Ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run Lórí Ọ̀ràn Yíyan Ẹni Tí a Óò Fẹ́
Ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run Lórí Ọ̀ràn Yíyan Ẹni Tí a Óò Fẹ́
“Èmi yóò mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye, èmi yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà tí ìwọ yóò máa tọ̀. Dájúdájú, èmi yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.”—SÁÀMÙ 32:8.
1. Àwọn kókó wo ló ṣe pàtàkì kí ìdílé tó lè tòrò?
ÀWỌN onílù bẹ̀rẹ̀ sí lùlù. Obìnrin olóhùn iyọ̀ kan wá tẹnu bọ orin. Gbogbo rẹ̀ wá di orin àgbọ́máleèlọ, tó dùn yùngbà-yungba. Àwọn ọkùnrin méjì bẹ̀rẹ̀ sí já àwọn páálí ọjà tó wúwo látinú ọkọ̀ ńlá kan. Ọ̀kan ń ju àwọn páálí náà sí èkejì, pọ́nkán sì ni ìyẹn ń hán an, tí á tún máa retí òmíràn. Wọ́n ní ohun téèyàn bá mọ̀ ọ́n ṣe, bí idán ló ń rí. Àmọ́, ta ní jẹ́ ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀, láìkọ́kọ́ fi dánra wò, tàbí láìní ẹnì kejì tó dáńgájíá, pàápàá jù lọ bí kò bá sí ìtọ́sọ́nà tàbí ìtọ́ni yíyẹ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó lè dà bí ẹni pé ńṣe ni nǹkan ṣèèṣì bọ́ sí i fún ẹni tí ìdílé rẹ̀ tòrò minimini. Àmọ́, kò ṣàì sinmi lórí níní ọkọ tàbí aya rere, ìsapá àjùmọ̀ṣe, àti ní pàtàkì jù lọ, ó sinmi lórí ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n. Àní sẹ́, ìtọ́sọ́nà yíyẹ ṣe kókó.
2. (a) Ta ló dá ètò ìgbéyàwó sílẹ̀, fún ète wo sì ni? (b) Báwo làwọn kan ṣe ń ṣètò ìgbéyàwó?
2 Kì í ṣe nǹkan àjèjì pé kí ọ̀dọ́kùnrin tàbí ọ̀dọ́bìnrin tí kò tíì ṣègbéyàwó máa ronú nípa ẹni tí òun máa fẹ́—ìyẹn ẹni tí wọ́n jọ máa bára wọn kalẹ́. Ìgbéyàwó láàárín ọkùnrin àti obìnrin ni ọ̀nà ìgbésí ayé tó mọ́ àwa èèyàn lára látìgbà tí Jèhófà Ọlọ́run ti dá ètò yìí sílẹ̀. Ṣùgbọ́n kì í ṣe Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́, ló yan aya tó fẹ́. Jèhófà ló fi tìfẹ́tìfẹ́ fún un láya. (Jẹ́nẹ́sísì 2:18-24) Ète rẹ̀ ni pé kí tọkọtaya àkọ́kọ́ yẹn máa bí sí i, kí wọ́n sì fi ẹ̀dá ènìyàn kún ayé nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín. Lẹ́yìn ìgbéyàwó àkọ́kọ́ yẹn, àwọn òbí ọkọ àti ti ìyàwó ló sábà máa ń ṣètò ìgbéyàwó, èyí sì máa ń jẹ́ lẹ́yìn tí àwọn méjèèjì tó fẹ́ wọnú ìdè ìgbéyàwó bá ti gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 21:21; 24:2-4, 58; 38:6; Jóṣúà 15:16, 17) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ní àwọn ilẹ̀ kan, ó ṣì wọ́pọ̀ kí wọ́n máa báni yan ẹni tí a óò fẹ́, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló ń fúnra wọn yan ẹni tí wọ́n fẹ́ẹ́ fẹ́.
