A Tẹ́ Àìní Rẹ̀ Nípa Tẹ̀mí Lọ́rùn
Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
A Tẹ́ Àìní Rẹ̀ Nípa Tẹ̀mí Lọ́rùn
KÍPÍRỌ́SÌ jẹ́ erékùṣù kan ní àríwá ìlà oòrùn ẹ̀bá Òkun Mẹditaréníà. Bàbà àti ojúlówó gẹdú tó pọ̀ ní Kípírọ́sì ló sọ ọ́ di ìlú tó gbajúmọ̀ láwọn àkókò táa kọ Bíbélì. Pọ́ọ̀lù àti Bánábà wàásù ìhìn rere Ìjọba náà níbẹ̀ nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì wọn àkọ́kọ́. (Ìṣe 13:4-12) Ìhìn rere náà ṣì ń nípa tó dára lórí ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ àwọn ará Kípírọ́sì lóde òní. Dájúdájú, bí ọ̀ràn Lucas ṣe rí gan-an nìyí, ọkùnrin kan tó ti lé lẹ́ni ogójì ọdún. O ròyìn pé:
“Inú ìdílé kan tó ní àwa ọmọ méje ni wọ́n ti bí mi, nínú oko kan tí wọ́n ti ń sin màlúù. Àtikékeré ni mo tí nífẹ̀ẹ́ sí ìwé kíkà bí nǹkan míì. Ìwé tí mo sì máa ń kà jù lọ ní ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tó ṣeé tì bọ àpò. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́wàá, èmi àtàwọn ọ̀rẹ́ bíi mélòó kan dá ẹgbẹ́ kékeré kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sílẹ̀. Àmọ́, kò pẹ́ tó fi forí ṣánpọ́n, nítorí àwọn àgbàlagbà kan lábúlé sọ pé aládàámọ̀ ni wá.
“Lẹ́yìn náà, nígbà tí mo lọ sílé ìwé ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, mo bá àwọn èèyàn tí wọ́n ń ṣe onírúurú ìsìn pàdé. Ìyẹn tún ta ìfẹ́ tí mo ní sí àwọn nǹkan tẹ̀mí jí. Ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni mo fi wà nínú ibi ìkówèésí ti yunifásítì náà, tí mò ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa onírúurú ẹ̀sìn. Mo tún lọ sí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì bíi mélòó kan, ṣùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo akitiyan tí mo ń ṣe, mi ò tíì rí ìtẹ́lọ́rùn nípa tẹ̀mí.
“Lẹ́yìn tí mo parí ẹ̀kọ́ mi, mo padà sí Kípírọ́sì, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùdarí ibi ìwádìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìṣègùn. Bàbá àgbàlagbà kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Antonis, tí í ṣe ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, máa ń wá sọ́dọ̀ mi níbi iṣẹ́. Àmọ́, gbogbo bó ṣe ń wá yẹn ni Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì ń kíyè sí.
“Láìpẹ́, ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan wá bá mi, ó sì sọ pé kí n máà bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ̀rọ̀ mọ́. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àtìgbà ọmọdé ni wọ́n ti kọ́ mi pé Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì ni ìjọ tòótọ́, mo fara mọ́ ohun tó sọ, mi ò sì bá Antonis jíròrò mọ́, mo wá bẹ̀rẹ̀ sí bá ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn náà jíròrò Bíbélì. Mo tún ṣèbẹ̀wò sí ọ̀pọ̀ ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé ní Kípírọ́sì. Mo tiẹ̀ rìnrìn àjò lọ sí àríwá Gíríìsì pàápàá tí mo sì ṣèbẹ̀wò sí Òkè Ńlá Athos, táa gbà pé ó jẹ́ òkè ńlá mímọ́ jù lọ nínú ẹ̀sìn Kristẹni ti Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì lágbàáyé. Síbẹ̀, mi ò rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè mi tó jẹ mọ́ Bíbélì.
“Mo wá gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ràn mí lọ́wọ́ láti rí òtítọ́. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ni Antonis tún wá bá mi níbi iṣẹ́, mo sì gbà pé ìdáhùn sí ìbéèrè mi nìyẹn. Bí mi ò ṣe lọ sọ́dọ̀ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn yẹn mọ́ nìyẹn, tí mo bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ Antonis. Mo ń tẹ̀ síwájú, nígbà tó sì dì October 1997, mo fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ mi sí Jèhófà hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi.
“Ìyàwó mi àtàwọn ọmọ wa obìnrin méjì tó dàgbà jù, tí ọ̀kan jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá tí èkejì sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá nígbà yẹn, kọ́kọ́ kọ̀ jálẹ̀. Àmọ́ nítorí pé ìwà mi dára, ìyàwó mi pinnu láti wá sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Inú rẹ̀ dùn gan-an sí inúure àwọn Ẹlẹ́rìí àti bí wọ́n ṣe fi ìfẹ́ hàn sí i. Ohun tó wú u lórí jù lọ ni bí wọ́n ṣe ń lo Bíbélì. Nítorí ìdí èyí, ìyàwó mi àtàwọn ọmọbìnrin wa méjì tó dàgbà jù gbà pé kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá máa bá àwọn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹ fojú inú wo bí ayọ̀ mi ṣe kún tó nígbà táwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ṣe batisí ní Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run” ní 1999!
“Dájúdájú, mo ti rí òtítọ́ tí mo ń wá. Nísinsìnyí, gbogbo ìdílé wa, títí kan aya mi àtàwọn ọmọ wa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ló wà ní ìṣọ̀kan nínú ìjọsìn mímọ́ ti Jèhófà.”