Èṣù Kì Í Ṣe Ẹni Ìtàn Àròsọ
Èṣù Kì Í Ṣe Ẹni Ìtàn Àròsọ
“Májẹ̀mú tuntun látòkèdélẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa agbára Ọlọ́run àti ti ìwà rere ní ìdojúùjàkọ agbára ibi, tí Sátánì ń lò. Èyí kì í kàn-án ṣe ìgbàgbọ́ òǹkọ̀wé kan tàbí méjì, àmọ́ gbogbo wọn ló gbà bẹ́ẹ̀. . . . Májẹ̀mú Tuntun fi èyí hàn kedere. Sátánì olubi wà lóòótọ́, ìgbà gbogbo ló máa ń kọjú ìjà sí Ọlọ́run àtàwọn èèyàn Ọlọ́run.”—“The New Bible Dictionary.”
KÍ WÁ nìdí tí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń pera wọn ní Kristẹni—tí wọ́n sọ pé àwọn gba Bíbélì gbọ́—fi sọ pé àwọn ò gbà pé Èṣù kan wà níbì kan? Òótọ́ ìdí ọ̀rọ̀ náà ni pé wọn ò gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì. (Jeremáyà 8:9) Wọ́n sọ pé ìmọ̀ ọgbọ́n orí àwọn orílẹ̀-èdè tó ń gbé ní àyíká àwọn tó kọ Bíbélì ló kún inú ohun tí wọ́n kọ, wọ́n ní fún ìdí yìí, ohun tí wọ́n kọ sínú rẹ̀ kì í ṣe òtítọ́ tó péye látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Fún àpẹẹrẹ, Hans Küng, ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn Kátólíìkì nì, kọ̀wé pé: “Àwọn ìtàn àròsọ nípa Sátánì pẹ̀lú ẹgbàágbèje irúnmalẹ̀ rẹ̀ . . . yọ́ wọlé látinú ìtàn ìwáṣẹ̀ àwọn ará Bábílónì, ó sì wọnú ẹ̀sìn àwọn Júù ìjímìjí, ibẹ̀ ló sì gbà yọ́ wọnú Májẹ̀mú Tuntun.”—On Being a Christian.
Ṣùgbọ́n Bíbélì kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹ̀dá ènìyàn lásán-làsàn; ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí ni lóòótọ́. Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé ká fojú pàtàkì wo ohun tó sọ nípa Èṣù.—2 Tímótì 3:14-17; 2 Pétérù 1:20, 21.
Kí Ni Èrò Jésù?
Jésù Kristi gbà gbọ́ pé Èṣù wà lóòótọ́. Kì í ṣe èrò ibi lásán tó wà nínú Jésù ló bẹ̀rẹ̀ sí dán Jésù wò. Ẹni gidi kan ló gbéjà kò ó, ẹni yìí ló wá pè ní “olùṣàkóso ayé” lẹ́yìn náà. (Jòhánù 14:30; Mátíù 4:1-11) Ó tún gbà gbọ́ pé àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí mìíràn lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú Sátánì nínú iṣẹ́ ibi rẹ̀. Ó wo àwọn èèyàn “tí ẹ̀mí èṣù ti sọ di òǹdè” sàn. (Mátíù 12:22-28) Àní ìwé kan táwọn kan tí kò gbà pé Ọlọ́run wà kọ, tí wọ́n pè ní A Rationalist Encyclopædia sọ ìjẹ́pàtàkì èyí nígbà tó sọ pé: “Òtítọ́ náà pé Jésù táa sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú Àwọn Ìwé Ìhìn Rere gbà pé àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí búburú wà ti dá ìṣòro ńlá sílẹ̀ fáwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn.” Nígbà tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa Èṣù àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀, kì í ṣe pé ó wulẹ̀ ń tún ìgbàgbọ́ nínú ohun asán tó wá látinú ìtàn àròsọ àwọn ará Bábílónì sọ. Ó mọ̀ pé wọ́n wà lóòótọ́.
