Títẹ́wọ́gba Ìkésíni Látọ̀dọ̀ Jèhófà Ń Mú Èrè Wá
Ìtàn Ìgbésí Ayé
Títẹ́wọ́gba Ìkésíni Látọ̀dọ̀ Jèhófà Ń Mú Èrè Wá
GẸ́GẸ́ BÍ MARIA DO CÉU ZANARDI ṢE SỌ Ọ́
“Jèhófà mọ ohun tó ń ṣe. Tó bá fi ìwé ìkésíni ránṣẹ́ sí ọ, ńṣe ló yẹ kó o fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ tẹ́wọ́ gbà á.” Ọ̀rọ̀ tí baba mi sọ ní nǹkan bí ọdún márùndínláàádọ́ta sẹ́yìn yìí ràn mí lọ́wọ́ láti tẹ́wọ́ gba ìkésíni tí mo kọ́kọ́ rí gbà látọ̀dọ̀ ètò àjọ Jèhófà, pé kí n wá sìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Títí di òní olónìí, mo ṣì ń dúpẹ́ fún ìmọ̀ràn bàbá mi yẹn, nítorí pé títẹ́wọ́gba irú ìkésíni bẹ́ẹ̀ ti mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ èrè wá fún mi.
NÍ ỌDÚN 1928, Baba forúkọ sílẹ̀ fún ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́, ó sì nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì. Nítorí pé àárín gbùngbùn ilẹ̀ Potogí ló ń gbé, ohun kan ṣoṣo tí ó so òun àti ìjọ Ọlọ́run pọ̀ ni àwọn ìtẹ̀jáde tó ń rí gbà láti ilé iṣẹ́ ìfìwéránṣẹ́ àti Bíbélì kan tó jẹ́ ti àwọn òbí mi àgbà. Ní ọdún 1949, nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá, ìdílé wa kó lọ sí Brazil tó jẹ́ ìlú màmá mi, a si fìdí kalẹ̀ sí ẹ̀yìn odi ìlú Rio de Janeiro.
Àwọn aládùúgbò wa tuntun sọ pé ká bá àwọn lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, a sì tẹ̀ lé wọn lọ fúngbà bíi mélòó kan. Baba máa ń béèrè àwọn ìbéèrè nípa iná ọ̀run àpáàdì, ọkàn àti ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé ní ọjọ́ iwájú—àmọ́ wọn ò lè dáhùn àwọn ìbéèrè rẹ̀. Baba sábà máa ń sọ pé: “A ní láti dúró de àwọn tó jẹ́ ojúlówó akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”
Lọ́jọ́ kan, baba afọ́jú kan wá sílé wa, ó sì fún wa ní Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Baba mi béèrè àwọn ìbéèrè kan náà lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì fún un ní àwọn ìdáhùn tó bá Bíbélì mu. Ní ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, Ẹlẹ́rìí Jèhófà mìíràn tún wá sílé wa. Lẹ́yìn tó ti dáhùn ọ̀pọ̀ ìbéèrè, ó ní ká jọ̀ọ́ ká yọ̀ǹda òun pé òun fẹ́ lọ sí “pápá.” Nígbà tí Baba ṣe kàyéfì Mátíù 13:38 fún un pé: “Pápá náà ni ayé.” Baba wá béèrè pé: “Ṣé èmi náà lè lọ?” Ó fèsì pé: “Bẹ́ẹ̀ ni.” Inú wa dùn kọjá ààlà pé a tún rí òtítọ́ Bíbélì lẹ́ẹ̀kan sí i! Ìpàdé àgbègbè tó tẹ̀ lé e ni baba ti ṣe ìrìbọmi, kété lẹ́yìn ìyẹn ni èmi náà ṣe ìrìbọmi ní November 1955.