3. Báwo ló ṣe yẹ ká yan ẹni tí a óò fẹ́?
3 Báwo ló ṣe yẹ ká yan ẹni tí a óò fẹ́? Ohun táwọn kan ń wò ni ìrísí—bí ojú onítọ̀hún ṣe gún régé, tó sì fani mọ́ra tó. Àwọn míì ń wá ẹni tó rí jájẹ, ẹni táá lè tọ́jú wọn dáadáa, táá sì lè pèsè àwọn nǹkan tí wọ́n nílò àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n fẹ́. Ṣùgbọ́n èyíkéyìí nínú àwọn ọ̀nà wọ̀nyí nìkan ha lè yọrí sí àjọṣe aláyọ̀ tó fini lọ́kàn balẹ̀? Ìwé Òwe 31:30 sọ pé: “Òòfà ẹwà lè jẹ́ èké, ẹwà ojú sì lè jẹ́ asán; ṣùgbọ́n obìnrin tí ó bẹ̀rù Jèhófà ni ẹni tí ó gba ìyìn fún ara rẹ̀.” Kókó tó ṣe pàtàkì gan-an nìyẹn, pé: A ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ rọ́ Jèhófà sẹ́yìn nígbà táa bá fẹ́ yan ẹni tí a óò fẹ́.
Ìtọ́sọ́nà Onífẹ̀ẹ́ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run
4. Ìrànlọ́wọ́ wo ni Ọlọ́run pèsè lórí ọ̀ràn yíyan ẹni tí a óò fẹ́?
4 Jèhófà, Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́, ti pèsè Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó wà ní àkọsílẹ̀ láti fi tọ́ wa sọ́nà nínú gbogbo ọ̀ràn. Ó sọ pé: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn.” (Aísáyà 48:17) Ìdí nìyẹn tí kò fi yani lẹ́nu pé àwọn ìtọ́sọ́nà tó dáńgájíá wà nínú Bíbélì fún yíyan ẹni tí a óò fẹ́. Jèhófà fẹ́ kí ìgbéyàwó wa jẹ́ aláyọ̀, kí ó má sì tú ká. Ìyẹn ló jẹ́ kó pèsè ìrànlọ́wọ́ fún wa láti lóye ìtọ́sọ́nà wọ̀nyí, ká sì mú wọn lò. Ǹjẹ́ ìyẹn kọ́ ló yẹ ká retí látọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́?—Sáàmù 19:8.
5. Kí lohun tó ṣe kókó tí ìgbéyàwó fi lè ní ayọ̀ pípẹ́ títí?
5 Nígbà tí Jèhófà dá ètò ìgbéyàwó sílẹ̀, ìdè alọ́májàá ló pète pé kó jẹ́. (Máàkù 10:6-12; 1 Kọ́ríńtì 7:10, 11) Ìdí nìyẹn tó fi “kórìíra ìkọ̀sílẹ̀,” àfi tí ẹnì kan bá ṣe “àgbèrè.” (Málákì 2:13-16; Mátíù 19:9) Nítorí náà, yíyan ẹni tí a óò fẹ́ jẹ́ ọ̀kan lára ìgbésẹ̀ tó wúwo jù lọ láti gbé, kì í sì í ṣe ọ̀ràn ṣeréṣeré. Ṣàṣà làwọn ìpinnu tí à ń ṣe tó lè yọrí sí yálà ayọ̀ tàbí ìbànújẹ́ bíi ti ìgbéyàwó. Nígbà tó jẹ́ pé yíyan ẹni tó dáa lè fi kún adùn ìgbésí ayé, kí ó sì mú kí ayé ẹni tòrò, yíyan ẹni tí kò dáa lè mú ìbànújẹ́ ayérayé báni. (Òwe 21:19; 26:21) Bí a kò bá ní pàdánù ayọ̀ wa, ó pọndandan láti fọgbọ́n ṣe yíyàn náà, ká sì múra tán láti wọnú àdéhùn tí yóò wà pẹ́ títí, nítorí pé ètò tí Ọlọ́run ṣe ni pé kí ìgbéyàwó jẹ́ àjọṣe aláásìkí, níbi tí ìfohùnṣọ̀kan àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ yóò wà.—Mátíù 19:6.
