Àwọn Hasmonaean àti Ohun Tí Wọ́n Fi Sílẹ̀ Lọ
Àwọn Hasmonaean àti Ohun Tí Wọ́n Fi Sílẹ̀ Lọ
NÍGBÀ tí Jésù wà láyé, ẹ̀sìn àwọn Júù ti pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ, gbogbo wọn ló sì ń wá ẹni kúnra. Ohun tí àwọn Ìwé Ìhìn Rere àtàwọn ìwé Josephus, ìyẹn Júù tí í ṣe òpìtàn ní ọ̀rúndún kìíní, sọ pé ó ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn.
Abẹnugan làwọn Farisí àti Sadusí nígbà tí wọ́n dóde, wọ́n ń yí èrò gbogbo ìlú padà, kódà wọ́n ṣe é débi pé wọ́n sún àwọn èèyàn láti kọ Jésù tí í ṣe Mèsáyà. (Mátíù 15:1, 2; 16:1; Jòhánù 11:47, 48; 12:42, 43) Ṣùgbọ́n, Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù kò sọ nǹkan kan nípa àwọn ẹgbẹ́ méjèèjì tó jẹ́ abẹnugan yìí.
Ìgbà tí Josephus ń sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rúndún kejì ṣááju Sànmánì Tiwa ló kọ́kọ́ mẹ́nu kan àwọn Sadusí àtàwọn Farisí. Sáà yìí ni ọ̀pọ̀ Júù bẹ̀rẹ̀ sí tẹ́wọ́ gba ọ̀làjú àwọn Hélénì, ìyẹn, àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àti ọgbọ́n orí Gíríìkì. Gbọ́nmi-si-omi-ò-to láàárín àwọn Hélénì àtàwọn Júù wá dé góńgó nígbà tí àwọn alákòóso láti ìlà ọba Seleucid sọ tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù di ẹlẹ́gbin, tí wọ́n yà á sí mímọ́ fún òrìṣà Súúsì. Judah Maccabee, tí í ṣe akíkanjú aṣáájú àwọn Júù, látinú ìdílé kan tí wọ́n ń pè ní Hasmonaean, kó àwọn jagunjagun ọlọ̀tẹ̀ kan jọ, wọ́n sì gba tẹ́ńpìlì náà lọ́wọ́ àwọn ará Gíríìkì. a
Àwọn ọdún àkọ́kọ́ lẹ́yìn ìdìtẹ̀ àti ìṣẹ́gun àwọn Maccabee wá kún fún ìtẹ̀sí láti dá àwọn ẹ̀ya ìsìn sílẹ̀, nítorí àwọn èròǹgbà tí ń figa gbága, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan ń wá ọ̀nà lójú méjèèjì láti mókè láàárín àwọn Júù. Àmọ́ kí ló fa irú ìtẹ̀sí yìí? Kí ló dé tí ẹ̀sìn àwọn Júù fi wá pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ báyẹn? Ká lè dáhùn ìbéèrè wọ̀nyí, ẹ jẹ́ ka yẹ ìtàn àwọn Hasmonaean wò.
