“Máa Wá Àlàáfíà, Kí o Sì Máa Lépa Rẹ̀”
“Máa Wá Àlàáfíà, Kí o Sì Máa Lépa Rẹ̀”
“Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.”—RÓÒMÙ 12:18.
1, 2. Kí làwọn ìdí tí àlàáfíà èyíkéyìí tó bá ti ọwọ́ èèyàn wá kò fi lè wà pẹ́ títí?
FOJÚ inú wo ilé kan tí ìpìlẹ̀ rẹ̀ kò lágbára, tí àwọn igi rẹ̀ ti ju, tí òrùlé rẹ̀ sì ti di hẹ́gẹhẹ̀gẹ. Ṣé wàá fẹ́ kó sínú rẹ̀, kí o sì fi irú ilé bẹ́ẹ̀ ṣe ibùgbé? O ò ní fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. Kódà, bí wọ́n tilẹ̀ fi ọ̀dà tuntun kùn ún, síbẹ̀ ẹgẹrẹmìtì ni ilé náà. Bópẹ́ bóyá, ilé náà yóò wó lulẹ̀.
2 Bí ilé yẹn ṣe rí gẹ́ẹ́ ni àlàáfíà èyíkéyìí tó bá pilẹ̀ṣẹ̀ nínú ayé yìí ṣe rí. Orí ìpìlẹ̀ tí kò lágbára ni wọ́n kọ́ ọ lé—ìyẹn ni àwọn ìlérí àti ọgbọ́n èèyàn, “tí ìgbàlà kò sí lọ́wọ́ rẹ̀.” (Sáàmù 146:3) Ìtàn àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá fi hàn pé ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìforígbárí ló ti wáyé láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn ẹ̀yà, àti ìran. Ní tòótọ́, àlàáfíà ti wà láwọn àkókò ráńpẹ́ kan, àmọ́ irú àlàáfíà wo ni? Bí orílẹ̀-èdè méjì bá ń jagun, tí wọ́n wá kéde àlàáfíà, bóyá nítorí pé orílẹ̀-èdè kan ti ṣẹ́gun tàbí nítorí pé àwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì kò rí àǹfààní kankan nínú ogun jíjà mọ́, irú àlàáfíà wo nìyẹn? Ìkórìíra, ìfura, àti owú tó bẹ̀rẹ̀ ogun náà ṣì wà níbẹ̀. Àlàáfíà ojú ayé, tó jẹ́ ‘ọ̀dà’ tí wọ́n fi bo gbúngbùngbún mọ́lẹ̀, kì í ṣe àlàáfíà tó lè wà pẹ́ títí.—Ìsíkíẹ́lì 13:10.
3. Èé ṣe tí àlàáfíà àwọn èèyàn Ọlọ́run fi yàtọ̀ sí àlàáfíà èyíkéyìí tí ènìyàn lè mú wá?
3 Síbẹ̀síbẹ̀, ojúlówó àlàáfíà wà nínú ayé tí ogun ti pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ yìí. Ibo ló wà? Ó wà láàárín àwọn tó ń tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Jésù Kristi, ìyẹn àwọn ojúlówó Kristẹni, tí wọ́n ń pa ọ̀rọ̀ Jésù mọ́, tí wọ́n sì ń sapá láti fara wé ipa ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 11:1; 1 Pétérù 2:21) Àlàáfíà tó wà láàárín àwọn Kristẹni tó ti ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wá, tí ipò wọn láàárín ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà yàtọ̀ síra, tí wọ́n sì wá láti onírúurú orílẹ̀-èdè jẹ́ ojúlówó, nítorí pé ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti inú àjọṣe alálàáfíà tó wà láàárín àwọn àti Ọlọ́run, èyí tí wọ́n gbé karí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi. Àlàáfíà wọ́n jẹ́ ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, kì í ṣe èyí táwọn èèyàn mú wá. (Róòmù 15:33; Éfésù 6:23, 24) Ó jẹ́ àbájáde fífi tí wọ́n fi ara wọn sábẹ́ Jésù Kristi, “Ọmọ Aládé Àlàáfíà,” tí wọ́n sì ń sìn Jèhófà, “Ọlọ́run ìfẹ́ àti àlàáfíà.”—Aísáyà 9:6; 2 Kọ́ríńtì 13:11.
