Ṣọ́ọ̀ṣì Àti Ìjọba Ní Ilẹ̀ Ọba Byzantium
Ṣọ́ọ̀ṣì Àti Ìjọba Ní Ilẹ̀ Ọba Byzantium
ẸNI tó dá ẹ̀sìn Kristẹni sílẹ̀ kò fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ rárá nípa ìyàtọ̀ tó gbọ́dọ̀ wà láàárín àwọn ọmọlẹ́yìn òun àti aráyé tó ti kẹ̀yìn sí Ọlọ́run. Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Bí ẹ̀yin bá jẹ́ apá kan ayé, ayé yóò máa ní ìfẹ́ni fún ohun tí í ṣe tirẹ̀. Wàyí o, nítorí pé ẹ kì í ṣe apá kan ayé, ṣùgbọ́n mo ti yàn yín kúrò nínú ayé, ní tìtorí èyí ni ayé fi kórìíra yín.” (Jòhánù 15:19) Jésù sọ fún Pílátù tó jẹ́ aṣojú ètò ìṣèlú tó wà nígbà ayé rẹ̀ pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.”—Jòhánù 18:36.
Kí àwọn Kristẹni lè ṣe ojúṣe wọn láti wàásù “dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé,” wọ́n ní láti yẹra fún jíjẹ́ kí àwọn nǹkan ti ayé pín ọkàn wọn níyà. (Ìṣe 1:8) Bíi ti Jésù, àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ kò kópa nínú ìṣèlú. (Jòhánù 6:15) Ó sì hàn gbangba pé àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í di ipò òṣèlú mú. Àmọ́, èyí yí padà nígbà tó yá.
“Apá Kan Ayé”
Nígbà tó ṣe díẹ̀ lẹ́yìn ikú èyí tó kẹ́yìn nínú àwọn àpọ́sítélì, àwọn aṣáájú ìsìn bẹ̀rẹ̀ sí dìídì yí èrò wọn padà nípa ohun tó yẹ kó pa àwọn àti ayé pọ̀. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fọkàn yàwòrán “ìjọba” kan, tí kì í ṣe pé ó wà nínú ayé nìkan, àmọ́ tó jẹ́ apá kan rẹ̀ pàápàá. Ṣíṣàgbéyẹ̀wò bí ìsìn àti ìṣèlú ṣe so kọ́ra ní Ilẹ̀ Ọba Byzantium—tó wà ní Ìlà Oòrùn Ilẹ̀ Ọba Róòmù, tí Byzantium (Istanbul nísinsìnyí) jẹ́ olú ìlú rẹ̀—yóò jẹ́ kí ohun tá à ń sọ yé wa dáadáa.
Nínú àwùjọ kan tí ìsìn ti kó ipa tó lágbára, Ṣọ́ọ̀ṣì ìlú Byzantium rọ́wọ́ mú gan-an ni. Ọ̀gbẹ́ni Panayotis Christou, tí í ṣe òpìtàn nípa ṣọ́ọ̀ṣì fìgbà kan sọ pé: “Àwọn ará Byzantium ka ilẹ̀ ọba wọn orí ilẹ̀ ayé sí ohun tó dúró fún Ìjọba Ọlọ́run.” Àmọ́, àwọn aláṣẹ ilẹ̀ ọba náà kì í sábà fara mọ́ èrò yẹn. Nítorí ìdí èyí, àárín Ṣọ́ọ̀ṣì àti Ìjọba kì í gún láwọn ìgbà mìíràn. Ìwé atúmọ̀ èdè náà, The Oxford Dictionary of Byzantium, sọ pé: “Onírúurú ìwà làwọn bíṣọ́ọ̀bù Constantinople [ìyẹn Byzantium] ń hù, títí kan pípá kúbẹ́kúbẹ́ lábẹ́ alákòóso kan tó jẹ́ alágbára . . . , lílẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú ọba . . . , àti fífi ìgboyà lòdì sí ohun tó jẹ́ ìfẹ́ inú olú ọba.”
Bíṣọ́ọ̀bù Constantinople, tó jẹ́ olórí Ṣọ́ọ̀ṣì Ìlà Oòrùn, wá di abẹnugan. Òun ni afọbajẹ. Ó sì retí pé kí olú ọba tìtorí ìyẹn máa gbèjà ẹ̀kọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì wọn lójú méjèèjì. Bíṣọ́ọ̀bù tún lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀, nítorí pé ìkáwọ́ rẹ̀ ni dúkìá rẹpẹtẹ tí ṣọ́ọ̀ṣì ní wà. Agbára rẹ̀ jẹ́ kó ní ọlá àṣẹ lórí àìmọye àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé àtàwọn ọmọ ìjọ.
