Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Ká Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Ká Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
BILL jẹ́ ọ̀dọ́, tó ń ta kébé, tó kàwé, tó sì rí já jẹ. Síbẹ̀ inú ẹ̀ ò dùn. Kò mọ ibi tí ìgbésí ayé òun dorí kọ, èyí sì kó ìdààmú bá a gan-an. Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí wá ète ìgbésí ayé kiri, ó ń ti inú ẹ̀sìn kan bọ́ sí òmíràn, ṣùgbọ́n kò rí ohun tó ń wá. Ní 1991, ó pàdé ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tó fún un ní ìwé kan tó jíròrò ohun tí Bíbélì sọ nípa ìtumọ̀ ìgbésí ayé. Wọ́n ṣètò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí Bill lè lóye kókó yìí àtàwọn kókó mìíràn.
Bill rántí pé: “Gbàrà táa bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ni mo ti rí i pé ohun tí mo ti ń wá kiri rèé, nítorí pé Bíbélì là ń tọ́ka sí léraléra. Àwọn ìdáhùn tó wá látinú Bíbélì gbámúṣé. Lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ yẹn, mo wakọ̀ lọ sẹ́bàá àwọn òkè kan, mo bọ́ọ́lẹ̀ nínú ọkọ̀ mi, mo sì bú sí igbe ayọ̀. Inú mi dùn gan-an pé mo ti bẹ̀rẹ̀ sí rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè mi nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín.”
Àmọ́ o, kì í ṣe gbogbo ẹni tó rí òtítọ́ Bíbélì ló máa ń bú sí igbe ayọ̀ bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n, rírí ìdáhùn Mátíù 13:44.
sáwọn ìbéèrè pàtàkì nínú ìgbésí ayé jẹ́ ìrírí aláyọ̀ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn. Ìmọ̀lára wọn dà bíi ti ọkùnrin tí Jésù sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àkàwé kan pé ó ṣàwárí ìṣúra kan táa fi pa mọ́ sínú pápá. Jésù sọ pé: “Nítorí ìdùnnú tí ó ní, ó lọ, ó sì ta àwọn ohun tí ó ní, ó sì ra pápá yẹn.”—Àṣírí Ìgbésí Ayé Tó Nítumọ̀
Bill ti ronú ronú lórí ìbéèrè pàtàkì náà, Kí ni ète ìgbésí ayé? Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún làwọn ọ̀mọ̀ràn, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn, àtàwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ń jà raburabu láti rí ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn. Àwọn akọ̀wé-kọwúrà tó ń gbìyànjú láti dáhùn ìbéèrè náà ti kọ àìmọye ìwé nípa rẹ̀. Àmọ́, pàbó ni gbogbo làálàá wọn já sí, ibi tí ọ̀pọ̀ sì parí èrò sí ni pé ìbéèrè náà kò ní ìdáhùn. Ṣùgbọ́n ó ní ìdáhùn. Ó kàn jinlẹ̀ ni, àmọ́ kò díjú. Bíbélì ṣàlàyé rẹ̀. Àṣírí ìgbésí ayé aláyọ̀, tó nítumọ̀ ni pé: A gbọ́dọ̀ ní àjọṣe yíyẹ pẹ̀lú Jèhófà, Ẹlẹ́dàá àti Baba wa ọ̀run. Báwo la ṣe lè nírú àjọṣe yẹn?