4. Báwo ni Kristẹni kan ṣe ń “lépa” àlàáfíà?
4 Àlàáfíà kì í ṣàdédé wá sọ́dọ̀ àwọn aláìpé ènìyàn. Ìdí nìyẹn tí Pétérù fi sọ pé kí Kristẹni kọ̀ọ̀kan “máa wá àlàáfíà, kí ó sì máa lépa rẹ̀.” (1 Pétérù 3:11) Báwo la ṣe lè ṣèyẹn? Àsọtẹ́lẹ̀ ìgbàanì kan fúnni ni èsì rẹ̀. Nígbà tí Jèhófà ń tipasẹ̀ Aísáyà sọ̀rọ̀, ó ní: “Gbogbo ọmọ rẹ yóò sì jẹ́ àwọn tí a kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ yóò sì pọ̀ yanturu.” (Aísáyà 54:13; Fílípì 4:9) Bẹ́ẹ̀ ni o, ojúlówó àlàáfíà ń wá sọ́dọ̀ àwọn tó ń pa ohun tí Jèhófà fi ń kọ́ni mọ́. Yàtọ̀ síyẹn, àlàáfíà, pa pọ̀ pẹ̀lú “ìfẹ́, ìdùnnú, . . . ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu,” ni èso ti ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. (Gálátíà 5:22, 23) Ẹnì kan tí kò nífẹ̀ẹ́, tí kò láyọ̀, tí kò ní sùúrù, tí kò lójú àánú, tó jẹ́ ẹni ibi, tó jẹ́ aláìṣòótọ́, tó jẹ́ òǹrorò, tàbí tí kò ní ìkóra-ẹni-níjàánu kò lè ní irú àlàáfíà yẹn.
“Jẹ́ Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà Pẹ̀lú Gbogbo Ènìyàn”
5, 6. (a) Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín jíjẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ àti jíjẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà? (b) Àwọn wo làwọn Kristẹni ń tiraka láti jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà sí?
5 Àlàáfíà túmọ̀ sí “ipò ìtòròmini tàbí ìparọ́rọ́.” Irú ìtumọ̀ yẹn wé mọ́ ọ̀pọ̀ ipò nínú èyí tí kò ti sí gbọ́nmi-si omi-ò-to. Àní, ẹni tó ti kú pàápàá wà nínú irú ipò bẹ́ẹ̀! Àmọ́, kéèyàn tó lè gbádùn ojúlówó àlàáfíà, irú ẹni bẹ́ẹ̀ gbọ́dọ̀ máa wá àlàáfíà. Nínú Ìwàásù Lórí Òkè, Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà, níwọ̀n bí a ó ti pè wọ́n ní ‘ọmọ Ọlọ́run.’” (Mátíù 5:9) Àwọn tó máa láǹfààní láti di ọmọ Ọlọ́run nípa tẹ̀mí, tí wọn ó sì gba ìyè àìleèkú ní ọ̀run ni Jésù ń bá sọ̀rọ̀. (Jòhánù 1:12; Róòmù 8:14-17) Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, gbogbo olóòótọ́ ènìyàn tí kò ní ìrètí ti òkè ọ̀run yóò gbádùn “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.” (Róòmù 8:21) Kìkì àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà ló lè ní irú ìrètí bẹ́ẹ̀. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì fún “ẹlẹ́mìí àlàáfíà” ní ṣáńgílítí túmọ̀ sí “olùwá àlàáfíà.” Lójú ohun tí Ìwé Mímọ́ wí, jíjẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà túmọ̀ sí kéèyàn máa gbé àlàáfíà lárugẹ, ìgbà mìíràn tiẹ̀ wà tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè mú kí àlàáfíà wà níbi tí kò sí àlàáfíà tẹ́lẹ̀.
