Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Báwo ni ejò ṣe fi èrò náà sọ́kàn Éfà pé kí ó rú òfin Ọlọ́run nípa igi ìmọ̀ rere àti búburú nínú ọgbà Édẹ́nì?

Jẹ́nẹ́sísì 3:1 sọ pé: “Wàyí o, ejò jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra jù lọ nínú gbogbo ẹranko inú pápá tí Jèhófà Ọlọ́run dá. Nítorí náà, ó sọ fún obìnrin náà pé: ‘Ṣé bẹ́ẹ̀ ni ní tòótọ́, pé Ọlọ́run sọ pé ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú gbogbo igi ọgbà?’” Onírúurú àbá làwọn èèyàn ti gbé kalẹ̀ nípa ọ̀nà tí ejò náà gbà gbin èrò yìí sí Éfà lọ́kàn. Àbá kan ni pé ejò náà ṣe bẹ́ẹ̀ nípa fífi ara sọ̀rọ̀ tàbí fífi ara ṣàpèjúwe. Fún àpẹẹrẹ, àlùfáà Joseph Benson, tí í ṣe ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, sọ pé: “Àfàìmọ̀ kí ó máà jẹ́ pé irú àwọn àmì kan ni ó lò. Àwọn kan tiẹ̀ ti dá a lábàá pé ejò ìgbà yẹn ní làákàyè, ó sì lè sọ̀rọ̀, . . . àmọ́ kò sí ẹ̀rí kankan tó ti èyí lẹ́yìn.”

Ṣùgbọ́n bó bá jẹ́ pé ó kàn fara ṣàpèjúwe lásán ni, báwo ni ejò náà ṣe lè gbin èrò náà sí Éfà lọ́kàn pé bó bá jẹ nínú èso tá a kà léèwọ̀ náà, òun yóò dà bí Ọlọ́run, yóò sì lè dá pinnu ohun tó dára àtohun tó burú? Láfikún sí i, Éfà kópa nínú ìfèròwérò náà, ní ti pé ó dáhùn ìbéèrè tí ejò náà bi í. (Jẹ́nẹ́sísì 3:2-5) Èrò náà pé kìkì àmì tàbí ìfaraṣàpèjúwe ni ejò náà lò yóò múni parí èrò sí pé ọ̀nà kan náà yìí ni Éfà gbà dá a lóhùn, ṣùgbọ́n ohun tí Bíbélì sọ ni pé Éfà sọ̀rọ̀.

Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ó kìlọ̀ fáwọn Kristẹni pé: “Mo ń fòyà pé lọ́nà kan ṣáá, bí ejò ti sún Éfà dẹ́ṣẹ̀ nípasẹ̀ àlùmọ̀kọ́rọ́yí rẹ̀, a lè sọ èrò inú yín di ìbàjẹ́.” Ewu tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ látọ̀dọ̀ àwọn “èké àpọ́sítélì, àwọn oníṣẹ́ ẹ̀tàn.” Ìfaraṣàpèjúwe nìkan kọ́ ni irú ‘àwọn àpọ́sítélì adárarégèé’ bẹ́ẹ̀ fi ń ṣọṣẹ́. Wọ́n ń lo ọ̀rọ̀ ẹnu—ìyẹn ọ̀rọ̀ àlùmọ̀kọ́rọ́yí tí wọ́n fi ń tanni jẹ.—2 Kọ́ríńtì 11:3-5, 13.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ la fi tan Éfà jẹ nínú ọgbà Édẹ́nì, kì í kúkú ṣe pé ejò lásán yìí ní ohùn tó fi sọ̀rọ̀. Kò sóhun tó fẹ́ fi ohùn ṣe. Nígbà tí áńgẹ́lì Ọlọ́run gbẹnu abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ bá Báláámù sọ̀rọ̀, ẹranko náà kò nílò irú ohùn téèyàn ní. (Númérì 22:26-31) Ó dájú pé nígbà tí ‘ẹranko arẹrù tí kò lè fọhùn yìí fi ohùn ènìyàn sọ̀rọ̀,’ ilẹ̀ ọba ẹ̀mí ni ohùn yẹn ti wá.—2 Pétérù 2:16.

Bíbélì pe ẹ̀dá ẹ̀mí tó gbẹnu ejò náà sọ̀rọ̀ ní “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì.” (Ìṣípayá 12:9) Ẹni tó sọ ọ̀rọ̀ tí Éfà gbọ́, tí Éfà sì fèsì ni Sátánì, ẹni tí ń “pa ara rẹ̀ dà di áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀.”—2 Kọ́ríńtì 11:14.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

“Ó . . . dájú pé ẹ̀yin yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú”