Jèhófà Kọ́ Wa ní Ìfaradà àti Ìforítì
Ìtàn Ìgbésí Ayé
Jèhófà Kọ́ Wa ní Ìfaradà àti Ìforítì
GẸ́GẸ́ BÍ ARISTOTELIS APOSTOLIDIS ṢE SỌ Ọ́
Ìlú Pyatigorsk wà ní àríwá ẹsẹ̀ Òkè Ńlá Caucasus, ní ilẹ̀ Rọ́ṣíà. Ìlú yìí lókìkí nítorí ohun àmúṣọrọ̀ tó pọ̀ níbẹ̀ àti nítorí pé ojú ọjọ́ ibẹ̀ tura. Ìlú yìí làwọn òbí mi tí wọ́n jẹ́ Gíríìkì, tí wọ́n sì tún jẹ́ olùwá-ibi-ìsádi bí mi sí ní ọdún 1929. Ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn náà, nígbà tójú àwọn èèyàn ń rí màbo lábẹ́ ìjọba oníkùmọ̀ ti Stanlin, nígbà tí wọ́n ń pa àwọn èèyàn, tí ìdágìrì wọ̀lú, tí ẹsẹ̀ gìrì sì gbòde, tí wọ́n fẹ́ run àwọn ẹ̀yà kan lódindi, tó di bóò-lọ-o-yà-fún-mi, la tún padà di olùwá-ibi-ìsádi, nígbà tá a sá wá sí ilẹ̀ Gíríìsì.
LẸ́YÌN tá a ṣí wá sílùú Piraiévs, nílẹ̀ Gíríìsì, ni ọ̀rọ̀ náà “olùwá-ibi-ìsádi” wá ní ìtumọ̀ tuntun pátápátá lọ́kàn wa. A wá di àjèjì pátápátá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé orúkọ àwọn gbajúmọ̀ ọ̀mọ̀ràn Gíríìkì méjì lèmi àti ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin ń jẹ́, ìyẹn Socrates àti Aristotle, a kì í fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ káwọn èèyàn máa pè wá ní orúkọ yẹn mọ́. Orúkọ tí gbogbo èèyàn ń pè wá ni àwọn ọmọ Rọ́ṣíà kéékèèké.
Kété lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ́ sílẹ̀ ni ìyá mi ọ̀wọ́n kú. Òun ni ìdílé wa gbójú lé, ikú rẹ̀ sì gbò wá gidigidi. Níwọ̀n bí ó ti wà lẹ́nu àìsàn náà fún sáà kan, ó ti kọ́ mi ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ilé. Àwọn ohun tó kọ́ mi yìí wúlò fún mi gan-an nígbà tó yá.
Ogun àti Òmìnira
Ogun náà àti ìjọba Násì tó ṣígun wá, àtàwọn ọmọ ogun Onígbèjà ti ń rọ̀jò bọ́ǹbù sórí ìlú wa láìdábọ̀, jẹ́ kí ojúmọ́ kọ̀ọ̀kan dà bí ọjọ́ tá a máa lò kẹ́yìn láyé. Òṣì ń ta àwọn èèyàn, ebi fẹ́rẹ̀ẹ́ yọjú àwọn míì, bẹ́ẹ̀ náà ni àìmọye èèyàn ń kàgbákò ikú. Láti ẹni ọdún mọ́kànlá ni mo ti ń ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó pẹ̀lú
bàbá mi kí àwa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta lè rí nǹkan fi gbọ́ bùkátà ara wa. Àgbọ́ọ̀gbọ́tán èdè Gíríìkì àti ogun àti oríṣiríṣi wàhálà tó dé lẹ́yìn ogun náà dí ẹ̀kọ́ mi lọ́wọ́.Àwọn ọmọ ogun Jámánì tó ṣígun wá sí Gíríìsì kógun wọn lọ ní October 1944. Láìpẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ni mo bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé. Ìbànújẹ́ tó dorí mi kodò, tílé ayé fi sú mi poo, jẹ́ kí ìrètí tí Bíbélì sọ nípa ọjọ́ ọ̀la gbígbámúṣé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run wọ̀ mí lọ́kàn. (Sáàmù 37:29) Ìlérí Ọlọ́run nípa ìwàláàyè tí kò lópin nínú àlàáfíà níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé tù mí lára pẹ̀sẹ̀. (Aísáyà 9:7) Ọdún 1946 lèmi àti bàbá mi ṣèrìbọmi, láti fi ẹ̀rí hàn pé a ti ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà.
