Gbogbo Kristẹni Tòótọ́ Ni Ajíhìnrere
Gbogbo Kristẹni Tòótọ́ Ni Ajíhìnrere
“Ẹ kọrin sí Jèhófà, ẹ fi ìbùkún fún orúkọ rẹ̀. Ẹ máa sọ ìhìn rere ìgbàlà rẹ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́.”—SÁÀMÙ 96:2.
1. Kí ni ìhìn rere tó yẹ káwọn èèyàn gbọ́, báwo sì làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ nínú títan irú ìhìn bẹ́ẹ̀ ká?
NÍNÚ ayé kan tí jàǹbá ti ń ṣẹlẹ̀ lójoojúmọ́, ìtùnú ńlá ló jẹ́ láti mọ̀ pé ogun, ìwà ọ̀daràn, ebi, àti ìninilára, yóò dópin láìpẹ́ gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ ọ́. (Sáàmù 46:9; 72:3, 7, 8, 12, 16) Láìṣe àní-àní, ǹjẹ́ èyí kì í ṣe ìhìn rere tó yẹ kí gbogbo èèyàn gbọ́? Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rò bẹ́ẹ̀. Ibi gbogbo la ti mọ̀ wọ́n sí ẹni tó ń wàásù “ìhìn rere ohun tí ó dára jù.” (Aísáyà 52:7) Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí la ti ṣe inúnibíni sí nítorí ìpinnu wọn láti sọ ìhìn rere náà. Àmọ́ ire àwọn èèyàn ló jẹ wọ́n lọ́kàn jù lọ. Ẹ sì wo ìtara àti ìpamọ́ra bíbùáyà táwọn Ẹlẹ́rìí ti fi hàn.
2. Kí ni ìdí àkọ́kọ́ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi nítara?
2 Ìtara àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní bá ti àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní mu. Ìwé ìròyìn Kátólíìkì náà, L’Osservatore Romano, sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ yìí nípa àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní pé: “Gbàrà tí àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ bá ti ṣe batisí tán ni wọ́n gbà pé ojúṣe àwọn ni láti tan Ìhìn Rere náà ká. Ọ̀rọ̀ ẹnu ni àwọn ẹrú fi ń tan Ìhìn Rere náà ká.” Kí nìdí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi rí bí àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ yẹn, tí ìtara wọn kàmàmà? Lákọ̀ọ́kọ́, nítorí pé ìhìn rere tí wọ́n ń kéde rẹ̀ wá látọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀. Ǹjẹ́ ìdí yẹn nìkan kò tó fún wọn láti nítara? Ìwàásù wọn jẹ́ ṣíṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ onísáàmù nì, pé: “Ẹ kọrin sí Jèhófà, ẹ fi ìbùkún fún orúkọ rẹ̀. Ẹ máa sọ ìhìn rere ìgbàlà rẹ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́.”—Sáàmù 96:2.
3. (a) Kí ni ìdí kejì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi nítara? (b) Kí ni “ìgbàlà [Ọlọ́run]” wé mọ́?
3 Ọ̀rọ̀ onísáàmù náà rán wa létí ìdí kejì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi nítara. Iṣẹ́ wọ́n jẹ́ iṣẹ́ ìgbàlà. Àwọn èèyàn kan ń ṣe iṣẹ́ ìṣègùn, iṣẹ́ afẹ́nifẹ́re, iṣẹ́ lórí ọ̀ràn ìṣúnná owó, tàbí àwọn ìgbòkègbodò mìíràn kí wọ́n lè mú kí ìgbésí ayé àwọn èèyàn bíi tiwọn sunwọ̀n sí i, a sì gbóríyìn fún irú àwọn ìsapá bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ohunkóhun tẹ́nì kan lè ṣe fún ẹlòmíràn kéré gan-an bá a bá fi wé “ìgbàlà [Ọlọ́run].” Jèhófà yóò tipasẹ̀ Jésù Kristi gba àwọn ọlọ́kàn tútù lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, àìsàn, àti ikú. Àwọn tó bá jàǹfààní rẹ̀ yóò wà láàyè títí láé! (Jòhánù 3:16, 36; Ìṣípayá 21:3, 4) Lóde òní, ìgbàlà wà lára “àwọn iṣẹ́ àgbàyanu” tó máa ń wá sọ́kàn àwọn Kristẹni nígbà tí wọ́n bá ń ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ tó sọ pé: “Ẹ máa polongo ògo [Ọlọ́run] láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ láàárín gbogbo ènìyàn. Nítorí pé Jèhófà tóbi lọ́lá, ó sì yẹ fún ìyìn gidigidi. Ó jẹ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ju gbogbo ọlọ́run yòókù lọ.”—Sáàmù 96:3, 4.
