‘Ẹ Fi Ìpamọ́ra Wọ Ara Yín Láṣọ’
‘Ẹ Fi Ìpamọ́ra Wọ Ara Yín Láṣọ’
“Ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú . . . àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ.”—KÓLÓSÈ 3:12.
1. Sọ àpẹẹrẹ àtàtà kan nípa ìpamọ́ra.
ỌDÚN 1952 ni Régis, tó ń gbé ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Faransé, di Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ṣe batisí. Ọ̀pọ̀ ọdún ni aya rẹ̀ fi ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kí ó lè dí ìsapá rẹ̀ láti sin Jèhófà lọ́wọ́. Ó gbìyànjú láti jo táyà ọkọ̀ rẹ̀ kí ó má lè lọ sípàdé. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tó ń tẹ̀ lé e bó ṣe ń wàásù ìhìn Bíbélì láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà, tó ń fi í ṣe ẹlẹ́yà nígbà tó ń bá onílé sọ̀rọ̀ nípa ìhìn rere Ìjọba náà. Láìfi àtakò léraléra yìí pè, Régis ń lo ìpamọ́ra nìṣó. Nípa bẹ́ẹ̀, Régis jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún gbogbo Kristẹni, níwọ̀n bí Jèhófà ti fẹ́ kí gbogbo àwọn tí ń sin òun jẹ́ onípamọ́ra nínú àjọṣe wọn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.
2. Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tí Gíríìkì lò fún “ìpamọ́ra” ní ṣáńgílítí, kí sì ni ọ̀rọ̀ náà fi hàn?
2 Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “ìpamọ́ra” ní ṣáńgílítí túmọ̀ sí “gígùn ẹ̀mí.” Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì túmọ̀ ọ̀rọ̀ yìí sí “ìpamọ́ra” nígbà mẹ́wàá, ó túmọ̀ rẹ̀ sí “sùúrù” nígbà mẹ́ta, ó sì túmọ̀ rẹ̀ sí “mímú sùúrù” lẹ́ẹ̀kan. Ọ̀rọ̀ Hébérù àti ti Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “ìpamọ́ra” wé mọ́ sùúrù, ìfàyàrán nǹkan, àti lílọ́ra láti bínú.
3. Báwo ni ojú táwọn Kristẹni fi wo ìpamọ́ra ṣe yàtọ̀ pátápátá sí ojú táwọn Gíríìkì ọ̀rúndún kìíní fi wò ó?
3 Àwọn Gíríìkì ọ̀rúndún kìíní kò wo ìpamọ́ra gẹ́gẹ́ bí ìwà funfun. Àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí Sítọ́íkì kò tiẹ̀ lo ọ̀rọ̀ náà rí. Gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ nì, William Barclay, ṣe sọ ọ́, ìpamọ́ra “jẹ́ òdìkejì ìwà funfun lọ́dọ̀ àwọn Gíríìkì,” nítorí pé lára nǹkan “tí wọ́n kọ̀ ni ìwọ̀sí tàbí ìrẹ́jẹ.” Ó sọ pé: “Lójú àwọn Gíríìkì, ẹni tó yẹ ká pè lọ́kùnrin ni ẹni tó máa ń wá ọ̀nàkọnà láti foró yaró. Lójú ti àwọn Kristẹni, ẹni tó yẹ ká pè lọ́kùnrin ni ẹni tó jẹ́ pé, nígbà tó bá tiẹ̀ yẹ kó foró yaró pàápàá, kò ní jẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀.” Àwọn Gíríìkì ti lè ka ìpamọ́ra sí àmì àìlera, ṣùgbọ́n níhìn-ín yìí, bó ṣe rí nínú àwọn ọ̀ràn mìíràn, “ohun òmùgọ̀ ti Ọlọ́run gbọ́n ju àwọn ènìyàn lọ, ohun aláìlera ti Ọlọ́run sì lágbára ju àwọn ènìyàn lọ.”—1 Kọ́ríńtì 1:25.
Àpẹẹrẹ Ìpamọ́ra Kristi
4, 5. Kí ni àgbàyanu àpẹẹrẹ ìpamọ́ra tí Jésù fi lélẹ̀?