Òmìnira àti Ìyapa Púpọ̀ sí I
Lẹ́yìn tí ọwọ́ Judah Maccabee tẹ góńgó rẹ̀ láti dá ìjọsìn padà sí tẹ́ńpìlì Jèhófà, ó wá tọwọ́ bọ ọ̀ràn òṣèlú. Èyí ló mú kí ọ̀pọ̀ àwọn Júù padà lẹ́yìn rẹ̀. Síbẹ̀, ó ń bá a nìṣó ní bíbá àwọn alákòóso Seleucid jà, ó wọnú àdéhùn pẹ̀lú Róòmù, ó sì fẹ́ dá Orílẹ̀-Èdè olómìnira Júù sílẹ̀. Lẹ́yìn ikú Judah lójú ogun, Jonathan àbúrò rẹ̀, àti Simon ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ń bá ìjà náà nìṣó. Àwọn alákòóso Seleucid kọ́kọ́ fìjà pẹẹ́ta pẹ̀lú àwọn Maccabee. Àmọ́ nígbà tó yá, àwọn alákòóso náà wá gbà láti bá wọn wọnú àjọṣe nínú ọ̀ràn ìṣèlú, wọ́n fún tẹ̀gbọ́n-tàbúrò tí í ṣe Hasmonaean wọ̀nyí ní agbára díẹ̀.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlà ìdílé àlùfáà làwọn Hasmonean ti wá, kò sí ìkankan lára wọn tó sìn ní ipò àlùfáà àgbà rí. Ọ̀pọ̀ Júù gbà pé àwọn àlùfáà tó wá láti ìlà ìdílé Sádókù, tí Sólómọ́nì yàn ṣe àlùfáà àgbà, ló yẹ kó wà ní ipò yìí. (1 Àwọn Ọba 2:35; Ìsíkíẹ́lì 43:19) Jonathan lo ogun àti ọgbọ́n mẹ̀bẹ́mẹ̀yẹ̀ láti fi mú kí àwọn Seleucid yan òun ṣe àlùfáà àgbà. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ikú Jonathan, Simon ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tilẹ̀ tún ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ní September 140 ṣááju Sànmánì Tiwa, àṣẹ pàtàkì kan jáde ní Jerúsálẹ́mù, tí wọ́n gbẹ́ sára wàláà idẹ lọ́nà ìkọ̀wé Gíríìkì, pé: “Ọba Demetrius [ìyẹn, alákòóso tó wá láti ìlà ọba Seleucid ti àwọn Gíríìkì] fi í [Simon] jẹ àlùfáà àgbà, ó sọ ọ́ di ọ̀kan lára àwọn Ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó sì fi í sí ipò ọlá ńlá. . . . Àwọn Júù àtàwọn àlùfáà ti pinnu pé Simon làwọn fẹ́ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú àti àlùfáà àgbà títí láé, títí wòlíì tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé yóò fi dé.”—1 Àwọn Maccabee 14:38-41 (ìwé ìtàn kan táa rí nínú ìwé Apocrypha).
Bó ṣe jẹ́ nìyẹn tí ipò Simon gẹ́gẹ́ bí alákòóso àti àlùfáà àgbà—fún òun àti àtọmọdọ́mọ rẹ̀—fi di èyí táa fìdí rẹ̀ múlẹ̀, kì í ṣe kìkì nípasẹ̀ Seleucid agbókèèrè-ṣàkóso nìkan ni, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ “Ìgbìmọ̀ Ńlá” àwọn èèyàn tirẹ̀ pẹ̀lú. Èyí ló wá sàmì sí àkókò ìyípadà pàtàkì kan. Gẹ́gẹ́ bí òpìtàn Emil Schürer ti wí, gbàrà táwọn Hasmonaean fìdí ìlà ọba múlẹ̀, “ohun tó wá wà ní góńgó ẹ̀mí wọn kì í ṣe ìmúṣẹ Tórà [Òfin Júù] mọ́, bí kò ṣe bí agbára ìṣèlú ò ṣe ní bọ́ lọ́wọ́ wọn, àti bí wọn ó ṣe máa gba agbára kún agbára.” Ṣùgbọ́n, Simon alára dọ́gbọ́n sí i, kò fẹ́ ṣe ohun tí àwọn Júù á fi fura sóun, nítorí náà ó bẹ̀rẹ̀ sí lo orúkọ oyè náà “aṣíwájú àwọn èèyàn,” dípò “ọba.”
