Báwo Ni Àlàáfíà Kristi Ṣe Lè Máa Ṣàkóso Nínú Ọkàn-àyà Wa?
Báwo Ni Àlàáfíà Kristi Ṣe Lè Máa Ṣàkóso Nínú Ọkàn-àyà Wa?
“Ẹ jẹ́ kí àlàáfíà Kristi máa ṣàkóso nínú ọkàn-àyà yín, nítorí, ní ti tòótọ́, a pè yín sínú rẹ̀ ní ara kan.”—KÓLÓSÈ 3:15.
1, 2. Ọ̀nà wo ni “àlàáfíà Kristi” fi ń ṣàkóso nínú ọkàn-àyà Kristẹni kan?
ÌṢÀKÓSO jẹ́ ọ̀rọ̀ kan tó ń kó ọ̀pọ̀ ènìyàn nírìíra, nítorí pé èrò tó ń mú wá sí wọn lọ́kàn ni fífagbára múni àti fífi ọgbọ́n àyínìke darí ẹni. Ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni tó wà ní Kólósè pé, “Ẹ jẹ́ kí àlàáfíà Kristi máa ṣàkóso nínú ọkàn-àyà yín,” lè wá dà bí ohun tí kò mọ́gbọ́n dání lójú àwọn kan. (Kólósè 3:15) Ṣé a kì í ṣe ẹ̀dá olómìnira ìwà híhù ni? Èé ṣe táa ó fi wá jẹ́ kí ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni máa ṣàkóso nínú ọkàn-àyà wa?
2 Kì í ṣe pé Pọ́ọ̀lù ń sọ fún àwọn ará Kólósè pé kí wọ́n yááfì òmìnira tí wọ́n ní láti ṣe ohun tó wù wọ́n. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà táa tú sí “ṣàkóso” nínú Kólósè 3:15 tan mọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún olùdarí tó ń fún àwọn eléré ìdárayá lẹ́bùn láyé ọjọ́un. Àwọn eléré ìdárayá náà ní òmìnira dé ìwọ̀n kan láìjẹ́ pé wọ́n tàpá sí àwọn òfin eré ìdárayá náà, àmọ́ níkẹyìn, olùdarí ló ń pinnu àwọn tó pa àwọn òfin eré náà mọ́ tí wọ́n sì wá borí. Bákan náà la ní òmìnira láti ṣe ọ̀pọ̀ ìpinnu nínú ìgbésí ayé wa, àmọ́ bí a ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ máa jẹ́ kí àlàáfíà Kristi jẹ́ “olùdarí”—tàbí ká sọ ọ́ gẹ́gẹ́ bí olùtumọ̀ nì, Edgar J. Goodspeed, ṣe sọ ọ́ pé kó jẹ́ “agbára tí ń darí” ọkàn-àyà wa.
3. Kí ni “àlàáfíà Kristi”?
3 Kí ni “àlàáfíà Kristi”? Ó jẹ́ ìtẹ́lọ́rùn, ìbàlẹ̀ ọkàn, táa ní nígbà táa di ọmọ ẹ̀yìn Jésù, táa sì wá mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ wa, wọ́n sì tẹ́wọ́ gbà wá. Nígbà tó kù díẹ̀ kí Jésù fi àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sílẹ̀, ó sọ fún wọn pé: “Mo fi àlàáfíà mi fún yín. . . . Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn-àyà yín dààmú tàbí kí ó kó sókè nítorí ìbẹ̀rù.” (Jòhánù 14:27) Ó ti ń lọ sí nǹkan bí ẹgbàá [2,000] ọdún tí àwọn tó jẹ́ mẹ́ńbà olóòótọ́ ẹni àmì òróró ara Kristi ti ń gbádùn àlàáfíà yẹn. Àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn, ìyẹn “àwọn àgùntàn mìíràn,” sì ń nípìn-ín nínú rẹ̀ lóde òní. (Jòhánù 10:16) Àlàáfíà yẹn ló yẹ kó máa darí ọkàn-àyà wa. Nígbà táa bá wà lábẹ́ àdánwò líle koko, ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún dídi ẹni tí ìbẹ̀rù tàbí wàhálà kó jìnnìjìnnì bá. Ẹ jẹ́ ká wo bí èyí ṣe jẹ́ òótọ́ tó, nígbà tí wọ́n bá rẹ́ wa jẹ, nígbà tí hílàhílo bá bá wa, àti nígbà táa bá ń nímọ̀lára pé a kò wúlò.
