Fífarada ‘Ẹ̀gún Nínú Ẹran Ara’
Fífarada ‘Ẹ̀gún Nínú Ẹran Ara’
“Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí mi ti tó fún ọ.”—2 KỌ́RÍŃTÌ 12:9.
1, 2. (a) Kí nìdí tí kò fi yẹ kó yà wá lẹ́nu pé à ń dojú kọ àdánwò àti ìṣòro? (b) Èé ṣe tí ọkàn wa fi lè balẹ̀ bí a tilẹ̀ wà nínú àdánwò?
“GBOGBO àwọn tí ń ní ìfẹ́-ọkàn láti gbé pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú Kristi Jésù ni a ó ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.” (2 Tímótì 3:12) Èé ṣe? Nítorí Sátánì ń jiyàn pé ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan ló ń sún wa sin Ọlọ́run. Ó sì ti ṣe tán láti fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tóun sọ yìí. Jésù kìlọ̀ nígbà kan rí fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́, pé: “Sátánì ti fi dandan béèrè láti gbà yín, kí ó lè kù yín bí àlìkámà.” (Lúùkù 22:31) Jésù kúkú mọ̀ pé Ọlọ́run máa ń gba Sátánì láyè nígbà míì láti fi àwọn ìṣòro líle dán wa wò. Àmọ́, ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé gbogbo ìṣòro tá a bá dojú kọ nínú ìgbésí ayé ló wá tààràtà látọ̀dọ̀ Sátánì tàbí látọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀. (Oníwàásù 9:11) Ṣùgbọ́n Sátánì kò kọ̀ láti lo gbogbo ohun tí ọwọ́ rẹ̀ bá bà láti fi ba ìwà títọ́ wa jẹ́.
2 Bíbélì sọ pé kí a má ṣe jẹ́ kí ó yà wá lẹ́nu pé à ń rí àdánwò. Kò sóhun tó ṣàjèjì tàbí tó jẹ́ àìròtẹ́lẹ̀ nínú ohun yòówù tó lè dé bá wa. (1 Pétérù 4:12) Ní tòótọ́, “àwọn ohun kan náà ní ti ìyà jíjẹ ní ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará [wa] nínú ayé.” (1 Pétérù 5:9) Lónìí, Sátánì ń fínná mọ́ gbogbo ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Inú Èṣù máa ń dùn nígbà tó bá rí i pé ọ̀pọ̀ ìṣòro tí ń gúnni lára bí ẹ̀gún ń dá wa lóró. Fún ìdí yìí, ó máa ń lo ètò àwọn nǹkan rẹ̀ lọ́nà tí yóò fi pa kún àwọn ‘ẹ̀gún tó wà nínú ẹran ara wa.’ (2 Kọ́ríńtì 12:7) Síbẹ̀síbẹ̀, a lè borí ogun Sátánì. Gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti ń “ṣe ọ̀nà àbájáde” fún wa kí a lè fara da ìdẹwò, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò ṣe ọ̀nà àbájáde fún wa nígbà tá a bá dojú kọ àwọn wàhálà tó dà bí ẹ̀gún nínú ẹran ara wa.—1 Kọ́ríńtì 10:13.
Bá A Ṣe Lè Fara Da Ẹ̀gún
3. Kí ni Jèhófà fi dá Pọ́ọ̀lù lóhùn nígbà tó rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà pé kó mú ẹ̀gún náà kúrò lára òun?
3 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù bẹ Ọlọ́run pé kí ó mú ẹ̀gún náà kúrò lára òun. “Nítorí èyí, ìgbà mẹ́ta ni mo pàrọwà sí Olúwa pé kí ó lè kúrò lára mi.” Kí ni Jèhófà fi dá Pọ́ọ̀lù lóhùn ẹ̀bẹ̀ rẹ̀? “Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí mi ti tó fún ọ; nítorí agbára mi ni à ń sọ di pípé nínú àìlera.” (2 Kọ́ríńtì 12:8, 9) Ẹ jẹ́ ká gbé ìdáhùn yìí yẹ̀ wò, ká sì wo bó ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro èyíkéyìí tó bá ń gún wa lára bí ẹ̀gún.