Kì í ṣe gbogbo èèyàn ni inú wọ́n dùn sí bí àwọn Hasmonaean ṣe já ọ̀pá àṣẹ ẹ̀sìn àti ti ìṣèlú gbà. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀mọ̀wé kan ti wí, sáà yìí ni àwùjọ Qumran kóra jọ. Àlùfáà kan láti ìlà ìdílé Sádókù, tó jọ pé òun ni wọ́n pè ní “Olùkọ́ni ní Òdodo” nínú àwọn ìwé kan tí wọ́n rí ní Qumran, fi Jerúsálẹ́mù sílẹ̀, ó kó àwọn alátakò jọ, wọ́n sì forí lé Aṣálẹ̀ Júdà lẹ́bàá Òkun Òkú. Ọ̀kan lára Àkájọ Ìwé Òkun Òkú, táa fi ṣàlàyé ìwé Hábákúkù, bẹnu àtẹ́ lu “Àlùfáà Burúkú náà tí wọ́n kọ́kọ́ ń fi orúkọ òtítọ́ pè, ṣùgbọ́n tí ọkàn rẹ̀ wá ń wú fùkẹ̀ nígbà tó ń ṣàkóso Ísírẹ́lì.” Ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé ló gbà pé Jonathan tàbí Simon ni ẹ̀ya ìsìn yẹn pè ní “Àlùfáà Burúkú.”
Simon ń jagun nìṣó láti lè fi kún ìpínlẹ̀ tó wà lábẹ́ àkóso rẹ̀. Àmọ́ òjijì ni ìṣàkóso rẹ̀ dópin nígbà tí Pẹ́tólẹ́mì ọkọ ọmọ rẹ̀ pa òun àti ọmọkùnrin rẹ̀ méjì bí wọ́n ti ń jàsè nítòsí Jẹ́ríkò. Ìgbésẹ̀ tí wọ́n gbé láti gba agbára yìí forí ṣánpọ́n. Wọ́n kìlọ̀ fún John Hyrcanus, ọmọ Simon kan ṣoṣo tó ṣẹ́ kù, pé wọ́n fẹ́ gbẹ̀mí ẹ̀. Ọwọ́ rẹ̀ tẹ àwọn èèyàn tó fẹ́ pa á, ó sì di aṣíwájú àti àlùfáà àgbà nípò bàbá rẹ̀.
Ìmúgbòòrò àti Ìtẹnilóríba Síwájú sí I
Àwọn ọmọ ogun Síríà kọ́kọ́ da gìrìgìrì bo John Hyrcanus, àmọ́ nígbà tó wá di ọdún 129 ṣááju Sànmánì Tiwa, ìlà ọba Seleucid pàdánù ogun ńlá kan tí wọ́n bá àwọn ará Pátíà jà. Nígbà tí ọ̀mọ̀wé Júù nì, Menahem Stern, ń kọ̀wé nípa àkóbá tí ogun yìí ṣe fáwọn ọba ìlà ìdílé Seleucid, ó sọ pé: “Gbogbo ìjọba náà látòkè délẹ̀ ló fẹ́rẹ̀ẹ́ fọ́ yángá.” Ìyẹn ló jẹ́ kí Hyrcanus “ráyè gba gbogbo òmìnira Jùdíà padà, tó sì wá bẹ̀rẹ̀ sí gba ilẹ̀ kún ilẹ̀ lọ́tùn-ún lósì.” Ilẹ̀ àkóso rẹ̀ sì wá fẹ̀ lóòótọ́.
Nísinsìnyí tí ará Síríà kankan kò lè rí Hyrcanus gbé ṣe mọ́, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí gbógun ti àwọn ìpínlẹ̀ tó wà lóde Jùdíà, ó ń tẹ̀ wọ́n lórí ba. Ó fi dandan lé e pé àwọn ará ìpínlẹ̀ wọ̀nyí gbọ́dọ̀ tẹ́wọ́ gba ẹ̀sìn àwọn Júù, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ gbogbo ìlú ńlá wọn ló máa pa rẹ́. Ó gbé irú ogun bẹ́ẹ̀ ja àwọn ará Ídúmíà (Édómù). Ọ̀gbẹ́ni Stern sọ nípa ogun yìí pé: “Yíyí àwọn ará Ídúmíà lọ́kàn padà jẹ́ àkọ́kọ́ irú ẹ̀, nítorí pé odindi ẹ̀yà kan ló yí padà, kì í kàn-án ṣe àwọn èèyàn díẹ̀ látinú ẹ̀yà náà.” Ara àwọn àgbègbè míì tó ṣẹ́gun ni Samáríà, níbi tí Hyrcanus ti wó tẹ́ńpìlì Samáríà tó wà lórí Òkè Gérísímù palẹ̀. Nígbà tí òpìtàn nì, Solomon Grayzel, ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó jẹ́ ìyàlẹ́nu nínú bí ìlà ìdílé Hasmonaean ṣe ń fagbára yíni lọ́kàn padà, ó sọ pé: “Ọmọ-ọmọ Mattathias [bàbá Judah Maccabee] sì nìyí o, tó ń rú ìlànà náà gan-an—ìyẹn òmìnira ẹ̀sìn—tí ìran ìṣáájú jà fitafita láti dáàbò bò.”
