“Ọ̀tọ̀ Ni Nọ́ńbà Tí O Fẹ́ Pè”
Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
“Ọ̀tọ̀ Ni Nọ́ńbà Tí O Fẹ́ Pè”
NÍ Johannesburg, tó wà ní Gúúsù Áfíríkà, Leslie àti Caroline ń fi tẹlifóònù jẹ́rìí fáwọn tó wà lágbègbè kan táwọn tó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ń gbé, nítorí pé ó lójú àwọn tí wọ́n ń gbà láyè láti wọlé. Àwọn èèyàn díẹ̀ ni wọ́n rí bá sọ̀rọ̀, àwọn èèyàn náà ò sì fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn Kristẹni tí wọ́n ń jẹ́, ìdí nìyẹn tínú Caroline fi dùn gan-an nígbà tí ìyá kan dá a lóhùn.
Caroline béèrè pé: “Ṣé Ìyáàfin B— nìyẹn?”
Ẹnì kan dá a lóhùn bí ọ̀rẹ́ pé: “Ó tì o, Ìyáàfin G— lorúkọ mi. Bóyá ọ̀tọ̀ ni nọ́ńbà tí o fẹ́ pè.”
Bí Caroline ṣe rí i pé ó dá òun lóhùn tẹ̀rín-tẹ̀yẹ, ló yáa sọ pé: “Tóò, jẹ́ kí n ṣàlàyé ohun tí mo fẹ́ bá Ìyáàfin B— sọ.” Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìbùkún tí Ìjọba Ọlọ́run tó ń bọ̀ máa mú wá. Lẹ́yìn tí wọ́n ti jọ ṣètò bó ṣe máa wá fún un ní ìwé pẹlẹbẹ Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?, ni Ìyáàfin G— wá béèrè pé: “Dúró ná o, ẹ̀sìn wo ni tìẹ ná?”
Caroline dáhùn pé: “Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni.”
“Rárá o, mi ò mọ̀ pé ẹ̀sìn yẹn ni! Jọ̀ọ́ máà jẹ́ kí n rí ẹ.”
Caroline wá rọ̀ ọ́ pé: “Àmọ́ o, Ìyáàfin G—, fún ogún ìṣẹ́jú la ti jọ ń sọ̀rọ̀ nípa ìrètí tó jẹ́ àgbàyanu jù lọ, tí mo sì fi Bíbélì ṣàlàyé ohun tí Ìjọba Ọlọ́rùn máa ṣe fún ìran ènìyàn láìpẹ́. Inú rẹ dùn láti gbọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí—kódà ó wú ọ lórí—o sì fẹ́ túbọ̀ mọ̀ nípa rẹ̀. Kí lo ti gbọ́ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Tó o bá ń ṣàìsàn, ṣé ọ̀dọ̀ mẹkáníìkì lo máa lọ? O ò ṣe jẹ́ kí èmi sọ ohun tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ fún ọ?”
Ó kọ́kọ́ dákẹ́ lọ gbári, lẹ́yìn náà ó ní: “Ó dà bíi pé òótọ́ lo sọ. Á dáa kó o wá. Àmọ́, o ò lè yí mi lọ́kàn padà láé!”
Caroline wáá fèsì pé: “Ìyáàfin G—, mi ò lè yí ọ lọ́kàn padà láé, ká tiẹ̀ ní mo fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ pàápàá. Jèhófà nìkan ló lè ṣèyẹn.”
Nǹkan lọ dáadáa nígbà tó mú ìwé pẹlẹbẹ náà lọ, Ìyáàfin G— (ìyẹn Betty) sì gbà pé kó tún padà bẹ òun wò. Nígbà tí Caroline padà wá, Betty sọ fún un pé òun ti sọ fáwọn obìnrin táwọn jọ máa ń jókòó sídìí tábìlì kan náà lákòókò oúnjẹ pé òun ti ń bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jíròrò. Ó ní, ńṣe ni wọ́n da ìbéèrè bo òun, tí wọ́n káwọ́ sókè pé: “Kí lo rò débẹ̀? Àwọn èèyàn tí ò tiẹ̀ gba Jésù gbọ́ wọ̀nyẹn!”
Ojú ẹsẹ̀ ni Caroline rán Betty létí kókó pàtàkì kan tí wọ́n jíròrò kẹ́yìn nípa Ìjọba Ọlọ́run.
Caroline wá béèrè pé: “Ta ló máa jẹ́ Ọba ibẹ̀?”
Betty fèsì pé: “Lóòótọ́, Jésù mà ni.”
Caroline ní: “Bó ṣe rí gan-an nìyẹn.” Ó wá ṣàlàyé pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jésù, ṣùgbọ́n a ò gbà pé ó bá Ọlọ́run dọ́gba gẹ́gẹ́ bí apá kan Mẹ́talọ́kan.—Máàkù 13:32; Lúùkù 22:42; Jòhánù 14:28.
Lẹ́yìn ìbẹ̀wò bíi mélòó kan, ó wá hàn kedere pé aláìlera ni Betty, bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú rẹ̀ máa ń dùn, ó sì lẹ́mìí nǹkan yóò dára. Ní ti tòótọ́, ó ní àrùn jẹjẹrẹ, ẹ̀rù ikú sì ń bà á. Ó sọ pé: “Ó dùn mí pé mi ò ti gbọ́ nǹkan wọ̀nyí láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, kí n sì ti ní irú ìgbàgbọ́ tó o ní.” Caroline tù ú nínú nípa fífi àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó sọ pé ikú jẹ́ oorun àsùnwọra, téèyàn ń sùn tá á sì jí nígbà àjíǹde, hàn án. (Jòhánù 11:11, 25) Èyí múnú Betty dùn gan-an ni, ó sì ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé báyìí. Ó kàn jẹ́ pé hẹ́gẹhẹ̀gẹ ara kò jẹ́ kó lè máa wá sípàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.
Caroline sọ pé: “Mo wá rí i kedere pé àwọn áńgẹ́lì ló ń darí iṣẹ́ yìí. ‘Nọ́ńbà ọ̀tọ̀,’ tí kì í ṣe ti Betty, ni mo fẹ́ pè, kẹ́ ẹ sì wá wò ó, ẹni ọdún mọ́kàndínláàádọ́rùn-ún [89] ni!”—Ìṣípayá 14:6.