6 Pẹ̀lú èrò yìí lọ́kàn, gbé ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún àwọn ará Róòmù yẹ̀ wò pé: “Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.” (Róòmù 12:18) Kì í ṣe pé Pọ́ọ̀lù wulẹ̀ ń sọ fún àwọn ará Róòmù pé kí wọ́n jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn náà lè ṣèrànwọ́. Ńṣe ló ń gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n máa wá àlàáfíà. Pẹ̀lú ta ni? Pẹ̀lú “gbogbo ènìyàn”—àwọn mẹ́ńbà ìdílé wọn ni o, àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn ni o, kódà pẹ̀lú àwọn tí ìgbàgbọ́ wọ́n yàtọ̀ sí tiwọn pàápàá. Ó gba àwọn ará Róòmù níyànjú láti wá àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn ‘níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ wọn ni ó wà.’ Rárá o, kì í ṣe pé ó fẹ́ kí wọ́n fi ìgbàgbọ́ wọn báni dọ́rẹ̀ẹ́ nítorí àtiwá àlàáfíà. Dípò kí wọ́n máa sọ ara wọn di ọ̀tá àwọn ẹlòmíràn láìnídìí, wọ́n ní láti máa fi ẹ̀mí àlàáfíà bá wọn lò. Àwọn Kristẹni ní láti máa ṣe bẹ́ẹ̀, yálà nínú ìbálò wọn pẹ̀lú àwọn tó wà nínú ìjọ ni o, tàbí pẹ̀lú àwọn tí kò sí nínú ìjọ. (Gálátíà 6:10) Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nígbà gbogbo ẹ máa lépa ohun rere sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì àti sí gbogbo àwọn ẹlòmíràn.”—1 Tẹsalóníkà 5:15.
7, 8. Báwo làwọn Kristẹni ṣe lè jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà sí àwọn tí kì í ṣe onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn, èé sì ti ṣe?
7 Báwo la ṣe lè jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn yàtọ̀ sí tiwa, tí wọ́n tiẹ̀ lè máa takò wá pàápàá? Lọ́nà kan, a ń yẹra fún ṣíṣe bíi pé a sàn jù wọ́n lọ. Bí àpẹẹrẹ, a ò lè jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà bí a bá ń lo àwọn èdè tó bẹnu àtẹ́ luni nígbà táa bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Jèhófà ti sọ bí òun ṣe máa ṣèdájọ́ àwọn ètò àjọ àti onírúurú ẹgbẹ́, ṣùgbọ́n a ò lẹ́tọ̀ọ́ kankan láti sọ̀rọ̀ ẹnikẹ́ni bí ẹni pé a ti dá irú ẹni bẹ́ẹ̀ lẹ́bi. Ní ti tòótọ́, a kì í ṣèdájọ́ àwọn ẹlòmíràn, kódà a kì í dá àwọn tó ń takò wá pàápàá lẹ́jọ́. Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù sọ fún Títù pé kó bá àwọn Kristẹni tó wà ní Kírétè sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ó ṣe máa bá àwọn aláṣẹ lò, ó ní kó rán wọn létí “láti má sọ̀rọ̀ ẹnì kankan lọ́nà ìbàjẹ́, láti má ṣe jẹ́ aríjàgbá, láti jẹ́ afòyebánilò, kí wọ́n máa fi gbogbo ìwà tútù hàn sí ènìyàn gbogbo.”—Títù 3:1, 2.
