‘Ẹ Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Mi’
‘Ẹ Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Mi’
“Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín.”—MÁTÍÙ 11:29.
1. Èé ṣe tí kíkẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Jésù fi lè máyọ̀ wá, kí ó sì mú kí ayé wa dùn bí oyin?
JÉSÙ KRISTI máa ń ronú, ó máa ń kọ́ni, ó sì máa ń gbégbèésẹ̀ tó tọ́ nígbà gbogbo. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọdún díẹ̀ ló lò láyé, síbẹ̀ ó gbélé ayé ṣe ohun rere, tó fún un ní ìtẹ́lọ́rùn, tó sì mú ayọ̀ rẹ̀ kún. Ó kó àwọn ọmọ ẹ̀yìn jọ, ó kọ́ wọn nípa bí wọ́n ṣe lè sin Ọlọ́run, bí wọ́n ṣe lè nífẹ̀ẹ́ aráyé àti bí wọ́n ṣe lè ṣẹ́gun ayé. (Jòhánù 16:33) Ó fi ìrètí kún ọkàn wọn, ó sì “tan ìmọ́lẹ̀ sórí ìyè àti àìdíbàjẹ́ nípasẹ̀ ìhìn rere.” (2 Tímótì 1:10) Tó o bá wà lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, kí lo rò pé ó túmọ̀ sí láti jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn? Ẹ jẹ́ ká gbé ohun tí Jésù sọ nípa ọmọ ẹ̀yìn yẹ̀ wò, ìyẹn á mú kí ayé wa dùn bí oyin. Èyí wé mọ́ níní èrò kan náà tí òun ní àti títẹ̀lé àwọn ìlànà pàtàkì kan.—Mátíù 10:24, 25; Lúùkù 14:26, 27; Jòhánù 8:31, 32; 13:35; 15:8.
2, 3. (a) Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù? (b) Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì láti bi ara wa pé, ‘Ọmọ ẹ̀yìn ta lèmi jẹ́?’
2 Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ohun tí ọ̀rọ̀ tá a tú sí “ọmọ ẹ̀yìn” túmọ̀ sí gan-an ni ẹni tí ń fọkàn sí nǹkan kan, tàbí akẹ́kọ̀ọ́. Ọ̀rọ̀ kan tó fara pẹ́ ẹ wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a gbé àpilẹ̀kọ yìí kà, èyíinì ni Mátíù 11:29, tó kà pé: “Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín.” Bẹ́ẹ̀ ni o, èyí fi hàn pé ẹni tí ń kẹ́kọ̀ọ́ ni ọmọ ẹ̀yìn jẹ́. Àwọn ìwé Ìhìn Rere sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “ọmọ ẹ̀yìn” fún àwọn tó ń tọ Jésù lẹ́yìn tímọ́tímọ́, tí wọ́n ń bá a rìnrìn àjò bó ṣe ń wàásù kiri, tí wọ́n sì ń gba ìtọ́ni látọ̀dọ̀ rẹ̀. Àwọn kan lè wulẹ̀ fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ Jésù, bóyá ní bòókẹ́lẹ́ pàápàá. (Lúùkù 6:17; Jòhánù 19:38) Àwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere tún sọ̀rọ̀ nípa “àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù [Oníbatisí] àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn àwọn Farisí.” (Máàkù 2:18) Níwọ̀n bí Jésù ti kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé “kí wọ́n ṣọ́ra . . . fún ẹ̀kọ́ àwọn Farisí,” a lè béèrè lọ́wọ́ ara wa pé, ‘Ọmọ ẹ̀yìn ta lèmi jẹ́?’—Mátíù 16:12.