4. Ní àwọn ọ̀nà wo ni Pọ́ọ̀lù gbà jàǹfààní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà?
4 Ṣàkíyèsí pé Ọlọ́run sọ fún Pọ́ọ̀lù pé kí ó mọyì inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí òun ti nawọ́ rẹ̀ sí i nípasẹ̀ Kristi. Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ ìbùkún ni Pọ́ọ̀lù ti rí gbà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àtakò burúkú ló ń gbé ko àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tẹ́lẹ̀, Jèhófà fi tìfẹ́tìfẹ́ fún un láǹfààní dídi ọmọlẹ́yìn Jésù. (Ìṣe 7:58; 8:3; 9:1-4) Lẹ́yìn náà ni Jèhófà ṣojú àánú sí Pọ́ọ̀lù nípa fífún un ní ọ̀pọ̀ àǹfààní kíkọyọyọ. Ẹ̀kọ́ ńlá ni èyí jẹ́ fún wa. Kódà nígbà ìṣòro, a ṣì ní ọ̀pọ̀ ìbùkún tá a lè máa dúpẹ́ fún. A kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àdánwò mú wa gbàgbé ọ̀pọ̀ oore tí Jèhófà ṣe fún wa.—Sáàmù 31:19.
5, 6. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe kọ́ Pọ́ọ̀lù pé agbára Ọlọ́run máa ń di èyí tí a “sọ di pípé nínú àìlera”? (b) Báwo ni àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì?
5 Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà tún pọ̀ yanturu lọ́nà mìíràn. Agbára Ọlọ́run pọ̀ débi pé ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn àdánwò wa. (Éfésù 3:20) Jèhófà kọ́ Pọ́ọ̀lù pé agbára Òun máa ń di èyí tí a “sọ di pípé nínú àìlera.” Lọ́nà wo? Ó fi tìfẹ́tìfẹ́ fún Pọ́ọ̀lù ní gbogbo okun tó nílò láti fi kojú àdánwò rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ìfaradà àti ìgbẹ́kẹ̀lé pátápátá tí Pọ́ọ̀lù ní nínú Jèhófà jẹ́ kí gbogbo àwa Kristẹni rí i pé agbára Ọlọ́run borí nínú ọ̀ràn ọkùnrin aláìlera àti ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí. Wàyí o, ronú nípa bí èyí ṣe máa rí lára Èṣù, tó sọ pé ìgbà tá a bá wà nínú ìdẹ̀ra, tí nǹkan rọgbọ nìkan la lè sin Ọlọ́run. Ìwà títọ́ Pọ́ọ̀lù mú kí ẹnu òpùrọ́ yẹn wọhò!
6 Ṣebí Pọ́ọ̀lù rèé, tó jẹ́ agbódegbà Sátánì tẹ́lẹ̀ nínú ìjà tó ń bá Ọlọ́run jà, Pọ́ọ̀lù tó ń ṣe inúnibíni gbígbóná janjan sáwọn Kristẹni tẹ́lẹ̀ rí, tó jẹ́ Farisí onítara, tó jẹ́ pé ilé ọlá la bí i sí. Pọ́ọ̀lù ọ̀hún ló wá dẹni tó ń sin Jèhófà àti Kristi báyìí gẹ́gẹ́ bí ẹni tó “kéré jù lọ nínú àwọn àpọ́sítélì.” (1 Kọ́ríńtì 15:9) Ó sì ń fi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ tẹrí ba fún ọlá àṣẹ àwọn Kristẹni tí í ṣe ẹgbẹ́ olùṣàkóso ọ̀rúndún kìíní. Ó tún ń fi ìṣòtítọ́ fara dà á nìṣó láìfi ẹ̀gún tó wà nínú ẹran ara rẹ̀ pè. Ìtìjú gbáà ló jẹ́ fún Sátánì pé gbogbo àdánwò tó bá Pọ́ọ̀lù kò paná ìtara rẹ̀. Pọ́ọ̀lù kò fìgbà kan gbàgbé pé òun yóò kópa nínú Ìjọba ọ̀run ti Kristi. (2 Tímótì 2:12; 4:18) Kò sí ẹ̀gún náà, bó ti wù kó máa gún un lára tó, tó lè dín ìtara rẹ̀ kù. Ǹjẹ́ kí ìtara àwa náà máa gbóná bí ìyẹn! Nípa mímú ẹsẹ̀ wa dúró nígbà àdánwò, Jèhófà ń buyì kún wa nípa fífún wa ní àǹfààní láti fi Sátánì hàn ní òpùrọ́.—Òwe 27:11.