Àpẹẹrẹ Ọ̀gá Náà
4-6. (a) Kí ni ìdí kẹta táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi nítara? (b) Báwo ni Jésù ṣe fi ìtara tó ní fún iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere náà hàn?
4 Ìdí kẹta tún wà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi nítara. Wọ́n ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù Kristi. (1 Pétérù 2:21) Ọkùnrin pípé nì fi tọkàntọkàn tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ tá a yàn fún un “láti sọ ìhìn rere fún àwọn ọlọ́kàn tútù.” (Aísáyà 61:1; Lúùkù 4:17-21) Nípa bẹ́ẹ̀, ó di ajíhìnrere, ìyẹn ni ẹni tí ń sọ ìhìn rere. Ó rìn jákèjádò Gálílì àti Jùdíà, ó “ń wàásù ìhìn rere ìjọba náà.” (Mátíù 4:23) Nítorí pé ó mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ló máa tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́. Nítorí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè láti rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.”—Mátíù 9:37, 38.
5 Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Jésù wí nínú àdúrà rẹ̀, ó kọ́ àwọn mìíràn láti di ajíhìnrere. Nígbà tó yá, ó rán àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ jáde láwọn nìkan, ó sì sọ fún wọn pé: “Bí ẹ ti ń lọ, ẹ máa wàásù, pé, ‘Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.’” Ṣé ohun tí ì bá gbéṣẹ́ jù ni pé kí wọ́n ṣe àwọn ètò kan láti dín àwọn ìṣòro tó wà láwùjọ wọn nígbà yẹn lọ́hùn-ún kù? Tàbí ṣe ló yẹ kí wọ́n kópa nínú ọ̀ràn ìṣèlú láti gbógun ti ìwà ìbàjẹ́ tó gbòde kan láyé ìgbà yẹn? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù fi ìlànà lélẹ̀ fún gbogbo àwọn Kristẹni ajíhìnrere nígbà tó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Bí ẹ ti ń lọ, ẹ máa wàásù.”—Mátíù 10:5-7.
6 Lẹ́yìn ìyẹn, Jésù tún rán àwùjọ ọmọ ẹ̀yìn mìíràn jáde láti kéde pé: “Ìjọba Ọlọ́run ti sún mọ́ tòsí.” Nígbà tí wọ́n padà dé, tí wọ́n ròyìn àṣeyọrí tí wọ́n ṣe nínú iṣẹ́ ìjíhìnrere tí wọ́n lọ fún, inú Jésù dùn gan-an. Ó gbàdúrà pé: “Mo yìn ọ́ ní gbangba, Baba, Olúwa ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, nítorí pé ìwọ ti rọra fi ohun wọ̀nyí pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti amòye, o sì ti ṣí wọn payá fún àwọn ìkókó.” (Lúùkù 10:1, 8, 9, 21) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, tí wọ́n ti fìgbà kan jẹ́ akíkanjú apẹja, àgbẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, dà bí ìkókó tá a bá fi wọ́n wé àwọn aṣáájú ìsìn tí wọ́n ti kàwé débi gbì lórílẹ̀-èdè náà. Ṣùgbọ́n a kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn láti kéde ìhìn rere tó dára jù lọ.
7. Lẹ́yìn tí Jésù gòkè re ọ̀run, àwọn wo làwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ kọ́kọ́ wàásù ìhìn rere náà fún?