3 Bó bá jẹ́ pé ọmọ ẹ̀yìn Jésù ni wá, bó bá jẹ́ pé a ti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀, ó yẹ kí ara máa tu àwọn èèyàn nípa tẹ̀mí nígbà tí wọ́n bá wà ní sàkáání wa. Ó yẹ kí wọ́n rí wa bí ẹni tó ti túbọ̀ jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ àti onírẹ̀lẹ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Bá a bá jẹ́ ọ̀gá níbi iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa, bá a bá jẹ́ òbí, tàbí bá a bá jẹ́ ẹni tó ní ẹrù iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn nínú ìjọ Kristẹni, ǹjẹ́ àwọn tó wà lábẹ́ àbójútó wa lè gba ẹ̀rí wa jẹ́, pé à ń tọ́jú àwọn gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe ń tọ́jú àwọn tó wà lábẹ́ àbójútó rẹ̀?
Ọwọ́ Tí Jésù Fi Mú Àwọn Èèyàn
4, 5. (a) Kí nìdí tí kò fi ṣòro láti mọ irú ọwọ́ tí Jésù fi mú àwọn èèyàn tó wà nínú ìṣòro? (b) Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù lọ jẹun nínú ilé Farisí kan?
4 Ó yẹ ká mọ ọwọ́ tí Jésù fi mú àwọn èèyàn, àgàgà àwọn tó wà nínú ìṣòro líle koko. Ìyẹn ò ṣòroó mọ̀; torí pé ìtàn pọ̀ nínú Bíbélì tó dá lórí àjọṣe àárín Jésù àtàwọn ẹlòmíì. Àwọn kan lára wọn sì jẹ́ àwọn tí ìpọ́njú dé bá. Ẹ tún jẹ́ ká kíyè sí ọwọ́ tí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn, àgàgà àwọn Farisí, fi mú àwọn èèyàn tó ní irú ìṣòro kan náà. A óò rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú kíkíyèsí ìyàtọ̀ tó wà láàárín wọn.
5 Lọ́dún 31 Sànmánì Tiwa, nígbà tí Jésù wà lẹ́nu iṣẹ́ wíwàásù ní Gálílì, “ẹnì kan nínú àwọn Farisí ń rọ [Jésù] ṣáá láti bá òun jẹun.” Jésù kò kọ ìkésíni náà. “Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, ó wọ ilé Farisí náà, ó sì rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì. Sì wò ó! obìnrin kan tí a mọ̀ sí ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ìlú ńlá náà gbọ́ pé ó ń rọ̀gbọ̀kú nídìí oúnjẹ nínú ilé Farisí náà, ó sì mú orùba alabásítà òróró onílọ́fínńdà wá, àti, ní bíbọ́ sí ipò kan lẹ́yìn lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sunkún, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi omijé rẹ̀ rin ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ̀ nù ún kúrò. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó fi ẹnu ko ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́, ó sì fi òróró onílọ́fínńdà náà pa á.”—Lúùkù 7:36-38.
6. Báwo ni obìnrin kan tó jẹ́ “ẹlẹ́ṣẹ̀” ṣe ráyè wọlé Farisí náà?
6 Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn? Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé: “Obìnrin náà (ẹsẹ 37) lo àǹfààní àṣà ìbílẹ̀ wọn tó fàyè gba àwọn aláìní láti wá síbi irú àsè bẹ́ẹ̀ láti wá gba àjẹkù oúnjẹ.” Bóyá ìdí nìyẹn tẹ́nì kan fi lè ráyè wọlé láìjẹ́ pé a pè é. Àwọn míì tún lè wà tí wọ́n á fẹ́ wá re àjẹkù jọ lẹ́yìn àsè. Àmọ́, ọ̀tọ̀ ni ohun tí obìnrin yìí bá wá. Kò ṣe bí àwọn mo-gbọ́-mo-yà, tó ń retí kí àsè parí. Kò lórúkọ rere ládùúgbò. “Ẹlẹ́ṣẹ̀” paraku ni, tó bẹ́ẹ̀ tí Jésù fi sọ pé òun mọ̀ pé ‘àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ pọ̀.’—Lúùkù 7:47.
7, 8. (a) Kí ni ó ṣeé ṣe ka sọ, bá a bá rí ara wa nínú irú ipò tí ìwé Lúùkù 7:36-38 ròyìn? (b) Kí ni Símónì sọ?
7 Ká sọ pé o wà láyé nígbà yẹn lọ́hùn-ún, tó o sì wà nípò tí Jésù wà. Kí lò bá ṣe? Ṣé ojú ò ní tì ọ́ bí obìnrin yìí ti ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ? Kí ni wíwà nínú irú ipò bẹ́ẹ̀ ì bá sún ọ ṣe? (Lúùkù 7:45) Ǹjẹ́ orí rẹ ò ní fẹ́rẹ̀ẹ́ fò lọ, àní ǹjẹ́ àyà rẹ ò ní já?
8 Ká ní ọ̀kan lára àwọn àlejò ni ọ́, ó kéré tán ǹjẹ́ èrò rẹ máa fara pẹ́ ti Símónì tí í ṣe Farisí? “Ní rírí èyí, Farisí tí ó ké sí [Jésù] sọ nínú ara rẹ̀ pé: ‘Ọkùnrin yìí, bí ó bá jẹ́ wòlíì ni, ì bá mọ ẹni àti irú obìnrin tí ẹni tí ń fọwọ́ kan òun jẹ́, pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.’” (Lúùkù 7:39) Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí èyí, ojú àánú Jésù pọ̀. Ó rí ipò ìbànújẹ́ tí obìnrin náà wà. Ó rí i pé làásìgbò ti bá a. A ò mọ bí obìnrin náà ṣe di ẹrú ẹ̀ṣẹ̀. Bó bá jẹ́ pé aṣẹ́wó lobìnrin náà lóòótọ́, á jẹ́ pé àwọn Júù olùfọkànsìn, tí wọ́n jẹ́ aráàlú yẹn kò ràn án lọ́wọ́.
9. Kí ni Jésù sọ, kí ni ó sì ṣeé ṣe kí ó jẹ́ àbájáde rẹ̀?
9 Ṣùgbọ́n Jésù fẹ́ ràn án lọ́wọ́. Ó sọ fún obìnrin náà pé: “A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì.” Ó wá fi kún un pé: “Ìgbàgbọ́ rẹ ti gbà ọ́ là; máa bá ọ̀nà rẹ lọ ní àlàáfíà.” (Lúùkù 7:48-50) Ibi tí ìtàn yẹn parí sí nìyẹn. Ẹnì kan lè sọ pé òun ò rò pé Jésù ran obìnrin náà lọ́wọ́ lọ títí. Ó kéré tán, ó súre fún un. Ṣé o rò pé ó tún padà sídìí ìranù tó ń ṣe tẹ́lẹ̀? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò mọ̀ dájú, ṣàkíyèsí ohun tí Lúùkù sọ tẹ̀ lé e. Ó ṣàlàyé pé Jésù “ń rin ìrìn àjò lọ láti ìlú ńlá dé ìlú ńlá àti láti abúlé dé abúlé, ó ń wàásù, ó sì ń polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run.” Lúùkù tún ròyìn pé “àwọn obìnrin kan” wà pẹ̀lú Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, tí wọ́n “ń ṣèránṣẹ́ fún wọn láti inú àwọn nǹkan ìní” àwọn obìnrin náà. Ó ṣeé ṣe kí obìnrin tó ti ronú pìwà dà, tó sì moore yìí wà lára wọn, kó ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbé ayé tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, pẹ̀lú ète gúnmọ́ nínú ìgbésí ayé àti pẹ̀lú ìfẹ́ jíjinlẹ̀ fún Ọlọ́run.—Lúùkù 8:1-3.
Ìyàtọ̀ Tó Wà Láàárín Jésù Àtàwọn Farisí
10. Èé ṣe tó fi dáa pé ká gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín Jésù àti obìnrin kan nílé Símónì yẹ̀ wò?
