Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà—Ọlọ́run Tó Jẹ́ Ẹni Gidi

Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà—Ọlọ́run Tó Jẹ́ Ẹni Gidi

Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà—Ọlọ́run Tó Jẹ́ Ẹni Gidi

Ǹjẹ́ o ti wo ojú ọ̀run rí ní òru ọjọ́ kan tí gbogbo rẹ̀ mọ́lẹ̀ kedere, tó o sì rí ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ìràwọ̀? Ǹjẹ́ o mọ bí wọ́n ṣe débẹ̀?

BÍ IBI gbogbo ti dákẹ́ rọ́rọ́ ní òru, àwọn ìràwọ̀ bá Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì sọ̀rọ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ ló sún un láti kọ̀wé pé: “Àwọn ọ̀run ń polongo ògo Ọlọ́run; òfuurufú sì ń sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.” (Sáàmù 19:1) Bẹ́ẹ̀ ni o, kì í ṣe ìṣẹ̀dá bí kò ṣe Ẹlẹ́dàá fúnra rẹ̀ ló yẹ “láti gba ògo àti ọlá àti agbára.”—Ìṣípayá 4:11; Róòmù 1:25.

Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run.” (Hébérù 3:4) Láìṣe àní-àní, Ọlọ́run tòótọ́, ‘tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.’ (Sáàmù 83:18) Òun kì í ṣe ìran ojú àlá—bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe òjìji. Jésù Kristi sọ nípa Jèhófà, Baba rẹ̀ ọ̀run pé: “Ẹni tí ó rán mi jẹ́ ẹni gidi.”—Jòhánù 7:28.

Jèhófà—Ẹni Tí Ń Mú Àwọn Ète Rẹ̀ Ṣẹ

Jèhófà, orúkọ aláìlẹ́gbẹ́ tí Ọlọ́run ń jẹ́, fara hàn ní ìgbà tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún méje [7,000] nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù nìkan ṣoṣo. Orúkọ yẹn nìkan fi hàn pé ẹni gidi ni. Ohun tí orúkọ Ọlọ́run túmọ̀ sí ní ṣáńgílítí ni “Alèwílèṣe.” Jèhófà Ọlọ́run sì tipa bẹ́ẹ̀ fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí Ẹni tí ń mú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ. Nígbà tí Mósè sọ fún Ọlọ́run pé òun fẹ́ mọ orúkọ rẹ̀, Jèhófà ṣàlàyé ìtumọ̀ rẹ̀ fún un lọ́nà yìí pé: “Èmi yóò jẹ́ ohun tí èmi yóò jẹ́.” (Ẹ́kísódù 3:14) Ìtumọ̀ ti Rotherham sọ ọ́ ní ṣàkó pé: “Èmi Yóò Di ohunkóhun tí ó bá wù mí.” Jèhófà máa ń di ohunkóhun tí ó bá wù ú kí ó lè mú àwọn ète àti ìlérí òdodo rẹ̀ ṣẹ. Abájọ tó fi ń jẹ́ àwọn orúkọ oyè tó pọ̀ rẹpẹtẹ, bí Ẹlẹ́dàá, Bàbá, Olúwa Ọba Aláṣẹ, Olùṣọ́ Àgùntàn, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Olùgbọ́ àdúrà, Onídàájọ́, Olùkọ́ni Atóbilọ́lá, Olùtúnnirà.—Àwọn Onídàájọ́ 11:27; Sáàmù 23:1; 65:2; 73:28; 89:26; Aísáyà 8:13; 30:20; 40:28; 41:14.

Ọlọ́run tòótọ́ nìkan ṣoṣo ló lè jẹ́ orúkọ náà Jèhófà, nítorí pé àwọn èèyàn ò lè fọwọ́ sọ̀yà pé ohun táwọn wéwèé rẹ̀ yóò kẹ́sẹ járí. (Jákọ́bù 4:13, 14) Jèhófà nìkan ṣoṣo ló lè sọ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ọ̀yamùúmùú òjò ti ń rọ̀, àti ìrì dídì, láti ọ̀run, tí kì í sì í padà sí ibẹ̀, bí kò ṣe pé kí ó rin ilẹ̀ ayé gbingbin ní tòótọ́, kí ó sì mú kí ó méso jáde, kí ó sì rú jáde, tí a sì fi irúgbìn fún afúnrúgbìn àti oúnjẹ fún olùjẹ ní tòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tí ó ti ẹnu mi jáde yóò já sí. Kì yóò padà sọ́dọ̀ mi láìní ìyọrísí, ṣùgbọ́n ó dájú pé yóò ṣe èyí tí mo ní inú dídùn sí, yóò sì ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tí mo tìtorí rẹ̀ rán an.”—Aísáyà 55:10, 11.

