O Nílò Ẹ̀rí Ọkàn Tá A Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́
O Nílò Ẹ̀rí Ọkàn Tá A Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́
Àwọn èrò ọkọ̀ àtàwọn òṣìṣẹ́ inú ọkọ̀ òfuurufú Air New Zealand Nọ́ńbà 901, tó ń fò lọ sí ilẹ̀ oníyìnyín ti Antarctica ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ pé ọjọ́ ńlá yìí ṣojú ẹ̀mí àwọn. Oríṣiríṣi kámẹ́rà ti wà ní sẹpẹ́, ìrìn àjò náà sì lárinrin bí ọkọ̀ òfuurufú DC-10 yìí ti ń sún mọ́ àgbáálá ilẹ̀ tí yìnyín bò náà. Ọkọ̀ òfuurufú náà wá túbọ̀ sún mọ́lẹ̀ gan-an káwọn èèyàn lè rí ìran àrímáleèlọ yìí dáadáa.
AWAKỌ̀ náà ti ń wakọ̀ òfuurufú fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Ó ti lò tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà [11,000] wákàtí lẹ́nu iṣẹ́ fífi ọkọ̀ òfuurufú fò. Kí wọ́n tiẹ̀ tó gbéra rárá ló ti kọ́kọ́ fara balẹ̀ tẹ gbogbo bí wọ́n ṣe fẹ́ rìn ín sínú kọ̀ǹpútà tí ń darí ọkọ̀ òfuurufú náà, láìmọ̀ pé àwọn ìsọfúnni tí wọ́n fún òun kò tọ̀nà. Bí ọkọ̀ òfuurufú DC-10 náà ṣe wọnú ìkuukùu tó wà ní ibi tí kò ga tó ẹgbẹ̀ta [600] mítà sílẹ̀, ńṣe ló lọ larí mọ́ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Òkè Erebus, gbogbo igba ó lé mẹ́tàdínlọ́gọ́ta [257] èrò ọkọ̀ sì ṣègbé.
Gan-an gẹ́gẹ́ bí kọ̀ǹpútà ṣe ń tọ́ àwọn ọkọ̀ òfuurufú òde òní sọ́nà lójú òfuurufú, bẹ́ẹ̀ náà làwọn èèyàn ní ẹ̀rí ọkàn tí ń tọ́ wọn sọ́nà ní ìgbésí ayé wọn. Jàǹbá burúkú tó ṣẹlẹ̀ sí ọkọ̀ òfuurufú Nọ́ńbà 901 yìí sì lè kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n gidi nípa ẹ̀rí ọkàn wa. Fún àpẹẹrẹ, bí gígúnlẹ̀ láyọ̀ ọkọ̀ òfuurufú ṣe sinmi lórí níní ohun èlò atọ́ka ọ̀nà tó ń ṣiṣẹ́ dáadáa àtàwọn ìlànà tó gún régé, bẹ́ẹ̀ náà ni ìlera wa nípa tẹ̀mí, nípa ti ìwà rere, àti nípa ti ara pàápàá ṣe sinmi lórí níní ẹ̀rí ọkàn tó jí pépé, tí àwọn ìlànà ìwà rere tó gún régé ń darí.
Ó mà ṣe o, pé irú àwọn ìlànà bẹ́ẹ̀ ti ń dàwátì, tàbí pé àwọn èèyàn ò kà wọ́n sí mọ́ lóde òní. Olùkọ́ni kan ní Amẹ́ríkà sọ pé: “Lóde òní, à ń gbọ́ pé ọ̀pọ̀ ọmọléèwé ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ni kò lè kàwé, tí wọn ò lè kọ̀wé, tí wọn ò tiẹ̀ mọ ibi tí ilẹ̀ Faransé wà nínú àwòrán ilẹ̀. Òótọ́ tún ni pé ọ̀pọ̀ ọmọléèwé wọ̀nyí ni kò mọ̀yàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. Wọn ò mọ̀ọ́kọ, wọn ò mọ̀ọ́kà, wọn ò mọ ìṣirò, wọn ò sì tún wá mọ dòò nípa ọ̀ràn ìwà rere.” Ó tún sọ pé “àwọn èwe ìwòyí ò mọ ọwọ́ ọ̀tún wọn yàtọ̀ sí tòsì nínú ọ̀ràn ìwà rere. Béèrè lọ́wọ́ ọ̀kan lára wọn bóyá ó mọ̀yàtọ̀ láàárín ‘ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́,’ ojú ẹsẹ̀ ni á máa wò bọ̀ọ̀, tí kò sì ní lè sọ̀rọ̀ mọ́, tí ojora á mú un, tí àyà rẹ̀ á sì bẹ̀rẹ̀ sí já. . . . Dípò kí ìṣòro yìí dín kù, ńṣe ló tún ń burú sí i nígbà tí wọ́n bá wọ yunifásítì.”