10 Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú ìtàn tó fakíki yìí? Ó wọ̀ wá lọ́kàn ṣinṣin, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ká sọ pé o wà nílé Símónì lọ́jọ́ tá a ń wí yìí. Kí lò bá ṣe? Ṣé ohun tí Jésù ṣe lò bá ṣe, tàbí wàá ṣe bíi Farisí tó gba àlejò? A mọ̀ pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jésù, nítorí náà ọwọ́ tí a máa fi mú ọ̀ràn náà àti ìgbésẹ̀ tá a máa gbé lè máà bá tirẹ̀ mu gẹ́lẹ́. Àmọ́, a lè fọwọ́ sọ̀yà pé àwa ò ní ṣe bíi Símónì, Farisí. Ṣàṣà lẹni tó máa fẹ́ ká pe òun ní Farisí.
11. Èé ṣe tí a kò fi ní fẹ́ kí wọ́n kà wá mọ́ àwọn Farisí?
11 Látinú ohun tí Bíbélì àtàwọn ìwé ayé sọ, ó dájú pé àwọn Farisí jọ ara wọn lójú bí nǹkan míì. Kódà wọ́n sọ pé àwọn ni ẹgbẹ́ má-jẹ̀ẹ́-ó-bà-jẹ́ tó ń bójú tó ire àwọn aráàlú àti ti orílẹ̀-èdè náà. Bí Òfin Ọlọ́run ṣe ṣe kedere, tó sì yéni yékéyéké yẹn kò tẹ́ wọn lọ́rùn rárá. Nígbà tí Òfin náà kò bá sojú abẹ níkòó tó lójú tiwọn, kíá ni wọ́n á lọ gbé òfin awúrúju kan kalẹ̀, láti fi dí ohun tí wọ́n pè ní àlàfo, kí ẹ̀rí ọkàn àwọn èèyàn má bàa wúlò mọ́ rárá. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn wọ̀nyí bá a débi pé wọ́n fẹ́ ṣòfin lórí gbogbo ìgbòkègbodò ẹ̀dá, àní lórí àwọn ohun tí kò tó nǹkan pàápàá. a
12. Irú ojú wo làwọn Farisí fi ń wo ara wọn?
12 Òpìtàn ọ̀rúndún kìíní nì, Josephus, tí í ṣe Júù, sọ pé àwọn Farisí máa ń fi yé àwọn èèyàn pé àwọn jẹ́ onínúure, oníwà pẹ̀lẹ́, aláìṣègbè àti pé àwọn dáńgájíá fún iṣẹ́ tí àwọn ń ṣe. Lóòótọ́, àwọn kan nínú wọn lè rí báyẹn títí dé àyè kan. Bóyá ọkàn rẹ lọ sọ́dọ̀ Nikodémù. (Jòhánù 3:1, 2; 7:50, 51) Bí àkókò ti ń lọ, àwọn díẹ̀ lára wọn di Kristẹni. (Ìṣe 15:5) Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa àwọn Júù kan, irú bí àwọn Farisí, pé: “Wọ́n ní ìtara fún Ọlọ́run; ṣùgbọ́n kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye.” (Róòmù 10:2) Àmọ́ ṣá o, bí wọ́n ṣe rí lójú àwọn mùtúmùwà ni àwọn ìwé Ìhìn Rere sọ—wọ́n jẹ́ agbéraga, ajọra-ẹni-lójú, olódodo lójú ara ẹni, alárìíwísí, aláìgbatẹnirò àti pẹ̀gànpẹ̀gàn.