Ìmúṣẹ ète Jèhófà dájú, kódà bó tilẹ̀ dà bí ohun tí kò ṣeé ṣe rárá lójú ènìyàn, ó jẹ́ ohun tó ṣeé ṣe lójú rẹ̀. Lẹ́yìn tó ti pẹ́ tí Ábúráhámù, Ísákì, àti Jékọ́bù ti kú, Jésù mẹ́nu kàn wọ́n, ó sì sọ pé: “[Jèhófà] kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, bí kò ṣe ti àwọn alààyè, nítorí gbogbo wọn wà láàyè lójú rẹ̀.” (Lúùkù 20:37, 38) Àwọn baba ńlá mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ló ti kú, ṣùgbọ́n ète Ọlọ́run láti jí wọn dìde dájú pé yóò nímùúṣẹ, àní ó dájú débi pé ńṣe ló dà bí ẹni pé wọ́n ṣì wà láàyè. Mímú àwọn ìránṣẹ́ olóòótọ́ wọ̀nyí padà bọ̀ sí ìyè kò lè ṣòro lójú Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí kò ti ṣòro láti dá ọkùnrin àkọ́kọ́ látinú ekuru ilẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 2:7.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tún fúnni ní àpẹẹrẹ mìíràn tó fi hàn pé Ọlọ́run máa ń mú ète rẹ̀ ṣẹ. Nínú Ìwé Mímọ́, a pe Ábúráhámù ní “baba ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.” (Róòmù 4:16, 17) Nígbà tí Ábúrámù kò tíì bí ọmọ kankan, Jèhófà yí orúkọ rẹ̀ padà sí Ábúráhámù, tó túmọ̀ sí “Baba Ogunlọ́gọ̀ (Ògìdìgbó).” Jèhófà mú kí ìtumọ̀ orúkọ yẹn rí bẹ́ẹ̀ nípa fífi iṣẹ́ ìyanu dá agbára ìbímọ Ábúráhámù arúgbó àti ti Sárà, aya rẹ̀ tí òun náà ti di arúgbó padà.—Hébérù 11:11, 12.

Nítorí agbára àti ọlá àṣẹ tí Jésù Kristi ní, ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun gidi tó kọjá agbára àwọn ẹ̀dá ènìyàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Lásárù, tó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ ti kú, Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Lásárù ọ̀rẹ́ wa ti lọ sinmi, ṣùgbọ́n mo ń rìnrìn àjò lọ sí ibẹ̀ láti jí i kúrò lójú oorun.” (Jòhánù 11:11) Kí nìdí tí Jésù fi sọ pé oorun lásán ni ẹni tó ti kú ń sùn?

Nígbà tí Jésù dé ìlú Lásárù ní Bẹ́tánì, ó lọ sí ibojì náà, ó sì sọ pé kí wọ́n gbé òkúta tí wọ́n gbé dí ẹnu ọ̀nà rẹ̀ kúrò. Lẹ́yìn tó gbàdúrà sókè, ó pàṣẹ pé: “Lásárù, jáde wá!” Bí àwọn òǹwòran ṣì ṣe tẹjú mọ́ ibojì náà, “ọkùnrin tí ó ti kú náà jáde wá pẹ̀lú ẹsẹ̀ àti ọwọ́ rẹ̀ tí a fi àwọn aṣọ ìdìkú dì, ojú rẹ̀ ni a sì fi aṣọ dì yí ká.” Jésù wá sọ pé: “Ẹ tú u, ẹ sì jẹ́ kí ó máa lọ.” (Jòhánù 11:43, 44) Jésù jí Lásárù dìde—ó dá ẹ̀mí ọkùnrin tó ti kú fún odindi ọjọ́ mẹ́rin padà! Kristi ò parọ́ rárá nígbà tó sọ pé oorun ni ọ̀rẹ́ òun ń sùn. Lójú Jèhófà àti Jésù, ńṣe ló dà bíi pé Lásárù wulẹ̀ ń sùn. Dájúdájú, ìdí ohun tó jẹ́ gidi la ti ń bá Jésù àti Baba rẹ̀ ọ̀run.

