Ibi Ìfarapamọ́sí Kúrò Lọ́wọ́ Ẹ̀fúùfù
Ibi Ìfarapamọ́sí Kúrò Lọ́wọ́ Ẹ̀fúùfù
O LÈ rí àwọn òdòdó róòsì tó rọ́kú lórí àwọn òkè ńlá tó kún fún àpáta págunpàgun ní Yúróòpù. Àwọn ewéko kúńtá wọ̀nyí sábà máa ń ṣù pọ̀, kí ìjì ẹ̀fúùfù orí òkè má bàa gbé wọn lọ. Ẹ̀fúùfù tí kì í jẹ́ kí ewéko wọ̀nyí gbádùn máa ń jẹ́ kí àyíká tutù mọ́ wọn lára, kí afẹ́fẹ́ àti ilẹ̀ sì gbẹ táútáú, ó sì ń fẹ́ erùpẹ̀ kúrò nídìí gbòǹgbò wọn.
Ohun tó sábà máa ń jẹ́ kí òdòdó róòsì orí òkè yìí yè é ni pé pàlàpálá àpáta ló máa ń hù sí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iyẹ̀pẹ̀ lè má pọ̀ níbẹ̀, àárín àpáta tó wà kì í jẹ́ kí ẹ̀fúùfù gbá a lọ, kì í sì í jẹ́ kí omi gbẹ́ mọ ọ́n lára. Níwọ̀n bí ó ti sábà máa ń fara sin ní àkókò tó pọ̀ jù lọ láàárín ọdún, òdòdó yìí máa ń yọ ìtànná pupa yòò lórí òkè nígbà tí ẹ̀ẹ̀rùn bá dé.
Wòlíì Aísáyà ṣàlàyé pé Ọlọ́run yóò yan “àwọn ọmọ aládé,” tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n á jẹ́ “ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù.” (Aísáyà 32:1, 2) Lábẹ́ ìdarí Kristi Jésù, Ọba náà, àwọn ọmọ aládé tẹ̀mí wọ̀nyí, ìyẹn àwọn alábòójútó, yóò dà bí àpáta gàǹgà, atóófaratì lọ́jọ́ ìpọ́njú tàbí lọ́jọ́ wàhálà. Wọ́n á pèsè ààbò tó dájú nígbà yánpọnyánrin, wọ́n á sì ran àwọn aláìní lọ́wọ́ kí omi tẹ̀mí tí wọ́n ń rí látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run má bàa gbẹ.
Ìjì inúnibíni, ìrẹ̀wẹ̀sì, tàbí àìlera lè rọ́ lu Kristẹni kan, kí ó sì fa ìgbàgbọ́ rẹ̀ gbẹ, bí kò bá ríbi fara pa mọ́ sí. Àwọn Kristẹni alàgbà lè pèsè ààbò nípa fífarabalẹ̀ fetí sí ìṣòro rẹ̀, kí wọ́n fún un nímọ̀ràn látinú Bíbélì, kí wọ́n sì fún un níṣìírí tàbí ìrànlọ́wọ́ tó gbéṣẹ́. Gẹ́gẹ́ bíi Kristi Jésù, Ọba wọn tí ń jọba, wọ́n máa ń fẹ́ ṣèrànwọ́ fún àwọn tí a ‘fọ́n ká.’ (Mátíù 9:36) Wọ́n sì máa ń fẹ́ ṣèrànwọ́ fún àwọn tí ẹ̀fúùfù ẹ̀kọ́ èké ti pa lára. (Éfésù 4:14) Ṣíṣe irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ lákòókò tá a nílò rẹ̀ gan-an ṣe pàtàkì.
Miriam ṣàlàyé pé: “Ayé sú mi pátápátá nígbà tí ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ kan kúrò nínú òtítọ́. Ó tún wá lọ jẹ́ pé àkókò náà ni ẹ̀jẹ̀ ń dà ní ọpọlọ bàbá mi. Kí n lè ṣẹ́pá ìsoríkọ́ náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí bá ọkùnrin kan tó jẹ́ ẹni ti ayé rìn. Láìpẹ́ lẹ́yìn ìgbà yẹn ni mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í wo ara mi gẹ́gẹ́ bí ẹni tí kò wúlò. Ìyẹn ló jẹ́ kí n sọ fáwọn alàgbà ìjọ pé mo ti pinnu láti kúrò nínú òtítọ́, níwọ̀n bó ti dá mi lójú pé Jèhófà kò lè nífẹ̀ẹ́ mi.
“Ní àkókò wàhálà yìí ni alàgbà oníyọ̀ọ́nú kan rán mi létí ọ̀pọ̀ ọdún tí mo fi sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé. Ó sọ fún mi pé gbogbo ìgbà tóun bá rí mi ni orí òun máa ń wú nítorí ìṣòtítọ́ mi. Ó fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ sọ pé kí n jẹ́ kí àwọn alàgbà ràn mí lọ́wọ́. Ó fi mí lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà ṣì nífẹ̀ẹ́ mi. Ìfẹ́ àtọkànwá tí wọ́n fi hàn sí mi ní àkókò lílekoko yẹn dà bí ‘ibi ìfarapamọ́sí’ fún mi ní àkókò tí ìjì tẹ̀mí fẹ́ gbé mi lọ. Mo fòpin sí àjọṣe àárín èmi àti ọ̀rẹ́ mi ọkùnrin náà láàárín oṣù kan. Mo ti ń tẹ̀ síwájú ní ọ̀nà òtítọ́ látìgbà yẹn.”
Inú àwọn alàgbà máa ń dùn pé iṣẹ́ àwọn ò já sásán nígbà tí wọ́n bá rí i tí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, nítorí ààbò tí wọ́n ń pèsè nígbà ìṣòro. Bẹ́ẹ̀, kékeré lèyí jẹ́ lára ọ̀pọ̀ ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí tí àwọn “ibi ìfarapamọ́sí” wọ̀nyí yóò ṣe fún wa nígbà Ẹgbẹ̀rúndún Ìṣàkóso Kristi.