Ojú Tí Jésù Fi Ń Wò Wọ́n
13. Kí ni Jésù sọ nípa àwọn Farisí?
13 Jésù na àwọn akọ̀wé àtàwọn Farisí ní patiyẹ ọ̀rọ̀. Ó ní alágàbàgebè ni wọ́n. Ó sọ pé: “Wọ́n di àwọn ẹrù wíwúwo, wọ́n sì gbé wọn lé èjìká àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn tìkára wọn kò fẹ́ láti fi ìka wọn sún wọn kẹ́rẹ́.” Lóòótọ́ ni ẹrù ọ̀hún wúwo, àjàgà kànńpá sì ni wọ́n gbé kọ́ àwọn èèyàn lọ́rùn. Jésù tún pe àwọn akọ̀wé àtàwọn Farisí ní “òmùgọ̀.” A sì mọ̀ pé òmùgọ̀ lè kó àwọn ará àdúgbò sí yọ́ọ́yọ́ọ́. Jésù tún pe àwọn akọ̀wé àtàwọn Farisí ní “afọ́jú afinimọ̀nà,” ó sì là á mọ́lẹ̀ pé wọ́n “ṣàìka àwọn ọ̀ràn wíwúwo jù lọ nínú Òfin sí, èyíinì ni, ìdájọ́ òdodo àti àánú àti ìṣòtítọ́.” Ta ló máa fẹ́ kí Jésù ka òun sí Farisí?—Mátíù 23:1-4, 16, 17, 23.
14, 15. (a) Àjọṣe tí Jésù ní pẹ̀lú Mátíù Léfì fi kí ni hàn nípa irú èèyàn táwọn Farisí jẹ́? (b) Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la lè rí kọ́ nínú ìtàn yìí?
14 Ṣàṣà lẹni tó ń ka àwọn ìtàn inú ìwé Ìhìn Rere tí kò ní rí i pé alárìíwísí gbáà lèyí tó pọ̀ jù lára àwọn Farisí. Lẹ́yìn tí Jésù ké sí Mátíù Léfì, tí í ṣe agbowó orí, pé kí ó wá di ọmọ ẹ̀yìn òun, Léfì filé pọntí, ó fọ̀nà rokà, nítorí Jésù. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Látàrí èyí, àwọn Farisí àti àwọn akọ̀wé òfin wọn bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, pé: ‘Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé ẹ ń jẹ, ẹ sì ń mu pẹ̀lú àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀?’ Ní ìfèsìpadà, Jésù wí fún wọn pé: ‘. . . Èmi kò wá láti pe àwọn olódodo bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sí ìrònúpìwàdà.’”—Lúùkù 5:27-32.
15 Léfì alára mọrírì ọ̀rọ̀ kan tí Jésù sọ níbẹ̀ yẹn, pé: “Ẹ lọ, nígbà náà, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí èyí túmọ̀ sí, ‘Àánú ni èmi fẹ́, kì í sì í ṣe ẹbọ.’” (Mátíù 9:13) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Farisí sọ pé àwọn gba ìwé àwọn wòlíì Hébérù gbọ́, wọn ò gba ọ̀rọ̀ tó wá látinú Hóséà 6:6 yìí gbọ́. Lójú tiwọn, rírinkinkin mọ́ òfin ṣe pàtàkì ju níní ojú àánú lọ. Kálukú wá lè béèrè lọ́wọ́ ara rẹ̀ pé, ‘Ṣé n kì í rinkinkin mọ́ àwọn ìlànà jù, pàápàá tó bá jẹ́ èyí tó dá lórí èrò ti ara ẹni tàbí àwọn ọ̀ràn èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́? Tàbí kẹ̀, ṣé aláàánú àti onínúure làwọn èèyàn mọ̀ mí sí?’