Àwọn Ìpèsè Jèhófà Ṣe Kókó
7, 8. (a) Kí ni Jèhófà ń lò láti fi fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lágbára lóde òní? (b) Kí nìdí tí kíka Bíbélì àti kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lójoojúmọ́ fi ṣe pàtàkì gan-an láti lè fara da ẹ̀gún nínú ẹran ara wa?
7 Àwọn nǹkan tí Jèhófà ń lò lóde òní láti fi fún àwọn Kristẹni olóòótọ́ lágbára ni ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ẹgbẹ́ àwọn ará tó jẹ́ Kristẹni. Àwa náà lè ṣe bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ká ju ẹrù wa sọ́dọ̀ Jèhófà nínú àdúrà. (Sáàmù 55:22) Òótọ́ ni pé Ọlọ́run lè ṣàì mú àwọn àdánwò wa kúrò, síbẹ̀ ó lè fún wa ní ọgbọ́n tí a óò fi máa bá wọn yí, kódà àwọn èyí tó ṣòroó forí tì pàápàá. Jèhófà tún lè fún wa ní okun inú—ìyẹn “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá”—kí a lè fara dà á.—2 Kọ́ríńtì 4:7.
8 Báwo la ṣe lè rí irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ gbà? A gbọ́dọ̀ máa fi tọkàntọkàn kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, torí pé ibẹ̀ la ó ti rí ìtùnú tó dájú gbà látọ̀dọ̀ rẹ̀. (Sáàmù 94:19) Nínú Bíbélì, a máa ń ka àwọn ọ̀rọ̀ wíwọnilọ́kàn tó tẹnu àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run jáde, bí wọ́n ṣe ń bẹ̀ ẹ́ pé kí ó ran àwọn lọ́wọ́. Èsì tí Jèhófà máa ń fún wọn, tó sábà máa ń ní ọ̀rọ̀ ìtùnú nínú, jẹ́ ohun tó yẹ fún ṣíṣe àṣàrò lé lórí. Ìkẹ́kọ̀ọ́ yóò fún wa lókun kí “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá lè jẹ́ ti Ọlọ́run, kí ó má sì jẹ́ èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ àwa fúnra wa jáde.” Gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe pàtàkì láti máa jẹ oúnjẹ nípa tara lójoojúmọ́ ká lè ní okun àti agbára, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ ká máa fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bọ́ ara wa déédéé. Ǹjẹ́ à ń ṣe bẹ́ẹ̀? Bá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a óò rí i pé “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” tí à ń rí gbà ló ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti fara da ẹ̀gún ìṣàpẹẹrẹ yòówù tó lè máa gún wa lára lónìí.
9. Báwo làwọn alàgbà ṣe lè jẹ́ alátìlẹyìn fún àwọn tó ń bá òkè ìṣòro yí?
9 Àwọn Kristẹni alàgbà tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run lè jẹ́ “ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù” hílàhílo, wọ́n sì lè jẹ́ “ibi ìlùmọ́ kúrò lọ́wọ́ ìjì” wàhálà. Àwọn alàgbà tó fẹ́ mú ara wọn bá àpèjúwe onímìísí yẹn mu máa ń fi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ àti tòótọ́-tòótọ́ bẹ Jèhófà pé kí ó fún àwọn ní “ahọ́n àwọn tí a kọ́,” kí àwọ́n lè mọ irú ọ̀rọ̀ ìtùnú tó yẹ káwọn sọ fáwọn tí ìpọ́njú dé bá. Ọ̀rọ̀ àwọn alàgbà lè dà bí òjò winniwinni tó ń tu ọkàn wa lára nígbà tíná bá jó dóríi kókó. Nípa sísọ̀rọ̀ “ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́,” ńṣe làwọn alàgbà ń fi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí alátìlẹyìn àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn nípa tẹ̀mí, tó ṣeé ṣe kí àárẹ̀ mú tàbí tí wọ́n soríkọ́ nítorí ẹ̀gún kan nínú ẹran ara wọn.—Aísáyà 32:2; 50:4; 1 Tẹsalóníkà 5:14.
