Ṣé Ọlọ́run Tòótọ́ Lo Gbẹ́kẹ̀ Lé?
Ṣé Ọlọ́run Tòótọ́ Lo Gbẹ́kẹ̀ Lé?
Àwọn kan gbéra ìrìn àjò ìwádìí kan tí Ibi Ìkóhun-Ìṣẹ̀ǹbáyé-Nípa-Ìtàn-Sí ní Amẹ́ríkà ṣonígbọ̀wọ́ rẹ̀. Wọ́n fẹ́ lọ ṣèwádìí nípa Ilẹ̀ Olótùútù Nini kan tí wọ́n ròyìn pé olùṣàwárí Robert E. Peary rí ní nǹkan bí ọdún méje ṣáájú ní 1906.
LÁTI Cape Colgate tó wà ní ìpẹ̀kun ìhà àríwá ìwọ̀ oòrùn North America ni Peary ti rí ohun kan tó dà bíi ṣóńṣó orí òkè funfun tó wà ní ilẹ̀ jíjìnnà réré. Ó pè é ní Ilẹ̀ Crocker, tí í ṣe orúkọ ọ̀kan lára àwọn tó ń fi owó ṣètìlẹ́yìn fún un. Ẹ wo bí inú àwọn mẹ́ńbà tó rin ìrìn àjò kejì yìí á ti dùn tó nígbà tí wọ́n kófìrí àgbègbè kan tó ní àwọn òkè, àwọn àfonífojì, àtàwọn ṣóńṣó tí yìnyín bo níwájú wọn! Àmọ́, kò pẹ́ tí wọ́n fi wá rí i pé òjìji kan lásán tó dà bí Ilẹ̀ Olótùútù Nini làwọn rí. Ipa tí ìrí ojú ọjọ́ ní yìí ló tan Peary jẹ, kí àwọn aráabí tó mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀, wọ́n ti lo àkókò, agbára àti owó láti ṣàwárí nǹkan tí kò sí.
Lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń lo ara wọn àti àkókò wọn fún àwọn ọlọ́run tí wọ́n gbà gbọ́ pé ó jẹ́ gidi. Àwọn ọlọ́run bíi Hẹ́mísì àti Súúsì làwọn èèyàn ń sìn nígbà ayé àwọn àpọ́sítélì Jésù. (Ìṣe 14:11, 12) Lóde òní, ọ̀kẹ́ àìmọye làwọn ọlọ́run tí àwọn ẹlẹ́sìn Ṣintó, Híńdù, àtàwọn ẹ̀sìn mìíràn nínú ayé ń sìn. Àní, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ ọ́, “ọ̀pọ̀ ‘ọlọ́run’ àti ọ̀pọ̀ ‘olúwa’” ló wà. (1 Kọ́ríńtì 8:5, 6) Ṣé ọlọ́run tòótọ́ ni gbogbo àwọn ọlọ́run wọ̀nyí?
Àwọn Ọlọ́run Tí “Kò Lè Gbani Là”
Fún àpẹẹrẹ, ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀rọ̀ nípa lílo àwọn ère tàbí àmì nínú ìjọsìn. Lójú àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé àwọn òrìṣà tàbí tí wọ́n ń gbàdúrà nípasẹ̀ wọn, ńṣe lòrìṣà dà bí olùgbàlà tó lágbára tó ju ti ẹ̀dá lọ, tó lè fún àwọn èèyàn lérè tàbí kí ó yọ wọ́n nínú ewu. Àmọ́, ǹjẹ́ wọ́n lè gbani là lóòótọ́? Onísáàmù kọrin nípa irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ pé: “Fàdákà àti wúrà ni òrìṣà àwọn orílẹ̀-èdè, iṣẹ́ ọwọ́ ará ayé. Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò Sáàmù 135:15-17; Aísáyà 45:20.
lè sọ nǹkan kan; wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò lè rí nǹkan kan; wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò lè fi etí sí nǹkan kan. Pẹ̀lúpẹ̀lù, kò sí ẹ̀mí kankan ní ẹnu wọn.” Láìsí àní-àní, àwọn ọlọ́run “tí kò lè gbani là” ni wọ́n.—Lóòótọ́, àwọn tó ń ṣe ère wọ̀nyẹn lè sọ pé iṣẹ́ tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe ní ẹ̀mí àti agbára. Àwọn tó sì ń bọ òrìṣà ń gbẹ́kẹ̀ lé wọn. Wòlíì Aísáyà sọ pé, “Wọ́n gbé [òrìṣà] sí èjìká, wọ́n rù ú, wọ́n sì gbé e kalẹ̀ sí àyè rẹ̀ kí ó lè dúró bọrọgidi.” Ó fi kún un pé: “Kò ṣísẹ̀ kúrò ní ibi tí ó dúró sí. Ẹnì kan tilẹ̀ ń ké jáde sí i, ṣùgbọ́n kò dáhùn; kò gbani là kúrò nínú wàhálà ẹni.” (Aísáyà 46:7) Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé òrìṣà kò ní ẹ̀mí kankan bó ti wù kí ìgbàgbọ́ àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé e jinlẹ̀ tó. Irú àwọn ère gbígbẹ́ àti àwọn ère dídà bẹ́ẹ̀ jẹ́ “àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí.”—Hábákúkù 2:18.