Ìhà méjì tó dà bíi pé ó ta kora ló wà nínú ọ̀ràn sísúnmọ́ Ọlọ́run. Àwọn tó sún mọ́ Ọlọ́run ń bẹ̀rù rẹ̀, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ méjì tó ti gbólóhùn yẹn lẹ́yìn. Láyé ọjọ́un, Sólómọ́nì ọlọgbọ́n Ọba fara balẹ̀ ṣàkíyèsí ọmọ aráyé, ó sì ṣàkọsílẹ̀ ohun tó ṣàwárí sínú ìwé Oníwàásù nínú Bíbélì. Nígbà tó kó gbogbo ohun tó rí pọ̀, ó kọ̀wé pé: “Òpin ọ̀ràn náà, lẹ́yìn gbígbọ́ gbogbo rẹ̀, ni pé: Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Nítorí èyí ni gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ènìyàn.” (Oníwàásù 12:13) Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, nígbà táa bi Jésù léèrè nípa àṣẹ títóbi jù lọ nínú Òfin Mósè, ó fèsì pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.” (Mátíù 22:37) Ǹjẹ́ ó dún bí ohun tó ṣàjèjì létí rẹ láti bẹ̀rù Ọlọ́run, ká sì tún nífẹ̀ẹ́ rẹ̀? Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ìjẹ́pàtàkì ìbẹ̀rù àti ìfẹ́, àti bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ láti jẹ́ kí a ní àjọṣe tí ń múni lọ́kàn yọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.
Ohun Tí Ìbẹ̀rù Ọlọ́run Túmọ̀ Sí
Ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ ṣe kókó bí Ọlọ́run yóò bá tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa. Bíbélì sọ pé: “Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ọgbọ́n.” (Sáàmù 111:10) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa bá a lọ láti ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, nípasẹ̀ èyí tí a fi lè ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run lọ́nà tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ìbẹ̀rù Ọlọ́run àti ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀.” (Hébérù 12:28) Bákan náà, bí áńgẹ́lì kan tí àpọ́sítélì Jòhánù rí nínú ìràn ní agbedeméjì ọ̀run ṣe bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbà tó ń polongo ìhìn rere náà ni pé: “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un.”—Ìṣípayá 14:6, 7.
Ìbẹ̀rù Ọlọ́rùn yìí, tó ṣe pàtàkì gan-an láti ní, kí ìgbésí ayé wa lè nítumọ̀, yàtọ̀ sí gbígbọ̀n jìnnìjìnnì. A lè bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n jìnnìjìnnì bí ọ̀daràn tó jẹ́ òǹrorò àti òṣónú bá ń halẹ̀ mọ́ wa. Àmọ́ ìbẹ̀rù Ọlọ́run túmọ̀ sí níní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún Ẹlẹ́dàá. Ó tún wé mọ́ ìbẹ̀rù tó bójú mu, ti ṣíṣàì ṣe ohun tó máa mú Ọlọ́run bínú nítorí pé òun ni Onídàájọ́ Gíga Jù Lọ àti Olódùmarè, tó ní agbára àti ọlá àṣẹ láti fìyà jẹ àwọn tó bá ṣàìgbọràn sí i.
Ìbẹ̀rù àti Ìfẹ́ Ń Ṣiṣẹ́ Pa Pọ̀ Ni
Ṣùgbọ́n o, Jèhófà kò fẹ́ káwọn èèyàn máa sin òun kìkì nítorí pé wọ́n ń bẹ̀rù òun. Ní pàtàkì, Ọlọ́run ìfẹ́ ni Jèhófà jẹ́. Tọkàntọkàn ni àpọ́sítélì Jòhánù fi kọ̀wé pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Ìfẹ́ ńlá ni Jèhófà Ọlọ́run fi bá aráyé lò, ó sì fẹ́ káwọn èèyàn ní irú ìfẹ́ yẹn sóun. Ṣùgbọ́n báwo ni irú ìfẹ́ yẹn ṣe bá ìbẹ̀rù Ọlọ́run mu? Ní ti gidi, méjèèjì kò ṣeé yà. Onísáàmù náà kọ̀wé pé: “Ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ ti àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.”—Sáàmù 25:14.