Nígbà Tí Wọ́n Bá Rẹ́ Wa Jẹ
4. (a) Báwo ni Jésù ṣe mọ̀ nípa ìwà ìrẹ́nijẹ? (b) Báwo làwọn Kristẹni ṣe hùwà nígbà táa rẹ́ wọn jẹ?
4 Sólómọ́nì Ọba sọ pé: “Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Jésù mọ̀ pé òótọ́ ni àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn. Nígbà tó wà ní ọ̀run, ó rí ìwà ìrẹ́nijẹ bíburú jáì táwọn èèyàn ń hù sí ọmọnìkejì wọn. Nígbà tó wá sáyé, òun alára fara gbá ìwà ìrẹ́nijẹ tó ga jù lọ nígbà tí wọ́n fi ẹ̀sùn ọ̀rọ̀ òdì kàn án, ẹni tó jẹ́ aláìlẹ́ṣẹ̀, tí wọ́n sì pa á gẹ́gẹ́ bí arúfin. (Mátíù 26:63-66; Máàkù 15:27) Lóde òní, ìwà ìrẹ́nijẹ tún pọ̀ bí nǹkan míì, àwọn Kristẹni tòótọ́ sì ti jìyà gan-an gẹ́gẹ́ bí “ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mátíù 24:9) Síbẹ̀, lójú gbogbo ìrírí bíburú jáì tí wọ́n ní nínú àgọ́ ikú ìjọba Násì àti Àgọ́ Iṣẹ́ Àṣekú ti Soviet Union, lójú bí àwọn èèyànkéèyàn ṣe lù wọ́n bí ẹni máa kú, tí wọ́n fẹ̀sùn èké kàn wọ́n, tí wọ́n sì parọ́ mọ́ wọn, àlàáfíà Kristi ti jẹ́ kí wọ́n dúró gbọn-in. Wọ́n ti fara wé Jésù, ẹni tí a kà nípa rẹ̀ pé: “Nígbà tí a ń kẹ́gàn rẹ̀, kò bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́gàn padà. Nígbà tí ó ń jìyà, kò bẹ̀rẹ̀ sí halẹ̀ mọ́ni, ṣùgbọ́n ó ń bá a nìṣó ní fífi ara rẹ̀ lé ọwọ́ ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ lọ́nà òdodo.”—1 Pétérù 2:23.
5. Nígbà táa bá gbọ́ nípa ohun tó jọ ìwà ìrẹ́nijẹ nínú ìjọ, kí ló yẹ ká kọ́kọ́ gbé yẹ̀ wò?
5 Ẹ jẹ́ ká tibi tó kéré gan-an wo ọ̀ràn yìí, a lè gbà pé wọ́n ti rẹ́ ẹnì kan jẹ nínú ìjọ Kristẹni. Nínú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, a lè ní irú ìmọ̀lára tí Pọ́ọ̀lù ní, ẹni tó sọ pé: “Ta ní a mú kọsẹ̀, tí ara mi kò sì gbaná jẹ?” (2 Kọ́ríńtì 11:29) Kí la lè ṣe? A dáa ká bi ara wa pé, ‘Ṣé ìwà ìrẹ́nijẹ ni lóòótọ́?’ Ọ̀pọ̀ ìgbà ni a kì í mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀ràn náà. Inú ti lè bí wa gan-an lẹ́yìn táa gbọ́ ohun tí ẹni tó sọ pé òun mọ̀ nípa ọ̀ràn náà sọ. Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀.” (Òwe 14:15) Nítorí náà, a ní láti ṣọ́ra.
6. Kí ló yẹ ká ṣe nígbà táa bá ronú pé a ti rẹ́ wa jẹ́ nínú ìjọ?
6 Àmọ́, ó lè jẹ́ pé àwa gan-an ló dà bí ẹni pé wọ́n rẹ́ jẹ. Báwo ni ẹni tó ní àlàáfíà Kristi nínú ọkàn-àyà rẹ̀ ṣe máa hùwà padà? A lè rí i pé ó yẹ ká bá ẹni táa rò pé ó ṣẹ̀ wá náà sọ̀rọ̀. Lẹ́yìn ìyẹn, dípò tí a ó fi máa sọ ọ̀rọ̀ náà fún gbogbo èèyàn, a ò ṣe kúkú fi ọ̀ràn náà lé Jèhófà lọ́wọ́ nínú àdúrà, kí a sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀ pé yóò ṣe ìdájọ́ òdodo? (Sáàmù 9:10; Òwe 3:5) Ó lè ṣẹlẹ̀ pé lẹ́yìn táa bá ti ṣe bẹ́ẹ̀, a lè gba kámú, kí a sì “dákẹ́ jẹ́ẹ́.” (Sáàmù 4:4) Nínú ọ̀ràn tó pọ̀ jù lọ, ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù yóò gbéṣẹ́ pé: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe.”—Kólósè 3:13.