4 Ẹnì kan tó tún fi àpẹẹrẹ àtàtà lórí ìpamọ́ra lélẹ̀ lẹ́yìn ti Jèhófà ni Kristi Jésù. Nígbà tí Jésù wà nínú ìṣòro líle koko, ó lo ìkóra-ẹni-níjàánu lọ́nà tó ga lọ́lá. Òun ni a sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ pé: “A ni ín lára dé góńgó, ó sì jẹ́ kí a ṣẹ́ òun níṣẹ̀ẹ́; síbẹ̀síbẹ̀, kò jẹ́ la ẹnu rẹ̀. A ń mú un bọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn fún ìfikúpa; àti bí abo àgùntàn tí ó yadi níwájú àwọn olùrẹ́run rẹ̀, òun kò jẹ́ la ẹnu rẹ̀ pẹ̀lú.”—Aísáyà 53:7.
5 Ìpamọ́ra tí Jésù fi hàn látìbẹ̀rẹ̀ dópin iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé mà bùáyà o! Ó fara da àwọn ìbéèrè aládàkàdekè tí àwọn ọ̀tá rẹ̀ ń béèrè àti ìwọ̀sí táwọn alátakò fi lọ̀ ọ́. (Mátíù 22:15-46; 1 Pétérù 2:23) Ó mú sùúrù pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, kódà nígbà tí wọ́n ń fi gbogbo ìgbà ṣaáwọ̀ nípa ẹni tí ó tóbi jù lọ. (Máàkù 9:33-37; 10:35-45; Lúùkù 22:24-27) Ẹ sì tún wo ìkóra-ẹni-níjàánu tó tayọ lọ́lá tí Jésù lò ní òru ọjọ́ tí wọ́n dà á, nígbà tí Pétérù àti Jòhánù sùn lọ lẹ́yìn tó sọ fún wọn pé kí wọ́n “máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà”!—Mátíù 26:36-41.
6. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe jàǹfààní nínú ìpamọ́ra Jésù, ẹ̀kọ́ wo la sì rí kọ́ nínú èyí?
6 Lẹ́yìn ikú àti àjíǹde Jésù, ó tún ń ní ìpamọ́ra nìṣó. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ èyí dáadáa, níwọ̀n bó ti fìgbà kan jẹ́ ẹni tó ń ṣenúnibíni sí àwọn Kristẹni. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ṣíṣeégbíyèlé àti yíyẹ fún ìtẹ́wọ́gbà kíkún ni àsọjáde náà pé Kristi Jésù wá sí ayé láti gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ là. Nínú àwọn wọ̀nyí èmi jẹ́ ẹni àkọ́kọ́. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìdí tí a fi fi àánú hàn sí mi ni pé nípasẹ̀ mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀ràn àkọ́kọ́, kí Kristi Jésù lè fi gbogbo ìpamọ́ra rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ kan lára àwọn tí yóò gbé ìgbàgbọ́ wọn lé e fún ìyè àìnípẹ̀kun.” (1 Tímótì 1:15, 16) Irú ẹni yòówù kí a jẹ́ tẹ́lẹ̀ rí, bí a bá ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù, yóò ní ìpamọ́ra fún wa—àmọ́, yóò retí pé ká ṣe “àwọn iṣẹ́ tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà.” (Ìṣe 26:20; Róòmù 2:4) Àwọn iṣẹ́ tí Kristi rán sáwọn ìjọ méje tó wà ní Éṣíà Kékeré fi hàn pé bó tilẹ̀ jẹ́ onípamọ́ra, síbẹ̀ ó fẹ́ kéèyàn máa ṣàtúnṣe.—Ìṣípayá, orí kejì àti ìkẹta.