6. Èé ṣe tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin àti ọ̀dọ́bìnrin ní pàtàkì fi ní láti ṣọ́ra nígbà tí wọ́n bá fẹ́ yan ẹni tí wọn óò fẹ́, báwo sì ni wọ́n ṣe lè ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání jù lọ?
6 Ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn ọ̀dọ́kùnrin àti ọ̀dọ́bìnrin má ṣe jẹ́ kí ẹwà ojú àti òòfà àtinúwá ru bò wọ́n lójú nígbà tí wọ́n bá fẹ́ yan ẹni tí wọn óò fẹ́. Kò sí àní-àní pé àjọṣe táa bá gbé ka kìkì àwọn nǹkan wọ̀nyẹn kò ní pẹ́ dìdàkudà tàbí kó wá kún fún ìkórìíra pàápàá. (2 Sámúẹ́lì 13:15) Lódìkejì ẹ̀wẹ̀, a lè mú ìfẹ́ tó lágbára dàgbà báa ti túbọ̀ ń mọ ọkọ tàbí aya wa, táa sì túbọ̀ ń mọ irú ẹni tí àwa fúnra wa jẹ́. Ó tún yẹ ká mọ̀ pé ó lè máà jẹ́ ohun tó máa ṣe wá láǹfààní jù lọ ni ọkàn wa máa fà sí. (Jeremáyà 17:9) Ìdí nìyẹn tí ìtọ́sọ́nà tó ń ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, èyí tó wà nínú Bíbélì fi ṣe pàtàkì gidigidi. Ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti mọ báa ṣe lè ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání jù lọ nínú ìgbésí ayé. Onísáàmù náà gbẹnu sọ fún Jèhófà nígbà tó sọ pé: “Èmi yóò mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye, èmi yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà tí ìwọ yóò máa tọ̀. Dájúdájú, èmi yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.” (Sáàmù 32:8; Hébérù 4:12) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìgbéyàwó lè tẹ́ àìní àdánidá táa ní fún ìfẹ́ àti ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ lọ́rùn, ṣùgbọ́n ó tún ń fa àwọn ìṣòro tó ń béèrè ìdàgbàdénú àti agbára ìmòye.
7. Kí nìdí táwọn kan kì í fi í gba ìmọ̀ràn táa fún wọn látinú Bíbélì nípa yíyan ẹni tí wọn óò fẹ́, ṣùgbọ́n kí ni irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè yọrí sí?
7 Ohun tó mọ́gbọ́n dání ni láti tẹ́tí sí ohun tí Olùdásílẹ̀ ìgbéyàwó ní í sọ lórí ọ̀ràn yíyan ẹni tí a óò fẹ́. Ṣùgbọ́n a lè ranrí nígbà tí àwọn òbí tàbí àwọn Kristẹni alàgbà bá fún wa ní ìmọ̀ràn tó wá látinú Bíbélì. A lè ronú pé ṣe ni wọn ò lóye wa délẹ̀délẹ̀, ìfẹ́ tó kó sí wa lórí sì lè jẹ́ ká fi ìwàǹwára tẹ̀ lé ìtẹ̀sí ọkàn wa. Àmọ́, nígbà tójú wa bá wá dá tán, a lè wá ti ìka àbámọ̀ bọnu, pé ká ní a mọ̀ ni à bá ti gba ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí wọ́n fún wa fún ire ara wa. (Òwe 23:19; 28:26) A lè wá bá ara wa nínú ìgbéyàwó tí kò ti sí ìfẹ́, pẹ̀lú àwọn ọmọ tó ni wá lára láti tọ́jú, bóyá pẹ̀lú ọkọ tàbí aya aláìgbàgbọ́ pàápàá. Á mà bani nínú jẹ́ o, tí ètò tí ì bá mú ayọ̀ ńláǹlà bá wa bá di èyí tó kó wàhálà tó pọ̀ gan-an bá wa!
