Ní Irú Ìgbàgbọ́ Tí Ábúráhámù Ní!
Ní Irú Ìgbàgbọ́ Tí Ábúráhámù Ní!
“Àwọn tí ó rọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ ni àwọn tí ó jẹ́ ọmọ Ábúráhámù.”—GÁLÁTÍÀ 3:7.
1. Ọgbọ́n wo ni Ábúrámù rí dá sí àdánwò tuntun tó dé bá a ní Kénáánì?
ÁBÚRÁMÙ fi ìgbésí ayé ìdẹ̀ra tó ń gbé nílùú Úrì sílẹ̀ nítorí àṣẹ tí Jèhófà pa fún un. Kékeré ni gbogbo ìnira tó dé bá a láwọn ọdún tó tẹ̀ lé e jẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ àdánwò ìgbàgbọ́ tó dojú kọ lẹ́yìn náà ní Íjíbítì. Bíbélì ròyìn pé: “Wàyí o, ìyàn kan mú ní ilẹ̀ náà.” Ẹ wo bí ì bá ti rọrùn tó fún Ábúrámù láti bara jẹ́ nítorí ipò tó wà yìí! Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ṣe ohun tó lè ṣe láti gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ̀. “Ábúrámù sì sọ̀ kalẹ̀ lọ ní ọ̀nà rẹ̀ sí Íjíbítì láti ṣe àtìpó níbẹ̀, nítorí pé ìyàn náà mú gidigidi ní ilẹ̀ náà.” Ṣàṣà lẹni tí kò ní mọ agboolé ńlá Ábúrámù ní Íjíbítì. Ǹjẹ́ Jèhófà yóò mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, kí ó sì kó Ábúrámù yọ nínú ewu?—Jẹ́nẹ́sísì 12:10; Ẹ́kísódù 16:2, 3.
2, 3. (a) Èé ṣe tí Ábúrámù kò fi jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ìyàwó òun ni Sárà? (b) Lójú ipò tó wà nílẹ̀, ọwọ́ wo ni Ábúrámù fi mú aya rẹ̀?
2 Jẹ́nẹ́sísì 12:11-13 kà pé: “Ó sì ṣẹlẹ̀ pé gbàrà tí ó sún mọ́ àtiwọnú Íjíbítì, nígbà náà ni ó sọ fún Sáráì aya rẹ̀ pé: ‘Wàyí o, jọ̀wọ́! Mo mọ̀ dáadáa pé o jẹ́ obìnrin kan tí ó lẹ́wà ní ìrísí. Nítorí náà, ó dájú pé yóò ṣẹlẹ̀ pé àwọn ará Íjíbítì yóò rí ọ, wọn yóò sì wí pé, “Aya rẹ̀ nìyí.” Dájúdájú, wọn yóò sì pa mi, ṣùgbọ́n ìwọ ni wọn yóò pa mọ́ láàyè. Jọ̀wọ́, sọ pé arábìnrin mi ni ọ́, kí ó bàa lè lọ dáadáa fún mi ní tìtorí rẹ, ó sì dájú pé ọkàn mi yóò wà láàyè nítorí rẹ.’” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sáráì ti lé lẹ́ni ọdún márùndínláàádọ́rin [65], obìnrin yẹn ṣì lẹ́wà gan-an. Èyí sì fi ẹ̀mí Ábúrámù sínú ewu. a (Jẹ́nẹ́sísì 12:4, 5; 17:17) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ọ̀ràn yìí wé mọ́ ète Jèhófà, nítorí ó ti sọ pé ipasẹ̀ irú ọmọ Ábúrámù ni gbogbo orílẹ̀-èdè ayé yóò gbà bù kún ara wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 12:2, 3, 7) Nígbà tó sì jẹ́ pé Ábúrámù ò tíì bímọ di báa ti ń wí yìí, bó bá kú, nǹkan bà jẹ́ nìyẹn.