Èso Ti Ẹ̀mí
7. Kí ni ìbátan tó wà láàárín ìpamọ́ra àti ẹ̀mí mímọ́?
7 Nínú orí karùn-ún lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Gálátíà, ó fi ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn iṣẹ́ ti ara àti èso ti ẹ̀mí hàn. (Gálátíà 5:19-23) Níwọ̀n bí ìpamọ́ra ti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ Jèhófà, ànímọ́ yìí pilẹ̀ ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì tún jẹ́ èso ti ẹ̀mí rẹ̀. (Ẹ́kísódù 34:6, 7) Àní sẹ́, ìpamọ́ra ni Pọ́ọ̀lù fi ṣe ìkẹrin nínú ibi tó ti ṣàpèjúwe èso ti ẹ̀mí, ó tò ó mọ́ “ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, . . . inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.” (Gálátíà 5:22, 23) Nítorí náà, nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run bá fi sùúrù rẹ̀, tàbí ìpamọ́ra hàn, wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ lábẹ́ ìdarí ẹ̀mí mímọ́ ni.
8. Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ní èso ti ẹ̀mí, títí kan ìpamọ́ra?
8 Àmọ́ ṣá o, èyí kò wá túmọ̀ sí pé ńṣe ni Jèhófà máa ń fi tipátipá fúnni ní ẹ̀mí rẹ̀. A gbọ́dọ̀ múra tán láti tẹ̀ lé ìdarí ẹ̀mí rẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 3:17; Éfésù 4:30) A óò jẹ́ kí ẹ̀mí náà máa ṣiṣẹ́ nínú ìgbésí ayé wa nípa mímú èso rẹ̀ dàgbà nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe. Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù to iṣẹ́ ti ara àti èso ti ẹ̀mí lẹ́sẹẹsẹ tán, ó fi kún un pé: “Bí a bá wà láàyè nípa ẹ̀mí, ẹ jẹ́ kí a máa rìn létòletò nípa ẹ̀mí pẹ̀lú. Ẹ má ṣe jẹ́ kí a ṣì yín lọ́nà: Ọlọ́run kì í ṣe ẹni tí a lè fi ṣe ẹlẹ́yà. Nítorí ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú; nítorí ẹni tí ń fúnrúgbìn pẹ̀lú níní ẹran ara rẹ̀ lọ́kàn yóò ká ìdíbàjẹ́ láti inú ẹran ara rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ń fúnrúgbìn pẹ̀lú níní ẹ̀mí lọ́kàn yóò ká ìyè àìnípẹ̀kun láti inú ẹ̀mí.” (Gálátíà 5:25; 6:7, 8) Bí a bá fẹ́ kẹ́sẹ járí nínú níní ìpamọ́ra, a gbọ́dọ̀ tún ní àwọn èso yòókù tí àwọn Kristẹni ń tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ mú jáde.
“Ìfẹ́ A Máa Ní Ìpamọ́ra”
9. Kí nìdí tó lè mú kí Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará Kọ́ríńtì pé “ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra”?
9 Pọ́ọ̀lù fi hàn pé ìbátan àrà ọ̀tọ̀ kan wà láàárín ìfẹ́ àti ìpamọ́ra nígbà tó sọ pé: “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra.” (1 Kọ́ríńtì 13:4) Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ kan, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Albert Barnes sọ pé Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ èyí nítorí asọ̀ àti gbọ́nmi-si omi-ò-to tó wà nínú ìjọ Kristẹni ní Kọ́ríńtì. (1 Kọ́ríńtì 1:11, 12) Barnes là á mọ́lẹ̀ pé: “Ọ̀rọ̀ tá a lò níhìn-ín [fún ìpamọ́ra] jẹ́ òdì kejì ṣíṣe nǹkan wàdùwàdù: ó jẹ́ òdì kejì ọ̀rọ̀ àti èrò ìbínú, àti ìkanra. Ó ń tọ́ka sí ọkàn tó lè RÍ ARA GBA NǸKAN FÚN ÌGBÀ PÍPẸ́ nígbà tí wọ́n bá ni ín lára, tí wọ́n bá sì mú un bínú.” Ìfẹ́ àti ìpamọ́ra tún ń fi kún àlàáfíà ìjọ Kristẹni lọ́nà tó ga.