pé ìyẹn ni pé ẹ̀yìn Ẹlẹ́rìí náà máa ń ṣe eré ìdárayá, obìnrin náà kaTítẹ́wọ́gba Ìkésíni Tí Mo Kọ́kọ́ Rí Gbà
Ọdún kan àtààbọ̀ lẹ́yìn ìyẹn ni mo rí àpòòwé ńlá kan tó ní àwọ̀ ilẹ̀ gbà láti ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rio de Janeiro. Ìwé ìkésíni kan wà nínú rẹ̀ tí wọ́n fi sọ pé kí n wá wọnú iṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún. Màmá mi wà lórí àìsàn líle koko ní àkókò yẹn, mo wá sọ pé kí baba mi gbà mí nímọ̀ràn. Ìdáhùn rẹ̀ sojú abẹ níkòó, ó ní: “Jèhófà mọ ohun tó ń ṣe. Tó bá fi ìwé ìkésíni ránṣẹ́ sí ọ, ńṣe ló yẹ kó o fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ tẹ́wọ́ gbà á.” Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún mi níṣìírí gan-an ni, bí mo ṣe kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù tí wọ́n fi ránṣẹ́ náà nìyẹn, tí mo sì wọnú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ní July 1, 1957. Ibi tí wọ́n kọ́kọ́ yàn mí sí ni Três Rios, ìlú kan ní Ìpínlẹ̀ Rio de Janeiro.
Nígbà tá a kọ́kọ́ débẹ̀, àwọn ará Três Rios kò fẹ́ gbọ́ ìhìn tá a mú wá nítorí pé a ò lo Bíbélì tó jẹ́ ẹ̀dà ti Kátólíìkì. Ìrànlọ́wọ́ wá dé nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí bá Geraldo Ramalho, tó jẹ́ Kátólíìkì tí kò fọ̀rọ̀ ẹ̀sìn rẹ̀ ṣeré, ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, mo rí Bíbélì kan gbà tí àlùfáà àdúgbò náà fọwọ́ sí. Látìgbà yẹn, bí ẹnikẹ́ni bá ti fẹ́ ṣàtakò, màá fi ibi tí àlùfáà fọwọ́ sí hàn án, kò sì ní lè sọ ohunkóhun mọ́. Geraldo ṣe batisí lẹ́yìn náà.
Inú mi dùn gan-an nígbà tá a ṣe ìpàdé àyíká kan ní àárín gbùngbùn Três Rios ní 1959. Ọ̀gá ọlọ́pàá kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní àkókò yẹn tiẹ̀ ṣètò pé kí wọ́n polongo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà káàkiri ìlú. Lẹ́yìn tí mo ṣiṣẹ́ fún ọdún mẹ́ta ní Três Rios, wọ́n tún yan ibi iṣẹ́ tuntun fún mi ní Itu, tó wà ní nǹkan bí àádọ́fà kìlómítà ní ìwọ̀ oòrùn São Paulo.
Àwọn Ìwé Aláwọ̀ Pupa, Aláwọ̀ Búlúù, àti Aláwọ̀ Ìyeyè
Lẹ́yìn tá a wá ilé fúngbà díẹ̀, èmi àti aṣáájú ọ̀nà tó jẹ́ ẹnì kejì mi wá rí ibì kan tó dára láti gbé ní àárín ìlú, nílé opó onínúure kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Maria. Ńṣe ni Maria ń ṣe wá bí ẹni pé òun gan-an ló bí wa. Àmọ́, kò pẹ́ tí bíṣọ́ọ̀bù ìjọ Kátólíìkì fi wá sọ́dọ̀ rẹ̀ tó sì sọ pé kó lé wa jáde, àmọ́ kò gbà fún un. Ó sọ pé: “Nígbà tí ọkọ mi kú, ẹ ò ṣe nǹkan kan láti tù mí nínú. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wọ̀nyí ti ràn mí lọ́wọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ń kì í ṣe mẹ́ńbà ẹ̀sìn wọn.”
