Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wàhálà Tí Ìwà Kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ Ń Dá Sílẹ̀

Wàhálà Tí Ìwà Kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ Ń Dá Sílẹ̀

Wàhálà Tí Ìwà Kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ Ń Dá Sílẹ̀

“ÒÓTỌ́ NI PÉ ÀPARÒ KAN Ò GA JÙKAN LỌ. ÀMỌ́ KÒ SÍ ỌLỌGBỌ́N TÀBÍ Ọ̀MỌ̀RÀN NÁÀ TÓ LÈ MÚ KÍ ÌKA ỌWỌ́ DỌ́GBA.”

Honoré de Balzac, ọmọ ilẹ̀ Faransé kan tó jẹ́ òǹkọ̀wé eré onítàn ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, ló sọ ọ̀rọ̀ yìí. Ṣó o gbà pé òótọ́ ló sọ? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ̀ pé ìwà kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ kò dáa. Síbẹ̀ ìwà kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ ṣì gbòde kan nínú ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà wa ní ọ̀rúndún kọkànlélógún yìí pàápàá.

Ọ̀GBẸ́NI Calvin Coolidge, tó jẹ́ ààrẹ Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà láti ọdún 1923 sí 1929, dìídì fẹ́ wá nǹkan ṣe sí ọ̀ràn kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́, ó sì sọ̀rọ̀ nípa “fífòpin sí ẹgbẹ́ àwọn lọ́gàálọ́gàá.” Àmọ́, ní nǹkan bí ogójì ọdún lẹ́yìn tí Ọ̀gbẹ́ni Coolidge ṣèjọba, ni Ìgbìmọ̀ Kerner tí wọ́n gbé kalẹ̀ láti ṣèwádìí lórí ọ̀ràn kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, sọ pé àfàìmọ̀ ni kò fi ní jẹ́ pé ní àbárèbábọ̀, àwùjọ méjì ni Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà máa pín sí: “ìkan dúdú, ìkan funfun—tí kálukú wọ́n wà lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, tí wọn ò sì bára dọ́gba.” Àwọn kan sọ pé ọ̀rọ̀ ìgbìmọ̀ yẹn ló ń ṣẹ yìí. Torí pé “ọ̀gbun tó wà láàárín olówó àti tálákà ń fẹ̀ sí i ni. Ṣe ni ẹ̀yà méjèèjì sì túbọ̀ ń kẹ̀yìn síra wọn” ní orílẹ̀-èdè yẹn.

Kí ló dé tó fi ṣòro tó bẹ́ẹ̀ láti rí i pé gbogbo èèyàn ní ẹ̀tọ́ ọgbọọgba? Ọ̀kan lára ohun pàtàkì tó ń fà á ni irú ẹ̀dá téèyàn jẹ́. Ọ̀gbẹ́ni William Randolph Hearst, tó jẹ́ ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà tẹ́lẹ̀, sọ nígbà kan rí pé: “Gbogbo èèyàn ni a ṣẹ̀dá ní dọ́gbadọ́gba lọ́nà kan, ó kéré tán. Ọ̀nà kan náà sì ni pé kò sẹ́ni tó fẹ́ kí ẹlòmíràn bá òun dọ́gba.” Kí ló ní lọ́kàn? Eléré orí ìtàgé ọmọ ilẹ̀ Faransé nì, Henry Becque, tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, ló wá jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà yéni yékéyéké nígbà tó sọ pé: “Ohun tó sọ ẹ̀tọ́ ọgbọọgba di àléèbá ni pé ìgbà tá a bá rí àwọn tó jù wá lọ nìkan lọ̀ràn ẹ̀tọ́ ọgbọọgba máa ń ká wa lára.” Lédè mìíràn, àwọn èèyàn máa ń fẹ́ láti lé ará iwájú bá; ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò fẹ́ kí àwọn tí wọ́n kà sí èrò ẹ̀yìn bá àwọn.

Láyé àtijọ́, ìbí ẹrú la bí àwọn kan. Ìbí ọlọ́lá la bí àwọn míì. Àwọn kan sì rèé, láti kékeré ni wọ́n ti ń jayé ọba. Bọ́ràn ṣì ṣe rí láwọn ibi díẹ̀ lónìí nìyẹn. Ṣùgbọ́n, ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ lónìí, owó—tàbí àìlówó lọ́wọ́—ló ń pinnu bóyá ẹgbẹ́ ọlọ́lá, ẹgbẹ́ bọ̀rọ̀kìnní, tàbí ẹgbẹ́ tálákà lèèyàn á wà. Àmọ́ àwọn nǹkan míì tó ń pinnu ìsọ̀rí téèyàn máa bá ara rẹ̀ ni ẹ̀yà, béèyàn ṣe kàwé sí àti bóyá ó mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà. Ní àwọn ibòmíì sì rèé, ẹ̀yà akọ tàbí ti abo ni ọ̀ràn kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ pín sí. Ní irú ibi wọ̀nyẹn, wọn kì í ka àwọn obìnrin séèyàn gidi.

Ṣé Ìrètí Ń Bẹ?

Àwọn òfin ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ti jẹ́ kó ṣeé ṣe láti fòpin sí àwọn ìwà kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ kan. Òfin ti de àṣà ìran-tèmi-lọ̀gá ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Wọ́n ti ṣòfin tó ka àṣà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà léèwọ̀ ní Gúúsù Áfíríkà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òwò ẹrú ṣì ń lọ lọ́wọ́ láwọn ibì kan láyé, wọ́n ti gbẹ́sẹ̀ lé e níbi tó pọ̀ jù lọ. Àwọn ilé ẹjọ́ kan ti pa á láṣẹ pé wọn ò gbọ́dọ̀ fi ẹ̀tọ́ àwọn ọmọ onílẹ̀ dù wọ́n. Àwọn òfin tó ka ẹ̀tanú léèwọ̀ sì ti dáàbò bo àwọn ẹni tí nǹkan ò rọgbọ fún.

Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé kò sí àṣà kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ mọ́ nìyẹn? Ó tì o. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìwà kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ kan ti rọlẹ̀ báyìí, àwọn míì tún ti bẹ̀rẹ̀ sí yọjú. Ìwé náà Class Warfare in the Information Age sọ pé: “Ó jọ pé wíwulẹ̀ pín àwọn èèyàn sí ìsọ̀rí ọ̀gá àti ọmọọṣẹ́ kò tó mọ́ lóde òní. Nítorí pé ìsọ̀rí wọ̀nyí tún ti pín sí àwọn ìsọ̀rí pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tó kún fún àwọn èèyàn tí inú ń bí.”

Ṣé títí láé ni àṣà kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ yóò máa da àárín àwọn èèyàn rú ni? Tóò, àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e fi hàn pé ìrètí ń bẹ.