7. Kí ló yẹ ká máa fìgbà gbogbo rántí nínú ìbálò wa pẹ̀lú àwọn arákùnrin wa?
7 Àmọ́ ṣá o, ohun yòówù ká ṣe, ó yẹ ká rántí pé bí a ò tiẹ̀ lè ṣe ohunkóhun nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn, síbẹ̀ a lè ṣàkóso ara wa. Bí a bá lọ tutọ́ sókè táa fojú gbà á nítorí tí a gbà pé wọ́n rẹ́ wa jẹ, ìyẹn tiẹ̀ lè wá ní ipa tó burú jáì lórí àlàáfíà wa ju ipa tí ìrẹ́nijẹ ọ̀hún fúnra rẹ̀ máa ní lọ. (Òwe 18:14) A tiẹ̀ lè kọsẹ̀, ká má sì dara pọ̀ mọ́ ìjọ náà mọ́ títí dìgbà táa bá ronú pé wọ́n ti mú ọ̀ràn náà tọ́. Onísáàmù náà kọ̀wé pé “kò sí ohun ìkọ̀sẹ̀ fún” àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òfin Jèhófà. (Sáàmù 119:165) Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé gbogbo wa la máa ń fara gbá ìwà ìrẹ́nijẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Má ṣe jẹ́ kí irú ìrírí búburú bẹ́ẹ̀ nípa lórí ìjọsìn rẹ sí Jèhófà láé. Kàkà bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí àlàáfíà Kristi máa ṣàkóso nínú ọkàn-àyà rẹ.
Nígbà Tí Àníyàn Bá Dé Lọ́tùn-ún Lósì
8. Kí làwọn nǹkan tó ń fa àníyàn, kí sì ni àníyàn lè yọrí sí?
8 Àníyàn jẹ́ apá kan ìgbésí ayé nínú “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” wọ̀nyí. (2 Tímótì 3:1) Lóòótọ́, Jésù sọ pé: “Ẹ jáwọ́ nínú ṣíṣàníyàn nípa ọkàn yín, ní ti ohun tí ẹ ó jẹ tàbí nípa ara yín, ní ti ohun tí ẹ ó wọ̀.” (Lúùkù 12:22) Àmọ́, kì í ṣe gbogbo àníyàn ló jẹ́ nítorí ríronú nípa àwọn ohun ìní ti ara. “Wàhálà ọkàn” bá Lọ́ọ̀tì “gidigidi” nítorí ìwà búburú tí wọ́n ń hù ní Sódómù. (2 Pétérù 2:7) Ìdààmú bá Pọ́ọ̀lù nítorí “àníyàn fún gbogbo àwọn ìjọ.” (2 Kọ́ríńtì 11:28) Ẹ̀dùn ọkàn ńlá bá Jésù ni alẹ́ tó ṣáájú ikú rẹ̀ débi pé “òógùn rẹ̀ sì wá dà bí ẹ̀kán ẹ̀jẹ̀ tí ń jábọ́ sí ilẹ̀.” (Lúùkù 22:44) Ó ṣe kedere pé, kì í ṣe gbogbo àníyàn ló jẹ́ ẹ̀rí ìgbàgbọ́ tí kò lágbára. Àmọ́, ohun yòówù tó lè fà á, bí àníyàn bá lágbára jù tí kò sì lọ bọ̀rọ̀, ó lè gba àlàáfíà wa. Àníyàn tí mú ọkàn àwọn kan pòrúurùu débi tí wọ́n fi rò pé àwọn kò ní lè máa ṣe ojúṣe wọn nínú ìjọsìn Jèhófà mọ́. Bíbélì sọ pé: “Àníyàn ṣíṣe nínú ọkàn-àyà ènìyàn ni yóò mú un tẹ̀ ba.” (Òwe 12:25) Kí la wá lè ṣe, bí àníyàn bá dorí wa kodò?