A óò túbọ̀ mọ̀ nípa Èṣù táa bá ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fáwọn tí ń kọ́ni ní ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn nígbà ayé rẹ̀, ó sọ pé: “Láti ọ̀dọ̀ Èṣù baba yín ni ẹ ti wá, ẹ sì ń fẹ́ láti ṣe àwọn ìfẹ́-ọkàn baba yín. Apànìyàn ni ẹni yẹn nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀, kò sì dúró ṣinṣin nínú òtítọ́, nítorí pé òtítọ́ kò sí nínú rẹ̀. Nígbà tí ó bá ń pa irọ́, ó ń sọ̀rọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìtẹ̀sí-ọkàn ara rẹ̀, nítorí pé òpùrọ́ ni àti baba irọ́.”—Jòhánù 8:44.
Gẹ́gẹ́ bí ohun táa kà yìí ti wí, ‘òpùrọ́ àti baba irọ́’ ni Èṣù, ẹni tórúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí “afọ̀rọ̀-èké-bani-jẹ́.” Òun ni ẹ̀dá àkọ́kọ́ tó purọ́ mọ́ Ọlọ́run, ó sì pẹ́ gan-an tó ti purọ́ yẹn nínú ọgbà Édẹ́nì. Jèhófà sọ pé àwọn òbí wa ìpilẹ̀ṣẹ̀ ‘yóò kú dájúdájú’ bí wọ́n bá jẹ lára èso igi ìmọ̀ rere àti búburú. Sátánì gba ẹnu ejò kan sọ pé irọ́ ni ohun tí Ọlọ́run sọ yẹn. (Jẹ́nẹ́sísì 2:17; 3:4) Ìdí nìyẹn táa fi pè é ní “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì.”—Ìṣípayá 12:9.
Èṣù purọ́ nípa igi ìmọ̀ rere àti búburú náà. Ó ní kò sídìí fún ṣíṣòfin pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ èso igi náà; ó ní àṣìlò agbára ni. Ó sọ pé Ádámù àti Éfà lè “dà bí Ọlọ́run,” kí wọ́n máa fúnra wọn pinnu ohun rere àti búburú. Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5) Àtakò tó gbé dìde sí ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń ṣàkóso, gbé àwọn ọ̀ràn pàtàkì dìde. Ìyẹn ló jẹ́ kí Jèhófà fàyè sílẹ̀ láti yanjú ọ̀ràn wọ̀nyí. Èyí túmọ̀ sí pé a ti fàyè gba Sátánì kí ó máa wà láàyè nìṣó fún sáà kan. Sáà kúkúrú táa fún un ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bùṣe báyìí. (Ìṣípayá 12:12) Ṣùgbọ́n, kò yéé ya aráyé nípa sí Ọlọ́run, nípa pípurọ́ àti ṣíṣẹ̀tàn, nípa lílo àwọn èèyàn bí àwọn akọ̀wé àtàwọn Farisí tí ń bẹ nígbà ayé Jésù láti tan àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ kálẹ̀.—Mátíù 23:13, 15.
Ohun tí Sátánì ń dọ́gbọ́n sọ ni pé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá tó mọnúúrò, àwọn ló yẹ kó máa dá pinnu gbogbo ọ̀ràn ara wọn. (Jésù tún sọ pé Èṣù jẹ́ ‘apànìyàn nígbà tó bẹ̀rẹ̀,’ àti pé ‘kò dúró ṣinṣin nínú òtítọ́.’ Èyí kò túmọ̀ sí pé “apànìyàn” ni Èṣù nígbà tí Jèhófà dá a. A kò dá a gẹ́gẹ́ bí ẹbọra tí yóò máa koná nídìí iná táa fi ń dá ẹnikẹ́ni tó bá tako Ọlọ́run lóró. “Ọ̀run àpáàdì” tí Bíbélì sọ̀rọ̀ rẹ̀ kì í ṣe ibùjókòó Sátánì. Isà òkú gbogbo aráyé lásán ni.—Ìṣe 2:25-27; Ìṣípayá 20:13, 14.