16. Kí ni ìwà àwọn Farisí, báwo la sì ṣe lè yàgò fún dídàbí wọn?
16 Àríwísí, àríwísí, àríwísí ṣáá ni. Àwọn Farisí ò mọ̀ jùyẹn lọ. Ńṣe làwọn Farisí ń wá àléébù kiri—ì báà jẹ́ àléébù gidi, tàbí ohunkóhun tí wọ́n bá rò pé ó jẹ́ àléébù. Ohun táwọn èèyàn ń ṣe tó kù díẹ̀ káàtó nìkan ni wọ́n ń rí sọ ṣáá. Àwọn Farisí ń yangàn pé àwọn ń san ìdámẹ́wàá ewébẹ̀ tó kéré jù lọ, bí efinrin, dílì àti kúmínì. Wọ́n ń gbé aṣọ gẹ̀rẹ̀jẹ̀-gẹ̀rẹ̀jẹ̀ wọ̀ láti fi ṣe kárími níbi ìjọsìn. Wọ́n sì ń ṣe ìṣe àwa-la-wà-ńbẹ̀ nínú ọ̀ràn orílẹ̀-èdè. Láìsí àní-àní, bí ìṣesí wa yóò bá bá àpẹẹrẹ Jésù mu, a ó yàgò fún ẹ̀mí wíwá àléébù kiri.
Báwo Ni Jésù Ṣe Ń Yanjú Ìṣòro?
17-19. (a) Ṣàlàyé bí Jésù ṣe yanjú ọ̀ràn kan tí ì bá di ńlá. (b) Kí ló mú kí ipò náà jẹ́ èyí tí kò fara rọ, tí kò sì bára dé rárá? (d) Ká ní o wà níbẹ̀ nígbà tí obìnrin náà tọ Jésù wá ni, kí lò bá ṣe?
17 Bí Jésù ṣe ń yanjú ìṣòro yàtọ̀ pátápátá sí bí àwọn Farisí ṣe ń yanjú rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo bí Jésù ṣe yanjú ọ̀ràn kan tí ì bá di wàhálà ńlá. Obìnrin kan mà ni o, tí ó ti ní ìsun ẹ̀jẹ̀ fún ọdún méjìlá gbáko. O lè ka ìtàn náà ní Lúùkù 8:42-48.
18 Àkọsílẹ̀ Máàkù sọ pé ‘jìnnìjìnnì bá obìnrin náà, ó sì ń wárìrì.’ (Máàkù 5:33) Èé ṣe? Nítorí ó mọ̀ pé òun ti rú Òfin Ọlọ́run. Léfítíkù 15:25-28 sọ pé obìnrin tí ẹ̀jẹ̀ bá ń sun lára rẹ̀ lódìlódì jẹ́ aláìmọ́ ní gbogbo ìgbà tí ẹ̀jẹ̀ náà bá ń sun, yóò sì tún wà ní aláìmọ́ lọ́sẹ̀ kan lẹ́yìn náà. Gbogbo nǹkan, àti gbogbo ẹni tí ara rẹ̀ bá kàn yóò di aláìmọ́. Kí obìnrin yìí lè dé ọ̀dọ̀ Jésù, ó forí la ọ̀nà gba àárín ogunlọ́gọ̀ kọjá. Tá a bá ka àkọsílẹ̀ náà lónìí, ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, àánú rẹ̀ ò ní ṣàìṣe wá nítorí ohun tó ti ń rún mọ́ra.
19 Ká ní o wà níbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn ni, ojú wo lò bá fi wo ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn? Kí lò bá sọ? Wàá rí i pé Jésù káàánú obìnrin yìí, ó hùwà sí i tìfẹ́tìfẹ́, ó sì gba tirẹ̀ rò. Àní kò tiẹ̀ mẹ́nu kan wàhálà tó ṣeé ṣe kó ti dá sílẹ̀.—Máàkù 5:34.