Inú mi dùn gan-an lọ́dún tó tẹ̀ lé nígbà tá a yàn mí gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ tí ń bójú tó ìpolongo (tá a wá ń pè ní ìránṣẹ́ tí ń bójú tó ìwé ìròyìn) nínú ìjọ kejì tá a dá sílẹ̀ nílùú Piraiévs. Ìpínlẹ̀ wa nasẹ̀ láti Piraiévs títí lọ dé ìlú Eleusis, tí í ṣe nǹkan bí àádọ́ta kìlómítà. Ọ̀pọ̀ Kristẹni ẹni àmì òróró ló ń sìn nínú ìjọ náà nígbà yẹn. Mo láǹfààní láti bá wọn ṣiṣẹ́, mo sì rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára wọn. Mo gbádùn ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ wọn nítorí pé àìmọye ìrírí ni wọ́n sọ nípa bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe gba akitiyan. Ọ̀nà ìgbésí ayé wọn jẹ́ kí n rí i kedere pé fífi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà gba sùúrù àti ìforítì tí kò kéré. (Ìṣe 14:22) Ẹ wo bí inú mi ti dùn tó pé ìjọ tó wà lágbègbè yìí lónìí ti lé ní àádọ́ta!
Ìṣòro Àìròtẹ́lẹ̀
Ní àkókò kan lẹ́yìn náà lèmi àti ọ̀dọ́bìnrin Kristẹni awẹ́lẹ́wà kan tó ń gbé nílùú Patras, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Eleni rí ara wa. A bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ra sọ́nà ní apá ìparí ọdún 1952. Àmọ́ oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, àìsàn burúkú kan kọlu Eleni. Àwọn dókítà sọ pé kókó kan wà nínú ọpọlọ rẹ̀, wọn ò sì mọbi tí ọ̀ràn náà lè já sí. Wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ abẹ fún un lójú ẹsẹ̀. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ wàhálà, a jàjà rí dókítà kan nílùú Áténì tó sọ pé òun fara mọ́ ìgbàgbọ́ wa àti pé òun ṣe tán láti ṣe iṣẹ́ abẹ náà láìlo ẹ̀jẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò fi bẹ́ẹ̀ sí àwọn ohun èlò tó wà lóde òní láyé ìgbà yẹn. (Léfítíkù 17:10-14; Ìṣe 15:28, 29) Lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ náà, àwọn dókítà fi mí lọ́kàn balẹ̀ díẹ̀ pé àfẹ́sọ́nà mi á yè é, àmọ́ wọn ò lè fi gbogbo ẹnu sọ pé àìsàn yẹn ò ní padà wá.
Èwo wá ni ṣíṣe báyìí? Níbi tọ́ràn dé yìí, ṣé kò ní dáa kí n já àfẹ́sọ́nà mi jù sílẹ̀ báyìí, kí n yọ ara mi nínú wàhálà? Rárá o! Níwọ̀n bí mo ti sọ fún un pé màá fẹ́ ẹ, mo fẹ́ kí bẹ́ẹ̀ ni mi jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni. (Mátíù 5:37) Mi ò tiẹ̀ jẹ́ kí ọkàn mi ronú lọ sórí jíjá a jù sílẹ̀ rárá ni. Ọ̀dọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin ni Eleni wà tó ń gba ìtọ́jú. Nígbà tí ara rẹ̀ sì yá díẹ̀, a ṣègbéyàwó ní December 1954.
Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà làìsàn ọ̀hún tún dé sí Eleni lára. Dókítà kan náà sì ṣe iṣẹ́ abẹ mìíràn fún un. Lọ́tẹ̀ yìí, ó ṣiṣẹ́ wọnú ọpọlọ rẹ̀ gan-an láti mú kókó náà kúrò pátápátá. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé apá kan ara ìyàwó mi rọ. Ó tún ṣàkóbá fún apá tó ń darí ọ̀rọ̀ sísọ nínú ọpọlọ. Àwọn òkè ìṣòro dídíjú mìíràn
wá dojú kọ wá wàyí. Kódà iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ wá di ẹtì fún aya mi ọ̀wọ́n. Hẹ́gẹhẹ̀gẹ tí òkùnrùn yìí sọ ìyàwó mi dà wá jẹ́ kó di kàráǹgídá fún wa láti yí ìgbésí ayé wa padà pátápátá. Lékè gbogbo rẹ̀, ó gba ìfaradà àti ìforítì gidi.Ìsinsìnyí ni ẹ̀kọ́ tí ìyá mi kọ́ mi wá wúlò gan-an. Lójoojúmọ́ ní òwúrọ̀ hàì, màá ṣètò gbogbo èròjà tá a máa fi se oúnjẹ, Eleni á wá sè é. Lemọ́lemọ́ la máa ń pe àwọn àlejò, títí kan àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún àtàwọn tá a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn Kristẹni tó jẹ́ aláìní nínú ìjọ wa. Wọ́n máa ń sọ pé oúnjẹ yìí mà dùn o! Èmi àti Eleni tún ń ran ara wa lọ́wọ́ nínú àwọn iṣẹ́ ilé yòókù. Ìyẹn ló jẹ́ kí ilé wa mọ́, tí kò sì rí wúruwùru. Ọgbọ̀n ọdún gbáko la fi wà nínú ipò lílekoko yìí.
Jíjẹ́ Onítara Láìfi Àìlera Pè
Ó jọ èmi àtàwọn mìíràn lójú pé kò sí nǹkan tó lè paná ìfẹ́ tí ìyàwó mi ní fún Jèhófà àti ìtara tó ní fún iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Bí àkókò ti ń lọ, Eleni bẹ̀rẹ̀ sí tiraka láti pe àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀-dìẹ̀-díẹ̀. Ó fẹ́ láti máa sọ ìhìn rere Bíbélì fáwọn èèyàn lójú pópó. Nígbà tíṣẹ́ bá gbé mi lọ sí àjò, tèmi tirẹ̀ jọ ń lọ ni. Mo máa ń gbé ọkọ̀ sí ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà ibi táwọn èrò ń gbà kọjá. Ó máa ń yọjú látinú ọkọ̀, á sì máa fi Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọ àwọn èrò tí ń lọ. Lọ́jọ́ kan, ó fi ọgọ́rin ìwé ìròyìn síta láàárín wákàtí méjì. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló ń fi gbogbo ògbólógbòó ìwé ìròyìn tá a ní nínú ìjọ síta. Eleni tún ń kópa nínú àwọn ọ̀nà ìjẹ́rìí mìíràn déédéé.
Ní gbogbo ọdún tí ìyàwó mi fi jẹ́ abirùn ló máa ń bá mi lọ sí ìpàdé. Kò pa àpéjọ kan jẹ rí, kódà nígbà tó bá di dandan pé ká rìnrìn àjò lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn nítorí inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Gíríìsì. Láìfi àìlera rẹ̀ pè, tayọ̀tayọ̀ ló fi lọ sí àpéjọ tí a ṣe ní orílẹ̀-èdè Austria, Jámánì, Cyprus àtàwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Eleni kò ráhùn rí, bẹ́ẹ̀ ni kì í fi tirẹ̀ ni ẹnikẹ́ni lára, kódà nígbà tí àfikún ẹrù iṣẹ́ tí mo ní nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà bá mú kí nǹkan nira fún un nígbà míì.
Ní tèmi, ipò yìí jẹ́ kí n kọ́ béèyàn ṣe ń ní ìfaradà àti ìforítì fún àkókò gígùn. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo rí ọwọ́ Jèhófà lára mi. Àwọn ará fi ọ̀pọ̀ nǹkan du ara wọn kí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́ ní gbogbo ọ̀nà. Àwọn dókítà sì dúró tì wá gbágbáágbá. Ní gbogbo ọdún lílekoko wọ̀nyẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ àbọ̀ṣẹ́ ni mo ráyè ṣe nítorí òkè ìṣòro tí à ń bá yí, kò sígbà tí a kò ní ohun kòṣeémánìí. Àwọn nǹkan tẹ̀mí àti iṣẹ́ ìsìn Jèhófà la máa ń fi sí ipò àkọ́kọ́.—Mátíù 6:33.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti béèrè ohun tó mẹ́sẹ̀ wa dúró ní àkókò ìṣòro yìí. Bí mo ti ń wẹ̀yìn wò báyìí, mo rí i pé ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àdúrà àtọkànwá sí Ọlọ́run, lílọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé àti fífi tìtaratìtara lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ìwàásù náà ló jẹ́ ká túbọ̀ ní ìfaradà àti ìforítì. Ìgbà gbogbo ni ọ̀rọ̀ ìṣírí tó wà nínú Sáàmù 37:3-5 máa ń wá sọ́kàn wa. Ó kà pé: “Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí o sì máa ṣe rere; . . . Máa ní inú dídùn kíkọyọyọ nínú Jèhófà . . . Yí ọ̀nà rẹ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà, kí o sì gbójú lé e, òun yóò sì gbé ìgbésẹ̀.” Ẹsẹ mìíràn tó tún ràn wá lọ́wọ́ gan-an ni Sáàmù 55:22, tó kà pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró.” Bí ọmọ tó gbọ́kàn lé bàbá rẹ̀ pátápátá, a ò wulẹ̀ ju ẹrù ìnira wa sọ́dọ̀ Jèhófà, ṣùgbọ́n a tún fi í sílẹ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú.—Jákọ́bù 1:6.
Ní April 12, 1987, nígbà tí ìyàwó mi ń wàásù níwájú ilé wa, ilẹ̀kùn irin wíwúwo kan ṣí látẹ̀yìn rẹ̀, ó sì gbá a sójú ọ̀nà, ó ṣe é léṣe gan-an. Èyí mú kó dákú lọ gbári fún odindi ọdún mẹ́ta, tó sì wá kú lẹ́yìn náà níbẹ̀rẹ̀ ọdún 1990.
Mo Fi Gbogbo Agbára Mi Sin Jèhófà
Lẹ́yìn lọ́hùn-ún lọ́dún 1960 ni wọ́n yàn mí láti máa sìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ ìjọ ní Nikaia, nílùú Piraiévs. Látìgbà yẹn, mo ti láǹfààní láti sìn ní àwọn ìjọ mélòó kan ní Piraiévs. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò bímọ, síbẹ̀ inú mi dùn pé ó ṣeé ṣe fún mi láti ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ nípa tẹ̀mí lọ́wọ́ láti dúró ṣinṣin nínú òtítọ́. Àwọn kan lára wọn ń sìn báyìí gẹ́gẹ́ bí alàgbà ìjọ, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, aṣáájú ọ̀nà àti ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì.
Nígbà tí ìjọba tiwa-n-tiwa tún fìdí múlẹ̀ nílẹ̀ Gíríìsì ní 1975, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láǹfààní láti máa ṣe àpéjọ wọn ní fàlàlà, láìsí pé wọ́n ń yọ́ ọ ṣe nínú igbó mọ́. Ìrírí tí ọ̀pọ̀ nínú wa ti ní nígbà tá à ń ṣètò àpéjọ ní orílẹ̀-èdè mìíràn wá wúlò gan-an báyìí. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé mo ní ayọ̀ àti àǹfààní sísìn nínú onírúurú ìgbìmọ̀ àpéjọ fún ọ̀pọ̀ ọdún.
Nígbà tó wá di ọdún 1979, wọ́n ní ká kọ́ Gbọ̀ngàn Àpéjọ àkọ́kọ́ nílẹ̀ Gíríìsì, sí ẹ̀yìn odi ìlú Áténì. Wọ́n ní kí n ṣètò, kí n sì bójú tó iṣẹ́ ìkọ́lé ńlá yìí. Iṣẹ́ yìí tún gba ọ̀pọ̀ ìfaradà àti ìforítì. Bíbá ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ ṣiṣẹ́ fún odindi ọdún mẹ́ta mú kí ìdè ìfẹ́ àti ìrẹ́pọ̀ tó lágbára wà láàárín wa. Mánigbàgbé làwọn ìrírí tí mo ní lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé yìí.