Ọ̀kan lára ohun tó ń fa ìṣòro yìí ni pé ayé ti sọ ọ̀ràn ìwà rere di èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́. Èrò tó gbòde ni pé ìlànà tó bá wu kálukú tàbí tó bá bá kálukú lára mu ni kó máa tẹ̀ lé. Fojú inú wo ohun tó máa ṣẹlẹ̀ bó bá jẹ́ pé ohun èlò tí kò láyọ̀lé tàbí tó tiẹ̀ máa ń dàwátì nígbà míì, ló ń tọ́ àwọn awakọ̀ òfuurufú sọ́nà! Ó dájú pé irú jàǹbá tó ṣẹlẹ̀ ní Òkè Erebus á pọ̀ káàkiri. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, pípa tí ayé pa ìlànà gígún régé nípa ìwà rere tì ló fà á tí àgbákò àti ikú fi ń pọ̀ sí i lóríṣiríṣi, bí àwọn ìdílé ti ń tú ká nítorí ìwà àìṣòótọ́, tí àrùn éèdì àtàwọn àrùn mìíràn táwọn èèyàn ń kó nípasẹ̀ ìbálòpọ̀ takọtabo sì ń fojú ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn gbolẹ̀.
Lóòótọ́, ìlànà èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́ lè dún bí èdè àwọn tó lajú. Ṣùgbọ́n àwọn tó ń tẹ̀ lé ìlànà yìí kò yàtọ̀ sáwọn ará Nínéfè ìgbàanì tí wọn kò “mọ ìyàtọ̀ rárá láàárín ọwọ́ ọ̀tún wọn àti òsì wọn.” Àwọn tó ń tẹ̀ lé ìlànà èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́ nínú ọ̀ràn ìwà rere dà bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì apẹ̀yìndà tí ń sọ pé “ohun tí ó dára burú àti pé ohun tí ó burú dára.”—Jónà 4:11; Aísáyà 5:20.
Nítorí náà, níbo la ti lè rí òfin àti ìlànà tó ṣe kedere, tí kò díjú, tá a lè fi kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa lẹ́kọ̀ọ́ 2 Tímótì 3:16) Ẹ̀rí ti fi hàn láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá pé ó ṣeé gbára lé pátápátá. Ìlànà ìwà rere tó wà nínú Bíbélì wúlò fún gbogbo ẹ̀dá ènìyàn, nítorí pé Ẹlẹ́dàá wa, tí í ṣe aláṣẹ gíga jù lọ, ló gbé e kalẹ̀. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé kò sídìí tó fi yẹ ká ya òpè nípa ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́.
kí ó má bàa ṣì wá lọ́nà? Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ti rí i pé Bíbélì nìkan ni atọ́nà yìí. Gbogbo ọ̀ràn pàtàkì ni Bíbélì sọ̀rọ̀ lé lórí, látorí ọ̀ràn ìwà rere títí dórí jíjẹ́ òṣìṣẹ́kára, látorí ọ̀ràn ọmọ títọ́ títí kan jíjọ́sìn Ọlọ́run. (Àmọ́, àwọn ohun tó lè fa jàǹbá fún ẹ̀rí ọkàn rẹ pọ̀ gan-an báyìí ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Báwo lo sì ṣe lè dáàbò bo ẹ̀rí ọkàn rẹ? Ohun tó yẹ kó o kọ́kọ́ mọ̀ ni ibi tí jàǹbá wọ̀nyí ti ń wá, àti onírúurú ọgbọ́n tí oníjàǹbá yìí ń ta. Ìwọ̀nyí la óò jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.