Bíṣọ́ọ̀bù lè fọwọ́ pa idà olú ọba lójú dáadáa. Ó lè sọ pé òun yọ ọ́ kúrò nínú ìjọ—kó máa ṣe ìfẹ́ inú rẹ̀ lórúkọ Ọlọ́run—tàbí kó dá ọgbọ́n mìíràn tó lè mú kí wọ́n rọ olú ọba lóyè.
Bí agbára ìjọba ṣe ń dín kù láwọn ibi tí kì í ṣe olú ìlú ni àwọn bíṣọ́ọ̀bù wá ń di ẹni tó lágbára jù lọ láwọn ìlú ńlá, àní agbára wọn bá táwọn gómìnà pàápàá dọ́gba, àwọn ló kúkú yan gómìnà ọ̀hún síbẹ̀. Àwọn bíṣọ́ọ̀bù ló ń bójú tó ọ̀ràn ìgbẹ́jọ́ àti iṣẹ́ ajé níbikíbi tí ọ̀ràn náà bá ti kan ṣọ́ọ̀ṣì—kódà bí ò tiẹ̀ kàn wọ́n pàápàá. Ohun tó tún jẹ́ kí ọ̀ràn náà rí bẹ́ẹ̀ ni pé àwọn àlùfáà àtàwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé, tí ń bẹ lábẹ́ àwọn bíṣọ́ọ̀bù àdúgbò pọ̀ rẹpẹtẹ, àní iye wọn ń lọ sí ẹgbẹẹgbàárùn-ún.
Ìṣèlú àti Ríra Ipò
Gẹ́gẹ́ bí ohun tó wà lókè yìí ti fi hàn, iṣẹ́ pásítọ̀ àti ọ̀ràn ìṣèlú wá di ọ̀kan náà. Ìyẹn nìkan kọ́ o, àní èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn àlùfáà àti àwọn ìgbòkègbodò
wọn wá ń mú owó gọbọi wọlé. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn àlùfáà tó wà nípò gíga ló ń gbé ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ. Bí ṣọ́ọ̀ṣì ṣe túbọ̀ ń ní agbára àti ọrọ̀ sí i ni ọ̀ràn ipò òṣì àti ìjẹ́mímọ́ àwọn àpọ́sítélì ń pòórá. Àwọn àlùfáà àtàwọn bíṣọ́ọ̀bù kan fowó ra ipò wọn. Ríra ipò wá di ti gbogbo gbòò látorí ipò kékeré títí dórí àwọn ipò tó ga jù lọ. Àwọn àlùfáà, tí àwọn ọlọ́rọ̀ tó jẹ́ abẹnugan láwùjọ ń tì lẹ́yìn, wá bẹ̀rẹ̀ sí du àwọn oyè ṣọ́ọ̀ṣì níwájú olú ọba.Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ wá di ohun tí wọ́n fi ń fa ojú àwọn aṣáájú ìsìn mọ́ra. Nígbà tí Ọbabìnrin Zoe (tó gbé ayé ní nǹkan bí ọdún 978 sí 1050 Sànmánì Tiwa) ṣekú pa Romanus Kẹta, tí í ṣe ọkọ rẹ̀, tó sì fẹ́ẹ́ fẹ́ olólùfẹ́ rẹ̀ tó máa di Olú Ọba Michael Kẹrin, kíákíá ló pàṣẹ pé kí Bíṣọ́ọ̀bù Alexius yọjú sóun ní ààfin. Ibẹ̀ ni bíṣọ́ọ̀bù ọ̀hún ti gbọ́ nípa ikú Romanus àti ìsìn ìgbéyàwó tí ọbabìnrin yìí fẹ́ kí bíṣọ́ọ̀bù wá bá òun ṣe. Ayẹyẹ ọjọ́ Good Friday tí ṣọ́ọ̀ṣì náà ń ṣe lálẹ́ ọjọ́ yẹn ṣòroó pa tì fún Alexius. Síbẹ̀, ó gba ẹ̀bùn ńlá tí olú ọba obìnrin náà fún un, ó ṣì ṣe ohun tó fẹ́ fún un.