Àwọn Farisí àti Sadusí Dóde
Ìgbà tí Josephus ń kọ̀wé nípa Hyrcanus ló kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa bí agbára àwọn Farisí àti
Sadusí ṣe ń pọ̀ sí i. (Josephus ti mẹ́nu kan àwọn Farisí tó gbé ayé nígbà àkóso Jonathan.) Kò sọ nǹkan kan nípa orírun wọn. Àwọn ọ̀mọ̀wé kan kà wọ́n sí ẹgbẹ́ kan tó jáde látinú àwọn Hasidim, ìyẹn ẹ̀ya ìsìn tó gbárùkù ti Judah Maccabee nígbà tó fi ọ̀ràn ẹ̀sìn ṣe góńgó rẹ̀, àmọ́ tí wọ́n wá kẹ̀yìn sí i nígbà tó tọwọ́ bọ ọ̀ràn òṣèlú.Ìtumọ̀ orúkọ náà Farisí kò jìnnà sí ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “ọ̀tọ̀lórìn,” bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan gbà pé ó tan mọ́ ọ̀rọ̀ náà “olùtumọ̀.” Àwọn Farisí jẹ́ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ láti àárín àwọn gbáàtúù, ilé ọlá kọ́ ni wọ́n ti wá. Wọ́n yàgò fún títa àbààwọ́n sí ààtò ìsìn nípa ṣíṣe fínnífínní dórí bíńtín, wọ́n sì gbà pé àwọn òfin tẹ́ńpìlì tó sọ̀rọ̀ nípa ìjẹ́mímọ́ àlùfáà kan gbogbo nǹkan táa ń bá pàdé lójoojúmọ́ ayé. Àwọn Farisí wá bẹ̀rẹ̀ sí túmọ̀ Ìwé Mímọ́ lọ́nà tó yàtọ̀, wọ́n sì gbé èròǹgbà kan jáde táa wá mọ̀ sí òfin àtẹnudẹ́nu. Agbára wọn pọ̀ sí i nígbà àkóso Simon, ìgbà yẹn la yan àwọn kan lára wọn gẹ́gẹ́ bí mẹ́ńbà Gerousia (ìgbìmọ̀ àwọn àgbààgbà), èyí táa wá mọ̀ sí Sànhẹ́dírìn lẹ́yìn náà.
Josephus sọ pé John Hyrcanus kọ́kọ́ ń gba ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ àwọn Farisí, ó sì wà lẹ́yìn wọn gbágbáágbá. Àmọ́, nígbà kan, àwọn Farisí bá a wí torí pé ó kọ̀ láti gbé ipò àlùfáà àgbà sílẹ̀. Bí gbogbo nǹkan ṣe yí bìrí nìyẹn o, tí wọ́n sì pín gaàrí. Hyrcanus fòfin de gbogbo ààtò ìsìn àwọn Farisí. Kí àjẹkún ìyà lè jẹ àwọn Farisí, ó wá ń gbè sẹ́yìn àwọn Sadusí, tí í ṣe ọ̀tá àwọn Farisí nínú ọ̀ràn ẹ̀sìn.