Èṣù wà “nínú òtítọ́” ní àtètèkọ́ṣe. Nígbà kan rí, ó jẹ́ ara ìdílé Jèhófà lókè ọ̀run, ẹ̀dá ẹ̀mí pípé, ọmọ Ọlọ́run. Àmọ́, ‘kò dúró ṣinṣin nínú òtítọ́.’ Tinú rẹ̀ ló fẹ́ máa ṣe, àwọn ìlànà èké rẹ̀ ló sì fẹ́ máa tẹ̀ lé. ‘Ìgbà tí ó bẹ̀rẹ̀,’ kì í ṣe ìgbà táa dá a gẹ́gẹ́ bí áńgẹ́lì ọmọ Ọlọ́run, bí kò ṣe ìgbà tó mọ̀ọ́mọ̀ ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, tó sì purọ́ tan Ádámù àti Éfà jẹ. Èṣù dà bí àwọn èèyàn tó ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà nígbà ayé Mósè. A kà nípa wọn pé: “Wọ́n ti gbé ìgbésẹ̀ tí ń fa ìparun níhà ọ̀dọ̀ àwọn fúnra wọn; wọn kì í ṣe ọmọ rẹ̀, àbùkù náà jẹ́ tiwọn.” (Diutarónómì 32:5) Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀ràn Sátánì rí. Ó di “apànìyàn” nígbà tó ṣọ̀tẹ̀, tó sì ṣekú pa Ádámù àti Éfà, àní títí kan gbogbo ìdílé ẹ̀dá ènìyàn.—Róòmù 5:12.
Àwọn Áńgẹ́lì Aláìgbọràn
Àwọn áńgẹ́lì mìíràn lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ Sátánì nínú ọ̀tẹ̀ rẹ̀. (Lúùkù 11:14, 15) Àwọn áńgẹ́lì wọ̀nyí “ṣá ibi gbígbé tiwọn tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu tì,” wọ́n gbé ara ènìyàn wọ̀, kí wọ́n lè gbádùn ìbálòpọ̀ takọtabo pẹ̀lú “àwọn ọmọbìnrin ènìyàn” nígbà ayé Nóà. (Júúdà 6; Jẹ́nẹ́sísì 6:1-4; 1 Pétérù 3:19, 20) “Ìdá mẹ́ta àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run,” ìyẹn ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí, ló tọ ipa ọ̀nà yìí.—Ìṣípayá 12:4.
Ìwé Ìṣípayá tí ń sọ̀rọ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ tó kàmàmà pe Èṣù ní “dírágónì ńlá aláwọ̀ iná.” (Ìṣípayá 12:3) Èé ṣe? Kì í ṣe nítorí pé ó rí bí iwin tàbí ẹbọra. A ò kúkú mọ irú ara tí àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí ní, àmọ́ bóyá ni ara Sátánì fi máa yàtọ̀ sí ara àwọn áńgẹ́lì ẹ̀dá ẹ̀mí yòókù. Ṣùgbọ́n, “dírágónì ńlá aláwọ̀ iná” jẹ́ ọ̀nà tó ṣe wẹ́kú láti gbà ṣàpèjúwe ẹ̀mí apanijẹ, adáyàjáni, alágbára, àti apanirun tí Sátánì ní.
A ti há Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ mọ́ báyìí. Wọn ò lè gbé ara wọ̀ bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Kété lẹ́yìn ìfilọ́lẹ̀ Ìjọba Ọlọ́run ní ìkáwọ́ Kristi lọ́dún 1914 ni a fi wọ́n sọ̀kò sí sàkáání ilẹ̀ ayé.—Ìṣípayá 12:7-9.