Ìfọkànsin Ọlọ́run Ṣe Kókó
8. Báwo ni ìfọkànsin Ọlọ́run ṣe lè jẹ́ kí ìgbéyàwó wà pẹ́ títí, kí ó sì máyọ̀ wá?
8 A ò jiyàn pé òòfà ẹwà láàárín àwọn méjèèjì náà yóò jẹ́ kí ìdè ìgbéyàwó túbọ̀ lágbára. Ṣùgbọ́n bí ìdè ìgbéyàwó yóò bá wà pẹ́ títí, tí yóò sì máyọ̀ wá, àwọn góńgó àjùmọ̀ní tún ṣe pàtàkì ju ọ̀ràn ẹwà lọ. Jíjùmọ̀ fọkàn sin Jèhófà Ọlọ́run ń jẹ́ kí ìdè náà wà pẹ́ títí, èyí sì ni kókó tó ṣe pàtàkì jù lọ tí ń mú kí ìṣọ̀kan wà. (Oníwàásù 4:12) Nígbà tí Kristẹni tọkọtaya bá jẹ́ kí ìjọsìn tòótọ́ ti Jèhófà wà ní góńgó ẹ̀mí wọn, wọn yóò wà ní ìṣọ̀kan nípa tẹ̀mí, nípa ti èrò orí, àti nípa ti ìwà híhù. Wọ́n á máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pa pọ̀. Wọn á máa gbàdúrà pa pọ̀, èyí á sì mú kí ọkàn wọn ṣọ̀kan. Wọ́n á máa jọ lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni, wọ́n á sì jọ máa ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Gbogbo èyí á jẹ́ kí ìdè tẹ̀mí wà, tí yóò túbọ̀ fà wọ́n mọ́ra. Boríborí gbogbo rẹ̀, á yọrí sí ìbùkún Jèhófà.
9. Kí ni Ábúráhámù ṣe nígbà tó ń wá ìyàwó fún Ísáákì, kí sì ni ìyọrísí rẹ̀?
9 Nítorí ẹ̀mí ìfọkànsìn tí Ábúráhámù baba ńlá olóòótọ́ ní, ó fi ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run síwájú, nígbà tó ń wá ìyàwó fún Ísáákì ọmọ rẹ̀. Ábúráhámù sọ fún ìránṣẹ́ ilé rẹ̀ tó fọkàn tán pé: “Èmi yóò . . . mú ọ fi Jèhófà, Ọlọ́run ọ̀run àti Ọlọ́run ilẹ̀ ayé búra, pé ìwọ kì yóò mú aya fún ọmọkùnrin mi nínú àwọn ọmọbìnrin Kénáánì láàárín àwọn ẹni tí mo ń gbé, ṣùgbọ́n ìwọ yóò lọ sí ilẹ̀ mi àti sọ́dọ̀ àwọn ìbátan mi, dájúdájú, ìwọ yóò sì mú aya fún ọmọkùnrin mi, fún Ísákì. . . . [Jèhófà] yóò rán áńgẹ́lì rẹ̀ lọ ṣáájú rẹ, ìwọ yóò sì mú aya fún ọmọkùnrin mi láti ibẹ̀ wá dájúdájú.” Rèbékà sì wá jẹ́ aya tó dáńgájíá, tí Ísáákì nífẹ̀ẹ́ gidigidi.—Jẹ́nẹ́sísì 24:3, 4, 7, 14-21, 67.
10. Àwọn ojúṣe wo ni Ìwé Mímọ́ là sílẹ̀ fún tọkọtaya?