3 Ábúrámù fọ̀ràn náà lọ aya rẹ̀, wọ́n sì jọ fẹnu kò pé ọgbọ́n làwọn máa ta sí i, ńṣe ni kí Sáráì sọ pé àbúrò Ábúrámù lòun. Kíyè sí i pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni baálé ilé, kò kàn pàṣẹ wàá, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló kọ́kọ́ wá ọ̀nà láti jèrè ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti ìtìlẹyìn aya rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 12:11-13; 20:13) Nínú ọ̀ràn yìí, Ábúrámù fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fáwọn ọkọ, pé kí wọ́n máa fìfẹ́ lo ipò orí wọn, Sáráì ní tirẹ̀ sì jẹ́ àpẹẹrẹ rere fáwọn aya lónìí, nítorí pé ó tẹrí ba fún ọkọ rẹ̀.—Éfésù 5:23-28; Kólósè 4:6.
4. Ìgbésẹ̀ wo ló yẹ káwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run gbé lónìí nígbà tí ẹ̀mí àwọn ará wọn bá wà nínú ewu?
4 Irọ́ kọ́ ni Sáráì pa nígbà tó sọ pé àbúrò Ábúrámù lòun, torí pé ọbàkan ni wọ́n lóòótọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 20:12) Ìyẹn nìkan kọ́ o, kì í ṣe ọ̀ranyàn fún Ábúrámù láti sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe jẹ́ gan-an fún ẹnikẹ́ni tí ọ̀ràn ò kàn. (Mátíù 7:6) Àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run láyé táa wà yìí ń pa àṣẹ Bíbélì mọ́ pé kí wọ́n máa ṣòótọ́. (Hébérù 13:18) Fún àpẹẹrẹ, wọn ò jẹ́ purọ́ lẹ́yìn bíbúra ní ilé ẹjọ́. Àmọ́ o, nígbà tí ẹ̀mí àwọn ará wọn bá wà nínú ewu, yálà nípa tara tàbí nípa tẹ̀mí, bóyá nígbà inúnibíni tàbí rògbòdìyàn, wọ́n máa ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù pé kí wọ́n “jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra gẹ́gẹ́ bí ejò, síbẹ̀ kí [wọ́n] jẹ́ ọlọ́rùn-mímọ́ gẹ́gẹ́ bí àdàbà.”—Mátíù 10:16; wo Ilé Ìṣọ́, November 1, 1996, ojú ìwé 18, ìpínrọ̀ 19.
5. Kí nìdí tí Sáráì fi gbà láti gbọ́rọ̀ sí Ábúrámù lẹ́nu?
5 Ojú wo ni Sáráì fi wo ohun tí Ábúrámù ní kó ṣe yìí? Àpọ́sítélì Pétérù pe irú obìnrin bíi tirẹ̀ ní àwọn “tí wọ́n ní ìrètí nínú Ọlọ́run.” Nítorí náà, Sáráì mọ̀ pé ọ̀rọ̀ nípa nǹkan tẹ̀mí ló délẹ̀ yìí. Yàtọ̀ síyẹn, ó nífẹ̀ẹ́ ọkọ rẹ̀, kò sì kóyán rẹ̀ kéré. Ìyẹn ló jẹ́ kí Sáráì yàn láti ‘fi ara rẹ̀ sábẹ́ ọkọ rẹ̀,’ tí kò sì jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé tọkọtaya làwọn. (1 Pétérù 3:5) Àmọ́, ohun tó ṣe yẹn léwu nínú o. “Gbàrà tí Ábúrámù wọ Íjíbítì, àwọn ará Íjíbítì sì rí obìnrin náà, pé ó lẹ́wà gidigidi. Àwọn ọmọ aládé Fáráò sì rí i pẹ̀lú, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí yìn ín lójú Fáráò, tí ó fi jẹ́ pé a mú obìnrin náà lọ sí ilé Fáráò.”—Jẹ́nẹ́sísì 12:14, 15.
Jèhófà Gbà Wọ́n
6, 7. Inú wàhálà wo ni Ábúrámù àti Sáráì kó sí, báwo sì ni Jèhófà ṣe kó Sáráì yọ?