Láàárín àkókò yẹn ni obìnrin kan sọ fún wa pé àlùfáà Kátólíìkì tó wà ní Itu ti sọ fún àwọn ọmọ ìjọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ gba àwọn ẹ̀dà “ìwé pupa tó ń sọ̀rọ̀ Èṣù” yẹn mọ́. Wọ́n ń tọ́ka sí ìwé “Jeki Ọlọrun Jẹ Olõtọ,” ìyẹn ìtẹ̀jáde tá a gbé ka Bíbélì, èyí tá a ń pín fáwọn èèyàn láàárín ọ̀sẹ̀ yẹn. Níwọ̀n bí àlùfáà ti “fòfin de” ìwé aláwọ̀ pupa yìí, a wá múra bí a ó ṣe máa fi
ìwé aláwọ̀ búlúù lọni (ìyẹn ìwé “New Heavens and a New Earth”). Nígbà tó yá, tí àlùfáà tún gbọ́ nípa èyí, a tún bẹ̀rẹ̀ sí lo ìwé aláwọ̀ ìyeyè (ìyẹn ìwé What Has Religion Done for Mankind?), àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹ ò rí i pé ó dára gan-an tá a ní àwọn onírúurú ìwé tí àwọ̀ wọ́n yàtọ̀ síra lọ́wọ́!Lẹ́yìn nǹkan bí ọdún kan ní Itu, mo gba wáyà kan tí wọ́n fi pè mí pé kí n wá ṣiṣẹ́ fún ìgbà díẹ̀ ní Bẹ́tẹ́lì, tó jẹ́ ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Rio de Janeiro, ní ìmúrasílẹ̀ de àpéjọ àgbáyé. Tayọ̀tayọ̀ ni mo fi tẹ́wọ́ gbà á.
Àwọn Àǹfààní Mìíràn Àtàwọn Ìpèníjà Ibẹ̀
Iṣẹ́ pọ̀ láti ṣe ní Bẹ́tẹ́lì, inú mi sì dùn pé mo ṣèrànwọ́ ní gbogbo ọ̀nà tí mo lè gbà ṣé e. Ẹ wo bó ṣe fúnni lókun tó láti wà níbi ìjíròrò ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́ lárààárọ̀ àti ní ibi Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ láwọn ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Monday! Àwọn àdúrà àtọkànwá tí Otto Estelmann àtàwọn mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì mìíràn tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ máa ń gbà nípa tó lágbára lórí mi.
Nígbà tí àpéjọ àgbáyé náà parí, mo di ẹrù mi pé kí n padà sí Itu, àmọ́ ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi nígbà tí Grant Miller, tó jẹ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ka náà, fún mi ní lẹ́tà kan tí wọ́n fi sọ pé kí n di mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì. Ẹni tá a jọ wà ní yàrá kan náà ni Arábìnrin Hosa Yazedjian, ó ṣì ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì ti Brazil di bá a ti ń sọ̀rọ̀ yìí. Láyé ọjọ́un, ìdílé Bẹ́tẹ́lì náà kéré gan-an ni—méjìdínlọ́gbọ̀n péré ni wá—ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ sì ni gbogbo wa.
Ní 1964, João Zanardi, ọ̀dọ́kùnrin kan tó jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, wá gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní Bẹ́tẹ́lì. Lẹ́yìn náà ni wọ́n wá yàn án gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ àyíká, tàbí alábòójútó arìnrìn-àjò sí àyíká kan tó wà nítòsí. A sábà máa ń pàdé nígbà tó bá mú ìròyìn rẹ̀ wá sí Bẹ́tẹ́lì. Ìránṣẹ́ ẹ̀ka fún João láyè láti máa wá fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé láwọn ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Monday, bá a ṣe ń ráyè lo àkókò pa pọ̀ nìyẹn. Èmi àti João ṣègbéyàwó ní August 1965. Tayọ̀tayọ̀ ni mo sì fi gbà láti dara pọ̀ mọ́ ọkọ mi nínú iṣẹ́ àyíká tó ń ṣe.
Láyé ọjọ́un, bí ẹni ń forí la ewu ni iṣẹ́ àyíká rí láwọn eréko Brazil. Mi ò lè gbàgbé ìbẹ̀wò wa sí àwùjọ àwọn akéde kan tó wà ní Aranha, ní Ìpínlẹ̀ Minas Gerais. A ní láti kọ́kọ́ wọkọ̀ ojú irin, lẹ́yìn náà la wá fẹsẹ̀ rin ibi tó kù—a sì ru àwọn àpótí, ẹ̀rọ ìtẹ̀wé, ẹ̀rọ projector tí ń gbáwòrán yọ, àpò òde ẹ̀rí, àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lérí. Ẹ sì wá wo bínú wa ṣe dùn tó nígbà tá a rí Lourival Chantal, arákùnrin àgbàlagbà kan, tó sábà máa ń dúró dè wá ní ibùdó ọkọ̀ ojú irin náà, láti bá wa gbé lára ẹrù wa.