9. Kí ni àwọn ìgbésẹ̀ táa lè gbé láti mú àníyàn kúrò, àmọ́ kí ni àwọn ohun tó ń fa àníyàn tí kò ṣeé mú kúrò?
9 Nínú àwọn ipò kan, a lè rọ́gbọ́n dá sí i. Tó bá jẹ́ pé àìsàn ni olórí ohun tó ń fa àníyàn, yóò bọ́gbọ́n mu ká wá nǹkan ṣe sí i, bó tilẹ̀ jẹ́ pé irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìpinnu ara ẹni. a (Mátíù 9:12) Tó bá jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ẹrù iṣẹ́ táa ń bójú tó ló wọ̀ wá lọ́rùn, a lè pín lára iṣẹ́ náà fún àwọn ẹlòmíràn. (Ẹ́kísódù 18:13-23) Àmọ́, àwọn kan—irú bí àwọn òbí—tó jẹ́ pé ẹrù wíwúwo tí wọ́n ń gbé kì í ṣe èyí tó ṣeé gbé lé ẹlòmíràn lọ́wọ́ ńkọ́. Kristẹni kan tí ọkọ tàbí aya tí wọ́n jọ ń gbélé ń ṣàtakò ńkọ́? Ìdílé tó ní ìṣòro àtijẹ àtimu ńkọ́, tàbí àwọn tó ń gbé níbi tí ogun ti ń jà? Ó ṣe kedere pé, a ò lè mú gbogbo ohun tó ń fa àníyàn kúrò pátápátá nínú ètò nǹkan ìsinsìnyí. Síbẹ̀, a lè ní àlàáfíà Kristi nínú ọkàn-àyà wa. Lọ́nà wo?
10. Ọ̀nà méjì wo ni Kristẹni kan lè gbà bọ́ lọ́wọ́ àníyàn?
10 Ọ̀nà kan ni pé kéèyàn máa wá ìtùnú látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ọba Dáfídì kọ̀wé pé: “Nígbà tí ìrònú tí ń gbé mi lọ́kàn sókè di púpọ̀ nínú mi, ìtùnú tìrẹ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣìkẹ́ ọkàn mi.” (Sáàmù 94:19) A lè rí “ìtùnú” Jèhófà nínú Bíbélì. Lílọ sínú Ìwé onímìísí yẹn ní gbogbo ìgbà yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ní àlàáfíà Kristi nínú ọkàn-àyà wa. Bíbélì sọ pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró. Kì yóò jẹ́ kí olódodo ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n láé.” (Sáàmù 55:22) Bákan náà ni Pọ́ọ̀lù tún kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílípì 4:6, 7) Àdúrà àtọkànwá táa ń gbà déédéé yóò ràn wá lọ́wọ́ láti máa ní àlàáfíà wa nìṣó.
11. (a) Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ rere nínú ọ̀ràn àdúrà gbígbà? (b) Ojú wo ló yẹ ká fi máa wo àdúrà?
11 Jésù jẹ́ àpẹẹrẹ títayọ nínú ọ̀ràn yìí. Ìgbà kan wà tó bá Baba rẹ̀ ọ̀run sọ̀rọ̀ nínú àdúrà fún ọ̀pọ̀ wákàtí láìdánudúró. (Mátíù 14:23; Lúùkù 6:12) Àdúrà ràn án lọ́wọ́ láti fara da àdánwò tó burú jù lọ. Ní alẹ́ tó ṣáájú ikú rẹ̀, wàhálà tó dé bá a kọjá sísọ. Kí ló ṣe? Ó túbọ̀ “fi taratara gbàdúrà.” (Lúùkù 22:44) Dájúdájú, Ọmọ Ọlọ́run tó jẹ́ ẹni pípé kò fi àdúrà ṣeré rárá. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì fún àwa ọmọlẹ́yìn rẹ̀ aláìpé láti sọ àdúrà gbígbà dàṣà! Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ “láti máa gbàdúrà nígbà gbogbo àti láti má ṣe juwọ́ sílẹ̀.” (Lúùkù 18:1) Àdúrà jẹ́ ọ̀nà tó dára jù lọ tó sì ṣe pàtàkì láti gbà bá Ẹni tó mọ̀ wá ju bí a ti mọ ara wa sọ̀rọ̀. (Sáàmù 103:14) Bí a bá fẹ́ kí àlàáfíà Kristi máa wà nínú ọkàn-àyà wa, a óò “máa gbàdúrà láìdabọ̀.”—1 Tẹsalóníkà 5:17.