7 Lẹ́yìn tí Jésù gòkè re ọ̀run, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ń bá a lọ láti sọ ìhìn rere ìgbàlà náà fáwọn èèyàn níbi gbogbo. (Ìṣe 2:21, 38-40) Àwọn wo ni wọ́n kọ́kọ́ wàásù fún? Ṣé ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí kò mọ Ọlọ́run ni wọ́n lọ? Rárá o, Ísírẹ́lì ni pápá tí wọ́n ti kọ́kọ́ ṣiṣẹ́, ìyẹn àwọn ènìyàn tó ti mọ Jèhófà fún ohun tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] ọdún. Ǹjẹ́ wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti wàásù lórílẹ̀-èdè tó jẹ́ pé àwọn èèyàn ibẹ̀ ti ń sin Jèhófà ṣáájú àkókò yẹn? Bẹ́ẹ̀ ni. Jésù ti sọ fún wọn pé: “Ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní Jerúsálẹ́mù àti ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Ó pọn dandan fún Ísírẹ́lì láti gbọ́ ìhìn rere náà bíi ti orílẹ̀-èdè èyíkéyìí mìíràn.
8. Báwo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní ṣe ń fara wé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ti ọ̀rúndún kìíní?
8 Bákan náà ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù ní gbogbo ayé lónìí. Wọ́n fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú áńgẹ́lì tí Jòhánù rí tó “ní ìhìn rere àìnípẹ̀kun láti polongo gẹ́gẹ́ bíi làbárè amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn.” (Ìṣípayá 14:6) Ní ọdún 2001, wọ́n ń ṣe iṣẹ́ àṣekára ní 235 ilẹ̀ àti àwọn ìpínlẹ̀, títí kan àwọn ilẹ̀ táwọn èèyàn kà sí tàwọn Kristẹni. Ṣé ohun tó burú ni kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ wàásù láwọn ibi tí àwọn ẹlẹ́sìn Kristi ti dá ìjọ sílẹ̀? Àwọn kan sọ pé ó burú, wọ́n tiẹ̀ gbà pé “jíjí àgùntàn kó” ni irú iṣẹ́ ìjíhìnrere bẹ́ẹ̀ jẹ́. Àmọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rántí bí ọ̀ràn àwọn Júù tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ nígbà ayé Jésù ṣe rí lára rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ní ẹgbẹ́ àlùfáà, Jésù ò lọ́ tìkọ̀ láti sọ ìhìn rere náà fún wọn. “Àánú wọn ṣe é, nítorí a bó wọn láwọ, a sì fọ́n wọn ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.” (Mátíù 9:36) Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá rí àwọn onírẹ̀lẹ̀ ènìyàn, tí wọn ò mọ̀ nípa Jèhófà àti Ìjọba rẹ̀, ṣé ó yẹ kí wọ́n fi ìhìn rere náà du irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ nítorí pé àwọn ẹ̀sìn kan ti sọ pé àwọn ló ni wọ́n? Tá a bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn àpọ́sítélì Jésù, ohun tó máa jẹ́ ìdáhùn wa ni bẹ́ẹ̀ kọ́. A gbọ́dọ̀ wàásù ìhìn rere náà “ní gbogbo orílẹ̀-èdè,” láìfi ibì kankan sílẹ̀.—Máàkù 13:10.
Gbogbo Kristẹni Àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ Ló Jíhìn Rere
9. Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn wo ló kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù náà lára àwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni?
9 Àwọn wo ló kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù náà ní ọ̀rúndún kìíní? Òkodoro òtítọ́ náà fi hàn pé gbogbo Kristẹni ni ajíhìnrere. Òǹkọ̀wé W. S. Williams sọ pé: “Ẹ̀rí tó hàn sí gbogbo gbòò ni pé gbogbo Kristẹni tó jẹ́ mẹ́ńbà Ṣọ́ọ̀ṣì ìjímìjí . . . ló wàásù ìhìn rere náà.” Ohun tí Bíbélì sọ nípa ohun tó wáyé lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa ni pé: “Gbogbo wọ́n [tọkùnrin tobìnrin] sì wá kún fún ẹ̀mí mímọ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi onírúurú ahọ́n àjèjì sọ̀rọ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí ti ń yọ̀ǹda fún wọn láti sọ̀rọ̀ jáde.” Tọkùnrin, tobìnrin, tọmọdé, tàgbà, ẹrú àti òmìnira ló jẹ́ ajíhìnrere. (Ìṣe 1:14; 2:1, 4, 17, 18; Jóẹ́lì 2:28, 29; Gálátíà 3:28) Nígbà tí inúnibíni lé ọ̀pọ̀ Kristẹni kúrò ní Jerúsálẹ́mù, “àwọn tí a tú ká la ilẹ̀ náà já, wọ́n ń polongo ìhìn rere ọ̀rọ̀ náà.” (Ìṣe 8:4) Gbogbo “àwọn tí a tú ká,” ló jíhìn rere, kì í ṣe àwọn díẹ̀ kéréje tá a yàn.