Bíbójútó Àìní Tẹ̀mí Àwọn Ẹlẹ́wọ̀n
Àǹfààní kan ṣí sílẹ̀ ní ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà. Ìpínlẹ̀ tó wà nítòsí ìjọ mi nílùú Korydallos ni ọgbà ẹ̀wọ̀n tó tóbi jù lọ nílẹ̀ Gíríìsì wà. Láti April 1991 ni wọ́n ti yàn mí láti máa bẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n yìí wò lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n gbà mí láyè láti máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níbẹ̀, kí èmi àtàwọn ẹlẹ́wọ̀n tó bá fìfẹ́ hàn jùmọ̀ máa ṣe àwọn ìpàdé Kristẹni. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ti ṣe ìyípadà kíkàmàmà, tó fi bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lágbára tó hàn. (Hébérù 4:12) Èyí jẹ́ ìwúrí ńláǹlà fáwọn òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n àtàwọn ẹlẹ́wọ̀n míì. Àwọn kan lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí mo kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti jáde lẹ́wọ̀n, wọ́n sì ti di akéde ìhìn rere náà báyìí.
Mo bá àwọn ògbóǹtagí oníṣòwò oògùn olóró mẹ́ta kan ṣèkẹ́kọ̀ọ́ fún sáà kan. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Nígbà tí wọ́n bá ń bọ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n á fárùngbọ̀n, wọ́n á ya irun wọn, wọ́n á wọ ṣẹ́ẹ̀tì, wọ́n á sì de táì mọ́rùn, kódà láàárín oṣù August—tí ooru ń mú burúkú-burúkú nílẹ̀ Gíríìsì! Olùdarí ọgbà ẹ̀wọ̀n àti ọ̀gá wọ́dà, àtàwọn òṣìṣẹ́ míì máa ń sáré jáde látinú ọ́fíìsì wọn láti wá wo nǹkan àrà tó ń ṣẹlẹ̀ yìí. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún wọn!
Ìrírí mìíràn tó wúni lórí tún wáyé níbi táwọn obìnrin wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n náà. A bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú obìnrin kan tó ń ṣẹ̀wọ̀n gbére torí pé ó pààyàn. Gbogbo èèyàn ló mọ̀ pé jàǹdùkú ni. Àmọ́ láìpẹ́ láìjìnnà, òtítọ́ Bíbélì tó ń kọ́ mú kó ṣe àwọn ìyípadà tó kàmàmà, dépò pé ọ̀pọ̀ èèyàn sọ pé ńṣe ló dà bíi kìnnìún tó wá di ọ̀dọ́ àgùntàn! (Aísáyà 11:6, 7) Kò pẹ́ rárá tí olùdarí ọgbà ẹ̀wọ̀n náà fi bẹ̀rẹ̀ sí fojú èèyàn gidi wò ó, tó sì gbẹ́kẹ̀ lé e. Inú mi dùn pé ó ń tẹ̀ síwájú gan-an nípa tẹ̀mí, dórí yíya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà.
Ríran Àwọn Aláìlera Àtàwọn Arúgbó Lọ́wọ́
Rírí tí mo rí àìsàn burúkú tó fìtínà ìyàwó mi fún àkókò gígùn jẹ́ kí ìṣòro àwọn aláìsàn àtàwọn àgbàlagbà máa ká mi lára. Gbogbo ìgbà tí àwọn ìtẹ̀jáde wa bá gbà wá níyànjú láti dé ọ̀dọ̀ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ láti fi tìfẹ́tìfẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́ ni irú ìṣírí bẹ́ẹ̀ máa ń gbún mi ní kẹ́ṣẹ́. Ìṣúra ni irú àpilẹ̀kọ bẹ́ẹ̀ jẹ́, mo sì máa ń tọ́jú wọn pa mọ́. Lẹ́yìn ọdún mélòó kan, mo ti wá ní àpilẹ̀kọ tó lé ní ọgọ́rùn-ún—bẹ̀rẹ̀ látorí àpilẹ̀kọ náà “Bíbìkítà Fáwọn Àgbàlagbà Àtàwọn Tó Wà Nínú Ìpọ́njú” èyí tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ July 15, 1962, lédè Gẹ̀ẹ́sì. Ọ̀pọ̀ irú àpilẹ̀kọ wọ̀nyí fi hàn pé ó dáa kí ìjọ kọ̀ọ̀kan ṣètò ìrànlọ́wọ́ fáwọn aláìlera àtàwọn àgbàlagbà.—1 Jòhánù 3:17, 18.