Inú ilé kan tí wọ́n háyà la ti ń ṣèpàdé ní Aranba. Yàrá kékeré kan tó wà lẹ́yìn rẹ̀ la sì ń sùn. Ẹrù igi ìdáná kan wá lẹ́gbẹ̀ẹ́ yàrá ọ̀hún, òun la fi ń dáná oúnjẹ, tá a sì fi ń gbé omi táwọn ará ń fi korobá pọn fún wá kaná. Ihò kan tí wọ́n gbẹ́ sí ilẹ̀ tó wà láàárín oko ọparun kan nítòsí ni ilé ìyàgbẹ́. A máa ń tan àtùpà ńlá kan sílẹ̀ ní alaalẹ́, kó lè bá wa lé irú àwọn ọ̀bọ̀n-ùnbọn-ùn kan lọ—ìyẹn àwọn kòkòrò tó lè fa àrùn Chagas. Nígbà tó bá di àárọ̀, èéfín á ti sọ ihò imú wa di dúdú. Ìrírí tó ga ni ẹ jọ̀ọ́!
Nígbà tá a ń sìn ní àyíká kan tó wà ní Ìpínlẹ̀ Paraná, a tún rí ọ̀kan lára àwọn àpòòwé ńlá Lúùkù 14:28 yẹ̀ wò, ká sì rò ó dáadáa, ká tó tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ yìí nítorí pé wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ Kristẹni wa níbẹ̀, ìjọba ilẹ̀ Potogí sì ti mú ọ̀pọ̀ lára àwọn arákùnrin wa.
aláwọ̀ ilẹ̀ yẹn gbà láti ẹ̀ka iléeṣẹ́. Ìkésíni mìíràn tún nìyẹn látọ̀dọ̀ ètò àjọ Jèhófà—lọ́tẹ̀ yìí, wọ́n ní ká lọ sìn ní ilẹ̀ Potogí! Lẹ́tà náà sọ pé ká kọ́kọ́ gbé ohun tó wà nínúṢé ká wá lọ síbi tá a ti máa lọ kojú irú àtakò yẹn ni? João sọ pé: “Bí àwọn arákùnrin wa tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Potogí bá lè fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà níbẹ̀, èé ṣe táwa náà kò fi ní ṣe bẹ́ẹ̀?” Èmi náà rántí ọ̀rọ̀ ìyànjú tí baba mi fún mi, mo sì gbà pé: “Bí Jèhófà bá fi ìwé ìkésíni ránṣẹ́ sí wa, ńṣe ló yẹ ká tẹ́wọ́ gbà á, ká sí gbẹ́kẹ̀ lé e.” Láìpẹ́, lẹ́yìn náà la dé Bẹ́tẹ́lì ní São Paulo, tá a ń gba ìtọ́ni, tá a sì ń ṣètò àwọn ìwé ìrìnnà wa.
João Maria àti Maria João
September 6, 1969 ni ọkọ̀ wa tá a ń pè ní Eugênio C, gbéra láti èbúté Santos, ní Ìpínlẹ̀ São Paulo. Lẹ́yìn tá a lo ọjọ́ mẹ́sàn-án lójú òkun, a gúnlẹ̀ sí ilẹ̀ Potogí. Lákọ̀ọ́kọ́, a ń fi oṣù bíi mélòó kan bá àwọn arákùnrin tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ṣiṣẹ́ ní àwọn pópó tóóró ti Alfama àti Mouraria ní àgbègbè Lisbon tó ti wà tipẹ́. Wọ́n kọ́ wa pé ká máa ṣọ́ra kí àwọn ọlọ́pàá má bàa tètè mú wa.
Ilé àwọn Ẹlẹ́rìí la ti ń ṣe àwọn ìpàdé ìjọ. Tá a bá rí i pé àwọn aládùúgbò ti ń fura, kíá la máa kó ìpàdé náà lọ síbòmíràn kí ó má di pé àwọn ọlọ́pàá á wá tú ilé ọ̀hún tàbí kí wọ́n mú àwọn ará. Ìjáde fàájì, bá a ṣe máa ń pe àwọn àpéjọ wa, la máa ń ṣe ní Ọgbà Ìtura Monsanto, tó wà ní ẹ̀yìn ìlú Lisbon, àti ní Costa da Caparica, ìyẹn àgbègbè kan tí igi pọ̀ sí ní etíkun náà. Ńṣe la kàn máa ń múra bákan ṣáá lọ síbi àpéjọ náà, àwọn olùtọ́jú èrò sì wà ní àwọn ibi pàtàkì níbi tí wọ́n ti ń ṣọ́nà lójú méjèèjì. Bá a bá rí ẹnì kan tá a fura sí, kíá la máa bẹ̀rẹ̀ eré àṣedárayá kan, tá a ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣeré, tàbí ká máa kọ orin ìbílẹ̀ kan.