Bíborí Àwọn Àìlera Wa
12. Kí làwọn ìdí tó lè mú kí àwọn kan rò pé iṣẹ́ ìsìn àwọn kò kúnjú ìwọ̀n?
12 Jèhófà ka ọ̀kọ̀ọ̀kan àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ sí ohun tó níye lórí gan-an. (Hágáì 2:7, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Síbẹ̀síbẹ̀, ó máa ń nira fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti gba èyí gbọ́. Àwọn kan lè rẹ̀wẹ̀sì nítorí ọjọ́ ogbó, ẹrù ìdílé tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i, tàbí nítorí ara tó túbọ̀ ń di hẹ́gẹhẹ̀gẹ. Àwọn kan lè ka ara wọn sí kò-tẹ́gbẹ́ nítorí ohun tí wọ́n fojú winá rẹ̀ ní kékeré. Àwọn mìíràn tún wà tó jẹ́ pé àwọn àṣìṣe tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn lè máa dà wọ́n láàmú, kí wọ́n máa ronú pé bóyá ni Jèhófà lè dárí jì àwọn láé. (Sáàmù 51:3) Kí la lè ṣe nípa irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀?
13. Ìtùnú wo ló wà nínú Ìwé Mímọ́ fáwọn tó lérò pé àwọn kò kúnjú ìwọ̀n?
13 Àlàáfíà Kristi yóò mú un dá wa lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa. A lè dá àlàáfíà yẹn padà sínú ọkàn-àyà wa nípa ríronú lórí kókó náà pé Jésù kò fìgbà kan sọ pé ìgbà táa bá fi ohun táa ṣe wé tàwọn ẹlòmíràn la tó lè mọ báa ṣe níye lórí tó. (Mátíù 25:14, 15; Máàkù 12:41-44) Ohun tó tẹnu mọ́ ni ìdúróṣinṣin. Ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.” (Mátíù 24:13) Àwọn èèyàn “tẹ́ńbẹ́lú” Jésù pàápàá, síbẹ̀ kò ṣiyè méjì rárá pé Baba òun nífẹ̀ẹ́ òun. (Aísáyà 53:3; Jòhánù 10:17) Ó sì sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé ẹni ọ̀wọ́n làwọn náà jẹ́. (Jòhánù 14:21) Láti ṣàlàyé èyí, Jésù sọ pé: “Kì í ha ṣe ológoṣẹ́ méjì ni a ń tà ní ẹyọ owó kan tí ìníyelórí rẹ̀ kéré? Síbẹ̀, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò jábọ́ lulẹ̀ láìjẹ́ pé Baba yín mọ̀. Ṣùgbọ́n gbogbo irun orí yín gan-an ni a ti kà. Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù: ẹ níye lórí púpọ̀ ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.” (Mátíù 10:29-31) Ẹ wo bí èyí ti fi wá lọ́kàn balẹ̀ tó pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa!
14. Ìdánilójú wo la ní pé Jèhófà ka ẹnì kọ̀ọ̀kan wa sí pàtàkì?
14 Jésù tún sọ pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á.” (Jòhánù 6:44) Níwọ̀n bí Jèhófà ti fà wá láti tẹ̀ lé Jésù, Ó fẹ́ kí a rí ìgbàlà ni. Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Kì í ṣe ohun tí Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run ní ìfẹ́-ọkàn sí, pé kí ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí ṣègbé.” (Mátíù 18:14) Nítorí náà, bí o bá ń fi gbogbo ọkàn rẹ sìn, o lè máa yọ̀ nínú iṣẹ́ rere rẹ. (Gálátíà 6:4) Bí àwọn àṣìṣe tóo ti ṣe sẹ́yìn bá ń dà ọ́ láàmú, mọ̀ dájú pé àwọn tó ronú pìwà dà látọkànwá ni Jèhófà yóò dárí jì “lọ́nà títóbi.” (Aísáyà 43:25; 55:7) Bí àwọn nǹkan mìíràn bá tún wà tó ń mú ọ rẹ̀wẹ̀sì, rántí pé “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.”—Sáàmù 34:18.
15. (a) Báwo ni Sátánì ṣe ń gbìyànjú láti jẹ́ kí a pàdánù àlàáfíà wa? (b) Ìgbẹ́kẹ̀lé wo la lè ní nínú Jèhófà?