Àwọn alàgbà ṣètò pé kí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn máa bójú tó àìní àwọn aláìlera àtàwọn arúgbó tó wà nínú ìjọ wa. A pín àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Àwọn kan wà tí ń ṣèrànwọ́ lójú mọmọ, àwọn míì ń ṣèrànwọ́ ní gbogbo òru, àwọn tó lè fi ohun ìrìnnà ṣèrànwọ́ tún wà, bẹ́ẹ̀ làwọn tó máa wà lárọ̀ọ́wọ́tó látàárọ̀ ṣúlẹ̀ tún wà. Àwọn tá a mẹ́nu kàn gbẹ̀yìn wọ̀nyí wúlò gan-an nígbà pàjáwìrì.
Ìṣètò yìí ṣiṣẹ́ gan-an ni. Fún àpẹẹrẹ, ilẹ̀ẹ́lẹ̀ níbi tí arábìnrin kan tó ń dá gbé, tí ara rẹ̀ kò sì yá, dákú sí la bá a nígbà tá a lọ bẹ̀ ẹ́ wò lọ́jọ́ kan. Kíá la kàn sí arábìnrin kan tó ń gbé nítòsí, tó ní ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́. Ó gbé arábìnrin tó dákú náà lọ sí ọsibítù tó wà nítòsí lójú ẹsẹ̀—àní sẹ́ láàárín ìṣẹ́jú mẹ́wàá péré! Àwọn dókítà sọ pé ìyẹn ló gba ẹ̀mí rẹ̀ là.
Bí àwọn aláìlera àtàwọn àgbàlagbà ṣe ń dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn wọ̀nyí ń mú inú wọn dùn lọ́pọ̀lọpọ̀. Ìrètí gbígbé pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọ̀nyí nínú ètò tuntun Ọlọ́run lábẹ́ àwọn ipò tó yàtọ̀ ń múni lọ́kàn yọ̀. Mímọ̀ tí wọ́n mọ̀ pé ìtìlẹyìn àwọn ará wọ̀nyí wà lára ohun tó jẹ́ káwọn lè fàyà rán àwọn ìṣòro náà tún jẹ́ èrè mìíràn.
Ìforítì Ti Mú Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Èrè Wá
Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, mò ń sìn bí alàgbà ní ọ̀kan lára ìjọ tó wà nílùú Piraiévs. Láìka ọjọ́ ogbó àti àìlera tí mo ń bá yí sí, inú mi dùn pé mo ṣì ń sa gbogbo ipá mi nínú ìgbòkègbodò ìjọ.
Ní gbogbo ọdún wọ̀nyí, àwọn ipò lílekoko, àwọn ìṣòro tí ń kóni láyà sókè, àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rò tì, ti jẹ́ kó di dandan pé kí n mọwọ́ yí padà, kí n sì ní ìforítì. Síbẹ̀, ìgbà gbogbo ni Jèhófà ń fún mi lókun tí mo nílò láti lè borí ìṣòro wọ̀nyí. Léraléra ni mo ti rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ onísáàmù náà, pé: “Nígbà tí mo wí pé: ‘Ṣe ni ẹsẹ̀ mi yóò máa rìn tàgétàgé,’ Jèhófà, inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ni ó ń gbé mi ró. Nígbà tí ìrònú tí ń gbé mi lọ́kàn sókè di púpọ̀ nínú mi, ìtùnú tìrẹ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣìkẹ́ ọkàn mi.”—Sáàmù 94:18, 19.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Èmi àti Eleni, ìyàwó mi, lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ kejì tí wọ́n ṣe fún un lọ́dún 1957
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ní àpéjọpọ̀ nílùú Nuremberg, ní Jámánì, lọ́dún 1969
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Àwọn ará tí ń ran àwọn aláìsàn àtàwọn àgbàlagbà lọ́wọ́