Kí ó má bàa rọrùn fún àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ láti dá wa mọ̀, a máa ń yẹra fún lílo orúkọ wa gan-an. Ohun táwọn arákùnrin mọ̀ wá sí ni João Maria àti Maria João. Wọn ò lè rí orúkọ wa lára lẹ́tà èyíkéyìí tàbí nínú àkọsílẹ̀
kankan. Dípò ìyẹn, a fún ara wa ní nọ́ńbà. Mo dìídì yẹra fún híhá àdírẹ́sì àwọn ará sórí. Nípa bẹ́ẹ̀, bí wọ́n tilẹ̀ mú mi, kò ní ṣeé ṣe fún mi láti dà wọ́n.Láìfi gbogbo ìkálọ́wọ́kò yẹn pè, èmi àti João pinnu láti lo gbogbo àǹfààní tá a bá rí láti jẹ́rìí, níwọ̀n ìgbà tá a mọ̀ pé a lè pàdánù òmìnira wa nígbàkigbà. A kọ́ láti máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, Baba wa ọ̀run. Gẹ́gẹ́ bí Aláàbò wa, ó lo àwọn áńgẹ́lì lọ́nà tá a fi wá mọ̀ pé a “ń rí Ẹni tí a kò lè rí.”—Hébérù 11:27.
Ní àkókò kan, tá a wà lẹ́nu iṣẹ́ àtilé-dé-ilé ní Porto, a rí ọkùnrin kan tó rọ̀ wá pé ká wọ ilé òun. Kíá ni arábìnrin tá a jọ ń ṣiṣẹ́ wọlé láìjanpata, kò sí ohun tí mo lè ṣe ju kí n tẹ̀ lé e. Ẹ̀rù bà mí nígbà tí mo rí fọ́tò ẹnì kan tó wọ aṣọ ológun ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ ilé náà. Kí ni ká wá ṣe báyìí? Onílé ní ká jókòó, ó sì bi mí pé: “Ṣé o lè jẹ́ kí ọmọ rẹ̀ wọ iṣẹ́ ológun bí wọ́n bá pè é?” Ìbéèrè tó gbẹgẹ́ ni. Àmọ́, lẹ́yìn àdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́, mo rọra dá a lóhun pé: “Mi ò lọ́mọ kankan, mo sì mọ̀ pé bí mo bá bi ọ́ ní irú ìbéèrè àbámodá bẹ́ẹ̀, bákan náà lo ṣe máa dá mi lóhùn.” Kò sọ̀rọ̀. Mo wá ń bá ọ̀rọ̀ mi lọ pé: “Wàyí o, ká ní o bi mí pé báwo ló ṣe máa ń rí lára ẹni nígbà tí ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò tàbí baba èèyàn bá kú, ìyẹn ni ǹ bá lè dáhùn dáadáa, nítorí pé àbúrò mi ọkùnrin àti baba mi ti kú.” Omijé lé ròrò sójú mi bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀, mo sì kíyè sí i pé òun náà fẹ́rẹ̀ẹ́ máa bá mi sunkún. Ó ṣàlàyé pé ìyàwó òun náà kú lẹ́nu àìpẹ́ yẹn. Ó tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́ nígbà tí mo ń ṣàlàyé ìrètí àjíǹde. Lẹ́yìn náà, a rọra fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ kí ara wa pé ó dìgbòóṣe, a sì fi ibẹ̀ sílẹ̀ lálàáfíà, a fi ọ̀ràn náà lé Jèhófà lọ́wọ́.