6 Áà, èyí á mà fa ìbànújẹ́ púpọ̀ fún Ábúrámù àti Sáráì o! Sáráì ni wọ́n fẹ́ bá ṣèṣekúṣe yìí. Fáráò, tí kò kúkú mọ̀ pé aya aláya ni Sáráì, tún wá lọ ń kó ẹ̀bùn rẹpẹtẹ fún Ábúrámù, tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó “wá ní àwọn àgùntàn àti àwọn màlúù àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti àwọn ràkúnmí.” b (Jẹ́nẹ́sísì 12:16) Ẹ̀bùn wọ̀nyẹn ò tiẹ̀ ní jọ Ábúrámù lójú rárá! Nínú gbogbo pákáǹleke yìí, Jèhófà kò gbàgbé Ábúrámù.
7 “Nígbà náà ni Jèhófà fọwọ́ ìyọnu àjàkálẹ̀ ńlá ba Fáráò àti agbo ilé rẹ̀ nítorí Sáráì, aya Ábúrámù.” (Jẹ́nẹ́sísì 12:17) A ò mọ bí Fáráò ṣe mọ ohun náà gan-an tó fa “ìyọnu àjàkálẹ̀” wọ̀nyẹn. Ojú ẹsẹ̀ ló gbégbèésẹ̀: “Pẹ̀lú èyí, Fáráò pe Ábúrámù, ó sì wí pé: ‘Kí ni ìwọ ṣe sí mi yìí? Èé ṣe tí ìwọ kò fi sọ fún mi pé aya rẹ ni? Èé ṣe tí o fi sọ pé, “Arábìnrin mi ni” tí mo fi fẹ́rẹ̀ẹ́ mú un ṣe aya mi? Wàyí o, aya rẹ rèé. Mú un, kí o sì máa lọ!’ Fáráò sì pa àṣẹ fún àwọn ọkùnrin nípa rẹ̀, wọ́n sì sin òun àti aya rẹ̀ àti gbogbo ohun tí ó ní jáde.”—Jẹ́nẹ́sísì 12:18-20; Sáàmù 105:14, 15.
8. Irú ààbò wo ni Jèhófà ṣèlérí fáwọn Kristẹni lónìí?
8 Lónìí, Jèhófà kò ṣèlérí fún wa pé ikú, ìwà ọ̀daràn, ìyàn, tàbí ìjábá kò lè rí wa gbé ṣe. Ohun tí Jèhófà ṣèlérí ni pé òun yóò máa dáàbò bò wá nígbà gbogbo lọ́wọ́ àwọn nǹkan tó lè ba ipò tẹ̀mí wa jẹ́. (Sáàmù 91:1-4) Ọ̀nà pàtàkì tó ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó ń pèsè ìkìlọ̀ tó bá àkókò mu, nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” (Mátíù 24:45) Tí àwọn onínúnibíni bá wá ń fi ikú halẹ̀ mọ́ wa ńkọ́? Òótọ́ ni pé Ọlọ́run lè yọ̀ǹda kí àwọn kan kú, ṣùgbọ́n kò ní gbà láé kí àwọn èèyàn rẹ̀ lódindi kú àkúrun. (Sáàmù 116:15) Bí ikú bá sì mú àwọn olóòótọ́ kan lọ, a mọ̀ pé àjíǹde wọ́n dájú.—Jòhánù 5:28, 29.
Ó Fi Nǹkan Du Ara Rẹ̀ Kí Àlàáfíà Lè Wà
9. Kí ló fi hàn pé Ábúrámù kò tẹ̀ dó sójú kan ní Kénáánì?
9 Nígbà tí ìyàn náà ti kásẹ̀ ńlẹ̀ ní Kénáánì, “Ábúrámù gòkè lọ kúrò ní Íjíbítì, òun àti aya rẹ̀ àti gbogbo ohun tí ó ní, àti Lọ́ọ̀tì pẹ̀lú rẹ̀, sí Négébù [ìyẹn, àgbègbè tí òjò kì í ti í dunlẹ̀ ní gúúsù àwọn òkè ńlá Júdà]. Ábúrámù sì ní ọ̀pọ̀ wọ̀ǹtìwọnti ọ̀wọ́ ẹran àti fàdákà àti wúrà.” (Jẹ́nẹ́sísì 13:1, 2) Nítorí èyí, àwọn ará àdúgbò yẹn á máa fojú èèyàn ńlá, ojú bọ̀rọ̀kìnní wò ó, wọ́n á kà á sí ìjòyè pàtàkì. (Jẹ́nẹ́sísì 23:6) Ábúrámù kò ní èrò fífi ibẹ̀ ṣelé, kí ó sì wá tọrùn bọ ọ̀ràn òṣèlú ní Kénáánì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó “mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n lọ láti ibùdó sí ibùdó jáde kúrò ní Négébù àti sí Bẹ́tẹ́lì, sí ibi tí àgọ́ rẹ̀ ti wà ní àkọ́kọ́, láàárín Bẹ́tẹ́lì àti Áì.” Bí Ábúrámù ti sábà máa ń ṣe, ìjọsìn Jèhófà ló jẹ ẹ́ lógún níbikíbi tó bá lọ.—Jẹ́nẹ́sísì 13:3, 4.