8 Jíjẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn yàtọ̀ sí tiwa ń mú kó rọrùn láti darí wọn sí òtítọ́. Àmọ́ ṣá o, a ò ní bá wọn dọ́rẹ̀ẹ́ tó lè “ba ìwà rere jẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 15:33) Síbẹ̀, a lè yẹ́ wọn sí, ká sì máa fi iyì àti inú rere bá gbogbo ènìyàn lò. Pétérù kọ̀wé pé: “Ẹ tọ́jú ìwà yín kí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, pé, nínú ohun náà tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lòdì sí yín gẹ́gẹ́ bí aṣebi, kí wọ́n lè tipa àwọn iṣẹ́ yín àtàtà tí wọ́n fojú rí, yin Ọlọ́run lógo ní ọjọ́ náà fún àbẹ̀wò rẹ̀.”—1 Pétérù 2:12.
Jíjẹ́ Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́
9, 10. Àpẹẹrẹ wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀ nípa jíjẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́?
9 A mọ àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní mọ́ ìgboyà wọn. Wọn kò bomi la iṣẹ́ tí wọ́n ń jẹ́, nígbà táwọn èèyàn bá sì gbé àtakò dìde sí wọn, wọ́n pinnu láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn. (Ìṣe 4:29; 5:29) Síbẹ̀síbẹ̀, ìgboyà wọn kò sọ wọ́n di ẹni tó ń rí àwọn ẹlòmíràn fín. Ṣàgbéyẹ̀wò bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ̀rọ̀ nígbà tó ń gbèjà ìgbàgbọ́ rẹ̀ níwájú Ọba Hẹ́rọ́dù Àgírípà Kejì. Hẹ́rọ́dù Àgírípà gbé Bẹ̀níìsì, àbúrò rẹ̀ sílé, ó ń bá a ṣèṣekúṣe. Àmọ́, Pọ́ọ̀lù kò bẹ̀rẹ̀ sí bá Àgírípà sọ̀rọ̀ nípa ìwà rere. Dípò ìyẹn, àwọn kókó tí kò ní fa àríyànjiyàn ló tẹnu mọ́, tó ń gbóríyìn fún Àgírípà pé ó jẹ́ ògbógi nínú àṣà àwọn Júù, ó sì gba àwọn wòlíì gbọ́.—Ìṣe 26:2, 3, 27.
10 Ṣé Pọ́ọ̀lù wulẹ̀ ń fi orí ahọ́n lásán gbóríyìn fún ọkùnrin yìí kó lè dá a sílẹ̀ lómìnira ni? Rárá o. Pọ́ọ̀lù tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí òun fúnra rẹ̀ fúnni, ó sì sọ òtítọ́. Kò sí irọ́ nínú ohun tó sọ fún Hẹ́rọ́dù Àgírípà. (Éfésù 4:15) Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù jẹ́ ẹni tó ń wá àlàáfíà, ó sì mọ bí a ṣe ń di “ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo.” (1 Kọ́ríńtì 9:22) Olórí ète rẹ̀ ni láti gbèjà ẹ̀tọ́ tó ní láti wàásù nípa Jésù. Gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ tó gbéṣẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ nípa mímẹ́nu kan ohun kan tí òun àti Àgírípà kò ní jiyàn lé lórí. Pọ́ọ̀lù tipa bẹ́ẹ̀ ran ọba oníwà pálapàla yìí lọ́wọ́ láti ní èrò tí ó dára nípa ẹ̀sìn Kristẹni.—Ìṣe 26:28-31.