20. Ká sọ pé òfin inú Léfítíkù 15:25-28 kàn wá lónìí, irú ipò wo ló ṣeé ṣe kó dojú kọ wá?
20 Ǹjẹ́ a lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí? Ká sọ pé alàgbà ni ọ́ nínú ìjọ Kristẹni lónìí. Ká tún sọ pé òfin inú Léfítíkù 15:25-28 yẹn kan àwa Kristẹni lónìí. Ó sì wá ṣẹlẹ̀ pé obìnrin kan tó jẹ́ Kristẹni ti rú òfin yẹn. Àmọ́ ara rẹ̀ ò wá lélẹ̀ mọ́. Ó sì ń wò tàánútàánú. Kí ni wàá ṣe? Ṣé o ò ní nà án lẹ́gba ọ̀rọ̀ níṣojú gbogbo èrò títí á fi kárí sọ? O lè fèsì pé: “Áà, ó tì o, mi ò jẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀! Àpẹẹrẹ Jésù ni màá tẹ̀ lé. Màá rí i dájú pé mo ṣe é jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, mo hùwà sí i tìfẹ́tìfẹ́, mo ṣaájò rẹ̀, mo sì gba tirẹ̀ rò.” O káre láé! Àmọ́, kì í ṣe ká kàn sọ ọ́ lọ́rọ̀ ẹnu, bí kò ṣe ṣíṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ní àfarawé Jésù.
21. Kí ni Jésù fi kọ́ni nípa Òfin?
21 Ara sábà máa ń tu àwọn èèyàn ní sàkáání Jésù. Wọ́n máa ń túra ká, wọ́n máa ń rí ìṣírí gbà. Níbi tí Òfin Ọlọ́run bá ti sojú abẹ níkòó, kò sí ọ̀rọ̀ pé a tún ń yí i síbòmíràn. Níbi tí Òfin kò bá ti sojú abẹ níkòó, àwọn èèyàn lè gbé ìpinnu wọn ka ohun tí ẹ̀rí ọkàn wọn bá wí. Ìpinnu wọ́n á sì fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Òfin náà jẹ́ kí wọ́n rímú mí, kì í ṣe òfin má-ṣu-má-tọ̀. (Máàkù 2:27, 28) Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀. Ó ń fẹ́ kó dáa fún wọn. Ó sì ṣe tán láti fojú àánú hàn sí wọn nígbà tí wọ́n bá ṣi ẹsẹ̀ gbé. Bí Jésù ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn.—Jòhánù 14:9.
Àbájáde Àwọn Ẹ̀kọ́ Jésù
22. Irú èèyàn wo ni ẹ̀kọ́ tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kọ́ lára rẹ̀ sọ wọ́n dà?
22 Àwọn tó fetí sí Jésù, tí wọ́n sì di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mọyì òótọ́ ọ̀rọ̀ tó sọ, pé: “Àjàgà mi jẹ́ ti inú rere, ẹrù mi sì fúyẹ́.” (Mátíù 11:30) Kò dẹrù pa wọ́n rí, kò fòòró wọn rí, bẹ́ẹ̀ ni kò sọ ọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí wọn rí. Wọ́n túra ká, wọ́n láyọ̀, ọkàn wọn sì túbọ̀ balẹ̀ nípa àjọṣe tó wà láàárín àwọn àti Ọlọ́run àti láàárín ara wọn lẹ́nì kìíní kejì. (Mátíù 7:1-5; Lúùkù 9:49, 50) Wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ lára Jésù pé jíjẹ́ aṣáájú nípa tẹ̀mí túmọ̀ sí jíjẹ́ ẹni tí ń tuni lára, ẹni tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ní èrò inú àti ní ọkàn.—1 Kọ́ríńtì 16:17, 18; Fílípì 2:3.
23. Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo làwọn ọmọ ẹ̀yìn rí kọ́ nítorí pé wọ́n wà pẹ̀lú Jésù, èyí sì jẹ́ kí wọ́n pinnu láti ṣe kí ni?