Láìfi ìfòfindè náà pè, a ran àwọn olóòótọ́ èèyàn lọ́wọ́ láti jèrè ìmọ̀ òtítọ́. Porto ni ọkọ mi ti bẹ̀rẹ̀ sí bá Horácio tó jẹ́ oníṣòwò ṣèkẹ́kọ̀ọ́, ó sì tẹ̀ síwájú gan-an. Lẹ́yìn náà, Emílio, ọmọ rẹ̀, tó jẹ́ dókítà tó mọṣẹ́ dunjú, tún pinnu pé òun máa sin Jèhófà, ó sì ṣe batisí. Dájúdájú, kò sí ohun tó lè dá ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà dúró.
“Ẹ Kò Lè Mọ Ohun Tí Jèhófà Máa Fàyè Gbà”
Ní 1973, wọ́n pe èmi àti João sí Ìpàdé Àgbáyé “Ìṣẹ́gun Àtọ̀runwá” ní Brussels, Belgium. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Sípéènì àti Belgium ló wà níbẹ̀, títí kan àwọn tí wọ́n wá sí àpéjọpọ̀ náà láti Mòsáńbíìkì, Àǹgólà, Cape Verde, Madeira, àti Azore. Nínú ọ̀rọ̀ tí Arákùnrin Knorr, tó wá láti orílé iṣẹ́ ní New York sọ kẹ́yìn, ó gbà wá níyànjú pé: “Ẹ máa fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà nìṣó. Ẹ kò lè mọ ohun tí Jèhófà máa fàyè gbà. Ta ló lè sọ, bóyá ilẹ̀ Potogí lẹ ti máa ṣe àpéjọpọ̀ àgbáyé tó máa tẹ̀ lé èyí!”
Ní ọdún tó tẹ̀ lé e, iṣẹ́ ìwàásù náà di èyí tí wọ́n fàyè gbà lábẹ́ òfin nílẹ̀ Potogí. Bí Arákùnrin Knorr ṣe sọ ọ́ gẹ́ẹ́ ló sì rí, ní 1978, a ṣe àpéjọpọ̀ àgbáyé wa àkọ́kọ́ ní Lisbon. Ẹ wo irú
àǹfààní ńlá tó jẹ́ láti rìn yí ká gbogbo àwọn àdúgbò tó wà ní Lisbon, tá a ń fi páálí tá a gbé kọ́ àyà, àwọn ìwé ìròyìn, àtàwọn ìwé ìkésíni síbi àsọyé fún gbogbo ènìyàn jẹ́rìí! Àlá tó wá ṣẹ ni.A ti wá nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin wa tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Potogí gan-an, àwọn tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nínú wọn ló ti fẹ̀wọ̀n jura, tí wọ́n sì ti lù bí ẹni máa kú nítorí àìdásí-tọ̀túntòsì Kristẹni wọn. Ìfẹ́ ọkàn wa ni pé ká máa bá iṣẹ́ ìsìn wa lọ nílẹ̀ Potogí. Àmọ́ ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀. Ní 1982, àrùn ọkàn bẹ̀rẹ̀ sí ṣe João, àìsàn náà sì le débi pé ẹ̀ka iléeṣẹ́ wá dámọ̀ràn pé ká padà sí Brazil.
Àkókò Líle Koko
Àwọn arákùnrin tó wà ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ ní Brazil ràn wá lọ́wọ́ gan-an ni, wọ́n sì yàn wá láti lọ sìn ní Ìjọ Quiririm tó wà nílùú Taubaté, ní Ìpínlẹ̀ São Paulo. Àìsàn João wá le gan-an, kò sì pẹ́ tí kò fi lè jáde nílé mọ́. Àwọn olùfìfẹ́hàn máa ń wá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nílé wa, àwọn ará sì máa ń pàdé níbẹ̀ fún òde ẹ̀rí lójoojúmọ́, a tún ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ níbẹ̀ pẹ̀lú. Àwọn ìpèsè wọ̀nyí ràn wá lọ́wọ́ láti mú ìdúró wa nípa tẹ̀mí.
João ń bá a lọ láti ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà títí di ọjọ́ ikú rẹ̀ ní October 1, 1985. Inú mi bà jẹ́ gan-an, mo sì sorí kọ́, àmọ́ mo pinnu láti máa bá iṣẹ́ mi lọ. Ìṣòro mìíràn tún dé ní April 1986, nígbà táwọn olè fọ́ ilé mi tí wọ́n sì fẹ́rẹ̀ẹ́ kó gbogbo ohun tí mo ní lọ tán. Fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé mi, ó ṣe mí bíi pé mi ò ní aláfẹ̀yìntì, ẹ̀rù sì wá ń bà mí. Àwọn tọkọtaya kan fìfẹ́ ké sí mi láti wá gbé lọ́dọ̀ wọn fúngbà díẹ̀, mo sì dúpẹ́ púpọ̀ fún èyí.