11. Báwo la ṣe lè jẹ́ olùwá àlàáfíà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
11 Báwo la ṣe lè jẹ́ olùwá àlàáfíà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa? Bíi ti Pọ́ọ̀lù, a gbọ́dọ̀ yẹra fún àwọn ìjiyàn. Lóòótọ́, àwọn ìgbà kọ̀ọ̀kan wà táa ní láti “sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láìbẹ̀rù,” kí a fi àìṣojo gbèjà ìgbàgbọ́ wa. (Fílípì 1:14) Àmọ́, lọ́pọ̀ ìgbà, olórí ète wa ni láti wàásù ìhìn rere náà. (Mátíù 24:14) Bí ẹnì kan bá rí òtítọ́ nípa àwọn ète Ọlọ́run, ó lè wá bẹ̀rẹ̀ sí jáwọ́ nínú àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn èké, kí ó sì wẹ ara rẹ̀ mọ́ kúrò nínú àwọn àṣà tí kò mọ́. Nítorí náà, títí dé ibi tó bá ti lè ṣeé ṣe dé, ó dára láti máa tẹnu mọ́ àwọn nǹkan tí yóò fa àwọn olùgbọ́ wa mọ́ra, kí a bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ohun tí a kò ní jiyàn lé lórí. Òdì kejì pátápátá ni yóò yọrí sí bí a ba lọ sọ ara wa di ọ̀tá ẹnì kan tó jẹ́ pé ì bá fetí sí ìhìn wa, bí a bá rọra fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ bá a sọ̀rọ̀.—2 Kọ́ríńtì 6:3.
Olùwá Àlàáfíà Nínú Ìdílé
12. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà jẹ́ olùwá àlàáfíà nínú ìdílé?
12 Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn tó gbéyàwó “yóò ní ìpọ́njú nínú ẹran ara wọn.” (1 Kọ́ríńtì 7:28) Onírúurú ìṣòro ni wọn óò máa bá pàdé. Ọ̀kan lára wọn ni pé, àwọn tọkọtaya kan yóò máa ní èdèkòyédè lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Báwo ni wọ́n ṣe lè yanjú ìwọ̀nyí? Pẹ̀lú ẹ̀mí àlàáfíà ni. Ẹni tó jẹ́ olùwá àlàáfíà yóò sapá láti fòpin sí aáwọ̀ náà kó tó di ńlá. Lọ́nà wo? Lákọ̀ọ́kọ́, nípa kíkó ahọ́n níjàánu. Nígbà táa bá fi ahọ́n wa sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ tàbí àwọn ọ̀rọ̀ èébú, ẹ̀yà ara kékeré yìí lè jẹ́ “ohun ewèlè tí ń ṣeni léṣe, [tí] ó kún fún panipani májèlé” ní ti tòótọ́. (Jákọ́bù 3:8) Ńṣe ni ẹni tó ń wá àlàáfíà máa ń fi ahọ́n rẹ̀ gbéni ró, kì í fi bini ṣubú.—Òwe 12:18.
13, 14. Báwo la ṣe lè wá àlàáfíà nígbà tí a bá ṣẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ tàbí nígbà tí inú bá ń bí wa?
13 Nítorí pé a jẹ́ aláìpé, gbogbo wa la máa ń sọ àwọn nǹkan míì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, táa ó sì wá máa kábàámọ̀ rẹ̀ níkẹyìn. Nígbà tí èyí bá ṣẹlẹ̀, tètè ṣe àtúnṣe—wá àlàáfíà lójú ẹsẹ̀. (Òwe 19:11; Kólósè 3:13) Yẹra fún kíkó wọnú “fífa ọ̀rọ̀” àti “awuyewuye lílenípá lórí àwọn ohun tí kò tó nǹkan.” (1 Tímótì 6:4, 5) Kàkà bẹ́ẹ̀, ro ọ̀rọ̀ náà jinlẹ̀, kí o sì gbìyànjú láti mọ ẹ̀dùn ọkàn ọkọ tàbí aya rẹ. Bí a bá sọ ọ̀rọ̀ tí kò bára dé sí ọ, má ṣe gbẹ̀san. Rántí pé “ìdáhùn kan, nígbà tí ó bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, máa ń yí ìhónú padà.”—Òwe 15:1.