10. Ìṣòro wo ló dìde láàárín àwọn darandaran Ábúrámù àti ti Lọ́ọ̀tì, èé sì ti ṣe tó fi pọndandan pé kí wọ́n tètè yanjú rẹ̀?
10 “Wàyí o, Lọ́ọ̀tì pẹ̀lú, ẹni tí ń bá Ábúrámù lọ, ní àwọn àgùntàn àti màlúù àti àwọn àgọ́. Nítorí èyí, ilẹ̀ náà kò gba gbogbo wọn láti máa gbé pa pọ̀, nítorí pé ẹrù wọn ti di púpọ̀, gbogbo wọn kò sì lè máa gbé pa pọ̀. Aáwọ̀ sì dìde láàárín àwọn olùda ohun ọ̀sìn Ábúrámù àti àwọn olùda ohun ọ̀sìn Lọ́ọ̀tì; ní àkókò yẹn, àwọn ọmọ Kénáánì àti àwọn Pérísì sì ń gbé ní ilẹ̀ náà.” (Jẹ́nẹ́sísì 13:5-7) Omi àti pápá ìjẹko tó wà ní ilẹ̀ náà kò tó àwọn agbo ẹran Ábúrámù àti ti Lọ́ọ̀tì mọ́. Ni èdèkòyédè àti gbúngbùngbún bá bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn darandaran náà. Irú aáwọ̀ bẹ́ẹ̀ ò sì yẹ àwọn olùjọsìn Ọlọ́run tòótọ́. Bí wọn ò bá sì tètè yanjú awuyewuye yìí, ó lè dá ìjà tí kò ní tán sílẹ̀. Báwo wá ni Ábúrámù ṣe máa yanjú ọ̀ràn tó délẹ̀ yìí? Ó ti gba Lọ́ọ̀tì ṣọmọ lẹ́yìn tí bàbá Lọ́ọ̀tì kú, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun ló tọ́ ọ dàgbà bíi pé ọmọ tirẹ̀ gan-an ni. Nígbà tó sì jẹ́ pé Ábúrámù làgbà, ṣé kò lẹ́tọ̀ọ́ láti yan ibi tó dára jù lọ fún ara rẹ̀ ni?
11, 12. Àǹfààní ńlá wo ni Ábúrámù nawọ́ rẹ̀ sí Lọ́ọ̀tì, èé sì ti ṣe tí ibi tí Lọ́ọ̀tì yàn kò fi bọ́gbọ́n mu?
11 Ṣùgbọ́n “Ábúrámù sọ fún Lọ́ọ̀tì pé: ‘Jọ̀wọ́, má ṣe jẹ́ kí aáwọ̀ máa bá a lọ láàárín èmi àti ìwọ àti láàárín àwọn olùṣọ́ agbo ẹran mi àti àwọn olùṣọ́ agbo ẹran rẹ, nítorí arákùnrin ni wá. Gbogbo ilẹ̀ kò ha wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ? Jọ̀wọ́, yà sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi. Bí ìwọ bá lọ sí apá òsì, nígbà náà, èmi yóò lọ sí apá ọ̀tún; ṣùgbọ́n bí ìwọ bá lọ sí apá ọ̀tún, nígbà náà, èmi yóò lọ sí apá òsì.’” Ibì kan ń bẹ nítòsí Bẹ́tẹ́lì tí wọ́n sọ pé ó jẹ́ “ọ̀kan lára ibi tó dára jù lọ láti dúró sí wo òréré Palẹ́sìnì.” Bóyá látibẹ̀, “Lọ́ọ̀tì gbé ojú rẹ̀ sókè, ó sì rí gbogbo Àgbègbè Jọ́dánì, pé gbogbo rẹ̀ jẹ́ ẹkùn ilẹ̀ olómi púpọ̀ kí Jèhófà tó run Sódómù àti Gòmórà, bí ọgbà Jèhófà, bí ilẹ̀ Íjíbítì títí dé Sóárì.”—Jẹ́nẹ́sísì 13:8-10.