Sísọ àwọn òṣèré, àwọn eléré ìdárayá, ètò ìṣèlú, àtàwọn olórí ìsìn kan di òrìṣà, kí wọ́n bọlá fún wọ́n, tàbí kí wọ́n máa júbà wọn ti di ohun tó gbòde kan lóde òní. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, owó tún jẹ́ ọlọ́run fún ọ̀pọ̀ èèyàn. Nínú gbogbo ọ̀ràn tó wà nílẹ̀ yìí, ńṣe làwọn èèyàn sọ òrìṣà wọ̀nyí di ohun tí wọn kò jẹ́. Àwọn òrìṣà wọ̀nyí kò lè ṣe gbogbo ohun táwọn tó nígbàgbọ́ nínú wọn retí pé kí wọ́n ṣe. Fún àpẹẹrẹ, ọrọ̀ lè dà bí ohun tó jẹ́ ìdáhùn sí gbogbo ìṣòro, ṣùgbọ́n agbára ọrọ̀ ń tanni jẹ. (Máàkù 4:19) Olùwádìí kan béèrè pé: “Kí ló fà á tó fi jẹ́ pé ohun kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń fi ìháragàgà lé kiri, tí wọ́n sì gbà pé yóò yanjú gbogbo ìṣòro àwọn tí ọwọ́ bá ti lè tẹ̀ ẹ́ ṣe wá di ohun tí àbájáde rẹ̀ máa ń ti orí ìjákulẹ̀ bọ́ sórí hílàhílo?” Bẹ́ẹ̀ ni o, wíwá ọrọ̀ lè mú kí ẹnì kan fi ohun tí ó dìídì níye lórí du ara rẹ̀, irú nǹkan bí ìlera ara, ìgbésí ayé ìdílé aláyọ̀, àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, tàbí àjọṣe tó gbámúṣé pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá. Ọlọ́run irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò wá ní yàtọ̀ sí “òrìṣà àìjóòótọ́”!—Jónà 2:8.
“Kò . . . Sí Ẹnì Kankan Tí Ó Dáhùn”
Ìwà òmùgọ̀ gbáà ni kéèyàn máa pe ohun tí kì í ṣe gidi ní ohun gidi. Àwọn olùjọsìn ọlọ́run Báálì nígbà ayé Èlíjà kan ìdin nínú iyọ̀ kí wọ́n tó mọ èyí. Wọ́n gbà gbọ́ gan-an pé Báálì lágbára láti mú kí iná sọ láti ọ̀run, kí ó sì sun ẹran tí wọ́n fi rúbọ. Àní, wọ́n “ń ké pe orúkọ Báálì ṣáá láti òwúrọ̀ títí di ọ̀sán gangan, pé: ‘Báálì, dá wa lóhùn!’” Ǹjẹ́ Báálì ní etí tó lè fi gbọ́rọ̀ àti ẹnu tó lè fi sọ̀rọ̀? Ìtàn náà ń bá a lọ pé: “Kò sí ohùn kankan, kò sì sí ẹnì kankan tí ó dáhùn.” Ní ti tòótọ́, “kò sì sí fífetísílẹ̀.” (1 Àwọn Ọba 18:26, 29) Báálì kì í ṣe ẹni gidi, kò sí láàyè, bẹ́ẹ̀ ni kò lè ṣe ohunkóhun.
Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an láti mọ Ọlọ́run tó jẹ́ ẹni gidi, ká sì máa sìn ín! Ṣùgbọ́n ta ni ẹni náà? Báwo sì ni gbígbẹ́kẹ̀lé e ṣe lè ṣe wá láǹfààní?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Egingwah tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ Peary ń wá ilẹ̀ ní ibi tí ó jọ pé ilẹ̀ òun òfuurufú ti pàdé
Robert E. Peary
[Àwọn Credit Line]
Egingwah: Láti inú ìwé náà, The North Pole: Its Discovery in 1909 Under the Auspices of the Peary Arctic Club, 1910; Robert E. Peary: NOAA
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Ohun táwọn èèyàn sọ dòrìṣà ti tàn ọ̀pọ̀ èèyàn jẹ́ nínú ayé yìí