10. (a) Ọ̀nà wo ni ìfẹ́ gbà ń ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ onípamọ́ra, ìmọ̀ràn wo sì ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá nínú ọ̀ràn yìí? (b) Ọ̀rọ̀ wo ni ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ kan sọ nípa ìpamọ́ra àti inú rere Ọlọ́run? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
10 “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere. Ìfẹ́ . . . kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan, a kì í tán an ní sùúrù.” Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni ìfẹ́ ń gbà ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ onípamọ́ra. a (1 Kọ́ríńtì 13:4, 5) Ìfẹ́ ń mú kó ṣeé ṣe fún wa láti máa mú sùúrù fún ara wa ká sì máa rántí pé gbogbo wa ni aláìpé tá a ní àwọn àléébù àti kùdìẹ̀-kudiẹ. Ó dáa ká máa gba tẹni rò, ká sì máa dárí jini. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú láti máa rìn ‘pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ pátápátá ti èrò inú àti ìwà tútù, pẹ̀lú ìpamọ́ra, ní fífaradà á fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì nínú ìfẹ́, kí a máa fi taratara sakun láti máa pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè asonipọ̀ṣọ̀kan ti àlàáfíà.’—Éfésù 4:1-3.
11. Èé ṣe tí ìpamọ́ra fi jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì gan-an láàárín àwùjọ Kristẹni?
11 Bí wọ́n bá ní ìpamọ́ra láàárín ara wọn, èyí yóò mú kí àlàáfíà àti ayọ̀ wà láàárín àwùjọ Kristẹni, yálà nínú ìjọ, ní Bẹ́tẹ́lì, ní àwọn ilé míṣọ́nnárì, láàárín ẹgbẹ́ àwọn kọ́lékọ́lé, tàbí láwọn ilé ẹ̀kọ́ táwọn Kristẹni ṣètò. Àwọn ohun tí ń múni bínú lè wáyé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nítorí ìwà kálukú, nítorí ọ̀ràn èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́, nítorí ohun tí kálukú kà sí ìwà ọmọlúwàbí, kódà nítorí ìlànà ìmọ́tótó tó yàtọ̀ síra. Bẹ́ẹ̀ náà ló rí láàárín ìdílé pàápàá. Ó ṣe pàtàkì láti jẹ́ ẹni tí ń lọ́ra láti bínú. (Òwe 14:29; 15:18; 19:11) Ìpamọ́ra—ìyẹn ìfaradà onísùúrù, pẹ̀lú èrò pé ẹni náà yóò yí padà sí rere—jẹ́ ohun tó pọndandan fún gbogbo wa.—Róòmù 15:1-6.
Ìpamọ́ra Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Ní Ìfaradà
12. Èé ṣe tí ìpamọ́ra fi ṣe pàtàkì láwọn àkókò tí nǹkan bá le koko?
12 Ìpamọ́ra ń ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àwọn ipò líle koko tó dà bí èyí tí kò ní dópin tàbí tí kò ní ojútùú kankan lójú ẹsẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Régis, tá a mẹ́nu kàn níṣàájú nìyẹn. Ọ̀pọ̀ ọdún ni aya rẹ̀ fi ń tako gbogbo ipá tó ń sà láti sin Jèhófà. Àmọ́, ọjọ́ kan ni aya rẹ̀ ọ̀hún wá bá a pẹ̀lú omijé lójú, tó sọ pé: “Mo mọ̀ pé òtítọ́ ni. Ràn mí lọ́wọ́. Mo fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, òun náà ṣe batisí, ó di Ẹlẹ́rìí. Régis sọ pé: “Èyí fi hàn pé Jèhófà bù kún àwọn ọdún ìlàkàkà, sùúrù, àti ìfaradà wọ̀nyẹn.” Ìpamọ́ra rẹ̀ lérè.
13. Kí ló ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ láti ní ìfaradà, báwo sì ni àpẹẹrẹ rẹ̀ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìfaradà?