Ikú João àti olè tó jà mí tún nípa lórí iṣẹ́ ìsìn mi sí Jèhófà. Ọkàn mi ò balẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà mọ́. Lẹ́yìn tí mo kọ̀wé sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ nípa ìṣòro tí mo ní, wọ́n ní kí n wá lo àkókò díẹ̀ ní Bẹ́tẹ́lì kí ọkàn mi lè balẹ̀. Àkókò yẹn mà fún mi lókun o!
Bí mo ṣe rí i pé ara mi ti bọ̀ sípò díẹ̀, mo gbà láti sìn ní Ipuã, ìlú kan ní Ìpínlẹ̀ São Paulo. Iṣẹ́ ìwàásù náà jẹ́ kí ọwọ́ mi dí, àmọ́ àwọn àkókò kan wà tí ìrẹ̀wẹ̀sì máa ń dé bá mi. Ní irú àkókò bẹ́ẹ̀, mo máa ń tẹ àwọn ará ní Quiririm láago, ìdílé kan a sì wá bá mi ṣeré fún ọjọ́ bíi mélòó kan. Àwọn ìbẹ̀wò wọ̀nyẹn mà fún mi níṣìírí o! Láàárín ọdún àkọ́kọ́ tí mo lò ní Ipuã, àwọn arákùnrin àti arábìnrin méjìdínlógójì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló rin ìrìn àjò gígùn yẹn láti wá kí mi.
Ní 1992, ìyẹn ọdún mẹ́fà lẹ́yìn ikú João, mo tún rí ìkésíni mìíràn gbà látọ̀dọ̀ ètò-àjọ Jèhófà. Lọ́tẹ̀ yìí, wọ́n ní kí n lọ sí Franca, ní Ìpínlẹ̀ São Paulo, níbi tí mo ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún di òní olónìí. Ìpínlẹ̀ yìí méso jáde gan-an ni. Ní 1994, mo bẹ̀rẹ̀ sí bá olórí ìlú ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lákòókò yẹn, ó ń bá ìpolongo ìbò kiri nítorí ipò kan tó ń dù ní Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ilẹ̀ Brazil, àmọ́ bí ọwọ́ rẹ̀ ṣe dí tó yẹn, gbogbo ọ̀sán Monday la máa ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́. Kí ó má bàa sí ìyọlẹ́nu kankan, á pa tẹlifóònù rẹ̀. Inú mi dùn gan-an nígbà tí mo rí i tó ń jáwọ́ nínú ìṣèlú díẹ̀díẹ̀, tí òtítọ́ sì ràn án lọ́wọ́ láti fẹsẹ̀ ìgbéyàwó rẹ̀ múlẹ̀! Òun àti aya rẹ̀ jọ ṣe batisí ní 1998.
Bí mo bá bojú wẹ̀yìn, mo lè rí i pé ìgbésí ayé mi gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún jẹ́ èyí tó kún fún àwọn ìbùkún àti àǹfààní ńláǹlà. Títẹ́wọ́gba ìkésíni tí Jèhófà nawọ́ rẹ̀ sí mi nípasẹ̀ ètò àjọ rẹ̀ ti mú èrè ńlá wá fún mi ní tòótọ́. Ìkésíni èyíkéyìí tó bá sì ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú, mo ṣe tán láti tẹ́wọ́ gbà á bíi ti àtẹ̀yìnwá.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ní ọdún 1957, nígbà tí mo wọnú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, àti lónìí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Èmi àti ìdílé Bẹ́tẹ́lì ti Brazil ní 1963
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Ìgbéyàwó wa ní August 1965
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Àpéjọ kan ní ilẹ̀ Potogí ní àkókò tí wọ́n fòfin de iṣẹ́ wa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Ìjẹ́rìí òpópónà ní Lisbon lákòókò Àpéjọpọ̀ Àgbáyé “Ìgbàgbọ́ Aṣẹ́gun” ti 1978