Ọba Henry Kẹjọ Àti Bíbélì
Ọba Henry Kẹjọ Àti Bíbélì
NÍNÚ ìwé náà, History of the English-Speaking Peoples (Apá Kejì), Winston Churchill kọ̀wé pé: “Ẹgbẹ́ Alátùn-únṣe mú ìyípadà ńláǹlà bá ọ̀ràn ẹ̀sìn. Bíbélì wá di ìwé àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n, táwọn èèyàn jákèjádò ayé kò kóyán rẹ̀ kéré mọ́. Àwọn àgbààgbà ayé ìgbà yẹn sọ pé ewu ńlá ń bẹ nínú jíjẹ́ kí Ìwé Mímọ́ tẹ àwọn ọ̀gbẹ̀rì lọ́wọ́. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi sọ pé àwọn àlùfáà nìkan ni kí ó máa kà á.”
Ìròyìn náà tẹ̀ síwájú pé: “Apá ìparí ìgbà ìwọ́wé ọdún 1535 ni Bíbélì tá a tẹ̀ jáde lódindi, èyí tí Tyndale àti Coverdale tú sí èdè Gẹ̀ẹ́sì, kọ́kọ́ dóde. Ẹ̀dà rẹ̀ sì ti pọ̀ lóde báyìí. Ìjọba rọ àwọn àlùfáà pé kí wọ́n fún àwọn èèyàn níṣìírí láti máa ka Bíbélì.” Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún tí àwọn ará ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fi jẹ́ òpè nípa ẹ̀kọ́ Bíbélì, wọ́n á ṣẹ̀ṣẹ̀ wá bẹ̀rẹ̀ sí lóye rẹ̀ ni báyìí. Ọpẹ́lọpẹ́ Ọba Henry Kẹjọ ni o, kì í ṣe ọpẹ́lọpẹ́ ṣọ́ọ̀ṣì. a
“Láti túbọ̀ ṣẹ́pá àwọn tí kò fẹ́ kí Bíbélì tẹ àwọn èèyàn lọ́wọ́, Ìjọba ṣètò pé kí wọ́n tẹ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ Bíbélì èdè Gẹ̀ẹ́sì nílùú Paris. Ó ní kí wọ́n tẹ̀ ẹ́ kó dára rèǹtè-rente ju ẹ̀dà èyíkéyìí tó ti wà tẹ́lẹ̀ lọ. Nígbà tó sì di September 1538, wọ́n pàṣẹ pé kí gbogbo ìjọ tó wà lórílẹ̀-èdè náà ra Bíbélì tó tóbi jù lọ lédè Gẹ̀ẹ́sì, kí wọ́n gbé e sí ṣọ́ọ̀ṣì kọ̀ọ̀kan, kí wọ́n gbé e síbi tó ti máa rọ àwọn ọmọ ìjọ lọ́rùn láti kà á. Wọ́n gbé ẹ̀dà mẹ́fà sí Kàtídírà Pọ́ọ̀lù Mímọ́, nílùú London. Àwọn èèyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí wọ́ tìrítìrí ní kàtídírà náà látàárọ̀ ṣúlẹ̀ láti wá gbọ́ kíkà rẹ̀, àgàgà nígbà tí wọ́n bá rí ẹni tó lè kà á sí wọ́n létí lọ́nà tó já gaara, gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan ti wí.”
Ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò lo àǹfààní tí wọ́n ní láti máa ka Bíbélì déédéé ní àwọn orílẹ̀-èdè bíi mélòó kan. Ọ̀rọ̀ yìí gbèrò gan-an o. Nítorí pé Bíbélì nìkan ni ìwé tí “Ọlọ́run mí sí, [tí] ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo.”—2 Tímótì 3:16.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọba Henry Kẹjọ ṣàkóso ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì láti ọdún 1509 sí 1547.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Ọba Henry Kẹjọ: Àwòrán tí ń bẹ ní Royal Gallery nílùú Kensington, látinú ìwé náà, The History of Protestantism, (Apá Kìíní)