Ó Lálòpẹ́ Ju Ògidì Wúrà Lọ
Ó Lálòpẹ́ Ju Ògidì Wúrà Lọ
ÌDÍ táwọn èèyàn fi ń wá wúrà lọ́tùn-ún lósì ni pé ó jojú ní gbèsè, ó tún lálòpẹ́. Ìdí tójú àwọn èèyàn fi ń wọ̀ ọ́ ni pé ńṣe ló máa ń dán yinrin-yinrin, ó sì jọ pé kò lè ṣì láé. Ìdí ni pé ṣàṣà ni nǹkan tó lè ba wúrà jẹ́, ì báà jẹ́ omi, afẹ́fẹ́, tàbí imí ọjọ́. Ọ̀pọ̀ nǹkan táa fi wúrà ṣe, táa ṣàwárí nínú àwọn ọkọ̀ òkun tó rì àti nínú àwọn nǹkan mìíràn ṣì ń dán gbinrin lẹ́yìn ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún.
Àmọ́, ó yẹ fún àfiyèsí pé Bíbélì sọ pé nǹkan kan wà tó lálòpẹ́, tó sì “níye lórí púpọ̀púpọ̀ ju wúrà tí ń ṣègbé láìka fífi tí a fi iná dá an wò sí.” (1 Pétérù 1:7) Wúrà táa fi iná àtàwọn ọ̀nà mìíràn ‘dán wò,’ tàbí yọ́ mọ́, lè mọ́ gaara dé ibi tí nǹkan ń mọ́ gaara dé. Síbẹ̀síbẹ̀, wúrà táa yọ́ mọ́ pàápàá ń ṣègbé, ìyẹn ni pé ó ń yòrò, táa bá da ásíìdì kan tí wọ́n ń pè ní aqua regia sí i, ásíìdì yìí jẹ́ àpòpọ̀ ìwọ̀n mẹ́ta ásíìdì hydrochloric àti ìwọ̀n kan ṣoṣo ásíìdì nitric. Fún ìdí yìí, ọ̀rọ̀ Bíbélì bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu nígbà tó sọ pé ‘wúrà ń ṣègbé.’
Ní ìyàtọ̀ pátápátá gbáà, ńṣe ni ìgbàgbọ́ Kristẹni tòótọ́ ‘ń pa ọkàn mọ́ láàyè.’ (Hébérù 10:39) Àwọn èèyàn lè pa ẹnì kan tó ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti pa Jésù Kristi. Àmọ́ ìlérí táa ṣe fáwọn tó ní ojúlówó ìgbàgbọ́ ni pé: “Jẹ́ olùṣòtítọ́ àní títí dé ikú, dájúdájú, èmi yóò sì fún ọ ní adé ìyè.” (Ìṣípayá 2:10) Àwọn tó bá ṣolóòótọ́ dójú ikú wà ní ìrántí Ọlọ́run, yóò sì jí wọn dìde. (Jòhánù 5:28, 29) Kò sí ìwọ̀n wúrà tó lè ṣe ìyẹn. Báa bá wò ó lọ́nà yìí, á óò rí i pé lóòótọ́ ni ìgbàgbọ́ níye lórí púpọ̀púpọ̀ ju wúrà lọ. Àmọ́ kí ìgbàgbọ́ tó lè níye lórí tóyẹn, a gbọ́dọ̀ dán an wò. Ní tòótọ́, ‘ìgbàgbọ́ táa ti dán wò’ ni Pétérù sọ pé ó níye lórí lọ́pọ̀lọpọ̀ ju wúrà. Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí o lè ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́, àti nínú Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀. Jésù sọ pé èyí ni yóò “túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 17:3.