Ọ̀tá Tó Ṣòroó Borí Ni Èṣù
Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ọ̀tá tó ṣòroó borí ni Èṣù jẹ́ o. Ó “ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.” (1 Pétérù 5:8) Kì í ṣe èrò ibi lásán-làsàn tí ń gbé nínú ara àìpé wa. Òótọ́ ni pé ojoojúmọ́ là ń bá àwọn ìtẹ̀sí ẹ̀ṣẹ̀ tó ń dìde nínú àgọ́ ara wa wọ̀yá ìjà. (Róòmù 7:18-20) Àmọ́ ìjà gidi tí à ń jà jẹ́ “lòdì sí àwọn olùṣàkóso ayé òkùnkùn yìí, lòdì sí àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú ní àwọn ibi ọ̀run.”—Éfésù 6:12.
1 Jòhánù 5:19) Bó ti wù kó rí, kò yẹ ká jẹ́ kí ìbẹ̀rù Èṣù gbà wá lọ́kàn tàbí ká wá jẹ́ kí jìnnìjìnnì rẹ̀ sọ wá di akídanidání. Àmọ́ o, á dáa ká wà lójúfò, kí ó má bàa ré wa lọ kúrò nínú òtítọ́, kí ó sì ba ìwà títọ́ wa sí Ọlọ́run jẹ́.—Jóòbù 2:3-5; 2 Kọ́ríńtì 4:3, 4.
Báwo ni agbára Èṣù ti rinlẹ̀ tó? Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (Ìgbà gbogbo kọ́ ni Èṣù ń fi àtakò rírorò bá àwọn tó fẹ́ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run jà. Nígbà míì, ó máa ń fara hàn bí “áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀.” Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fáwọn Kristẹni nípa ewu yìí nígbà tó kọ̀wé pé: “Mo ń fòyà pé lọ́nà kan ṣáá, bí ejò ti sún Éfà dẹ́ṣẹ̀ nípasẹ̀ àlùmọ̀kọ́rọ́yí rẹ̀, a lè sọ èrò inú yín di ìbàjẹ́ kúrò nínú òtítọ́ inú àti ìwà mímọ́ tí ó tọ́ sí Kristi.”—2 Kọ́ríńtì 11:3, 14.
Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ ‘pa agbára ìmòye wa mọ́, kí a máa kíyè sára, kí a sì mú ìdúró wa lòdì sí i, ní dídúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́.’ (1 Pétérù 5:8, 9; 2 Kọ́ríńtì 2:11) Yẹra fún kíkó sí pańpẹ́ Sátánì nípa títọwọ́ bọ ohunkóhun tó bá jẹ mọ́ iṣẹ́ òkùnkùn. (Diutarónómì 18:10-12) Máa fi aápọn kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, máa rántí pé léraléra ni Jésù Kristi tọ́ka sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nígbà tí Èṣù ń dán an wò. (Mátíù 4:4, 7, 10) Máa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún ọ ní ẹ̀mí rẹ̀. Èso ẹ̀mí rẹ̀ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti yẹra fún àwọn iṣẹ́ ti ara, tí Sátánì ti ń gbé lárugẹ lójú méjèèjì. (Gálátíà 5:16-24) Pẹ̀lúpẹ̀lù, fi taratara gbàdúrà sí Jèhófà nígbà tí àdánwò bá dé lóríṣiríṣi látọ̀dọ̀ Èṣù àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀.—Fílípì 4:6, 7.
Kò sídìí láti máa gbọ̀n jìnnìjìnnì nítorí Èṣù. Jèhófà ṣèlérí pé òun ò ní jẹ́ kí Sátánì rí wa gbé ṣe. (Sáàmù 91:1-4; Òwe 18:10; Jákọ́bù 4:7, 8) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ máa bá a lọ ní gbígba agbára nínú Olúwa àti nínú agbára ńlá okun rẹ̀.” Bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a ó “lè dúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí àwọn ètekéte Èṣù.”—Éfésù 6:10, 11.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Jésù mọ̀ pé Èṣù wà lóòótọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
“Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà”
[Credit Line]
Fọ́tò NASA
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Kọ ojú ìjà sí Èṣù nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti gbígbàdúrà déédéé