10, 11. Báwo ni àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣe lè fún àwọn tí ń fojú winá àdánwò mímúná níṣìírí?
10 Gbogbo ìránṣẹ́ Jèhófà ló jẹ́ ara ìdílé Kristẹni tó wà níṣọ̀kan. Bẹ́ẹ̀ ni o, gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ‘jẹ́ ti ara wa lẹ́nì kìíní-kejì,’ a sì “wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe láti nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.” (Róòmù 12:5; 1 Jòhánù 4:11) Báwo la ṣe ń ṣe ojúṣe yìí? Gẹ́gẹ́ bí 1 Pétérù 3:8 ti wí, à ń ṣe ojúṣe yìí nípa fífi ‘ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì hàn, nípa níní ìfẹ́ni ará, àti nípa fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn’ sí gbogbo àwọn tó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́. Gbogbo wa ló yẹ ká máa ṣaájò àwọn tó ń fara da ẹ̀gún tí ń roni lára gógó, wọn ì báà jẹ́ ọ̀dọ́ tàbí àgbàlagbà. Lọ́nà wo?
11 Kò yẹ ká fojú kékeré wo ìyà tó ń jẹ wọ́n rárá. Bí a bá ń ṣe bíi pé ọ̀ràn wọn ò kàn wá, tàbí tí a kò bìkítà, tàbí tí a kò kọbi ara sí wọn, a lè máa dá kún ìṣòro wọn láìmọ̀. Mímọ̀ tí a mọ àwọn àdánwò tí wọ́n ń bá yí, á jẹ́ ká ṣọ́ irú ọ̀rọ̀ tí a ó sọ sí wọn àti bí a ó ṣe sọ ọ́ àti irú ìgbésẹ̀ tí a óò gbé. Níní ẹ̀mí rere àti fífún wọn níṣìírí lè pẹ̀rọ̀ sí ìrora gógó ẹ̀gún tó ń gún wọn lára. A lè tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ àrànṣe afúnnilókun fún wọn.—Kólósè 4:11.
Bí Àwọn Kan Ṣe Fara Dà Á Láìjuwọ́sílẹ̀
12-14. (a) Kí ni Kristẹni kan ṣe láti kojú àrùn jẹjẹrẹ? (b) Báwo làwọn arákùnrin àti arábìnrin nípa tẹ̀mí ṣe dúró ti obìnrin yìí, tí wọ́n sì fún un níṣìírí?
12 Bí a ti ń sún mọ́ òpin ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí ni “ìroragógó wàhálà” ń pọ̀ sí i lójoojúmọ́. (Mátíù 24:8) Fún ìdí yìí, ó jọ pé ńṣe ni àdánwò á máa pọ̀ sí i fún kálukú, àgàgà àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà, tó ń sapá láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀ràn ti Kristẹni kan tó wà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún yẹ̀ wò. Àyẹ̀wò fi hàn pé ó ní àrùn jẹjẹrẹ. Ó sì di dandan kí wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ fún un láti gé ibi tí itọ́ àti àwọn omi ara kan ti ń sun jáde kúrò. Nígbà tóun àti ọkọ rẹ̀ gbọ́ pé àìsàn tó ń bá a jà nìyẹn, ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n tọ Jèhófà lọ nínú àdúrà gígùn, tí wọ́n rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí i. Obìnrin náà sọ lẹ́yìn náà pé ńṣe ni ọkàn àwọn wá balẹ̀ pẹ̀sẹ̀. Àmọ́, ó tún ní láti fara da onírúurú ìṣòro tó yọjú, pàápàá jù lọ àwọn ìṣòro tí àwọn oògùn tó ń lò ń fà.