14 Nígbà mìíràn, o lè ní láti gbé ìmọ̀ràn inú Òwe 17:14 yẹ̀ wò, tó sọ pé: “Kí aáwọ̀ tó bẹ́, fi ibẹ̀ sílẹ̀.” Kó ara rẹ níjàánu, kí o má ṣe tọrùn bọ wàhálà tó fẹ́ bẹ́ sílẹ̀. Níkẹyìn, nígbà tí gbogbo rẹ̀ bá ti rọlẹ̀, ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti fi sùúrù yanjú ìṣòro náà. Nínú àwọn ọ̀ràn mìíràn, ó lè bọ́gbọ́n mú láti pe Kristẹni alábòójútó tó dàgbà dénú láti ṣèrànwọ́. Irú àwọn ọkùnrin tí wọ́n nírìírí, tí wọ́n sì jẹ́ aláàánú bẹ́ẹ̀ lè fini lọ́kàn balẹ̀ nígbà tí wàhálà bá fẹ́ bẹ́ sílẹ̀ láàárín tọkọtaya.—Aísáyà 32:1, 2.
Olùwá Àlàáfíà Nínú Ìjọ
15. Gẹ́gẹ́ bí Jákọ́bù ti wí, kí ni ẹ̀mí búburú tó ti dìde láàárín àwọn Kristẹni kan, èé sì ti ṣe tí ẹ̀mí yẹn fi jẹ́ “ti ilẹ̀ ayé,” “ti ẹranko,” àti “ti ẹ̀mí èṣù”?
15 Ó ṣeni láàánú pé àwọn kan lára àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ní ẹ̀mí owú àti ti asọ̀—èyí tí í ṣe òdìkejì àlàáfíà. Jákọ́bù sọ pé: “Èyí kọ́ ni ọgbọ́n tí ó sọ̀ kalẹ̀ wá láti òkè, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti ilẹ̀ ayé, ti ẹranko, ti ẹ̀mí èṣù. Nítorí níbi tí owú àti ẹ̀mí asọ̀ bá wà, níbẹ̀ ni rúdurùdu àti gbogbo ohun búburú wà.” (Jákọ́bù 3:14-16) Àwọn kan gbà gbọ́ pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì táa tú sí “ẹ̀mí asọ̀” ní í ṣe pẹ̀lú ìwà anìkànjọpọ́n, jíjẹ àwọn èèyàn lẹ́sẹ̀ nítorí ipò. Abájọ tí Jákọ́bù fi pè é ní “ti ilẹ̀ ayé, ti ẹranko, ti ẹ̀mí èṣù.” Jálẹ̀ ìtàn ni àwọn aláṣẹ ayé ti ń bára wọn ṣe aáwọ̀, bí àwọn ẹranko ẹhànnà tó ń bá ara wọn jà. Ká sọ tòótọ́, ẹ̀mí aáwọ̀ jẹ́ “ti ilẹ̀ ayé” àti “ti ẹranko.” Ó tún jẹ́ ti “ẹ̀mí èṣù.” Ìwà burúkú yìí kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ látọ̀dọ̀ áńgẹ́lì tí ń wá agbára lójú méjèèjì, tó sọ ara rẹ̀ di ọ̀tá Jèhófà Ọlọ́run, tó sì wá di Sátánì, olórí àwọn ẹ̀mí èṣù.