23 Ìyẹn nìkan kọ́ o, ọ̀pọ̀ ló wá rí ìjẹ́pàtàkì wíwà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi, tí wọ́n sì ní irú ẹ̀mí tó ní. Ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba ti nífẹ̀ẹ́ mi, tí èmi sì nífẹ̀ẹ́ yín, ẹ dúró nínú ìfẹ́ mi. Bí ẹ bá pa àwọn àṣẹ mi mọ́, ẹ óò dúró nínú ìfẹ́ mi, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti pa àwọn àṣẹ Baba mọ́, tí mo sì dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀.” (Jòhánù 15:9, 10) Bí wọn yóò bá kẹ́sẹ járí bí òjíṣẹ́ àti ìránṣẹ́ Ọlọ́run, wọn ní láti sapá láti fi ohun tí Jésù kọ́ wọn sílò, nínú wíwàásù àti kíkọ́ni ní gbangba nípa àgbàyanu ìhìn rere Ọlọ́run àti nínú bí wọ́n ṣe ń ṣe sí ìdílé àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn. Bí ẹgbẹ́ àwọn ará ti ń gbèrú sí i tó ń di ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjọ, léraléra ni yóò di dandan kí wọ́n máa rán ara wọn létí pé ọ̀nà tí Jésù tọ̀ ni ọ̀nà títọ́. Òtítọ́ ni ohun tó fi kọ́ wọn. Irú ìgbésí ayé tí wọ́n sì rí i pé ó gbé ló yẹ kí àwọn náà máa sapá láti gbé.—Jòhánù 14:6; Éfésù 4:20, 21.
24. Kí làwọn nǹkan tó yẹ ká fi sọ́kàn látinú àpẹẹrẹ Jésù?
24 Bó o ṣe ń ronú báyìí lórí díẹ̀ lára àwọn nǹkan tá a ti ń sọ bọ̀, ǹjẹ́ o rí àwọn ibi tó yẹ kó o ti ṣàtúnṣe? Ǹjẹ́ o gbà pé lóòótọ́ ni Jésù ń ronú, pé ó ń kọ́ni àti pé ó ń gbégbèésẹ̀ tó tọ́ nígbà gbogbo? Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, mọ́kàn le. Ọ̀rọ̀ ìṣírí tó sọ fún wa ni pé: “Bí ẹ bá mọ nǹkan wọ̀nyí, aláyọ̀ ni yín bí ẹ bá ń ṣe wọ́n.”—Jòhánù 13:17.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a “Ìyàtọ̀ pàtàkì [tó wà láàárín Jésù àtàwọn Farisí] hàn kedere-kèdèrè nínú ojú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n fi ń wo Ọlọ́run. Lójú àwọn Farisí, olófìn-íntótó ni Ọlọ́run; lójú Jésù olóore ọ̀fẹ́ àti oníyọ̀ọ́nú ni Ọlọ́run. Kì í kúkú ṣe pé àwọn Farisí ò gbà pé Ọlọ́run jẹ́ onínúrere àti onífẹ̀ẹ́. Ṣùgbọ́n lójú tiwọn, ó fi ànímọ́ wọ̀nyẹn hàn nípasẹ̀ ẹ̀bùn Tórà [ìyẹn Òfin] àti nípasẹ̀ ìmúṣẹ ohun tó wà nínú Òfin. . . . Lójú àwọn Farisí, ọ̀nà téèyàn lè gbà mú Tórà ṣẹ ni kéèyàn rọ̀ mọ́ òfin àtẹnudẹ́nu, títí kan àwọn ìlànà rẹ̀ fún títúmọ̀ òfin. . . . Gbígbé tí Jésù gbé òfin méjèèjì nípa ìfẹ́ lékè (Mát 22:34-40), tó sì sọ wọ́n di ìlànà ìwà híhù àti bó ṣe bẹnu àtẹ́ lu òfin àtẹnudẹ́nu tó fi ayé ni àwọn èèyàn lára . . . ló fa wàhálà láàárín òun àtàwọn Farisí tó ti fi òfin rọ́pò ẹ̀rí ọkàn.”—The New International Dictionary of New Testament Theology.
Kí Ni Èsì Rẹ?
• Kí ni jíjẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù túmọ̀ sí lójú tìẹ?
• Kí ni ìṣarasíhùwà Jésù sáwọn èèyàn?
• Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú ọ̀nà tí Jésù gbà kọ́ni?
• Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín Jésù àtàwọn Farisí?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18, 19]
Ẹ wo bí ìṣarasíhùwà Jésù sáwọn èèyàn ti yàtọ̀ sí ti àwọn Farisí tó!