Ó jọ pé orúkọ náà Sadusí wá látinú orúkọ Sádókù Àlùfáà Àgbà, tí àtọmọdọ́mọ rẹ̀ ti ń di ipò àlùfáà mú láti ìgbà Sólómọ́nì. Àmọ́ kì í ṣe gbogbo Sadusí ló wá láti ìlà ìdílé yìí. Gẹ́gẹ́ bí Josephus ti wí, àwọn Sadusí ni àwọn ọ̀tọ̀kùlú àtàwọn ọlọ́rọ̀ orílẹ̀-èdè náà, àwọn gbáàtúù kò sì gba tiwọn. Ọ̀jọ̀gbọ́n Schiffman sọ pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn . . . jẹ́ àlùfáà tàbí àwọn tó jẹ́ àna àlùfáà àgbà.” Nítorí náà, ọjọ́ ti pẹ́ tí wọ́n ti ń bá àwọn aláṣẹ ṣe wọlé wọ̀de. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé nígbà táwọn Farisí bẹ̀rẹ̀ sí rọ́wọ́ mú láwùjọ, táwọn Farisí sì tún ń sọ pé gbogbo èèyàn ló lè jẹ́ mímọ́ bíi ti àlùfáà, wọ́n wá ń wo gbogbo èyí bí ohun tó lè jin ọlá àṣẹ tí àwọn Sadusí gbà pé ó jẹ́ tiwọn lẹ́sẹ̀. Wàyí o, láwọn ọdún tó gbẹ̀yìn àkóso Hyrcanus, ọ̀pá àṣẹ ti padà sọ́wọ́ àwọn Sadusí.
Wọ́n Tọrùn Bọ Ìṣèlú, Wọ́n Pa Ẹ̀sìn Tì
Ọdún kan péré ni Aristobulus, àkọ́bí Hyrcanus, fi jọba kó tó kú. Ó tẹ̀ síwájú láti fagbára mú àwọn ará Ítúréà ṣẹ̀sìn, ó sì mú Gálílì òkè wá sábẹ́ ìdarí àwọn Hasmonaean. Ṣùgbọ́n ìgbà ìjọba Alexander Jannaeus àbúrò rẹ̀, tó jọba látọdún 103 sí 76 ṣááju Sànmánì Tiwa, ni àwọn Hasmonean dé òtéńté agbára wọn.
Alexander Jannaeus pa ìlànà tẹ́lẹ̀ yẹn tì, ó sì kéde pé òun ni àlùfáà àgbà àti ọba. Ìforígbárí àárín àwọn Hasmonean àtàwọn Farisí wá túbọ̀ le sí i, àní ó fa ogun abẹ́lé níbi tí b
ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [50,000] àwọn Júù ti ṣègbé. Lẹ́yìn tí wọ́n paná ọ̀tẹ̀ náà, Jannaeus ṣe ohun táwọn ọba kèfèrí máa ń ṣe, ó ní kí wọ́n gbé ẹgbẹ̀rin [800] lára àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà kọ́ sórí igi. Nígbà tí wọ́n ń kú lọ, ìṣojú wọn báyìí ni wọ́n ti dúńbú àwọn aya wọn àtọmọ wọn, níbi tí Jannaeus àtàwọn wáhàrì rẹ̀ ti ń jàsè lọ́wọ́ ní gbangba.Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jannaeus ń bá àwọn Farisí ṣọ̀tá, ọgbọ́n òṣèlú kún agbárí rẹ̀. Ó rí i pé àwọn èèyàn túbọ̀ ń gba tàwọn Farisí. Ìtọ́ni tó fún Salome Alexandra, ìyàwó rẹ̀, nígbà tó ń kú lọ ni pé kí ó fún àwọn Farisí lágbára. Jannaeus sọ pé aya òun ni kó jọba lẹ́yìn òun, dípò àwọn ọmọ òun. Alákòóso tó dáńgájíá lobìnrin náà, ìgbà tirẹ̀ ló tu orílẹ̀-èdè náà lára jù lọ ní sáà àkóso àwọn Hasmonaean (76 sí 67 ṣááju Sànmánì Tiwa). A dá àwọn Farisí padà sípò àṣẹ, a sì fagi lé àwọn òfin tí wọ́n fi ka ààtò ìsìn wọn léèwọ̀.