13 Láti lè fara da ìṣòro yìí, arábìnrin yìí gbìyànjú láti mọ gbogbo nǹkan tó lè mọ̀ nípa àrùn jẹjẹrẹ. Ó lọ bá àwọn dókítà rẹ̀ sọ̀rọ̀. Ó ka ìrírí àwọn èèyàn nínú Ilé Ìṣọ́, Jí!, àtàwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni mìíràn, èyí tó ṣàlàyé bí àwọn kan ṣe kojú àìsàn yìí. Ó tún ka àwọn ìtàn kan nínú Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe mẹ́sẹ̀ àwọn èèyàn rẹ̀ dúró nígbà ìṣòro, ó sì tún ṣàyẹ̀wò àwọn ìsọfúnni mìíràn tó wúlò.
14 Àpilẹ̀kọ kan tó sọ̀rọ̀ nípa kíkojú àìnírètí tọ́ka sí ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n yìí, pé: “Ẹni tí ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ yóò máa wá ìyánhànhàn onímọtara-ẹni-nìkan.” (Òwe 18:1) Àpilẹ̀kọ náà wá fúnni ní ìmọ̀ràn yìí: “A kò gbọ́dọ̀ máa ya ara wa sọ́tọ̀.” a Arábìnrin yìí ṣàlàyé pé: “Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sọ fún mi pé àwọn ń gbàdúrà fún mi; àwọn míì ń fóònù mi. Àwọn alàgbà méjì ń fóònù mi déédéé láti mọ bí mo ṣe ń ṣe sí. Àìmọye òdòdó àti káàdì kára-ó-le ni mo rí gbà. Àwọn kan tiẹ̀ ṣoúnjẹ wá. Bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀pọ̀ yọ̀ǹda láti gbé mi lọ síbi tí mo ti ń gba ìtọ́jú.”
15-17. (a) Báwo ni Kristẹni kan ṣe kojú ìṣòro tó dìde nítorí jàǹbá ọkọ̀? (b) Ìtìlẹyìn wo làwọn ará ìjọ ṣe?
15 Ìránṣẹ́ Jèhófà kan tó ti ń sìn ín tipẹ́tipẹ́ nílùú New Mexico, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, bá ara rẹ̀ nínú jàǹbá ọkọ̀ lẹ́ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ó fi ọrùn àti èjìká ṣèṣe, èyí sì wá dá kún àrùn oríkèé-ara-ríro tó ti ń bá yí fún ohun tó lé ní ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n. Obìnrin náà ṣàlàyé pé: “Àtigbé orí sókè ń ni mí lára gan-an. Mi ò lè gbé ohunkóhun tó wúwo ju kìlógíráàmù méjì. Ṣùgbọ́n àdúrà àtọkànwá sí Jèhófà ti mẹ́sẹ̀ mi dúró gbọn-in. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn àpilẹ̀kọ tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú Ilé Ìṣọ́. Àpilẹ̀kọ kan sọ̀rọ̀ lórí Míkà 6:8, ó sì ṣàlàyé pé jíjẹ́ ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rìn túmọ̀ sí mímọ̀wọ̀n ara ẹni. Èyí jẹ́ kí n mọ̀ pé nínú ipòkípò tí mo bá wà, kò yẹ kí n rẹ̀wẹ̀sì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò lè ṣe tó bí mo ṣe fẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà mọ́. Fífi tọkàntọkàn sin Jèhófà lohun tó jà jù.”
16 Obìnrin náà tún sọ pé: “Ìgbà gbogbo làwọn alàgbà máa ń yìn mí fún ìsapá mi láti wá sípàdé àti láti jáde òde ẹ̀rí. Àwọn ọ̀dọ́ máa ń gbá mi mọ́ra. Àwọn aṣáájú ọ̀nà máa ń mú sùúrù fún mi gan-an, wọ́n sì máa ń yíwọ́ padà láwọn ọjọ́ tí wọ́n bá rí i pé àìsàn náà kì mí mọ́lẹ̀. Lọ́jọ́ tí ojú ọjọ́ ò bá dára, wọ́n á rọra mú mi jáde fún ìpadàbẹ̀wò tàbí kí wọ́n ní kí n jókòó ti àwọn nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn. Níwọ̀n bí mi ò sì ti lè gbé àpò òde ẹ̀rí, àwọn akéde mìíràn máa ń fi ìwé tí màá lò sínú àpò tiwọn nígbà tí mo bá jáde òde ẹ̀rí.”