10 Bí a bá jẹ́ Kristẹni tí kò tíì ṣègbéyàwó, ìfọkànsin Ọlọ́run yóò jẹ́ kí a ní àwọn ànímọ́ tí yóò jẹ́ kí a dé ojú ìlà ohun tí Ìwé Mímọ́ ń béèrè fún ìgbéyàwó. Lára ojúṣe ọkọ àti aya ni ìwọ̀nyí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn, pé: “Kí àwọn aya wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ wọn gẹ́gẹ́ bí fún Olúwa . . . Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti nífẹ̀ẹ́ ìjọ, tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún un . . . Ó yẹ kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn. . . . Kí olúkúlùkù yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀; ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, kí aya ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.” (Éfésù 5:22-33) Gẹ́gẹ́ bí a ti lè rí i, àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀. Títẹ̀lé ìmọ̀ràn yìí wé mọ́ níní ìbẹ̀rù Jèhófà. Ó ń béèrè pé kí a má ṣe yẹ àdéhùn wa, ká mọ̀ pé lọ́jọ́ jíjẹ àti lọ́jọ́ àìríjẹ, èkùrọ́ ni alábàákú ẹ̀wà. Àwọn Kristẹni tó bá ń ronú àtiṣe ìgbéyàwó gbọ́dọ̀ múra tán láti tẹ́wọ́ gba ẹrù iṣẹ́ yìí.
Pípinnu Ìgbà Tó Yẹ Láti Ṣègbéyàwó
11. (a) Ìmọ̀ràn wo ni Ìwé Mímọ́ fúnni nípa ìgbà tó yẹ láti ṣègbéyàwó? (b) Àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé ó bọ́gbọ́n mu láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 7:36?
11 Mímọ ìgbà tí a ti múra tán láti ṣègbéyàwó ṣe pàtàkì. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ìgbà tí kálukú ń ṣe tán, Ìwé Mímọ́ kò fi òté lé ọjọ́ orí kan pàtó. Àmọ́, ó fi hàn pé ó sàn láti dúró di ìgbà táa bá “ti ré kọjá ìgbà ìtànná òdòdó èwe,” nígbà tí òòfà ìbálòpọ̀ lè kó síni lórí. (1 Kọ́ríńtì 7:36) Michelle sọ pé: “Nígbà tí mo rí i táwọn ọ̀rẹ́ mi ń ní àfẹ́sọ́nà tí wọ́n sì ń ṣègbéyàwó, nígbà tí ọ̀pọ̀ nínú wọn kò tíì pé ọmọ ogún ọdún, ó máa ń nira nígbà míì láti fi ìmọ̀ràn yìí sílò. Ṣùgbọ́n mo gbà pé ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìmọ̀ràn yìí ti wá, kìkì ohun tó ń ṣe wá láǹfààní ló sì máa ń sọ fún wa. Dídúró tí mo dúró díẹ̀ kí n tó lọ́kọ ló mú kó ṣeé ṣe fún mi láti mú kí àjọṣe àárín èmi àti Jèhófà túbọ̀ lágbára sí i, kí n sì túbọ̀ ní ìrírí nínú ìgbésí ayé, ìrírí tí ẹni tí kò tíì pé ọmọ ogún ọdún kò lè ní láé. Ní ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, mo ti wá tóótun láti kojú àwọn ẹrù iṣẹ́ àti ìṣòro tó máa ń bá ìgbéyàwó rìn.”
12. Èé ṣe tí kò fi bọ́gbọ́n mu láti kánjú ṣègbéyàwó nígbà tí ọjọ́ orí èèyàn ṣì kéré?