10. Àṣẹ alápá méjì wo ló nímùúṣẹ ṣáájú ìparun ètò àwọn Júù?
10 Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn ní gbogbo àwọn ọdún ìjímìjí wọ̀nyẹn. Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14) Nígbà tí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn nímùúṣẹ ní ọ̀rúndún kìíní, wọ́n ti wàásù ìhìn rere náà gan-an kó tó di pé àwọn ọmọ ogun Róòmù wá pa ìsìn Júù àti ètò ìṣèlú rẹ̀ run. (Kólósè 1:23) Síwájú sí i, gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ló ṣègbọràn sí àṣẹ tó pa, pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mátíù 28:19, 20) Kì í ṣe pé àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ wulẹ̀ ń rọ àwọn ọlọ́kàn tútù pé kí wọ́n gba Jésù gbọ́, lẹ́yìn náà kí wọ́n wá fi wọ́n sílẹ̀ pé kí wọ́n máa sin Ọlọ́run lọ́nà tó wù wọ́n, bí àwọn oníwàásù kan ti ń ṣe lóde òní. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n kọ́ wọ́n láti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù, wọ́n ṣètò wọn sáwọn ìjọ, wọ́n sì dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ kí àwọn náà lè máa wàásù ìhìn rere náà, kí wọ́n sì sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. (Ìṣe 14:21-23) Ọ̀nà kan náà ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé lónìí.
11. Àwọn wo ló ń kópa nínú kíkéde ìhìn rere tó dára jù lọ fún ìran ènìyàn lónìí?
11 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bíi mélòó kan tó tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù, Bánábà, àti ti àwọn mìíràn ní ọ̀rúndún kìíní, ti lọ sìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì ní àwọn ilẹ̀ òkèèrè. Iṣẹ́ wọn sì ti ṣàǹfààní gan-an, níwọ̀n bí wọn ò ti kópa nínú ọ̀ràn ìṣèlú tàbí kí wọ́n ti ṣáko láwọn ọ̀nà mìíràn kúrò nínú àṣẹ tá a pa fún wọn láti wàásù ìhìn rere náà. Wọ́n ti ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù náà pé: “Bí ẹ ṣe ń lọ, ẹ máa wàásù.” Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe míṣọ́nnárì nílẹ̀ òkèèrè. Ọ̀pọ̀ lára wọn ló níṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tí wọ́n ń ṣe, àwọn mìíràn ṣì wà nílé ìwé. Àwọn kan ń tọ́ àwọn ọmọ. Àmọ́ gbogbo Ẹlẹ́rìí pátá ló ń nípìn-ín nínú sísọ ìhìn rere tí wọ́n ti gbọ́ fún àwọn ẹlòmíràn. Àtọmọdé àtàgbà, àtọkùnrin àtobìnrin, ló ń fi tayọ̀tayọ̀ tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Bíbélì fúnni pé: “Wàásù ọ̀rọ̀ náà, wà lẹ́nu rẹ̀ ní kánjúkánjú ní àsìkò tí ó rọgbọ, ní àsìkò tí ó kún fún ìdààmú.” (2 Tímótì 4:2) Bíi ti àwọn tó kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ ọ̀hún ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn tòde òní ń bá a lọ “láìdábọ̀ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere nípa Kristi náà, Jésù.” (Ìṣe 5:42) Wọ́n ń kéde ìhìn rere tó dára jù lọ fún ọmọ aráyé.
Ṣé Sísọni Di Aláwọ̀ṣe ni Tàbí Jíjíhìnrere?