13 Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà nínú ìpamọ́ra. (2 Kọ́ríńtì 6:3-10; 1 Tímótì 1:16) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sún mọ́ ọjọ́ ikú rẹ̀, tó ń fún Tímótì, alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ tó kéré sí i lọ́jọ́ orí nímọ̀ràn, ó jẹ́ kó mọ̀ pé gbogbo Kristẹni ni yóò dojú kọ àdánwò. Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí àpẹẹrẹ ti ara rẹ̀, ó sì dábàá àwọn ojúlówó ànímọ́ Kristẹni tó pọndandan fún ìfaradà. Ó kọ̀wé pé: “Ìwọ ti tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ mi pẹ́kípẹ́kí, ipa ọ̀nà ìgbésí ayé mi, ète mi, ìgbàgbọ́ mi, ìpamọ́ra mi, ìfẹ́ mi, ìfaradà mi, àwọn inúnibíni mi, àwọn ìjìyà mi, irú àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí mi ní Áńtíókù, ní Íkóníónì, ní Lísírà, irú àwọn inúnibíni tí mo ti mú mọ́ra; síbẹ̀, Olúwa dá mi nídè nínú gbogbo wọn. Ní ti tòótọ́, gbogbo àwọn tí ń ní ìfẹ́-ọkàn láti gbé pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú Kristi Jésù ni a ó ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.” (2 Tímótì 3:10-12; Ìṣe 13:49-51; 14:19-22) Gbogbo wa la nílò ìgbàgbọ́, ìfẹ́, àti ìpamọ́ra ká lè ní ìfaradà.
Ẹ Gbé Ìpamọ́ra Wọ̀
14. Kí ni Pọ́ọ̀lù fi àwọn ànímọ́ Ọlọ́run bí ìpamọ́ra wé, ìmọ̀ràn wo ló sì fún àwọn Kristẹni tó wà ní Kólósè?
14 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ìpamọ́ra àti àwọn ànímọ́ mìíràn wé aṣọ tí Kristẹni ní láti gbé wọ̀ lẹ́yìn tó bá bọ́ àwọn ìṣe tó jẹ́ ti “ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà” sílẹ̀. (Kólósè 3:5-10) Ó kọ̀wé pé: “Gẹ́gẹ́ bí àyànfẹ́ Ọlọ́run, mímọ́ àti olùfẹ́, ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ. Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe. Ṣùgbọ́n, yàtọ̀ sí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.”—Kólósè 3:12-14.
15. Kí ló máa ń jẹ́ àbájáde rẹ̀ nígbà táwọn Kristẹni bá fi ìpamọ́ra àti àwọn ànímọ́ mìíràn ‘wọ ara wọn láṣọ’?
15 Nígbà táwọn mẹ́ńbà ìjọ bá fi ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, ìpamọ́ra àti ìfẹ́ ‘wọ ara wọn láṣọ,’ yóò ṣeé ṣe fún wọn láti yanjú àwọn ìṣòro, wọn ó sì máa fi ìṣọ̀kan tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Àwọn Kristẹni alábòójútó gan-an ló gbọ́dọ̀ jẹ́ onípamọ́ra jù. Àwọn ìgbà mìíràn lè wà tó yẹ kí wọ́n tọ́ Kristẹni mìíràn sọ́nà, àmọ́ onírúurú ọ̀nà ni wọ́n lè gbà ṣe èyí. Pọ́ọ̀lù ṣàpèjúwe ọ̀nà tó dára jù lọ nígbà tó kọ̀wé sí Tímótì pé: “Fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, báni wí kíkankíkan, gbani níyànjú, pẹ̀lú gbogbo ìpamọ́ra àti ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́.” (2 Tímótì 4:2) Bẹ́ẹ̀ ni o, a gbọ́dọ̀ máa fi ìpamọ́ra, ọ̀wọ̀, àti ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn bá àwọn àgùntàn Jèhófà lò.—Mátíù 7:12; 11:28; Ìṣe 20:28, 29; Róòmù 12:10.
