Ìgbà Kan Wà Táa Jẹ́ Ìkookò—A Ti Di Àgùntàn Báyìí!
Ìgbà Kan Wà Táa Jẹ́ Ìkookò—A Ti Di Àgùntàn Báyìí!
Aládùúgbò lèmi àti Sakina nígbà táa wà lọ́mọdé. Ọmọbìnrin tó tóbi, tó sì ki pọ́pọ́ ni Sakina, èmi kẹ̀ rèé, ọmọbìnrin tó rí kóńkóló ni mi, mi ò sì ju jáńjálá báyìí lọ. A máa ń bára wa ṣe aáwọ̀ ṣáá ni, ṣùgbọ́n lọ́jọ́ kan, a wọ̀yá ìjà gidi. Látọjọ́ yẹn, a kì í bára wa sọ̀rọ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ la ò kíra wa mọ́. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, àwa méjèèjì kó kúrò ládùúgbò yẹn, a ò sì gbúròó ara wa mọ́.
Ní 1994, mo bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ìwà mi bẹ̀rẹ̀ sí yí padà. Ìyàlẹ́nu ńlá ló jẹ́ fún mi ní ọdún mẹ́rin lẹ́yìn náà, nígbà tí mo bá Sakina pàdé ní àpéjọ àkànṣe táa ṣe ní Bujumbura nílùú Burundi. Inú mi dùn láti rí i níbẹ̀, àmọ́ ńṣe la kàn kí ara wa bákan ṣáá. Nígbà tó ṣe díẹ̀ lọ́jọ́ yẹn, ó yà mí lẹ́nu gan-an nígbà tí mo rí i láàárín àwọn tó fẹ́ ṣe batisí! Òun náà ti yí padà pátápátá. Ó ti kúrò ní aríjàgbá tí mo máa ń bá ṣaáwọ̀ nígbà gbogbo. Ẹ wo bó ṣe jẹ́ ohun àgbàyanu tó láti rí i tó ń fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ rẹ̀ sí Ọlọ́run hàn ní gbangba nípa ṣíṣe batisí!
Nígbà tó jáde kúrò nínú omi, mo sáré lọ dì mọ́ ọn, mo sì fẹnu kò ó létí, mo ní: “Ǹjẹ́ o rántí báa ṣe máa ń bá ara wa jà?” Ó dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, mo rántí, ṣùgbọ́n, ayé àtijọ́ nìyẹn. Mo ti di ẹni tuntun báyìí.”
Inú àwa méjèèjì dùn pé a ti rí òtítọ́ Bíbélì tó so wá pọ̀, tó sì yí ìwà ìkookò wa padà sí ti àgùntàn tó jẹ́ ti Olùṣọ́ Àgùntàn Ńlá náà, Jèhófà Ọlọ́run. Láìsí àní-àní, òtítọ́ Bíbélì ń yí ìgbésí ayé padà.