12 Àwọn tó bá kánjú ṣègbéyàwó nígbà tí wọ́n ṣì kéré lọ́jọ́ orí sábà máa ń rí i pé ohun tó jẹ́ àìní àti ìfẹ́ ọkàn wọn ń yí padà bí wọ́n ti ń dàgbà sí i. Wọ́n máa ń rí i pé àwọn nǹkan tó máa ń wù wọ́n tẹ́lẹ̀ kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì sí wọn mọ́. Kristẹni ọ̀dọ́ kan fọkàn sí i pé òun gbọ́dọ̀ lọ́kọ nígbà tóun bá pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún. Ìdí ni pé ìgbà tí ìyá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ àgbà pé iye ọdún yẹn làwọn náà lọ́kọ. Nígbà tí ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń fojú sí lára kọ̀ láti fẹ́ ẹ nígbà yẹn, kíá ló ta mọ́ ẹlòmíràn tó gbà láti fẹ́ ẹ. Àmọ́ bí ọdún ti ń gorí ọdún, ó kábàámọ̀ ìpinnu tó fi ìwàǹwára ṣe yẹn.
13. Ìṣòro wo làwọn tó bá ṣègbéyàwó láìtọ́jọ́ sábà máa ń ní?
13 Nígbà tóo bá ń ronú àtiṣe ìgbéyàwó, ó ṣe pàtàkì láti ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye nípa gbogbo ohun tó wé mọ́ ọn. Ṣíṣègbéyàwó láìtọ́jọ́ lè fa ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìṣòro tí apá tọkọtaya tó kéré lọ́jọ́ orí kò ní ká. Wọ́n lè máà ní ìrírí àti ọgbọ́n àgbà táa nílò láti fi kojú másùnmáwo ìgbéyàwó àti wàhálà ọmọ títọ́. Téèyàn ò bá tíì múra tán nípa tara, nípa ti èrò orí, àti nípa tẹ̀mí láti wọnú àjọṣe tí yóò wà pẹ́ títí, kò yẹ kó dáwọ́ lé ọ̀ràn ìgbéyàwó rárá.
14. Kí ni a nílò láti lè yanjú àwọn ìṣòro tó fẹ́rẹ̀ẹ́ lè pinni lẹ́mìí nínú ìgbéyàwó?
14 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé àwọn tó bá ṣègbéyàwó “yóò ní ìpọ́njú nínú ẹran ara wọn.” (1 Kọ́ríńtì 7:28) Ìṣòro yóò yọjú nítorí pé ẹ̀dá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni tọkọtaya jẹ́, ojú ìwòye wọn sì máa ń yàtọ̀ síra. Nítorí àìpé ẹ̀dá, ó lè ṣòro láti ṣe ohun tí Ìwé Mímọ́ pè ní ojúṣe wa nínú ètò ìgbéyàwó. (1 Kọ́ríńtì 11:3; Kólósè 3:18, 19; Títù 2:4, 5; 1 Pétérù 3:1, 2, 7) Ó ń béèrè ìdàgbàdénú àti dídúró dáadáa nípa tẹ̀mí láti lè rí ìjẹ́pàtàkì wíwá ìtọ́sọ́nà tó ń ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, ká sì tẹ̀ lé irú ìtọ́sọ́nà bẹ́ẹ̀ láti lè fìfẹ́ yanjú àwọn ìṣòro tó fẹ́rẹ̀ẹ́ lè pinni lẹ́mìí.