16. Báwo láwọn Kristẹni kan ní ọ̀rúndún kìíní ṣe fi ẹ̀mí bíi ti Sátánì hàn?
16 Jákọ́bù rọ àwọn Kristẹni láti yẹra fún níní ẹ̀mí asọ̀, nítorí pé kì í mú àlàáfíà wá. Ó kọ̀wé pé: “Láti orísun wo ni àwọn ogun ti wá, láti orísun wo sì ni àwọn ìjà ti wá láàárín yín? Wọn kì í ha ṣe láti orísun yìí, èyíinì ni, láti inú àwọn ìfàsí-ọkàn yín fún adùn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara èyí tí ń bá ìforígbárí nìṣó nínú àwọn ẹ̀yà ara yín?” (Jákọ́bù 4:1) Níhìn-ín, “ìfàsí-ọkàn . . . fún adùn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara” lè tọ́ka sí fífi ìwọra máa wá nǹkan ti ara tàbí ìfẹ́ fún òkìkí, ọlá àṣẹ, tàbí agbára. Bíi ti Sátánì, àwọn kan nínú ìjọ lè fẹ́ sọ ara wọn di ẹni ńlá, dípò kí wọ́n jẹ́ ‘ẹni tí ó kéré jù,’ bí Jésù ṣe sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun yóò jẹ́. (Lúùkù 9:48) Irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ lè máà jẹ́ kí àlàáfíà wà nínú ìjọ.
17. Báwo làwọn Kristẹni òde òní ṣe lè jẹ́ olùwá àlááfíà nínú ìjọ?
17 Lónìí, àwa náà gbọ́dọ̀ dènà ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, owú jíjẹ, tàbí ìlépa ipò ọlá. Báa bá jẹ́ ojúlówó olùwá àlàáfíà, a ò ní máa jowú bí àwọn kan bá já fáfá jù wá lọ nínú àwọn iṣẹ́ kan, bẹ́ẹ̀ la ò ní máa bẹnu àtẹ́ lù wọ́n lójú àwọn ẹlòmíràn nípa níní èrò òdì sí wọn. Bí a bá ní ànímọ́ àrà ọ̀tọ̀ kan, a ò ní lò ó láti ṣe fọ́rífọ́rí fún àwọn ẹlòmíràn, ká máa ṣe bí ẹni pé ìjáfáfá àti mímọ̀-ọ́n-ṣe wa ni ìjọ fi ń gbérí. Ìyapa ni irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ ń mú wá; kò lé mú àlàáfíà wá. Àwọn olùwá àlàáfíà kì í fi àwọn ẹ̀bùn tí wọ́n ní ṣakọ, ńṣe ni wọ́n máa ń lò wọ́n fún àǹfààní àwọn arákùnrin wọn àti láti bọlá fún Jèhófà. Wọ́n mọ̀ pé bópẹ́ bóyá, ìfẹ́ ló ń fi Kristẹni tòótọ́ hàn, kì í ṣe mímọ nǹkan ṣe.—Jòhánù 13:35; 1 Kọ́ríńtì 13:1-3.
A Ó Yan “Àlàáfíà Ṣe Àwọn Alábòójútó Rẹ”
18. Báwo ni àwọn alàgbà ṣe ń jẹ́ kí àlàáfíà wà láàárín ara wọn?
18 Àwọn alàgbà ìjọ máa ń mú ipò iwájú nínú jíjẹ́ olùwá àlàáfíà. Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: “Èmi yóò sì yan àlàáfíà ṣe àwọn alábòójútó rẹ àti òdodo ṣe àwọn tí ń pínṣẹ́ fún ọ.” (Aísáyà 60:17) Ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí, àwọn tí wọ́n ń sìn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni olùṣọ́ àgùntàn ń ṣe iṣẹ́ àṣekára láti jẹ́ kí àlàáfíà wà láàárín ara wọn àti láàárín agbo. Àwọn alàgbà lè jẹ́ kí àlàáfíà wà láàárín ara wọn nípa fífi ẹ̀mí àlàáfíà àti ìfòyebánilò tí ó jẹ́ ti “ọgbọ́n tí ó wá láti òkè” hàn. (Jákọ́bù 3:17) Nítorí pé ibi táwọn alàgbà ìjọ ti wá àti ìrírí tí wọ́n ti ní yàtọ̀ síra, ojú tí wọ́n fi ń wo nǹkan lè yàtọ̀ síra nígbà mìíràn. Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé kò sí àlàáfíà láàárín wọn ni? Kò lè rí bẹ́ẹ̀, bí wọ́n bá bójú tó ọ̀ràn náà dáradára. Àwọn olùwá àlàáfíà máa ń fi ìrẹ̀lẹ̀ sọ èrò wọn jáde, wọ́n sì máa ń fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ fetí sí èrò àwọn ẹlòmíràn. Dípò kí ẹni tó ń wá àlàáfíà rin kinkin mọ́ ọ̀nà tirẹ̀, yóò fi tàdúràtàdúrà gbé èrò arákùnrin rẹ̀ yẹ̀ wò. Onírúurú ọ̀nà la lè gbé nǹkan gbà, tí kò bá ti takò ìlànà Bíbélì. Nígbà táwọn ẹlòmíràn kò bá fara mọ́ ohun tí ẹni tó jẹ́ olùwá àlàáfíà sọ, kò ní rin kinkin mọ́ èrò tirẹ̀, yóò fara mọ́ ìpinnu tí àwọn tó pọ̀ jù lọ bá ṣe. Yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òun jẹ́ ẹni tí ń fòye báni lò. (1 Tímótì 3:2, 3) Àwọn alábòójútó tó ti ní ìrírí mọ̀ pé jíjẹ́ kí àlàáfíà wà ṣe pàtàkì ju kéèyàn máa fẹ́ kó jẹ́ pé ohun tí òun bá sọ ni abẹ́ gé.
19. Báwo ni àwọn alàgbà ṣe ń ṣe bí olùwá àlàáfíà nínú ìjọ?
19 Àwọn alàgbà ń jẹ́ kí àlàáfíà wà láàárín àwọn àti agbo nípa ríràn wọ́n lọ́wọ́ àti nípa ṣíṣàì bẹnu àtẹ́ lu ìsapá wọn. Lóòótọ́, ìgbà mìíràn wà tí wọ́n ní láti tọ́ àwọn kan sọ́nà. (Gálátíà 6:1) Àmọ́, iṣẹ́ Kristẹni alábòójútó kì í ṣe pé kó máa fi gbogbo ìgbà báni wí. Ó máa ń sọ̀rọ̀ ìwúrí lọ́pọ̀ ìgbà. Àwọn alàgbà tó nífẹ̀ẹ́ máa ń gbìyànjú láti rí ohun tó ń wúni lórí nínú ìwà àwọn ẹlòmíràn. Àwọn alábòójútó mọyì iṣẹ́ àṣekára tí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn ń ṣe, ó sì dá wọn lójú pé àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn ń sa gbogbo ipá wọn.—2 Kọ́ríńtì 2:3, 4.
20. Ní ọ̀nà wo ni ìjọ gbà ń jàǹfààní bí gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ bá jẹ́ olùwá àlàáfíà?
20 Nítorí náà, nínú ìdílé, nínú ìjọ, àti nínú bí a ṣe ń bá àwọn tí ìgbàgbọ́ wọ́n yàtọ̀ sí tiwa lò, a ń tiraka láti jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà, láti ṣe ohun tó ń mú àlàáfíà wá. Táa bá ń fi taápọntaápọn wá àlàáfíà, a ó máa fi kún ayọ̀ ìjọ. Nígbà kan náà, a óò ní ààbò, a ó sì máa rí okun gbà ní ọ̀pọ̀ ọ̀nà, bí a ó ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà?
• Báwo la ṣe lè jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà nígbà táa bá ń bá àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí lò?
• Kí làwọn ọ̀nà díẹ̀ táa fi lè mú àlàáfíà dàgbà nínú ìdílé?
• Báwo làwọn alàgbà ṣe lè jẹ́ kí àlàáfíà wà nínú ìjọ?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Àwọn olùwá àlàáfíà máa ń yẹra fún fífi ara wọn hàn bí ẹni tó lọ́lá jù
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Àwọn Kristẹni jẹ́ olùwá àlàáfíà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, nínú ilé, àti nínú ìjọ