Lẹ́yìn ikú Salome, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, ìyẹn Hyrcanus Kejì, tó di àlùfáà àgbà, àti Aristobulus Kejì bẹ̀rẹ̀ sí du agbára mọ́ ara wọn lọ́wọ́. Àwọn méjèèjì kò ní ọgbọ́n ìṣèlú àti ọgbọ́n ológun tí àwọn baba ńlá wọ́n ní, ó sì jọ pé kò sí ìkankan lára wọn tó mọ̀ pé àwọn ará Róòmù kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn mọ́ lágbègbè yẹn lẹ́yìn tí ìjọba àwọn Seleucid ti dópin pátápátá. Lọ́dún 63 ṣááju Sànmánì Tiwa, àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò yìí lọ kó ara wọn bá Pompey alákòóso Róòmù nígbà tó ṣì wà ní Damásíkù pé kó wá báwọn parí ìjà. Ọdún yẹn gan-an ni Pompey àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ wọ Jerúsálẹ́mù, tí wọ́n sì gbà á. Bí ìjọba àwọn Hasmonaean ṣe bẹ̀rẹ̀ sí wọ̀ọ̀kùn nìyẹn. Lọ́dún 37 ṣááju Sànmánì Tiwa, Ọba Hẹ́rọ́dù Ńlá tí í ṣe ará Ídúmíà, ẹni tí Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Róòmù ti fọwọ́ sí gẹ́gẹ́ bí “Ọba Jùdíà,” tí wọ́n sì pè ní “onígbèjà àti ọ̀rẹ́ àwọn ará Róòmù,” wá gba ìlú Jerúsálẹ́mù. Bí ìjọba àwọn Hasmonaean ṣe pa rẹ́ nìyẹn o.
Ohun Tí Àwọn Hasmonaean Fi Sílẹ̀ Lọ
Sáà àwọn Hasmonaean, látìgbà Judah Maccabee títí dìgbà Aristobul Kejì, ni ìyapa ẹ̀sìn tí Jésù bá láyé ti bẹ̀rẹ̀. Àwọn Hasmonaean bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìtara fún ìjọsìn Ọlọ́run, ṣùgbọ́n wọ́n wá fi ìfẹ́ ìmọtara-ẹni-nìkan bà á jẹ́. Àwọn àlùfáà wọn, tó ní àǹfààní láti so àwọn èèyàn náà pọ̀ ṣọ̀kan nínú títẹ̀lé Òfin Ọlọ́run, ló dá ìjà òṣèlú sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè náà. Èyí ló fà á tí ìyapa ẹ̀sìn fi wá pọ̀ rẹpẹtẹ. Àwọn Hasmonaean kò sí mọ́, ṣùgbọ́n ìjà láti mọ ẹ̀sìn tí yóò dọ̀gá wá ń jà ràn-ìn láàárín àwọn Sadusí, àwọn Farisí, àtàwọn yòókù lórílẹ̀-èdè náà tó bá ara wọn lábẹ́ àṣẹ Hẹ́rọ́dù àti Róòmù.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Wo Là Ń Pè Ní Maccabee?” nínú Ilé Ìṣọ́ November 15, 1998.
b Ìwé náà, “Àlàyé Lórí Náhúmù,” tó jẹ́ ara Àkájọ Ìwé Òkun Òkú sọ̀rọ̀ nípa “Kìnnìún Ìbínú” tó “gbé àwọn èèyàn kọ́ sórí igi láàyè,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìṣẹ̀lẹ̀ táa mẹ́nu kàn lókè yìí ló ń tọ́ka sí.
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 30]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Ìlà Ọba Àwọn Hasmonaean
Judah Maccabee Jonathan Maccabee Simon Maccabee
↓
John Hyrcanus
↓ ↓
Salome Alexandra — fẹ́ — Alexander Jannaeus Aristobulus
↓ ↓
Hyrcanus Kejì Aristobulus Kejì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Judah Maccabee ń wá bí àwọn Júù ṣe máa gbòmìnira
[Credit Line]
The Doré Bible Illustrations/Dover Publications, Inc.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Àwọn Hasmonaean ti ń jà fitafita láti gba àwọn ìlú ńlá tí kì í ṣe ti Júù sábẹ́ àkóso wọn
[Credit Line]
The Doré Bible Illustrations/Dover Publications, Inc.