15. Ipa wo làwọn òbí lè kó nínú mímúra ọmọ wọn sílẹ̀ fún ìgbéyàwó? Ṣàpèjúwe.
15 Àwọn òbí lè múra ọmọ wọn sílẹ̀ fún ìgbéyàwó nípa ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye ìjẹ́pàtàkì títẹ̀lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. Nípa lílo Ìwé Mímọ́ àtàwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni lọ́nà tó já fáfá, àwọn òbí lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti mọ̀ bóyá àwọn tàbí ẹni tí wọ́n sọ pé àwọn fẹ́ fẹ́ ti múra tán láti wọnú ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó. a Blossom ọmọ ọdún méjìdínlógún gbà pé ìfẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó wà nínú ìjọ òun ti kó sóun lórí. Aṣáájú ọ̀nà òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ni ọmọkùnrin náà, wọ́n sì ti fẹ́ ṣègbéyàwó. Ṣùgbọ́n àwọn òbí Blossom sọ pé kó dúró ọdún kan sí i, nítorí pé ó ṣì kéré jù lójú tàwọn. Blossom kọ̀wé lẹ́yìn náà pé: “Mo dúpẹ́ gan-an pé mo fetí sí ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n yẹn. Láàárín ọdún yẹn, mo túbọ̀ dàgbà dénú, mo sì wá bẹ̀rẹ̀ sí rí i pé ọ̀dọ́mọkùnrin yìí kò ní àwọn ànímọ́ tó yẹ kí ọkọ rere ní. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ó fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀, bí mo sì ṣe bọ́ lọ́wọ́ ohun tí ì bá jẹ́ kí n kàgbákò nínú ìgbésí ayé mi nìyẹn o. Ẹ ò rí i bó ṣe dáa tó pé ká ní àwọn òbí ọlọgbọ́n, táa lè gbára lé èrò wọn!”
‘Ṣe Ìgbéyàwó Kìkì Nínú Olúwa’
16. (a) Báwo la ṣe lè dán àwọn Kristẹni wò nínú ọ̀ràn ‘ṣíṣe ìgbéyàwó kìkì nínú Olúwa’? (b) Táa bá dán àwọn Kristẹni wò láti fẹ́ aláìgbàgbọ́, kí ló yẹ kí wọ́n ronú lé lórí?
16 Ìtọ́ni tí Jèhófà fún àwọn Kristẹni ṣe kedere, ó ní: ‘Ṣe ìgbéyàwó kìkì nínú Olúwa.’ (1 Kọ́ríńtì 7:39) A lè dán àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni àti ọmọ wọn wò nínú ọ̀ràn yìí. Lọ́nà wo? Àwọn ọ̀dọ́ lè fẹ́ ṣègbéyàwó àmọ́ kí ó máà sí ẹni tí wọ́n lè fẹ́ nínú ìjọ. Tàbí ká kúkú sọ pé ó jọ pé bọ́ràn ṣe rí nìyẹn. Àwọn ọkùnrin tó wà ládùúgbò kan lè kéré níye sáwọn obìnrin, tàbí kí a máà rí ẹnì kankan tó wù wá ní àgbègbè kan. Ọ̀dọ́kùnrin kan tí kò tíì ya ara rẹ̀ sí mímọ́ gẹ́gẹ́ bíi mẹ́ńbà ìjọ lè fẹ́ fẹ́ ọ̀dọ́bìnrin kan tó jẹ́ Kristẹni (tàbí kí ó jẹ́ pé ọ̀dọ́bìnrin ló fẹ́ fẹ́ ọ̀dọ́kùnrin), èyí sì lè le débi táa ti lè wá fẹ́ fi ìlànà Jèhófà báni dọ́rẹ̀ẹ́. Nínú irú ipò bẹ́ẹ̀, yóò dára láti ronú lórí àpẹẹrẹ Ábúráhámù. Ohun tó ṣe tí kò jẹ́ kí àjọṣe dídánmọ́rán tó ní pẹ̀lú Ọlọ́run bàjẹ́ ni pé ó rí i dájú pé Ísáákì ọmọ òun fẹ́ ẹni tó ń fi òtítọ́ inú sin Jèhófà. Bẹ́ẹ̀ náà ni Ísáákì ṣe nínú ọ̀ràn ti Jékọ́bù ọmọ rẹ̀. Èyí béèrè ìsapá níhà ọ̀dọ̀ kálukú wọn, ṣùgbọ́n wọ́n múnú Ọlọ́run dùn, ó sì bù kún wọn.—Jẹ́nẹ́sísì 28:1-4.
17. Èé ṣe tí ọ̀ràn fífẹ́ aláìgbàgbọ́ fi máa ń di wàhálà, kí sì ni ìdí tó ṣe pàtàkì jù lọ tó fi yẹ láti ‘ṣègbéyàwó kìkì nínú Olúwa’?
