́nà wo? Nicholas ṣàlàyé pé: “Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn alàgbà méjì tó jẹ́ olóye, mo gbà pé mo ní ìṣòro yẹn, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tí wọ́n fún mi láti inú Ìwé Mímọ́ sílò.” Ó fi kún un pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbínú díẹ̀díẹ̀ máa ń wáyé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, mo ti kó ẹ̀mí ọ̀tẹ̀ tí mo ní níjàánu báyìí.”
ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ẹni àmì òróró—“ẹrú olóòótọ́ àti olóye”—láti pèsè oúnjẹ tẹ̀mí ní àkókò tó bẹ́tọ̀ọ́ mu. (Malinda náà ń gba ìmọ̀ràn àwọn alàgbà nígbàkigbà tó bá ń ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Ó wá rí i pé àwọn onírúurú àpilẹ̀kọ tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ni ohun tó ṣeyebíye jù lọ tí òun lè lò láti fi borí èrò àìnírètí àti ìmọ̀lára àìjámọ́ nǹkan kan tó ti ní láti kékeré. Ó sọ pé: “Nígbà mìíràn, ó lè jẹ́ ìpínrọ̀ kan ṣoṣo tàbí gbólóhùn kan—ìyẹn kókó kan péré—nínú àpilẹ̀kọ kan ló máa wọ̀ mí lákínyẹmí ara. Ní nǹkan bí ọdún mẹ́sàn-án sẹ́yìn, mo bẹ̀rẹ̀ sí fi irú àwọn àpilẹ̀kọ bẹ́ẹ̀ pa mọ́ sínú ìwé tó lè mú un rọrùn fún mi láti yẹ̀ wọ́n wò.” Lónìí, àwọn ìwé náà ti pé mẹ́ta tí wọ́n sí ti ní nǹkan bí irínwó [400] àpilẹ̀kọ́ nínú!
Rárá o, kò túmọ̀ sí pé ayé àwọn tí ìdílé wọn ò dáa látilẹ̀wá ti bàjẹ́ pátápátá. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, wọ́n lè kẹ́sẹ járí nípa tẹ̀mí. Gan-an gẹ́gẹ́ bí títọ́ni dàgbà lọ́nà tó dára kò ṣe túmọ̀ sí pé ẹnì kan máa pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni jíjẹ́ ọmọdé tí a kò tọ́ dáadáa kò sọ pé kéèyàn má di olùbẹ̀rù Ọlọ́run.
Lẹ́yìn tí wọ́n ṣàwárí ìwé òfin náà nígbà tí wọ́n ń tún tẹ́ńpìlì ṣe lọ́wọ́, Jòsáyà ‘bẹ̀rẹ̀ sí dá májẹ̀mú níwájú Jèhófà pé òun yóò máa fi gbogbo ọkàn-àyà àti gbogbo ọkàn òun tọ Jèhófà lẹ́yìn, àti pé òun yóò máa ṣègbọràn sí i.’ (2 Kíróníkà 34:31) Kò sì yẹsẹ̀ kúrò nínú ìpinnu yìí títí dọjọ́ ikú rẹ̀. Malinda àti Nicholas náà ti pinnu láti dúró ṣinṣin ti Jèhófà Ọlọ́run, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ kẹ́sẹ járí bí olùpa ìwà títọ́ mọ́. Ǹjẹ́ kí ìwọ náà sún mọ́ Ọlọ́run, kí o sì fi tòótọ́tòótọ́ sìn ín. Fọkàn balẹ̀, wàá kẹ́sẹ járí, nítorí Jèhófà ṣèlérí pé: “Má fòyà, nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ. Má wò yí ká, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Dájúdájú, èmi yóò fi okun fún ọ. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́. Èmi yóò fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin ní ti tòótọ́.”—Aísáyà 41:10, 13.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbà ọmọdé Jòsáyà burú jáì, síbẹ̀ ó wá ọ̀nà láti mọ Jèhófà, ó sì kẹ́sẹ járí nínú ìgbésí ayé rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Àwọn alàgbà lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣẹ́pá àwọn ìwà tó ti di bára kú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
“Ilé Ìṣọ́” àti “Jí!” lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti pa ìwà títọ́ mọ́