“Ìpamọ́ra fún Gbogbo Ènìyàn”
16. Kí ló lè jẹ́ àbájáde rẹ̀ tá a bá “ní ìpamọ́ra fún gbogbo ènìyàn”?
16 Ìpamọ́ra tí Jèhófà ní fún ìran ènìyàn ti sọ ọ́ di dandan fún wa láti “ní ìpamọ́ra fún gbogbo ènìyàn.” (1 Tẹsalóníkà 5:14) Èyí túmọ̀ sí mímú sùúrù fún àwọn mẹ́ńbà ìdílé wa, àwọn aládùúgbò wa, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́, àti àwọn ọmọ kíláàsì wa tí wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí. Àwọn Ẹlẹ́rìí, tí wọ́n ti fi ọ̀pọ̀ ọdún dojú kọ àwọn ọ̀rọ̀ kòbákùngbé tàbí àtakò ojúkoojú látọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí nílé ìwé, ti borí ọ̀pọ̀ ẹ̀tanú. (Kólósè 4:5, 6) Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Ẹ tọ́jú ìwà yín kí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, pé, nínú ohun náà tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lòdì sí yín gẹ́gẹ́ bí aṣebi, kí wọ́n lè tipa àwọn iṣẹ́ yín àtàtà tí wọ́n fojú rí, yin Ọlọ́run lógo ní ọjọ́ náà fún àbẹ̀wò rẹ̀.”—1 Pétérù 2:12.
17. Báwo la ṣe lè fara wé ìfẹ́ Jèhófà àti ìpamọ́ra rẹ̀, èé sì ti ṣe tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀?
17 Ìpamọ́ra Jèhófà yóò túmọ̀ sí ìgbàlà fún ọ̀kẹ́ àìmọye ènìyàn. (2 Pétérù 3:9, 15) Bá a bá fara wé ìfẹ́ àti ìpamọ́ra Jèhófà, a óò máa fi sùúrù bá iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lọ, a ó sì máa kọ́ àwọn ẹlòmíràn láti tẹrí ba fún ìṣàkóso Ìjọba Kristi. (Mátíù 28:18-20; Máàkù 13:10) Tá a bá lọ ṣíwọ́ wíwàásù pẹ́nrẹ́n, ńṣe ló máa dà bíi pé a fẹ́ bẹ́gi dínà ìpamọ́ra Jèhófà, tá á sì fi hàn pé a ò mọ ète rẹ̀, tó wà fún mímú káwọn èèyàn wá sí ìrònúpìwàdà.—Róòmù 2:4.
18. Àdúrà wo ni Pọ́ọ̀lù gbà fún àwọn ará Kólósè?
18 Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn Kristẹni tó wà ní Kólósè, Éṣíà Kékeré, ó kọ̀wé pé: “Ìdí tún nìyẹn tí ó fi jẹ́ pé, láti ọjọ́ tí a ti gbọ́ nípa rẹ̀, àwa kò ṣíwọ́ gbígbàdúrà fún yín àti bíbéèrè pé kí ẹ lè kún fún ìmọ̀ pípéye nípa ìfẹ́ rẹ̀ nínú ọgbọ́n gbogbo àti ìfinúmòye ti ẹ̀mí, kí ẹ lè máa rìn lọ́nà tí ó yẹ Jèhófà fún ète wíwù ú ní kíkún bí ẹ ti ń bá a lọ ní síso èso nínú iṣẹ́ rere gbogbo, tí ẹ sì ń pọ̀ sí i nínú ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run, tí a ń sọ yín di alágbára pẹ̀lú gbogbo agbára dé ìwọ̀n agbára ńlá rẹ̀ ológo kí ẹ bàa lè fara dà á ní kíkún, kí ẹ sì máa ní ìpamọ́ra pẹ̀lú ìdùnnú.”—Kólósè 1:9-11.
19, 20. (a) Báwo la ṣe lè yẹra fún wíwo ìpamọ́ra tí Jèhófà ṣì ní gẹ́gẹ́ bí àdánwò? (b) Àwọn àǹfààní wo ni yóò wá látinú jíjẹ́ tí a bá jẹ́ onípamọ́ra?