12 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì pe Lọ́ọ̀tì ní “olódodo,” fún ìdí kan tàbí òmíràn, kò ka Ábúrámù kún nínú ọ̀ràn yìí, kò sì jọ pé ó fọ̀ràn lọ àgbà iwájú rẹ̀. (2 Pétérù 2:7) “Lọ́ọ̀tì yan gbogbo Àgbègbè Jọ́dánì fún ara rẹ̀, Lọ́ọ̀tì sì ṣí ibùdó rẹ̀ lọ sí ìlà-oòrùn. Nítorí náà, wọ́n yà sọ́tọ̀, ẹnì kìíní kúrò lọ́dọ̀ ẹnì kejì. Ábúrámù ń gbé ní ilẹ̀ Kénáánì, ṣùgbọ́n Lọ́ọ̀tì ń gbé láàárín àwọn ìlú ńlá Àgbègbè náà. Níkẹyìn, ó pàgọ́ sí tòsí Sódómù.” (Jẹ́nẹ́sísì 13:11, 12) Ìlú aásìkí, téèyàn ti lè tètè dọlọ́rọ̀ ni Sódómù. (Ìsíkíẹ́lì 16:49, 50) Téèyàn bá sì ro ti nǹkan tara wọ̀nyí, ó lè jọ pé ibi tí Lọ́ọ̀tì yàn yìí ló dáa jù, àmọ́ téèyàn bá fojú tẹ̀mí wò ó, á rí i pé kò rò ó re. Èé ṣe? Nítorí Jẹ́nẹ́sísì 13:13 sọ pé “àwọn ọkùnrin Sódómù . . . burú, wọ́n sì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ paraku sí Jèhófà.” Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ibi tí Lọ́ọ̀tì yàn yìí á kó ìdílé rẹ̀ sí yọ́ọ́yọ́ọ́.
13. Báwo ni àpẹẹrẹ Ábúrámù ṣe lè ṣèrànwọ́ fáwọn Kristẹni tó bá ń ṣawuyewuye lórí ọ̀ràn owó?
13 Ábúrámù ní tirẹ̀ gba ìlérí Jèhófà gbọ́, pé irú ọmọ òun ni yóò jogún gbogbo ilẹ̀ yẹn bópẹ́ bóyá; kò tiẹ̀ ṣòpò ṣawuyewuye nítorí apá kékeré kan lára ilẹ̀ náà. Ó fi ọ̀ràn náà ṣe osùn, ó fi pa ara, ó gbégbèésẹ̀ níbàámu pẹ̀lú ìlànà táa gbé kalẹ̀ lẹ́yìn náà nínú 1 Kọ́ríńtì 10:24, pé: “Kí olúkúlùkù má ṣe máa wá àǹfààní ti ara rẹ̀, bí kò ṣe ti ẹnì kejì.” Ìránnilétí tó dára rèé fáwọn ará tó bá ń bára wọn fa wàhálà nítorí ọ̀ràn owó. Dípò kí àwọn kan tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú Mátíù 18:15-17, ńṣe ni wọ́n ń gbé arákùnrin wọn lọ sílé ẹjọ́. (1 Kọ́ríńtì 6:1, 7) Àpẹẹrẹ Ábúrámù fi hàn pé ó sàn kéèyàn pàdánù owó ju pé kó mú ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà tàbí kí ó ṣe nǹkan tó máa da ìjọ Kristẹni rú.—Jákọ́bù 3:18.