Sáà ronú ọ̀wọ̀ àti ìbẹ̀rù tí ọmọ máa ń ní fún bàbá rẹ̀ tó jẹ́ alágbára àti ọlọgbọ́n. Lẹ́sẹ̀ kan náà, irú ọmọ bẹ́ẹ̀ yóò nífẹ̀ẹ́ bàbá rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí bàbá náà ti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ọmọ náà yóò gbẹ́kẹ̀ lé bàbá rẹ̀, yóò máa gba ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ rẹ̀, ọkàn rẹ̀ yóò sì balẹ̀ pé ìtọ́sọ́nà yìí yóò ṣe òun láǹfààní. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, bí a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, táa sì bẹ̀rù rẹ̀, a óò máa tẹ̀ lé ìtọ́ni rẹ̀, èyí yóò sì ṣe wá láǹfààní. Gbọ́ ohun tí Jèhófà sọ nípa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó ní: “Kìkì bí wọn yóò bá mú ọkàn-àyà wọn yìí dàgbà láti bẹ̀rù mi àti láti pa gbogbo àṣẹ mi mọ́ nígbà gbogbo, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún àwọn àti àwọn ọmọ wọn fún àkókò tí ó lọ kánrin!”—Diutarónómì 5:29.
Ó dájú pé ìbẹ̀rù Ọlọ́run kì í sọni dẹrú, bí kò ṣe kí ó sọni dòmìnira, kò lè yọrí sí ìbànújẹ́, bí kò ṣe ayọ̀. Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa Jésù pé: “Ìgbádùn rẹ̀ yóò sì wà nínú ìbẹ̀rù Jèhófà.” (Aísáyà 11:3) Onísáàmù náà sì kọ̀wé pé: “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí ó bẹ̀rù Jèhófà, tí ó ní inú dídùn gidigidi sí àwọn àṣẹ rẹ̀.”—Sáàmù 112:1.
Àmọ́, a ò lè bẹ̀rù Ọlọ́run, a ò sì lè nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bí a kò bá mọ̀ ọ́n. Ìdí nìyẹn tí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fi ṣe pàtàkì gan-an. Irú ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mọ àwọn ànímọ́ Ọlọ́run, ká sì wá mọyì ọgbọ́n tó wà nínú títẹ̀lé ìtọ́ni rẹ̀. Báa ti túbọ̀ ń sún mọ́ Ọlọ́run, a fẹ́ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, ọkàn wa sì ń sún wa láti pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, nítorí a mọ̀ pé àṣẹ wọ̀nyí yóò ṣe wá láǹfààní.—1 Jòhánù 5:3.
Ó jẹ́ nǹkan ayọ̀ láti mọ̀ pé èèyàn ń tọ ọ̀nà tí ó tọ́ nínú ìgbésí ayé. Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀ràn Bill táa mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀ rí. Ó sọ lẹ́nu àìpẹ́ yìí pé: “Láàárín ọdún mẹ́sàn-án tó ti kọjá látìgbà tí mo ti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àjọṣe èmi pẹ̀lú Jèhófà ti túbọ̀ jinlẹ̀ sí i. Ayọ̀ tó kún inú mi níbẹ̀rẹ̀ yẹn ti di ọ̀nà ìgbésí ayé fún mi. Èrò rere ni mo ń ní nípa ìgbésí ayé látìgbà yẹn. Gbogbo ọjọ́ ayé mi ló kún fún ìgbòkègbodò tó nítumọ̀, kì í ṣe ṣíṣe fàájì ìranù kiri. Jèhófà ti di ẹni gidi lójú mi, mo sì mọ̀ pé ó ní ire mi lọ́kàn.”
Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, a óò túbọ̀ jíròrò bí ìmọ̀ nípa Jèhófà ṣe ń máyọ̀ wá, tó sì ń ṣàǹfààní fáwọn tó ń lo ìmọ̀ yẹn nínú ìgbésí ayé wọn.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
Sísúnmọ́ Ọlọ́run túmọ̀ sí pé ká nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ká sì bẹ̀rù rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Jésù fi tayọ̀tayọ̀ bẹ̀rù Jèhófà