17 Nínú àwọn ọ̀ràn mélòó kan, aláìgbàgbọ́ náà wá di Kristẹni nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín. Bó ti wù kó rí, fífa ìjọ̀ngbọ̀n lẹ́sẹ̀ lọ̀ràn lílọ fẹ́ aláìgbàgbọ́. Àwọn táa fi àìdọ́gba so pọ̀ kì í gba ohun kan náà gbọ́, ìlànà, tàbí góńgó wọn kì í sì í bára mu. (2 Kọ́ríńtì 6:14) Èyí lè jẹ́ kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ nira, kí ó sì ba ayọ̀ ìgbéyàwó jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, obìnrin kan tó jẹ́ Kristẹni kédàárò pé ó máa ń dun òun gan-an pé lẹ́yìn lílọ sí ìpàdé tí ń gbéni ró, òun kò lè délé kóun sì bá ọkọ òun aláìgbàgbọ́ jíròrò àwọn nǹkan tẹ̀mí. Àmọ́ ṣá o, ìdí tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé ‘ṣíṣe ìgbéyàwó kìkì nínú Olúwa’ jẹ́ ọ̀ràn dídúróṣinṣin ti Jèhófà. Táa bá ṣègbọràn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ọkàn-àyà wa kò ní dá wa lẹ́bi, nítorí a mọ̀ pé a “ń ṣe àwọn ohun tí ó dára lójú rẹ̀.”—1 Jòhánù 3:21, 22.
18. Nígbà táa bá ń ronú àtiṣe ìgbéyàwó, àwọn nǹkan pàtàkì wo ló yẹ ká fún láfiyèsí, èé sì ti ṣe?
18 Nígbà táa bá ń ronú àtiṣe ìgbéyàwó, ànímọ́ rere àti ipò tẹ̀mí ẹni táa fẹ́ fẹ́ ló yẹ kó jẹ wá lógún jù. Àkópọ̀ ìwà Kristẹni, pa pọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti fífi tọkàntọkàn sìn ín, níye lórí lọ́pọ̀lọpọ̀ ju ẹwà ojú. Ọlọ́run máa ń ṣojú rere sí àwọn tó bá fojú pàtàkì wo ṣíṣe ojúṣe wọn gẹ́gẹ́ bí ọkọ tàbí aya tó dúró dáadáa nípa tẹ̀mí. Ohun tó sì máa ń mú kí ìgbéyàwó dúró sán-ún ni bí tọkọtaya bá jùmọ̀ ń fi ọkàn kan sin Ẹlẹ́dàá, tí wọ́n sì ń fi tinútinú tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀. Báyìí la ṣe lè fi hàn pé a ń bọlá fún Jèhófà, a ó sì gbé ìgbéyàwó náà ka orí ìpìlẹ̀ tẹ̀mí tó dúró sán-ún, tí yóò jẹ́ kó wà pẹ́ títí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Ilé Ìṣọ́ February 15, 1999, ojú ìwé 4 sí 8.
Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?
• Èé ṣe táa fi nílò ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run láti yan ọkọ tàbí aya rere?
• Báwo ni ìfọkànsin Ọlọ́run yóò ṣe jẹ́ kí ìdè ìgbéyàwó túbọ̀ lágbára?
• Báwo làwọn òbí ṣe lè múra àwọn ọmọ wọn sílẹ̀ fún ìgbéyàwó?
• Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì láti ‘ṣe ìgbéyàwó kìkì nínú Olúwa’?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Fífi ìmọ̀ràn Ọlọ́run sílò nínú yíyan ẹni tí o fẹ́ẹ́ fẹ́ lè yọrí sí ayọ̀ ńláǹlà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ọ̀pọ̀ ìbùkún máa ń wá látinú ‘ṣíṣe ìgbéyàwó kìkì nínú Olúwa’