14. Báwo la ó ṣe san èrè fún Ábúrámù nítorí ìwà ọ̀làwọ́ rẹ̀?
14 A ó san èrè fún Ábúrámù nítorí ìwà ọ̀làwọ́ rẹ̀ yìí. Ọlọ́run polongo pé: “Èmi yóò sì sọ irú-ọmọ rẹ dà bí egunrín ekuru ilẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé, bí ènìyàn kan bá lè ka egunrín ekuru ilẹ̀, nígbà náà, irú-ọmọ rẹ ni a ó lè kà.” Ẹ wo ìṣírí ńláǹlà tí ìṣípayá yìí yóò jẹ́ fún Ábúrámù tí kò tíì bímọ! Lẹ́yìn èyí, Ọlọ́run pàṣẹ pé: “Dìde, lọ káàkiri la ilẹ̀ náà já ní gígùn rẹ̀ àti ní ìbú rẹ̀, nítorí pé ìwọ ni èmi yóò fi í fún.” (Jẹ́nẹ́sísì 13:16, 17) Rárá, a kò ní yọ̀ǹda kí Ábúrámù fìdí kalẹ̀ kí ó sì máa jayé orí rẹ̀ nínú ìlú ńlá. Nǹkan kan kò gbọ́dọ̀ da òun àtàwọn ará Kénáánì pọ̀. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lónìí, nǹkan kan kò gbọ́dọ̀ da àwọn Kristẹni àti ayé pọ̀. Kì í ṣe pé wọ́n ka ara wọn sí ẹni tó mọ́ ju àwọn yòókù lọ, àmọ́ wọn kì í ṣe wọlé wọ̀de pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tó lè mú wọn hu ìwà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu.—1 Pétérù 4:3, 4.
15. (a) Kí ló ṣeé ṣe kó jẹ́ ìdí fún ìrìnkèrindò Ábúrámù? (b) Àpẹẹrẹ wo ni Ábúrámù fi lélẹ̀ fáwọn ìdílé Kristẹni lóde òní?
15 Nígbà táa ń kọ Bíbélì, kéèyàn tó ra ilẹ̀, ó lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ́kọ́ lọ yẹ̀ ẹ́ wò. Rírìn yí ká ilẹ̀ yìí lè tipa báyìí tẹ̀ ẹ́ mọ́ Ábúrámù lọ́kàn pé, níjọ́ ọjọ́ kan, ilẹ̀ yìí yóò di ti àtọmọdọ́mọ òun. Láìjiyàn, “Ábúrámù ń bá a lọ láti gbé nínú àwọn àgọ́. Lẹ́yìn náà, ó wá, ó sì ń gbé láàárín àwọn igi ńlá Mámúrè, èyí tí ó wà ní Hébúrónì; ibẹ̀ ni ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí mọ pẹpẹ kan fún Jèhófà.” (Jẹ́nẹ́sísì 13:18) Ábúrámù tún fi hàn lẹ́ẹ̀kan sí i pé ọ̀ràn ìjọsìn jẹ òun lógún. Ṣé ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé, àdúrà ìdílé, àti lílọ sípàdé jẹ ìdílé tìrẹ náà lógún?
Ogun Ọ̀tá Dé
16. (a) Èé ṣe tí ọ̀rọ̀ ìṣáájú inú Jẹ́nẹ́sísì 14:1 kò fi fọre? (b) Kí nìdí táwọn ọba ìlà oòrùn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin fi kógun dé?
16 “Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ ní àwọn ọjọ́ Ámúráfélì ọba Ṣínárì, Áríókù ọba Élásárì, Kedoláómà ọba Élámù, c àti Tídálì ọba Góíímù, pé àwọn wọ̀nyí” kógun dé. Nínú èdè Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀, ọ̀rọ̀ ìṣáájú yìí (“Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ ní àwọn ọjọ́ . . . ”) kò fọre, ńṣe ló ń tọ́ka sí “sáà àdánwò tí yóò yọrí sí ìbùkún.” (Jẹ́nẹ́sísì 14:1, 2, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Àdánwò ọ̀hún bẹ̀rẹ̀ nígbà tí àwọn ọba ìlà oòrùn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí àtàwọn ọmọ ogun wọn kó ogun ńlá ja ilẹ̀ Kénáánì. Kí ni ète wọn? Láti paná ọ̀tẹ̀ tí ìlú ńlá márààrún náà Sódómù, Gòmórà, Ádímà, Sébóímù, àti Bélà dì. Lẹ́yìn tí wọ́n ṣe àwọn ọmọ ogun ìlú wọ̀nyẹn bọ́ṣẹ ṣe ń ṣojú, wọ́n wá “lọ, gẹ́gẹ́ bí alájọṣepọ̀, sí Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Rírẹlẹ̀ Sídímù, [èyíinì] ni, Òkun Iyọ̀.” Itòsí ibẹ̀ ni Lọ́ọ̀tì àti ìdílé rẹ̀ ń gbé.—Jẹ́nẹ́sísì 14:3-7.