17 Ṣàkíyèsí bí àwọn alàgbà ìjọ àtàwọn akéde ṣe ran àwọn arábìnrin méjèèjì yìí lọ́wọ́ láti kojú àìlera tó ń gún wọn lára bí ẹ̀gún. Wọ́n ń ṣe ìrànlọ́wọ́ gidi, tó jẹ́ ti inú rere fún wọn, tó jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wọn láti máa ṣe dáadáa nípa tẹ̀mí, nípa tara àti nípa ti ìmí ẹ̀dùn. Ǹjẹ́ ìyẹn ò fún ọ níṣìírí láti máa ran àwọn ará mìíràn tó níṣòro lọ́wọ́? Ẹ̀yin ọ̀dọ́ pàápàá lè ṣèrànwọ́ fún àwọn ará ìjọ yín tó ń fara da ẹ̀gún nínú ẹran ara wọn.—Òwe 20:29.
18. Ìṣírí wo la lè rí nínú àwọn ìtàn ìgbésí ayé tá à ń tẹ̀ jáde nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí!?
18 Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ti tẹ ọ̀pọ̀ ìtàn ìgbésí ayé àti ìrírí jáde, nípa àwọn Ẹlẹ́rìí tó ti forí ti onírúurú ìṣòro nínú ìgbésí ayé wọn, tí wọ́n ṣì ń forí tì í di bá a ti ń sọ̀rọ̀ yìí. Bó o ṣe ń ka irú àpilẹ̀kọ bẹ́ẹ̀ déédéé, wàá rí i pé ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ nípa tẹ̀mí kárí ayé ló ti fara da ìṣòro ìṣúnná owó àti ikú olólùfẹ́ nígbà àjálù, àtàwọn ipò eléwu tó ń dìde lákòókò ogun. Àwọn míì lára wọn ló ń bá àìsàn tí ń sọni di akúrẹtẹ̀ yí. Ọ̀pọ̀ ni kò lè ṣe àwọn iṣẹ́ tí àwọn tí ara wọn le máa ń ṣe wẹ́rẹ́. Àìsàn wọn máa ń dán wọn wò dé góńgó, àgàgà nígbà tí wọn ò bá lè kópa nínú ìgbòkègbodò Kristẹni bí wọ́n ṣe fẹ́. Ẹ wo bí wọ́n ṣe ń mọrírì ìrànlọ́wọ́ àti ìtìlẹyìn tí àwọn ará, lọ́mọdé lágbà, ń ṣe fún wọn!
Ìfaradà Ń Máyọ̀ Wá
19. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi láyọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àdánwò àti àìlera tó dà bí ẹ̀gún ń bá a fínra?
19 Inú Pọ́ọ̀lù dùn nígbà tó rí i bí Ọlọ́run ṣe fún òun lókun. Ó sọ pé: “Ṣe ni èmi yóò kúkú máa fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ gan-an ṣògo nípa àwọn àìlera mi, kí agbára Kristi lè wà lórí mi bí àgọ́. Nítorí náà, mo ní ìdùnnú nínú àwọn àìlera, nínú àwọn ìwọ̀sí, nínú àwọn ọ̀ràn àìní, nínú àwọn inúnibíni àti àwọn ìṣòro, fún Kristi. Nítorí nígbà tí èmi bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.” (2 Kọ́ríńtì 12:9, 10) Nítorí àwọn nǹkan tójú Pọ́ọ̀lù alára rí, ó fi ìdánilójú sọ pé: “Kì í ṣe pé mò ń sọ̀rọ̀ nípa wíwà nínú àìní, nítorí mo ti kẹ́kọ̀ọ́, nínú àwọn ipò yòówù tí mo bá wà, láti máa ní ẹ̀mí ohun-moní-tómi. Ní tòótọ́, mo mọ bí a ṣe ń wà pẹ̀lú àwọn ìpèsè bín-ín-tín, ní tòótọ́ mo mọ bí a ṣe ń ní ọ̀pọ̀ yanturu. Nínú ohun gbogbo àti nínú ipò gbogbo, mo ti kọ́ àṣírí bí a ti ń jẹ àjẹyó àti bí a ti ń wà nínú ebi, bí a ti ń ní ọ̀pọ̀ yanturu àti bí a ti ń jẹ́ aláìní. Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.”—Fílípì 4:11-13.