Pípá Kúbẹ́kúbẹ́ Lábẹ́ Olú Ọba
Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, nínú ìtàn Ilẹ̀ Ọba Byzantium, olú ọba máa ń lo agbára rẹ̀ láti yan ẹni tó wù ú sípò bíṣọ́ọ̀bù Constantinople. Ní irú àkókò yẹn, kò sí ẹni tó lè di bíṣọ́ọ̀bù láìjẹ́ pé olú ọba fọwọ́ sí i, kò sì sẹ́ni tó lè pẹ́ lórí oyè náà láìjẹ́ pé olú ọba fẹ́ bẹ́ẹ̀.
Olú Ọba Andronicus Kejì (láti 1260 sí 1332) rí i pé ó pọn dandan fún òun láti pààrọ̀ àwọn bíṣọ́ọ̀bù nígbà mẹ́sàn-án ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ohun tó fa èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ìyípadà yẹn ni láti fi àwọn tó bá máa gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu sórí oyè. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé náà, The Byzantines, wí, bíṣọ́ọ̀bù kan tiẹ̀ kọ ìlérí rẹ̀ fún olú ọba sínú ìwé, pé “láti ṣe ohunkóhun tó bá béèrè, bó ti wù kó lòdì sófin tó, àti láti yẹra fún ṣíṣe ohunkóhun tí inú rẹ̀ kò bá dùn sí.” Ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àwọn olú ọba gbìyànjú láti lo agbára wọn lórí ṣọ́ọ̀ṣì nípa fífi ẹni tó tinú ìdílé ọba wá jẹ oyè bíṣọ́ọ̀bù. Olú Ọba Romanus Kìíní gbé ọmọ rẹ̀ Theophylact, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún péré gorí oyè bíṣọ́ọ̀bù.
Bí bíṣọ́ọ̀bù kan bá kùnà láti múnú olú ọba dùn, ó lè sọ pé kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ fi ipò rẹ̀ sílẹ̀ tàbí kó pàṣẹ fún ẹgbẹ́ alákòóso ṣọ́ọ̀ṣì pé kí wọ́n lé e dànù. Ìwé náà, Byzantium, sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ló ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn ilẹ̀ ọba Byzantium pé àwọn aláṣẹ onípò gíga àti Olú Ọba alára ló kó apá tó pọ̀ jù lọ nínú yíyan àwọn bíṣọ́ọ̀bù sórí oyè.”
Olú ọba tún máa ń ṣe alága níbi àwọn àpérò ṣọ́ọ̀ṣì, tí bíṣọ́ọ̀bù yóò sì dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Òun ló máa ń darí àwọn àríyànjiyàn, òun ló máa lànà ẹ̀kọ́ ìsìn, ó si máa ń bá àwọn bíṣọ́ọ̀bù àtàwọn aládàámọ̀ jiyàn, ẹni tó bá bá a jiyàn jù—ikú lórí igi oró ni ìyà rẹ̀. Olú ọba náà ló tún máa ń fìdí àwọn òfin tí wọ́n bá gbé kalẹ̀ láwọn ibi àpérò múlẹ̀, òun ló sì máa ń rí sí i pé wọ́n mú un lò. Kì í ṣe pé ó ń fi ẹ̀sùn ìdìtẹ̀ síjọba kan àwọn tó bá lòdì sí i nìkan ni, àmọ́ ó tún ń kà wọ́n sí ọ̀tá ṣọ́ọ̀ṣì àti ọ̀tá Ọlọ́run. Bíṣọ́ọ̀bù kan ní ọ̀rúndún kẹfà sọ pé: “Kò sẹ́ni tó gbọ́dọ̀ ṣe nǹkan kan tó lòdì sí ìfẹ́ àti àṣẹ Olú Ọba ní Ṣọ́ọ̀ṣì.” Àwọn bíṣọ́ọ̀bù tí ń bẹ láàfin—àwọn
dọ̀bọ̀sìyẹsà, ọ̀rẹ́-ò-dénú gbogbo, tó rọrùn láti fi àpọ́nlé àti ọ̀rọ̀ dídùndídùn fajú wọn mọ́ra—kàn gbẹ́nu dákẹ́ ni, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀gá wọn ṣe gbẹ́nu dákẹ́.Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Bíṣọ́ọ̀bù Ignatius (nǹkan bíi 799 sí 878 Sànmánì Tiwa) kọ̀ láti fún Mínísítà Àgbà Bardas ní Ara Olúwa, mínísítà náà gbọ̀nà ẹ̀bùrú yọ sí i. Bardas kó bá Ignatius nígbà tí ọ̀ràn ìdìtẹ̀-gbàjọba kan wáyé. Wọ́n fàṣẹ ọba mú bíṣọ́ọ̀bù náà, wọ́n sì lé e dànù. Nígbà tí wọ́n wá fẹ́ fi ẹlòmíràn rọ́pò rẹ̀, mínísítà náà yan Photius, ọ̀gbẹ̀rì kan, tó jẹ́ pé àárín ọjọ́ mẹ́fà péré ló fi dé ipò tó ga jù nínú oyè ṣọ́ọ̀ṣì, tó sì wá di ẹni tí wọ́n fi jẹ oyè bíṣọ́ọ̀bù ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀. Ǹjẹ́ Photius tóótun láti wà ní ipò tẹ̀mí yẹn? Irú èèyàn tí wọ́n sọ pé ó jẹ́ ni ẹni tó “ń lépa ipò ọlá lójú méjèèjì, tó jọra ẹ̀ lójú bí nǹkan míì, tó sì jẹ́ ògbóǹtagí nínú ọ̀ràn ìṣèlú.”