17. Èé ṣe tí mímú tí wọ́n mú Lọ́ọ̀tì lóǹdè fi jẹ́ ìdánwò ìgbàgbọ́ fún Ábúrámù?
17 Àwọn ọba Kénáánì fìjà pẹẹ́ta pẹ̀lú àwọn tó kógun wá jà wọ́n, ṣùgbọ́n a ṣẹ́gunṣẹ́tẹ̀ wọn. “Lẹ́yìn náà, àwọn ajagunmólú kó gbogbo àwọn ẹrù Sódómù àti Gòmórà àti gbogbo oúnjẹ wọn, wọ́n sì bá ọ̀nà wọn lọ. Wọ́n tún kó Lọ́ọ̀tì ọmọkùnrin arákùnrin Ábúrámù àti àwọn ẹrù rẹ̀, wọ́n sì ń bá ọ̀nà wọn lọ. Ó ń gbé ní Sódómù nígbà yẹn.” Kò pẹ́ tí ìròyìn tí ń bani nínú jẹ́ yìí fi dé etí ìgbọ́ Ábúrámù: “Lẹ́yìn ìyẹn, ọkùnrin kan tí ó ti sá àsálà wá, ó sì sọ fún Ábúrámù tí í ṣe Hébérù. Nígbà yẹn, ó pàgọ́ sáàárín àwọn igi ńlá Mámúrè tí í ṣe Ámórì, arákùnrin Éṣíkólì àti arákùnrin Ánérì; wọ́n sì jẹ́ alájùmọ̀ṣepọ̀ pẹ̀lú Ábúrámù. Nípa báyìí, Ábúrámù gbọ́ pé a ti mú arákùnrin òun ní òǹdè.” (Jẹ́nẹ́sísì 14:8-14) Ìdánwò ìgbàgbọ́ rèé o! Ǹjẹ́ Ábúrámù máa di ọmọ arákùnrin rẹ̀ sínú nítorí pé ó yan èyí tó dára jù lọ nínú ilẹ̀ náà? Ká má sì gbàgbé o, pé Ṣínárì ilẹ̀ ìbílẹ̀ rẹ̀ làwọn agbóguntini yìí ti wá. Láti lọ dojúùjà kọ wọ́n túmọ̀ sí pé àtipadà sílé kò lè ṣeé ṣe mọ́ láé nìyẹn o. Yàtọ̀ síyẹn, báwo ni apá Ábúrámù ṣe lè ká agbo ọmọ ogun tí àpapọ̀ gbogbo ọmọ ogun ilẹ̀ Kénáánì kò lè ṣẹ́gun?
18, 19. (a) Báwo ni Ábúrámù ṣe dá Lọ́ọ̀tì nídè? (b) Ta ni ọpẹ́ yẹ nítorí ìṣẹ́gun yìí?