12. Kí ni sísọni di aláwọ̀ṣe, ojú wo làwọn èèyàn sì wá fi ń wò ó?
12 Ọ̀rọ̀ kan wà nínú èdè Gíríìkì tí a ń pè ní pro·se’ly·tos tó túmọ̀ sí “aláwọ̀ṣe.” Ẹni tó kúrò nínú ẹ̀sìn rẹ̀ lọ wọnú ẹ̀sìn mìíràn là ń pè ní “aláwọ̀ṣe.” Àwọn kan ń sọ lóde òní pé wíwàásù fáwọn èèyàn pé kí wọ́n kúrò nínú ẹ̀sìn wọn kì í ṣe nǹkan tó dára. Ìwé kan tí Ìgbìmọ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì Àgbáyé tẹ̀ jáde tiẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa “ẹ̀ṣẹ̀ sísọni di aláwọ̀ṣe.” Kí nìdí? Ìwé Catholic World Report sọ pé: “Àròyé tí ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ń ṣe ní gbogbo ìgbà ti jẹ́ kí ‘sísọni di aláwọ̀ṣe’ di ohun tí a kà sí fífi agbára yíni lọ́kàn padà.”
13. Kí ni àpẹẹrẹ àwọn kan tá a sọ di aláwọ̀ṣe lọ́nà tí kò tọ́?
13 Ǹjẹ́ ohun tó burú ni sísọni di aláwọ̀ṣe? Ó lè jẹ́ bẹ́ẹ̀. Jésù sọ pé ńṣe ni àwọn akọ̀wé àtàwọn Farisí ń ba ti àwọn tí wọ́n sọ di aláwọ̀ṣe jẹ́. (Mátíù 23:15) Dájúdájú, “fífi agbára yíni lọ́kàn padà” lòdì. Bí àpẹẹrẹ, gẹ́gẹ́ bí ohun tí òpìtàn nì, Josephus sọ, nígbà tí John Hyrcanus tó jẹ́ ara àwọn Maccabee ṣẹ́gun àwọn ará Ídúmíà, ó “gbà wọ́n láyè láti máa gbé orílẹ̀-èdè wọn níwọ̀n bí wọ́n bá ti gbà láti dádọ̀dọ́, tí wọ́n sì ṣe tán láti pa òfin àwọn Júù mọ́.” Bí àwọn ará Ídúmíà bá fẹ́ wà lábẹ́ ìṣàkóso Júù, wọ́n ní láti ṣe ẹ̀sìn àwọn Júù. Àwọn òpìtàn sọ fún wa pé ní ọ̀rúndún kẹjọ Sànmánì Tiwa, Charlemagne ṣẹ́gun àwọn Saxon tó jẹ́ kèfèrí ní àríwá Yúróòpù, ó sì fi tipátipá mú wọn láti yí ìsìn wọn padà. a Àmọ́ báwo ni ìyípadà àwọn Saxon tàbí ti àwọn ará Ídúmíà ti jẹ́ ojúlówó tó? Fún àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ a lè sọ pé Ọba Hẹ́rọ́dù tí í ṣe ará Ídúmíà—tó gbìyànjú láti pa Jésù jòjòló—ní ojúlówó àjọṣe pẹ̀lú Òfin Mósè tí Ọlọ́run mí sí?—Mátíù 2:1-18.
14. Báwo làwọn míṣọ́nnárì ẹlẹ́sìn Kristi kan ṣe máa ń fagbára yí àwọn èèyàn lọ́kàn padà?
14 Ǹjẹ́ a ń fagbára yíni lọ́kàn padà lónìí? Àwọn kan kúkú ń ṣe bẹ́ẹ̀. A ti gbọ́ ìròyìn àwọn míṣọ́nnárì ẹlẹ́sìn Kristi kan tí wọ́n ṣèlérí ẹ̀bùn ìrànwọ́ ẹ̀kọ́ lókè òkun fáwọn tó bá gbà láti yí ẹ̀sìn wọn padà. Tàbí kí wọ́n kó àwọn olùwá-ibi-ìsádi tí ebi ń pa síbì kan kí wọ́n sì máa wàásù fún wọn kí wọ́n tó gbà láti fún wọn ní oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ kan tí àpéjọpọ̀ àwọn Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì gbé jáde ní ọdún 1992, wọ́n ní “sísọni di aláwọ̀ṣe sábà máa ń wáyé nípa fífi àwọn nǹkan ti ara fani mọ́ra tàbí nígbà mìíràn nípa onírúurú ìwà ipá.”
15. Ǹjẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń sọni di aláwọ̀ṣe lọ́nà tá a gbà túmọ̀ ọ̀rọ̀ náà lóde òní? Ṣàlàyé.
15 Fífi agbára mú kí àwọn èèyàn yí ẹ̀sìn wọn padà jẹ́ ohun tó lòdì. Dájúdájú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe bẹ́ẹ̀ rárá. b Nítorí náà, wọn kì í sọni di aláwọ̀ṣe lọ́nà tá a gbà ń túmọ̀ ọ̀rọ̀ yẹn lóde òní. Dípò ìyẹn, bíi ti àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ni wọ́n ṣe ń wàásù ìhìn rere náà fún gbogbo èèyàn. Àwọn tó bá sì fínnúfíndọ̀ tẹ́wọ́ gbà á la máa ń rọ̀ láti gba ìmọ̀ kún ìmọ̀ nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Irú àwọn olùfìfẹ́hàn bẹ́ẹ̀ ń kọ́ bí a ṣe ń ní ìgbàgbọ́, tá a gbé karí ìmọ̀ Bíbélì tó péye, nínú Ọlọ́run àti àwọn ète rẹ̀. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ń pe orúkọ Ọlọ́run, tí ń jẹ́ Jèhófà, láti lè rí ìgbàlà. (Róòmù 10:13, 14, 17) Yálà wọ́n máa tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́ jẹ́ ìpinnu kálukú. Kì í ṣe ọ̀ranyàn rárá. Tó bá jẹ́ ọ̀ranyàn ni, a jẹ́ pé ìyínilọ́kànpadà kò já mọ́ nǹkan kan nìyẹn. Kí Ọlọ́run tó lè tẹ́wọ́ gba ẹnì kan, ìjọsìn onítọ̀hún gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tó tinú ọkàn rẹ̀ wá.—Diutarónómì 6:4, 5; 10:12.
Jíjíhìnrere Lóde Òní
16. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe lóde òní ṣe ń bí sí i?
16 Jálẹ̀ àkókò tiwa yìí làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wàásù ìhìn rere Ìjọba náà ní ìmúṣẹ Mátíù 24:14 lọ́nà gbígbòòrò. Ọ̀kan lára ohun èlò wọn pàtàkì nínú iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere náà ni ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́. c Ní 1879, nígbà tí wọ́n tẹ àwọn ẹ̀dà àkọ́kọ́ Ilé Ìṣọ́ jáde, nǹkan bí ẹgbàata [6,000] ẹ̀dà ìwé ìròyìn náà ni wọ́n ń pín kiri ní èdè kan ṣoṣo. Ní ọdún 2001, tó lé ní ọdún méjìlélọ́gọ́fà [122] lẹ́yìn ìgbà yẹn, wọ́n ti ń pín ẹ̀dà tí ó tó 23,042,000 kiri ní èdè mọ́kànlélógóje [141]. Ohun mìíràn tó tún pẹ̀lú ìbísí náà ni ìtẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Fi ẹgbẹ̀rún díẹ̀ wákàtí tí wọ́n ń lò lọ́dọọdún nínú iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún wé 1,169,082,225 wákàtí tí wọ́n fi ṣe iṣẹ́ ìwàásù ní ọdún 2001. Tún ronú nípa ìpíndọ́gba 4,921,702 ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n darí lọ́fẹ̀ẹ́ lóṣù kọ̀ọ̀kan. Ẹ ò rí i pé iṣẹ́ àtàtà tí wọ́n ṣe kàmàmà! Àwọn 6,117,666 oníwàásù Ìjọba náà ló sì ṣe iṣẹ́ yìí.
17. (a) Irú àwọn ọlọ́run èké wo làwọn èèyàn ń jọ́sìn lóde òní? (b) Láìfi èdè tẹ́nì kan ń sọ, orílẹ̀-èdè onítọ̀hún, tàbí ipò rẹ̀ láwùjọ pè, kí ló yẹ kí gbogbo ènìyàn mọ̀?