Ẹ̀kọ́ Ìsìn Tí Wọ́n Gbé Kalẹ̀ Nítorí Ìṣèlú
Aáwọ̀ nínú ọ̀ràn ìṣèlú pọ́ńbélé ni ọ̀pọ̀ olú ọba ń jà lé, tí wọ́n kàn ń fi ọ̀ràn nípa ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì àtàwọn aládàámọ̀ bojú, bí ẹni pé ìfẹ́ láti gbé ẹ̀kọ́ tuntun jáde ló jẹ àwọn lógún. Ní gbogbo gbòò, olú ọba ló lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ ohun tó jẹ́ ẹ̀kọ́ ìsìn, ó sì máa rí sí i pé ṣọ́ọ̀ṣì ṣègbọràn sí ohun tó jẹ́ ìfẹ́ inú òun.
Fún àpẹẹrẹ, Olú Ọba Heraclius (575 sí 641 Sànmánì Tiwa) sa gbogbo ipá rẹ̀ láti yanjú àìfohùnṣọ̀kan tó wáyé nípa irú ẹni tí Kristi jẹ́, èyí tó fẹ́ pín ilẹ̀ ọba rẹ̀ tí kò lágbára, tó sì jẹ́ ẹlẹgẹ́ níyà. Kí ọ̀ràn náà lè lójútùú, ó mú ẹ̀kọ́ ìsìn tuntun kan jáde, èyí tó pè ní Monothelitism. a Láti rí i dájú pé àwọn tó wà ní ìhà gúúsù ilẹ̀ ọba rẹ̀ fara mọ́ ọn, Heraclius yan bíṣọ́ọ̀bù tuntun ti Alẹkisáńdíríà, ìyẹn Kírúsì ti Phasis, tó fọwọ́ sí ẹ̀kọ́ tí olú ọba tì lẹ́yìn. Kì í ṣe bíṣọ́ọ̀bù nìkan ni olú ọba fi Kírúsì ṣe, àmọ́ ó tún fi ṣe alákòóso Íjíbítì pẹ̀lú, ó sì fún un ní ọlá àṣẹ lórí àwọn alákòóso àgbègbè yẹn. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó wà ní Íjíbítì ló fara mọ́ Kírúsì nígbà tó fínná mọ́ wọn díẹ̀.
Kò Bímọ Re
Báwo làwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí ṣe bá ọ̀rọ̀ àti ẹ̀mí tó wà nínú àdúrà Jésù mu, níbi tó ti sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun kò ní jẹ́ “apá kan ayé”?— Jòhánù 17:14-16.
Àwọn aṣáájú tó pera wọn ní Kristẹni ní àkókò àwọn ará Byzantium àti lẹ́yìn náà kò ṣàìjìyà lílọ́wọ́ tí wọ́n lọ́wọ́ sí ọ̀ràn ìṣèlú àti ọ̀ràn ogun ayé. Kí ni ìtàn tá a rọra gbé yẹ̀ wò yìí ń sọ fún ọ? Ǹjẹ́ àwọn aṣáájú Ṣọ́ọ̀ṣì ilẹ̀ ọba Byzantium rí ojú rere Ọlọ́run àti ti Jésù Kristi?—Jákọ́bù 4:4.
Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn wọ̀nyẹn tí ń dupò ọlá àtàwọn olóṣèlú tí wọ́n jọ lẹ̀dí àpò pọ̀ kò ṣe ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ ní oore kankan. Dída ìsìn pọ̀ mọ́ ìṣèlú lọ́nà àìmọ́ yìí ti gbé ìsìn mímọ́ gaara tí Jésù fi kọ́ni gbòdì pátápátá. Ǹjẹ́ kí a kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá, kí a má sì jẹ́ “apá kan ayé.”