18 Ábúrámù tún gbára lé Jèhófà pátápátá. “Pẹ̀lú ìyẹn, ó pe àwọn ọkùnrin tí ó ti kọ́ jọ, ọ̀ọ́dúnrún lé méjìdínlógún ẹrú tí a bí ní agbo ilé rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa wọn títí dé Dánì. Nígbà tí ó sì di òru, ó yíjú sí pípín àwọn agbo ọmọ ogun rẹ̀, òun àti àwọn ẹrú rẹ̀, láti gbéjà kò wọ́n, ó sì tipa báyìí ṣẹ́gun wọn, ó sì ń lépa wọn nìṣó títí dé Hóbà, tí ó jẹ́ àríwá Damásíkù. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gba gbogbo àwọn ẹrù náà padà, ó sì tún gba Lọ́ọ̀tì arákùnrin rẹ̀ àti àwọn ẹrù àti àwọn obìnrin àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú padà.” (Jẹ́nẹ́sísì 14:14-16) Nítorí ìgbàgbọ́ lílágbára tí Ábúrámù ní nínú Jèhófà, agbo ọmọ ogun rẹ̀ tí kò tó nǹkan rárá lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ ogun ọ̀tá ló ṣẹ́gun, ó sì dá Lọ́ọ̀tì àti ìdílé rẹ̀ nídè. Wàyí o, Ábúrámù pàdé Melikisédékì, tí í ṣe ọba-òun-àlùfáà ìlú Sálẹ́mù. “Melikisédékì ọba Sálẹ́mù sì gbé oúnjẹ àti wáìnì jáde, òun sì ni àlùfáà Ọlọ́run Gíga Jù Lọ. Nígbà náà, ó súre fún un, ó sì wí pé: ‘Ìbùkún ni fún Ábúrámù láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Gíga Jù Lọ wá, Ẹni tí Ó Ṣe ọ̀run àti ilẹ̀ ayé; ìbùkún sì ni fún Ọlọ́run Gíga Jù Lọ, ẹni tí ó ti fi àwọn tí ń ni ọ́ lára lé ọ lọ́wọ́!’ Látàrí èyí, Ábúrámù fi ìdá mẹ́wàá ohun gbogbo fún un.”—Jẹ́nẹ́sísì 14:18-20.
19 Dájúdájú, ti Jèhófà ni ìṣẹ́gun. Nítorí ìgbàgbọ́ Ábúrámù, ó tún rí ìdáǹdè Jèhófà lẹ́ẹ̀kan sí i. Àwọn èèyàn Ọlọ́run lóde òní kì í ja ogun nípa tara, àmọ́ wọ́n ń dojú kọ ọ̀pọ̀ àdánwò àti ìpèníjà. Àpilẹ̀kọ wa tó tẹ̀ lé e yóò fi hàn bí àpẹẹrẹ Ábúrámù ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí nínú kíkojú ipò wọ̀nyí.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Gẹ́gẹ́ bí ìwé Insight on the Scriptures (táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde) ti wí, “ìwé ayé àtijọ́ kan sọ nípa Fáráò kan tó pàṣẹ pé káwọn kan tó dira ogun mú obìnrin òrékelẹ́wà kan, kí wọ́n sì pa ọkọ rẹ̀.” Fún ìdí yìí, Ábúrámù mọ itú tí wọ́n lè pa.
b Ó ṣeé ṣe kí Hágárì, tó di wáhàrì Ábúrámù lẹ́yìn náà, wà lára àwọn ìránṣẹ́ táa fún Ábúrámù lákòókò yìí.—Jẹ́nẹ́sísì 16:1.
c Àwọn olùṣelámèyítọ́ sọ nígbà kan pé Élámù ò fìgbà kan rí ní irú agbára yẹn lágbègbè Ṣínárì, wọ́n ní irọ́ ni ìtàn nípa ogun tí Kedoláómà wá jà. Ìjíròrò nípa ẹ̀rí táa hú jáde nínú ilẹ̀ tó ti àkọsílẹ̀ Bíbélì lẹ́yìn wà nínú Ilé-Ìṣọ́nà, July 1, 1989, ojú ìwé 4 sí 7.
Ǹjẹ́ O Ṣàkíyèsí?
• Báwo ni ìyàn tó mú ní ilẹ̀ Kénáánì ṣe wá di ìdánwò ìgbàgbọ́ fún Ábúrámù?
• Báwo ni Ábúrámù àti Sáráì ṣe fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fáwọn ọkọ àti aya lóde òní?
• Àwọn ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú ọ̀nà tí Ábúrámù gbà yanjú awuyewuye tó wáyé láàárín àwọn ìránṣẹ́ tirẹ̀ àti ti Lọ́ọ̀tì?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Ábúrámù kò wonkoko mọ́ ẹ̀tọ́ rẹ̀ ṣùgbọ́n ó fi ire Lọ́ọ̀tì ṣíwájú ti ara rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ábúrámù fi hàn pé òun gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nígbà tó lọ dá Lọ́ọ̀tì ọmọ arákùnrin rẹ̀ nídè