Ìwọ Ha Rántí Bí?
Ìwọ Ha Rántí Bí?
Ǹjẹ́ o mọrírì kíka àwọn ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ ti ẹnu àìpẹ́ yìí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, wò ó bóyá o lè dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí:
• Kí nìdí táwọn ìbéèrè táa gbé dìde nínú Jóòbù orí kejìdínlógójì fi yẹ fún àgbéyẹ̀wò, kódà lóde òní pàápàá?
Ọ̀pọ̀ àgbàyanu iṣẹ́ tí Ọlọ́run pé àfiyèsí sí ni àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní pàápàá kò lóye rẹ̀ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Lára wọn ni bí agbára òòfà ṣe ń jẹ́ kí ayé wà lójú òpó tó ń tọ̀, ohun tí ìmọ́lẹ̀ jẹ́ gan-an, ìdí tí ọ̀kẹ́ àìmọye ọ̀kan-kò-jọ̀kan àwọn ìrì wínníwínní dídì fi wà, bí òjò ṣe ń kán, àti bí ààrá tó ń sán ṣe ń lo agbára.—4/15, ojú ìwé 4-11.
• Àwọn àpẹẹrẹ wo ló wà nínú Bíbélì tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí èrò òdì?
Ásáfù, Bárúkù, àti Náómì ní ìrẹ̀wẹ̀sì tàbí èrò òdì láwọn àkókò kan, àkọsílẹ̀ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ nípa bí wọ́n ṣe borí irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀ lè ràn wá lọ́wọ́.—4/15, ojú ìwé 22-24.
• Àwọn ọ̀nà gbígbéṣẹ́ wo la lè gba ran àwọn Kristẹni tó jẹ́ opó lọ́wọ́?
Àwọn ọ̀rẹ́ lè finú rere ṣèrànwọ́ lọ́nà tó ṣe kedere. Àwọn mẹ́ńbà ìdílé àtàwọn ẹlòmíràn lè fi owó tàbí nǹkan ìní ṣèrànwọ́, níbi tí àìní gidi bá wà. Àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn náà tún lè ṣèrànwọ́ nípa nínawọ́ ìfẹ́ ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ sí wọn, kí wọ́n sì máa fún wọn ní ìtìlẹ́yìn àti ìtùnú nípa tẹ̀mí.—5/1, ojú ìwé 5-7.
• Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì láti gbéyàwó “kìkì nínú Olúwa,” bí 1 Kọ́ríńtì 7:39 ṣe gbani nímọ̀ràn?
Bíbá àwọn aláìgbàgbọ́ ṣe ìgbéyàwó sábà máa ń yọrí sí jàǹbá. Àti pé, títẹ̀lé ìmọ̀ràn àtọ̀runwá yìí ń fi ìdúróṣinṣin wa sí Jèhófà Ọlọ́run hàn. Ọkàn wa kì í sì í dá wa lẹ́bi nígbà táa bá tẹ̀ lé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (1 Jòhánù 3:21, 22)—5/15, ojú ìwé 20-21.
• Nígbà tó jẹ́ pé Jèhófà nìkan ló lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, èé ṣe táwọn Kristẹni fi ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo fún àwọn àgbà ọkùnrin nínú ìjọ?
Ní tòótọ́, rírí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà ló yẹ kó jẹ Kristẹni kan lógún. (2 Sámúẹ́lì 12:13) Àmọ́, bí wòlíì Nátánì ṣe ran Dáfídì lọ́wọ́ ni àwọn àgbà ọkùnrin tó dàgbà dénú nínú ìjọ ṣe lè ran àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà lọ́wọ́. Títọ àwọn alàgbà lọ wà níbàámu pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà táa fúnni nínú Jákọ́bù 5:14, 15.— 6/1, ojú ìwé 31.
• Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé ó yẹ ká máa bójú tó àwọn ọmọ òrukàn àtàwọn opó tó jẹ́ aláìní?
Àkọsílẹ̀ fi hàn pé pípèsè irú àbójútó bẹ́ẹ̀ jẹ́ ara ohun táa fi ń dá ìsìn tòótọ́ mọ̀ láàárín àwọn Hébérù ìgbàanì àti láàárín àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀. (Ẹ́kísódù 22:22, 23; Gálátíà 2:9, 10; Jákọ́bù 1:27) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ ìtọ́ni tó ṣe kedere sínú Ìwé Mímọ́ fún àwọn Kristẹni pé kí wọ́n máa bójú tó àwọn opó tó jẹ́ tálákà. (1 Tímótì 5:3-16)—6/15, ojú ìwé 9-11.
• Kí ni àṣírí ìgbésí ayé tó láyọ̀, tó sì nítumọ̀?
A gbọ́dọ̀ ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà, Baba wa ọ̀run, ká má sì jẹ́ kí àjọṣe yẹn bà jẹ́. Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jẹ́ ọ̀nà pàtàkì táa lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀.—7/1, ojú ìwé 4-5.
• Ǹjẹ́ èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀mí tí kì í kú?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn kan gbà gbọ́ pé ẹ̀mí ló jẹ́ aláìleèkú, kì í ṣe ọkàn, Bíbélì kò fara mọ́ èrò yẹn. Ó fi hàn pé nígbà tí ẹnì kan bá kú, ó padà sí ekuru, kò sì sí mọ́. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ṣì ní agbára láti mú un padà wà láàyè, nítorí náà ìrètí èyíkéyìí tó ní fún wíwàláàyè lọ́jọ́ iwájú, nípasẹ̀ àjíǹde, wà lọ́wọ́ Ọlọ́run. (Oníwàásù 12:7)—7/15, ojú ìwé 3-6.
• Ibo ni Dáníẹ́lì wà nígbà táa ń dán àwọn Hébérù mẹ́ta náà wò ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dúrà?
Bíbélì kò sọ. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé wọn ò mú un ní dandan pé kí Dáníẹ́lì wà níbẹ̀ nítorí ipò rẹ̀, tàbí kó jẹ́ pé iṣẹ́ ìlú ló bá lọ lákòókò yẹn. Àmọ́, ìdánilójú wà pé kò fi ìṣòtítọ́ rẹ̀ sí Jèhófà báni dọ́rẹ̀ẹ́.—8/1, ojú ìwé 31.