17 Onísáàmù náà sọ pé: “Gbogbo ọlọ́run àwọn ènìyàn jẹ́ àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí; ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, òun ni ó ṣe ọ̀run pàápàá.” (Sáàmù 96:5) Nínú ayé òde òní tí kò fi ti ẹ̀sìn ṣe, ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni, àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ orílẹ̀-èdè, àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn, ohun ìní ti ara, kódà ọrọ̀ pàápàá ti di ohun táwọn èèyàn ń jọ́sìn. (Mátíù 6:24; Éfésù 5:5; Kólósè 3:5) Mohandas K. Gandhi sọ nígbà kan pé: “Èrò tèmi tí kò ṣeé já ní koro ni pé . . . àwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́ nìkan ló kún Yúróòpù lónìí. Ní ti gidi, Mámónì [ọrọ̀] ni wọ́n ń sìn.” Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, ó yẹ káwọn èèyàn gbọ́ ìhìn rere náà níbi gbogbo. Gbogbo èèyàn pátá ló yẹ kó mọ̀ nípa Jèhófà àtàwọn ète rẹ̀, láìfi èdè yòówù kí wọ́n máa sọ, orílẹ̀-èdè yòówù kí wọ́n wà, tàbí ipò yòówù kí wọ́n wà láwùjọ pè. A retí pé kí gbogbo èèyàn ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ onísáàmù náà, pé: “Ẹ gbé ògo àti okun fún Jèhófà. Ẹ gbé ògo tí ó jẹ́ ti orúkọ Jèhófà fún un”! (Sáàmù 96:7, 8) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà kí wọ́n lè yìn ín lógo lọ́nà tí ó tọ́. Àwọn tó sì ń fetí sí wọn ń jẹ àǹfààní tó pọ̀. Àwọn àǹfààní wo ni wọ́n ń gbádùn? Ìwọ̀nyí ni a óò jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The Catholic Encyclopedia, ti wí, nígbà ayé àwọn Alátùn-únṣe Ìsìn, fífi agbára mú àwọn èèyàn ṣe ẹ̀sìn mìíràn ni wọ́n máa ń fi àkọlé èdè Látìn kan ṣàpèjúwe, èyí tó túmọ̀ sí: “Ẹnikẹ́ni tó bá ń ṣàkóso ilẹ̀ kan ló máa pinnu ìsìn táwọn ará ibẹ̀ máa ṣe.”
b Níbi ìpàdé kan tí Ìgbìmọ̀ Tí Ń Bójú Tó Òmìnira Ìsìn Lágbàáyé ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ṣe ní November 16, 2000, ọ̀kan lára àwọn tó wà níbẹ̀ sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn tó ń gbìyànjú láti fagbára yíni lọ́kàn padà àti ìgbòkègbodò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá ń wàásù, wọ́n kì í fi agbára mú àwọn èèyàn láti gbọ́ ọrọ̀ wọn, tí ó bá sì wu ẹnì kan ó lè sọ pé “Mi ò fẹ́ gbọ́,” kó sì pa ilẹ̀kùn rẹ̀ dé.
c Àkòrí ìwé ìròyìn náà lọ́nà tó kún rẹ́rẹ́ ni Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jèhófà.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Kí nìdí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi jẹ́ ajíhìnrere tó nítara?
• Èé ṣe táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń wàásù láwọn ibi tí àwọn ẹlẹ́sìn Kristi ti dá ìjọ sílẹ̀?
• Kí nìdí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi í ṣe àwọn tí ń sọni di aláwọ̀ṣe lọ́nà tá a gbà túmọ̀ ọ̀rọ̀ náà lóde òní?
• Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe lóde òní ṣe ń bí sí i?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Jésù jẹ́ ajíhìnrere tó nítara, ó sì kọ́ àwọn mìíràn láti ṣe iṣẹ́ kan náà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ ọ̀rúndún kìíní ló kópa nínú iṣẹ́ wíwàásù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Fífi agbára mú kí àwọn èèyàn yí ẹ̀sìn wọn padà jẹ́ ohun tó lòdì