20, 21. (a) Kí nìdí tá a fi lè láyọ̀ tá a bá ń ṣàṣàrò lórí “àwọn ohun tí a kò rí”? (b) Kí ni díẹ̀ lára “àwọn ohun tí a kò rí” tí wàá fẹ́ rí nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé?
20 Nítorí náà, nípa fífarada ẹ̀gún ìṣàpẹẹrẹ yòówù tó bá ń gún wa lára, a ó fi tayọ̀tayọ̀ mú un ṣe kedere sí gbogbo èèyàn pé agbára Jèhófà ń di pípé nínú àìlera wa. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Àwa kò juwọ́ sílẹ̀ . . . Dájúdájú, ẹni tí àwa jẹ́ ní inú ni à ń sọ dọ̀tun láti ọjọ́ dé ọjọ́. Nítorí bí ìpọ́njú náà tilẹ̀ jẹ́ fún ìgbà díẹ̀, tí ó sì fúyẹ́, fún àwa, ó ń ṣiṣẹ́ yọrí sí ògo tí ó jẹ́ ti ìwọ̀n títayọ síwájú àti síwájú sí i, tí ó sì jẹ́ àìnípẹ̀kun; nígbà tí àwa . . . tẹ ojú wa mọ́ . . . àwọn ohun tí a kò rí. Nítorí . . . àwọn ohun tí a kò rí jẹ́ fún àìnípẹ̀kun.”—2 Kọ́ríńtì 4:16-18.
21 Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn Jèhófà lóde òní ló ní ìrètí àtigbé nínú Párádísè rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé, kí wọ́n sì máa gbádùn àwọn ìbùkún tó ti ṣèlérí. A lè sọ pé “àwọn ohun tí a kò rí” ni irú ìbùkún yẹn jẹ́ lónìí. Àmọ́, àkókò náà tí a ó fi ojú ara wa rí ìbùkún wọ̀nyẹn, àní tí a óò máa gbádùn wọn títí láé, ti kù sí dẹ̀dẹ̀ báyìí. Ọ̀kan lára irú ìbùkún bẹ́ẹ̀ ni bíbọ́ lọ́wọ́ ìṣòro èyíkéyìí tí ń gúnni lára bí ẹ̀gún! Ọmọ Ọlọ́run yóò “fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú,” yóò sì “sọ ẹni tí ó ní ọ̀nà àtimú ikú wá di asán.”—1 Jòhánù 3:8; Hébérù 2:14.
22. Ìdánilójú àti ìpinnu wo ló yẹ ká ní?
22 Nítorí náà, ẹ̀gún yòówù kí ó máa gún wa lára lónìí, ẹ jẹ́ ká máa fara dà á nìṣó. Gẹ́gẹ́ bíi Pọ́ọ̀lù, a óò lè fara dà á, nípasẹ̀ Jèhófà, ẹni tí ń fún wa lágbára lọ́pọ̀lọpọ̀. Nígbà tá a bá dénú Párádísè orí ilẹ̀ ayé náà, a óò máa fi ìbùkún fún Jèhófà Ọlọ́run wa lójoojúmọ́ nítorí àwọn ohun àgbàyanu tó ń ṣe fún wa.—Sáàmù 103:2.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ náà, “Ojú Ìwòye Bíbélì: Bí A Ṣe Lè Kápá Àìnírètí,” nínú ìtẹ̀jáde Jí! ti May 8, 2000.
Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?
• Èé ṣe tí Èṣù fi máa ń gbìyànjú láti ba ìwà títọ́ àwọn Kristẹni tòótọ́ jẹ́, ọ̀nà wo ló sì ń gbà?
• Báwo la ṣe ń sọ agbára Jèhófà “di pípé nínú àìlera”?
• Báwo làwọn alàgbà àtàwọn mìíràn ṣe lè máa fún àwọn tó ń fojú winá ìṣòro níṣìírí?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Pọ́ọ̀lù gbàdúrà pé kí Ọlọ́run mú ẹ̀gún náà kúrò lára òun