15 Sátánì kò níṣẹ́ méjì ju pé kí ó rí i dájú pé o pàdánù àlàáfíà rẹ. Òun ló ṣokùnfà ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá, tí gbogbo wa ń bá wọ̀yá ìjà. (Róòmù 7:21-24) Ó sì dájú pé yóò fẹ́ kóo lérò pé àìpé rẹ ti mú kí iṣẹ́ ìsìn rẹ di èyí tí Ọlọ́run kò tẹ́wọ́ gbà. Má ṣe jẹ́ kí Èṣù kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ láé! Mọ àwọn ète rẹ̀, kí o sì jẹ́ kí mímọ̀ tí o mọ̀ ọ́n mú ọ pinnu pé wàá fara dà á. (2 Kọ́ríńtì 2:11; Éfésù 6:11-13) Rántí pé, “Ọlọ́run tóbi ju ọkàn-àyà wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.” (1 Jòhánù 3:20) Jèhófà ríran kọjá ìkùdíẹ̀-káà-tó wa. Ó tún mọ àwọn ète àti ìpètepèrò wa. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ onísáàmù náà máa tù wá nínú pé: “Jèhófà kì yóò ṣá àwọn ènìyàn rẹ̀ tì, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi ogún tirẹ̀ sílẹ̀.”—Sáàmù 94:14.
Wíwà ní Ìṣọ̀kan Nínú Àlàáfíà Kristi
16. Ní ọ̀nà wo la ò fi dá nìkan wà báa ṣe ń sapá láti fara dà á?
16 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé kí a jẹ́ kí àlàáfíà Kristi máa ṣàkóso nínú ọkàn-àyà wa nítorí pé ‘a pè wá sínú rẹ̀ ní ara kan.’ Àwọn ẹni àmì òróró tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí la pè láti jẹ́ apá kan ara Kristi, bíi tàwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ẹni àmì òróró náà lóde òní. “Àwọn àgùntàn mìíràn” tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú wọn gẹ́gẹ́ bí “agbo kan” lábẹ́ “olùṣọ́ àgùntàn kan,” Jésù Kristi. (Jòhánù 10:16) Lápapọ̀, jákèjádò ayé ni “agbo” kan tó ní àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn nínú ń jẹ́ kí àlàáfíà Kristi ṣàkóso nínú ọkàn-àyà wọn. Mímọ̀ pé a ò dá nìkan wà ń ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà á. Pétérù kọ̀wé pé: “Ẹ mú ìdúró yín lòdì sí [Sátánì], ní dídúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́, ní mímọ̀ pé àwọn ohun kan náà ní ti ìyà jíjẹ ní ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará yín nínú ayé.”—1 Pétérù 5:9.
17. Kí ló ń mórí wa yá láti jẹ́ kí àlàáfíà Kristi máa ṣàkóso nínú ọkàn-àyà wa?
17 Ǹjẹ́ kí gbogbo wa máa bá a lọ láti mú àlàáfíà dàgbà, ìyẹn èso pàtàkì ti ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. (Gálátíà 5:22, 23) Àwọn tí Jèhófà bá rí i pé wọ́n wà ní àìléèérí àti ní àìlábààwọ́n àti ní àlàáfíà ni a ó fi ìyè ayérayé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé, níbi tí òdodo yóò máa gbé, dá lọ́lá nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín. (2 Pétérù 3:13, 14) A ní ìdí tó pọ̀ rẹpẹtẹ láti jẹ́ kí àlàáfíà Kristi máa ṣàkóso nínú ọkàn-àyà wa.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nínú àwọn ọ̀ràn kan, ohun tó ń fa àníyàn tàbí tó ń mú kí ó peléke ni àìsàn, irú bí akọ ìsoríkọ́.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí ni àlàáfíà Kristi?
• Báwo ni àlàáfíà Kristi ṣe lè ṣàkóso nínú ọkàn-àyà wa nígbà tí wọ́n bá ń rẹ́ wa jẹ?
• Báwo ni àlàáfíà Kristi ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti borí àníyàn?
• Báwo ni àlàáfíà Kristi ṣe ń tù wá nínú nígbà táa bá lérò pé a ò wúlò?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Jésù fi ọ̀ràn ara rẹ̀ lé Jèhófà lọ́wọ́ níwájú àwọn olùfisùn rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Bí ìgbà tí baba onífẹ̀ẹ́ bá fi ọ̀yàyà gbáni mọ́ra, bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni ìtùnú Jèhófà ṣe lè mú kí àníyàn wa rọlẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ìfaradà ṣe pàtàkì gan-an lójú Ọlọ́run