Jèhófà Lè Jẹ́ Kí Ọwọ́ Wa Tẹ Ohun Tí À Ń Retí

Ẹ ò rí i pé ìyàtọ̀ ńlá ló wà láàárín àwọn òrìṣà tí ń tanni jẹ àti Ọlọ́run gidi! Àwọn abọ̀rìṣà ń fi àìtọ́ rò pé ohun táwọn ń jọ́sìn ní agbára tó ju ti ẹ̀dá lọ. Àmọ́, kò sí bí wọ́n ṣe júbà wọn tó, tí àwọn òrìṣà wọ̀nyí fi lè ní agbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu. Ní ìyàtọ̀ sí ìyẹn, Jèhófà Ọlọ́run lè sọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ti kú tipẹ́ bí ẹni pé wọ́n ṣì wà láàyè nítorí ó ní agbára láti fún wọn ní ìyè lẹ́ẹ̀kan sí i. ‘Ní tòótọ́, Jèhófà ni Ọlọ́run,’ kò sì tan àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ rí.—Jeremáyà 10:10.

Ó mà tuni nínú gan-an o, láti mọ̀ pé nígbà tí ó bá tó àkókò lójú Jèhófà, yóò jí àwọn òkú tó wà ní ìrántí rẹ̀ dìde—ìyẹn ni pé yóò mú wọn padà bọ̀ sí ìyè! (Ìṣe 24:15) Bẹ́ẹ̀ ni o, àjíǹde wé mọ́ mímú irú ẹ̀dá tí ẹnì kan jẹ́ padà bọ̀ sípò. Rírántí irú ẹ̀dá tí àwọn tó ti kú jẹ́ àti jíjí wọn dìde kì í ṣe ìṣòro fún Ẹlẹ́dàá, tó ní ọgbọ́n àti agbára ńlá. (Jóòbù 12:13; Aísáyà 40:26) Níwọ̀n bí Jèhófà ti pọ̀ gidigidi ní ìfẹ́, yóò lo agbára ìrántí rẹ̀ pípé láti mú àwọn òkú padà bọ̀ sí ìyè nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé, yóò sì fún wọn ní gbogbo àkópọ̀ ìwà tí wọ́n ní kí wọ́n tó kú.—1 Jòhánù 4:8.

Bí òpin ayé Sátánì ti ń sún mọ́lé, ó dájú pé ọjọ́ iwájú yóò ṣẹnuure fún àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run tòótọ́. (Òwe 2:21, 22; Dáníẹ́lì 2:44; 1 Jòhánù 5:19) Onísáàmù náà mú un dá wa lójú pé: “Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́; . . . ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” (Sáàmù 37:10, 11) Ìwà ọ̀daràn àti ìwà ipá yóò di ohun àtijọ́. Ìdájọ́ òdodo yóò gbilẹ̀, ìṣòro ìṣúnná owó yóò kọjá lọ. (Sáàmù 37:6; 72:12, 13; Aísáyà 65:21-23) Gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ẹ̀tanú ní ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, ní ti ẹ̀yà, èdè àti ìran yóò pòórá. (Ìṣe 10:34, 35) Ogun àti ohun ìjà ogun kò ní sí mọ́. (Sáàmù 46:9) Ní àkókò yẹn, “kò . . . sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” (Aísáyà 33:24) Gbogbo èèyàn ni ara wọn yóò lè koko. (Ìṣípayá 21:3, 4) Párádísè orí ilẹ̀ ayé yóò dé láìpẹ́. Jèhófà ti ṣèlérí rẹ̀!

Bẹ́ẹ̀ ni o, gbogbo ìrètí tá a gbé ka Bíbélì yóò nímùúṣẹ láìpẹ́. Èé ṣe tí a ó fi jẹ́ kí ohun táwọn èèyàn sọ dòrìṣà nínú ayé yìí tàn wá jẹ nígbà tá a lè ní ìgbọ́kànlé kíkún nínú Jèhófà? Ìfẹ́ rẹ̀ ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tímótì 2:3, 4) Dípò tí a ó fi máa lo gbogbo àkókò wa àti ohun ìní wa sórí àwọn àlá tí kò lè ṣẹ, tàbí ìmúlẹ̀mófo, ti ètò àwọn nǹkan yìí àti ti àwọn ọlọ́run rẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa fi kún ìmọ̀ wa nípa Ọlọ́run tó jẹ́ ẹni gidi, ká sì fi gbogbo ọkàn wa gbẹ́kẹ̀ lé e.—Òwe 3:1-6; Jòhánù 17:3.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Lójú Jèhófà àti Jésù, ńṣe ni Lásárù wulẹ̀ ń sùn

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Párádísè orí ilẹ̀ ayé yóò dé láìpẹ́