19 Bí Jèhófà ṣe ń ní ìpamọ́ra tàbí sùúrù nìṣó kò ní jẹ́ àdánwò fún wa bí a bá “kún fún ìmọ̀ pípéye nípa ìfẹ́ rẹ̀,” ìfẹ́ rẹ̀ sì ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tímótì 2:4) A óò máa “bá a lọ ní síso èso nínú iṣẹ́ rere gbogbo,” àgàgà nínú iṣẹ́ wíwàásù “ìhìn rere ìjọba yìí.” (Mátíù 24:14) Bí a bá ń fi ìṣòtítọ́ bá ṣíṣe èyí nìṣó, Jèhófà yóò sọ wá di “alágbára pẹ̀lú gbogbo agbára,” tí yóò máa jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti “fara dà á ní kíkún, kí [a] sì máa ní ìpamọ́ra pẹ̀lú ìdùnnú.” Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a óò “máa rìn lọ́nà tí ó yẹ Jèhófà,” a ó sì ní àlàáfíà tó ń wá látinú mímọ̀ pé a ń “wù ú ní kíkún.”
20 Ǹjẹ́ kí a gbà tọkàntọkàn pé ìpamọ́ra Jèhófà bọ́gbọ́n mu. Ó ń ṣiṣẹ́ fún ìgbàlà wa àti ti àwọn tó ń fetí sí ìwàásù àti ẹ̀kọ́ wa. (1 Tímótì 4:16) Mímú èso ti ẹ̀mí—ìyẹn ìfẹ́, inú rere, ìwà rere, àti ìkóra-ẹni-níjàánu dàgbà—yóò mú kó ṣeé ṣe fún wa láti máa fi tayọ̀tayọ̀ lo ìpamọ́ra. Yóò ṣeé ṣe fún wa láti máa wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn mẹ́ńbà ìdílé wa, títí kan àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa nínú ìjọ. Ìpamọ́ra yóò tún jẹ́ kí a máa mú sùúrù fún àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wa tàbí àwọn ọmọ ilé ìwé wa. Ìpamọ́ra wa yóò sì tún ní ète kan nínú, ìyẹn ni gbígba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ là àti yíyin Jèhófà, Ọlọ́run onípamọ́ra lógo.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nígbà tí Gordon D. Fee tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ ń sọ èrò tirẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ pé “ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere,” ó kọ̀wé pé: “Nínú ẹ̀kọ́ Pọ́ọ̀lù, [ìpamọ́ra àti inú rere] jẹ́ ìhà méjèèjì tí Ọlọ́run kọ sí ìran ènìyàn (Róòmù 2:4). Ní apá kan, ìfaradà onífẹ̀ẹ́ tí Ọlọ́run ní ló jẹ́ kó fawọ́ ìbínú rẹ̀ sí àwọn ọlọ̀tẹ̀ ẹ̀dá sẹ́yìn; ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, inú rere rẹ̀ fara hàn nínú ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀nà tó gbà ń fi àánú rẹ̀ hàn. Nípa bẹ́ẹ̀, àpèjúwe ìfẹ́ tí Pọ́ọ̀lù ṣe bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àpèjúwe méjì yìí tó ṣe nípa Ọlọ́run, ẹni tó tipasẹ̀ Kristi fi hàn pé òun jẹ́ onísùúrù àti onínúure sí àwọn tí ìdájọ́ rẹ̀ tọ́ sí.”
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Ọ̀nà wo ni Kristi gbà jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà nípa ìpamọ́ra?
• Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìpamọ́ra?
• Báwo ni ìpamọ́ra ṣe ń ran àwọn ìdílé, àwùjọ Kristẹni àti àwọn alàgbà lọ́wọ́?
• Báwo ni jíjẹ́ tí a bá jẹ́ onípamọ́ra yóò ṣe ṣàǹfààní fún àwa fúnra wa àti fún àwọn ẹlòmíràn?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Kódà nígbà tí Jésù wà lábẹ́ ipò líle koko, ó fi sùúrù bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lò
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
A rọ àwọn Kristẹni alábòójútó láti fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nínú fífi ìpamọ́ra bá àwọn arákùnrin wọn lò
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Bá a bá fara wé ìfẹ́ àti ìpamọ́ra Jèhófà, a óò máa wàásù ìhìn rere náà nìṣó
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Pọ́ọ̀lù gbàdúrà pé kí àwọn Kristẹni “ní ìpamọ́ra pẹ̀lú ìdùnnú”