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ohun tí Monothelitism fi kọ́ni ni pé bí Kristi tilẹ̀ jẹ́ Ọlọ́run àti ènìyàn, síbẹ̀ ọ̀kan ṣoṣo ni ìfẹ́ inú rẹ̀.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
‘BÍ ỌLỌ́RUN KAN TÓ Ń LA ÀWỌN Ọ̀RUN KỌJÁ’
Àwọn itú tí Bíṣọ́ọ̀bù Michael Cerularius (nǹkan bí 1000 sí 1059) pa jẹ́ àpẹẹrẹ ipa tí olórí ṣọ́ọ̀ṣì lè kó nínú ọ̀ràn Orílẹ̀-Èdè àti ọ̀ràn ipò dídù tó wé mọ́ ọn. Lẹ́yìn tí ọwọ́ Cerularius ti ba oyè bíṣọ́ọ̀bù tán, ó tún ń wá ipò tó ga ju ìyẹn lọ. Wọ́n ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni kan tó ń ṣakọ, tó jẹ́ ọ̀yájú, tó sì jẹ́ kìígbọ́-kìígbà—“ńṣe ni ìwà rẹ̀ dà bíi ti ọlọ́run kan tó ń la àwọn ọ̀run kọjá.”
Nítorí ìfẹ́ àtigbé ara rẹ̀ ga, Cerularius àti póòpù Róòmù lẹ̀dí àpò pọ̀ láti dá ìyapa sílẹ̀ ní 1054, wọ́n sì fagbára mú olú ọba láti tẹ́wọ́ gba ìpínyà náà. Nítorí pé inú Cerularius dùn sí ìṣẹ́gun yìí, ó ṣètò láti gbé Michael Kẹfà sórí ìtẹ́, ó sì fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀. Ọdún kan lẹ́yìn ìyẹn ni Cerularius lé olú ọba yẹn kúrò lórí ìtẹ́, tó sì gbé Isaac Comnenus (nǹkan bí 1005 sí 1061) gorí ìtẹ́.
Bí ìforígbárí tó wà láàárín bíṣọ́ọ̀bù àti ilẹ̀ ọba ṣe wá di ńlá nìyẹn. Cerularius—tó dá lójú pé àwọn èèyàn máa ti òun lẹ́yìn—halẹ̀, ó fagbára múni, ó sì wá bẹ̀rẹ̀ sí hùwà ipá. Òpìtàn kan tí wọ́n jọ gbáyé lákòókò kan náà sọ pé: “Ó fi ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìṣubú Olú Ọba, ó ní, ‘Èmi ni mo gbé ìwọ dìndìnrìn lásánlàsàn yìí dórí àlééfà; ṣùgbọ́n màá ba tìẹ jẹ́.’” Àmọ́, Isaac Comnenus ní kí wọ́n mú un, wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n, wọ́n sì lé e lọ sí erékùṣù Imbros.
Irú àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyẹn fi bí wàhálà tí bíṣọ́ọ̀bù Constantinople lè fà ṣe pọ̀ tó, àti bó ṣe lè yájú sí olú ọba tó. Olú ọba sábà máa ń fìyà jẹ irú àwọn ọkùnrin bẹ́ẹ̀, tí wọ́n jẹ́ ògbóǹtagí olóṣèlú, tó fojú di olú ọba àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun.
[Àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Ibi Tí Ilẹ̀ Ọba Byzantium Nasẹ̀ Dé
Ravenna
Róòmù
MAKEDÓNÍÀ
Constantinople
Òkun Dúdú
Niséà
Éfésù
Áńtíókù
Jerúsálẹ́mù
Alẹkisáńdíríà
Òkun Mẹditaréníà
[Credit Line]
Map: Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10, 11]
Comnenus
Romanus Kẹta (lápá òsì)
Michael Kẹrin
Ọbabìnrin Zoe
Romanus Kìíní (lápá òsì)
[Àwọn Credit Line]
Comnenus, Romanus Kẹta, àti Michael Kẹrin: Lọ́lá àṣẹ Classical Numismatic Group, Inc.; Ọbabìnrin Zoe: Hagia Sophia; Romanus Kìíní: Fọ́tò lọ́lá àṣẹ Harlan J. Berk, Ltd.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Photius
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Heraclius àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin
[Àwọn Credit Line]
Heraclius àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin: Fọ́tò lọ́lá àṣẹ Harlan J. Berk, Ltd.; gbogbo iṣẹ́ ọnà tó wà lójú ìwé 8-12: Láti inú ìwé L’Art Byzantin III Ravenne Et Pompose